Author name: 23?Racing_Horse

Agbára rẹ̀ wá ní àrọ́wọ́tó wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 31, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun ati sinu ọjọ ti o gbẹyin oṣu yi. Mo si gbadura pe, bi a ti ṣe n wọ inu oṣu tuntun lọ lọsẹ yi, iyẹn oṣu Igbe 2024, ki Ọlọrun jẹ ki agbara rẹ ti o ji Jesu Oluwa wa dide kuro ninu oku ji iwọ naa dide lati ibi ti o wa lọ si ibi ti o yẹ ki o wa laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi gbogbo wa ti ṣe mọ, ọpọ Kirisitiẹni kaakiri agbaye loni ni o n yọ ayọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa. Eyi si tọna. Amọ ṣa o, ayọ ajinde rẹ gbọdọ kọja eyi ti a n ya ọjọ kan silẹ lati yọ; dipo bẹẹ, o yẹ ki o jẹ eyi ti a o ma fi ojoojumọ yọ ayọ rẹ. A o si ma yọ ayọ ajinde rẹ lojoojumọ ati ni gbogbo asiko ninu aye wa, ti a ba ni oye ti o peye nkan ti o tunmọ si fun wa.

Wayi o, ki wa ni ajinde rẹ tunmọ si fun wa? Ki a sọ otitọ, bibeli menuba melokan ninu awọn nkan ti o tunmọ si fun wa. Ọkan lara rẹ si ni pe o fi agbara kanna ti o ji dide kuro ninu oku si arọwọto awọn ti o gbagbọ ninu rẹ. Wo bi Pọọlu ti ṣe gbe eyi kalẹ ninu adura rẹ kan fun awọn ijọ:

“Ki oju ọkan yin lee mọlẹ; ki ẹyin ki o le ni oye ohun ti ireti ipe rẹ jẹ ati ohun ti i ṣe ọrọ̀ ogo ini rẹ ninu awọn eniyan mimọ rẹ, ati agbara rẹ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ, eyi ti o tiṣe pari ninu Kirisiti nigba ti o ji i dide kuro ninu oku, ti o si mu un jokoo ni ọwọ ọtun ninu awọn ọrun. O gbe e ga ju gbogbo ijọba oju ọrun, ati agbara, ati ipa, ati ilẹ ọba, ati gbogbo orukọ ti a n da, ki i ṣe ni aye yii nikan ṣugbọn ati ni eyi ti n bọ pẹlu.” (Efesu 1:18-21)

Ki ni afojusun adura Pọọlu nibiyi? Akọkọ, o ni i ṣe pẹlu pe ki Ọlọrun ṣi oju wa lati le mọ ireti ayeraye ti O ti pe wa si. Ekeji, o ni i ṣe pẹlu pe ki O fi oye bi ini rẹ ninu wa, iyẹn awọn nkan daradara ti O ti gbin sinu aye wa, ti ṣe lọrọ ati logo to. Ẹkẹta, o ni i ṣe pẹlu pe ki Ọlọrun jẹ ki a da agbara rẹ ti ko lakawe, ti o ga, ti o si wa fun awa ti o gbagbọ mọ.

Ki wa ni Pọọlu sọ nipa agbara Ọlọrun ti ko lakawe, ti o si tun ga, yii? O sọ wipe o wa fun awa ti o gbagbọ. Iyẹn jasi pe agbara Ọlọrun wa ni arawọto iwọ ati emi lati ṣe amulo. Ṣugbọn a ko ni ṣe amulo rẹ lọna ti o peye, ti a ko ba mọ bi o ti ṣe tobi ati bi o tun ti ṣe lagbara to.

Nitorina, Pọọlu fun wa ni apẹrẹ kan ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ ati titobi agbara naa. Eyi si ni ti ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa kuro ninu oku. Gẹgẹ bi O ti ṣe sọ, agbara yi ni Ọlọrun tu sinu Jesu nigba ti O fẹ ji dide kuro ni ipo oku. Nitorina, lalai ṣe wipe ẹnikẹni gbadura tabi aawẹ fun ati laiṣepe ẹnikẹni gbe ọwọ le lori, agbara yi tu u silẹ kuro lẹnu iku, bi o tilẹ jẹ wipe O ti ku fun ọjọ mẹta. Aleluya!

Pọọlu tun wa tẹsiwaju lati sọ fun wa pe agbara yi kanna ni o jẹ ki o ṣeeṣe fun Jesu lati goke re ọrun ati lati joko si ọwọ ọtun Ọlọrun, nibi ti o ga fiofio ju gbogbo awọn alaṣẹ ati alagbara ati ju gbogbo orukọ ati oye ti a le fun ni lọ, Nitorina, a n wo agbara niwaju eyi ti iku ko ti le duro. Bẹẹni, a n wo agbara ti a ko le di lọwọ lati gbe awọn ti Ọlọrun ba fẹ ẹ gbega lọ si ibi ti O fẹ ki wọn wa. A si ti wa fi agbara yi si arọwọto awa ti o gbagbọ. Yatọ si eyi, agbara naa tun wa n ṣiṣẹ ninu wa lọwọlọwọ yi. (Wo: Efesu 3:20)

Nitorina, lakọkọ, nṣe ni o yẹ ki a ma fi igba gbogbo fi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe fi agbara yi, agbara ajinde ati igbasoke Krisiti, si arọwọto wa. Ekeji, nṣe ni o yẹ ki a ma gbadura ni gbogbo igba, gẹgẹ bi Pọọlu, pe ki Ọlọrun jẹ ki a mọ riri agbara yi, ki a si tun ma ṣe amulo rẹ lati bori gbogbo idojukọ aye yi ati lati jẹ irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ. Nje ki a gba okun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati fi ara wa jin fun ṣiṣe awọn nkan wọnyi, ki awọn anfaani ti o sọrọ mọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa ma ba fo wa ru. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Agbára rẹ̀ wá ní àrọ́wọ́tó wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 31, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 48 Read More »

Àwa náà le ṣe ohun tí a kà sí kò-ṣeéṣeLáti | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 24, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 47

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Ẹrẹ́nà 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati ma fi igba gbogbo tẹ oju rẹ mọ ọn ati mọ ọrọ rẹ, ki o ba le rin ni iṣẹgun lori gbogbo idena aye, ki o si da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu iwe iyinrere Matiu, o kọ akọsilẹ iṣẹlẹ kan fun wa ninu eyi ti Jesu ti rin lori omi. Bi akọsilẹ naa si ṣe lọ, ni alẹ ọjọ kan ati lẹyin ipade kan, Jesu jẹ ki awọn ọmọ ẹyin rẹ wọ inu ọkọ oju omi lọ lati ṣaaju rẹ lọ si ibi kan ti a n pe ni Gẹnẹsareti, nigba ti Oun si lọ gbadura. Ko si wa si ọkankan ninu wọn ti o tilẹ bikita lati bere pe bawo ni yoo ṣe darapọ mọ wọn. Wọn kan kuro naa ni nitoripe O ti sọ pe ki wọn maa lọ. (Wo: Mátíù 14:14-22)

Amọ ṣa o, nigba ti O ṣetan nidi adura gbigba, ti O si ri wipe afẹfẹ n fẹ lodi si wọn, O jade tọ wọn lọ nipa ririn lori omi. Nigba ti wọn si ri eyi, ẹru ba gbogbo wọn, wọn si bẹrẹ si ni pariwo ninu ìpayà, pẹlu ero wipe iwin ni awọn n ri. Ṣugbọn O sọ fun wọn pe ki wọn ma bẹru ati wipe Oun ni ẹni naa. (Wo: Mátíù 14:24-27)

Wayi o, ni kete ti Peteru gbọ pe Jesu ni O n rin lori omi ni o sọ wipe, “Oluwa, ti O ba ṣe pe Iwọ ni, paṣẹ ki emi ki o tọ ọ wa ni ori omi.” Ṣe o ronu nipa eyi ki o to sọ bi? Rara o! Ṣugbọn, nibikan ninu ọkan rẹ, o ṣaa mọ wipe ti o ba je pe Jesu Oluwa wa ni O n rin lori omi nitootọ, O wa ni ipo lati sọ ọrọ aṣẹ ati agbara ti yoo jẹ ki oun naa le ṣe bẹẹ gẹgẹ. Nkan ti o si sẹlẹ gan an niyẹn? Nigba ti o bere nkan yi, Jesu dahun, O si wipe, “Wa!” (Wo: Mátíù 14:28-29)

Ṣe Peteru wa rin lori omi tabi ko rin lori rẹ? O rin lori rẹ! O rin lori omi ni gbangba loju awọn ọmọ ẹyin yoku ti wọn wa pẹlu rẹ ninu ọkọ oju omi naa. Amọ ṣa o, Matiu tẹsiwaju lati sọ fun wa pe nigba ti ọkunrin yi ri iji, ẹru ba a, o si bẹrẹ si ni ri sinu omi. O wa pariwo si Oluwa lati gba a la. Ṣe O wa gba a la tabi ko gba a la? O gba a la, awọn mejiji si jọ rin pada lori omi sinu ọkọ oju omi naa. Ṣugbọn O sọ fun pe idi ti o ṣe bẹrẹ si ni ri ni pe o ṣiyemeji ati wipe iyemeji rẹ ni o fi irẹwẹsi si inu igbagbọ rẹ ti o ga, ti o si sọ di igbagbọ kekere. (Wo: Mátíù 14:28-32)

Ki a ma fọrọgun, titi aye ni yoo wa ninu akọsilẹ pe Peteru ṣe ohun ti a ka si kò-ṣeéṣe nipa ririn lori omi pẹlu Jesu Oluwa wa. Bẹẹni, titi aye ni yoo wa ninu akọsilẹ pe o ṣe ohun ti awọn ọmọ ẹyin Oluwa yoku ko ṣe. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe o wa lori ẹmi rẹ lati ṣe e. Ekeji, idi ni pe Oluwa sọ ọrọ jade pe o le ṣe e. Se o ri, nini erongba lati ṣe nkan tabi lati ni nkan ko to. Ti ko ba si ọrọ Ọlọrun lati gbe nkan naa lẹsẹ, inira tabi iparun ni yoo yọri si. Eyi tunmọ si pe igbagbọ ninu Ọlọrun gbọdọ da lori ọrọ rẹ dipo lori erongba tabi bi nkan ṣe ri lara wa tabi lori iriri awọn miran. A si wa ri awọn ti wọn ti fi aimọkan-mọkan ṣe ara wọn leṣe nibi ti wọn ti n gbiyanju lati lo igbagbọ ti a ko pilẹ sori ifihan ọrọ Ọlọrun ti o peye.

Idi kẹta ti Peteru fi rin lori omi pẹlu Jesu ni pe o ṣiṣẹ lori ọrọ Oluwa ti o sọ pe, “Wa!” Ti ko ba ṣiṣẹ lori ọrọ naa ni, ko ba ma ti rin lori omi bi o ti ṣe ṣe. Ṣugbọn wa kiyesi pe nigba ti Oluwa da Peteru lohun, ko sọ wipe, “Wa, Peteru!” Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O sọ wipe, “Wa!” Eyi tunmọ si pe ọrọ aṣẹ ati agbara wa fun gbogbo wọn ti o wa ninu ọkọ oju omi naa. Ṣugbọn Peteru nikan ni o ṣiṣẹ le lori. Peteru nikan ni o sọkalẹ kuro ninu ọkọ oju omi naa, ti o si rin lori omi. Awọn yoku kan duro sinu ọkọ oju omi naa pẹlu iyanu ni, ti wọn si n wo ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ wọn bi o ti ṣe n rin lori omi lati lọ pade Jesu.

Ki ni idi ti eyi ṣe wa ri bẹ? O ri bẹ ẹ nitoripe Peteru nikan ni o ni ifẹ ati itara ti o ga to ninu ọkan rẹ ni asiko yi lati ṣe ohun ti Oluwa sọ wipe gbogbo wọn le ṣe e. Ẹkọ ti eyi si kọ wa ko le rara. Oun naa si pe awa naa le ya ara wa sọtọ kuro laarin awọn miran lati ṣe ohun ti a ka si kò-ṣeéṣe nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu Oluwa. Bẹẹni awa naa le rin lori awọn omi aisan, iṣẹ, ainilọsiwaju, ibẹru ati iku. Idi si ni pe ọrọ Ọlọrun ti sọ wipe a le ṣe bẹ ẹ. Nkan ti a wa nilo naa ko ju pe ki a ni itara ti o ga lati ṣe bẹ ẹ, ki a ma fi ojoojumọ gbe igbesẹ igbagbọ ti Ọlọrun n sọ fun wa pe ki a gbe, ki a si tẹjumọ Jesu. Ki ẹnikẹni si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, a o ti ṣe nkan ti a ka si kò-ṣeéṣe, a o si tun ti silẹkun silẹ fun ọpọ lati yin Ọlọrun nipasẹ wa.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àwa náà le ṣe ohun tí a kà sí kò-ṣeéṣeLáti | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 24, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 47 Read More »

Ìwọ náà le jẹ́ olùtùnú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 17, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 46

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2024. Adura mi fun ọ ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ni iriri itunu rẹ ni gbogbo ọna, ki iwọ naa ba a le jẹ olutunu fun gbogbo awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu lẹta rẹ si awọn ara Kọrinti, Pọọlu sọ awọn ọrọ wọnyi ti o ṣe pataki ki a kiyesi: “Olubukun ni Ọlọrun, ati Baba Jesu Kirisiti Oluwa wa, Baba ìyọ́nú, ati Ọlọrun itunu gbogbo; Ẹni ti n tu wa ninu ni gbogbo idaamu wa, ki awa le maa pẹlu tu awọn ti o wa ninu idaamu ninu, nipa itunu naa ti a n fi n tu awa funra wa ninu lati ọdọ Ọlọrun wa.” (2Kọ́ríntì 1:3-4) Ki ni idi ti Pọọlu ṣe yin Ọlọrun ninu ẹṣẹ bibeli yi: O yin in nitoripe O jẹ olutunu fun un.

Njẹ iwọ naa wa mọ Ọlọrun gẹgẹ bi olutunu bi? Pọọlu sọ fun wa pe olutunu ni. O tilẹ sọ siwaju pe Ọlọrun ju ẹni ti a le pe ni olutunu lọ — Oun gan ni Baba aanu ati Ọlọrun gbogbo itunu otitọ. Eyi jasi pe, ọdọ Ọlọrun ni ohun gbogbo ti a n pe ni aanu ati itunu otitọ ti n jade wa. Nitorina, ti o ba nilo aanu ati itunu ninu aye rẹ, fi tọkan-tọkan kọju si Ọlọrun. Yoo si fi aanu ti o ga han ọ, yoo si tun tu ọ ninu ni gbogbo ọna, lalai wo ailera ati ikuna rẹ

Bi Pọọlu ti ṣe fi han wa ninu ẹṣẹ bibeli yẹn, bi o tilẹ jẹ wipe oun ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ba oniruuru iṣoro ati idojkọ pade laye, Ọlọrun tu wọn ninu ninu ọkọọkan ninu awọn nkan wọnyi. Ọna wo ni Ọlọrun gba ṣe e? Ko salaye eyi fun wa. Amọ daju ṣaka ni pe irufẹ itunu ti wọn gba lọdọ Ọlọrun ga debi wipe wọn kun fun iyin nitori rẹ. Lafikun, irufẹ itunu ti wọn ri gba lọdọ rẹ ga debi wipe awọn naa tun le tu awọn miran ti o wa ninu idamu ninu pẹlu rẹ.

Eyi si n fi han wa pe kiki awọn ti o ti ni iriri aanu ati itunu Ọlọrun nitootọ, ti wọn si mọ-ọn lore nikan ni o le tu awọn miran ninu lotitọ. Awọn ti ko mọ aanu ati itunu Ọlọrun ko le je olutunu otitọ fun awọn ti iya n jẹ tabi ti ara n ni ni ayika wọn. Wo awọn ọrẹ Jobu, fun apẹrẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe ọlọrọ, ọlọgbọn ati olododo ni gbogbo wọn jẹ, wọn ko le tu u ninu ni asiko inira rẹ. Nṣe ni wọn kan tun da kun irora rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ko mọ pe gbogbo itura ti awọn n jẹ igbadun ninu aye wọn ko wa nitori iṣẹ ododo ati iṣẹ afọkanṣe wọn ṣugbọn nitori aanu Ọlọrun.

Nibakana, ti awa naa ba ro wipe irufẹ itura yowu ti a n jẹ igbadun jẹ eyi ti o tọ si wa, a ko ni ri idi kankan lati ṣaanu fun awọn miran ati lati tu wọn ninu. Dipo bẹẹ, ọpọ igba ni a o ma woye lọkan wa pe wọn n jẹ iya nitoripe wọn ko ki i ṣe olododo tabi nitoripe wọn ko jafafa lẹnu iṣẹ to. Amọ, a ko ma jẹgbadun aye wa nitoripe a jẹ olododo ati ẹni ti o jafafa lẹnu iṣẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki a jẹ olododo ati ẹni ti o jafafa lẹnu iṣẹ. Dipo bẹẹ, a n jẹ igbadun aye wa nitoripe Ọlọrun yan lati ṣaanu fun wa ati lati tu wa lara. Ti a ba si wa kọ lati mọ eyi, ki a si ma fi iyin fun nitori rẹ, a le bẹrẹ si ni padanu irufẹ itura yowu ti a le ni titi a o fi mọ, ti a o si tun gba pe Oun ni orisun gbogbo itura.

Ni kukuru, koko nkan ti a n sọ nipe ti o ba fẹ itura ni ọnakọna ninu aye rẹ lọwọlọwọ yi, kọju si Ọlọrun, Baba aanu ati Ọlọrun itunu fun un. Yoo si fi aanu ati itura fun ọ. Siwaju si, bi o ba ti ṣe n fi ojoojumọ ni iriri itura ninu aye rẹ, ṣi oju rẹ silẹ lati ri awọn ti o wa ni ayika rẹ ti iwọ naa le tu ninu pẹlu itunu ti o rigba lọwọ rẹ. Eyi si wa kọja ki a fun eniyan lowo. Idi ni pe a ri awọn ti o jẹ pe ara ko le tu wọn rara, bi a tilẹ fun wọn ni gbogbo owo ti o wa ninu aye yi. Ṣugbọn gbolohun adura kan tabi ọrọ iyanju kan ti a ba sọ fun wọn nipasẹ idari Ẹmi Ọlọrun le tu wọn silẹ kuro lọwọ gbogbo ibẹru ati idaamu wọn, ki o si kun aye wọn pẹlu itura.

Nitorina, ma ṣe gbẹkẹle owo tabi ipo rẹ ni titu ẹnikẹni ninu. Dipo bẹẹ, gbẹkẹle Ọlọrun, ẹni ti o jẹ orisun gbogbo itunu, fun ohun gbogbo ti o nilo lati tu awọn ti o wa ninu aye rẹ ninu lotitọ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe o ni olutunu otitọ fun gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ ti o wa ninu inira, ki wọn ba le fi ogo fun orukọ rẹ nitori rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìwọ náà le jẹ́ olùtùnú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 17, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 46 Read More »

Taló sọ pé kí wọ́n kúrò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 10, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 45

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di ọpọlọpọ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Erele 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu imọ ti o peye lori awọn igbese ti o yẹ ki o gbe lati rin ni iṣẹgun lori awọn iṣoro iṣuna ati aabo ti orilẹ-ede yi n ba finra lọwọlọwọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ko ki i ṣe iroyin mọ ni pe orilẹ-ede wa n doju kọ awọn ipenija ti o ga lori eto isuna ati ọrọ aabo rẹ. Idasi Ọlọrun nikan si ni o le mu wa laa ja. Idi si ni yi ti awa ti a mọ ọn ko fi gbọdọ dẹkun lati ma gbadura si i titi ayọ wa yoo fi kun lori orilẹ-ede naa. Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ fun wa pe ki a bere titi ayọ wa yoo fi kun. Nitorina, niwọn igba ti ayọ wa ko ba i ti kun lori orilẹ-ede wa, a gbọdọ tẹsiwaju lati ma gbadura si Ọlọrun fun un. (Wo: Jòhánù 16:24)

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe n fi itara reti pe ki Ọlọrun dasi ọrọ wa, ki O si gba orilẹ-ede wa la, bẹẹ na ni awa, gẹgẹ bi ẹnikọọkan, tun ṣe nilo lati mọ awọn igbesẹ ti o tọ fun wa lati gbe lati gberu ni orilẹ-ede yi dipo eyi ti awọn iṣoro rẹ yoo fi pa wa run. Ẹnikan ṣoṣo ti O si le fi eyi han wa ni Ọlọrun. Nitorina, bi a ti ṣe n gbadura si fun orilẹ-ede wa, a tun gbọdọ ma gbadura si fun ara wa. A gbọdọ ma gbadura si pe ki O kun ọkan wa pẹlu imọ ti o peye nipa ohun ti o ye ki a ṣe lati la asiko ipenija orilẹ-ede yi kọja, ki a si yege. Ti a ba si fi tọkantọkan ṣe bẹẹ, O di dandan ki O dawa lohun, ki O si dari wa ni oju ọna ti o yẹ ki a tọ.

Tun ranti pe ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe ki a gbẹkele Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkan wa, ki a kaa si ni gbogbo ọna wa, ki a si tun ma ṣe tẹ si oye tara wa. Nipa eyi, Oun yoo dari wa nipa ọna iṣẹgun. O wa ṣeni laanu pe ọpọ laarin awọn ti o tilẹ jẹ eniyan Ọlọrun ni ko gbe ọkan wọn le mọ lati dari wọn si ọna ti o yẹ ki wọn tọ ni asiko yi. Nṣe ni wọn n gbojule ọgbọn ati oye wọn. O si wa di dandan ki awọn ti o n ṣe eyi ba ẹtẹ pade, bopẹ-boya, ti a ko ba fi aanu han si wọn lati ọdọ Ọlọrun. (Wo: Ìwé Òwe 3:5-6)

Ranti itan Naomi ati awọn ẹbi rẹ. Gbogbo wọn ni o fi ilẹ Isiraẹli silẹ lọ si ilẹ Moabu nitoro pe iyan kan ti o le gan mu ni ilẹ naa. Ṣugbọn tani o sọ fun wọn pe ki wọn kuro? Ṣe Ọlọrun ni? A ko sọ fun wa rara. Ṣugbọn a sọ fun wa pe Naomi pada kabamọ lori nkan ti wọn ṣe. Idi si ni pe oun nikan ni o pada wa si ile laaye. Ati pe bi o tilẹ jẹ wipe o pada laaye, nṣe ni o pada pẹlu ọwọ ofifo. (Wo: Rúùtù 1)

Amọ wa wo ọrọ arabinrin Ṣunemu, ẹni ti Eliṣa fi igbakanri ji ọmọkunrin rẹ dide kuro ni ipo oku. Asiko kan naa wa ti oun naa kuro ni ilẹ Isiraẹli pẹlu awọn ara ile rẹ nitori iyan. Ṣugbọn ṣe o padanu ẹbi rẹ tabi nkan ini rẹ kankan nibi ti wọn ṣipo-pada lọ? Rara! Dipo eyi, bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, nigba ti iyan naa kasẹ nlẹ tan, o pada wa silu pẹlu awọn eniyan rẹ, ninu okun ati ilera. Yatọ si eyi, ọba tun paṣẹ pe ki a da ohun gbogbo ti o fi silẹ pada fun, iyẹn pẹlu gbogbo owo ti a pa lori awọn nkan ini rẹ. (Wo: 2Àwọn Ọba 8:3-6)

Ki ni idi ti arabinrin fi ri ojurere gba bi eyi? Idi ni pe igbeṣẹ ti o gbe lati kuro ni ilẹ naa ni asiko iyan yi jẹ eyi ti Oluwa pa laṣẹ fun un. Wo nkan ti bibeli sọ nipa eyi: “Eliṣa si wi fun obinrin naa, ọmọ ẹni ti o ti sọ di aaye wi pe, “Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitori ti Oluwa pe iyan: yoo si mu pẹlu ni ilẹ yii ni ọdun meje. Obinrin naa si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọrọ eniyan Ọlọrun naa? Oun si lọ pẹlu ile rẹ, wọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filisitini ni ọdun meje.” (2 Awọn Ọba 8:1-2)

Njẹ o ri bayẹn? Arabinrin yi ko sa kuro ni ilẹ naa pẹlu awọn ẹbi rẹ nitoripe o kan ro wipe nkan ti o tọ fun oun lati ṣe niyẹn. Dipo eyi, o fi ilẹ naa silẹ nitoripe adari rẹ ninu ẹmi, Wolii Eliṣa, sọ fun pe ifẹ Ọlọrun ni fun lati ṣe bẹẹ. Nitorina, nṣe ni o ṣe nkan ti o ṣe ni gbigbọran si aṣẹ Ọlọrun. Alabajọ ti ko ṣe kabamọ lori rẹ.

Awa naa ko ni kabamọ lori awọn igbesẹ wa, ti a ba jẹ ki Ọlọrun dari wa ni asiko rogbodiyan ti ilẹ wa lapapọ n ba finran lasiko yi, dipo ti a o kan fi ma fo lati ibikan si ibikan lati ṣe ohun yowu ti o ba ko si wa lọkan tabi ohun yowu ti awọn ti o wa ni ayika wa n ṣe. Yoo si dari wa, ti a ba le gbadura si lati ṣe bẹẹ. Lọna wo? O le jẹ nipasẹ iwe mimọ, nipasẹ iran tabi ala, nipasẹ awọn angẹli tabi nipasẹ awọn adari wa ninu ẹmi. Ṣugbọn dandan ni ki Ọlọrun dari wa lati ṣoriire, pẹlu bi gbogbo nkan ti ri yi, niwọn igba ti a ba ṣi ọkan wa paya fun lati dari wa.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Taló sọ pé kí wọ́n kúrò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 10, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 45 Read More »

Ìfẹ̀hónúhàn kò tó | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 44

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, oṣu Ẹrẹna 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu asiko itura wa fun wa ni ibi gbogbo ni orilẹ-ede yi loṣu naa, ki O si tun pa iwọ ati ẹbi rẹ mọ lati jẹ igbadun asiko itura ti O ba fun wa ni ẹkunrẹrẹ. Amin.

Gẹgẹ bi gbogbo wa ti ṣe le ri, a ti sọ orilẹ-ede wa sinu asiko iyan ti o buru jọjọ. Idi ni yi ti o fi jẹ pe bi ọpọ tilẹ n ṣiṣẹ kakakara ati pẹlu ọpọlọ, nṣe ni o n nira si ni gbogbo igba fun wọn lati ri ounjẹ jẹ. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, nkan ti a nilo ni idasi Ọlọrun, ko ki i ṣe iṣẹ aṣekara si tabi ifẹhonuhan lọpọ yanturu si.

Wayi o, mi o wa fẹ ki o ṣi mi gbọ. Iṣẹ aṣekara ṣe koko, o si ni ipo tirẹ laye. Nitorina, ọrọ Ọlọrun gba wa niyanju lati ma ṣe iṣẹ karakara, ki a si ma ya ọlẹ. Ifẹhonuhan naa si tun wa ni ipo tirẹ ni aye, iyẹn nigba ti ko ba ki i ṣe ẹmi iṣọtẹ ni o wa lẹyin rẹ tabi ti ko ki i ṣe pe a ṣe e lati jẹ ki nkan ti o bajẹ tun buru si. Fun apẹrẹ, nigba ti Kora, Datani, Abiramu ati Oni fẹhonu han lodi si iṣẹdari Mose ati Aarọni, Ọlọrun ṣe idajọ awọn ati awọn ti o wa pẹlu wọn pẹlu iku kayefi. Ilẹ la ẹnu rẹ, o si gbe gbogbo wọn mi. Ki ni o fa? Wọn mura lati doju iṣedari awọn ẹni-ami ororo Ọlọrun ti o wa laarin wọn delẹ, ki wọn si kọ ẹyin gbogbo orilẹ-ede wọn si ifẹ Ọlọrun. (Wo: Numeri 16)

Amọ ṣa o, nigba ti awọn ọmọbinrin marun-un ọkunrin kan ti o n jẹ Selofẹhadi fẹhonu han si Mose pe ki wọn ma pa ile baba wọn ti nidi ogun pinpin, nitoripe ko ni ọmọkunrin, Ọlọrun ko ba wọn wi tabi fi iya jẹ wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni O fun wọn ni nkan ti wọn bere fun. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ko lepa lati fa iṣedari Mose ya tabi lati ru awọn eniyan soke lodi si i. Dipo eyi, wọn kan fẹ ki o mọ wipe iyanjẹ ni yoo jasi ti a ba pa ile baba wọn ti ṣi ẹgbẹ kan nigba ti a ba n pin ilẹ-ileri. (Wo: Numeri 27:1-7)

Nitorina, ko buru ki a fẹhonu han lodi si nkan ti ko ṣiṣẹ tabi si nkan ti ko tọna nibi ti a ba wa. Aijẹbẹ, awọn alaṣẹ tabi awọn ti o wa ni ipo lati tun nkan ṣe kan le ro lọkan wọn pe nkan n lọ deede fun gbogbo eniyan. Fun apẹrẹ, ni asiko Eliṣa, iyan kan mu ni Isiraẹli ti o sọ diẹ lara awọn eniyan naa di ẹranko, ẹranko ti o n jẹ awọn ọmọ bibi inu wọn. Ọba wọn, niwọn igba ti o si n gbe ni ifọkanbalẹ ninu aafin rẹ, ko ba ma ti wa mọ nkan ti iyan yi ti n ṣe si awọn eniyan rẹ, ti ọkan ninu awọn obinrin orilẹ-ede naa ti o ti n jẹ awọn ọmọ-ọwọ wọn ko ba wa fẹhonu han si i. (Wo: 2Awọn Ọba 6:24-30)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe ifẹhonuhan arabinrin yi sọ ọba yi ji, o kan jẹ ki o mọ pe ohun ti jinna rere si iṣoro awọn eniyan rẹ ni. Ko yanju iṣoro naa. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọba yi ko mọ ọna abayọ si iṣoro ti o wa nilẹ, nitoripe o kọja ọpọlọ rẹ. Nitorina, gbogbo nkan ti o ṣe ko kọja pe o wọ aṣọ ọfọ, o si tun leri si wolii ti o gbajumọ ju ni ilẹ naa ni asiko naa, iyẹn Eliṣa. Ki ni idi? Idi ni pe o ro wipe nitoripe wolii yi ko ṣipẹ too fun ilẹ naa ni nkan ṣe bajẹ to bi o ti ṣe bajẹ. (Wo: 2Awọn Ọba 6:30-31)

Nitorina, nibi ti ifẹhonuhan gan ba ti ṣe pataki, ko le fun awọn adari ni ọna abayọ si iṣoro ilẹ wọn tabi ti awọn eniyan wọn. Ti wọn ko ba mọ ohun ti o tọ lati ṣe lati ran awọn eniyan wọn lọwọ, ifẹhonuhan ko le yanju iṣoro yowu ti o ba wa nilẹ. Bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ifẹhonuhan arabinrin yẹn ko fi opin si iyan ti o wa ni ilẹ Isiraẹli. Ṣugbọn o sọ ọba ji si pataki ki wọn ni idasi Ọlọrun. Ṣe Ọlọrun wa da si ọrọ wọn tabi ko da si? O da si nipa mimojuto gbongbo iyan ti ilẹ naa ni ati fifun wọn ni ọrọ̀ ki a to wi, ki a to fọ. (Wo: 2Awọn Ọba 7)

Nibakana, Ọlọrun le mojuto gbogbo gbongbo iyan ti a n ni iriri rẹ ni orilẹ-ede wa lọwọlọwọ yi, ki O si tun fun wa ni ọrọ̀ ki a to wi, ki a to fọ. A ko wa nilo lati duro de igba ti awọn eniyan ba to bẹrẹ si ni jẹ awọn ọmọ bibi inu wọn tabi ti ifẹhonuhan ti o n bi itajẹsilẹ ba gba ibi gbogbo kan ki awa ti a mọ ọn to bẹrẹ si ni ke pe fun idasi rẹ ni kiakia. Ṣugbọn awa melo gan ni a tilẹ ṣi gbagbọ pe Ọlọrun le yi nkan pada si rere fun wa ni orilẹ-ede yi? Kiki awa ti o ba gbagbọ ni ko ni dẹkun lati ma gbadura si i titi iṣẹ iyanu itusilẹ yoo fi ṣẹlẹ fun wa. Awọn naa si ni yoo tọ iyanu ti o n bọ yi wo, ti yoo si tun jẹ igbadun rẹ. Njẹ ki ọkan rẹ gba okun ki a ba le ka ọ mọ iye wọn, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ẹrẹna 2024 alaririn.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìfẹ̀hónúhàn kò tó | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 44 Read More »

Kò ní fi ẹlòmíràn rópọ̀ rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Èrèlé 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ wa ni ailewu ati ni pipe ni gbogbo ọsẹ naa, ki O si tun ma jẹ ki o ṣe ohunkohun ti yoo jẹ ki o padanu ipo ti O ti yan fun ọ si ọwọ ẹlomiran, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọba Sọọlu, iyẹn ọba akọkọ fun orilẹ-ede Isiraẹli, ko ki i ṣe ààyò awọn eniyan tabi ààyò eniyan Ọlọrun ti o n dari orilẹ-ede naa ni asiko naa, iyẹn Samuẹli. Dipo eyi, ààyò Ọlọrun ni o jẹ. Ọlọrun funrarẹ ni O mọ-ọn-mọ ṣe awari rẹ, ti O si tun yan an lati jẹ ọba lori awọn eniyan rẹ. Sibẹsibẹ, ni asiko kan, Ọlọrun kọ ọ ni ọba, O si wa elomiran lati rọpo rẹ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 9-15)

Ki ni eyi n sọ fn wa? Oun naa ni pe wipe Ọlọrun yan eniyan fun ipo tabi iṣẹ kan ko tunmọ si pe ko le kọ ẹni naa silẹ, ki O si wa ẹlomiran lati fi rọpo rẹ. O le ṣe bẹẹ. Amọ ṣa o, eyi ko wa jasi pe Ọlọrun yoo kọ ẹni naa silẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ. Ti a ko ba kọ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi Ọlọrun wa, Oun naa ko ni kọ wa silẹ gẹgẹ bi eniyan rẹ. Ṣugbọn O le kọ wa silẹ gẹgẹ bi ẹni ti ko yẹ tabi ti ko koju osuwọn fun ipo tabi iṣẹ ti O ti fi igba kan ri yan wa fun.

Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun kọ Sọọlu ni ọba, ti O si tun fi ẹlomiran dipo rẹ, ko kọ ọ ṣilẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ. Ṣugbọn nigba ti Sọọlu kọ ọ gẹgẹ bi Ọlọrun, ti o si wa iranwọ lọ si ọdọ àjẹ́ kan, Ọlọrun naa kọ ọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ. Nitorina, iṣoro yowu ti a le ma dojukọ, bi o tilẹ jẹ eyi ti a fi ọwọ ara wa fa sori ara wa ni, a ko gbọdọ lailai kọ Ọlọrun silẹ tabi yi pada kuro lọdọ rẹ. Aijẹbẹ, Oun naa ko ni ṣemeni-ṣemeji ju ki O kọ wa silẹ lọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 28; 2Tímótì 2:12)

Ki wa lo fa ti a fi kọ Sọọlu, ti a si tun fi ẹlomiran rọpo rẹ? Wo nkan ti awọn akọsilẹ iwe Mimọ yi sọ nipa rẹ:

“Samuẹli si wi fun un pe, “Iwọ hu iwa aṣiwere, iwọ ko si pa ofin ti Oluwa Ọlọrn rẹ fi fun ọ mọ, bi o ko ba ṣe bẹẹ, oun iba fi idi ijọba rẹ kalẹ lori Isirẹli laelae. Ṣugbọn nisinsin yii ijọba rẹ ki yoo duro pẹ, Oluwa ti wa ọkunrin ti o wu u ni ọkan rẹ fun ara rẹ, o si ti yan an lati ṣe olori fun awọn eniyan rẹ, nitori pe iwọ ko pa ofin Oluwa mọ.” (1Sámúẹ́lì 13:13-14)

“Ṣugbọn Samuẹli wi fun un pe, “Emi ko ni ba ọ pada. Iwọ ti kọ ọrọ Oluwa silẹ, Oluwa si ti kọ ọ ni ọba lori Isirẹli!”” (1Sámúẹ́lì 15:26)

Ṣe o ri wipe iṣoro Sọọlu ni pe ko mu ọrọ Ọlọrun ni pataki? Ṣugbọn Ọlọrun lo sọ ọ di ọba; ko sọ ara rẹ di ọba. Yatọ si iyẹn, Ọlọrun, ti o yan lati di ọba, tun fẹ fi idi ijọba rẹ mulẹ fun gbogbo igba. Ṣugbọn nitoripe, ni asiko kan, o bẹrẹ si ni ro wipe oun gbọn ju Ọlọrun lọ ati wipe oun le lọ aṣẹ Ọlọrun lọrun bi o ṣe wu oun, ki oun si tun tabuku wolii rẹ, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, O kọ ọ silẹ, O si tun yan ọdọmọdekurin kan rọpo rẹ.

Nitorina, ti o ba ni aṣa ki o ma gbe oye rẹ leke awọn aṣẹ Ọlọrun fun aye rẹ, o wa labẹ ewu ki Ọlọrun kọ ọ silẹ, ki O si tun fi ẹlọmiran rọpo rẹ fun awọn ipo giga tabi awọn iṣẹ rere kan ni aye yi, bi o tilẹ jẹ wipe iwọ ni ẹni naa ti a kọkọ yan fun wọn. Lotitọ, o le ni awọn idi ti o fi ma n fẹ ki ifẹ tirẹ leke ifẹ Ọlọrun tabi ti o ko fi ni ọ̀wọ̀ ti ko nitunmọ kankan fun awọn ti o yan le ọ lori. Ṣugbọn ni opin ohun gbogbo, iwọ naa yoo ri wipe awọn idi wọnyi ko kọja awawi asan ti Ọlọrun ko le lailai tẹwọgba.

Sọọlu naa ni awọn idi ti o fi tabuku ọrọ Ọlọrun ati wolii rẹ. Itara gbigbona rẹ lati di itẹ rẹ mu jẹ ọkan. Ibẹru awọn jagunjagun rẹ jẹ omiran. Ṣibẹsibẹ, Ọlọrun kọ ọ, O si tun fi ẹlomiran rọpo rẹ. Ko si wa si nkankan ti o ṣe lati gba itẹ rẹ fun awọn arọmọdọmọ rẹ ti o ṣiṣẹ. Ko si si nkankan ti awa naa le ṣe lati gba ipokipo tabi iṣẹkiṣẹ ti Ọlọrun ba ti gba kuro lọwọ wa fun ara wa. Nitorina, nṣe ni ki a ṣọ ara wa, ki a si ma fi aye gba aigbagbọ, agidi-inu, ibẹru, itara-gbigbona, ojukokoro, ifẹkufẹ, ẹtanu, igberaga, ilara tabi ohun miran lati fi aye silẹ fun un lati fi ẹlomiran ropo wa. Adura mi si ni pe ki a ma fi gbogbo igba kun wa pẹlu ọgbọn ati okun ti o peye lati rin pẹlu afiyesi eyi, ni orikọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kò ní fi ẹlòmíràn rópọ̀ rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 43 Read More »

A tú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìbẹ̀rù rẹ̀. | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 18, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 42

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2024. Mo si tun gbadura pe ki Ọlọrun ya ọkan rẹ ya ero ibẹru yowu ti o n sọ ọ di alailagbara, ti o si tun n di ọ lọwọ lati gbe awọn igbesẹ ti o tọ lati ni iriri isoriire ti o le jẹ tirẹ laye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu owe ọkunrin kan ti o fun awọn iranṣẹ rẹ ni owo lati fi ṣiṣẹ, eyi ti Jesu Oluwa wa sọ fun wa, idi ti iransẹ ti ko ṣe nkankan pẹlu owo ti a fun ko ṣe ṣe nkankan pẹlu rẹ ni pe ẹru ba a. Fun ọpọ ọdun, awọn oniwaasu kọ wa pe idi ti ko ṣe ṣe nkankan pẹlu owo ti a fun ni pe o woye pe o kere ju fun oun, iyẹn ti a ba wo si owo ti a fun awọn yoku. Ṣugbọn ko si nkankan ninu akọsilẹ ọrọ yi ti o sọ bẹ ẹ tabi ti o fun wa ni ero ti o jọ bẹ ẹ. (Wo: Mátíù 25:14-30)

Ni akọkọ, bi a ti se ri ninu akọsilẹ ọrọ yi, nkan ti oluwa iransẹ yi fun pọ gidigidi, bi o tilẹ jẹ wipe talẹnti kan pere ni. Idi si ni pe, ni asiko ti a n sọ yi, ọpọlọpọ owo ni talẹnti kan jẹ. Ekeji, oluwa rẹ fun oun ati awọn iransẹ yoku bi tirẹ ni owo ni ibamu pẹlu bi agbara wọn lati ṣe amulo rẹ ti ṣe to (Mátíù 25:15). Nitorina, ko ki i ṣe nitori pe owo ti a fun un kere pupọ tabi pe ko to ti awọn yoku ni ko ṣe ṣe nkankan pẹlu rẹ. Gẹgẹ bi ọrọ oun funrarẹ, ko ṣe nkankan pẹlu rẹ nitoripe o bẹru ati padanu rẹ. (Wo: Mátíù 25:24-25)

Ni kukuru, nitoripe iransẹ yi jẹ ki ibẹru pe oun yoo padanu owo ti a fun un ki o gbakoso ọkan rẹ, oju rẹ fọ si gbogbo anfaani ti ko ba ṣe amulo lati lo owo naa ati lati sọ di ilọpo-ilọpo. Nitorina, nigba ti awọn iransẹ yoku bi tirẹ n sọ talenti ti wọn di ilọpo-ilọpo, nṣe ni o tẹpamọ awọn nkan ti ko nitunmọ, awọn nkan ti oluwa rẹ ko ni bere ọrọ lọwọ rẹ lori wọn. Bayi si ni o ṣe padanu talẹnti rẹ si ọwọ ọkan lara awọn ti o ṣiṣẹ aṣekara pẹlu talẹnti tiwọn, ti o si tun padanu ipo rẹ niwaju oluwa rẹ, dipo ki a gbe e ga. (Wo: Mátíù 25:24-30)

Ki si ni ẹkọ yi n kọ wa? Oun naa ni pe ẹru ma n sọni di abirun. Kiki ikuna nikan si ni ẹru ma n ṣi oju awọn eniyan si. Ti gbogbo nkan ti o wa n ri ko ba wa ju ikuna lọ, ko si ki o ma ba gbagbe pe o ni Ọlọrun ati wipe O le fi ọna han ọ lati sọ ikuna di aṣeyọri. Nitorina, nṣe ni wa ka ri wipe o ti sọ ireti nu, ti o si ti yọnda ara rẹ fun ikuna, ikú tabi ìṣẹ́.

Ṣugbọn o ko nilo lati yọnda ara rẹ fun ikuna, iku tabi ìṣẹ́. Ọkankan ninu wa ko nilo lati yọnda ara rẹ fun awọn nkan wọnyi. Lotitọ, a le koju ija si wa pẹlu oniruuru ẹru nitori asiko ti a ba ara wa tabi asiko ti orilẹ-ede wa wa. A le kọju ija si wa pẹlu ibẹru ebi, ibẹru owo ile-iwe awọn ọmọ wa, ibẹru owo ile ti a n gbe ti a ko i ti san, ibẹrun aisan kan ti o n yọ agọ ara wa lẹnu, ibẹru awọn gbese kan ti a ko i ti ri san, ibẹru okowo tabi iṣẹ kan ti o n kuna lọwọ wa, ibẹru idanwo kan ti o n bọ tabi ibẹru wipe a o padanu ẹnikan ti o ṣe iyebiye si wa.

Irufẹ aṣo yowu ti ibẹru ti a n dojukọ le da a, nkan ti a nilo lati ṣe ni pe ki a ba Ọlọrun sọrọ nipa rẹ. Yoo si mojuto. Dafidi, ninu ọkan ninu awọn orin rẹ, sọ wipe, “Emi wa Oluwa, o si da mi lohun; O si gba mi kuro ninu ibẹru mi gbogbo.” (Sáàmù 34:4) Njẹ o ri bayẹn? Nigba ti Dafidi safẹri Oluwa nipa ohun gbogbo ti o n yọ ọ lẹnu, ti o si n da ẹru ba a, O gba a kuro lọwọ gbogbo ibẹru rẹ.

Bawo ni Oluwa ti ṣe gba ọkunrin yi kuro lọwọ gbogbo ibẹru rẹ? A ko mọ ọn, nitoripe ko salaye rẹ fun wa lẹkunrẹrẹ. Amọ ijẹri rẹ ni wipe nigba ti oun wa Oluwa, a tu oun silẹ kuro lọwọ gbogbo ẹru oun. Nitorina, ti iwọ ko ba mọ tẹlẹ, mọ bayi pe Ọlọrun le gba ọ kuro lọwọ irufẹ ibẹru yowu ti o n kun ọ pẹlu ironu, ti o n jẹ ki o ṣaarẹ tabi ti o n jẹ ki o fẹ ki o salọ tabi gba ẹmi ara rẹ. Nkan ti o nilo lati ṣe naa ko ju ki o wa oju Oluwa lori ọrọ naa. Oun yoo si tu ọ silẹ kuro lọwọ rẹ, yoo ṣi oju rẹ si awọn ipese rẹ fun ọ lati ni iriri aṣeyọri ati iṣẹgun, yoo si tun fun ọ ni ẹri ti o ga lati jẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

A tú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìbẹ̀rù rẹ̀. | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 18, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 42 Read More »

Ọlọ́run yóò bẹ̀ wá wò lótìtọ́ọ́ pẹ̀lú ìrànwọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 11, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 41

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun bẹ iwọ ati idile rẹ wo pẹlu asiko itura nibikibi ti ara ba ti n ni yin, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni ọjọ wọnni ti awọn Onidajọ n ṣe idari ni Isiraẹli, ìyàn ti o le kan mu, eyi ti o jẹ ki awọn eniyan bẹrẹ si ni fi ilẹ naa silẹ lọ si awọn ibomiran ti wọn gbagbọ pe awọn yoo ti le jẹun daradara ati gbe aye daradara. Asiko yi si ni ọkunrin kan ti a n pe ni Ẹlimeleki ati aya rẹ Naomi fi ilẹ naa silẹ pẹlu awọn ọmọkunrin wọn mejeji lati lọ si Moabu. O wa ṣeni laanu pe iṣipopada wọn lọ si Moabu ko jasi ire fun wọn rara. Idi si ni pe Elimeleki ati awọn ọmọkunrin rẹ mejeji padanu ẹmi wọn nibẹ. Yatọ si iyẹn, awọn ọmọkunrin rẹ mejeji yi ko fi ọmọ kankan silẹ si aye. Nitorina, ko si nkan ti o ku idile yi ku ju opó mẹta lọ. (Wo: Rúùtù 1)

Wayi o, o wa ṣeeṣe ki a ri awọn miran ti awọn naa ko lọ si Moabu tabi si awọn ibomiran ni asiko yi kanna ti ko ni irufẹ iriri buruku ti idile Elimeleki ni. Ṣugbọn ọkan lara ẹkọ ti itan yi n kọ wa ni pe ki a ṣipo-pada kuro ni ibi iṣẹ wa, ile wa, ilu wa tabi orilẹ-ede wa lọ si ibomiran ko ki i fi gbogbo jẹ ọna ti o tọ lati wa ojutu si iyan tabi si asiko inira. Ti a ba paarọ iṣẹ wa tabi ibi ti a n gbe lalai ṣe pe a gba ifihan tabi itọni lati ọdọ Ọlọrun, o ṣeeṣe ki a kabamọ rẹ nigbẹyin.

Nitorina, ma kanju sa jade kuro ni orilẹ-ede yi ni asiko iyan yi nitoripe gbogbo awọn ti o mọ ni o n sa a lọ kuro ninu rẹ. Eyi le ma jẹ ọna ti Ọlọrun fẹ lo lati pa ọ mọ ati lati jẹ ki o ṣe rere. Fun apẹrẹ, bi a tun ti ṣe fi han wa ninu bibeli, asiko kan wa ti Isaki fẹ sọkalẹ lọ si Ijibiti nitori iyan ti o le kan ti o mu nibi ti o wa. Amọ Ọlọrun sọ fun pe ki o ma lọ ṣugbọn ki o duro sibi ti o wa. Ki ni idi? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe iyan mu nibẹ, ipese rẹ fun un lati ṣoriire naa wa nibẹ pẹlu. Nkan ti Isaki kan nilo ni ki o ri awọn ipese yi, ki o si bẹrẹ si ni ṣe amulo wọn. Nigba ti o si ri wọn, ti o si bẹrẹ si ni ṣe amulo wọn, o di ọlọrọ to bẹẹ gẹẹ ti gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ fi bẹrẹ si ni ṣe ilara rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 26)

Ki wa ni koko eyi? Oun naa ni pe wipe inira wa ni ibikan ko tunmọ si pe ipese Ọlọrun fun wa lati ṣoriire ko si nibẹ fun wa bakanna. Nitorina, ki a to bẹrẹ si ni gbero lati ṣi ipo pada nitori inira ti o wa nibi ti a wa tabi nitori pe anfaani kan jẹyọ fun wa lati gbe igbe aye ti o suwọn si ni ibomiran, o yẹ ki a kọkọ gbadura si Ọlọrun naa, ki a si gbọ ọrọ lati ẹnu rẹ. Aijẹbẹ, a le fi aimọkan-mọkan sa kuro ni bi ti oriire wa wa lọ si ilẹ ofo.

Elimeleki ati idile rẹ fi Isiraẹli silẹ lọ si Moabu nitoripe wọn woye pe ibẹ yoo jẹ ile iṣoriire ati isinmi fun wọn. Ṣugbọn, wọn wa pada ri ibẹ bi ilẹ ofo fun wọn. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe wọn lọ si ilẹ yi pẹlu ọpọ, nṣe ni Naomi, ẹnikanṣoṣo ti o ye laarin wọn, pada pẹlu ọwọ ofifo. Njẹ ki o ma fi aye rẹ, nkan ini rẹ ati ifarajin rẹ ṣofo lori lile ofo, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni kukuru, nigba ti Naomi si wa ni ilẹ Moabu, ti ko si mọ nkan ti yoo ṣe pẹlu aye rẹ ati aye awọn iyawo awọn ọmọ rẹ, Ọlọrun bẹ orilẹ-ede Isiraẹli wo. Bibeli sọ pe, “Nigba ti Naomi gbọ ni Moabu ti o wa wi pe Oluwa ti bẹ awọn eniyan rẹ wo nipa fi fun wọn ni ọpọ ounjẹ. O si dide pẹlu awọn iyawọ ọmọ rẹ mejeeji lati pada si ilu rẹ.” (Rúùtù 1:6) Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun pàpà bẹ awọn eniyan rẹ wo pẹlu iranwọ nipa pipese ounjẹ fun wọn. Ibẹwo yi si ga to bẹẹ gẹẹ ti Naomi gan fi ranti ile, ti o si mura lati pada si ibẹ.

Nitorina, bi o ti wu ki nkan le to fun wa ni orilẹ-ede yi ni asiko yi, Ọlọrun si le bẹ wa wo pẹlu iranwọ ti o ga, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo awọn eniyan wa ti wọn ti ko lọ si orilẹ-ede miran bẹrẹ si ni pada wale. Ọlọrun yoo si bẹ wa wo lotitọ pẹlu irawọ nitoripe awa kan n gbadura laisinmi pe ki O ṣe bẹẹ. Adura mi si ni pe ibi ti o yẹ ki o wa gẹlẹ ni iwọ yoo wa nigba ti iranwọ rẹ ba papa de, ti a si mu awọn asiko itura tọ wa wa. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọlọ́run yóò bẹ̀ wá wò lótìtọ́ọ́ pẹ̀lú ìrànwọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 11, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 41 Read More »

Ìbòjú fún ibi | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 04, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 40

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Èrèlé 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ojurere rẹ ki o di ilọpo-ilọpo si fun ọ ni gbogbo igba ninu oṣu naa, ki o ma ba ṣe alaini ohun rere kankan ninu rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Peteru ti o sọ wipe, “Ẹ maa gbe gẹgẹ bi ẹni ominira, ṣugbọn ẹ maṣe lo ominira yin lati bo ibi mọlẹ; ṣugbọn ki ẹ gbe gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun.” (1Pétérù 2:16) Tani ki o ma gbe gẹgẹ bi ominira enyan? Awa ti a ti tu silẹ npasẹ Jesu Oluwa wa kuro lọwọ awọn ẹṣẹ wa ati kuro lọwọ agbara eṣu ni. Ranti wipe ọrọ Ọlọrun sọ pe, “Ti ọmọ ba sọ yin di ominira, ẹ o si di ominira nitootọ.” O si ti tu wa silẹ. Nitorina, a ti di ominira nitootọ, ominara lododo. (Wo: Jòhánù 8:36)

Wayi o, niwọn igba ti a ti di ominira eniyan, Peteru wa sọ fun pe ki a tẹsiwaju, ki a si bẹrẹ si ni gbe igbe aye awọn ẹni ti o ti di ominira nitootọ. Eyi jasi pe ki a tẹsiwaju, ki a si ma gbe ile aye wa gẹgẹ bi awọn ti ko si ni abẹ agbara ẹṣẹ, eṣu ati awọn aṣa eniyan ti o n pani lara. Bẹẹni, ki a tẹsiwaju, ki a si ma gbe igbe aye ti o larinrin, ti o si tun kun fun ayọ pẹlu.

Amọ ṣa o, bi Peteru tun ṣe wa tẹsiwaju lati fi han wa, a ko gbọdọ lo ominira wa ninu Kirisiti Jesu gẹgẹ bi boju-boju fun iṣẹ ibi kankan. Ki ni idi ti o ṣe sọ eyi? O ṣọ eyi nitoripe o ṣeeṣe fun wa lati lo ominira wa ninu Kirisiti Jesu gẹgẹ bi boju-boju fun oniruuru iṣẹ ibi.

Lọna wa ni eyi gba ṣeeṣe? Nikukuru, o ṣeeṣe ni ọna yi: ti a ba gbe aye awa gẹgẹ bi onigbagbọ ododo ninu Kirisiti Jesu fun igba ti o pẹ diẹ, awọn ti o wa ni ayika wa yoo bẹrẹ si ni gbagbọ pe a ti gba wa la nitootọ kuro lọwọ ẹṣẹ, kuro lọwọ eṣu ati kuro lọwọ awọn imisi buburu aṣa awọn eniyan. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ, awọn eniyan yoo bẹrẹ si ni fi ọkan tan wa, wọn o si tun ma ri wa gẹgẹ bi ẹni ti ko le kopa ninu iṣẹ ibi kankan. Asiko yi gan an wa ni a le tan wọn jẹ, ki a si lo igbẹkẹle ti wọn ti ni ninu wa gẹgẹ bi iboju fun iṣẹ ibi.

Wo Judasi Isikariọti, fun apẹrẹ. Johanu sọ fun wa ninu iyinrere rẹ pe ole ni. O ma n ji owo Jesu. Bawo ni Johanu ṣe mọ eyi? Jesu funrarẹ lo gbọdọ sọ fun un, nitori awọn ọmọ ẹyin yoku ko mọ ni asiko naa. Bawo si ni Jesu ṣe mọ? Ṣe o gba mu lọrun ọwọ ni? Rara! Ti o ba jẹ bẹ ni, a ko ba kọ ọ sinu bibeli. Bawo gan ni O ṣe wa mọ pe Judasi n ja Oun lole? Nipa ifihan ni O ṣe mọ. Ṣe O si wa ba sọ nkankan tààrà-táárá lori ọrọ naa? Rara o! Kini idi? Idi ni pe iwaasu ti o ti gbọ ti to lati jẹ ki o yi iṣesi rẹ pada. (Wo: Jòhánù 12:4-6)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ni o wa loni ninu ijọ ti a ko le ma mọ nkankan nipa awọn iwa ibajẹ ti wọn n wu, ti Ọlọrun ko ba fi han wa. Ki si ni idi? Wọn ti jagbọn bi a ti ṣe n ṣe boju-boju. Wọn ti kọ bi a ti ṣe n ṣi igbẹkẹle awọn eniyan ninu wọn bi ọmọ Ọlọrun lo lati jale, ṣe agbere, lu jibiti, ṣiṣẹ oṣo tabi kopa ninu oniruuru iṣẹ ibi.

Bi Judasi si ṣe n ṣe niyẹn. O bẹrẹ, gẹgẹ bi awọn apọsiteli yoku naa ṣe bẹrẹ, gẹgẹ bi ẹni ti o ni igbagbọ otitọ ninu Kirisiti Jesu. Nitori ijẹri igbagbọ ati ifọkantan rẹ, Jesu si wa fi ṣe akapo rẹ. Ṣugbọn nigba ti o ṣe diẹ si, o bẹrẹ si ni ja Oluwa lole. Ṣibẹṣibẹ ko si ọkankan ninu awọn apọsiteli ti o fura si. Kini idi? Wọn n ro wipe ẹni ti awọn mọ ọn si tẹlẹ naa ni o si jẹ. Ṣugbọn o ti yipada, o si ti di olojukokoro ati onikupani eniyan. Nṣe ni o kan n lo iwa rere ti o ti ni sẹyin lati bo nkan ti o n ṣe mọlẹ.

Njẹ ki wa ni bibeli sọ nipa awọn ti o n ṣe bayi, awọn ti o n bo ẹṣẹ wọn mọlẹ? O sọ wipe wọn ko ni ṣe rere. Nkan ti o si ṣẹlẹ si Judasi Isikariọti naa leyi. Ko ṣe rere. Dipo bẹẹ, o ṣegbe lalai si atunṣe. Ko si ọkankan ninu awọn apọsiteli yoku ti o le ran an lọwọ tabi gba a la, nitori wọn ko mọ nkan ti o n ba kaakiri. O ti ṣe aṣepe iṣẹ lati bo ohun gbogbo mọlẹ pẹlu ẹri iwa rere ti o ni tẹlẹ. (Wo: Ìwé Òwe 28:13)

Ni kukuru, koko nkan ti a n sọ ni pe a gbọdọ kiyesara lati ma fi ominira wa ninu Kirisiti Jesu ṣe boju-boju fun ibi. Ki a ma fi igbẹkẹle awọn eniyan ninu wa gẹgẹ bi Kirisitiẹni rere ṣe boju-boju lati ma tan wọn jẹ, ja wọn lole, lu wọn ni jibiti tabi kẹ pakute iṣekuṣe fun wọn. Nṣe ni a o ma di ifarahan iṣẹ ibukun Ọlọrun ninu aye wa lọwọ, ti a ba n ṣe eyi. Ọlọrun si wa le ma sọ nkankan tààrà-táárá fun wa lori ọrọ yi, ti O ba gbagbọ pe a ti gbọ ọrọ rẹ to lati yi iṣesi wa pada. Lafikun, O le ma fun ẹnikẹni ni ifihan nipa wa ti yoo jẹ ki wọn le gba wa la. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ, o ṣeeṣe ki a kan parun lojiji lalai si atunṣe. Njẹ ki eyi ma jẹ ipin rẹ ni orukọ Jesu. Amin. Ṣugbọn dẹkun lati ma fi ominira rẹ ninu Kirisiti Jesu ṣe boju-boju fun ibi.

A ku oṣu tuntun.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìbòjú fún ibi | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 04, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 40 Read More »

Lawọ́ sí Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 39

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Sẹrẹ ati Èrèlé ọdun yi pọ mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ si gbogbo igbesẹ ti o nilo lati gbe lati fi idi mulẹ sinu dídara rẹ ati sinu iṣerere ninu ọdun yi, ki O si tun fun ọ ni okun lati gbe wọn, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn igbesẹ ti o nilo lati bẹrẹ si ni gbe lati fi idi mulẹ sinu didara Ọlọrun ati sinu iṣoriire lọdun yi ni lilawọ si Ọlọrun. Bawo ni a ṣe le fi han pe a lawọ si Ọlọrun? O kere ju, gbogbo wa ni a mọ pe Ọlọrun ko ni naa owo wa, jẹ ounjẹ wa tabi gbe ninu ile yowu ti a ba kọ fun un. Bawo wa ni a ṣe fẹ fi ilawọ han si?

Ni kukuru, a le fi ilawọ han si Ọlọrun, lakọkọ, nipa fifi nkan silẹ lati gbe iṣẹ rẹ laarin awọn eniyan lárugẹ. Ekeji, a le fi ilawọ han si nipa fifi fun awọn ti O ran lati ma bọ wa pẹlu ọrọ rẹ ati lati dari wa ni ipa ọna ododo. Ẹkẹta, a le fi han pe a lawọ si i nipa fifi fun awọn alaini ti o wa ni ayika wa. (Wo: Ditarónómì 15:7-11; 1Kiróníkà 29:1-9; Ìwé Òwe 19:17; Mátíù 25:40)

Ki wa ni idi ti o ṣe ṣe pataki ki a lawọ si Ọlọrun ni awọn ọna ti a mẹnuba yi? Akọkọ, o ṣe pataki nitoripe ki a ma la ọwọ si le ṣi ilẹkun silẹ fun aṣedanu ninu aye wa. Fun apẹrẹ, ninu iwe Wolii Hagai, a ri wipe idi kan pataki ti awọn eniyan Ọlọrun ti o pada wa lati ikọlọ Babiloni ṣe n ni iriri aṣedanu ni pe wọn pa kikọ tẹmpili Ọlọrun ti. Awọn eniyan wọnyi kan ṣa ri wipe bi o tilẹ jẹ wipe awọn n ṣiṣẹ karakara, iṣẹ karakara naa ko gbe iṣoriire larugẹ ninu aye wọn – o kan n ja si asan ni. Ti Ọlọrun ko ba wa lọ ran Hagai lati jẹ ki wọn mọ ibi ti nkan ti yiwọ ni, nṣe ni ọpọ wọn ko ba ṣegbe sinu iṣẹ. (Wo: Hágáì 1)

Nibakanna, ọpọ awọn onigbagbọ ni o jẹ wipe wọn n ṣiṣẹ bi erin loni ṣugbọn ti wọn n jẹ ijẹ ẹliri nitoripe wọn ko lawọ si Ọlọrun., Awọn naa, bi awọn eniyan igba aye Hagai, ma n fi gbogbo igba ni awawi kan tabi omiran lati ma fi nkan silẹ fun iṣẹ Ọlọrun, fun awọn iranṣẹ rẹ tabi fun awọn alaini ti o wa ni ayika wọn. Ti ko ba wa ṣe pe irufẹ awọn wọnyi ronupiwada, ki wọn si ma ṣe nkan ti o tọ, o ṣeeṣe ki wọn ku sinu iṣẹ nikẹyin-kẹyin. Ki eyi ma ṣe jẹ ipin rẹ laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Siwajusi, o tun ṣe pataki ki a lawọ si Ọlọrun, ti a ba fẹ jẹ igbadun ere iṣẹ ọwọ wa. Jesu Oluwa wa sọ owe kan nipa ọkunrin ọlọrọ kan ti ilẹ rẹ ṣe daradara ni ọdun kan. Gẹgẹ bi O ti jẹ ki o ye wa, gbogbo ero ọkunrin yi ko wa kọja bi yoo ti ṣe kọ awọn àká (ilé-ìkó-oúnjẹ-pamọ́sí) ti o tobi ju awọn eyi ti o ni tẹlẹ lọ ati bi yoo ti ṣe farabalẹ bẹrẹ si ni gbadun ọrọ̀ rẹ fun ọpọlọpọ ọdun ti o n bọ. Ko tilẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun tabi sọ ohunkohun nipa fifi nkan silẹ fun iṣẹ rẹ. Lafikun, ko sọ nkankan nipa riran awọn alufa ti o wa nilẹ naa lọwọ tabi nipa riran awọn alaini ti o wa ni ayika rẹ lọwọ. Ti ara rẹ nikan ni o n ro. Alánìkànjọ́pọ́n ati ahun eniyan gba a ni! (Wo: Luùkù 12:16-21)

Ki a ma fa ọrọ gun, nigba ti o ṣetan gbigboriyin fun ara rẹ ati sisọrọ nipa igbadun ọjọ́-ọ̀la rẹ, Ọlọrun fesi, O si sọ fun pe ni alẹ ọjọ ti a n wi yi gan ni a o bere ẹmi rẹ lọwọ rẹ. Eyi tunmọ si pe a ko ni fun ni aaye lati jẹ igbadun ere iṣẹ ọwọ rẹ. Awọn miran ni yoo jẹgbadun rẹ. Oluwa wa pari owe naa nipa sisọ pe bayi gẹlẹ ni yoo ti ṣe ri fun olukuluku eniyan ti o n to iṣura jọ fun ara rẹ ṣugbọn ti ko lawọ si Ọlọrun. Nitornia, ki a hawọ si Ọlọrun le ge ọjọ aye eniyan kuru. Mo si fẹ ki o fi eyi si ọkan.

Idi kẹta ti a fi nilo lati lawọ si Ọlọrun ni pe iṣoriire wa laye nigbamiran le sorọ mọ ọn. Fun apẹrẹ, fun opo Sarefati ati ọmọkunrin rẹ lati ma ku danu ati lati ṣerere ni asiko iyan aye Ọba Ahabu, o nilo lati lawọ si eniyan Ọlọrun ni, Elija. O wa ṣeeṣe pe obinrin yi ti lawọ sẹyin ni asiko ti o ni ọpọ. Amọ ko ki i ṣe ilawọ rẹ ni asiko ti o ni ọpọ ni o ṣi ilẹkun iṣẹ iyanu ipese fun ni asiko iyan yi. Dipo eyi, ilawọ rẹ ni asiko iyan naa, nigba ti o jẹ wipe nkan diẹ kerekere ni o ni lọwọ, ni o ṣi ilẹkun naa fun un. Ti ko ba wa fi tọkantọkan pin nkan ti o ni pẹlu eniyan Ọlọrun naa ni asiko yẹn nkọ? Ṣe yoo le la iyan naa kọja? Rara! (Wo: 1Awọn Ọba 17)

Nitorina, ọrọ Ọlọrun sọ wipe, “Eniyan kan n fun ni lọfẹ ẹ, sibẹ o n ni si i; omiran n hawọ ju bi o ti yẹ ṣugbọn o di alaini. Ẹni ti n ṣoore yoo maa gberu si i; ẹni ti o tu ẹlomiran lara yoo ni itura.” (Ìwé Òwe 11:24-25) Njẹ o ri bayẹn? Awọn ọ̀lawọ́ eniyan yoo ṣe rere. Ṣugbọn awọn ahun eniyan yoo pari aye wọn sinu ìṣẹ́. Nitori eyi, pinnu ninu ọkan rẹ lati lawọ si Ọlọrn lọdun yi ati la ma ya ahun si i. Ọlọrun yoo si fẹ aala iṣerere rẹ gbooro lọna ti o ga lotitọ. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Lawọ́ sí Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 39 Read More »