Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Adura mi ni pe ki Ọlọrun pa ọ mọ ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo iyoku ọdun yi kuro ninu gbogbo ikọlu eṣu. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti a sọ fun wa ninu bibeli ni pe ọta wa ni eṣu jẹ. Eyi jasi pe, ko ki i ṣe ọrẹ wa, a ko si gbọdọ ri gẹgẹ bi ọrẹ. Dipo eyi, nṣe ni a gbọdọ ma a fi igba gbogbo ṣọ ara wa fun un. Aijẹbẹ, yoo ba aye wa
Wo nkan ti Peteru sọ fun nipa rẹ:
“Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri: Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ.” (1 Pétérù 5:8-9)
jẹ.
Njẹ o ri bayẹn? Peteru n sọ fun wa nibiyi pe Satani ko kan ki i ṣe ọta wa lasan; ọta ti o jafafa ni. Iha wo wa ni ki a kọ si i? Akọkọ, a gbọdọ ma fi igba gbogbo wa ni ikiyesara fun un. Eyi tunmọ si pe, a gbọdọ ma a fi igba gbogbo kiyesi awọn anfaani ti o le fẹ lo lodi si wa, ki a ba a le mu wọn kuro.
Woo, Satani ṣetan lati lo anfaani yowu ti o ba ri lodi si wa, ti a ba fi aaye gba. O le lo awọn ibaṣepọ wa lodi si wa. O le lo awọn nkan ini wa lodi si wa. O si tun le lo aikiyesra tabi imẹlẹ wa lodi si wa. O wa ku si ọwọ wa lati tete da ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o ba fẹ lo lodi si wa mọ, ki a si tete gbe igbesẹ lati di i lọwọ.
Nkan ekeji ti Peteru sọ fun wa ni pe ki a kọju ija si esu. Eyi jasi pe, a gbọdọ kọ lati ma gbogun ti I ati lati le danu kuro ninu aye wa. Ṣe a wa le ṣe eyi? Bẹẹni, a le e ṣe. Ti a ko ba le le eṣu jina si aye wa ni, Ọlọrun ko ni sọ fun wa pe ki a ṣe bẹ ẹ. Idi ti O ṣe sọ fun wa pe ki a ṣe bẹ ẹ ni pe a le e ṣe bẹ ẹ.
Bawo wa ni a ṣe le ṣe bẹ ẹ? Nkan meji ni a nilo! Akọkọ ni pe ki a fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun, ki a si ṣe ohunkohun ti O ba sọ fun wa pe ki a ṣe lati le eṣu jina si aye wa. Nkan ekeji ni ki a duro ṣinṣin ni ṣiṣe ohun yowu ti Ọlọrun ba sọ fun wa pe ki a ṣe lati le eṣu danu. Eyi tunmọ si pe a gbọdọ ma a fi igba gbogbo ṣe ohunkohun ti O ba sọ fun wa pe ki a ṣe titi Satani yoo fi salọ kuro lọdọ wa.
Wayi o, ki ni nkan naa ti Ọlọrun n sọ fun wa pe ki a ṣe lati le Satani jinna si aye wa, ile wa ati awọn adugbo wa? O n sọ fun wa pe ki a fi ara wa jin fun ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ rẹ, fun pipolongo ọrọ rẹ ati fun ṣiṣe amulo ọrọ rẹ. O tun n sọ fun wa pe ki a fi ara wa jin fun adura gbigba lai sinmi. Lafikun, O n sọ fun wa pe ki a mu ibaṣepọ wa pẹlu awọn eniyan rẹ ni ọkunkundun. Ti a ba si ti n ṣe awọn nkan wọnyi, ti a ko si rẹwẹsi, a o le ma a fi igba gbogbo le Satani jinna si wa.
Nkan ẹkẹta ti Peteru sọ fun wa ninu awọn ẹsẹ bibeli yẹn ni pe ki a ma a fi igba gbogbo ranti pe awa nikan kọ ni eṣu n kọlu. Gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun bi ti wa ni o n kọlu pẹlu. Nitorina, a ko gbọdọ ro wipe awa nikan ni awọn iyọnu ti o n tọ wa wa n tọ wa, ki a si sọ ireti nu. Dipo eyi, nṣe ni ki a tẹsiwaju lati ma kọju ija si eṣu ati iṣẹ rẹ ninu aye wa. A o si ma a fi igba gbogbo rin ni iṣẹgun lori rẹ.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)