Ọjọ: Ebibi 30, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 4
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọsẹ yi. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati duro gẹgẹ bi olooto si Oluwa, ki o si tun fidimulẹ pẹlu iduroṣinṣin ninu ododo rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Gẹgẹ bi Oluwa ti ṣe fi ye mi, ọkan pataki lara awọn nkan ti o n di itankalẹ ati igbooro si ọrọ Ọlọrun ni ilẹ wa lọwọ ni igbe aye ọpọ awọn ti o pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun ti ko wa ni ibamu pẹlu ododo rẹ. Eyi jasi pe idi ti pupọ eniyan si ko ṣe ma tọ Jesu Oluwa wa fun igbala ni pe wọn ko ri eso igbala ninu aye ọpọ awa ti a n fẹnu sọ pe O ti gba wa la. Bawo ni a ṣe le so fun awọn eniyan ki wọn tọ Jesu wa fun ominira kuro lọwọ Eṣu ati awọn ẹṣẹ wọn, nigba ti o han kedere pe awa gan si n gbe igbe aye ẹru Eṣu ati ẹṣẹ? Ta gan ni yoo kọbiara si wa?
Wo o, ko ki i ṣe pe awọn eniyan ko fẹ ni igbala kuro lọwọ ẹṣẹ, asakasa, imisi buburu, aisan, egun atirandiran, iṣẹ ati bẹẹbẹẹ lọ; wọn kan fẹ ri awọn ti aye wọn yoo jẹri han wọn pe o ṣeeṣe ki eniyan ri igbala gba kuro lọwọ awọn nkan wọnyi ni. Ọlọrun si ti gba wa, O tun wa bi, O kun wa fun Ẹmi Mimọ rẹ, O si tun gbin wa si ibikibi ti a ba wa lati jẹ irufẹ ẹri yi fun awọn eniyan. O wa ṣeni laanu pe ọpọ wa gan ni oye ete ati erongba rẹ ko ye. Nitorina, a n sọ ete ati erongba rẹ di aṣan nipa awọn igbe aye ti a n gbe ti o lodi si nkan ti a da wa lati gbe.
Lotitọ, eyi ko jẹ ajoji rara si ijọ. Nigba aye awọn apositeli igbaani gan, irufẹ awọn nkan wọnyi n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ Ọlọrun. A si ri awọn kan ti wọn pe ara wọn ni onigbagbọ ni igba na ti wọn ko dẹkun ole jija, pansaga ṣiṣe, lilu awọn eniyan ni jibiti, yiyan odi, gbigbe igbe aye ojukokoro, yiyan awọn oṣiṣẹ wọn jẹ tabi ṣiṣe iṣẹ ajẹ tabi oṣo. Awọn apaniyan, alagabagebe ati ọmuti paapaa wa ninu ijọ ni awọn ọjọ wọnni. Nitorina, ko si ọkankan ninu awọn iwa ibi ti a n ri ninu ijọ loni ati laarin awọn ọmọ Ọlọrun ti o jẹ tuntun tabi ti o jẹ ajoji si akoko wa. (Woo: Roomu 2:21-22; 1Korinnti 5; Jemisi 4:1-2&5:1-6)
Amọ ṣa o, awọn apositeli Oluwa igbaani naa tun wa jẹ ki o yewa yekeyeke nipasẹ awọn akọsilẹ wọn pe irufẹ ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun ti o si n ṣe awọn nkan wọnyi ko ma gan orukọ Oluwa, ki o si ma tabuku oore-ọfẹ rẹ lasan, nṣe ni o tun n ba iṣẹ igbala ti O n ṣe ninu aye yi jẹ. Nitorina, nṣe ni iru ẹni bẹ yẹ ki o ma reti ifarahan ibinu Ọlọrun si i (Roomu 2:1-11; Heberu 0:26-31). Eyi si kọja nkan ti a n sun ṣiwaju di ọjọ idajọ. Dipo bẹ, o jẹ eyi ti yo bẹrẹ si ni ni iriri rẹ lati inu aye yi lọ.
Idi si ni yi ti Peteru ṣe sọ fun wa pe, “Nitori akoko naa de, ti idajọ yoo bẹrẹ lati ile Ọlọrun wa…” (1Peteru 4:17) Njẹ o ri bayi? Apositeli yi ko sọrọ nibi nipa idajọ ti o n bọ ni ọjọ Oluwa. Dipo eyi, o n sọrọ nipa idajọ Ọlọrun ti o n lọ lọwọlọwọ ati ni bayibayi ninu aye yi. O si n sọ pe ijọ Ọlọrun gan ko ni ribi yẹ idajọ yi si. Ka tilẹ so otitọ, aarin wọn ati lori wọn gan ni yoo ti bẹrẹ.
Nitorina, ti o ba n mọn ọn mọn ṣe awọn nkan ti o lodi si ododo Ọlọrun, mọ wipe o jẹ ọkan lara awọn ti yoo foju wina idajọ rẹ. Ọna ti yoo wa gba ṣe idajọ rẹ ni ẹnikẹni ko le sọ. Ṣugbọn pẹlu nkan ti Jesu Oluwa sọ si ijọ Tiatira ati eyi Pọọlu sọ si awọn ara Korinnti, a ri mọ pe Ọlọrun le ṣe idajọ awọn eniyan rẹ pẹlu aisan, ailera, aṣedanu tabi pẹlupẹlu iku (1Korinnti 11:28-30; Ifihan 2:20-23). Ti o ko ba wa ti ni iriri ọkankan ninu awọn nkan wọnyi, bi o tilẹ jẹ pe inu ẹṣẹ ni o n gbe, jẹ ki o ye ọ pe Ọlọrun kan n fun ọ ni akoko lati ronupiwada ni. Ti o ba si wa kuna lati ronupiwada ni aarin gbedeke akoko ti O fun ọ, a jẹ pe laiṣe aniani, o di dandan ki Oṣe idajọ rẹ ninu ododo rẹ. Ibi ti eyi yoo wa yọri si fun ọ ni n ko le sọ. Nitorina, ronupiwada bayi, ki o si tun sọ fun awọn alabapin rẹ ninu ẹṣẹ dida ki awọn naa ronupiwada. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki ẹ parun si abẹ ibinu Ọlọrun nikẹyinkẹyin.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
