Author name: 23?Racing_Horse

Ìdí tí o ṣe yẹ kí o máa rìn nínú òdodo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 27

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọ yanturu lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu osu Belu, iyẹn oṣu kọkanla ọdun yi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun aye rẹ ninu oṣu naa pẹlu oniruuru ohun rere gbogbo ti yoo jẹ ki o gbagbe inira tabi adanu yowu ti o le ti ni iriri rẹ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu tuntun naa, mo fẹ gba ọ niyanju lati fi ara rẹ jin siwaju ati siwaju si lati maa ni rin ninu ododo. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe Ọlọrun ma n tẹ awọn ti o ba n rin ninu ododo lọrun pẹlu ohunkohun ti wọn ba nilo laye, bi o ti wu ki nkan le to nibi ti wọn wọn wa. Jesu sọ wipe, “Alabukun fun ni awọn ti ebi n pa, ti oungbẹ si n gbẹ fun ododo, nitoripe a o tẹ wọn lọrun.” O tun sọ wipe, “Ẹ kọkọ maa wa ijọba Ọlọrun naa, ati ododo rẹ; gbogbo awọn nnkan wọnyi ni a o si fi kun fun yin.” (Wo: Mátíù 5:6 & 6:33)

Nitorinaa, ti o ba fi ara rẹ jin fun ododo, Ọlọrun yoo ri daju pe o ko ṣe alaini ohunkohun ti o dara, bi o ti wu ki nkan buru to nibi ti o ba wa. Lotitọ, iwọ naa gbọdọ kọ bi a ti n tẹwọgba ipese Ọlọrun nipasẹ adura, ijẹwọ ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ-afọkanṣe. Amọ o le fọkanbalẹ lori pe Ọlọrun ko ni fi ohunkohun ti o nilo dun ọ, ti o ba fi ara rẹ jin lati ma rin ninu ododo.

Idi keji ti o ṣe yẹ ki o fi ara rẹ jin lati ma rin ninu ododo ni pe Ọlọrun yoo pa ọ mọ bi o ba ti n ṣe bẹ ẹ. Ọkan lara awọn idi ti awọn eniyan ko ki i fẹ fi ara wọn jin fun igbe aye ododo ni ibẹru inunibini. Bi a si ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ti o ba fẹ gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu yoo ba inunibini pade (2Tímótì 3:12). Amọ ṣa o, bibeli tun fi han wa pe aabo wa fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba fi ara wọn jin fun rinrin ninu ododo kuro lọwọ inunibini. Wọn kan nilo lati kan si Ọlọrun fun un ni.
Fun apẹrẹ, nitori ifarajin Daniẹli fun ododo ni mimojuto iṣẹ rẹ, iyẹn gẹgẹ bi adari ijọba, awọn akẹgbẹ rẹ, ọpọ awọn ẹni ti o jẹ oṣo, ṣe inunibini rẹ gidigan-an. Nigba ti wọn si ri wipe awọn ko le sasi tabi ri aleebu ninu itayọ iṣẹ-iriju rẹ, wọn dẹ pakute fun un. Nitorina, a sọ ọ ninu iho awọn kiniun. (Wo: Dáníẹ́lì 6:1-18)

Njẹ Ọlọrun wa pa a ti bi? Rara o! Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O ran angẹli kan lati pa awọn kiniun ti o wa pẹlu rẹ lẹnu mọ. Nitorina, wọn ko le e pa a lara. Nigbẹyingbẹyin, awọn ti o ditẹ mọ ọn, ati awọn aya ati awọn ọmọ wọn, ni o pada di jijẹ fun awọn kininu ti ebi n pa yi i. (Wo: Dáníẹ́lì 6:19-24)

Wayi o, eyi wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o sọ wipe:

“Nitori yoo fi aṣẹ fun awọn angẹli nipa tirẹ lati pa ọ mọ ni gbogbo ọna rẹ; Wọn yoo gbe ọ soke ni ọwọ wọn, nitori ki iwọ ma ba a fi ẹṣẹ rẹ gun okuta. Iwọ yoo rin lori kinniun ati paramọlẹ, iwọ yoo tẹ kinniun nla ati ejo ni iwọ yoo fi ẹsẹ tẹ mọlẹ. “Nitori ti ifẹ rẹ si mi, Emi yoo gba ọ, emi yoo pa ọ mọ, nitori iwọ jẹwọ orukọ mi.”” (Sáàmù 91:11-14)

Nitorina, ma lailai tun bẹru pe a o ṣe inunibini rẹ mọ nitoripe o n ṣe nkan ti o dara ati ti o tọ niwaju Ọlọrun. Idi si ni pe iwọ yoo ri aabo rẹ gba. Eyi yoo si yọri si igbega rẹ ati si idojuti fun awọn ọta rẹ, gẹgẹ bi o ti ri fun Daniẹli.

Ki o ni oṣu Belu 2024 alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìdí tí o ṣe yẹ kí o máa rìn nínú òdodo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 27 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Àkórí: Má ṣe gbàgbé Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 27, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 26

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu ti o so oṣu Ọ̀wàrà ati oṣu Belu 2024 pọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun tu ọ ninu nibikbi ti ara ti le ma ni ọ, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ki O si tun kun ọkan rẹ pẹlu ayọ akunwọsilẹ. Amin.

Ọrọ iyanju mi si ọ, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, ni a mu lati ara awọn nkan diẹ ti Ọlọrun tipasẹ Wolii Aisaya ba wa sọ, eyi ti o si ka bayi:

“Emi ni, ani emi ni ẹni ti n tu yin ninu: ta ni iwọ ti iwọ o fi bẹru eniyan ti yoo ku, ati ọmọ eniyan ti a ṣe bi koriko. Ti iwọ si gbagbe Oluwa Ẹlẹdaa rẹ ti o ti na awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aye sọlẹ; ti iwọ si ti n bẹru nigba gbogbo lojoojumọ nitori irunu aninilara ni, bi ẹni pe o ti mura lati panirun? Nibo ni irunu aninilara ha gbe wa? Onde ti a ti ṣi nipo yara ki a baa le tu u silẹ, ati ki o ma baa ku sinu iho, tabi ki ounjẹ rẹ ma baa tan.” (Àìsáyà 51:12-14)

Ki ni nkan akọkọ ti Ọlọrun kede si wa nibiyi? Oun naa ni pe Oun ni olutunu wa. Eyi jasi pe ti ko ba ṣe pe O ba tu wa ninu, ẹnikẹni ko le tu wa ninu. Eyi si ni alaye fun bi ọpọ ni orilẹ-ede wa loni, pẹlu awọn Kiristiẹni naa, ṣe n sorikọ, ti ọkan wọn si n poruru. Eyi ti wọn yoo fi ma a wo Ọlọrun fun itunu, nṣe ni wọn n wo awọn eniyan kan tabi ijọba fun itunu. Niwọn igba ti wọn ba si n ṣe eyi, wọn ko ni lailai ni iriri itunu otitọ lori gbogbo awọn nkan ti o n lepa lati dojuti wọn tabi lati pa wọn run.

Nkan ẹkeji ti Ọlọrun sọ fun wa nipasẹ Aisaya, bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ yẹn, ni pe aṣiṣe ni lati fi ààyè gba ibẹru eniyan lati jẹ ki a gbagbe pe Oun ni Ọlọrun ati Ẹlẹdaa wa. Lotitọ, a le ni oniruuru awọn eniyan ni ayika wa ti wọn ti mura tan lati pọn wa loju tabi pa wa run. Ijọba ilẹ wa gan le ma ni nkan miran ti o n ṣe ju ki o ma pa wa lara ati ki o ma mu aye le fun wa lọ.

Sibẹsibẹ, a ko gbọdọ gbagbe pe ijọba wa ko ki i ṣe ẹlẹdaa wa, bẹẹ si ni awọn ọdaran ti o wa ni ilẹ wa naa ko ki i ṣe ẹlẹdaa wa. Ọlọrun ni Ẹlẹdaa wa. Nitorina, a ko gbọdọ fi aye gba ohunkohun ti ijọba wa tabi ti awọn ọdaran ti o wa ni awujọ wa le e ma a ṣe lati jẹ ki a ma fi igba gbogbo gbe ninu ibẹru ati ifoya. Idi si ni pe Ọlọrun Ẹlẹdaa wa yoo tu wa lara lotitọ, yoo si tun yi ohun gbogbo ti a n ṣe lodi si wa pada si rere fun wa.

Iwọ naa tun wo nkan ti Ọlọrun sọ fun wa lati ipasẹ Aisaya lẹẹkan si. O sọ wipe bi o tilẹ jẹ wipe awọn aninilara ti mura tan lati pa wa run, Oun yoo sọ ete-ibi wọn si wa di asan. Nitorina, bi a tilẹ n duro lati ri nkan ti ete wọn lati pọn wa loju yoo ja mọ, a ko ni ri nkankan.

Lafikun, Ọlọrun sọ wipe Oun ti n ran irawọ si awọn ti ọrọ orilẹ-ede yi ti fi sinu atimọle, ti wọn ko si le tọju ara wọn ati ẹbi wọn bi o ti ṣe yẹ. O sọ wipe wọn ko ni ku sinu ipo ti wọn wa yi. Idi si nipe Oun yoo gba wọn, O yoo si tun tẹ ebi ti o n pa wọn lọrun.

Njẹ o wa gba awọn nkan wọnyi gbọ bi? Ṣe o gbagbọ pe Ọlọrun yoo tu gbogbo wa ni orilẹ-ede yi ti ara n ni, ti a si n woju rẹ fun iranlọwọ ninu lotitọ? Ṣe o gbagbọ pe, gẹgẹ bi Ẹlẹdaa wa, O ni agbara lati fooro gbogbo awọn ti o n pọ wọn loju ati ti o n ṣiṣẹ lati fi wa sinu tubu iṣẹ ati idojuti titi lailai?

Ti o ba gba awọn nkan wọnyi gbọ, nṣe ni ki o ya fi opin si gbogbo ibẹru rẹ. Bẹẹni, fi opin si ibẹru pe iwọ ati ile rẹ yoo ku sinu ebi tabi pe o ko ni i le fun awọn ọmọ rẹ ni ẹkọ ti o ye kooro tabi pe nṣe ni iwọ yoo ku gẹgẹ bi ayalegbe tabi pe o ko ni lailai tẹgbẹ laye. Idi si ni pe Ọlọrun Ẹlẹdaa rẹ yoo tu ọ ninu lọna ti o peye. Eyi yoo si jẹ ki o gbagbe gbogbo awọn ọjọ inira ati ibanujẹ rẹ. Bẹẹ si ni yoo ri, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Má ṣe gbàgbé Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 27, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 26 Read More »

Má ṣe jẹ́ kí a fún ọ̀rọ̀ rẹ pa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 20, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 25

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lai-lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o ba n di ọ lọwọ lati so eso lọpọlọpọ pẹlu ọrọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, ko to lati kan gbọ ọrọ Ọlọrun; o tun ṣe pataki ki a tun so eso nkan ti ọrọ ti a gbo n sọrọ nipa. Aijẹbẹ, gbogbo nkan ti a n gbọ yoo kan ṣofo danu lasan ni. Ọna kan pataki lati so eso nkan ti ọrọ ti a n gbọ n sọrọ nipa ni ki a gbe igbesẹ lori nkan ti ọrọ naa sọ. Sibẹsibẹ, ọpọ awọn ẹni ti o n gbọ ọrọ Ọlọrun ni ko ki i ṣiṣẹ le lori. Bibeli tilẹ sọrọ nipa awọn kan ti wọn ma n fi igba gbogbo kẹkọ ṣugbọn ti wọn ko si pàpà ni imọ otitọ. Ki ni idi ti eyi ṣe ri bẹ? Ki ni idi ti ẹnikan yoo fi ma fi igba gbogbo wa fun ipade ijọ, ti ko si tun ni ni imọ otitọ nkan ti Ọlọrun n ba a sọ, ka ma tilẹ ti sọ wipe ki o ṣiṣe le nkan ti a n ba a sọ? (2Tímótì 3:7)

Ki a ma deena pa ẹnu, gẹgẹ bi Oluwa ti fi han nipasẹ ọkan lara awọn owe rẹ, ọkan lara idi ti eyi fi ri bẹẹ ni pe awọn eniyan ma n jẹ ki ẹ̀gún fun nkan ti wọn n gbọ pa. Ki wa si ni awọn ẹgun ti Oluwa n sọrọ nipa? Nkan ti O sọ nipa wọn ni eyi: “Awọn wọnyi ni awọn ti a fun saarin ẹ̀gún: awọn ti o gbọ ọrọ naa. Aniyan aye, ati itanjẹ ọrọ, ati ifẹkufẹẹ ohun miiran si bọ sinu wọn, wọn fun ọrọ naa pa, bẹẹ ni o si jẹ alai-leso.” (Máàkù 4:18-19)

Njẹ o ri bayẹn? Lara awọn ẹgun ti o ma n fun ọrọ Ọlọrun pa ninu aye awọn eniyan aniyan. Eyi jasi pe, nigba ti awọn eniyan ba fi ara wọn jin lati ma ṣaniyan lori awọn iṣoro wọn, dipo ti wọn yoo fi maa ṣe aṣaro lori nkan ti Ọlọrun n ba wọn sọ, o di dandan ki awọn aniyan wọn wọnyi fun ọrọ ti wọn ti gba pa ti o ba to asiko kan. Nitorina, ọrọ naa ko ni ṣiṣẹ ninu aye wọn. O si wa ṣeni laanu pe, a ri ọpọ eniyan ti o n wa fun ipade ijọ, ti wọn si n fi gbogbo asiko wọn ṣe aniyan lori awọn iṣoro wọn dipo ti wọn yoo fi ma tẹtẹ si ọrọ Ọlọrun ti a n kọ wọn. Bawo wa ni irufẹ awọn wọnyi ṣe fẹ so eso rere pẹlu ọrọ Ọlọrun?

Ni afikun, Oluwa sọ fun wa pe itanjẹ ọrọ ati ilepa awọn eniyan naa tun wa lara awọn nkan ti o ma n fun ọrọ Ọlọrun pa ninu aye awọn eniyan. Eyi jasi pe nigba ti awọn eniyan ba ti fẹ fi tipa-tipa ni owo, ipo, iyi tabi igbadun, bi wọn tilẹ n gbọ ọrọ Ọlọrun, ọwọ wọn yoo ti kun debi pe wọn ko ni ri aye lati ṣe aṣaro lori ọrọ rẹ ati lati lo ninu aye wọn. Nitorina, ọrọ naa ko ni i le ṣiṣẹ ninu aye wọn, ki o si yi ati awọn ati igba wọn pada.

Idi niyi, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ti a fi ri ọpọ eniyan ti o n wa si ipade ijọ lọsọọsẹ, ti aye wọn ko si yipada. Bẹẹni, idi niyi ti ọpọ fi n gbọ ọrọ Ọlọrun lọsọọsẹ ninu awọn ipade ijọ wọn, ti wọn si tun n gbe igbesẹ omugọ lori aye wọn, igbeyawo wọn, okowo wọn ati bẹẹ-bẹẹ lọ. Wọn ko jẹ ki ọrọ Ọlọrun ko ṣiṣẹ ninu aye wọn, ki o si sọ wọn da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki wọn da. Dipo eyi, nṣe ni wọn n fun ọrọ naa pa nipasẹ awọn ibaṣepọ aimọ, ilepa ọrọ, ipo ati iyi ati itara fun aye-jijẹ.

Ṣe ki a wa pa gbogbo awọn ibaṣepọ wa ti sẹgbẹ kan nitoripe a fẹ wa pẹlu Jesu bi? Rara o! Ọrọ Ọlọrun ko pa a lasẹ fun wa pe ki a ṣe bẹ ẹ. Amọ ṣa o, o pa a laṣẹ fun wa lati ya gbogbo awọn ibaṣepọ wa si mimọ. Eyi jasi pe, o fẹ ki a ṣe amojuto awọn ibaṣepọ wa lọna ti o fi ogo fun Ọlọrun. Ibaṣepọ pẹlu ẹnikẹni, wayi, ti ko ba ti fi ogo fun Ọlọrun gbọdọ jẹ kikọ-silẹ fun wa. Aijẹbẹ, ibaṣepọ naa ko ni dẹkun lati ma fun ọrọ Ọlọrun pa ninu aye wa.

Lafikun, ṣe ko wa tọna fun wa ni lati ni ọrọ, lati wa ni ipo giga tabi lati jẹ gbajumọ? Rara o, eyi ko buru o. Amọ ti a ba fi aye gba ọkankan ninu awọn nkan wọnyi lati jẹ akọkọ ninu aye wa, ko si bi ọrọ Ọlọrun yoo ti le so eso ninu aye wa bi o ti tọ. Bawo wa ni ti faaji? Ṣe Ọlọrun ko fẹ ki jẹgbadun ara wa ni? O kuku fẹ ki a jẹgbadun ara wa. Amọ ti a ba wa sọ ohun gbogbo nipa aye yi di ọrọ faaji, ki a si bẹrẹ si ni ro wipe nkan yoo ṣe wa, ti a ko ba lọ si awọn ode kan, wo awọn sinima kan tabi jẹ awọn nkan adidun kan, ko si bi ọrọ Ọlọrun yoo ti ṣe so eso ninu aye wa bi o ti ọ — yoo ti di fifun pa.

Nitorina, ti isesorere rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ba jẹ ọ logun rara, nṣe ni ki o ṣe idamọ ohunkohun ti o le ma fun ọrọ yi pa ninu ayẹ rẹ, ki o si mojuto lẹsẹkẹsẹ. Aijẹbẹ, bi o tilẹ n tẹti si ọrọ Ọlọrun titi Jesu yoo fi de, aye rẹ ko ni yipada lati da ohun ti Ọlọrun fẹ ki o da. Ṣe nkan ti o wa fẹ niyẹn bi? Mo gbadura pe ki o gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ lati iṣẹju yi lọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe jẹ́ kí a fún ọ̀rọ̀ rẹ pa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 20, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 25 Read More »

Má ṣe ọlọgbọ́n lójú ara rẹ | By: J.O. Lawal | Date: October 13, 2024 | Series: From Pastor’s Desk | Number: Vol. 13, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Mo ba ọ yọ ninu Oluwa bi a ti ṣe wọ inu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2024. Adura mi ni pe ki a pa ẹsẹ rẹ mọ kuro ni ọna iparun ni ọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Solomọni ti o sọ wipe: “Ma ṣe jẹ ọlọgbọn loju ara a rẹ, bẹru Oluwa ki o si korira ibi. Eyi yoo mu ilera fun ara a rẹ ati okun fun awọn egungun rẹ”(Ìwé Òwe 3:7-8) Ki ni aṣẹ ti a pa fun wa nibiyi? Oun naa ni pe ki a ma ṣe jẹ ọlọgbọn loju ara wa ninu ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun. Eyi jasi pe a ko gbọdọ lailai ro wipe a mọ ju Ọlọrun Ẹlẹda wa lọ. Idi si ni pe a ko mọ ju u lọ tabi mọ to o rara. Ti a ba si gba pe a ko ni imọ to Ọlọrun ninu ohunkohun, nṣe ni a o rẹ ara wa silẹ niwaju rẹ, ti a o si ma rin ninu ibẹru rẹ.

O wa ṣeni laanu pe Solomọni gan ti o sọ awọn ọrọ yi kuna lati pa wọn mọ lori ọrọ igbeyawo ti ara rẹ. Lọna wo? Ni kukuru, Ọlọrun, ninu ọgbọn rẹ, ti sọ fun awọn ọmọ Isiraẹli lati ma ba awọn eniyan orilẹ-ede ti o wa ni ayika wọn da nkan pọ niti igbeyawo. Ki ni idi? Ṣe nitoripe ko fẹran awọn eniyan wọnyi ni? Rara o! Ọlọrun fẹran awọn naa pẹlu. Amọ Oun kọ ni wọn n sin bikoṣe ere ati awọn ẹmi eṣu. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, ti awọn ọmọ Isiraẹli ba bẹrẹ si ni fẹ wọn, ti wọn si tun gbe wọn niyawo, ko ni i pẹ rara ti wọn yoo fi tan wọn wọ inu ibọriṣa. Nitorina, Ọlọrun kilọ fun wọn gidigidi lati ma fẹ wọn tabi gbe wọn niyawo. (Wo: Ẹ́kísódù 34:16; Ditarónímì 7:3-4)

Ṣugbọn Solomọni kọ ọrọ ọgbọn Ọlọrun yi silẹ patapata, o si tẹsiwaju lati fẹ oniruuru ajeji obinrin. Ki ni idi? O ni lati jẹ wipe o ṣe eyi nitoripe o woye pe oun gbọn to lati ṣakoso awọn obinrin wọnyi. Ranti wipe Ọlọrun fun ni ọgbọn ati oye ti ko lodiwọn, bi iyanrin eti okun. Eyi lo si jẹ ki o ro wipe oun ni yoo tọ awọn obinrin yi i lati ma sin Ọlọrun dipo ki awọn tọ ọ lati ma sin awọn oriṣa wọn.

Amọ ṣa o, Ọlọrun kannaa ti O fun ni ọgbọn ni O tun pasẹ fun oun ati awọn eniyan rẹ lati ma ṣe fẹ tabi gbe awọn ajeji niyawo. Ti o ba si wa jẹ wipe oun gan an gba ọrọ oun tikararẹ ti o sọ wipe, “Ma ṣe jẹ ọlọgbọn ni oju ara rẹ,” gbọ ni, ko ba ti mọ wipe ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu iyapa kuro ninu aṣẹ Ọlọrun ki i ṣe ifarahan ọgbọn rara. Dipo bẹ, o ni i ṣe pẹlu ki a ma ṣe bi ọlọgbọn loju ara wa. Eyi jasi pe a n gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu ọgbọn ara wa. Nigba ti a ba si wa kọ ọgbọn Ọlọrun silẹ bi eyi lati tẹle ọgbọn ara wa, a o pada ri nikẹyin-kẹyin pe iṣe omugọ ni gbogbo nkan ti a n pe ni ọgbọn wa.

Wayi o, nitoripe Solomọni kọ ọgbọn Ọlọrun silẹ, ti o si tẹlẹ ọgbọn ẹlẹran-ara lori ọrọ igbeyawo rẹ, o pada di omugọ ọba. Wo nkan ti bibeli sọ lori eyi:

“O si ni ẹẹdẹgbẹrin (700) obinrin, awọn ọmọ ọba ati ọọdunrun (300) ale, awọn iyawo rẹ si yi i ni ọkan pada. Bi Solomoni si ti di arugbo, awọn iyawo rẹ si yi ni ọkan pada si ọlọrun miiran, ọkan rẹ ko si ṣe deede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ, gẹgẹ bi ọkan Dafidi baba rẹ ti ṣe. O tọ Asitoreti oriṣa awọn ara Sidoni lẹyin, ati Milikomi oriṣa irira awọn ọmọ Amoni. Bẹẹ ni Solomọni ṣe buburu niwaju Oluwa, ko si tọ Oluwa lẹyin ni pipe, bi Dafidi baba rẹ ti ṣe.” (1Àwọn Ọba 11:3-6)

Njẹ o ri bayẹn? Awọn ajeji obirin ti Solomọni kojọ pada ṣi i lọna nigba ti o darugbo tan, ki ko si ni okun-inu mọ lati ma kọbiara si iyọlẹnu wọn. Nitorina, nkan ti ọgbọn Ọlọrun sọ wipe yoo ṣẹlẹ gan an lo papa wa ṣẹlẹ. Eyi si jẹ ki Solomọni padanu pupọjulọ lara ijọba rẹ si ọwọ ọkan lara awọn ọmọ ti o wa labẹ iṣakoso rẹ. O ma ṣe o! (Wo: 1Awọn Ọba 11:26-39)

Ki wa ni koko ọrọ yi gan an? Oun naa ni pe ti ọgbọn Ọlọrun ba ti ba wa sọrọ lori nkan, nṣe ni ki a tẹwọgba oun ti o sọ, ki a si ma ṣe wa ọna miran, yala ọna miran ti o rọrun ni tabi eyi ti ko rọrun. Idi si ni pe ọna omugọ ni ọnakọna ti o ba yatọ si eyi ti ọgbọn Ọlọrun ti fi han. Ọna yi ko si ni mu ilera ati alaafia wa sinu aye wa bikoṣepe yoo le wọn jinna si wa, bi o ti ṣe ri fun Solomọni. Nitorina, ṣọra lati ma jẹ ọlọgbọn loju ara rẹ nidi okowo rẹ, ibi-iṣẹ rẹ, ile-iwe rẹ, adugbọ rẹ, eto-isuna rẹ, iṣẹ-isin Kirisitiẹni rẹ, igbeyawo rẹ tabi ibaniṣọrẹ rẹ. Idi si ni pe ṣiṣe bẹẹ di dandan ko fi ọ han gẹgẹ bi omugọ nikẹyin-kẹyin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe ọlọgbọ́n lójú ara rẹ | By: J.O. Lawal | Date: October 13, 2024 | Series: From Pastor’s Desk | Number: Vol. 13, No. 24 Read More »

Má sọ di tìpá-tìkúùkù | By: J.O. Lawal | Date: October 06, 2024 | Series: From Pastor’s Desk | Number: Vol. 13, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ pa ọ mọ kuro ninu ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu igbesẹ tipa-tikuuku, bi o ti wu ki nkan ti o n dojukọ laye yi ri, ki o ma ba ba alaafia, ayọ ati aye rẹ jẹ pẹlu ọwọ ara rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan rẹ ni ohun gbogbo ti wọn nilo lati gbe igbe aye ti o ni itumọ, ko fẹ ki wọn sọ nini ohunkohun di tipa-tikuuku. Idi si ni pe awọn ti o ba n ri irin tipa-tikuuku ko ni ṣe alai-ma ṣe awọn nkan omugọ ati awọn nkan ti o le pa wọn lara, ninu ilakaka wọn lati ni awọn nkan ti wọn fẹ. Nitorina, bi wọn tilẹ pada ni awọn nkan ti wọn n fẹ yi, nkan ti wọn yoo fi di le tobi to ẹmi awọn tikalara wọn. Ko tilẹ si wa si idaniloju pe wọn yoo ri nkan ti wọn n fẹ naa. Ti wọn ko ba si ri, a jẹ wipe wọn pofo ọna meji niyẹn.

Fun apẹrẹ, nitoripe Ọba Sọọlu fẹ fi tipa-tikuuku pa ijọba rẹ mọ, o fi igbakanri gbe igbesẹ lati ru ẹbọ ti o yẹ ki Samuẹli ru. Ṣe alufaa ni oun ni? Rara o! Boya o si ni awọn ifihan kan lati ọdọ Ọlọrun lori irufẹ ẹbọ ti o yẹ ki o ru ni asiko naa? Rara o! Ki wa lo fa ti o fi gbe igbesẹ lati ru ẹbọ naa? O ṣe bẹẹ nitoripe o fẹ fi tipa-tikuuku pa ijọba rẹ mọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 13)

Amọ ṣe oun lo fa ijọba yi le ara rẹ lọwọ? Rara o, oun ma kọ ni. Ọlọrun ni O fi fun un. Ki wa lo jẹ ki o ro wipe ohun le pa nkan naa ti ko fun ara rẹ mọ fun ara rẹ? Agọ̀ lo fa a! Nitori igbesẹ agọ ti o si gbe yi, Ọlọrun sọ fun pe ijọba rẹ ko ni pe titi ṣugbọn yoo wa si opin lori rẹ.

Lafikun, igba miran kan tun wa ti ọkunrin yi pinnu lati tọ àjẹ́ kan lọ nitoripe o fẹ fi tipa-tìpa mọ ibi ti ogun kan ti o fẹ ba awọn ara Filistini ja yoo yọri si. O ti gbiyanju lati jẹ ki Ọlọrun ba oun sọrọ lori ibi ti ogun naa yoo jasi. Ṣugbọn Ọlọrun ko ṣetan lati sọ ohunkohun fun un, niwọn igba ti o jẹ wipe oun funrarẹ ko ri ti Ọlọrun ro tẹlẹ ki o to di asiko iṣoro rẹ yi. Nigba ti o si ti wa mura lati fi tipa-tikuuku mọ ibi ti ogun naa yoo ja si, yala Ọlọrun ba a sọrọ lori rẹ tabi ko ba a sọrọ, o gba ọdọ àjẹ kan lọ fun ayẹwo. Bi o si ṣe sọ ọkan rẹ nu pẹlu ijọba rẹ ni eyi. (Wo: 1Sámúẹ́lì 28)

Ki wa ni nkan wọnyi n sọ ọ fun wa? Oun naa ni pe a ko gbọdọ fi aye gba nkan yowu ti a fẹ lọkan wa lati ni tabi lati ṣe lati jẹ ki a ma gbe igbesẹ tipa-tikuuku. Bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ko si nkan ti a fẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ti ko ni fẹ fi fun wa. Ṣugbọn asiko ti o ba tọ ni yoo to fun wa ni ohun yowu ti a nilo. Nitorina, a gbọdọ mu suuru pẹlu rẹ. Aijẹbẹ, ko si ni ki a ma sọ ọrọ wa di tipa-tikuuku.

Wayi o, ti a ba fi le jẹ ki ọrọ tipa-tikuuku ba aye wa, nṣe ni a o bẹrẹ si ni wa ohun ti ko sọnu kaakiri ni awọn ibi ti ko yẹ ki a de rara. Nitorina, ọmọ Ọlọrun le ba ara rẹ ni ile oṣo fun iṣeṣo-owo tabi fun eso inu. Tabi ki ọmọ Ọlọrun ba ara rẹ ninu igbeyawo ofege nitoripe o ṣa fẹ lo gbe òkè-òkun. Lẹyin-ọ-rẹyin, ayọ, ibalẹ-ọkan ati iṣoriire ti o ro wipe o yoo ni yoo ba fo o ru. Eyi si tun wa yatọ si pe yoo tun padanu ọkan rẹ pẹlu.

Nitorina, bi o ti wu ki o ni itara to lati ni nkan tabi bi o ti wu ki a ma figun mọ ọ to lati ṣe nkan, nṣe ni ki o kọ́ lati ma fi igbẹkele rẹ sinu Ọlọrun ati lati ma duro de asiko rẹ. Nipa ṣiṣe eyi, o ko ni pada wa padanu alaafia, ayọ ati ọkan rẹ ninu ilakaka rẹ lati ni ayọ tabi lati ṣe aṣeyọri laye.

Ki o ni ọsẹ ologo.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má sọ di tìpá-tìkúùkù | By: J.O. Lawal | Date: October 06, 2024 | Series: From Pastor’s Desk | Number: Vol. 13, No. 23 Read More »

Ebi àti ìpòngbẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 29, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òwewè ati Ọ̀wàrà 2024 pọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi igba gbogbo jẹ ki ọkan rẹ pongbẹ fun un, ki o ba a le e mọ ọn bi o ti ṣe yẹ ki o mọ ọn ati ki o ba a le gbadun ohun rere gbogbo ti O ni ni ipamọ fun ọ. Amin.

Bibeli sọ eyi fun wa nipa ọna lati mọ Ọlọrun ni ọna ti o peye ati lati gba itẹlọrun lọwọ rẹ laye yi: “Alabukun-fun ni awọn ti ebi n pa, ti oungbẹ n gbẹ nitori ododo, nitori wọn yoo yo.” (Mátíù 5:6) Ki ni eyi n sọ fun wa? Oun naa nipe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ fi ara rẹ han wa, ti O si tun fẹ mu ete rere rẹ fun aye wa ṣẹ, kiki awa ti ebi n ba pa wa, ti oungbẹ si tun n gbẹ wa fun un ati fun awọn nkan ti O ni fun wa ni yoo pada gba itẹlọrun lẹkunrẹrẹ. Awọn ti ebi ko pa wọn, ti oungbẹ ko si tun gbẹ wọn fun un n fi han pe awọn ko nilo rẹ. Nitorina, bi wọn tilẹ n fi ẹnu jẹwọ rẹ gẹgẹ bi Ọlọrun wọn, gbogbo nkan ti wọn le reti lati jẹgbadun lọwọ rẹ ko ju awọn ibukun gbogbogboo rẹ lọ.

Ti o ba wo inu bibeli, iwọ yoo ro wipe awọn ti o mọ Ọlọrun daradara, ti wọn si tun jẹgbadun Ibukun rẹ ni awọn ọna ti ko wọpọ ni awọn ti o fi han pe ebi ati oungbẹ fun un n pa awọn gidigidi. Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa nipa Mose ati awọn ọmọ Isiraẹli: “O fi ọna rẹ han fun Mose, iṣẹ rẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli.” (Sáàmù 103:7) Njẹ o ri bayi pe iyatọ ti o ga wa lara bi Ọlọrun ti ṣe ba Moṣe lo pọ ati bi O ti ṣe ba awọn ọmọ Isiraẹli lo pọ? Gbogbo nkan ti awọn ọmọ Isiraẹli n ri ko ju awọn iṣẹ iyanu Ọlọrun ti a ṣe fun wọn lọ. Wọn ko ni oye idi ti O ṣe n ṣe awọn iṣẹ yi tabi nkan ti wọn le ṣe lati jẹ ki awọn iṣẹ yi waye.

Ṣugbọn Mose le sọ idi ti Ọlọrun ṣe ṣe ohunkohun ti O ṣe fun awọn ọmọ Isiraẹli. O si tun le sọ idi ti Ọlọrun ṣe un wọn ni awọn ofin ti O fun wọn pẹlu. Idi si ni pe oun mọ ọna Ọlọrun. Bawo lo ṣe wa mọ ọna Ọlọrun? Ṣe nitoripe Ọlọrun pe, ti O si tun ran an lati lọ tu orilẹ-ede Isiraẹli silẹ kuro ni Ijibiti ni? Rara o! Dipo eyi, titoripe ebi n pa a, oungbẹ si tun n gbẹ ẹ lati mọ Ọlọrun ati lati mọ ọna rẹ ni o ṣe ribẹ. Iwọ naa wo diẹ lara awọn adura rẹ si Ọlọrun:

“Bi iwọ ba ni inu didun pẹlu mi, kọ mi ni ọna rẹ, ki emi ki o le mọ ọ, ki n si le maa wa oju rere rẹ pẹlu. Ranti wi pe orilẹ-ede yii eniyan rẹ ni.” (Ẹ́kísódù 33:13)

“Mose si wi pe, “Nisinsin yii fi ogo rẹ han mi.”” (Ẹ́kísódù 33:18)

Njẹ o ri bayẹn? Ko tẹ Mose lọrun lati kan jẹ adari orilẹ-ede Israẹli. Bẹẹ si ni ko tẹ lọrun lati kan jẹ oniṣẹ-iyanu. Dipo bẹẹ, o tun fẹ mọ Ọlọrun ni ọna ti o peye, ki o si tun ri ogo rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe o mọ wipe fun igba diẹ naa ni oun fi le jẹ adari orilẹ-ede Israẹli ati oniṣẹ-iyanu. Nigba ti o ba ya, yoo ku, yoo si fi ohun gbogbo silẹ. Ṣugbọn ti o ba mọ Ọlọrun, ti o si ri ogo rẹ, yoo ma a ba a gbe titi lailai. Niwọn igba ti o si jẹ wipe nkan ti ebi n pa a fun, ti oungbẹ si n gbẹ ẹ fun ni eyi, Ọlọrun fi tẹ lọrun.

Tun wo Dafidi naa. Ki ni idi ti o ṣe mọ Ọlọrun bi o ti ṣe mọ ọn, bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe alufaa tabi wolii bi ti Mose? Idi ni wipe ebi n pa oun naa, oungbẹ si tun n gbẹ ẹ fun un. O tilẹ fi igba kan sọ wipe, “Ọlọrun o, tọkantọkan ni mo n ṣafẹri rẹ; oungbẹ rẹ n gbẹ ọkan mi, ara mi si n fa si ọ.” (Wo: Sáàmù 63:1)

Nitorina, ti ebi ba n pa awa naa, ti oungbẹ si n gbẹ wa fun Ọlọrun, dipo fun awọn ere ori ẹrọ mohunmaworan, ẹfẹ, ariya ati awọn nkan miran ti ko ki ṣaba gbe aye eniyan ro, Oun yoo tẹ wa lọrun pẹlu ẹkunrẹrẹ rẹ, aye yoo si ri ogo rẹ ninu wa. Otitọ ti o si wa wa nibẹ ni pe idi ti pupọ-julọ lara wa ko ṣe ma ni iriri ogo Ọlọrun ninu aye wa bi o ti ṣe tọ ni pe ebi ati oungbẹ wa fun un ko to. Bawo wa ni a ṣe le fihan pe ebi n pa wa ati pe oungbẹ n gbẹ wa fun gidigidi? A le fihan nipa fifi itara lọ fun ọrọ rẹ, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ rẹ ni aisimi.

Ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe arugbo ati olukọ ti o ga ni Isiraẹli ni Nikodemu, o rẹ ara rẹ silẹ, o si wa kọ ẹkọ lọdọ Jesu Oluwa ni alẹ ọjọ kan (Jòhánù 3:1-2). Ki ni idi? Oungbẹ n gbẹ ẹ lati mọ Ọlọrun si. Emi naa si wa ranti pe, ni awọn ọdun melokan sẹyin, mo ṣe debi wipe mo n ya awọn iwe Kirisitiẹni ati awọn akasilẹ iwaasu lọwọ awọn ti ko tilẹ ki i ṣe ọmọ ijọ mi, nitoripe mo fẹ mọ Ọlọrun si i. Ọpọ igba ni mo si ma n ji ni ọganjọ oru lati ka awọn iwe yi tabi lati gbọ awọn akasilẹ iwaasu yi, ki n ba le da wọn pada fun awọn ti o ni wọn ni asiko. Ki ni a n pe eyi? Ebi ati ipongbẹ fun Ọlọrun! Ṣe o wa lere lori tabi ko ni? O lere lori.

Nitorina, ti ebi ba n pa iwọ naa, ti oungbẹ si n gbẹ ọ fun Ọlọrun, o di dandan ki o mọ ọn, ki o si tun jẹgbadun rẹ kọja ireti rẹ. Ṣugbọn ti ebi ko ba pa ọ, ti oungbẹ ko si tun gbẹ ọ fun un, awọn nkankan wa ti o ko le lailai mọ nipa rẹ tabi jẹgbadun lati ọwọ rẹ. Nitorina, gbadura pe ki O ma fi ojoojumọ ji ebi ati ipongbẹ otitọ fun ninu rẹ lọna ti o ga, ki o ba le ni iriri ẹkunrẹrẹ rẹ.

Kí ó ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ebi àti ìpòngbẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 29, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 22 Read More »

Ya ara rẹ sọ́tọ̀ fún ìyanu | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹrin ninu oṣu Owewe 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ ọsẹ naa ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ri gbogbo ipese rere rẹ fun ọ gba ati lati jẹgbadun wọn. Amin.

Wayi o, pẹlu nkan ti a ri ninu Iwe mimọ, awọn ti o ma n ri ipese Ọlọrun fun aye wọn gba ni ọna ara ṣaba ma n jẹ awọn ti o ṣetan lati ya ara wọn sọtọ kuro laarin awọn ero. Bẹẹni, wọn ma n ṣaba jẹ awọn ti o ṣetan lati ṣe ohun ti awọn miran ko ni ṣe tabi ohun ti ẹru n ba wọn lati ṣe. Nitorina, Ọlọrun yoo rekọja awọn miran lati ṣe agbayanu iṣẹ iyanu fun wọn.

Fun apẹrẹ, Jesu sọ eyi fun wa nipa Namani ati opo Sarefati:

“Ṣugbọn mo wi fun un yi nitootọ, opo pipọ ni o wa ni Isirẹli nigba ti ọrun fi ṣe ni ọdun mẹta oun oṣu mẹfa, nigba ti iyan nla fi mu ka ilẹ gbogbo; Ko si si ẹnikan ninu wọn ti a ran Elija si, bi ko ṣe si obinrin opo kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni. Adẹtẹ pupọ ni si n bẹ ni Isirẹli nigba wolii Eliṣa; ko si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ, bi ko ṣe Namani ara Siria.” (Lúùkù 4:25-27)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe adẹtẹ pọ ni Isirẹli ni asiko Eliṣa (a tilẹ mẹnuba mẹrin lara wọn ninu bibeli ti wọn yọju ni asiko iyan kan ti o mu ni ilẹ naa ni igba Eliṣa), ko ri akọsilẹ pe o wo ọkankan ninu wọn san. Ki ni idi? Ṣe ko fẹ wo wọn san ni? Rara o! Iba kuku dun mọ ninu lati wo wọn san. Ṣugbọn ọkankan ninu wọn ko ri bi ẹni ti o ni agbara Ọlọrun to lati wo wọn san. (Wo: 2Àwọn Ọba 7)

Amọ ṣa o, nigba ti Namani ara Siria gbọ nipa rẹ lati ẹnu ọdọmọdebirin ẹru kan, o rin irin ajo lati orilẹ-ede rẹ lati wa pade rẹ. Ko wa wo iye ti eyi yoo naa tabi wahala ti irinajo naa yoo ko si. Ko tilẹ wo ipo rẹ gẹgẹ bi balogun tabi bi nkan ti ri ti o jẹ wipe orilẹ-ede Isiraẹli wa ni abẹ akoso orilẹ-ede rẹ ni asiko naa. Dipo eyi, nṣe ni o rẹ ara rẹ silẹ, ti o si tọ ọ wa. Nigba ti o si ṣe bẹẹ, o ri agbayanu iṣẹ-iyanu iwosan. A wo ẹtẹ rẹ san. Ki si ni idi? Idi naa ni pe o ṣe ohun ti awọn adẹtẹ miran bi tirẹ ko gbe igbesẹ lati ṣe. O ya ara rẹ sọtọ fun iṣẹ iyanu. (Wo: 2Àwọn Ọba 5)

Opo Sarefati nkọ? Ki ni idi ti Ọlọrun fi re gbogbo awọn opo ti o wa ni Isiraẹli kọja lati wa a ni asiko iyan ọdun mẹta ati aabọ ti o waye ni igba Elija? Idi ni wipe o ya ara rẹ sọtọ bi oninudidun ọlọrẹ. Arabinrin yi ṣetan lati pin ounjẹ rẹ ti o ṣẹku pẹlu eniyan Ọlọrun, nitoripe Ọlọrun sọ fun pe ki o ṣe bẹ ẹ. Nitori eyi, yatọ si pe a bọ oun ati ọmọ rẹ pẹlu ounjẹ ni asiko iyan yi, o tun gba ọmọ rẹ pada laaye lati inu oku nigba ti iku wa lati ji ọmọ naa mọ lọwọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 17)

Ki wa ni koko gbogbo ọrọ yi? Ohun naa ni pe ti a ko ba ṣetan lati ya ara wa sọtọ kuro laarin awọn eniyan pẹlu itara nini, ninu adura gbigba, ninu ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati jijẹwọ rẹ ati ninu ififunni, awọn iṣẹ iyanu kan wa ti a ko ni lailai ri laye yi. Njẹ o wa ṣetan lati ya ara rẹ sọtọ lati ri awọn iṣẹ iyanu ti ko wọpọ gba lọwọ Ọlọrun bi?

Ki a ma fọrọgun, Ọlọrun ko ni mu wa ni tipatipa lati ṣe ohunkohun lati ya ara wa sọtọ kuro laarin awọn eniyan lati le ri gba lọwọ rẹ. Amọ ti a ba ṣe bẹ ẹ, o di dandan ki O re ọpọ kọja lati ya wa lẹnu. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti yoo ya ọ sọtọ fun awọn iṣẹ iyanu ti ko wọpọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ya ara rẹ sọ́tọ̀ fún ìyanu | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20 Read More »

Ìgbàgbọ́ àti sùúrù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu Òwewè 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọkan rẹ pẹlu okun lati ma fi igba gbogbo rin pẹlu rẹ ninu suuru, ki o ba a le ri ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o gba gba lẹkunrẹrẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igbagbọ ninu Ọlọrun nikan kọ ni a nilo lati ri nkan gba lọwọ rẹ; a tun nilo suuru lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Ki a ti lẹ sọ otitọ, awọn nkankan wa ti a ko le lailai ri gba ati jẹ igbadun lọwọ Ọlọrun ti ko ba ṣe pe a n ba a rin pẹlu rẹ pẹlu suuru. Ki ni idi? Ọkan gbogi laara idi ni pe nkan ti o wa lọkan Ọlọrun koja ki O kan ṣe nkan fun awọn eniyan rẹ tabi lati fun wọn ni nkan; nkan miran ti O tun ma n mumu laya rẹ ni bi wọn yoo ṣe jẹ igbadun lẹkunrẹrẹ ohunkohun ti O ba fun wọn tabi ṣe fun wọn.

Nitorina, ki Ọlọrun to ṣe nkankan tabi fun awọn eniyan rẹ ni nkan, yoo kọkọ ri daju pe Oun ti mojuto ohunkohun ti ko ni jẹ ki nkan naa fi ogo fun un nipasẹ aye wọn tabi ti yoo di wọn lọwọ lati jẹgbadun nkan naa lẹkunrẹrẹ. Eyi si wa le gba asiko diẹ. Ti oye eyi ko ba wa ye awọn eniyan rẹ pe o yẹ ki wọn ma a mu suuru ninu ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ, ọpọ nkan rere ti o yẹ ki wọn ri gba lọwọ rẹ ni wọn yoo ṣaba ma padanu.

Idi si ni yi ti bibeli ṣe sọ fun wa pe, “Ki ẹ ma ṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti wọn ti ipa igbagbọ ati suuru jogun awọn ileri.” (Hébérù 6:12) Njẹ o ri bayẹn? A nilo igbagbọ ati suuru lati ri gba lọwọ Ọlọrun. Nitorina, bi a tilẹ mọ daju wipe Ọlọrun fẹ ki nkankan jẹ ti wa, a nilo ju pe ki a kan gbagbọ pe O le fun wa ni nkan naa; a tun gbọdọ fi suuru duro lati ri nkan naa gba lọwọ rẹ.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa onigbagbọ ni a ko fẹ ni suuru rara lati ri gba lọwọ Ọlọrun. A ro wipe niwọn igba ti a ba ti ni igbagbọ ninu Ọlọrun, ti a si n ṣe ifẹ rẹ, ohun rere gbogbo ti O fẹ ki a ni ni yoo bẹrẹ si ni wa si ọdọ wa funra wọn. Ṣugbọn eyi ko ki i fi gbogbo igba ri bẹ. Rinrin ninu igbagbọ ninu Ọlọrun ati ṣiṣe ifẹ rẹ dabi iṣẹ ọgbin ni. Ko si agbẹ ti yoo fun irugbin rẹ loni, ti yoo si ma a reti ikore lẹsẹkẹsẹ. Dipo bẹ ẹ, nṣe ni yoo fi suuru mojuto awọn nkan ti o gbin titi di asiko ikore.

Wayi o, bayẹn gan ni rinrin ninu igbagbọ pẹlu Ọlọrun ati ṣiṣẹ ifẹ rẹ ti se ri. A nilo lati tẹsiwaju lati ma rin pẹlu rẹ ati lati ma ṣe ifẹ rẹ titi asiko ikore. Amọ igba wo ni asiko ikore. A ko le sọ. Igbakigba ti o ba jẹ naa ni. Lotitọ, awọn agbẹ, nipasẹ iriri, le sọ asiko ikore awọn nkan oko wọn. Ṣugbọn awa ko le sọ igba ti a o kore awọn ileri Ọlọrun fun aye wa tabi awọn ere fun ṣiṣe ifẹ rẹ. Nitorina, ọrọ Ọlọrun sọ eyi fun wa:

“Nitori naa ẹ ma ṣe gbe igboya yin sọnu, eyi ti o ni ere nla. Nitori ẹyin ko le ṣe alaini suuru, nitori igba ti ẹyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan ki ẹyin le gba ileri naa.” (Hébérù 10:35-36)

Njẹ o ri bayẹn? Ma ṣe gbe igboya rẹ ninu Ọlọrun ju sọnu nitori pe o ko i ti ri ikore awọn ileri rẹ fun ọ. Dipo eyi, nṣe ni ki o kọ suuru ni ṣiṣe ifẹ rẹ titi ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ tirẹ yoo fi tẹ ọ lọwọ. Bẹẹ ni, o nilo lati kọ suuru ni gbigbadura, ni ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati ninu jijẹwọ rẹ ati ninu rinrin ninu ododo. Bi o si ṣe n ṣe eyi, ohun gbogbo ti o yẹ ki jẹ tirẹ di dandan ki o jẹ tirẹ nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, ti o ko ba rẹwẹsi.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìgbàgbọ́ àti sùúrù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20 Read More »

Ìwọ fẹ́, kí o sì tún gbọ́ràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 08, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 19

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Òwewè 2024. Adura mi si ni pe ki a mu ọkan rẹ le nisisiyi ati ni gbogbo igba lati le fẹ fun ara rẹ ohun ti Ọlọrun fẹ fun ọ ati lati le fi fi ara rẹ balẹ lati lọ fun nkan naa. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a fi han wa leralera ninu Iwe Mimọ ni pe ko to ki Ọlọrun fẹ ki eniyan ni nkan; awa naa gbọdọ fẹ lati ni ohun yowu ti O fẹ ki a ni. Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ ṣetan lati ṣe ohun yowu ti O ba fẹ ki a ṣe lati le ni ohun yowu ti O ba fẹ ki a ni. Aijẹbẹ, ti ko ba jẹ wipe a ba ṣaanu fun wa, a ko ni ni ohun ti O fẹ ki a ni.

Idi si wa niyi ti Ọlọrun ṣe sọ eyi fun wa lati ipasẹ Àìsáyà: “Ti ẹyin ba fẹ, ti ẹ si gbọrọ, ẹyin yoo si jẹ ojulowo adun ilẹ naa.” (Àìsáyà 1:19) Pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ nibiyi, ki ni ohun naa ti O fẹ ki a ni? Awọn nkan ti o dara ju ni bi ti a n gbe ni. A wa gbọdọ jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun nibiyi ko ma sọrọ nipa awọn nkan ti o dara ju ni ibi ti a n gbe lọwọlọwọ yi. Idi si ni pe awọn nkan ti o dara ju ni ibi ti a n gbe lọwọlọwọ yi le ma dara to fun wa wa tabi fun ẹbi wa. Ṣugbọn awọn nkan ti o dara ju ti Ọlọrun ti gbin si ibẹ, ti o le ma ti han kedere si ẹnikẹni, di dandan ki o kọja bẹ ẹ fun wa.

Bawo wa ni a ṣe le fọwọgan awọn nkan ti o dara ju ti Ọlọrun ti gbin si ilẹ wa fun rere wa? Akọkọ, bi a ti ṣe fi han wa nipasẹ Aisaya, a gbọdọ fẹ lati ni awọn nkan yi i. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ ṣetan lati tẹba ti awọn nkan ti o kere si nkan ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ fun wa tabi ṣetan lati jẹ ki wọn tẹ wa lọrun. Eyi ko wa jasi pe ki a ma lẹmi ọpẹ fun awọn nkan ti Ọlọrun ti fẹkan-tẹlẹri fi fun wa tabi ṣe fun wa. A gbọdọ ma fi ọpẹ fun Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti ṣe fun wa ati ti O n ṣe ninu aye wa. Ṣugbọn bi a ti ṣe n fi ọpẹ fun fun awọn nkan ti a n jẹgbadun lati ọwọ rẹ, a tun gbọdọ ma tẹsiwaju lati nawọ gan ohun rere gbogbo ti O fẹ ki a ni. Aijẹbẹ, nṣe ni a o pada gbe igbe aye ti ko koju-oṣuwọn to irufẹ igba aye ti O fẹ ki a gbe.

Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu Iwe Mimọ nipa Joṣua nigba ti opin ọjọ aye rẹ sumọ etile: “Nigba ti Joṣua si darugbo ti ọjọ ori rẹ si pọ jọjọ, Oluwa sọ fun un pe, “Iwọ ti darugbo pupọ, bẹẹ ni ilẹ si ku lọpọlọpọ fun yin lati gba.”” (Jóṣúà 13:1) Njẹ o ri bayẹn? Lẹyin igba ti Joṣua ti di ogbo tan, Ọlọrun si tun ni ilẹ lọpọlọpọ fun lati gba. Iyẹn jasi pe ko ti ni ẹkunrẹrẹ iriri awọn nkan ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ ki o ni ni asiko yẹn. O wa ṣeni laanu pe ara rẹ ko mokun to mọ ni asiko naa lati nawọ gan gbogbo nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ni. O ma ṣe o!

Nitorina, titi di ọjọ ogbo wa, Ọlọrun ko ni dẹkun lati ma ṣi oju wa lati ri awọn ipese rere rẹ fun wa. Bawo wa ni yoo ti ṣe dara to, ti a ba le nawọ gan gbogbo wọn, ki a si jẹgbadun wọn? Nikukuru, ọna kan ti eyi ṣe le ṣẹlẹ ni ki a fẹ, ki a si tun ni itara lati ni gbogbo awọn nkan wọnyi. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi i Joṣua, igba ti awa naa ba di ogbo tan, ti ara wa ko si mokun to mọ lati ma sare kaakiri ni a o too maa ri gbogbo awọn nkan ti a ko ba ti gba ati jẹgbadun lati ọwọ Ọlọrun. Ṣugbọn o le e ti wa pẹju ni igba yẹn. Mo wa gbadura pe ko ni lailai pẹ ju fun ọ lati ṣe idamọ ipese Ọlọrun ti o dara ju fun ọ ati lati nawọ gan an. Amin.

Nkan ekeji ti Ọlọrun sọ wipe a gbọdọ ṣe lati le jẹ igbadun awọn ipese rẹ ti o dara julọ fun wa ni ilẹ wa ni ki a gbọran. Eyi tunmọ si pe a gbọdọ fi ara wa jin lati ma tẹle aṣẹ rẹ lori bi a ti ṣe le gba ipese rẹ ti o dara julọ fun wa ati bi a ti ṣe le gbadun rẹ. Aijẹbẹ, bi a tilẹ nifẹ si lati ni ipese rẹ ti o dara julọ fun wa, a ko ni le e nawọ gan an ati gbadun rẹ. Ti a ba si tilẹ nawọ gan awọn ipese rẹ ti o dara julọ fun wa nipa titẹle imọ tara wa, o di dandan ki nkan yowu ti a ba tipasẹ eyi ri fi ìkorò sinu aye wa. Nitorina, nikẹyinkẹyin a ko ni le e jẹ igbadun rẹ bi o ti ṣe tọ.

Wayi o, adura mi ni pe ki o ma kan jẹ wipe wa ri ipese Ọlọrun ti o dara julọ fun ọ ni orilẹ-ede yi gba, bi o ti wu ki nkan ri ninu orilẹ-ede naa, amọ ki o tun jẹ wipe wa a jẹ igbadun rẹ lẹkunrẹrẹ. Ṣugbọn iwọ naa gbọdọ fẹ lati ri gba ati lati jẹ igbadun rẹ, ki o si tun jẹ ẹni ti o n gbọran si gbogbo aṣẹ Ọlọrun si ọ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìwọ fẹ́, kí o sì tún gbọ́ràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 08, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 19 Read More »

Wọ́n le è ṣaájú rẹ nínú ìjọba náà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 01, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun yi, iyẹn oṣu Òwewè 2024. Mo si gbadura pe ọkankan ninu awọn nkan ti o yẹ fun ibalẹ-ọkan ati igbega rẹ ko ni di pipamọ fun ọ ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti n ṣe bẹrẹ oṣu yi, mo fẹ ran ọ leti owe Jesu Kirisiti Oluwa wa kan ti o lọ bayii:

“Ki ni ẹ ro nipa eleyii? Ọkunrin kan ti o ni awọn ọmọkunrin meji. O ṣọ fun eyi ẹgbọn pe, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara lonii.’ “O si da baba rẹ lohun pe, ‘Emi ko ni i lọ’, ṣugbọn nikẹyin o yi ọkan pada, o si lọ. Nigba naa ni baba yii tun sọ fun eyi aburo pe, ‘Lọ ṣiṣẹ ni oko.’ Ọmọ naa si sọ pe, ‘Emi yoo lọ, baba,’ ṣugbọn ko lọ rara. Ninu awọn mejeeji yii, ewo ni o ṣe ifẹ baba wọn? Gbogbo wọn si fohun ṣọkan pe, “Eyi ẹgbọn ni.” Jesu wi fun wọn pe, “Loootọ ni mo wi fun yin, awọn agbowo-ode ati awọn pansaga yoo wọ ijọba ọrun ṣiwaju yin.” (Mátíù 21:28-32)

Ki ni koko owe yi? Oun naa ni pe ko to ki a kan gba ninu ọkan wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun; a tun gbọdọ tẹsiwaju lati ṣe e. Ti ko ba si wa jẹ wipe a n ṣe ohun ti a mọ, ti a si tẹwọgba gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun fun wa ni gbogbo abala aye wa, a ko yatọ si awọn ti ko gba Ọlọrun gbọ rara.

Bi a ti ṣe ri ninu owe yi, nigba ti baba yẹn sọ fun ọmọkurin rẹ akọkọ nipa ki o lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara rẹ, ọdọmọkunrin yi sọ fun kedere pe oun ko ni lọ. Ki ni idi? A ko sọ fun wa. Amọ o ṣa di didan ki o ni idi tirẹ. Ṣugbọn nigba ti o ṣe diẹ si lọjọ yi kan naa, o ronu lori bi o ti ṣe kọ jalẹ lati gbọran si baba rẹ lẹnu, o si gba wipe nkan ti ko dara ni oun ṣe. Nitorina, o ronupiwada, o si lọ ṣe ohun ti baba rẹ pa a laṣẹ fun lati ṣe.

Ṣugbọn nigba ti baba yi ba ọmọkunrin rẹ keji sọrọ, ko ba a jiyan rara. Dipo bẹẹ, nṣe ni o sọ wipe, “Bẹẹni sà. Ma a lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara yin, gẹgẹ bi ẹ ti ṣe pa a laṣẹ.” Amọ ko lọ rara lati ṣe ifẹ baba yi. Ki ni idi? A ko sọ fun wa. O ṣeeṣe ki o ni oniruuru awawi lati ma lọ. Ṣugbọn koko ibẹ naa ni pe ko lọ ṣe ifẹ baba rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe o gba ni ibẹrẹ-pẹpẹ lati lọ ṣe e.

Wayi o, lẹyin igba ti o sọ owe yi tan, Jesu tẹsiwaju lati jẹ ki koko rẹ han si awọn adari ẹsin awọn Juu ti O sọ ọ fun. Ki si ni koko rẹ? Oun naa ni pe awọn ti wọn ka si ẹlẹṣẹ yoo ṣiwaju wọn wọ ijọba Ọlọrun. Ki ni idi? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe awọn mọ ifẹ Ọlọrun, ti wọn si tun n waasu nipa ifẹ rẹ, wọn ko ki i ṣe ifẹ rẹ. Ṣugbọn awọn ti wọn n pe ni ẹlẹṣẹ ati awọn alaiwulo eniyan n yipada kuro ninu ẹṣẹ wọn lati ṣe ifẹ Ọlọrun nipasẹ iwaasu Jesu. Nitorina, o di dandan ki wọn ṣiwaju wọn wọ ijọba Ọlọrun.

Nibakanna, a le ri ara wa gẹgẹ bi ẹni-bi-Ọlọrun ati ẹni ẹmi, nitoripe a n lọ si sọọsi deede, a n gbe bibeli kaakiri, a situn fi gbogbo igba sọ wipe, “Jesu loluwa.” Ṣugbọn ti a ko ba ṣe awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ninu aye wa ati ni awujọ wa, nṣe ni a kan n tan ara wa jẹ, ti a ko si yatọ si awọn ti ko gbagbọ rara. Amọ ti awọn ti a ro wipe ẹlẹṣẹ ti ko wulo rara ni wọn ba bẹrẹ si ni yipada lati ṣe ifẹ Ọlọrun ninu aye wọn, yoo ya wa lẹnu lọjọkan nigba ti a ba ri wipe wọn ti ṣiwaju wa wọ ijọba Ọlọrun.

Bawo wa ni yoo ti ṣe ri ni ara rẹ ni Ọjọ Oluwa ti o ba ri pe awọn kan ti o ko ro wipe wọn mọ nkankan nipa Ọlọrun tabi nipa ọna ododo ba wa ninu ijọba Ọlọrun nigba ti iwọ si wa ni ọrun apadi tabi ba wa ni ààyè ti o dara ju tirẹ lọ ninu ijọba Ọlọrun? Mo mọ wipe bi iru nkan wọnyi yoo ṣe ri lara kọja nkan ti a le e ro. Ṣugbọn bi yoo ti ri gẹlẹ niyẹn ti o ko ba fi ara rẹ jin lati ṣe ifẹ Ọlọrun tọkan-tọkan. Nitorina, dẹkun lati ma fi ẹsin ṣe boju-boju fun aigbọran si Ọlọrun lẹnu, ki o si bẹrẹ si ni ṣe ohun gbogbo ti o mọ gẹgẹ bi ifẹ rẹ fun aye rẹ. Mo si gbadura pe ki a fun ọ ni okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, bi o ti ṣe n la oṣu yi ati eyi ti o ku ninu ọdun yi kọja lọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọ́n le è ṣaájú rẹ nínú ìjọba náà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 01, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 18 Read More »