Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapda wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ akọkọ ninu oṣu Ọ̀wàrà 2026. Adura mi si nipe nibikibi ti o ba lọ Ọlọrun ko ni jẹ ki o lugbadi ẹtan awọn oniwaasu eke awọn ọjọ ikẹyin wọnyi. Amin.
Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, awọn ọjọ ikẹyin yi jẹ awọn ọjọ ninu eyi ti a o ri ọpọ eke oniwaasu. Awọn wọnyi si ni eṣu yoo ma a lo lati tan ọpọ eniyan jẹ ati lati dari wọn kuro ninu otitọ. Nitorina, a fun wa ni awọn aṣẹ wọnyi ninu bibeli lori wọn:
“Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn…” (Mátíù 7:15-16)
“OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.” (1 Jòhánù 4:1)
Ki ni awọn aṣẹ ti a fun wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli wọnyi? Akọkọ, a ni lati kiyesi awọn eke oniwaasu. Ki si ni idi ti a ṣe ni lati kiyesi wọn? Idi ni pe alarekereke ni wọn. Wọn ko ni fi ete inu wọn han wa lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba tọ wa wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn yoo fi ara wọn han bi ẹni ti o fẹran wa, ti o si fẹ ki a ṣe rere. Ṣugbọn bi wọn yoo ṣe jẹ aye wa run nipasẹ ojukokoro, iṣekuṣe ati awọn iwa ika miran ni wọn n wa.
Aṣẹ keji ti a gba ni pe ki a ma a dan gbogbo awọn oniwaasu ti o n tọ wa wa wo. Ki ni idi? Idi ni pe eyi ni yoo jẹ ki a le da awọn eke ti o wa ni aarin wọn mọ. Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yẹn, ọpọ eke oniwaasu ni wọn ti jade lọ sinu aye. Lati ibo si ni wọn ti jade lọ sinu aye? Lati inu ijọ ni! Nitorina, ki a to fi ara wa jin lati ma a tẹle oniwaasu kankan, a sọ fun wa pe ki a kọkọ dan wọn wo naa.
Bawo wa ni ki a ṣe dan wọn wo? Ọrọ Ọlọrun ni a o lo lati dan wọn wo. Ọrọ Ọlọrun fi han wa kedere bi a ti ṣe le mọ iyatọ laarin awọn ojulowo oniwaasu ati awọn eke. Fun apẹrẹ, ọrọ Ọlọrun sọ wipe nipa eso wọn ni a o fi mọ wọn. Nitorina, oniwaasu yowu ti ko ba ti so eso Ẹmi, eso ifẹ, ayọ, alaafia, iwa-pẹlẹ, suuru, irẹlẹ, ikora-ẹni-nijanu ati awọn wọn iwa rere miran ti a mẹnuba ninu bibeli, ko ki i ṣe ti Ọlọrun. Nitorina a gbọdọ takete si i.
Lafikun, oniwaasu yowu ti iṣọwọ ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ ko ba ti wa ni ibamu pẹlu nkan ti a ri ninu bibeli ko ki i ṣe ti Ọlọrun. A si ni ọpọ wọn loni ti wọn n ṣe oniruuru nkan ti ko wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Awọn wọnyi a ma a yan adura ti o takọ ọrọ Ọlọrun. Wọn a ma a bu awọn ẹda ọrun. Wọn a ma a ta ororo, omi ati awọn nkan miran. Wọn a tun ma ṣe iṣẹ oṣọ, pẹlu iboju pe awọn n ṣe akanṣe eto itusilẹ fun awọn eniyan.
Wayi o, ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe a gbọdọ takete si irufẹ awọn eniyan wọnyi, bi o ti wu ki awọn iṣẹ amin, iṣẹ iyanu ati iṣẹ ara ti wọn n ṣe le ga to. Aijẹbẹ, Satani yo o lo wọn lati pa aye wa run. Lafikun, nipa dida ara wa pọ mọ wọn, awọn naa le di alajọpin ninu idajọ Ọlọrun yowu ti o ba wa sori wọn. Nitorina, takete si awọn eke oniwaasu. Fun anfaani rẹ si ni lati ṣe bẹẹ gẹgẹ.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)