Ọjọ: Ebibi 23, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 3
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Ebibi 2021. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba siji bo ọ kuro lọwọ gbogbo ibi, ibiyowu ti wọn le ti ma bọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun si wa. Ki si ni ọrọ rẹ sọ? Lakọkọ, ọrọ rẹ sọ pe, “Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe aabo mi, iwọ ti fi ọga ogo ṣe ibugbe rẹ. Buburu kan ki yoo ṣẹlẹ si ọ, bẹẹ ni arunkarun ki yoo sun mọ ile rẹ. Nitori ti yoo fi aṣẹ fun awọn angẹli rẹ nitori rẹ lati pa ọ mọ ni ọna rẹ gbogbo. Wọn o gbe ọ soke ni ọwọ wọn, ki iwọ ki oo ma baa fi ẹsẹ rẹ gun okuta.” (Saamu 91:9-12) Ṣe o ri bayi? Niwọn igba ti a ba n gbe ninu Ọlọrun nipasẹ Kirisiti Jesu, ibi kankan ki yoo ṣubu lu wa, bẹẹ si ni ajalu kankan ki yoo sumọ ibugbe wa. Ki si ni idi? Idi ni pe yoo ri daju pe awọn angẹli mimọ rẹ rọgba yi wa ka lati pa wa mọ ni gbogbo ọna wa.
Ṣugbọn ṣe o tilẹ mọ pe awọn angẹli Ọlọrun rọgba yi ọ ka lati daabo bo ọ? Bibeli sọ fun wa pe gbogbo awa ti a ti wa sọdọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kirisiti ni a ti wa ni awujọ awọn angẹli ti wọn n yọ, ti iye wọn ko si ṣe e ka. O si tun sọ fun wa pe gbogbo awọn angẹli yi ni o n fi ojoojumọ gba aṣẹ lọdọ Ọlọrun lati sin wa. Ṣe a wa le fi oju ara yi ri wọn? Rara o! Ṣugbọn wọn rọgba yi wa ka, wọn si n ṣiṣẹ karakara lati ri pe a wa ni ailewu lati ni iriri imuṣẹ ifẹ Ọlọrun ninu aye wa ni ọna ti o peye. (Wo: Heberu 1:14 & 12:22)
O yẹ ki iwọ na wa ri idi ti bibeli ṣe tẹnumọ pe ajalu, iṣẹlẹ ẹru ati ipọniloju yoo jina si wa (Aisaya 54:14-15). Mi o wa fẹ ki o ṣi nkan ti a n sọrọ le lori nibiyi gbọ o. Ko ki i ṣe pe iṣẹlẹ buburu ko ni fẹ ṣẹlẹ si wa rara. Niwọn igba ti a ba wa ninu aye yi, ko si ki Eṣu ma lepa lati ri pe nkan buruku ṣẹlẹ si wa, boya a jẹ ọmọ Ọlọrun tabi bẹẹkọ. Ṣugbọn nitoripe a jẹ ọmọ Ọlọrun, gbogbo igba ni aabo rẹ ma n wa lori wa nipasẹ awọn angẹli alagbara rẹ. Awọn wọnyi a si ma fi gbogbo igba ri daju pe nkan yowu ti Eṣu le ṣe, awọn iṣẹlẹ ibi ti o ti gbimọ lati fi kọ lu wa ko sunmọ wa rara.
Mo wa fẹ ki o ranti nkan ti o ṣẹlẹ nigba ti awọn ọmọ Isiraẹli ṣẹṣẹ jade lati Ijibiti wa. Wọn jade taijade tan ni Farao tun pe gbogbo ogun rẹ jọ lati le wọn mu. Ṣugbọn bibeli sọ pe, “Angẹli Ọlọrun naa ti o ṣaaju ogun Israẹli, si ṣi lọ ṣẹyin wọn; ọwọn ikuukuu si ṣi kuro niwaju wọn, o si duro lẹyin wọn: O si wa si laarin ogun awọn ara Ijibiti ati ogun Isiraẹli; o si ṣe ikuukuu ati okunkun fun awọn ti ọhun, ṣugbọn o ṣe imọlẹ ni oru fun awọn ti ihin: bẹẹ ni ekin ni ko sun mọ ekeji ni gbogbo oru naa.” (Ekisodu 14:19-20) Kaasa! Gbeyẹwo! Angẹli Oluwa ti O n daabo bo orilẹ-ede Isiraẹli ri pe ogun Ijibiti ko le sunmọ wọn. O si ri pe bẹẹ gẹgẹ ni ọrọ naa ṣe ri titi gbogbo ogun Ijibiti ti o n lepa wọn fi parun sinu okun pupa.
Nibakanna, iwọ naa ni awọn angẹli ti a ti yan lati daabo bo ọ. Wọn o si ma ri daju ni gbogbo igba pe bi o ti wu ki ajalu, rogbodiyan, ajakalẹarun tabi aisan ti Eṣu ran si ọ le sunmọ ọ pẹkipẹki tabi le to, wọn ko fi ọwọ kan ọ tabi pa ọ lara. Nitorina, gbe gbogbo ibẹru rẹ ju danu, ki o si ma fi igba gbogbo rin pẹlu afiyesi pe iwọ naa ni awọn ẹṣọ tirẹ, awọn ẹṣọ ti Ọlọrun ran lati pa ọ mọ. Aijẹbẹ, nipasẹ ẹru, o le fi ẹnu ara rẹ fa jọgọdọ sori ara rẹ (Iwe owe 18:21).
Siwaju si, o tun nilo lati fi ara rẹ jin lati duro ninu ifẹ Ọlọrun ati lati ma a rin ninu ododo rẹ nikan yatọ si ododo ti ara rẹ. Aijẹbẹ, o le fi ọwọ ara rẹ ṣilẹkun silẹ fun Eṣu lati pọn ọ loju. Kini idi ti Jona fi ba ara rẹ ninu ikun ẹja? Ṣebi nitoripe o ṣe aigbọran si aṣẹ Ọlọrun ti o daju saka ni. Ki ni idi ti Lọti fi padanu ọrọ rẹ ni ọjọ kan? Ṣebi nitoripe o muleti awọn ti o n gbe igbe aye ti o lodi si ifẹ Ọlọrun ni? Ki si ni idi ti Ọlọrun fi fi aye gba Jobu lati ni awọn iriri buruku ti o ni ni asiko kan ni igbesi aye rẹ? Ọkan lara awọn idi naa ni pe Ọlọrun fẹ ẹ fihan an pe ninu ododo ara rẹ ni o ti n rin fun igba pipẹ, ti o si n ro pe awọn iṣẹ rere oun ni o fun oun ni amuyẹ lati ri aabo Ọlọrun gba.
Nitorina, ti a ko ba fẹ ṣilẹkun aye wa silẹ fun ajalu, awa naa gbọdọ mu gbogbo aṣẹ Ọlọrun ni ọkunkundun, ki a si tun gbọkanle fun aabo wa dipo ki a gbọkanle iṣẹ rere wa. Niwọn igba ti a ba si n ṣe eyi, ti awọn wahala tabi ajalu kan ba tilẹ wa si ọdọ wa nipaṣẹ aṣiṣe, aigbọran tabi ete buburu awọn kan, Ọlọrun yoo ri daju pe awọn angẹli rẹ wa pẹlu wa lati pa wa mọ nipa pipa awọn kiniun ti a ran lati pa wa run lẹnu mọ. (Wo: Daniẹli 6; Iṣe Awọn Apositeli 27)
Ki o ni ọsẹ adun.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
