Author name: 23?Racing_Horse

Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, iyẹn oṣu Ogun 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ninu oṣu naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n wọ inu ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti pe ifẹ Ọlọrun fun ọ ni pe ki o ma fi gbogbo igba gbe iṣiṣẹ rẹ laye lati inu ẹkunrẹrẹ Ẹmi Ọlọrun ti o n gbe inu rẹ. Eyi tunmọ si pe, O n fojusọna pe ki o ma fi igba gbogbo sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ Ẹmi Mimọ. Nipa bayi, ohunkohun ti o ba jẹ jade laye rẹ yoo jẹ ohun ti yoo dun mọ Ọlọrun ninu ati ti yoo gbe awọn ti o wa ni ayika rẹ ro.

Wayi o, wo nkan ti Pọọlu sọ nipa eyi fun wa:

“Nitori naa ẹ ma ṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ maa moye ohun ti ifẹ Oluwa ja si. Ẹ ma si ṣe mu waini ni amupara, nitori eyi yoo pa yin run; ṣugbọn ẹ kun fun Ẹmi Mimọ. Ẹ si maa ba ara yin sọrọ ninu saamu, ati orin iyin, ati orin Ẹmi, ẹ maa kọrin, ki ẹ si maa kọrin didun ni ọkan yin si Oluwa. Ẹ maa dupẹ nigba gbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa.” (Éfésú 5:17-19)

Ki ni nkan akọkọ ti Pọọlu sọ fun wa ninu ẹṣẹ yi? Ohun naa ni pe ki a ma jẹ omugọ tabi alailoye ṣugbọn ki a ni oye ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Nitorina, nkan omugọ ni fun wa lati ma mọ ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Bẹẹni, nkan omugọ ni fun wa lati ma ṣe awawi lori pe a ko mọ nkan ti Ọlọrun fẹ fun aye wa. Idi si ni pe a le mọ ifẹ rẹ fun aye wa ti a ba fẹ lati mọ ọn, ti a si tun n tiraka lati mọ ọn. Ti a ko ba si wa mọ ifẹ rẹ fun aye wa, ki a si ma gbe ni ibamu pẹlu rẹ, nṣe ni a o fi aye wa ṣofo.

Siwaju si, lẹyin igba ti o ti sọ pataki ki a mọ ifẹ Ọlọrun fun aye wa tan, Pọọlu tẹsiwaju lati sọ nkan kan fun wa nipa ifẹ Ọlọrun fun wa. Ki si ni eyi? Oun naa ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati má mu ọti-waini ni amupara ṣugbọn lati kun fun Ẹmi Mimọ. Ki ni idi ti o fi fi mumu ọti-waini ni amupara we kikun fun Ẹmi Ọlọrun? Idi ni pe ti awọn eniyan ba yo tan, wọn a sọ ara wọn nu si abẹ iṣakoso waini, wọn a si bẹrẹ si ni sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ ninu wọn. Nibakan naa, ti awọn eniyan ba kun fun Ẹmi Ọlọrun, wọn a sọ ara wọn nu sabẹ iṣakoso rẹ, wọn a si bẹrẹ si ni sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ ninu wọn. Ki wa ni o fẹ, ṣe ki ọti-waini ma ṣe akoso rẹ ni tabi ki Ẹmi Ọlọrun ma ṣe akoso rẹ?

Ni kukukuru, ifẹ Ọlọrun ni pe ki o fi aye gba Ẹmi Ọlọrun lati di ọ mu ati lati ma ṣe akoso ohun ti o n sọ ati eyi ti o n ṣe. Bawo si ni o ṣe le ṣe eyi? O le ṣe e nipa kikun ara rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun. Idi si ni pe ọkan ni ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi Ọlọrun. Ti o ba si kun ara rẹ pẹlu ọrọ rẹ, o di dandan ki o ma wuwa, sọrọ ati kọrin lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ rẹ ti o wa ninu rẹ pẹlu irọrun. Eyi si wa jasi pe ti o ko ba ki i wuwa, sọrọ tabi kọrin lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ Ọlọrun, o ko kun fun ọrọ rẹ niyẹn – nkan miran ni o kun fun.

Bi mo ti ṣe fihan tẹlẹ, ti awọn eniyan ba yo tabi kun fun ọti waini, wọn a ma sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ. Ṣugbọn ko ki i ṣe ọti waini nikan ni awọn eniyan le kun fun. Awọn eniyan le tun kun fun ikoro, ojukokoro, ibinu, ilara, igberaga tabi ifẹkufẹ. Ki a ma fọrọgun, ohun yowu ti wọn ba kun fun ni wọn yoo ma sọrọ, kọrin ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ.

Wayi o, lotitọ awọn eniyan le sọ wipe awọn kun fun Ẹmi Ọlọrun. Ṣugbọn nkan ti wọn sọ wipe awọn kun fun kọ ni o ṣe pataki bikoṣe ohun ti aye wọn n gbe jade. Njẹ o tilẹ mọ wipe nipa wiwo abala bi nkan ti ṣe n lọ (sitetọsi) Wasáàpù, Fesibúùkù tabi awọn opo ẹrọ-ayelujara miran awọn kan, o le sọ nkan ti wọn kun fun? Bẹẹni, o le sọ boya ọrọ ati ifẹ Ọlọrun ni wọn kun fun tabi ibinu, irẹwẹsi, iporuru, ẹtanu, ifẹkufẹ, owu, ikunsinu tabi igberaga ni wọn kun fun. Ṣugbọn ni tirẹ, nkan ti o gbọdọ kun fun ni ọrọ Ọlọrun. Bi o ba si ṣe n kun ara rẹ pẹlu ọrọ rẹ, nṣe ni o ri wipe o n gbe igbe aye ti o buyi kun Ọlọrun ati eyi ti o n bukun fun ayika rẹ pẹlu irọrun.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 17 Read More »

Àkórí: Onígbàgbọ́ tí kò dùn-ùn bá ṣepọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 18, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògun 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu idunnu ti o ga fun un ati fun ijọba rẹ, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara idi ti a ko fi ma ri ki ọpọ ma tikalara wọn tọ Jesu Oluwa wa fun igbala ni pe ọpọ ninu awa ti a pe ara wa ni Kirisitiẹni ni ara wa ko ya gaga si Ọlọrun ati si igbagbọ wa. Ara wa ko ya gaga lati ka ọrọ Ọlọrun tabi lati gbọ ọ. Ara wa ko ya gaga lati gbadura. Ara wa ko ya gaga lati kọrin ati lati jọ niwaju rẹ. Bẹẹ si ni ara wa ko ya gaga lati fi fun un. Ni kukuru, onigbagbọ ti ko dun un ba ṣepọ ni a jẹ.

Wayi o, ko si ẹni ti o fẹ wa nitosi awọn ti ara wọn ko ki i ya gaga. Ko si ẹni ti o fẹ wa ni arọwọto awọn ti ara wọn ko ki i ya gaga si aye wọn tabi si ohun yowu ti wọn ba n ṣe. Niwọn igba ti ọpọ wa ko si jẹ ẹni ti ara rẹ ya gaga lati ba gbe pọ, lati ba ṣiṣẹ tabi lati ba kẹkọ, awọn alaigbagbọ ti o wa ni ayika wa yo o yala gba ile-ọti tabi ile-ijo lọ dipo ki wọn wa pẹlu wa tabi ki wọn wa ninu awọn ipade ijọ wa. O ma ṣe o!

Ṣugbọn Ọlọrun ko ki i ṣe ẹni ti ara rẹ ko ya gaga lati ba gbe tabi lati wa pẹlu. A si ri ifarahan eyi ninu Jesu Kirisiti Oluwa wa, ẹni ti o jẹ aworan Ọlọrun ni gbogbo ọna. Ko ki i ṣe ẹni ti ara rẹ ko ya si eniyan lati ba gbe tabi lati wa pẹlu ni igba ti O wa ni orilẹ-aye yi. Ka awọn iwe iyinrere. Iwọ yoo si ri pe awọn ọmọ-ẹyin ko fi igba kankan ni asiko ikarisọnu pẹlu rẹ. Igba kan ṣoṣo ti inu wọn bẹrẹ si ni ba jẹ ni igba ti o han si wọn kedere pe a o gba kuro lọdọ wọn. Sibẹ O sọ fun wọn pe ki wọn banujẹ rara. Ki ni idi? Gẹgẹ bi O ti sọ, idi ni pe Ẹmi Mimọ yoo wa rọpo rẹ ninu aye wọn, lati ma gbe inu wọn, lati ma gbe pẹlu wọn ati lati ma gbe nipasẹ wọn. Nitorina, ko ni si idi fun wọn rara lati ma karisọ tabi lati ma gbe igbe aye ẹni ti ara rẹ ko ya gaga. (Wo: Jòhánù 14-16)

Ki wa gan ni idi ti ọpọ wa fi n karisọ, ti ara wa ko si tun ya gaga loni, bi o tilẹ jẹ wipe a n sọ pe a ni Ẹmi Mimọ ninu wa? Ki ni idi ti ara wa ko ṣe ya gaga si Ọlọrun, si ọrọ rẹ, si adura gbigba, si ififunni ati fun iṣẹ-isin ninu ijọ Ọlọrun? Ara wa a ma ya gaga lati wo awọn sinima ti awọn taye yi, lati gbọ orin aye, lati wa pẹlu awọn ọrẹ alaiwa-bi-Ọlọrun ati lati lọ si àjọyọ̀ awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. Ṣugbọn ti ọrọ ba ti kan ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun ati awọn eniyan rẹ, ikarisọ-sinu nikan ni a o ma ri ninu wa. Ki ni iṣoro wa gan?

Bi o ti ṣe han kedere, ẹmi ìlọ́wọ́wọ́ ti o wa ninu aye yi ni o ti gba wa mu. Ẹmi kan naa yi ni o pọn ijọ Ọlọrun ti o wa ni Laodesia igba aye bibeli loju, ti o si sọ wọn di ẹni-ikaanu, oloṣi, talaka, afọju ati ẹni-ihoho ninu ẹmi. Ki ẹ si wa ma wo o, ẹmi ika yi ko ni sọ pe ki a ma lọ si awọn ipade ijọ mọ, tabi pe ki a ma gbadura mọ, tabi pe ki a ma gbọ ọrọ Ọlọrun mọ tabi pe ki a ma fifun ni mọ. Ṣugbọn yoo jẹ ki a ma ṣe awọn nkan wọnyi ni ọna ti ko nitunmọ ati ti ko wu ni lori debi wi pe a ko ni jẹ ere kankan nipa ṣiṣe wọn. (Wo: Ìfihàn 3:14-22)

Wo o, bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, awọn eniyan ko ki di ẹni-ọtun ati ẹni-igbega lati ọwọ Ọlọrun nitoripe wọn kan tọ ọ wa. Dipo bẹẹ, wọn a ma di ẹni-ọtun ati ẹni-igbega nitoripe wọn tọ ọ wa pẹlu ọkan ti o mura giri lati ba a gbe ati lati di alabukunfun nipasẹ rẹ. Nkan ti mo n sọ ni pe kiki awọn ọkan ti o n fi imura-giri ṣafẹri Ọlọrun ati awọn nkan ti o ti pese silẹ fun wọn nikan ni yoo gbadun rẹ lotitọ, ti yoo si tun le fa awọn miran wa si ọdọ rẹ. (Wo: Hébérù 11:6)

Nitorina, ti aye rẹ ko ba ma fa awọn miran si ọdọ Jesu Kirisiti Oluwa wa, a jẹ wipe ara rẹ ko ya gaga si rara tabi ki o jẹ wipe itara ati idunnu rẹ si i ko to. Bi o ti wa ri pẹlu awọn ọmọ ijọ Laodesia, iwọ wa ni abẹ ewu ki Oluwa kọ ọ silẹ gẹgẹ bi eke onigbagbọ. Adura mi si pe nigba ti a ba duro niwaju Oluwa ni ọjọ-ologo ni, ki a ma ṣe kọ ọ silẹ gẹgẹ bi eke ọmọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Ṣugbọn o ni lati gbadura si Ọlọrun lọwọlọwọ yi pe ki O sọ ohun gbogbo ti o ti di oku niti itara rẹ ati idunnu rẹ si i ati si ijọba rẹ ji, ki aye rẹ ba a le ma jo bi ina fun titi asiko rẹ lori ilẹ-aye yi yoo fi wa si opin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Onígbàgbọ́ tí kò dùn-ùn bá ṣepọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 18, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 16 Read More »

Fi ara rẹ jìn fún ìtọ́ni rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 11, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ ma fi ojoojumọ fi ara rẹ jin fun itọni Ọlọrun, ki a ba a le dari rẹ sinu ohun ti o dara julọ ti O yan fun ọ laye. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun fẹran wa to bẹẹ gẹẹ ti ko fi fẹ ki a ṣi ẹṣẹ gbe laye yi. Ko fẹ rara pe ki a fi asiko wa ṣofo lati ma a le ojiji ati awọn nkan ti ko lere lori kiri. Ṣugbọn a o le ojiji ati awọn nkan ti ko lere, ti a ko ba ni itọni rẹ, nitoripe bibeli sọ wipe, “Emi mọ Oluwa wi pe aye eniyan ki i ṣe ti ara rẹ, ki i ṣe fun eniyan lati gbe igbesẹ ara rẹ.” (Jeremáyà 10:23)

Njẹ o ri bayẹn? Aye wa ko ki i ṣe ti wa, a ko si wa ni ipo lati tọ iṣiṣẹ ara wa. Ta wa ni o wa ni ipo lati tọ iṣiṣẹ wa laye yi? Ọlọrun ẹlẹda wa ni! Ṣe O si wa nifẹ lati ṣe eyi? Bẹẹni, O nifẹ lati ṣe e. Bibeli tilẹ sọ fun wa pe ko ki i ṣe pe Ọlọrun nifẹ si itọsọna wa ni ipa ọna ti o tọ nikan, nṣe ni ọkan rẹ tilẹ wa lori ṣiṣe bẹ ẹ.

Amọ ṣa o, a gbọdọ fi ara wa jin fun itọni rẹ sinu ohun ti o dara julọ ti O fẹ fun wa, ki a si ma ya alagidi tabi ẹni ti o gbọn loju ara rẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni a o dari ara wa sinu afonifoji ojiji iku. Ti eyi ba si wa ri bẹ ẹ, iku ati iyagan nikan ni a le reti, ti a ba fi asiko ṣofo ki a to kesi Ọlọrun fun aanu rẹ. (Wo: Sáàmù 32:8-9)

Wo Lọọti, fun apẹrẹ. Nigba ti o wa pẹlu Aburahamu, awọn mejeeji ko jẹ lọ si ibikibi ti Ọlọrun ko ba dari wọn si. Ṣugbọn ni ọjọ kaana ti o fi Aburahamu silẹ, o bẹrẹ si ni ṣe idari ara rẹ. O bẹrẹ si ni yan ni ibamu pẹlu ohun ti o ri ati nipasẹ ọgbọn ara rẹ. Awọn nkan ti o si yan wa pada jẹ ki o padanu ọrọ ati iyawo rẹ ati ki idibajẹ ba ẹbi rẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 13&19)

Nitorina, ma ṣe tun lailai gbiyanju lati dari ara rẹ. Dipo bẹẹ, jẹ ki Ọlọrun dari rẹ. Iwọ yoo si jẹ ki O dari rẹ, niwọn igba ti o ba gbagbọ pe O mọ nkan ti O n ṣe ati wipe ko le lailai dari rẹ sinu iparun bikoṣe si ibi iṣerere ti O ni lọkan fun ọ. Lotitọ, ni awọn igba miran, Ọlọrun le dari rẹ lọ si eti Okun Pupa. Nkan ti mo n sọ ni pe awọn asiko le wa ti Ọlọrun le fi ọ si aarin Okun Pupa ati ogun Farao. Ṣugbọn niwọn igba ti O ba ti tẹsiwaju lati ma a tẹle, pẹlu ọkan wipe O mọ nkan ti O n ṣe, ko si ọkankan ninu Okun Pupa tabi ogun Farao ti yoo le di ọ lọwọ lati bẹ ibi ti o yẹ ki o de laye.

Ọna wo wa ni Ọlọrun yoo gba dari mi, niwọn igba ti o jẹ wipe n ko le ri i? Nikukuru, ọna kan gbogi ti Ọlọrun ma n gba dari awọn ọmọ rẹ ni nipasẹ akọsilẹ ọrọ rẹ. Bẹẹni, O tun ma n dari wọn lẹkọọkan nipasẹ iran, ala, isọtẹlẹ tabi awọn angẹli. Ṣugbọn ko ni lailai dari wọn lati ṣe ohunkohun ti o tako akọsilẹ ọrọ rẹ. Idi si ni yi ti o fi gbọdọ ma fi ojoojumọ fi ara rẹ jin fun ọrọ rẹ ati adura gbigba. Niwọn igba ti o ba ti n ṣe eyi, o le fi ọwọ sọya pe ọna ti o yẹ ki o gba laye yi ko tun ni lailai dojuru fun ọ mọ. Idi si ni pe Ọlọrun yoo ri daju pe a dari rẹ si oju ọna ti o yẹ ki o tọ.

Nitorina, fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun ati adura gbigba lojoojumọ. O si di dandan ki Ọlọrun dari rẹ sinu ohun gbogbo ti o darajulọ fun aye rẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi ara rẹ jìn fún ìtọ́ni rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 11, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 15 Read More »

Àkórí: Àlàáfià fún ìṣerere | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 04, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Ògún 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni alaafia ni gbogbo ọna, ni gbogbo igba ati lori ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ninu oṣu naa. Amin.

Ki ni idi ti o ṣe ṣe pataki ki a ni alaafia ninu wa ati ni gbogbo ayika wa? Idi pataki kan fun eyi ni pe alaafia m n gbe iṣerere ati ìgbáyégbádùn larugẹ. Nigba ti awọn eniyan ba wa ni alaafia ninu ọkan wọn, wọn le fi ara balẹ ronu, ki wọn si ni awọn ala lati ṣe nkan ti o ga. Lafikun, ti awọn eniyan ba ni alaafia ni gbogbo ayika wọn, wọn yoo le dari gbogbo okun wọn lati mu awọn ala wọn ṣẹ.

Ṣugbọn ti ọkan awọn eniyan ba poruru, ti ko si si ibalẹ-ọkan fun wọn, bi anfaani tilẹ wa fun wọn lati gbe awọn nkan ti o ga ṣe, ibẹru ko ni jẹ ki wọn ṣe amulo awọn anfaani yi. Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi nipa asiko ranpẹ kan ti o le ni Tiroa: “Ṣugbọn nigba ti mo de Tiroa lati waasu iyinrere Kirisiti, ti mo si ri wi pe Oluwa ti ṣilẹkun fun mi, Sibẹ emi ko ni alaafia lọkan mi, nitori ti emi ko ri Titu arakunrin mi nibẹ. Nitori idi eyi ni moṣe dagbere fun wọn, mo si rekọja lọ si Makedonia.” (2Kọ́ríntì 2:12-13)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe anfaani ti o ga wa fun apọsiteli yi lati waasu iyinrere ni ilu yẹn, ko le e ṣe amulo anfaani naa. Ki ni idi? Ko ni ibalẹ-ọkan. Nkankan n yọ ọ lẹnu. Ki si ni nkan naa? Oun naa ni pe ko ri Titu, alabaṣiṣẹpọ rẹ, nibẹ. O wa ṣeeṣe ki awa naa ṣe bakan naa pẹlu, ti a ba ba ara wa ni irufẹ ipo kanna. A le jẹ ki anfaani ti o jọju lati gbe nkan nla ṣe tabi lati jẹgbadun ara wa lọ, ti ara ẹni ti a fẹran kan ko ba ya tabi ti ẹni naa ba wa ni ipo iyọnu.

Lafikun, ti idarudapọ ba yi wa ka, bi a tilẹ ni awọn ala ati amuyẹ ti o ga, a le e ma le mu nkankan ti o nitunmọ jade lati ipasẹ awọn ala ati amuyẹ naa. Ọpọ ni o si ti ku pẹlu awọn ala ti o ga ti wọn ni nitoripe ibi ti wọn gbe ko ni alaafia ti o peye to lati fi aye gba ilọsiwaju. Bẹẹ si ni pẹlu, bi a ba tilẹ ri awọn ala wa mu wa si imuṣẹ ni agbegbe ti o kun fun idarudapọ ati iyọnu, a le ma le jẹgbadun iṣẹ ọwọ wa bi o ti ṣe tọ ni ibẹ.

Nitorina, ki a ni amuyẹ ti o ga ati ala ti o ga ni ibi ti ko ti si alaafia dabi ki a ma ni nkankan rara ni. Ki a tilẹ sọ otitọ, o le ma jẹ nkan ti o mọgbọn wa fun wa lati ma ronu tabi la ala lati ṣe nkan ti o ga ni ibi ti ko ti si alaafia. Fun apẹrẹ, nkan ti Ọlọrun sọ fun ọkunrin kan ti a n pe ni Baruku, ẹni ti o jẹ akọwe fun Jeremaya, ni eyi: “Ṣe iwọ yoo wa ohun rere fun ara rẹ? Nitori naa, ma ṣe wa wọn. Emi yoo mu ibi wa si ori awọn eniyan gbogbo ni Oluwa wi. Nibikibi ti o ba lọ ni emi yoo jẹ ki o sa asala ẹmi rẹ ni alaafia.” (Jeremaya 45:5)

Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun sọ fun Baruku lati ma ronu lati gbe ohun giga kankan ṣe fun ara rẹ ni ilẹ Juda ni asiko yẹn. Ko gbọdọ ronu lati kọ ile, bẹrẹ okowo tabi fẹ aya fun ara rẹ. Ki ni idi? Ajalu n bọ lori ilẹ naa. Ajalu ti o si n bọ yoo pa gbogbo orilẹ-ede naa run, yoo si tun le gbogbo awọn ti o wa nibẹ danu. Amọ ṣa o, Ọlọrun ṣe ileri lati pa ọkunrin yi mọ nibikibi ti o ba lọ.

Ṣe o wa ri bayi pe alaafia ṣe pataki gidigid fun ilọsiwaju ati igbayegbadun. Idi si ni yi ti a ṣe gbọdọ ma fi igba gbogbo gbadura, bi a ti ṣe paṣẹ fun wa ninu Iwe Mimọ, fun alaafia Ọlọrun lati jọba ninu aye wa ati ni gbogbo ayika wa. Nitorina, mo tun gbadura fun ọ lẹẹkan si, bi a ti ṣe bẹrẹ oṣu tuntun yi, pe ki Ọlọrun jẹ ki alaafia rẹ ti o kọja oye eniyan jọba ninu aye rẹ, ni ayika rẹ ati lori ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ògún 2024 ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Àlàáfià fún ìṣerere | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 04, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 14 Read More »

Àkórí: Kò ní gbàgbé rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 13

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Agemọ ati oṣu Ògún 2024 papọ mọ ara wọn. Adura mi fun ọ ni pe ki Ọlọrun, ninu ọsẹ naa, sọ gbogbo awọn ti O ti yan lati ran ọ lọwọ ji lati bẹrẹ si ni ṣe ohun gbogbo ti O ran wọn lati ṣe fun ọ fun ọ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikanṣoṣo ti ko ṣeeṣe ki O gbagbe wa tabi gbagbe lati mu ete rere rẹ ṣe fun wa ni Ọlọrun. Eniyan, fun oniruuru idi, le gbagbe wa tabi ki wọn gbegbe ileri ti wọn ṣe fun wa. Ṣugbọn Ọlọrun ko jẹ lailai gbagbe wa tabi gbagbe lati ṣe ojuṣe rẹ ni ṣiṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe. Iwo naa wo ohun ti O sọ fun wa nipasẹ wolii Aisaya lori eyi:

“Njẹ abiyamọ ha le gbagbe ọmọ ọmu rẹ ki o ma si ṣaanu fun ọmọ rẹ ti o ti bi? Bi o tilẹ jẹ pe oun le gbagbe Emi ki yoo gbagbe rẹ!” (Àìsáyà 49:15)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe nigba miran abiyamọ le ṣiṣẹ gbagbe awọn nkan kan ti o yẹ ki o ṣe fun ọmọ rẹ, Ọlọrun ko ni lailai gbagbe lati ṣe ohun ti o tọ fun wa ni asiko ti o yẹ. Nitoripe ko si ni lailai gbagbe wa, a ko gbọdọ sọ ireti nu nitoripe nkan ko i ti ma a lọ deede fun wa bi a ti ṣe fẹ. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a ma fi igba gbogbo gbadura si pe ki O ṣe ohun gbogbo ti o jẹ ti wa laṣepe, ki O si tun fun ọkan wa ni okun lati ma a rin pẹlu rẹ pẹlu suuru, ki a ma ba doju iṣẹ rẹ ninu aye wa ru.

Lafikun, a tun gbọdọ ma gbadura pe ki Ọlọrun la ọna fun gbogbo awọn ti O ti yan lati ṣe awọn nkan ti yoo yọri si imuṣẹ ete rere rẹ fun aye wa lati ṣe ifẹ rẹ ninu aye wa. Idi si ni pe ko ki i ṣe gbogbo nkan ti Ọlọrun fẹ ṣe fun wa naa ni yoo ṣe funrarẹ. Awọn nkan kan wa ti o jẹ wipe nipasẹ awọn eniyan ni yoo gba ṣe wọn fun wa. Ti awọn nkankan ba si wa n yọ irufẹ awọn wọnyi lẹnu tabi ti awọn nkan ti aye yi ti gba ọkan wọn, wọn le ma ranti lati ṣe ohun ti Ọlọrun ran wọn lati ṣe fun wa ni asiko ti o tọ tabi ki wọn ma ranti rara.

Fun apẹrẹ, Ọlọrun ni o yan ijọye Farao kan ti Josefu ba pade ninu tubu lati ran an lọwọ lati jade ninu tubu naa ati lati tun ṣiṣẹ fun igbega rẹ ni Ijibiti. Lotitọ, ọkunrin ko mọ ni asiko naa pe Ọlọrun lo mu awọn mejeeji pade ara wọn tabi ọna ti Ọlọrun fẹ gba lo oun lati ran Josefu lọwọ. Ṣugbọn o wa lori ọkan rẹ lati ran an lọwọ, ti nkan ba ṣenu ire fun un. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ki awọn kan to le ran wa lọwọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti fẹ ki wọn ṣe, nkan gbọdọ ma a lọ deede fun wọn. Aijẹbẹ, airoju tabi irẹwẹsi le ma jẹ ki wọn ri ti wa ro. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 40)

Nikukuru, nkan ma ṣenu ire fun ọkunrin yi, gẹgẹ bi Josẹfu ti fẹẹkan-tẹlẹri sọ fun. O jade kuro ninu tubu, a si tun da a pada si ipo giga ti o wa tẹlẹ ni Ijibiti. Sibẹsibẹ, fun awọn idi ti a ko mẹnuba ninu akọsilẹ iṣẹlẹ yi, o gbagbe Josefu patapata. Ki a tilẹ sọ otitọ, o gbagbe rẹ fun ọdun meji gbako.

Njẹ Josefu wa sọ ara rẹ di jatijati nitori eyi bi? Rara o! Ṣe o sọ ireti ninu Ọlọrun ati lori aye rẹ nu nitori eyi bi, pẹlu ero wipe ireti ominira oun ti sọnu? Rara o! Dipo eyi, nṣe ni o tẹsiwaju lati ma ṣe ohun ti o tọ ninu tubu ati lati mu suuru fun Ọlọrun. Nitorina, nigba ti asiko to, Ọlọrun, ti ko ki i lailai gbagbe awọn eniyan rẹ, mu ki awọn iṣẹlẹ waye ti o la ọna fun ọkunrin yi lati ranti Josefu ati lati ṣe awọn nkan ti o tọ lati mu jade kuro ninu tubu. Bi awọn ala pe Josefu yoo di ẹni giga ti Ọlọrun ti fifun un lati igba ewe rẹ wa si ṣe bẹrẹ si ni di mimuṣẹ leyi. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 41)

Nibakanna, Ọlọrun ko ni gbagbe iwọ naa. Nitorina, o le gbẹkẹle lati mu awọn ala didi ẹni-giga ati awọn ete rere rẹ fun aye rẹ ti O ti fi han ọ wa si imuṣẹ. Iwọ naa, bi Josefu, kan nilo lati mu suuru fun ni, ki o si tun tẹsiwaju lati ma ṣe ohun ti o tọ niwaju rẹ. Lara awọn nkan ti o tọ ti o si gbọdọ ma ṣe ni ki o ma gbadura si pe ki O la ọna fun gbogbo awọn ti O fẹ lo fun ọ lati ma ṣe ohun rere gbogbo ti o yẹ ki wọn ṣe fun ọ ni aidẹsẹ-duro. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati fi awọn nkan wọyin sọkan ati lati ma fi ojoojumọ gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu wọn, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Kò ní gbàgbé rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 13 Read More »

Àkórí: Ṣọ́ ìrìn rẹ| Láti ọwọ́: J.O. Lawal| Ọjọ́: Agẹmọ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀| Nọ́múbà: Vol. 13, No. 12

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹrin ninu oṣu Agẹmọ 2024. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ kọ ọkan rẹ ni bi a ti ṣe n ṣin in lotitọ, ki gbogbo nkan ti o n ṣe ninu ijọba rẹ ati fun ijọba rẹ ma ba ja si asan. Amin.

Wayi o, mo fẹ pe akiyesi rẹ si awọn nkan melokan ti Solomoni sọ fun wa ninu ọkan ninu awọn iwe rẹ lori bi a ti ṣe le ṣe amulo ti o peye wiwa wa ninu awọn ipade ijọ. Wo o:

“Ṣọ irin rẹ nigba ti o ba lọ si ile Ọlọrun. Ki iwọ ki o si mura lati gbọ ju ati ṣe irubọ aṣiwere, ti ko mọ wi pe oun n ṣe buburu. Ma ṣe yara pẹlu ẹnu un rẹ, ma sọ ohunkohun niwaju Ọlọrun. Ọlọrun n bẹ ni ọrun iwọ si wa ni aye, nitori naa jẹ ki ọrọ rẹ mọ ni iwọn.” (Oníwàásù 5:1-2)

Ki ni nkan akọkọ ti Solomọni n sọ fun wa ni ibi lori bi a ti ṣe le ṣe amulo ti o peye awọn ipade ijọ wa? Oun naa ni pe ki a sọ irin wa nigba ti a ba n lọ si awọn ipade yi. Eyi jasi pe a gbọdọ lọ si ipade ijọ kọọkan pẹlu ero ati ikiyesara. Bẹẹni, a gbọdọ mọ idi ti a n fi n lọ si awọn ipade yi ati nkan ti a fẹ jere nipa lilọ. Ki ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? Oun naa ni pe ki a ma ba fi asiko, okun ati awọn nkan miran ti a le na lori lilọ si awọn ipade naa ṣofo.

O wa bani-ninujẹ pe ọpọ ti o n lọ si ipade ijọ loni ni o kan lọ lati mu gbogbo ododo ṣe. Wọn ti sọ fun wọn pe aṣa ti o dara ni ki eniyan ma a lọ si ipade ijọ. Otitọ si ni pe aṣa ti o dara ni lati ma ṣe bẹ ẹ. Ṣugbọn ki o ni lọkan lati jere nipa lilọ si ipade ijọ kan tabi omiran? Ṣe nkankan tilẹ wa ti eniyan le jere nipa lilọ si awọn ipade yi? Ti awọn nkan ti eniyan le jere ba wa nipa lilọ, bawo ni o ṣe le fi ara rẹ si ipo ẹni ti yoo jere wọn? Ọpọ ni ko ki i fi awọn nkan wọnyi sọkan ti wọn ba n lọ si ipade ijọ. Nitorina, wọn ko ki pada ri ohunkohun jere ati wipe wọn yoo tun wa fi asiko, okun ati pẹlupẹlu owo wọn ṣofo. O ma ṣe o!

Nkan ekeji ti Solomoni sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn lori bi a ti ṣe le ṣe amulo ti o peye awọn ipade ijọ wa ni pataki ki ohun ti Ọlọrun fẹ sọ fun wa jẹ wa logun ju ohun ti a fẹ sọ fun un tabi fifun un lọ. Ṣe ko ye ki sọ nkankan fun Ọlọrun ninu awọn ipade ijọ wa ni? Bẹẹni, o yẹ ki a sọ nkan fun un, oniruuru nkan. Ati pe ṣe ko yẹ ki a fifun Ọlọrun ninu awọn ipade ijọ wa ni? Bẹẹni, o yẹ ki a fi fun un, ohun yowu ti ọkan wa ba fẹ lati fi fun un.

Amọ ṣa o, a gbọdọ ma fi igba gbogbo ranti pe nkan ti Ọlọrun fẹ ṣe lori aye wa jẹ ẹ logun ju ohun yowu ti a fẹ fifun un lọ. Nitorina, a gbọdọ gbe titẹsilẹ si i ati kẹkọ ẹkọ lati ọdọ rẹ leke ohun miran gbogbo. Nipa bayi, Oun yoo le fi han wa bi a ti ṣe le ba a sọrọ ati fifun un ni ọna ti o jẹ itẹwọgba niwaju rẹ.

Fun apẹrẹ, Jesu ni ọjọ kan bẹ ilẹ Maria, Mata ati Lasaru wo. Nigba ti Maria si wa joko si ẹsẹ rẹ lati kọ ẹkọ lọdọ rẹ lori bi a ti ṣe n tẹ Ọlọrun lọrun, nṣe ni Mata n sare siwa-sẹyin lati pese ounjẹ fun un. Bi Mata si ṣe wa woye pe Maria ko ṣetan lati darapọ mọ ninu ohun ti o n ṣe, o wa sọdọ Jesu lati fi ehonu han ati lati sọ fun pe ki O sọ fun arabinrin rẹ yi lati darapọ mọ ninu iṣẹ ti o n ṣe. Amọ si iyalẹnu rẹ, Oluwa ko ṣe bẹ ẹ rara. Dipo eyi, ọna ti O gba da lohun niyi: “Ṣugbọn Jesu si dahun, o si wi fun un pe, “Mata, Mata, iwọ n ṣe aniyan ati laalaa nitori ohun pupọ. Ṣugbọn ohun kan ni a ko le ṣe alaini, Maria si ti yan ipa rere naa ti a ko le gba lọwọ rẹ.” (Lúùkù 10:41-42)

Njẹ o ri bayẹn? A le ma sare siwa-sẹyin lori ohun pupọ fun Ọlọrun, ki awọn nkan ti a n ṣe si ma nitunmọ si i. Bi yoo si ti ri niyẹn, ti a ko ba kọkọ fi ara wa jin lati kọ lọdọ rẹ ohun naa pato ti O fẹ lati ọwọ wa. Mata, daju-ṣaka, ni asiko ti a n sọ yi fẹ mu inu Jesu dun nipa sise ounjẹ aladun fun Oun ati awọn ọmọ ẹyin rẹ. Ṣugbọn kọ ba tilẹ kọkọ joko lati kẹkọ lọdọ rẹ naa, ki o ba le mọ ohun naa pato ti O fẹ. Eyi si wa le jẹ ki o ri wipe ko tilẹ nilo ounjẹ oun rara ni asiko naa ati wipe nkan miran ni o nilo.

Nibakan naa, awa naa gbọdọ mu kikọ ẹkọ lọdọ Oluwa ni pataki ju ohun gbogbo miran lọ, paapaa julọ ninu awọn ipade ijọ wa. A gbọdọ ri wipe ohunkohun ko ja wa lole anfaani wa lati kẹkọ lọdọ rẹ. Aijẹbẹ, bi Solomoni ti ṣe sọ ninu ẹsẹ bibeli yẹn, o ṣeeṣe ki awọn ọrẹ adura, orin, owo ati iṣẹ isin wa ti a n ru si i pada wa jasi ẹbọ aṣiwere. Ṣe yoo wa pin wa lere fun ẹbọ aṣiwere yowu ti a ba ru si i? Rara! Nitorina, ni igba miran ti o ba n bọ wa si ọkankan ninu awọn ipade ijọ, fi awọn nkan wọnyi si ọkan. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ma fi gbogbo igba fun ọ ni okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Ṣọ́ ìrìn rẹ| Láti ọwọ́: J.O. Lawal| Ọjọ́: Agẹmọ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀| Nọ́múbà: Vol. 13, No. 12 Read More »

Kò ní gbàgbé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 14, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 11

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ranti ohun rere gbogbo ti O ti pete-pero lati ṣe ninu aye rẹ ninu ọdun yi, ki O si bẹrẹ si ni ṣe wọn ni kiakia, ki ogo rẹ ba a le fi ara han lakọtun ninu aye rẹ ki ọdun yi to pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a fi han wa ninu Iwe mimọ ni pe Ọlọrun ko ki i gbagbe tabi fojufo iṣẹ rere awọn eniyan. Bakan naa si ni pẹlu, ko ki i gbagbe tabi fojufo iṣẹ buburu awọn eniyan. Lotitọ, ti eniyan ika ba wa oju Ọlọrun fun aanu ati idariji, ti o si tun yi pada kuro ninu iwa ika rẹ, Ọlọrun yoo gbagbe gbogbo awọn iṣẹ ibi ti o ti ṣe ṣẹyin, ko si ni jẹ ẹ niya fun wọn. Idi si ni pe Ọlọrun aanu ni. (Wo: Iṣikiẹli 18:21-23)

Amọ niwọn igba ti ika ba tẹsiwaju lati ma gbe ninu iwa ika rẹ, Ọlọrun ko ni gbagbe iṣẹ ibi rẹ rara. Nigba ti asiko ba si to, bi o tilẹ jẹ wipe lẹyin ẹgbẹrun ọdun ni, yoo fi iya jẹ ẹ dandan ni ibamu pẹlu iwa ika rẹ. Fun apẹrẹ, nigba ti Sọọlu jẹ ọba lori Isiraẹli, Ọlọrun ran ọrọ yi si i nipa awọn ara AmalekiL “Emi ranti eyi ti Amalẹki ti ṣe si Isiraẹli, bi o ti lugọ de e ni ọna, nigba ti oun goke ti Ijibiti jade wa. Lọ nisisinyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nnkan wọn ni aparun, ma si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wa ni ẹnu ọmu, maluu ati aguntan, rankunmi ati kẹtẹkẹtẹ.” (1Sámúẹ́lì 15:2-3)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọlọpọ ọdun ti kọja lọ, Ọlọrun ko gbagbe iwa ika awọn ara Amaleki si awọn ọmọ Isiraẹli nigba ti wọn ṣeṣẹ ti Ijibiti jade wa (Ẹ́kísódù 17). Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O ranti dadara ohun gbogbo ti wọn ṣe, ti O si pinnu lati fi iya jẹ wọn le lori ni asiko Ọba Sọọlu. Idi si ni pe Oun jẹ Ọlọrun onidajọ ododo. Nitorina, ti o ba n ṣe ibi lọwọlọwọ yi, ti O si dabi ẹni pe Ọlọrun ko kọbiara si, idi ni pe asiko fun ijiya rẹ ko i ti to. Nigba ti asiko fun ijiya rẹ ba to, Ọlọrun ko ni gbagbe lati ba ọ wi lọna ti o tọ ati ti o yẹ.

Nibakan naa, ti o ba n ṣe rere, ti o si dabi ẹni pe Ọlọrun ko kọbiara si rara, ma dawọduro. Idi si ni pe Ọlọrun ko ni gbagbe tabi fojufo iṣẹ rere rẹ. Bibeli sọ wipe, “Nitori Ọlọrun ki i ṣe alaiṣododo ti yoo fi gbagbe iṣẹ yin ati ifẹ ti ẹyin fihan si orukọ rẹ, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe ati eyi ti ẹ si n ṣe fun awọn eniyan mimọ.” (Hébérù 6:10) Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun ko ki i ṣe alaiṣododo Ọlọrun. Ko ki i ṣe Ọlọrun ti O ma n ranti lati ṣan awọn ika eniyan lẹsan fun iṣẹ ika wọn ṣugbọn ti ko ki i ranti lati san awọn olododo lẹsan fun iṣẹ rere wọn.

Awa kan ti ni awọn ọga kan ri lẹnu iṣẹ ti wọn ma n fi igba gbogbo ranti lati bu wa ati lati fi iya jẹ wa fun awọn ikuna wa ṣugbọn ti wọn ko ki i ranti lati yin wa tabu lati pin wa ni ere fun awọn aṣeyọri ti a mu wa fun wọn. O si di dandan ki eyi fi irẹwẹsi si ọkan wa ni ọpọlọpọ ọna. Ṣugbọn Ọlọrun ko ri bayẹn. Oun o ki i ṣe Ọlọrun ti O ma n ranti kiki iwa ika awọn eniyan, ki O ba a le jẹ wọn niya ni ibamu pẹlu rẹ. Dipo eyi, Oun jẹ Ọlọrun ti O tun ma n ranti iṣẹ rere awọn eniyan pẹlu, ki O ba a le pi wọn lere ni ibamu pẹlu rẹ.

Amọ ṣa o, asiko ti Ọlọrun ma n fun awọn eniyan lere ko ki i ṣe eyi ti ẹnikẹni ninu wa le yan fun. Ko si ọkankan ninu wa ti o gbọn to lati yan asiko fun Ọlọrun lati san wa lẹsan fun awọn nkan rere ti a n ṣe. Oun nikan ni O gbọn to lati san wa lẹsan ni asiko ti o tọ, ni asiko ti a o le fi ara balẹ jẹgbadun ohunkohun ti O ba fun gẹgẹ bi ere. Idi si ni yi ti a fi sọ fun wa pe ki a ma ṣe jẹ ki rere su wa lati ma a ṣe, nitoripe Ọlọrun yoo ranti lati san wa ni ẹsan fun ni asiko ti o yẹ, ti a ko ba rẹwẹsi (Galati 6:9).

Nitorina, bi ko tilẹ da bi ẹnipe ohun rere kankan yoo jẹyọ lati ara awọn nkan ti o n ṣe fun Oluwa, fun awọn eniyan rẹ ati fun awọn ti o wa ni ayika rẹ, ma ṣe rẹwẹsi. Idi ni pe Ọlọrun n kiyesi ohun gbogbo. Nigba ti asiko ba si to, yoo ranti lati ṣan ọ lẹsan. Amọ ti o ba ti fi aye gba irẹwẹsi nitoripe o ko ri ere awọn nkan ti o n ṣe fun Ọlọrun ni kiakia, mọ wipe Oun naa ko ni ranti lati fun ọ ni ere fun iṣẹ rere ti o ko ṣe fun un. Nitorina, ma ṣe dẹkn lati ma ṣe rere. Dipo bẹ ẹ, nṣe ni ki o ma ṣe e lọpọlọpọ si i. Mo si gbadura pe ohunkohun ko ni fi idibajẹ sinu iṣẹ rere rẹ, ki o si jẹ ki o padanu awọn ere ti o tọ si ọ fun un, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kò ní gbàgbé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 14, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 11 Read More »

Ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 07, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 10

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Agẹmọ 2024. Mo gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi ojoojumọ gba okun lati duro gẹgẹ bi olotitọ si Oluwa, bi gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ ba tilẹ n ja a kulẹ. Amin.

Bi Jesu Oluwa wa ti ṣe tọka si fun wa, ọkan lara awọn nkan ti yoo fi han pe a jẹ ọmọlẹyin rẹ nitootọ ni imura wa lati korira awọn ti o sunmọ wa. Wo bi Luuku ti ṣe gbe eyi kalẹ ninu iyinrere rẹ:

“Awọn ọpọ ijọ eniyan n ba a lọ; o si yipada, o si wi fun wọn pe, “Bi ẹnikẹni ba tọ mi wa, ti ko si korira baba rẹ, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabinrin, ani ati ọkan ara rẹ pẹlu, ko le ṣe ọmọ-ẹyin mi. Ẹnikẹni ti ko ba ru agbelebuu rẹ, ki o si maa tọ mi lẹyin, ko le ṣe ọmọ-ẹyin mi.” (Lúùkù 14:25-27)

Njẹ o ri bayẹn? Ẹnikẹni ti yoo ba jẹ ọmọlẹyin Jesu Kirisiti Oluwa wa nitootọ gbọdọ korira baba ati iya rẹ, aya ati ọmọ rẹ, arakunrin ati arabinrin rẹ ati pẹlupẹlu aye oun tikararẹ. Ṣe eyi ko wa tako ọrọ ifẹ ti Jesu Kirisiti n fi ṣe iwaasu bi? Rara!

Ṣe o ri, nigba ti Oluwa sọ nkan wọnyi, ko tunmọ si pe ki a ma fẹran awọn eniyan wa rara. Ranti pe Oun funrarẹ ni O sọ fun wa pe ki a fẹran awọn ọta wa, ki a si tun ma gbadura fun wọn. Ti O ba si fẹ ki a fẹran awọn ọta wa ati pẹlupẹlu awọn ti o n ṣe inunibini si wa, ki a si tun ma gbadura fun wọn, ṣe ko wa ni fẹ ki fẹran awọn ẹbi ati ọrẹ wa ju bẹ ẹ lọ bi? Yoo fẹ ẹ. (Wo: Mátíù 5:43-48)

Nitorina, nigba ti O sọ wipe ki a korira awọn eniyan wa ki a ba le jẹ ọmọlẹyin rẹ, ko tunmọ si pe ki a ma ba wọn ṣe pọ pẹlu ifẹ. Dipo bẹẹ, nkan ti O n sọ ni pe a gbọdọ fẹran Oun, ki a si tun mu ni pataki ju wọn lọ. Eyi jasi pe, Oun ni O gbọdọ ma fi gbogbo igba siwaju ninu aye wa. Ti O ba si jẹ wipe Oun ni ẹni akọkọ ninu aye wa, a jẹ wipe ti awọn ẹbi tabi ọrẹ wa ba n ṣe oun ti o lodi si ifẹ rẹ, a ko ni darapọ mọ wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni a o duro ṣinṣin lati tako wọn.

Fun apẹrẹ, nigba ti Mose fẹ ṣe idajọ awọn ọmọ Isiraẹli fun ṣiṣe ere wura fun ara wọn lati ma jọsin dipo Ọlọrun ati fun sisọ ìjánu wọn nu ninu ajọyọ dindinrin ti wọn n ṣe, O bere lọwọ awọn eniyan naa, “Tani o wa ni iha ti Oluwa?” Gbogbo awọn ọmọ Lefi si ya wa si ọdọ rẹ. O wa fun wọn ni aṣẹ Oluwa, eyi ti o ni i ṣe pẹlu ki wọn mu ida wọn, ki wọn la agbo awọn ọmọ Isiraẹli kọja, ki wọn si pa ẹnikẹni ti ara rẹ ko i ti balẹ, bi ti o tilẹ jẹ wipe ẹbi wọn, ọrẹ wọn tabi aladugbo wọn ni ẹni naa. Wọn si ṣe bẹẹ.

Njẹ o wa le jẹ nkan ti o rọrun fun awọn ọmọ Lefi yi lati pa awọn obi wọn, ọmọ wọn, arakunrin wọn, arabinrin wọn, ọrẹ wọn tabi aladugbo wọn ni ọjọ yi. Rara! Agbelebu ti o wuwo jọjọ ni eyi jẹ fun wọn lati gbe, nitori fun gbogbo iyoku ọjọ aye wọn ni wọn yoo fi ma ranti pe awọn pa awọn eniyan awọn. Ṣugbọn nitoripe ifẹ wọn si Ọlọrun pọ ju eyi ti wọn ni si awọn eniyan wọnyi lọ, wọn pa wọn. Nitoripe wọn si ṣe bẹ, bibeli tẹsiwaju lati sọ eyi fun wa: “Nigba naa ni Mose wi pe, “Ẹ ti ya ara yin sọtọ fun Oluwa lonii, nitori iwọ ti dide si awọn ọmọ rẹ ati arakunrin rẹ, o si ti bukun fun ọ lonii,” (Ẹ́kísódù 32:29)

Ṣe o wa ri idi ti Ọlọrun ṣe yan ẹya Lefi lati arin gbogbo ẹya Isiraẹli yoku lati fi ara rẹ ha wọn, ki wọn ba a le ma ṣin in ninu tẹmipili rẹ? Idi naa ko ju wipe wọn korira awọn ẹbi wọn, ọrẹ wọn ati aladugbo wọn lati le bu ọla fun Ọlọrun. Jesu Oluwa wa si wa n sọ wipe awa naa gbọdọ mura lati rin pẹlu ẹmi kan naa, ti a ba fẹ jẹ ọmọlẹyin rẹ nitootọ.

Eyi ko wa jasi pe awa naa gbọdọ ṣetan lati pa awọn ẹbi tabi ọrẹ wa, nitoripe a fẹ fi ifẹ wa si Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa han. O si wa ṣeni laanu pe a si tun ri ọpọ ẹsin ninu aye loni ninu eyi ti awọn eniyan ti ro wipe pipa ẹlomiran fun Ọlọrun jẹ ọna ti o ga lati fi ifẹ wọn han si i. Ṣugbọn Ọlọrun ko ran ẹnikẹni lati pa ẹnikẹni fun un loni. Idi si ni pe O ti fa Jesu kalẹ gẹgẹ bi etutu fun gbogbo wa.

Amọ ṣa o, nkan ti O n sọ fun wa ni pe a gbọdọ ṣetan lati duro ṣinṣin lati tako ohunkohun ti Oun ba lodi si, bi o tilẹ jẹ wipe nkan naa kan awọn ẹjẹ ati ẹran ara wa. Ṣe a wa ṣetan lati ṣe eyi? Ṣe a ṣetan lati tako awọn obi, arakunrin, arabinrin, ọrẹ, aya, ọkọ ati ọmọ wa, ti wọn ba n rin lodi si ifẹ Ọlọrun? Kiki awọn ti o ba ṣetan lati ṣe eyi ni wọn jẹ ọmọlẹyin Jesu Kirisiti Oluwa wa ni tootọ, ko ki i ṣe awọn ti wọn kan n fi ọrọ ẹnu nikan pe ara wọn ni ọmọlẹyin. Mo si gbadura pe ki gbogbo wa gba okun lọdọ Ẹmi Ọlọrun lati ma fi ojoojumọ wa ni imura lati gbe agbelebu yowu ti a ni lati gbe lati jẹ ọmọlẹyin Jesu Oluwa tootọ. Amin.

Ki o ni ọ̀sẹ̀ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 07, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 10 Read More »

Àkórí: Ní ìgbàgbọ́ ti ara rẹ nínú rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 30, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 9

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ si ọjọ ti o kẹyin oṣu yi ati si ọsẹ kini ninu oṣu Agẹmọ ti a ṣẹṣẹ fẹ wọ inu rẹ. Adura mi si ni pe ki o ni iriri ogo Ọlọrun ninu aye rẹ ni awọn ọna ti o kọja ero rẹ ni ọṣẹ yi ati ninu gbogbo oṣu tuntun ti o wa niwaju wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo fẹ gba ọ niyanju lori pataki ki o mu ibaṣepọ tikararẹ pẹlu Ọlọrun ni ọkunkundun, dipo eyi ti o o fi ma gbẹkẹle ibaṣepọ awọn miran pẹlu rẹ gẹgẹ bi ọna lati jẹgbadun rẹ. Mo si n pe akiyesi rẹ si eyi nitoripe ọpọ lo wa loni ti wọn pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ṣugbọn ti o jẹ wipe ori igbagbọ awọn adari ijọ wọn ninu Ọlọrun tabi igbagbọ awọn kan ninu ẹbi wọn ninu Ọlọrun ni wọn gbojule fun ilọsiwaju tabi fun aabo wọn laye. Eyi si le ni ewu gidigidi fun wọn.

Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu bibeli nipa ọba Juda kan ti a n pe ni Joasi: “Joasi ṣe ohun ti o dara ni oju Oluwa ni gbogbo akoko Jehoiada alufaa.” (2Kironika 24:2) Ki ni idi ti ọkunrin yi ṣe ṣe ohun ti o tọ niwaju Ọlọrun ni asiko alufaa Jehoiada? Idi ni pe alufaa yii n dari rẹ ni ipa ọna ododo. A tilẹ ti sọ fun wa ninu akọsilẹ igbe aye rẹ pe alufaa yi gan an ni o yan awọn iyawo meji ti o fẹ fun un (2Kíróníkà 24:2).

Amọ sa o, lẹyin iku alufaa yi, nkan yi pada fun Joasi. O pa Oluwa ti, O si bẹrẹ si ni ṣe bi o ti ṣe wu u. Wo nkan ti a sọ ninu bibeli lori eyi:

“Lẹyin iku Jehoiada, awọn oniṣẹ Juda wa lati fi iforibalẹ wọn han si ọba. O si fesi si wọn. Wọn pa ile Oluwa ti, Ọlọrun baba a wọn. Wo si n sin awọn ere Aṣerah ati awọn oriṣa. Nitori ẹṣẹ wọn yii, ibinu Ọlọrun de sori Juda ati Jerusalẹmu. Bi o ti wu ki o ri, Oluwa ran awọn wolii si awọn eniyan lati mu wọn pada si ọdọ rẹ. Bi o tilẹ jẹ wi pe, wọn jẹrii nipa wọn, wọn ki yoo gbọ.” (2Kíróníkà 24:17-19)

Njẹ o ri bayẹn? Lẹyin iku Jehoiada, awọn adari ilẹ naa tan Joasi wọ inu ibọriṣa. O si tẹlẹ wọn. Ki ni idi ti o fi tẹle wọn? O tẹle wọn nitoripe oun funararẹ ko ni ibaṣepọ kankan ti o danmọran pẹlu Ọlọrun. Nitorina, o ṣe ohun yowu ti o ṣe fun Ọlọrun ṣaaju asiko yi nitori Jehoiada ni, ko ki i ṣe nitoripe o gbagbọ ninu Ọlọrun tabi ni ifẹ rẹ ni tootọ. Eyi tunmọ si pe o kan n ṣe oju aye ni. O kan n gbiyanju lati tẹ Jehoiada lọrun ni nitoripe oun ni ko jẹ ki wọn ti pa nigba ti o si jẹ ọmọ-ọwọ ati wipe oun ni o tọ ọ dagba, ti o si tun jẹ ki o ṣeeṣe fun lati di ọba. (Wo: 2Kíróníkà 22-23)

Amọ nigba ti ọkunrin yi ku, ti ko si si idi kankan fun lati ṣe ohunkohun lati tẹ lọrun mọ, o pa Ọlọrun ti, O si tẹle awọn miran wọ inu ibọriṣa lọ. Nitorina, a ke ijọba rẹ kuru, o si ku iku aitọjọ. Eyi, bi mo si ti ṣe sọ tẹlẹ, n fi han wa pe o ṣe pataki ki awa tikarawa ni ibaṣepọ tiwa pẹlu Ọlọrun. Eyi tunmọ si pe ma ṣe sin Ọlọrun, lọ si ipade sọọsi tabi ṣe bi eniyan mimọ nitoripe o kan fẹ tẹ awọn obi, ọrẹ, ọkọ, aya tabi ẹni ti o gba ọ ṣiṣẹ lọrun. Dipo eyi, nṣe ni ki o sin Ọlọrun, ki o si gbe igbe aye iwa mimọ nitoripe o ti mọ daju pe Oun ni ẹni naa ti O to gba ijọsin rẹ. Aijẹbẹ, asiko n bọ ti yoo han kedere si gbogbo awọn eniyan pe eke ni ọ lati ibẹrẹpẹpẹ.

Ni afikun, ti o ko ba ni ibaṣepọ ti ara rẹ pẹlu Ọlọrun, ti o si je wipe ojurere Ọlọrun ti o wa ninu aye awọn miran ni o gbojule, asiko le de ninu eyi ti o jẹ wipe awọn nikan ni igbagbọ wọn ninu Ọlọrun yoo le ṣiṣẹ fun, ko ni i le ṣiṣẹ fun ọ. Wo nkan ti Ọlọrun funrarẹ ni lati sọ fun wa lori eyi:

“Ọrọ Ọluwa tọ mi wa wi pe: “Ọmọ Eniyan bi orilẹ-ede kan ba dẹṣẹ si mi nipa iwa aiṣododo, emi yoo nawọ mi jade si wọn, lati gẹ ipese ounjẹ wọn, emi yoo ran iyan si wọn, emi yoo si pa eniyan ati ẹranko inu rẹ, bi awọn ọkinrin mẹta yii, Noa, Daniẹli ati Jobu tilẹ wa ninu wọn rẹ, kiki ẹmi ara wọn nikan ni wọn le fi ododo wọn gbala, Oluwa Olodumare wi.”” (Ìsíkíẹ́lì 14:12-14)

Mo mọ daju pe o ti ri alaye fun iku aitọjọ ti gbogbo awọn ọmọ Joobu ku ni ọjọ kan bayẹn (Joobu 1). Lati ibẹrẹpẹpẹ, igbagbọ baba wọn ninu Ọlọrun ni o n gbe wọn ro. Ṣugbọn igbagbọ rẹ ko le daabo bo wọn kuro lọwọ eṣu ni ọjọ ti o wa lati kọ lu ẹbi wọn; ohun nikan ni igbagbọ rẹ le da aabo bo. Ka wa lọ sọ wipe awọn naa mu Ọlọrun ni ọkunkundun bi oun ti ṣe mu ni ọkunkundun ni, o ṣeeṣe ki ọrọ naa ma lọ bi o ti ṣe lọ. Nitorina, ni igbagbọ ti ara rẹ ninu Ọlọrun dipo eyi ti o o fi ma gbojule igbagbọ awọn miran ninu rẹ. Nipa bayi, ti igbagbọ awọn miran ninu rẹ ba tilẹ kuna tabi rẹwẹsi, igbagbọ tirẹ ninu rẹ yoo le gbe ọ bori.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Ní ìgbàgbọ́ ti ara rẹ nínú rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 30, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 9 Read More »

Jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 23, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 8

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Òkúdù 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ri daju pe ohun rere gbogbo ti o yẹ ki o jẹ tirẹ lọsu yi jẹ tirẹ ki oṣu naa to pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n lọ lọsẹ yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu diẹ lara ọrọ Pọọlu si awọn ọmọ ijọ Kọrinti lori awọn ara ijọ Masidonia, eyi ti o sọ wi pe:

“Pẹlupẹlu, ara, awa n sọ fun yin ni ti oore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun awọn ijọ Masidonia; Bi o tilẹ jẹ wi pe a dan wọn wo nipa ipọnju, ti wọn si jẹ alaini, ṣugbọn wọn fi funni lọpọlọpọ. Nitori mo jẹrii pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, wọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn. Wọn n fi ẹbẹ pupọ rọ wa, ki awọn pẹlu le ni oore-ọfẹ lati ṣe alabaapin ninu iṣẹ-iranṣẹ ti ififunni fun awọn eniyan mimọ. Eyi si ju bi awa ti ro o si lọ, ṣugbọn wọn tete kọ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun. (2Kọ́ríntì 8:1-5)

Ki ni apọsiteli yi fẹ ki awọn ara Korinti mọ nipa awọn ijọ ti o wa ni Masidonia? O fẹ ki wọn mọ nipa oore-ọfẹ ara-ọtọ kan ti Ọlọrun fi fun wọn. Irufẹ oore-ọfẹ wo wa ni yẹn? Oore-ọfẹ ififunni ni. Ṣugbọn ṣe o wa le jẹ wipe awọ ijọ Masidonia nikan ni o n fifun iṣẹ Oluwa ni asiko ti Pọọlu kọ lẹta yi bi? Rara o! Ki wa lo fa ti o ṣe n pe akiyesi awọn onigbagbọ yoku si ififunni wọn? O n ṣe eyi nitori pe irufẹ ififunni wọn ko wọpọ, o si tun jẹ eyi ti o n peni nija.

Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, awọn ara Masidonia ko fi ara wọn jin lati ma fifun awọn apọsiteli ati awọn eniyan Ọlọrun miran nitoripe wọn ni owo gidigidi tabi nitoripe wọn ni ọrọ ju awọn ijọ Ọlọrun yoku lọ. Dipo eyi, ni asiko ti o kọ lẹta yi, ọpọ awọn ara yi ni o n ba iṣẹ ti o lagbara finra. A ko mọ ohun ti o fa iṣẹ fun wọn ni asiko yi. Ṣibẹsibẹ, wọn fifun Pọọlu ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ lati ran awọn eniyan Ọlọrun miran lọwọ pẹlu ayọ ati lọpọlọpọ.

Bi Pọọlu tilẹ ṣe tẹsiwaju lati fi ha wa ninu awọn ẹsẹ bibeli ti o wa loke yẹn, awọn ara yi fifunni kọja bi wọn ti ṣe lówó lọ́wọ́ si ni asiko naa. Yatọ si iyẹn, wọn tun bẹ apọsiteli yi lati fi aaye gba wọn lati fifunni. Eyi jasi pe, ti a ba ni ki a wo bi nkan ti ṣe ri fun wọn ni asiko yẹn, Pọọlu ko tilẹ ni fẹ ki wọn fun oun tabi ẹnikẹni ni ohunkohun rara. Ṣugbọn wọn bẹ ẹ lati ma fi anfaani lati fifun Ọlọrun ni ọna yi dun wọn. O wa yẹ ki o ri kedere bayi idi ti Pọọlu ṣe n pe akiyesi awọn ijọ Ọlọrun yoku si nkan ti awọn eniyan wọnyi ṣe. O jẹ nkan ti ko wọpọ, ti o si tun n peni nija.

Ki wa ni idi ti awọn ara yi ṣe fifunni ni ọna yi? Ki idi ti ẹnikẹni yoo ṣe fi tayọ-tayọ lawọ si awọn miran ni asiko aini oun tikalara rẹ? Alaye kan ṣoṣo fun eleyi ko ju wipe ifẹ Ọlọrun ti gba akoso aye ẹni naa lọ. Wo o, ọkan lara awọn nkan ti yoo jẹ ki a mọ wipe Ọlọrun ti gba akoso aye eniyan patapata pẹlu ifẹ rẹ ni pe ẹni naa yoo fẹ ẹ fun ni ohunkohun ati ohun gbogbo. Ẹni naa ko ni ma wo nkan ti oun ni tabi eyi ti oun ko ni lati fifunni; dipo eyi, nkan ti yoo ma wo ni awọn aini ti Ọlọrun fẹ ki oun ba pade.

Wo opo Sarefati, fun apẹrẹ. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ki Elija to wa gbe pẹlu rẹ rara ni Ọlọrun ti kọkọ ba a sọrọ nipa ati lori pataki ki O ba Oun ṣe itọju rẹ. Ki wa ni arabinrin yi ni ni asiko yi? Nkan ti o ni ko ma ju ikunwọ iyẹfun kan ati ororo diẹ lọ. Nkan ti o ni ko tilẹ to lati ṣe ounjẹ ẹẹkan fun oun ati ọmọkunrin kan ṣoṣo ti o ni. Ṣibẹsibẹ Ọlọrun sọ fun pe ki o tọju iransẹ Oun ti O n ran an si. Ṣe o wa gbọran si Ọlọrun lẹnu tabi ko gbọ? O gbọ! Ki ni idi ti o ṣe gbọ? Akọkọ, o gbọ nitoripe o fẹran Ọlọrun to lati fun un ni ohunkohun ti O ba fẹ lati ọwọ rẹ. Ekeji, o gbẹkẹle Ọlọrun to fun itọju oun ati ọmọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn fun ni gbogbo nkan yoku ti wọn ni lọwọ. Ṣe Ọlọrun wa ja a kulẹ tabi dojuti i? Rara o! (Wo: 1Àwọn Ọba 17)

Nibakan naa, awọn ara Masidonia fifun iṣẹ Ọlọrun bi wọn ti ṣe ṣe nitoripe wọn fẹran rẹ ati nitoripe wọn gbagbọ ninu rẹ. Ki lo si fa ti wọn fi le fẹran rẹ, ki wọn si tun gbẹkẹle bi wọn ti ṣe ṣe? Oun ti o fa nipe wọn fi aaye gba oore-ọfẹ rẹ lati ṣiṣẹ ninu aye wọn, lati kun wọn pẹlu ifẹ rẹ ati lati pa iwa adanikanjọpọn inu wọn run.

Wayi o, ti awa naa ba fi aye gba oore-ọfẹ Ọlọrun, awọn ipese agbara rẹ lati ṣiṣẹ ninu wa, lati yi wa pada, lati yọ ẹru wa danu ati lati pa ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu imọtara-ẹni-nikan inu wa run, a ko ni ni iṣoro mọ niti fifẹran rẹ ati gbigbẹkẹle tọkantọkan. Bi a ba si ṣe n fẹran rẹ, ti a si tun gbọkan le tọkantọkan, gẹgẹ bi awọn ijọ Masidonia, awa naa yoo ri wipe nṣe ni a o ma fifun un ni awọn ọna ti yoo pe ọkan awọn miran nija, ti yoo si tun ṣi oniruuru ilẹkun ipese iyanu silẹ fun wa. Njẹ iwọ yoo wa fi aye gba oore-ọfẹ rẹ lati ṣiṣẹ ninu rẹ ati lati pa imọtara-ẹni-nikan inu rẹ ati gbogbo awọn awawi ti o ma n ṣe fun bi o ko ṣe lawọ run bi?

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 23, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 8 Read More »