Ó rí ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 12, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 28
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ si ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun da ọ lare ni gbogbo ibi ti a ti n yan ọ jẹ tabi ti a ko ti mojuto ọ ni ọna ti o tọ, ki O si tun gba wọn fun ọ, ohun rere gbogbo ti o jẹ tirẹ ṣugbọn ti awọn miran n fi pamọ fun ọ. Amin.
Ọkan lara awọn ẹkọ ti a kọ lati ara itan inu bibeli nipa Hagari, iransẹbinri Sara, ni pe ko si ẹni naa ti ọrọ rẹ ko jẹ Ọlọrun logun. Nitoripe ọrọ ẹnikọọkan wa ninu aye yi wa jẹ ẹ logun, O ma n fi gbogbo igba ṣe iṣọ lori aye wa lati ri nkan ti o n lọ nibẹ ati lati jẹ ki ohun gbogbo ṣiṣẹ pọ si rere fun wa. Amọ awa naa wa gbọdọ ni eyi lọkan, ki a ba le fi igbekẹle wa sinu rẹ patapata ati ki a ma ba fi ara wa jin fun iwa ibi yowu ti o le di imuṣẹ ete rẹ rere fun aye wa ṣẹ.
Bi itan Hagari ti ṣe lọ, oluwa rẹ, Sara, mu tọ ọkọ rẹ Aburahamu lọ ni igba kan, ki o ba le ba a sun. Ki si ni idi? Idi ni pe ọkan wọn n pongbẹ lati ni ọmọ ti ara wọn. Bi o tilẹ wa jẹ wipe Ọlọrun ti ṣeleri lati fun wọn ni ọmọ naa, Sara si tun ro wipe asiko ti n lọ fun oun. Nitorina, o mu Hagari wọ inu ọrọ naa, pẹlu ero wipe ọmọ ti o ba bi fun ọkọ oun yoo di ti oun. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 16:1-3)
Wayi o, gbogbo eto ti wọn to dabi ẹni pe o n lọ ni mẹlọmẹlọ fun gbogbo wọn ki o to di wipe Hagari loyun. Nigba ti o ri wipe oun ti loyun, o bẹrẹ si ni kẹgan Sara, oluwa rẹ. Eyi tunmọ si pe igberaga gba iṣakoso ọkan rẹ, o si dẹkun lati ma fi ọwọ ti o tọ fun oluwa rẹ. Ki ni idi? O ṣeeṣe ki o ro wipe oun ni o kan lati gba isakoso ati lati di oluwa ile naa.
Ṣugbọn fun abamọ rẹ, Aburahamu ko ni lọkan lati fi aye gba ọmọdebinrin onibajẹ kankan lati da igbeyawo rẹ ru, bi o tilẹ jẹ wipe ọmọdebinrin onibajẹ naa n ru oyun rẹ kaakiri. Nitorina, nigba ti Sara fi ẹjọ Hagari sun un, o sọ fun pe ki o da seriya fun bi o ba ti dara si loju rẹ. O si wa da seriya fun to bẹẹ gẹẹ ti o fi sa kuro nile. Ta wa ni o yẹ ki a bu julọ fun ikan ti o ṣẹlẹ si? Oun naa la gbọ bu julọ. Oun ni o ṣi oore-ọfẹ ti a fun lati ma ba ọga rẹ pin ọkọ rẹ lo. Oun ni o wa nidi ikoro aye rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 16:4-6)
Sibẹsibẹ, nibi ti o ti n sa a lọ, Oluwa wa ri, O si sọ ọrọ itunu si. Wo diẹ lara nkan ti sọ lori eyi ninu bibeli: “Angẹli Oluwa si ri Agai ni ẹgbẹ isun omi ni iju, isun omi ti o wa ni ẹgbẹ ọna ti o lọ si Ṣuri. O si wi pe, “Hagari, iransẹ Sarai, nibo ni o ti n bọ, nibo si ni iwọ n lọ?” O si dahun pe, “Mo n sa lọ kuro lọdọ ọga mi Sarai ni.” Angẹli Oluwa si wi fun un pe, “Pada lọ si ọdọ ọga rẹ ki o si tẹriba fun un.” Angẹli naa si fi kun fun un pe, “Emi yoo sọ ọ di orilẹ-ede nla, iran rẹ ki yoo si loonka.” (Jẹ́nẹ́sísì 16:7-10)
Njẹ o ri bayi pe bi o tilẹ jẹ wipe Hagari mọ ibi ti o ti n bọ ni asiko yi, ko ma mọ ibi ti o n lọ ni pato? O kan ṣa a woye pe o yẹ ki oun sa kuro lọdọ ọga oun. Ṣugbọn Oluwa sọ fun pe sisa kuro lọdọ oluwa rẹ kọ ni ọna abayọ si iṣoro rẹ. Ọna abayọ si iṣoro rẹ ni ki o ya ara ya igberaga ti o wa ninu rẹ, ki o si pada lọ tẹriba fun oluwa rẹ. Kini idi? Idi ni pe ti ko ba yanju igberaga ti o wa ninu rẹ, ko ni dẹkun lati ma ṣe awọn nkan ti yoo mu ki awọn ti o nifẹ rẹ le danu kuro lọdọ wọn.
Siwaju si, ki o ba le mọ pe ọrọ oun jẹ Ọlọrun logun, bi o tilẹ jẹ wipe ẹrú ni, O sọ fun pe Oun yoo sọ iru ọmọ rẹ di ilọpo-ilọpo ni orilẹ-aye, debi wipe ko si ẹni ti yoo le ka wọn. Yatọ si eyi, Ọlọrun tẹsiwaju lati sọ awọn aṣiri kan fun nipa ọjọ́-ọ̀la ọmọkunrin ti yoo bi. Idi eyi si ni ki o ma ba fi aye gba ipo rẹ gẹgẹ bi ẹru ni asiko naa lati jẹ ki o sọ ireti nu. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 16:12)
Wayi o, ṣe Hagari wa tẹle aṣẹ Oluwa si tabi ko tẹle? O tẹle! Yatọ si iyẹn, o tun sọ kanga ti o wa nibi ti Ọlọrun ti fi ara han ni ‘Beeri-Lahai-Roi’, eyi ti o tunmọ si ‘Kanga Ẹni Alààyè naa ti o ri mi.´ Njẹ o wa mọ wipe Ẹni Alaaye yi kanna ri iwọ naa pẹlu, bi o ti wu ki nkan dabi ẹni pe o buru to fun ọ ati nkan yowu ti o gbe ọ de ibi ti o wa? Yatọ si pe O ri ọ, O tun ni ọna abayọ si awọn ipenija ti o n dojukọ lọwọ. O mọ ibi ti o yẹ ki o wa ati awọn aṣiri ọjọ́-ọ̀la rẹ. Iwọ kan ni ki o tẹti silẹ gbọ nkan ti O ni lati sọ fun ọ, ki o si tun ṣetan lati ṣiṣẹ lori rẹ. Ohun gbogbo ti o si wa ni i ṣe pẹlu ainireti yoo fi iwọ naa silẹ, iwọ yoo si ba ara rẹ ni oju ọna ti ete rẹ ni rere gbogbo fun aye rẹ yoo ti wa si imuṣẹ lẹkunrẹrẹ.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)




