Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ṣe ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2026. Adura mi si ni pe ki oore-ọfẹ Ọlọrun ti a n tu lori aye rẹ nigba gbogbo ma lalai ṣofo, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o ṣeeṣe ki oore-ọfẹ Ọlọrun ṣofo ninu aye wa. Eyi jasi pe, o ṣeeṣe ki oore-ọfẹ Ọlọrun kuna lati ṣe nkan ti o ye ki o ṣe ninu aye wa. Idi si ni yi ti a fi kilọ fun wa pẹlu awọn ọrọ Apọsiteli Pọọlu wọnyi:
“NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan.” (2 Kọ́ríntì 6:1)
Ṣe o ri bayẹn? O ṣeeṣe ki a tẹwọgba oore-ọfẹ Ọlọrun lasan. Lọna wo ni eyi ṣe ṣeeṣe? O le waye nipasẹ ikuna wa lati ṣiṣe lori ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wa wa. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki a gbọ ọrọ Ọlọrun ninu ipade ijọ kan lọwọlọwọ yi, ki a si kuro ninu ipade na lati lo ṣe nkan ti o lodi patapata si nkan ti a gbọ. Nibakanna, o ṣeeṣe ki a ka bibeli ara wa lọwọlọwọ yi, ki a si tun dide kuro nibi ti a ti ka lati lọ ṣe nkan ti o lodi patapata si nkan ti a ṣẹṣẹ ka tan.
Judasi Isikariọtu, fun apẹrẹ, joko pẹlu gbogbo awọn apọsiteli yoku nigbati ti Jesu Oluwa wa n kọ wọn ni ọrọ Ọlọrun ni asiko diẹ ṣaaju igba ti a mu, ti a si kan an mọ agbelebu. Ọkunrin yi wa pẹlu wọn nigba ti Jesu n fọ ẹsẹ wọn, ti O si tun n tun wọn kọ lori pataki ki wọn fi ara wọn jin lati ma a sin ara wọn ninu ifẹ. Sibẹsibẹ, o kuro laarin wọn lalẹ ọjọ kanna lati lọ mu awọn ti yoo mu Oluwa, ti wọn yoo si kan mọ agbelebu wa sọdọ rẹ. Ṣe ko wa fi oore-ọfẹ Ọlọrun ti o ri gba ṣofo bi? O fi ṣofo. (Wo: Jòhánù 13)
Lafikun, nigba ti Ọlọrun n ba Isikiẹli sọrọ lori awọn ti o n wa sọdọ rẹ lati gbọ iwaasu rẹ, O sọ eyi:
“Iwọ ọmọ enia, sibẹ awọn ọmọ enia rẹ nsọ̀rọ si ọ lẹba ogiri ati lẹba ilẹkun ile, ẹnikini si sọ fun ẹnikeji, olukuluku fun arakunrin rẹ̀ wipe, Wá, emi bẹ̀ ọ si gbọ́ ọ̀rọ ti o ti ọdọ Oluwa jade wá. Nwọn si tọ̀ ọ wá, bi enia ti iwá, nwọn si joko niwaju rẹ bi enia mi, nwọn si gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kì yio ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni nwọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkàn wọn tẹ̀le ojukokoro wọn. Si kiyesi i, iwọ jẹ orin ti o dùn pupọ fun wọn, ti ẹnikan ti o ni ohùn daradara, ti o si le fún ohun-elò orin daradara: nitori nwọn gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kò ṣe wọn.” (Ìsíkíẹ̀lì 33:30-32)
Tani Oluwa n tọka si ninu awọn ẹsẹ yi? Awọn ti o n fi itara wa sọdọ Isikiẹli lati wa gbọ iwaasu rẹ! Ko tọka si awọn ti ko nifẹ rara lati gbọ nkan ti o n sọ. Dipo eyi, awọn ti o n fi itara wa sọdọ rẹ lati gbọ iwaasu rẹ ni o n tọka si. Sibẹsibẹ, awọn ti o n wa sọdọ eniyan Ọlọrun yi ko ni lọkan rara lati ṣiṣẹ tọ nkan ti o n kọ wọn. Ki a tilẹ sọ otitọ, Oluwa sọ fun Isikiẹli pe kọja adẹrinpoṣonu loju wọn. Ki wa ni awọn eniyan yi n ṣe si oore-ọfẹ Ọlọrun ti o n tọ wọn wa? Wọn n fi sofo.
Ki wa ni bibeli sọ nipa awọn ti o ba n fi oore-ọfẹ Ọlọrun ṣofo? O sọ wipe o di dandan ki idajọ Ọlọrun sọkalẹ sori wọn. Mo gbadura pe idajọ Ọlọrun ko ni wa sori rẹ. Ṣugbọn o kọ gbọdọ kan ma a gbọ ọrọ rẹ nikan lalai ma a gbe igbesẹ lati ṣiṣẹ le lori. Lotitọ, a le ri awọn abala aye rẹ nibi ti o ti ṣe alailera ni ṣiṣiṣẹ tọ ọrọ Ọlọrun. Nṣe si ni ki o ke pe e lati fun ọ ni okun ti o nilo lati ṣe ifẹ rẹ ni awọn abala wọnyi. Yoo si da ọ lohun. (Wo: Hébérù 10:26-31)
Pọọlu sọ eyi fun wa nipa iha ti o kọ si oore-ọfẹ Ọlọrun:
“Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi.” (1 Kọ́ríntì 15:10)
Ṣe o ri bayẹn? Idi ti Pọọlu ko ṣe fi oore-ọfẹ Ọlọrun lori aye rẹ ṣofo ni pe o n ṣiṣẹ karakara pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o n gba. Nitorina, o di ẹni naa ti Ọlọrun fẹ ki o da. Iwọ naa si gbọdọ bẹrẹ si ni ṣe bẹẹ gẹgẹ, ti o ba nitootọ fẹ jẹ ẹni ti Ọlọrun fẹ ki o jẹ. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ma a fi gbogbo igba kun ọ pẹlu okun lati ṣe bẹẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)