Tayọ ní ìlawọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 07, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 32

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu ayọ akunwọsilẹ ninu gbogbo ọsẹ naa, ni orukọ Jesu Oluwa wa. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ wọnyi lati ọdọ Pọọlu si awọn ijọ Korinti:

“Ṣugbọn bi ẹnyin ti pọ̀ li ohun gbogbo, ni igbagbọ́, ati ọ̀rọ, ati ìmọ, ati ninu igbiyanjú gbogbo, ati ni ifẹ nyin si wa, ẹ kiyesi ki ẹnyin ki o pọ̀ ninu ẹbun ọfẹ yi pẹlu.” (2Kọ́ríntì 8:7)

Njẹ o ri bayẹn? Pọọlu fẹ ki awọn ọmọ ijọ Kọrinti tayọ ninu ilawọ, bi wọn ti ṣe tayọ ninu igbagbọ, imọ, itara ati ifẹ. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wọn lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Ekeji, o ni lati jẹ wipe wọn ti wa lẹyin awọn ijọ Ọlọrun yoku ninu ilawọ ni asiko yi. Ẹkẹta, idi ni pe ko fẹ ki wọn padanu awọn ere ti o sorọ mọ lilawọ.

Wayi o, ṣe a tilẹ ri awọn ere ti o sorọ mọ ilawọ nitootọ? Bẹẹni! Ọkan lara wọn si ni pe o le jẹ ki awọn eniyan dide nitori rẹ, nigba ti o ko tilẹ lero rẹ. Fun apẹrẹ, bibeli sọ fun wa nipa asiko kan ti awọn adari Juu kan lọ ṣipẹ si Jesu lati wa wo iransẹ Balogun Ọrun Roomu kan san. Ki si ni idi ti wọn ṣe dide nitori ọkunrin yi lati ba Jesu sọrọ, bi o tilẹ jẹ wipe keferi ni ọkunrin naa? Idi ni pe ọkunrin yi tayọ ninu ilawọ rẹ si wọn. O kọ sinagọgu kan fun wọn. Nitorina, wọn ko kan le joko tẹtẹrẹ, ki wọn si maa woran titi ọkunrin yi yoo fi padanu iranṣẹ rẹ ti o ṣe iyebiye si. Ṣe Jesu wa da wọn lohun tabi ko da wọn lohun? O da wọn lohun. (Wo: Lúùkù 7:1-10)

Lafikun, a tun sọ fun wa ninu bibeli nipa arabinrin kan ti a n pe ni Dọ́kàsì ati nipa bi o ti ṣe ṣaisan, ti o si ku. Ṣe awọn ọmọ ijọ rẹ wa gba iku rẹ bi amuwa Ọlọrun? Rara o! Dipo eyi, nṣe ni wọn ran lara wọn lati lọ pe Peteru wa lati gbadura fun un. Ki ni idi? Idi ni pe o tayọ ninu ilawọ rẹ. O ti ran ọpọlọpọ ninu ijọ yi, paapaa julọ awọn opo, lọwọ ṣaaju iku rẹ. Ṣe Peteru wa jẹ ipe wọn tabi ko jẹ? O jẹ ẹ. Nitorina, a mu Dọ́kàsí pada saye lati tẹsiwaju lati maa jẹ olubukun fun awọn ti o wa ni ayika rẹ. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 9;36-43)

Nibakana, awọn igba miran ma n wa ti yoo ya wa lẹnu lati ri awọn iransẹ Ọlọrun kan ti wọn yoo fi ohun gbogbo ti wọn n ṣe silẹ lati lọ gbadura fun awọn eniyan kan tabi lati wa ni awọn ayẹyẹ wọn. Diẹ lara wa tilẹ le ro wipe ainikanṣe ni o n fa eyi tabi ifarahan ojuṣaaju. Ṣugbọn ọpọ igba ni o jẹ wipe ilawọ awọn ti ọrọ kan ni o ṣe okunfa nkan ti a n ri yi. Ṣe awa naa ko ki wa mu ni pataki awọn ti o ba lawọ si wa? Ṣe a ki tilẹ nigba miran fi ohun gbogbo ti a n ṣe silẹ lati kan ran wọn lọwọ tabi lati ṣe nkankan lati mu inu wọn dun?

Ṣe o wa ri bayi pe o dara lati tayọ ni ilawọ. Nitorina, ma jẹ ki ilawọ rẹ si awọn eniyan, paapaa julọ awọn eniyan Ọlọrun, jẹ ẹkọọkan. Dipo eyi, jẹ ki o jẹ nkan ti gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ yoo mọ ọ si. Ọjọ kan si n bọ, nigba ti o ko tile lero rẹ rara, ti yoo jẹ ki awọn eniyan dide lati ṣoore fun ọ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *