Nígbà tí Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán-an wò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Erele 15, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 41

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma tete fi igba gbogbo kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ati irẹlẹ ti o peye lati ma a fi igba gbogbo yan awọn nkan ti yoo dun mọ-ọn ninu ati ti ko ni fi ọ tabi awọn miran ti o wa ninu aye rẹ sinu iyọnu. Amin.

Bi a ti ṣe mọ nipasẹ bibeli, Ọba Hesekaya jẹ ọkan lara diẹ ninu awọn ọba Juda ti o sin Ọlọrun lotitọ ati tọkan-tọkan. Nitorina, Ọlọrun bukunfun gidigidi, O si tun fun ni isinmi kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ. Sibẹsibẹ, nkan ti a kọ sinu bibeli lori bi Ọlọrun ti ṣe dan an wo nigba ti ijọba rẹ n wa si opin ni eyi:

“Ṣugbọn niti awọn ikọ̀ awọn ọmọ-alade Babeli, ti nwọn ranṣẹ si i, lati bère ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na, Ọlọrun fi i silẹ lati dán a wò, ki o le mọ̀ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.” (2Kíróníkà 32:31)

Ki ni idi ti Ọlọrun fi fi Hesekaya silẹ lati dan an wo ati lati mọ ohun gbogbo ti o wa ninu ọkan rẹ? Ṣe lotitọ ni pe Ọlọrun nilo lati dan an wo ki O to mọ nkan ti o wa ninu ọkan rẹ ni? Rara o! Ọlọrun ti mọ nkan ti o wa ninu ọkan rẹ tẹlẹtẹlẹ. Nitorina, idanwo naa ko ki i ṣe fun Ọlọrun lati mọ nkan ti o wa ninu ọkan rẹ ṣugbọn fun oun alara lati mọ nkan ti o wa ninu ọkan ara rẹ.

Njẹ ọna wo wa ni Ọlọrun gba dan an wo? O dan an wo nipa fifi aaye gba lati pinnu lori ọrọ kan funrarẹ. Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, lẹyin igba ti Ọlọrun wo o san tan, ti O si tun fun ni ọdun marun-din-logun si laye, awọn oniṣẹ kan wa lati Babiloni lati ki i. Laisi fi ọrọ naa to Ọlọrun leti lori bi o ti ṣe yẹ ki o ṣe si awọn onisẹ yi, o fi gbogbo titobi rẹ ati ọla rẹ, ohun gbogbo ti o wa ninu aafin ati ninu ijọba rẹ, han wọn. (Wo: 2Àwọn Ọba 20:12-19)

Ki ni idi ti o ṣe ṣe eyi? Ipongbẹ fun oriyin awọn eniyan! Ipongbẹ lati ṣe ṣekarimi! Ki si ni o fa ti o fi wu u lati ṣe ṣekarimi ni asiko naa? Igberega! Nitorina, igberaga ti wa ninu Hesekaya tipẹ-tipẹ. Ṣugbọn ko farahan titi Ọlọrun fi jẹ ki o pinnu funrarẹ lori bi yoo ti ṣe ṣe si awọn oniṣẹ ti o wa lati Babiloni. Igba ti o wa tẹ ara rẹ lọrun tan ni Ọlọrun ṣẹṣẹ ran Wolii Aisaya si lati sọ atunbọtan igberaga rẹ fun. Ọlọrun sọ fun pe yoo padanu ohun gbogbo ti o fi han awọn ara Babaloni, pẹlupẹlu awọn arọmọdọmọ oun tikararẹ rẹ, si ọwọ wọn lẹyin iku rẹ. O ma ṣe o!

Njẹ ki ni eyi wa n kọ wa? Oun naa ni pe ọkan lara awọn ọna ti Ọlọrun ma n gba fi ibi ti o farasin ninu ọkan awọn eniyan han wọn ni nipa fifi aaye gba wọn lati yan awọn nkan kan funra wọn. Nitorina, a gbọdọ kọ lati ma gbadura pe ki Ọlọrun ma lailai fi wa silẹ lati yan ohunkohun, yala o tobi ni tabi o kere, funra wa, lalai fun wa ni ọgbọn rẹ. Nipa bayi, a ko ni lailai yan ohunkohun ti yoo pa aye wa tabi aye awọn ti a fẹran run.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *