Author name: 23?Racing_Horse

Ǹjẹ́ o wà ní àrọ́wọ́tó rẹ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, ọdun 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti ko jẹ ki o wa ni arọwọto rẹ fun lilo lati bukun fun awọn miran, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, gbogbo igba ni Ọlọrun ma n wa awọn irinṣẹ ti O le lo lati fi idi ete rere rẹ mulẹ ninu aye awọn eniyan. O le jẹ ete rere rẹ lati wo wọn san, lati gba wọn la tabi lati jẹ ki wọn ṣoriire ni O fẹ mu ṣe. O ṣa ma n fi igba gbogbo nilo ọkunrin tabi obinrin kan tabi ọdọmọdekurin tabi odemọdebinrin kan ti o wa ni arọwọto rẹ lati lo nigbakigba ti O ba fẹ.

Fun apẹrẹ, O sọ eyi fun Isikiẹli nipa awọn eniyan Isiraẹli: “Emi si wa ẹnikan laarin wọn, ti iba tun odi naa mọ, ti iba duro ni ibi ti o ya naa niwaju mi fun ilẹ naa, ki emi ma baa parun: ṣugbọn emi ko ri ẹnikan.” (Ísíkíẹ̀lì 22:30) Iwọ naa wo bayẹn. Bi o tilẹ jẹ pe o tọ ki Ọlọrun ṣe idajọ awọn eniyan wọnyi nitori ọpọlọpọ ẹṣẹ wọn, ko si papa kanju lati ṣe idajọ wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni O n fi suuru wa gbogbo ilẹ naa boya Oun yoo tilẹ ri ẹnikan ti o n gbadura si Oun fun wọn, ki O ba le ṣaanu fun wọn. O wa ṣeni laanu pe ko ri ẹnikankan. Nitorina, ko si nkan miran ti O le ṣe ju ki O ṣe idajọ wọn lọ.

Nibakanna, ọpọ ni a ti fi silẹ lati jiya tabi lati ku nitoripe Ọlọrun ko ri ẹnikẹni lati lo lati mojuto wọn. Iwọ naa wo bi awa kan ṣe n gbadura ni gbogbo igba pe ki Ọlọrun da si ọrọ iṣedari orilẹ-ede yi. Ṣe o ro pe Ọlọrun ko ki i tẹti si wa ni? Tabi ṣe o ro wipe ko tilẹ wu u lati dahun adura wa ni? O kuku n tẹti siwa, O si tun n fi idahun si adura wa. Iṣoro ti o wa nibẹ ni pe O le ma ti ri ọkan kankan ni arọwoto rẹ fun lilo lati mu irufẹ itura ati ibalẹ ọkan ti a fẹ tọ wa wa. Nitorina, a tun nilo lati ma gbadura pe ki awọn ọkan ti O le lo lati gba orilẹ-ede wa la wa ni arọwọto rẹ.

Ṣugbọn awa gan an tilẹ wa ni arọwọto rẹ lati lo lati gba irufẹ awọn adura wọnyi? Ṣe a wa ni arọwọto rẹ fun lilo lati ṣe ohunkohun rara? Eleyi kọja ki a ma wa si awọn ipade ijọ wa. A le ma wa si awọn ipade ijọ wa, ki a si ma wa ni arọwọto Ọlọrun fun lilo lati bukun fun ẹnikẹni. Bi o ti ṣeeṣe ki o mọ, o ṣeeṣe ki agọ ara wa wa ninu ipade ijọ kan ṣugbọn ki a wa ni ibomiran ninu ọkan wa. Nitorina, nigba ti wọn ba ṣe awọn nkan ti o le bukun fun awọn miran, bi gbigbadura fun wọn, ninu ipade naa, ọkan wa ko kopa ninu rẹ. Bawo gan wa ni Ọlọrun ṣe fẹ ri wa lo lati bukun fun ẹnikẹni?

Ninu iwe isọtẹlẹ rẹ, Aisaya sọ ọrọ asiko kan ti o ba ara rẹ niwaju Ọlọrun ninu iran kan fun wa. Gẹgẹ bi o ti fi han wa, bi o tilẹ wa jẹ wipe o wa niwaju rẹ, Ọlọrun si tun n bere pe, “Tani n o ran? Tani yoo si lọ fun wa?” Kini idi ti Ọlọrun ko kan ṣe sọ pe, “Aisaya, mo fẹ ran ọ si awọn eniyan mi ki o ba le kọ wọn ni ọna mi?” Idi ni pe Ọlọrun ko ṣetan lati tan ara rẹ pe Aisaya wa ni arọwọto Oun fun lilo nitoripe o kan duro siwaju rẹ. Nitorina, Aisaya nilo lati fihan pe oun wa ni arọwọto rẹ fun lilo ki O to le ran lọ si ibikibi. (Wo: Àìsáyà 6:1-10)

Lọna kanna, pe a n wa si ipade ijọ ko to fun Ọlọrun lati lero wipe a wa ni arọwọtọ rẹ̀ fun lilo, iyẹn ti awa gan an ko ba fihan pe a wa ni arọwọto rẹ ati wipe O le lo wa. Wo ọpọ ijọ wa loni. Njẹ o mọ wipe awọn adari awọn ijọ yi ko kan le gba wipe a wa ni arọwọto wọn lati fun ni iṣẹkiṣẹ, biko ba ṣe pe a fihan pe a wa ni arọwọto wọn?

Fun apẹrẹ, ti o ba ma n fi igba gbogbo parẹ ni kete ti ipade ijọ kan ba ti pari, njẹ a le sọ wipe oun fi ara rẹ han bi ẹni ti o wa ni arọwọto lati ṣiṣe fun Ọlọrun ninu ijọ rẹ bi? Rara! Tabi ti iṣẹ kan ba wa ti ijọ fẹ ṣe, ti o ko si fi ara rẹ han lati kopa ninu rẹ, lalai ṣe pe o gba aye, ṣe awọn adari rẹ yoo ri ọ gẹgẹ bi ẹni ti o wa ni arọwọto lati darapọ mọ wọn ni ṣi ṣe iṣẹ fun Ọlọrun bi? Rara! Wo o, ẹni ti adari ijọ rẹ ba n ri ṣaaṣa ni sakani rẹ tabi ẹni ti o n fi gbogbo igba kan si i ni yoo ri bi ẹni ti o wa ni arọwọto oun lati jọ ṣiṣẹ Oluwa. Ko le ri ẹni ti o n fi gbogbo igba tabi ọpọ igba farapamọ fun un bi ẹni ti o fẹ nkan ṣe.

Nitorina, ti a ko ba wa ni arọwọto lati ṣiṣẹ pẹlu awọn adari tabi awọn ọmọ ijọ wa ninu awọn ipade wa, ki lo fẹ fi idi rẹ mulẹ pe Ọlọrun gan yoo ri wa bi ẹni ti o wa ni arọwọto rẹ fun lilo ni ibi iṣẹ wa, ile-iwe wa tabi adugbo wa? Ko si. Lotitọ, pe eniyan wa ni arọwọto Ọlọrun ko tunmọ si pe ẹni naa koju-oṣuwọn fun un lati lo. Amọ bi o tilẹ jẹ wipe awa ni a koju-oṣuwọn julọ fun iṣẹ ti O fẹ ṣe, niwọn igba ti a ko ba ti si ni arọwọto rẹ, ko si ni ki a ma jẹ alaiwulo fun un. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, O ṣeeṣe ki Ọlọrun gba aṣálẹ̀ kan lọ lati lọ wa Mose kan lati lo tabi gba inu tubu lọ lati lọ mu Josẹfun miran jade wa tabi lọ si Babiloni lati lọ wa Nehemaya miran lati lo.

Adura mi ni pe ọrọ ko ni su Ọlọrun debi wipe yoo wa ẹni ti yoo fi rọpo wa lọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin. Ọna kan ti a si fi le ma jẹ ki eyi waye ni pe ki a bẹrẹ lati ma fi ara wa si arọwọto rẹ fun lilo.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ǹjẹ́ o wà ní àrọ́wọ́tó rẹ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 38 Read More »

Sọ ọ́ dí mímúṣẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 14, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu ọdun ọdun yi, ọdun 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni iyara lati ri erongba rere gbogbo ti O gbin sinu ọkan rẹ gbeṣe ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi o ti ṣe han si gbogbo wa, ọdun yi ti n kuro diẹdiẹ ni ọdun tuntun lati di ògbólógbòó ọdun. Nitorina, ti a ba ri ohun rere kankan ti Ọlọrun fi si wa lọkan lati ṣe ninu ọdun naa, isinsinyi ni asiko lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati ṣe e. Jesu fi igbakanri sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ: “Awa ni lati ṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, niwọn igba ti o ba ti jẹ ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ.” (Jòhánù 9:4) Njẹ o ri bayẹn? A ko ni gbogbo asiko ti o wa ni aye yi lati gbe erongba tabi ala rere yowu ti a ba ni fun ọdun yi ṣe. Nitorina, ti ko ba ṣe wipe a bẹrẹ ni kiakia lati ma ṣiṣẹ lati sọ ero tabi ala naa di otitọ, ilẹ yoo ṣu ba wa ki a to mọ ohun ti o n ṣẹlẹ, a o si ri wipe awọn nkan rere ti a fẹ gbeṣe ko jẹ ṣiṣẹ titi ọdun yi fi lọ.

Ọlọrun nikan ni o wa mọ iyẹ ilẹ ti o ti ṣu ba wa sẹyin, ti o si ti fi wa silẹ pẹlu awọn ero ati ala rere ti ko wa si imuṣẹ. Alẹ ọdun eyi naa yoo tun wa lẹ mọ wa lọwọ ati fi wa silẹ pẹlu awọn ero rere ti ko jẹ mimuṣẹ, ti a ko ba tete bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati jẹ ki wọn di mimuṣẹ. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Jakọbu, lẹyin igba ti o ti sin Labani fun ọdun melokan, ji lowurọ ọjọ kan lati ri wipe oun ko i ti ma ṣe ohunkohun fun ara rẹ ati ẹbi rẹ ti o n gbooro si. Gbogbo nkan ti o n ṣe ko ju ki o ṣiṣẹ fun ibatan oun ana rẹ lọ, ki o jẹ ati ki o mu ohun yowu ti o ba gbe le e lọwọ, ki o si tun bi ọmọ jọ.

Ṣugbọn ti ọkunrin yi ba wa binu si lọjọ kan nkọ, ti o si tun pinnu lati le e danu? Bawo ni yoo ṣe tẹsiwaju lati ma mojuto ebi rẹ? Tabi ti ọkunrin yi ba dede fosanlẹ, ti o si ku nkọ? Ṣe awọn ọmọ rẹ yoo pin ogun rẹ pẹlu rẹ? Ti wọn ba tilẹ pin ogun wọn pẹlu rẹ, ṣe nkan ti wọn yoo fun yoo to o lati bẹrẹ aye rẹ lakọtun ati lati tọju ẹbi nla ti o ni? Mo gbagbọ pe awọn ero wọnyi ni o n lọ ni ọkan Jakọbu ni asiko yi. Eyi si wa jẹ ki o pinnu pe ti oun ba ṣiṣẹ fun Labani pẹlu gbogbo awọn ọdun wọnni, ti oun ko si tun le mojuto ẹbi oun lalai jẹ wipe ọkunrin yi ba nawọ si oun, a jẹ wipe oun nilo lati kuro lọdọ rẹ ati lati wa nkan miran ṣe pẹlu aye oun. (Wo: Jẹ́nẹ́ṣíṣì 30:25-30)

Amọ ṣa o, Jakọbu ko gbero nikan lati kuro lọdọ Labani lati le mura fun ọjọ ọla idile rẹ, o tun gbe igbesẹ lati jẹ ki ero yi wa si imuṣẹ. Lọna wo? O fi igboya tọ Labani lọ lati sọ fun nkan ti oun ti pinnu lati ṣe. Lotitọ, Labani jẹ arakunrin iya rẹ. O si tun jẹ ana rẹ pẹlu, iyẹn baba awọn iyawo daradara rẹ mejeeji. Ṣugbọn ọrọ ọjọ ọla rẹ ati ti awọn aya ati ọmọ rẹ ni a n sọ nibiyi. Nitorina, ko fi aye gba itiju lati di i lọwọ lati ṣe nkan ti o tọ fun wọn. Lotitọ, a ko mọ bi o ti ṣe gba a ni asiko to lati ronu lori ọrọ yi ki o to gbe igbesẹ le lori. Ṣugbọn a mọ lati inu iwe mimọ pe lẹyin igba ti a bi ọmọ rẹ kọkanla, iyẹn Josẹfu, ni o sọ fun ara rẹ pe o to gẹẹ — oun nilo lati mu ero oun yi wa si imuṣẹ.

Bawo wa ni Labani ṣe tẹwọgba nkan ti Jakọbu sọ fun? Ṣe o binu si ni, ti o si sọ fun pe ko lọ ku danu? Rara o! Dipo ki o ṣe bẹyẹn, nṣe ni o bẹ ẹ pe ki o duro ti oun, ki o si sọ owo ọ̀yà rẹ. Kini idi? Idi ni pe oun funrarẹ mọ wipe oun ti n yan an jẹ lati ibẹrẹ wa ati wipe oun ko fun ni oun ti o tọ si fun iṣẹ aṣekara ti o n ṣe fun oun. Eyi, laifọrọgun, si ni ibẹrẹ iṣoriire Jakọbu, bi a ti ṣe fi han wa siwaju si ninu akọsilẹ naa. Nigba ti yoo si fi wa kuro lọdọ Labani, o ti di ọlọrọ eniyan. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 30-31)

Ti Jakọbu ko ba wa lọ ri idi fun un lati mura silẹ fun ọjọ ọla ẹbi rẹ ni asiko yi nkọ? Ṣe a ko ni le jade pẹlu ọwọ ofifo kuro ni ile Labani ni ọjọ kan? O di dandan ki a le jade kuro ni ile rẹ pẹlu ọwọ ofifo lọjọ kan. Ka tun wa sọ wipe ko gbe igbesẹ lori ero rẹ lati ṣe ohun ti o tọ fun ẹbi rẹ nkọ? Ṣe a ko si ni papa tabuku rẹ kuro ni ile Labani ni ọjọ kan? Ko fẹrẹ si ni ki o ma kan abuku jade kuro ni ile ọkunrin naa lati ọwọ awọn ọmọkunrin rẹ.

Nitorina, ni akọkọ, o ṣe pataki ki a ni ero ibi ti o yẹ ki a wa tabi nkan ti o yẹ ki o ma ṣẹlẹ laye wa ninu ọdun tuntun yi. Ṣugbọn eyi ko to. A tun gbọdọ bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ lati ma fi igboya gbe awọn igbesẹ ti o tọ lati mu ki erongba wa jẹ mimuṣẹ, bi o tilẹ jẹ wipe eyi le bi awọn kan ninu. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe ainitẹsiwaju tabi abuku ni a o fi ṣe ere jẹ ninu ọdun naa. Adura mi wa ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri ibi gbogbo ninu aye rẹ ti o ti yẹ fun igbega ati ti o ti yẹ ki o gbe igbesẹ fun ọjọ ọla ti o logo, ki O si tun ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati gbe igbesẹ ti o tọ lati jẹ ki awọn nkan wọnyi di mimuṣẹ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Sọ ọ́ dí mímúṣẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 14, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 37 Read More »

Ìhà yówù tí wọ́n le kọ sí ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 07, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 36

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọdun tuntun yi, iyẹn ọdun 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun mu wa si imuṣẹ ohun rere gbogbo ti O ni lọkan fun ọ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Pataki julọ, o yẹ ki a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun anfaani lati ri ọdun tuntun yi. Awọn kan wa ti o wu wọn lati ri ọdun naa ṣugbọn ti wọn ko si ni ibi mọ ni oni yi. Eyi ko si waye nitoripe awọn ni o buruju ni aarin awọn eniyan. O le jẹ wipe nitoripe asiko wọn ti to ni tabi nitoripe Satani ṣe aṣeyọri lati jẹ ki wọn ku siwaju asiko wọn tabi ki o jẹ wipe wọn ṣi ilẹkun aye wọn silẹ fun idajọ Ọlọrun nitoripe wọn fi oore-ọfẹ rẹ lori aye wọn ṣofo. Ohun yowu ki o jẹ, nkan ti o han kedere nipe a wa laye lati ri ọdun tuntun yi nitoripe Ọlọrun yan lati fi oju aanu rẹ wo wa ati lati fun wa ni asiko si lati gbe igbe aye ti yoo mu iyin wa fun un. Eyi si to gẹgẹ bi idi fun wa lati fi imoore wa han si i.

Wayi o, ọrọ iyanju mi si ọ, bi a ti ṣe n tẹsiwaju ninu irinajo wa sinu ọdun tuntun yi, ni pe ki o fi ara rẹ jin lati ṣe iṣẹ rere yowu ti Ọlọrun ba yan fun ọ lati ṣe, laifi ti iha yowu ti awọn ti o wa ni ayika rẹ le kọ si ọ ati si ohun ti o n ṣe ṣe. Kini idi? Idi ni pe nipa ṣiṣe ohun rere gbogbo ti O fẹ ki O ṣe gẹgẹ bi O ti ṣe fẹ ki O ṣe ni ogo re ṣe le farahan lẹkunrẹrẹ nipasẹ nkan ti o ṣe. Igba naa si tun ni iwọ naa yoo le ri ere ohun ti o ṣe gba lẹkunrẹrẹ.

Fun apẹẹrẹ, lẹyin igba ti Noa ti pari iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun lati kan ọkọ ni ojo ti o pa aye igba rẹ run to rọ. Lẹyin igba yi naa si ni a to ya oun ati idile rẹ ya iwa ika ti o ti sọ aye igba naa di ibi ti o lewu lati gbe. Ṣugbọn, Noa nilo lati kan ọkọ naa ni ibamu pẹlu aṣẹ ti Ọlọrun ti fun un. Aijẹbẹ, bi o tilẹ jẹ wipe oun ati ẹbi rẹ wọ inu rẹ, wọn ko ba ma ti di ẹni igbala rara. Nitorina, ṣiṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ko to lati ni iriri ogo, igbega ati igbala rẹ. A tun nilo lati ṣe ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, a le ma ri ere gba rara fun iṣẹ yowu ti a ba ṣe fun. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 6-7)

Lafikun, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lẹyin igba ti Mose pari iṣẹ kikan agọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe sọ fun pe ki o kan an, ni ogo Ọlọrun to sọkalẹ si ori rẹ. Nitorina, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe idi ti o ko ṣe ti ni iriri ogo Ọlọrun ni awọn abala aye rẹ kan ni wipe o ko i ti ṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe ki ogo naa ba le farahan tabi pe o ko ma ṣe awọn nkan ti O fẹ ki oṣe ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ti o ba wa gbajumọ ohun ti O fẹ ki o ṣe ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, o di dandan ki o ri ifarahan ogo ti o yẹ ki o tẹle ṣiṣe bẹ ẹ lẹkunrẹrẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 40)

Amọ ṣa o, a tun gbọdọ fi si ọkan pe irẹwẹsi ti ko ni jẹ ki a ṣe iṣẹ ti Ọlọrun fun wa, ki a si tun pari rẹ, le wa si ọkan wa lati ọdọ awọn ti o wa ni ayika wa. Fun apẹrẹ, aigbagbọ tabi inunibini wọn le fa irẹwẹsi si wa ni ọkan. Ranti wipe nigba ti Jesu lọ si ilu abinibi rẹ ko le ṣe iṣẹ iyanu pupọ ni aarin awọn eniyan rẹ nitori aigbagbọ ati inunibini wọn. Bibeli tilẹ sọ wipe ẹnu ya a gidigidi nitori aigbagbọ wọn. Ṣugbọn ṣe O wa jẹ ki eyi fa irẹwẹsi si lọkan, ki o si ma jẹ ki O tẹsiwaju lati ma ṣe iṣẹ ti Ọlọrun fun bi? Rara! Dipo bẹẹ, nṣe ni O tẹsiwaju lati ma lọ kaakiri lati kọni ati lati woni ṣan lati ibikan de ibomiran. Idi si ni pe O mọ wipe Oun gbọdọ pari iṣẹ ti Ọlọrun fun un, yala awọn eniyan tẹwọgba ati gbagbọ ninu rẹ tabi wọn ko ṣe bẹ ẹ. (Wo: Máàkù 6:1-6)

Yatọ si inunibini tabi aigbagbọ awọn eniyan, aimore wọn naa le tun fẹ fi irẹwẹsi si ọkan wa, ki o si tun di wa lọwọ lati ṣe ati lati pari awọn iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun wa. Fun apẹrẹ, ni asiko kan, ọkan ṣoṣo lara awọn adẹtẹ mẹwa ti Jesu wosan ni o pada wa lati dupẹ lọwọ rẹ. O si ya a lẹnu pe awọn mẹsan yoku ko yọju rara lati kan sọ wipe, “Ẹ ma ṣe, ọgbẹni.” Amọ ṣe O jẹ ki eyi bu omi tutu si lọkan, ki o si di i lọwọ lati ma wo awọn miran ti o tọ ọ wa san bi? Rara! Kini idi? Idi ni pe O mọ wipe ẹni ti yoo pada dupẹ lọwọ Oun fun ohun gbogbo ti Oun n ṣe ni ẹni ti o ran oun niṣẹ, iyẹn Ọlọrun. (Wo: Lúùkù 17:11-19)

Nibakanna, bi awọn eniyan tilẹ kọ wa silẹ, ti wọn n bu wa tabi ti wọn kọ lati mọ riri ohun ti Ọlọrun n tipasẹ wa ṣe lọdun yi, a ko gbọdọ ba ọkan jẹ, ki a si pa iṣẹ rẹ tabi igbe aye ododo ti. Dipo eyi, nṣe ni a gbọdọ pinnu lọkan wa lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati ṣe ohun gbogbo ti O fẹ ki a ṣe ninu ọdun yi ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ fun wa, iha yowu ti awọn eniyan le kọ si wa. Nipa ṣiṣe bayi, Oun yoo le mu ifẹ rẹ ṣẹ lẹkunrẹrẹ nipasẹ wa ati wipe awa naa yoo le wa ni ipo ti yoo fi le pin wa lere. Adura mi ni pe ki o gba okun lati rin ni ibamu pẹlu awọn ọrọ wọnyi ni gbigbe igbe aye rẹ fun Ọlọrun ati ni sisin in ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

A kun ọdun tuntun o.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìhà yówù tí wọ́n le kọ sí ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 07, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 36 Read More »

Ó ti lọ ṣíwájú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 31, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 35

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọjọ Isinmi ti o kẹyin ọdun yi, eyi ti o tun jẹ ọjọ naa ti o pari ọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu ayọ ati alaafia ni gbogbo ọjọ naa ati bi a ti ṣe n sọda sinu ọdun tuntun, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe fẹ wọ inu ọdun tuntun lọ, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu diẹ lara awọn ọrọ Mose si awọn ọmọ Isiraẹli, iyẹn bi wọn ti ṣe fẹ kọja lọ sinu ilẹ ileri, ti o sọ wipe:

“Oluwa Ọlọrun rẹ funra rẹ ni yoo rekọja fun ọ. Yoo pa awọn orilẹ ede yii run niwaju u rẹ, iwọ yoo si mu ini ilẹ wọn, Josua naa yoo rekọja fun ọ, bi Oluwa ti sọ.” (Deutaronomi 31:3)

Tani yoo rẹkọja lọ siwaju awọn ọmọ Isiraẹli wọnyi si ori ilẹ ti wọn fẹ gba? Akọkọ, Oluwa Ọlọrun wọn funrarẹ ni yoo rekọja siwaju wọn lọ. Ki si ni idi? Oun naa ni lati mojuto ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o le fẹ di wọn lọwọ lati wọ ilẹ naa ati lati gba a fun iṣoriire ati igbadun wọn. Nitorina, bi wọn ko tilẹ mọ gbogbo idojukọ ati anfaani ti wọn yoo ba pade ni ilẹ naa, wọn le fi igboya wọ inu rẹ, pẹlu imọ wipe Ọlọrun ti wa nibẹ ṣaaju wọn lati mojuto ohun gbogbo lati ṣiṣẹ fun rere wọn. Bi o si ṣe ri gẹlẹ naa niyẹn. Wọn fi igboya wọ ilẹ naa lọ, wọn si gba a, fun ogo Ọlọrun ati fun igbadun wọn.

Nibakanna, niwọn igba ti o jẹ wipe Ọlọrun kanna ti O lọ siwaju awọn ọmọ Isiraẹli yi lati gba ilẹ ti o n ṣan fun wara ati fun oyin fun wọn ni Ọlọrun ti awa naa, nṣe ni o yẹ ki a fi ọkan wa balẹ, pẹlu imọ wipe O ti rekọja siwaju wa sinu ọdun tuntun ti a fẹ wọ inu rẹ lọ fun wa. Ki si ni idi ti O ṣe rekọja sinu rẹ ṣiwaju wa? Oun naa ni lati ri pe ko si ohunkohun ti yoo di wa lọwọ lati gba ati lati jẹ igbadun ohun rere gbogbo ti O ti gbin sinu ọdun naa fun wa.

Nitorina, ẹ jẹ ki a gbe ibẹru yowu ti a le ni nipa ọdun tuntun ti a n wọ inu rẹ lọ ju silẹ, ki a si fi igboya wọ inu rẹ lọ. Idi si ni pe yoo jẹ ọdun ti o logo ju awọn ọdun tatẹyinwa lọ fun wa ati fun awọn ẹbi wa. Yoo jẹ ọdun ninu eyi ti Ọlọrun yoo jẹ ki ohun rere gbogbo ti O ti gbin sinu aye wa fun iṣoriire wa farahan. Bẹẹ si ni yoo jẹ ọdun ninu eyi ti yoo dari wa lati gba ati lati jẹ igbadun awọn nkan ti o dara julọ ti O ti gbin si ilẹ wa fun wa. A kan nilo lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu rẹ ni. O si di dandan ki a jẹgbadun ohun gbogbo ti O ni ni ipamọ fun wa.

Siwaju si, gẹgẹ bi Mose ti ṣe fi han awọn ọmọ Isiraẹli yẹn, ẹnikan naa tun wa ti yoo rekọja siwaju wọn lọ si inu ilẹ ileri naa. Ẹni naa ni Joṣua. Ta wa ni Joṣua? Joṣua ni ẹni naa ti Ọlọrun yan, ti O si tun ṣe yẹ lati dari wọn lati gba ilẹ naa ti O fẹ fun wọn. Eyi tunmọ si pe oun ni aṣoju tabi iranṣẹ Ọlọrun ti a yan lati ran gbogbo wọn lọwọ titi wọn yo fi fi ẹṣẹ mulẹ ni ilẹ naa. Ṣe o wa ṣe iṣẹ rẹ daradara tabi ko ṣe e? O ṣe daradara. O dari wọn, O si tun jagun-ṣẹgun pẹlu wọn titi ọkọọkan ninu wọn fi gba ini tirẹ, ti o si bẹrẹ si ni gbe ibẹ.

Nibakanna, mo fẹ ki o mọ pe Ọlọrun ti yan, O si tun ti ran awọn oluranlọwọ ṣiwaju wa lọ sinu ọdun tuntun ti a n wọ inu rẹ lọ. Ki ni idi? Idi naa ni ki wọn ba le ba wa ṣiṣẹ, ki wọn si tun ran wọn lọwọ titi gbogbo ete rẹ ni rere fun aye wa yoo fi wa si imuṣẹ. A kan nilo lati da ọkọọkan awọn oluranlọwọ yi mọ, ki a si tun fi irẹlẹ fi aye gba wọn lati ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe ninu aye wa ati fun aye wa. Ṣiṣe iṣẹ wọn, lotitọ, ṣeeṣe ki o ti wa kuro nibi ti a joko tẹtẹrẹ si. Ṣugbọn ti a ba fọwọsowọpọ pẹlu wọn, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, wiwa wọn ninu aye wọn di dandan ki o yọri si ifarahan ogo Ọlọrun ninu ọdun naa.

Nitorina, fi oju ṣọna fun ọdun tuntun alarinrin, bi o ti wu ki nkan ri fun ọ lọwọlọwọ yi. Adura mi ni pe ki a fun ọkan rẹ ni okun lati fọwọsowọpọ pẹlu Ọlọrun ati pẹlu gbogbo awọn ti O le e fẹ lo fun ọ ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

A kú ìmúra ọdún tuntun.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ó ti lọ ṣíwájú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 31, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 35 Read More »

Ìmọrírì Ọlọ́run àti ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 24, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 34

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin ọdun 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu rẹ ni aṣepe, ki O si tun kun ọkan rẹ ati ile rẹ pẹlu ayọ ati alaafia ninu ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n wọ awọn ọjọ ti o kẹyin ọdun yi, o ṣe pataki ki o fi tinutinu fi imọriri han si Ọlọrun ati si gbogbo awọn ti O ti lo fun igbega, itura ati aabo rẹ ninu ọdun naa. Ki ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? Akọkọ, idi ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma fi gbogbo igba mọ riri rẹ fun ohun ti O n ṣe fun wa ati lati mọ riri awọn ti O n lo fun wa ni ọna kan tabi omiran.

Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun wa nipa mimọ riri Ọlọrun: “Ẹ maa dupẹ nigba gbogbo ipokipo ti o wu ki ẹ wa; nitoti pe, eyi ni ifẹ Ọlọrun fun yin ninu Kirisiti Jesu nitootọ.” (1Tẹsalóníkà 5:18) Njẹ o ri bayẹn? Ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma fi ọpẹ fun un ni ipokipo ti a ba. Bawo si ni a ṣe le ṣe eyi? A le ṣe e nipa ruru ẹbọ iyin si I (Hébérù 13:15). A si tun le ṣe e nipa fifi fun un lati ara nkan ini wa (Ìwé Òwe 3:9).

Siwaju si, Pọọlu so eyi fun wa nipa mimo riri awọn ti o n dari wa ninu awọn ijọ wa: “Awọn alagba ti o ṣe akoso daradara ni ki a ka yẹ si ọla ilọpo meji, pẹlu pẹlu awọn ti o ṣe laalaa ni ọrọ ati ni kikọni.” (1Tímótì 5:17) Njẹ o ri bayẹn? Awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ yẹ fun ọla ilọpo meji. Eyi jasi pe wọn yẹ ni ẹni ti o yẹ ki a mo riri rẹ pẹlu ọrọ ẹnu wa ati pẹlu awọn nkan ini wa. Idi si ni pe nkan ti wọn n ṣe n mu aye wa tẹsiwaju, o si tun n pa ọkan wa mọ.

Amọ ṣa o, ko ki i ṣe kiki awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ Ọlọrun nikan ni ọlọ ilọpo meji tọ si. Awọn miran ti Ọlọrun tun ti lo ni ọna ara ọtọ lati mu aye wa ni itẹsiwaju tabi lati pa wọn mọ ninu ọdun yi naa yẹ ni ẹni ti a n bu ọla ilọpo meji fun. Ọrọ ti wọn naa kọja ki a kan fi ẹnu bu ọla fun wọn; o tun yẹ ki ẹbun diẹ ti ọdọ wa jade si wọn. Eyi ko si ni i ṣe pẹlu ki a ra ẹbun olowo nla fun wọn, bi ko tilẹ si ohun ti o buru ninu ki a ṣe eyi ti owo rẹ ba wa. Dipo bẹẹ, o ni i ṣe pẹlu ki a ba wọn lo pẹlu ọkan imọriri otitọ.

Wayi o, ti a ba wa kọ lati fi otitọ inu ati tọkantọkan mọ riri Ọlọrun ati awọn ti O ti lo lati bukun fun wa ni awọn ọna ti o farahan, akọkọ, nṣe ni a n ti ilẹkun lati ri gba si lọwọ wọn mọ ara wa. Yatọ si iyẹn, o ṣeeṣe ki a tipasẹ eyi ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun. Fun apẹrẹ, nigba ti Nabali kọ lati mọ riri Dafidi ati awọn eniyan rẹ fun ohun ti Ọlọrun lo wọn lati ṣe fun awọn eniyan rẹ, Ọlọrun da si ọrọ naa lati ṣe idajọ rẹ. Eyi si yọri si iku aitọjọ fun un. (Wo: 1Sámúẹ́lì 25)

Siwaju si, Jesu sọ owe ti o da lori okunrin ọlọrọ kan ti ilẹ rẹ so eso ọpọlọpọ ati bi ọkunrin naa ko ṣe ronu rara lati dupẹ lọwọ Ọlọrun tabi lati bu ọla fun pẹlu ohunkohun lati ara ere rẹ. Gbogbo ọrọ rẹ ko kọja bi yoo ṣe jẹgbadun aye si ati bi yoo ti ṣe fẹ awọn ibi ti o n ko eso ilẹ rẹ si. Nitorina, Ọlọrun ṣe idajọ rẹ gẹgẹ bi ahun, O si mu ẹmi rẹ kuro ni asiko iṣoriire rẹ. Oluwa wa wa pari owe yi nipa sisọ wipe bayi gẹlẹ ni yoo ti ṣe ri fun olukuluku ẹni naa ti o n to ọrọ jọ fun ara rẹ ṣugbọn ti ko lawọ si Ọlọrun. (Wo: Lúùkù 12:16-21)

Adura mi wa ni pe idajọ Ọlọrun ko ni wa si ori rẹ nitori ikuna rẹ lati mọ riri rẹ ati lati mọ riri awọn miran ti imọriri tọ si lati ọdọ rẹ ni ọna ti o peye. Ṣugbọn iwọ naa wa gbọdọ ronu jiinlẹ lori awọn nkan ti O ti ṣe fun ọ ni ọdun yi ati lori ọna ti o o gba mọ riri rẹ. Yatọ si eyi, tun ronu jinlẹ lori gbogbo awọn ti O ti lo fun iṣoriire ati ibalẹ-ọkan rẹ lọdun yi ati ọna ti o o gba mọ riri wọn, paapaa-julọ ni asiko ọdun yi. Mo si gbadura pe ki a tọ ọkan rẹ lati ṣe ohun ti o tọ lori awọn nkan wọnyi, ki a si tun kun apo rẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.

Ku ifojusọna fun ọdun Keresimesi!

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìmọrírì Ọlọ́run àti ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 24, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 34 Read More »

Má ṣe jẹ́ ẹlẹ́gàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 17, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 33

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun mu ki inu iwọ ati ile rẹ dun lotitọ ati ni gbogbo ọna ninu ọsẹ tuntun yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn ọna lati ma fi igba gbogbo ni iriri idunnu otitọ lati ọwọ Ọlọrun ni ki a ma fi gbogbo igba bọwọ fun ohunkohun ti O ba sọ fun wa, bi O tilẹ jẹ pe ohun ti O sọ ko mọgbọn wa loju wa. Bibeli sọ wipe omugọ Ọlọrun gbọn ju ọgbọn eniyan lọ ati wipe ailera rẹ ni agbara ju agbara eniyan lọ (1Kọ́ríntì 1:25). Nitorina, bi ọkan wa ko ba tilẹ le gbe nkan ti O n sọ fun wa nipa ara rẹ tabi nipa aye wa, nkan ti yoo jẹ iwa ọgbọn fun wa ni ki a tẹwọ gba a, ki a si gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu rẹ.

O wa ṣeni laanu pe, nitori ailoye nkan wọnyi, ọpọ ni o ma bu ẹnu atẹ lu ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun wọn ti ọpọlọ wọn ko ba le e gbe. Nitorina, wọn ko le ri ere igbọran si ọrọ rẹ jẹ. Yatọ si iyẹn, wọn tilẹ tun le padanu aye wọn tabi awọn nkan miran ti o ṣe pataki si wọn nitori ikẹgan wọn.

Fun apẹrẹ, ninu iwe Awọn ọba keji, ọri ikẹfa ati ikeje, a ri itan iransẹ ọba Isiraẹli kan ti o kẹgan ọrọ Oluwa ati nkan ti o ṣẹlẹ si nitori ikẹgan rẹ. Bi akọsilẹ naa ti lọ, iyan buruku kan ti o n ti awọn eniyan lati ma pa awọn ọmọ ara wọn jẹ ni o mu ni ilẹ Isiraẹli. Ni asiko ti awọn eniyan wa bẹrẹ si ni pa awọn ọmọ wọn jẹ yi ni oba ṣẹṣẹ wa ranti pe Wolii Eliṣa ma wa ni ilẹ naa ati wipe agba rẹ ko yẹ ki o wa ni ọja, ki ori ọmọ tuntun si ma ti oju rẹ wọ. Eyi si wa farapẹ iha ti awọn adari ijọba wa, paapaa-julọ ni orilẹ-ede wa, ma n kọ si nkan. Awọn adari ti wọn ma n duro ki nkan kọkọ bajẹ naa ki wọn to gbe igbesẹ lori rẹ ni. Nitorina, ti ko ba ṣe wipe iṣoro ọpọ eniyan ba da iṣoro wọn, ti ko ba jẹ wipe iṣoro ọpọ ba balẹ si ẹnu ọna wọn, wọn ko ni kọ iha ti o nitunmọ kankan si ibalẹ-ọkan awọn eniyan wọn.

Ni kukuru, nigba ti ọba yi pada taji kuro loju oorun rẹ, o ran oniṣẹ si Wolii Eliṣa, Ọlọrun si gba ẹnu wolii naa sọrọ si ilẹ naa, wipe, “Gbọ ọrọ OLUWA. Eyi ni ohun ti OLUWA sọ: Ni asiko yii ni ọla, a o ta oṣuwọn iyẹfun kikuna kan ni ṣekeli kan ati meji oṣuwọn ọka fun ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria.” (2Àwọn Ọba 7:1) Ti a ba fi oṣuwọn ti ode oni wo o, ṣekeli kan n lọ si bi igba naira o le mejila nigba ti oṣuwọn iyẹfun kan yoo si fẹrẹ gba to lítà omi meje ati aabọ. Nitorina, nṣe ni o dabi ki a sọ pe oṣuwọn (kongo) meji iyẹfun ko ni ju igba naira le ni aadọta lọ.

Njẹ iyẹn ko wa dabi àsé ati nkan ti ko le lailai ṣeeṣe leti? O da bẹẹ! Ṣugbọn ni asiko ti a n sọ yi, Ọlọrun sọrọ nipasẹ wolii rẹ, Eliṣa, wipe Oun yoo mu iṣẹlẹ kan waye ni aarin ọjọ kan ti yoo jẹ ki owo ounjẹ walẹ ni Samaria to bẹẹ gẹẹ ti ebi yoo fi poora ninu ilu naa. Boya ọba yii wa gba ọrọ yi gbọ tabi ko gba a gbọ, a ko le sọ. Idi si ni pe ko sọ nkankan le lori. Nṣe ni o kan ṣaa da a le, ti o si n woye bi ọrọ ti Ọlọrun sọ yoo ti ṣe wa si imuṣẹ.

Ṣugbọn a wa ri iransẹ kan ti o sunmọ ọba yi pẹkipẹki ti o ri ara rẹ bi ẹni ti o gbọdọ bu ẹnu atẹ lu nkan ti Oluwa sọ. Kini idi? O ro wipe ọrọ ti ko mọgbọn wa ni. Ni iwoye tirẹ, ti a ba tilẹ ṣi ferese ọrun silẹ, ti ounjẹ si bẹrẹ si ni rọ jade lati ibẹ bi ojo, nkan ti Ọlọrun sọ yi ko le e waye. Ki idi ti o fi sọrọ bi eyi? O sọrọ bi eyi nitoripe nkan ti Oluwa sọ silẹ yi ko ni itunmọ kankan ti awọn ti o mọ nipa eto iṣuna le tẹwọgba. Nitorina, o sọ ọ di ọrọ yẹyẹ. Nitoripe o si sọ ọ di ọrọ yẹyẹ, Oluwa ṣe idajọ ikẹgan rẹ lati ipasẹ Eliṣa. A sọ fun wipe a o jẹ ki oju rẹ ri ohun daradara ti Ọlọrun ti ṣeto lati ṣe fun awọn eniyan rẹ, ṣugbọn a ko ni gba ẹnu rẹ laaye lati tọ ọ wo. Bẹẹ gẹgẹ ni nkan si ṣe ri fun. (Wo: 2Àwọn Ọba)

Wayi o, ni aarin ọjọ melokan yii, mo ti ba awọn eniyan takurọsọ ti wọn gbagbọ pe ko si ohun ti Ọlọrun le ṣe fun orilẹ-ede wa ti o le jẹ ki nkan pada si bi wọn ti ṣe ri ni ọpọ ọdun sẹyin. Eyi jasi pe irufẹ awọn wọnyi, bi wọn tilẹ jẹ Kirisitiẹni, ko gbagbọ ninu adura ti a n gba fun orilẹ-ede wa. Iyẹn ni idi fun ikẹgan wọn. Amọ, a ti ri wipe nkan ti o lewu ni lati kẹgan ọrọ Oluwa, yala ọrọ ti O sọ nipa ara rẹ, nipa wa, nipa awọn miran tabi nipa ohunkohun. Ti o ko ba tilẹ gba ohun ti O sọ gbọ, jẹ ki aigbagbọ rẹ mọ ni ọdọ rẹ. Ma ṣe jẹ ki o tan kalẹ de ọdọ awọn miran tabi ki o ma fi ọrọ rẹ ṣẹ̀fẹ̀. Idi ni pe awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun ṣẹfẹ n fi ara wọn si abẹ idajọ rẹ laimọ (Sáàmù 1:1; 2Pétérù 3:3-9). Ti iru wọn ba wa lọ pade eniyan bi Wolii Elija tabi Apọsiteli Peteru, ti yoo mu ki idajọ yi wa si imuṣẹ lori wọn, wọn le ma gbe ile-aye royin ohun ti o ṣẹlẹ. Nitorina, ṣọ ara rẹ. Njẹ ki Oluwa rere ma fi igba gbogbo jẹ ki ọkan rẹ wa ni irẹlẹ niwaju rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe jẹ́ ẹlẹ́gàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 17, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 33 Read More »

Àyẹ́sí tí ó kọjá bẹ́ẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 10, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 32

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu ti o kẹyin ọdun yi, oṣu Ọ̀pẹ 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun dari rẹ lati ṣe ohun rere gbogbo ti o yẹ ki o ṣe lọdun yi, ki awọn èrè rẹ ti o yẹ ki o jẹ tirẹ naa ba a le jẹ tirẹ lálàì si idaduro, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, niwọn ọjọ diẹ ki a to kan Jesu mọ agbelebu, a ṣeto apejẹ kan lati fi yẹ ẹ si ni Bẹtani, iyẹn ni ibi ti o gbe ji Laṣaru dide kuro ninu oku. Maria, arabinrin Laṣaru, si ṣe amulo asiko yi lati yẹ ẹ si ni ọna ti ko si ẹni ti o reti ati ni ọna ti o kọja bẹ ẹ. Ki wa ni o ṣe? Akọsilẹ rẹ ni yiL

“Nigba naa ni Maria mu ororo ikunra nadi, osuwọn lita kan, ailabula, olowo iyebiye, o si n fi kun Jesu ni ẹṣẹ, o si n fi irun ori rẹ nu ẹsẹ rẹ nu. Ile si kun fu oorun ikunra naa. Nigba naa ni ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin rẹ, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni ti yoo fi I han, wi pe, “Eeṣe ti a ko ta ororo ikunra yii ni ọọdunrin owo idẹ ki a si fi fun awọn talaka?” Ṣugbọn o wi eyi, ki i ṣe nitori ti o naani awọn talaka; ṣugbọn nitori ti o jẹ ole, oun ni o ni apo, a si maa ji ohun ti a fi sinu rẹ lati fi ran ara rẹ lọwọ. Nigba naa ni Jesu wi pe, “Ẹ fi i ṣilẹ, o ṣe e silẹ de ọjọ isinku mi. Nigba gbogbo ni ẹyin sa a ni talaka pẹlu yinl; ṣugbọn emi ni ẹ ko ni nigba gbogbo.” (Jòhánù 12:3-8)

Njẹ o ri bayẹn? Lati yẹ Jesu si, arabinrin yi da odidi igo ororo ikunra kan ti o to owó ọ̀yà ọdun kan alagbaṣe si ni ẹṣẹ. Igba wo ni o bẹrẹ si ni gbero nkan yi? A ko mọ. Bawo si ni o ti ṣe ri irufẹ igo kan ororo ikunra olowo iyebiye yi? A ko mọ. Ṣugbọn a mọ wipe nkan ti o ṣe ni ọjọ ti a n wi yi ko jẹ itẹwọgba si ọpọ awọn ti o ri i. Kini idi? O kọja bẹ ẹ!

Ki a sọ otitọ, o kọja bẹ ki a fi owo oṣu ọdun kan ra igo ororo ikunra kan, ki a si tun wa fi gbogbo ororo ikunra naa ṣofo sori atẹlẹsẹ ẹnikan laarin iṣẹju melokan. Ọpọ ni yoo tilẹ ka si iwa apa lati lo irufẹ ororo ikunra yi tan ni arin oṣu melokan. Ṣugbọn Maria ko lo o tan ni aarin oṣu melokan bikoṣe ni aarin iṣẹju melokan. O si ṣe eyi lalai tilẹ bikita tabi lọra. O ṣe e tayọtayọ, o si tun n fi irun ori rẹ nu atẹlẹsẹ Oluwa, bi o ti n tu ororo ikunra naa si ori wọn.

Ki wa lo fa ti o fi ṣe bẹ ẹ? Idi ti o fi ṣe eyi kọja nkan ti a tilẹ le ro. Amọ daju-ṣaka ni pe Jesu tobi lọwọ rẹ debi wipe o fẹ ṣe ayẹsi rẹ lọna ti o fi ma jẹ wipe ẹnikẹni ti o ba gbọ nkan ti o ṣe di dandan ki o sọ wipe, “Emi wa leyun un? Eyun un ko wa pọju bi?” Nkan ti o si ṣẹlẹ gẹlẹ ni eyi. Gbogbo awọn ti o ri nkan ti o ṣe ni o n kọ ha, pe, “O to gẹ ẹ! Ki ni oun n ṣe? Eyi o wa pọju?” Judasi Isikarioti tilẹ gboju agan si, ti o si ọ wipe nṣe ni ko ba ti fun Oluwa ni ororo ikunra naa, ki awọn ba a le ta a, ki wọn si fun awọn talaka ni owo rẹ.

Amọ ṣa o, si iyalẹnu gbogbo wọn, Oluwa ko da Maria lẹkun tabi ba a wi fun nkan ti o ṣe. Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O sọ wipe o ṣe nkan ti o ṣe nipasẹ idari Ẹmi ni. O tilẹ fi kun un pe Ọlọrun gangan ni O jẹ ki o fi ororo ikunra naa pamọ di asiko naa, lati pese rẹ fun isinkun rẹ. Eyi jasi pe, ti ko ba lọ ṣe ayẹsi rẹ ni ọna ti o gba ṣe e ni ọjọ naa ni, anfaani lati ṣe e ko ba fo o ru titi lailai ni, nitoripe ni asiko yi kanna ni a mu un, ti a si pa a. Ṣugbọn nitoripe o ṣe e, gẹgẹ bi Matiu ati Maaku ti ṣe kọ silẹ ninu awọn iwe iyinrere wọn, Oluwa sọ wipe nibikibi ti wọn ba n ti polongo iyinrere ni wọn yoo ti ma sọ ohun ti o ṣe n iranti rẹ. Eyi ni mo si n ṣe nibiyi. (Wo: Mátíù 26:13; Máàkù 14:9)

Ni kukuru, ki ni koko itan yi? Koko akọkọ ni pe o yẹ ki a ma ni erongba lati ṣe ayẹsi Jesu ni ọna ti o kọja bẹ ẹ, ni ọna ti yoo jẹ ki awọn ti o wa ni ayika wa ma fẹ woye pe boya awa nikan ni O dara si ni. Idi si ni pe o tọ si i. Koko ekeji ni pe o yẹ ki a kọ bi a ti ṣe n gbadura si Ọlọrun lati ma dari wa lati ṣe idamọ gbogbo anfaani lati yẹ Oluwa si ti ko yẹ ki a padanu laye yi ati lati jẹ ki a ma wa ni imurasilẹ lati lo awọn anfaani naa. Aijẹbẹ, a o padanu awọn ere ara-ọtọ ti o yẹ ki o jẹ tiwa nikan.

Wayi o, boya Ẹmi Ọlọrun ti n sọ fun ọ pe opin-ọdun yi n fun ọ ni anfaani lati ṣe nkan àrà-ọ̀tà, nkan ti o kọja afẹnusọ lati yẹ Oluwa si. Yoo jẹ igbesẹ ọlọgbọn fun ọ lati gbọ nkan ti O n sọ ati lati ṣe ni kankan. Aijẹbẹ, anfani lati ṣe bẹ ẹ le ma yọju mọ lailai. Ti eyi ba si wa ṣẹlẹ, a jẹ wipe ere ti o yẹ ki o jẹ tirẹ naa ko ni yọju lailai. Adura mi ni pe gẹgẹ bi Maria, Ọba Solomọni ati Banaba ko ti ṣe padanu anfani ti wọn ni lati yẹ Ọlọrun si lọna ti o kọja afẹnusọ, ti wọn si gba ere ti ko wọpọ lati ọwọ rẹ, iwọ naa ko ni padanu tirẹ. Amin. (Wo: 1Àwọn Ọba 3:4-15; Ìṣe Àpọ́sítélì 4:36-37)

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àyẹ́sí tí ó kọjá bẹ́ẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 10, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 32 Read More »

Ìbá má ṣe pé Olúwa wà níhà wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 26, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 31

Olufẹ: ki oore–ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsu ti o kẹyin ọdun yi, iyẹn oṣu Ọ̀pẹ. Adura mi si ni pe ki oṣu naa jẹ eyi ti ayọ iwọ ati ile rẹ yoo kun akunwọsilẹ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

O yẹ ki a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe fun wa ni anfaani lati ri oṣu ti o kẹyin ọdun yi. Nitootọ, ọdun yi jẹ eyi ti o le gidigidi fun orilẹ-ede wa lapaapọ. O si ṣeeṣe ki o jẹ eyi ti o le gidigidi fun iwọ ati idile rẹ naa. Sibẹsibẹ, Ọlọrun ko jẹ ki gbogbo awọn iṣoro odun naa gbe wa mi. O si yẹ ki a dupẹ lọwọ rẹ fun eyi.

Wayi o, Saamu Dafidi kan wa ti mo woye pe o tọ fun wa lati ka ati lati ṣe asaro le lori ni irufẹ asiko yi. Eyi ni Saamu 124, ti o si ka bayi:

“iba ma ṣe pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa, ni ki Isiraẹli maa wi nisinsinyi; Iba ma a ṣe pe Oluwa ti o ti wa fun wa, nigba ti awọn eniyan dide si wa: Nigba naa ni wọn iba gbe wa mi laaye, nigba ti ibinu wọn ni ru si wa: Nigba naa ni omi wọn-ọn-ni iba bo wa mọlẹ, iṣan mi iba ti bori ọkan wa: Nigba naa ni agberaga omi iba bori ọkan wa. Olubunkun ni Oluwa, ti ko fi wa fun wọn bi ohun ọdẹ fun ẹyin wọn. Ọkan wa yọ bi ẹyẹ jade kuro ninu okun apẹyẹ: okun ja, awa si yọ. Iranlọwọ wa n bẹ ninu orukọ Oluwa, ti o da ọrun oun aye.” (Saamu 124)

Njẹ o ri bayẹn? Nkan ti o yẹ ki a ma sọ ni asiko yi pe idi ti awa ati awọn ti a nifẹ wọn ko ṣe ti lugbadi ibinu, ilara ati iwa ika awọn ọta ti o yiwa ka ninu ọdun yi ni pe Ọlọrun wa niha tiwa. Ti ko ba ṣe pe O wa ni iha wa ni, a ko ba ti lu igbadi erongba wọn ni ibi si wa. Eyi si ni o yẹ ki ẹri mi jẹ ni asiko yi. Oun si ni o yẹ ki ẹri ti iwọ naa jẹ ni asiko yi.

Lafikun, idi ti awọn idojukọ ti o dabi ikun omi ati omi ti o n binu ti o ti kọju ija si orilẹ-ede yi ati si iwọ naa pẹlu lọdun yi ko ṣe ti gba ọ lọ ni pe Ọlọrun wa ni iha tirẹ. Ti Ọlọrun ko ba si ni iha rẹ ni, o ṣeeṣe ki o ti di itan loni. Ṣugbọn nitori pe O n fi gbogbo igba wa pẹlu rẹ, o wa laye, o si tun wa ni ààyè tobẹ gẹẹ ti o fi le sọrọ nipa awọn nkan ti o ti la kọja. Ṣe ko wa yẹ ki o ma yin orukọ rẹ fun eyi? O yẹ.

Siwaju si, o ṣeeṣe ki o ti ba ara rẹ ni awọn ipo kan ninu ọdun yi ninu eyi ti o ti dabi ẹni pe Satani ti papa mu ọ, awọn ipo ti o ti ro wipe ko si ọna abayọ fun ọ kuro lọwọ idojuti, ìṣẹ́ tabi iku ti o n fẹju mọ ọ. Sibẹsibẹ, lọna kan tabi omiran, ikẹkun ti o mu ọ ja, o si bọ lalai fi ara pa. Tani o ro wipe o jẹ ki eyi ṣeeṣe? Ọlọrun ni. Oun ni O jẹ ki o bọ bi ẹyẹ ti ṣe n bọ ninu ikẹkun pẹyẹpẹyẹ. Oun ni ko jẹ ki o di ounjẹ fun eṣu ati awọn iranṣẹ rẹ.

Nitorina, bi o ti wu ki nkan ti o ti la kọja lọdun ti ṣe le ri, o yẹ ki o fi imore atọkanwa, eyi ti ko si lẹtan, han si Ọlọrun fun bi O ti ṣe pa ọ ma lati ri ọsu ti o kẹyin ọdun yi. Lotitọ, nkan le ma dara to bi o ti ṣe fẹ ki wọn ri ni aye rẹ ni asiko yi. O tilẹ ṣeeṣe pe awọn nkan kan ti o dara tẹlẹ ninu aye rẹ ti bajẹ, ki awọn nkan miran ti o si ti bajẹ tẹlẹ tun ti buru si. Amọ ṣa o, lakọkọ, o nílò lati ye ọ pe idi ti o ti tilẹ ṣe ri ohun daradara kankan gbeṣe tabi gbadun lọdun yi ni Ọlọrun. Lalai si rẹ, iba ma ti ṣeeṣe fun ọ lati ṣe ohunkohun, ri ohunkohun gba, ri ohunkohun jẹ tabi ri ohunkohun jẹgbadun rara ninu ọdun yi. (Wo: Oníwàásù 2:24-25; Àìsáyà 26:12; 1Tímótì 6:17)

Yatọ si iyẹn, nkan miran ti o tun ni lati yé ọ ni pe niwọn igba ti ẹmi ba si wa ninu rẹ, o si le ri didara Oluwa ni ilẹ alaaye, ti o ba le ri daju pe o ko dẹkun lati ma fi igbẹkẹle rẹ sinu rẹ ati lati ma dupẹ lọwọ rẹ. Dafidi, ninu Saamu rẹ miran, sọ wipe, “Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye.” (Saamu 27:13) Iwọ nkọ? Ṣe iwọ naa ni igbagbọ pe iwọ naa yoo ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye, ti ko si ni jẹ lẹyin igba ti o ba ku?

Ki a ma fọrọgun, emi ni igbagbọ pe emi yoo ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye, pẹlupẹlu ninu orilẹ-ede Naijeria, bi o ti wu ki nkan ti igba n sọ lasiko yi ri. Mo ni igbagbọ bi eyi nitoripe mo mọ pe Ọlọrun, Baba wa, yoo ma fi igba gbogbo wa pẹlu mi lati jẹ ki ohun gbogbo ṣiṣẹ pọ ni rere fun mi. Adura mi wa ni pe ki iwọ naa gba okun lati le ma fi igbagbọ rin pẹlu Ọlọrun lati ni iriri ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o ni laye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní oṣù Ọ̀pẹ 2023 alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìbá má ṣe pé Olúwa wà níhà wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 26, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 31 Read More »

Má dọwọ́ bò ó mọ́lẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 30

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Mo fi tayọ̀tayọ̀ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, iyẹn oṣu Belu 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o sorọ mọ abuku tabi ti o ti di orisun ikoro si ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu itan bibeli nipa Naamani, ẹni nla ni o jẹ. O jẹ ọkunrin kan ti ọba rẹ ati awọn eniyan rẹ n bu ọla fun gidigidi. Idi si ni pe, gẹgẹ bi adari ogun wọn, Ọlọrun ti lo gidigidi lati fun wọn ni iṣẹgun ti o ga lori awọn ọta wọn. (Wo: 2Awọn Ọba 5)

Amọ ṣa o, bi ọkunrin yi ṣe jẹ ẹni nla ati ọlọla eniyan to, nkankan ma jẹ orisun inira ati ibanujẹ fun oun ati idile rẹ. Nkan naa si ni pe o jẹ adẹtẹ. Ba wo lo ṣe di adẹtẹ? A ko sọ fun wa ninu bibeli. Ṣugbọn a sọ fun wa pe ẹtẹ rẹ yọ ọ lẹnu to bẹẹ gẹẹ ti o fi ṣetan lati ṣe ohunkohun, pẹlupẹlu ki o ṣe abẹwo si ọta ọba rẹ, ki o ba le yanju rẹ.

Ki si ni eyi n kọ wa? Nkan ti o n kọ wa naa ni pe ti a ba ri nkankan ti ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun tabi ti o sorọ mọ inira, ibanujẹ tabi idojuti ninu aye wa, ko yẹ ki a ma wo niran, bi o ti wu ki nkan ma a lọ deede fun wa to. Dipo eyi, a gbọdọ mojuto. O wa ṣeni laanu pe, ọpọ ni wọn n sun, ti wọn si tun n ji pẹlu awọn iwa kan tabi awọn ipo kan ti wọn wa, ti wọn si n pa aye wọn run, ti wọn ko si ṣe nkankan lori wọn. Kini idi? Wọn gbagbọ pe ọkan awọn balẹ to lati dọwọ bo ipalara ti awọn nkan wọnyi n ṣe si aye wọn.

Ṣugbọn, gẹgẹ bi ẹ̀tẹ̀ Naamani, o ko le dọwọ bo iwa tabi ipo ti o ba ara rẹ ti o n yọ kẹlẹkẹlẹ jẹ aye rẹ run titi lailai. Nigba ti o ba ya, ipalara ti nkan yi n ṣe si aye rẹ yoo han kedere si gbogbo eniyan. O wa le ti pẹ ju fun iranlọwọ yowu ti o ba ri gba lasiko naa lati le mu iyatọ ti o ni itunmọ wa. Nitorina, ma ṣe dọwọ bo ohunkohun ti o ba ti di orisun inira tabi ibanujẹ fun ọ tabi fun ẹbi rẹ. O ni lati fa a yọ si gbangba, ki o ba le jẹ amojuto.

Naamani ko dọwọ bo ẹtẹ rẹ. Idi si niyi ti ẹru ọmọdebinrin Isiraẹli ni ti a mu wa sinu ile rẹ ṣe le dari rẹ lati ri iwosan otitọ gba. Iwọ naa ko gbọdọ dọwọ bo ẹṣẹ, iwa tabi ipo yowu ti o wa ti o n jẹ aye rẹ run diẹdiẹ. Dipo bẹ, nṣe ni ki o tu laṣiri, ki o ba le ni iriri igbala otitọ kuro lọwọ rẹ.

Amọ ṣa o, wipe o ko dọwọ bo nkan ti o n fi gbogbo igba yọ ọ lẹnu ko tunmọ si pe o o ri iranwọ otitọ gba lori rẹ. Bẹẹni, ti awọn kan ninu aye rẹ ba mọ pe o wa ninu iṣoro, wọn le gbe igbesẹ lati ba ọ wa ojutu si. Amọ ojutu si iṣoro rẹ yowu ti awọn eniyan ba n dari rẹ si, ti ko si si ninu Ọlọrun, ko ki i ṣe ojutu rara. Bẹẹni, o le dabi igba ti o n ṣiṣẹ. Ṣugbọn ọna abayọ yowu si iṣoro rẹ ti ko ba wa lati ọdọ Ọlọrun di dandan ki o fa awọn iṣoro ti ko si ninu aye rẹ tẹlẹ wọ ibẹ. Nitorina, ma ṣe lọ fun un.

Inu Ọlọrun ni ọna abayọ ti a dari Naamani si wa. Nitorina, ọna abayọ ti o peye ni. Ti iwọ naa ba si kọju si Ọlọrun pẹlu ohun yowu ti o n pa ọ lara tabi ti o n jẹ ọ run, Oun yoo pese ọna abayọ ti o peye, ti yoo si yanju iṣoro rẹ patapata fun ọ. Iṣẹ tirẹ ko si ni kọja pe ki o ṣe amulo ọrọ rẹ, gẹgẹ bi Naamani ti ṣe ṣe, bi o ti wu ki o dabi ọrọ omugọ loju rẹ to. O si di dandan ki o ni awọn ẹri didara rẹ ati ifẹ rẹ ti o ga lati jẹ.

Ki o ni ọṣẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má dọwọ́ bò ó mọ́lẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 30 Read More »

Kò jìnnà sí ìjọba Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 19, 202 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 29

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia pọ si fun ọ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o jẹmọ irin rẹ pẹlu rẹ ni aṣepe, ki o ma ba kuna lati ri ati lati jẹgbadun lẹkunrẹrẹ ipin tirẹ ninu ogun ti O ti fi pamọ ni ọrun fun awọn eniyan mimọ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a ri kọ ninu Iwe Mimọ ni pe o ṣeeṣe ki a ni nkan ṣe pẹlu Jesu tabi awọn eniyan rẹ ṣugbọn ki a ma jẹ ẹni ijọba rẹ. O tilẹ ṣeeṣe fun wa lati waasu ati lati ṣe iṣẹ iyanu ni orukọ rẹ, ki a si tun ma jẹ ẹni ijọba rẹ. Fun apẹrẹ, Judasi Isikariọti jẹ ọkan lara awọn ọkunrin mejila ti o sunmọ Jesu Oluwa wa julọ ni asiko ti O wa laye yi. Gẹgẹ bi awọn yoku, oun naa waasu, o si tun ṣe oniruuru iṣẹ iyanu ni orukọ Jesu. Sibẹsibẹ, lẹyin-ọ-rẹyin, a fihan pe ko fi igba kankan jẹ alabapin ijọba Ọlọrun. Lotitọ, o sunmọ bebe ati wọ inu rẹ. Amọ ko wo inu rẹ rara. Nitorina, o padanu ọkan rẹ. (Wo: Mátíù 7:21-23 & Mátíù 10)

Siwajusi, olukọ ofin kan wa ti Jesu fi igbakanri ba ni gbolohun melokan. Nigba ti wọn si pari itakurọsọ wọn, Jesu sọ fun pe, “Iwọ ko jina si ijọba Ọlọrun.” Ṣugbọn olukọ ofin Mose ma ni ọkunrin yi jẹ. Ki lo wa fa ti Oluwa ṣe sọ fun pe nṣe ni o kan sunmọ ijọba Ọlọrun, ko i ti wọ inu rẹ? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe ọkan rẹ yẹ, ti o si tun ni lọkan lati sin Ọlọrun, ko i ti fi igbagbọ rẹ sinu Jesu gẹgẹ bi Oluwa rẹ. Kiki awọn ti o ba si wa fi igbagbọ wọn sinu rẹ gẹgẹ bi Oluwa wọn ni a o gbala, ti a o si tun ṣi ni ipo pada sinu ijọba ayeraye Ọlọrun. (Wo: Máàkù 12:28-34; Róòmù 10:9-10)

Ni afikun, a ri ninu bibeli itan ọkunrin kan ti a n pe ni Kọniliọsi. Bi o tilẹ wa jẹ wipe sọ́jà ni ọkunrin yi, Ọlọrun funrarẹ jẹri pe eniyan-bi-Ọlọrun, aladura ati ẹni ti o lawọ ni o jẹ. Sibẹsibẹ, ọjọ kan ma de ti Ọlọrun nilo lati sọ fun pe ki o ransẹ pe Peteru lati ba sọrọ nipa iyinrere Jesu Kirisiti, ki o ba a le gba a gbọ, ki o si di atunbi. Aijẹbẹ, yoo kan sunmọ ijọba Ọlọrun lasan ni, ko ni wọ inu rẹ titi di ọjọ iku rẹ. Ki wa ni gbogbo iṣẹ rere rẹ yoo jamọ? Wọn ko ni jamọ nkankan. (Wo: Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 10)

Ni bakanna, ọpọ ninu aye loni ni o kan sumọ ijọba Ọlọrun lasan ṣugbọn ti ko i ti wọ inu rẹ. Wọn le niwa, ki wọn lawọ, ki wọn si tun bẹru Ọlọrun ni ọpọlọpọ ọna. Amọ niwọn igba ti wọn ko ba i ti gba Jesu ni Oluwa wọn ati Olugbala ọkan wọn, wọn ko i ti wọ ijọba Ọlọrun niyẹn. A si nilo lati jẹ ki wọn mọ otitọ nipa eyi. A ni lati jẹ ki wọn mọ pe bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko jinna si ijọba Ọlọrun, wọn ko i ti wọ inu rẹ. Ti wọn ba si wa lọ ku lalai wọ inu rẹ, nṣe ni wọn yoo padanu ọkan wọn titi lailai, ti gbogbo iṣẹ rere wọn yoo si ṣofo danu.

Siwajusi, eyi si wa jẹ nkan ibanujẹ, a tun ri ọpọ miran ti wọn ti darapọ mọ ijọ awọn Kirisitiẹni kan tabi omiran ṣugbọn ti wọn ko i ti wa ninu ijọba Ọlọrun. Lotitọ, awọn wọnyi naa ko jina pupọ si ki wọn wọ inu rẹ. Amọ wo ko si ninu rẹ. Iru awọn wọnyi ni mo ma n ṣaba pe ni ọ̀rẹ́ ìjọ́. Idi si ni pe wọn nifẹ lati ma gbadura, kọrin, jo ati gbọ ọrọ Ọlọrun pẹlu wa ninu awọn ipade wa. Awọn kan lara wọn tilẹ tun ni ifẹ si ki wọn ma fi owo wọn gbe awọn akanṣe iṣẹ ijọ larugẹ. Ṣugbọn wọn ko i ti ṣetan ninu ọkan wọn lati tẹriba fun iṣedari Jesu Oluwa. Ko wa si bi wọn ti ṣe pẹ to ni aarin wa ati bi wọn ti ṣe darapọ mọ wa lati sin Ọlọrun to ni ipo ti wọn wa yi, ọrọ wọn ko le kọja ti ẹni ti o sunmọ ijọba Ọlọrun – wọn ko ni ipa ninu rẹ.

Wayi, wa bere lọwọ ara rẹ, “Njẹ mo wa ninu ijọba Ọlọrun lotitọ tabi nṣe ni mo kan sunmọ-ọn?” Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ọ ni olotitọ si ara rẹ ni didahun ibere yi, ki o ma ba taji lọjọ kan lati ri pe o ko ki i ṣe ara ibi ti o ro wipe o jẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kò jìnnà sí ìjọba Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 19, 202 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 29 Read More »