Author name: 23?Racing_Horse

Má fi ìwà jọ Sọ́ọ̀lù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọpẹ 18, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 33

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Pẹlu idunu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2022. Mo si fi gbogbo ọkan mi gbadura pe ki Ọlọrun kọ ọ, ki O si tun fun ọkan rẹ ni okun lati ma fi gbogbo igba mu ni ọkunkundun ni abala aye rẹ gbogbo, ki o le ma fi gbogbo igba ri okun ati ọgbọn gba ninu rẹ fun iṣẹgun, yala o n ba idojukọ pade tabi o ko ba a pade. Amin.

Ni ọpọ igba, ti awọn adari ijọ ba n gba awọn ọmọ Ọlọrun ni iyanju lati mu un ni pataki ninu aye wọn, ki wọn ṣi ma jẹ foniku-fọlande, nṣe ni wọn ma n ro wipe wọn kan n yọ ara wọn lẹnu lasan ni. Ṣugbọn fun anfaani ara wọn ni a ṣe n gba wọn ni iyanju lọna yi. Kiki awọn ti o ba si mu ọrọ iyanju yi ni pataki, ti wọn si ṣiṣẹ lori rẹ ni yoo ri okun ati ọgbọn gba ninu Ọlọrun fun iṣẹgun ni ọjọ ibi.

Bi Pọọlu ṣe fi han wa ninu iwe Efesu 5, awọn ọjọ ibi ni awọn ọjọ ti a n gbe ninu wọn yi jẹ. Ṣugbọn ko ki i ṣe ojoojumọ naa ni awọn ibi ti o wa ninu awọn ọjọ yi ma n fẹ gba ẹmi wa, alaafia wa tabi ayọ wa. Didara ati aanu Ọlọrun ni o si jẹ ki eyi ri bẹ. Ọlọrun ni ẹni naa, nitori didara ati aanu rẹ, ti ko fi igba kankan fi aye gba eṣu lati ma ṣe bi o ba ṣe wu lati ba aye wa tabi aye ti a n gbe inu rẹ jẹ. Ki iyin jẹ ti orukọ mimọ rẹ titi lailai.

Amọ ṣa o, lẹẹkọọkan, fun oniruuru idi, Ọlọrun ma n fi aye gba eṣu lati doju kọ wa pẹlu awọn ibi ọjọ ikẹyin yi kan tabi omiran. Igba naa, ẹwẹ, ni a ma n ro wipe awa nikan ni a n ba idojukọ pade laye. Bi Pọọlu ṣe wa sọ siwaju si fun wa ninu iwe Efesu, kiki awọn ti o ba mu Ọlọrun ni pataki, ti o si gbe ihamọra rẹ wọ ni yoo le doju ija kọ ete eṣu ni awọn ọjọ buburu yi. O wa di dandan ki awọn ti ko ba ma mu ni pataki, ti a ko ba ṣaanu fun wọn, di ẹni atẹpa lati ọwọ awọn idojukọ ti wọn ba n ba pade, debi pe wọn le salọ fun gbogbo awọn ti o wa ninu aye wọn, ki wọn yi pada kuro lọdọ Ọlọrun tabi ki wọn gba ẹmi ara wọn. (Wo: Efesu 6:11-18)

Ki lo fa ti ọba Sọọlu ṣe pada di ẹni ti o n tọ ajẹ lọ, ti o si tun wa gba ẹmi ara rẹ? Idi ni pe ko mu Ọlọrun ni pataki ni awọn ọjọ ti o ni ọrọ ati alaafia. Fun igba pipẹ ni o fi n gbe aye rẹ bi igba ti o jẹ wipe Ọlọrun ti o fi si ori itẹ Isiraẹli ko ja mọ nkankan. O tilẹ ṣe de bi pe o tabuku awọn wolii Ọlọrun, o si tun pa awọn alufa rẹ. Ṣugbọn nigba ti idojukọ ti o kọja ipa ọpọlọ rẹ ati awọn ẹgbẹ ogun rẹ yọju, o bẹrẹ si ni ṣe afẹri Ọlọrun. (Wo: 1Samuẹli 13, 15, 19, 22 & 28)

Amọ okete ti boru fun ọkunrin yi ni akoko yi nitori pe Ọlọrun ko ni nkankan sọ fun mọ. O ti n ba sọrọ ni ọpọlọpọ igba tẹlẹ. Ṣugbọn ko ni gbọ. Yatọ si eyi, iwe ofin Ọlọrun wa pẹlu rẹ ni akoko yi, ṣugbọn ko ni gbe yẹwo. Ki gan lo wa fẹ ki Ọlọrun sọ fun oun? Ni kukuru, nigba ti o ri wipe Ọlọrun ko ṣetan lati ba oun sọ nkankan, o lọ ba ajẹ kan, o ṣi ṣi ilẹkun aye rẹ silẹ fun iparun patapata.

Ni bakanna, a ri ọpọ ti wọn n pe ara wọn ni Kirisitiẹni loni ti wọn ro wipe igba iṣẹlẹ pajawiri nikan ni Ọlọrun wa fun. Awọn wọnyi ro wipe awọn le ma gbe igbe aye ti o wu wọn, ki wọn si tun wa sare tọ Ọlọrun wa fun igbala ni ọjọ iyọnu. Eyi ko le lailai ṣiṣẹ. Nitorina, o ṣeeṣe ki awọn naa, gẹgẹ bi Ọba Sọọlu, ri mọ pe Ọlọrun ko ni nkankan ba wọn sọ lori bi wọn yoo ṣe bọ ninu iyọnu wọn. Ti wọn ko ba si rẹ ara wọn silẹ, ki wọn pada lati lọ se awọn nkan ti O ti n ba wọn sọ tẹlẹ, wọn ko ni ri igbala.

Njẹ eyi wa jasi pe Ọlọrun ko ki ṣe Ọlọrun alaanu bi? Rara o! Ọlọrun alaanu ni. Amọ ṣa, Oun naa mọ awọn asiko ti aanu rẹ ko ni yi eniyan pada tabi di lọwọ lati ma pa ara rẹ run nigbẹyingbẹyin. Niwọn igba ti eyi ba si ri bẹ, O le pinnu lati ma sọ ohunkohun fun iru eniyan bẹ. Wo nkan ti Àìsáyà sọ nipa eyi: “Ọkan mi n poungbẹẹ rẹ ni ọganjọ oru; ni owurọ ni ẹmi mi n ṣafẹri rẹ. Nigba ti idajọ rẹ ba sọkalẹ sori aye awọn eniyan yoo kọ iṣododo. Bi o tilẹ jẹ pe a fi oore-ọfẹ han si awọn ika wọn ko kọ lati ṣododo; koda ni ilẹ awọn ti o duro ṣinṣin wọn tẹsiwaju lati maa ṣe ibi wọn ko si ka ọla nla Oluwa si.” (Àìsáyà 26:9-10)

Njẹ o ri bayi? Ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni oore-ọfẹ ati aanu ma n le jẹ ki awọn eniyan mu Ọlọrun ni ọkunkundun. Ṣugbọn gbogbo igba ni idojukọ ati idajọ ma n jẹ ki wọn mọ pe Ọlọrun ko ki i ṣe ẹni ti wọn le fi ọwọ yẹnpẹrẹ mu. Ki wa lo de ti iwọ na, bi Sọọlu, fẹ duro de igba ti idojukọ ba de ba ọ tabi ti idajọ ba wa sori rẹ ki o to gba pe o yẹ ki a mu Ọlọrun ni pataki? Ki ni o de ti o fẹ ti ara rẹ si ibi ti oore-ọfẹ Ọlọrun ko ti ni ṣiṣẹ fun ọ ni ọjọ iyọnu?

Ni kukuru, ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa bayi, o si n sọ fun pe ki o kọ bi a ti ṣe n mu Ọlọrun ni pataki ni gbogbo iṣẹju aye rẹ. Idojukọ ko fi igba kankan bori awọn eniyan bi Josẹfu, Dafidi ati Pọọlu apọsiteli. Dipo eyi, nṣe ni wọn ma n fi gbogbo igba rin ni iṣẹgun lori wọn. Idi si ni pe wọn ko duro ki idojukọ de ba wọn tabi ki idajọ Ọlọrun wa sori wọn ki wọn to mu Ọlọrun ni pataki. Yala idojukọ wa o tabi ko si, gbogbo igba ni wọn fi n mu un ni ọkunkundun. Ti iwọ naa ba si da bi wọn, ko si irufẹ ibi ti o le yọju si ọ, igbaradi ni iwọ yoo ma fi gbogbo igba wa lati mojuto ati lati rin ni iṣẹgun lori rẹ nipa agbara ati ọgbọn Ọlọrun, dipo ti idojukọ naa yoo fi yi ọ lori.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má fi ìwà jọ Sọ́ọ̀lù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọpẹ 18, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 33 Read More »

Iṣẹ́ wọn kọ́ ni láti tẹ́ ọ lọ́rùn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọpẹ 11, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 32

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2022. Adura mi ni pe ki a tẹri ọkan rẹ ba lati ma fi gbogbo igba tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ awọn ti Ọlọrun ran lati gbe ọ ro, ki ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ba a le jẹ aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, awọn kan wa ti a yan, ti a si tun fun ni ẹbun lati ọwọ Ọlọrun lati gbe ijọ rẹ ro ninu ifẹ rẹ (Éfésù 4:11-16). Iha ti a ba si kọ si iṣẹ iranṣẹ wọn yoo sọ, ni ọpọ ọna, boya a o ṣe aye wa ni aṣepe ninu ifẹ Ọlọrun tabi bẹẹkọ. Lotitọ, o le ma ni wa lara lati tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ wọn, niwọn igba ti wọn ba n ṣe awọn nkan tabi sọ awọn ọrọ ti o n mu inu wa dun tabi ti o n dun mọ wa ninu. Ṣugbọn ti wọn ba n ṣe awọn nkan tabi sọ awọn nkan ti ko mu inu wa dun nkọ, ti awọn nkan yi si wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun? Njẹ a o si tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ wọn, ki a si tun ma ba wọn lo pẹlu ọwọ ti o tọ si wọn bi?

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni wọn ro pe gbogbo igba ni awọn adari ijọ wọn gbọdọ ma sọ ati ṣe kiki awọn nkan ti yoo mu inu wọn dun. Ṣugbọn eyi ko ki i ṣe ifẹ Ọlọrun. Iṣẹ adari ijọ kọ ni lati ṣe ohunkohun lati mu inu ẹnikẹni dun ṣugbọn lati ṣe awọn nkan ti yoo gbe wọn ro.

Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinnti: “…ṣugbọn awa n ṣe ohun gbogbo, olufẹ ọwọn, lati gbe yin ro ni.” (2Kọ́rínntì 12:19) Njẹ o ri bayẹn? Afojusun adari ijọ kọọkan gbọdọ da lori bi yoo ṣe ma a ṣe kiki awọn nkan ti yoo gbe awọn ara ijọ rẹ ro, ti yoo si bu si igbagbọ wọn. Lara awọn nkan wọnyi si ni pipe akiyesi ẹniyan si aiṣedede rẹ, itọni-sọna ati biba awọn ọmọ ijọ wi wa.

Wayi o, a mọ wipe titọni-sọna, pipe akiyesi eniyan si aiṣede rẹ ati biba awọn eniyan wi ko ki i fi igba kankan dun mọ awọn ti ọrọ ba kan ninu. Ṣugbọn a nilo lati ṣe awọn nkan wọnyi fun ilera ijọ Ọlọrun. Nitorina, boya awọn ti a n ki nilọ, tọ sọna tabi ba wi ba mọ riri nkan ti a n ṣe fun wọn tabi wọn ko mọ, ohun ti o tọ fun wa lati ṣe gbọdọ jẹ ṣiṣe. Idi si niyi ti adari awọn ọmọ Ọlọrun kọọkan ṣe gbọdọ ni igboya, ki o si tun ni okun fun iwa ti o tọ. Aijẹbẹ, ko ni ṣe ohun ti o tọ fun lati ṣe fun idagbasoke ati ifidimulẹ awọn ọmọ Ọlọrun. Dipo eyi, nṣe ni yoo dabi Árónì, ẹni ti o bẹru to bẹẹ gẹẹ ti o fi fi aye gba awọn ọmọ Isiraẹli lati yawọ ninu aginju ati lati fi ara wọn jin fun iboriṣa, eyi ti o si ja si iparun fun wọn (Ẹkisodu 32).

Ṣugbọn ki ni Ọlọrun sọ fun Ìsíkíẹ̀lì nigba ti O n yan gẹgẹ bi aṣọna lori orilẹ-ede Isiraẹli? O sọ eyi fun:

“Awọn eniyan ti mo n ran ọ si jẹ alaigbọran ati ọlọkan lile. Sọ fun wọn pe, ‘Eyi ni ohun Oluwa Ọlọrun wi’ bi wọn fetisilẹ tabi wọn ko fetisilẹ – nitori pe ọlọtẹ ile ni wọn – wọn yoo mọ pe wolii kan wa laarin wọn. Ati iwọ, ọmọ eniyan, ma ṣe bẹru wọn tabi ọrọ ẹnu wọn. Ma ṣe bẹru, bi o tilẹ jẹ pe oṣuṣu ati ẹgun yi ọ ka, ti o si n gbe aarin awọn akeekee. Ma ṣe bẹru ohun ti wọn n sọ tabi bẹru wọn, bi o tilẹ jẹ pe ọlọtẹ idile ni wọn. Iwọ gbọdọ sọ ọrọ mi fun wọn, bi wọn gbọ bi wọn kọ lati gbọ tori pe ọlọtẹ ni wọn.” (Ìsíkíẹ̀lì 2:4-7)

Iwọ na wo bayẹn. Ọlọrun sọ fun ọkunrin yi lati ma kọbiara si iha yowu ti awọn ọmọ Isiraẹli le kọ si iṣẹ iranṣẹ rẹ. Dipo eyi, nṣe ni ki o tẹsiwaju lati ma polongo ọrọ rẹ si wọn, yala o dun mọ wọn ninu o tabi ko dun mọ wọn ninu. Ọna si niyi lati jẹ ki iṣẹ Ọlọrun di ṣiṣe. Afojosun wa ko gbọdọ wa lori bi a o ti ṣe dun awọn eniyan ninu ṣugbọn lori bi a o ti ṣe dun Ọlọrun ti o ran wa ninu.

Nitorina, ti o ba ṣẹlẹ pe a ba wa lọkanjẹ nipasẹ pe awọn adari ijọ wa n ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe si wa ati fun wa, ko yẹ ki a fi ṣe ibinu. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a rẹ ara wa silẹ lati tẹwọgba ifẹ Ọlọrun fun aye wa, niwọn igba ti a mọ pe ohunkohun ti O ba ṣe jẹ fun rere wa (Heberu 12:5-12). Adura mi si ni pe ki a tẹri ọkan rẹ ba ni gbogbo igba lati jọwọ ara rẹ fun ibawi ti Ẹmi, ki aye rẹ ba le jẹ aṣepe ni gbogbo ọna lati ọwọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Iṣẹ́ wọn kọ́ ni láti tẹ́ ọ lọ́rùn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọpẹ 11, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 32 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 5:1-12 | ỌJỌ́RÚ 07, ỌPẸ 2022

DOWNLOAD E-COPY HERE

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, o ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun wọn pe ipo ẹru ni awọn ti o wa labẹ ofin Moṣe wa. O tilẹ jẹ ki o ye wọn pe nkan ti ofin gan sọ ni eyi. Ara idi si ni yi ti a ṣe ran Jesu Oluwa wa lati gba awọn ti o wa labẹ ofin yi kuro ninu igbekun ati egun rẹ. Ti awọn ti a didi fun ni ofin Mose ba wa nilo irapada kuro labẹ rẹ ati kuro labẹ egun rẹ, ṣe o wa yẹ ki awọn ti a ko fun ni ofin yi fi ara wọn si abẹ igbekun rẹ? Ko yẹ rara. Nitorina, ninu abala lẹta yi ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi, Pọọlu tẹsiwaju ninu alaye rẹ lati fi nkan ti o sorọ mọ ki a fi ara wa si abẹ igbekun ofin Mose han awọn ara Galatia. O si wa yẹ ki gbogbo awọn ti o jẹ Kirisitiẹni loni, ti awọn naa si n gbiyanju lati fi ara wọn si abẹ ofin Mose ṣe aṣaro ti o peye lori awọn nkan ti apositeli yi sọ ninu awọn ẹsẹ lẹta ti a fẹ yẹwo naa.

MÁ ṢE TI ỌRÙN BỌ ÀJÀGÀ ÒFIN MÓSÈ
Ewu wo lo wa sorọ mọ ki a fi ara wa sabẹ igbekun ofin Mose? Tabi ki a sọ wipe awọn ọna wo ni ki a fi ara wa sabẹ isinru ofin Mose ṣe le pa igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu lara? Awọn nkan ti Pọọlu sọ lorin ọrọ naa niyi:

“Nitori naa, ẹ duro ṣinṣin ninu ominira naa eyi ti Kirisiti fi sọ wa di ominira, ki ẹma si ṣe tun fi ọrun bọ ajaga ẹru mọ. Kiyesi i, emi Pọọlu ni o wi fun yin pe, bi a ba kọ yin nila, Kirisiti ki yoo lere fun yin ni ohunkohun. Mo si tun sọ fun olukuluku eniyan ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ. A ti ya yin kuro lọdọ Kirisiti, ẹyin ti n fẹ ki a da yin lare nipa ofin; pe ẹ ti ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ.” (Galatia 5:1-4)

Nkan akọkọ ti apọsiteli yi jẹ ki o ye wa ni pe Kirisiti ti sọ wa di ominira. Ti a ba wa sọ pe Kirisiti sọ wa di ominira, o yẹ ki a mọ nkan ti O sọ wa di ominira kuro ninu rẹ. Bi a ti fihan ninu bibeli, Kirisiti ti sọ wa di ominira kuro ninu igbekun ẹṣẹ ati igbekun eṣu ati gbogbo iṣẹ ibi rẹ. Nitorina, a gbọdọ ma fi gbogbo igba ri ara wa bi ominira. Yatọ si eyi, Kirisiti tun ti sọ awọn Juu di ominira kuro ninu igbekun ofin Mose. Nitorina, awọn naa gbọdọ ma fi gbogbo igba ri ara wọn gẹgẹ bi ẹni ti o ti di ominira kuro labẹ ofin Mose.

Nkan ekeji ti Pọọlu tun pe akiyesi wa si ni pataki ki a duro ṣiṣin ninu ominira ti a ti ri gba lọwọ Kirisiti. Kirisiti ko sọ wa di ominira ki a ba le ma gbe igbe aye ẹru. Amọ ti a ko ba pinnu lati duro ṣinṣin gẹgẹ bi ẹni ti o ti di ominira, ko si ni ki eṣu, ẹṣẹ, ẹran-ara, aye ati oniruru ofin atọwọda awọn eniyan ma tun fẹ mu wa ni igbekun. Nkan ti a n sọ ni pe, pe a ti sọ wa di ominira ko sọ wipe ki awọn ẹṣẹ ti a ti gba wa lọwọ wọn ma tun fẹ jẹ gaba lori aye wa. Bẹẹ si ni ko sọ wipe ki aisan, airoju, airaye, egun idile, iku-ojiji ati bẹẹbẹẹ lọ ma fẹ ṣe ijọba lori aye wa. Awa ni a gbọdọ mura, ki a si pinnu lọkan wa lati ma fi aye gba ohunkohun tabi ẹnikẹni lati tun ma ṣe ijọba lori aye wa yatọ si Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa.

Siwaju si, pe Jesu sọ awọn Juu di ominira kuro ninu igbekun ofin Mose ko sọ wipe ki ero-ọkan wọn nipa ofin yi ma tun fẹ lo ofin naa lati fi wọn sinu ide. Eyi lo si fa ti a fi ri awọn Juu ni akoko ti Pọọlu kọ lẹta yi ti ko fẹ kọ ofin Mose silẹ gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ti da Kirisitiẹni. Luuku tilẹ sọrọ akoko kan fun wa ninu iwe Iṣe Awọn Apọsiteli ninu eyi ti a ti rọ Pọọlu lati darapọ mọ awọn Juu ẹgbẹ rẹ kan lati tun rubọ ninu Tẹmipili, ni ibamu pẹlu ofin Mose. Kini o fa eyi? Aimuratan lati kọ ofin Mose ati awọn ilana rẹ silẹ gẹgẹ bi ọna fun igbala ati m didi ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun lo fa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 21:18-26)

Nikukuru, irufẹ awọn Juu yi naa ni o lọ kaakiri, ti wọn si n gbiyanju lati mu awọn Heleni ti o ti gba Jesu gbọ ni tipatipa lati bẹrẹ si ni pa ofin Mose mọ, paapaa julọ eyi ti o ni i ṣe pẹlu ikọla abẹ. Pọọlu wa n jẹ ki o ye awọn ara Galatia pe ọwọ wọn lo ku si lati ri pe wọn ko fi aye gba awọn eniyan yi lati sọ wọn si abẹ igbekun ofin Mose. Bẹẹ gẹgẹ ni o si gbọdọ ri fun awa naa. Awa naa gbọdọ mura, ki a si ri daju pe a ko fi aye gba ẹnikẹni, bi o ti wu ki ẹni naa lọla to laarin awọn ọmọ Ọlọrun, lati fi wa si abẹ ofin Mose gẹgẹ bi ẹru rẹ.

Ki si ni idi ti a fi gbọdọ mura lati ma ṣe fi aye gba ẹnikẹni lati fi wa si abẹ igbekun ofin Mose? Idi akọkọ, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, ni pe a ko ni jẹ ere iṣẹ irapada ati isọdọmọ ti Kirisiti ṣe fun wa, niwọn igba ti a ba fi aye gba ofin Mose lati jẹ oluwa fun wa. Eyi tunmọ si pe ẹnikẹni ti o ba ro wipe ohun o ri nkankan gba lọwọ Ọlọrun nitori pe oun tẹle ilana ofin Mose kan n tan ara rẹ jẹ ni. Ko le ri ibukun kankan ti o sorọ mọ ki a jẹ ọmọ Ọlọrun nipa igbagbọ ninu Kirisiti gba.

Bawo wa ni ti awọn Kirisitiẹni ti o n fi gbogbo igba jẹri awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe fun wọn nipasẹ pipa ofin Mose mọ? Nkan ti awọn wọnyi ko mọ ni pe ko ki i ṣe nitoripe wọn n pa ofin Mose mọ ni Ọlọrun ṣe dara si wọn. Ọlọrun dara si wọn nitoripe alaanu ni, O si ma n ṣe daradara si awọn ika eniyan paapaa lati fi aye ironupiwada silẹ fun wọn (Matiu 5:44-45). Eyi jẹ ki a mọ pe eniyan le ma ṣe nkan ti o tako ifẹ Ọlọrun ki o si tun ma jẹ igbadun didara rẹ ni ọpọlọpọ ọna. Ṣugbọn ọjọ naa n bọ ti Ọlọrun yoo san ẹnikọọkan ni ẹsan fun iṣẹ ọwọ rẹ, yala o ba ifẹ rẹ mu tabi ko ba ifẹ rẹ.

Ki a ma fi ọrọ silẹ sọ nkan miran, koko nkan ti a n sọ ni pe ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni, ti o si tun wa dirọ mọ ofin Mose gẹgẹ bi ọna lati jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun ko le jẹ igbadun ipese Kirisiti ninu aye rẹ gẹgẹ bi o ti yẹ ki o ma jẹ ẹ. Awọn iṣẹ ti Kirisiti fẹ ṣe ninu aye rẹ ko ni le ṣeeṣe nitoripe igbagbọ rẹ ko si ninu iṣẹ Jesu Kirisiti mọ bikoṣe ninu iṣẹ ọwọ ara rẹ.

Idi keji, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, ti a fi gbọdọ mura lati ma jẹ ki ẹnikẹni fi wa si abẹ ajaga ofin Mose ni pe fifi ara wa jin lati pa abalakabala ninu ofin yi mọ yo sọ wa di onigbese ti o gbọdọ pa gbogbo abala ofin naa mọ. Eyi jasi pe niwọn igba ti a ba ti pinnu lọkan wa pe ofin Mose ni a fẹ tẹle gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba tabi idalare niwaju Ọlọrun, a gbọdọ mura lati bẹrẹ si ni pa gbogbo nkan ti ofin naa sọ mọ. Nkan wọnyi ni ko si ye awọn ara Galatia ti wọn fi ara wọn jin pe ki a kọ wọn ni ila abẹ, ni ibamu pẹlu ofin Mose. Wọn ko mọ wipe ko tọna fun wọn lati pa abala ofin yi kan mọ, ki wọn si wa kọ awọn abala yoku silẹ. Eyi yoo fi wọn si abẹ egun ofin naa ti o sọ wipe egbe ni fi ẹni naa ti ko ba tẹsiwaju lati ma pa gbogbo ọrọ ofin yi mọ (Ditaronomi 27:26).

Ṣe o wa mu ọgbọn wa ki eniyan tun lọ fi ara rẹ si abẹ egun ofin Mose lẹyin igba ti Jesu ti ku lati ra awọn ti o wa labẹ egun ofin yi pada? Ko mu ọgbọn wa rara. Nitorina, gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n mura kankan loni pe dandanla awọn gbọdọ ma tẹle ofin Mose gbọdọ mura bakanna lati pa gbogbo nkan ti a sọ sinu ofin naa mọ. Aijẹbẹ, abẹ egun ni wọn wa – awọn ibukun ọfẹ Kirisiti ti ẹnikẹni ti o ba gbagbọ ninu rẹ lẹtọ lati jẹgbadun ko si le ṣiṣẹ lọna ti o peye ninu aye wọn.

Idi kẹta ti Pọọlu tun fun wa, eyi ti o ṣe ṣe pataki ki a ma fi ara wa si abẹ ofin Mose ni pe gbogbo Kirisitiẹni ti o ba fi ara wọn si abẹ ofin yi ni a ti ya kuro ni ara Kirisiti, ti wọn si ti ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ rẹ. Bi Adamu ṣe ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Ọlọrun ninu ọgba Edẹni, ti a si le kuro nibi ipese Ọlọrun lati lọ ma fi oogun oju rẹ wa ounjẹ oojọ rẹ, bẹẹ gẹgẹ naa ni o ṣe ri fun gbogbo awọn ti o ba pa igbagbọ ninu Kirisiti ti lati ma tẹle ofin Mose. Awọn naa yoo nilo lati gboju le iṣẹ ọwọ wọn lati jẹ igbadun ipese Ọlọrun ni –oore-ọfẹ Kirisiti ko le ṣiṣẹ fun wọn mọ.

Lotitọ, irufẹ awọn wọnyi le ma gbadura ni orukọ Jesu, ki wọn ma gbawẹ ni orukọ rẹ, ki wọn si tun ma jọsin pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ṣugbọn a ti ya wọn ya Kirisiti nitori ifarajin wọn fun ofin Mose. Bawo wa ni yoo ṣe buru to ki eniyan ro wipe oun wa pẹlu Kirisiti, ki o si ma wa pẹlu rẹ? Bawo ni yoo ṣe bani lọkanjẹ to lati gbọ lati ẹnu Kirisiti Jesu nigba ti O ba de pe Oun ko mọ wa ri, lẹyin igba ti a ti fi ọpọlọpọ ọjọ aye wa jọsin ni orukọ rẹ, ti a si mura gidigidi lati gbe igbe aye olododo? Yoo buru jọjọ. (Wo: Matiu 7:21-23)

Pọọlu wa tẹsiwaju lati jẹ ki eyi ye wa:

“Nitori nipa Ẹmi awa n fi igbagbọ duro de ireti ododo. Nitori ninu Kirisiti Jesu ikọla ko jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ ti n ṣiṣẹ nipa ifẹ.” (Galatia 5:5-6)

Nibo ni ireti ipadabọ Jesu lati fi idi ijọba ayeraye Ọlọrun mulẹ ti a ni ti wa? O wa nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ti O tun wa bi, ti O si n gbe inu wa. Ko ki i ṣe nipasẹ ofin Mose tabi ẹkọ ti o kọ ni a ṣe ni ireti yi. Nitorina ni Pọọlu se wa sọ wipe pipa ofin Mose mọ nipa kikọ ila abẹ ko ja mọ nkankan. Idi si ni pe ikọla abẹ gan ni pataki julọ ninu awọn ofin Mose ti awọn ti o n yọ awọn ara Galatia yi lẹnu n tẹnumọ. Wọn n sọ wipe bi awọn ti ko ki i ṣe Juu ko ba tilẹ ni pa ofin Mose miran mọ, wọn gbọdọ pa ti ikọla abẹ mọ, ki wọn ba le jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun.

Ṣugbọn, bi Pọọlu ti jẹ ki o ye wa, ninu Kirisiti Jesu ikọla abẹ ko ja mọ nkankan, bẹẹ si ni aikọla abẹ naa ko ja mọ nkankan. Nkan ti o ṣe pataki julọ ni igbagbọ ninu Jesu Kirisiti ti o n gbe igbe aye ifẹ. Ifẹ si ni akoja gbogbo ofin. Nitorina, nkan ti awọn ti o gbagbọ ninu Jesu nilo lati gbaju mọ ni igbe aye ifẹ. Niwọn igba ti afojusun wọn ba ti da lori ki wọn ma ṣe ohun gbogbo ninu ifẹ, ko si ni bi wọn ko ṣe ni gbe igbe aye ti o wu Ọlọrun.

Pọọlu wa pari ọrọ rẹ ni abala ti a n gbe yẹwo ninu ẹkọ yi nipa sisọ eyi:

“Ẹyin ti n sare daradara; ta ni di yin lọwọ lati ṣe igbọran si otitọ? Iyipada yii ko ti ọdọ ẹni ti o pe yin wa. Iwukara diẹ ni i mu gbogbo iyẹfun wu. Mo ni igbẹkẹle si yin ninu Oluwa pe, ẹyin ki yoo ni ero ohun miiran; ṣugbọn ẹni ti n yọ yin lẹnu yoo ru idajọ tirẹ, ẹnikẹni ti o wu ki o jẹ. Ṣugbọn, ara, bi emi ba n waasu ikọla sibẹ, kin ni idi ti a fi n ṣe inunibini si mi ṣibẹ? Njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. Emi iba fẹ ki awọn ti n yọ yin lẹnu tilẹ ge ẹya-ara wọn kan kuro.” (Galatia 5:7-12)

Njẹ o ri bayi? Awọn ara Galatia yi ti n sare daradara tẹlẹ nipasẹ igbagbọ wọn ninu Jesu. Ṣugbọn awọn aṣinilọna kan ni wọn ko ba wọn, ti wọn si ti wọn ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Kirisiti. Pọọlu wa n jẹ ki o ye wọn pe o di dandan ki awọn ti o n yọ wọn lẹnu ru ẹru idajọ wọn. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun ko ni ṣe alaimajẹwọniya fun yiyọ ijọ rẹ lẹnu. Ti awa naa ba si n yọ ijọ Ọlọrun lẹnu tabi ti a n ṣi awọn ọmọ rẹ lọna, o di dandan ki a ri ijiya ti o tọ si wa, bopẹ-boya.

Ọ̀RỌ̀ ÌKẸ́YÌN
Nibiti ọrọ yi wa ka Pọọlu lara de, o pari ọrọ nipa sisọ wipe ki lo ṣe ti awọn ti o n yọ awọn ara Galatia yi lẹnu ko tilẹ kuku jan ara wọn ni ountẹ, ki wọn si di òkóbó? Nitirẹ, idi ti awọn ju ṣe n ṣe inunibini si ni pe o n jẹ ki awọn eniyan mọ wipe ikọla abẹ ko wulo fun igbala ẹmi wọn. Lotitọ, ikọla abẹ wulo fun eniyan lati jẹ Juu nipa ti ara ati lati jẹ ajogun ilẹ ileri Kenani. Amọ ti a ba n sọrọ nipa Juu ti ẹmi ati ajogun ijọba Ọlọrun, ikọla abẹ ko wulo rara. Igbagbọ ninu Jesu Kirisiti nikan ni o le jẹ ki awọn nkan wọnyi jẹ ti wa. Eyi si ni iyinrere tòótọ́.

ÌBÉÈRÈ

  • Pipa Jesu ti lati ma tẹle ofin Mose gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun lewu. Ṣalaye bi eyi ṣe lewu to.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 5:1-12 | ỌJỌ́RÚ 07, ỌPẸ 2022 Read More »

Ó yẹ kí òpin sán ju ìbẹ̀rẹ̀ lọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọpẹ 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 31

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu ti o pari ọdun yi, oṣu Ọ̀pẹ 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ni oṣu ti o san ju fun iwọ ati ile rẹ ninu gbogbo awọn oṣu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Solomọni, ninu iwe rẹ ti a n pe ni Oniwaasu, sọ wipe, “Opin nnkan san ju ipilẹsẹ re lọ: ati onisuuru kan san ju ọlọkan igberega.” (Oníwàásù 7:8) Ifẹ Ọlọrun fun wa si ni eyi. O fẹ ki opin ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye san ju ibẹrẹ rẹ lọ. Nitorina, ti a ba n fojusọna pe ki oṣu ti o kẹyin ọdun yi san ju gbogbo awọn oṣu ti o ṣaju rẹ lọ, a n rin ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa.

Amọ ṣa o, o tun ṣe pataki ki a mọ pe ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni opin ohun gbogbo ma n san ju ibẹrẹ rẹ lọ. Nkan ti eyi n jẹ ki o ye wa ni pe ko ki i ṣe gbogbo igba ni nkan ti Solomọni sọ ninu ẹsẹ bibeli yi jẹ otitọ. Fun apẹẹrẹ, bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, Ọba Sọọlu bẹrẹ daradara laye rẹ ati gẹgẹ bi ọba ti Ọlọrun yan. Ṣugbọn opin aye rẹ ko dara rara, ka ma tilẹ wa sọ wipe yoo san ju ibẹrẹ rẹ lọ. Lafikun, Samsoni bẹrẹ daradara gẹgẹ bi iransẹ ati olugbala ti Ọlọrun yan. Ṣugbọn igbẹyin rẹ ko dara rara. Judasi Isikarọti nkọ? Ṣe ko bẹrẹ daradara gẹgẹ bi ọkan lara awọn apọsiteli Oluwa? O bẹrẹ daradara. Ṣugbọn bawo wa ni igbẹyin rẹ ṣe ri? O buru jai.

Nitorina, opin nnkan tabi awọn eniyan ko ki fi igba gbogbo san ju ibẹrẹ wọn lọ. Ti awọn eniyan ko ba mu Ọlọrun ni ọ̀kúnkúndùn ninu ohun gbogbo ti wọn n ṣe, opin ọjọ wọn, ọsẹ wọn, oṣu wọn, ọdun wọn, akanṣe iṣẹ wọn, ẹkọ wọn, igbeyawo wọn tabi aye wọn le ma san ju ibẹrẹ rẹ lọ. Mo si n sọ eyi, bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu ti o kẹyin ọdun yi, ki o ba le mu Ọlọrun ni ọ̀kúnkúndùn ju bi o ti ṣe mu latẹyinwa lọ.

Woo, bibeli sọ fun wa pe Ọlọrun ni olubẹrẹ ati alaṣepe ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu aye ati igbagbọ wa. Eyi tunmọ si pe Oun nikan ni Ẹni naa ti o le ṣe aye wa ati ohunkohun ti a ba dawọ le ni aṣepe. Bẹẹni, Oun nikan ni Ẹni naa ti o le jẹ ki opin ohunkohun ti a ba ṣe san ju ibẹrẹ rẹ lọ. Ṣugbọn ki a ba le ni iriri aṣepe rẹ ninu aye wa, a sọ awọn nkan meji kan ti a gbọdọ ṣe. Akọkọ, a sọ wipe ki a gbe ohun gbogbo ti o n di wa lọwọ lati gbe igbe aye ti O fẹ ki a gbe ju danu si igbo. Ekeji, a sọ fun wa pe ki a tẹjumọ ọ dipo ki a tẹjumọ awọn idojukọ yowu ti a n ba pade. (Wo: Hébérù 12:1-2)

Wayi o, niwọn igba ti a ba ti tẹjumọ Oluwa, ti a si fi ọkan wa jin lati ma gbe aye wa bi O ṣe fẹ ki a gbe, a le fi ọkan wa balẹ pe yoo ṣe ohun gbogbo ti o jẹ ti wa ni aṣẹpe. Ọdun yi le jẹ eyi ti o le tabi ṣoro fun wa ni awọn ọna melokan tabi pupọ. Ṣugbọn o di dandan ki Oluwa wa ṣe awọn ọjọ ti o pari rẹ ni eyi ti o dara julọ fun wa. A si le fọkan tan an fun eyi.

Siwaju si, yatọ si pe ki a mu Ọlọrun ni ọ̀kúnkúndùn ninu aye wa, ki O ba le ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu wa ni aṣepe, a tun gbọdọ ṣọra lati ma mu aye le fun ara wa. O wa ṣeni laanu pe eyi gan ni iṣoro ọpọlọpọ wa. Bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ma n fi gbogbo igba ṣiṣẹ lati ṣe aṣepe ohun gbogbo ti o jẹ tiwa, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni iṣẹ rere rẹ ma n bu si aye wa. Ki si ni idi? Idi ni pe ọpọ igba ni a ma n ṣe awọn nnkan ti yoo pa iṣẹ ti O n ṣe ninu aye wa lara, ti o yoo si mu aye le mọ wa.

Iwọ naa wo nnkan ti Solomọni sọ nipa eyi: “Kiyesi i, eyi nikan ṣoṣo ni mo ri, pe, Ọlọrun ti da eniyan ni iduro-ṣinṣin; ṣugbọn wọn ti se afeeri etekete.” (Oníwàásù 7:29) Njẹ iwọ naa ri bayi? Ohunkokun ti Ọlọrun ba ṣe si wa tabi fun wa ma n fi gbogbo igba da lori bi aye wa yoo ṣe lọ deede, ti yoo si rọrun fun wa. Ṣugbọn nitori ọgbọn-agbọnju ti a ro pe a ni, nṣe ni a ma da oju gbogbo nkan delẹ funralara wa nikẹyin-kẹyin.

Ni kukuru, nkan ti mo n ṣọ ni pe ki a ma ṣe fi ọwọ ara wa ṣe ohunkohun ti yoo fooro iṣẹ ti Ọlọrun n ṣe ninu aye wa. Ọlọrun wa ni imura lati ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni opin ọdun yi laṣepe ati lati mu ki inu wa dun gidigidi. Ṣugbọn a gbọdọ ṣora lati ma doju nkan ti O n ṣe ninu wa ati fun wa delẹ. Nitorina, ma ṣe gbe ajagaga kankan sori ara rẹ ti ko gbe le ọ lori. Ma si ṣe pọn ara rẹ loju lori pe o fẹ jọ awọn ti ko ri ọrọ rẹ ro loju.

Iru awọn nkan bayẹn yoo kan fooro ibukun Ọlọrun lori aye rẹ ni, yoo si tun ta nnkan ni koko si fun ọ. Igba naa ni o wa bẹrẹ si ni gbadura fun aanu, igbala ati isọdọtun nibi ti o jẹ pe a ti fun ọ ni iṣẹgun tẹlẹtẹlẹ. Adura mi fun ọ ni pe ki a kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ti o peye láti má ṣe ohunkóhun ti yoo pa iṣẹ aṣepe ti Ọlọrun n ṣe lori aye rẹ lara, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ọpẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ó yẹ kí òpin sán ju ìbẹ̀rẹ̀ lọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọpẹ 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 31 Read More »

Wọn kò ní dúró bèrè àyè tàbí gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 27, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 30

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Adura mi ni pe ki a fun ọkan rẹ ni okun ati irẹlẹ lati fi aye gba Ọlọrun lati gba iṣakoso aye rẹ patapata, ki o ba le jẹ pe iṣẹ rẹ nikan, ti ko si ni jẹ iṣẹ Satani, ni yoo ma jẹyọ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu iwe Ifihan, ori ikẹta, ẹsẹ ogun, Johanu fi igbe rara Jesu Oluwa wa si ijọ awọn ara Laodikia han wa, eyi ti o ka bayi: “Kiyesi i, emi duro ni ẹnu ilẹkun, emi si n kankun, bi ẹnikẹni ba gbọ ohun mi, ti o si ṣi ilẹkun, emi yoo wọle tọ ọ wa, emi yoo si maa ba a jẹun, ati oun pẹlu mi.” (Ifihan 3:20) Kini nkan ti o le fa ki Oluwa wa ma kan ilẹkun aye Kirisitẹni? Ṣe Oun kọ ni Oluwa wa ni? Oun ni! Ati wipe, gẹgẹ bi Oluwa wa, ṣe ko ki i ṣe inu aye wa ni O yẹ ki O wa, ki O si ma ṣe akoṣo ohun gbogbo? Inu rẹ ni O yẹ ki o wa! Ki wa lo de ti O tun ṣe nilo aṣẹ ati ifọwọsowọpọ wa lati wole sinu abala aye wa kan tabi omiran lati ba wa lo pọ nibẹ?

Idi naa ko ruju rara. Oluwa ko ki i ti ara rẹ mọ eniyan lọrun. Dipo eyi, nṣe ni yoo fi aye gba wọn lati ro wo funralara wọn lati pinu boya wọn nilo rẹ ninu aye wọn tabi wọn ko nilo rẹ, ki wọn si gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu ero wọn. Eyi si ni alaye fun bi gbogbo agbaye ko ti se di ẹni igbala. Oluwa ko ni fi dandan mu wa tẹwọgba igbala rẹ. A wa ni a nilo lati gba pe a nilo igbala ati pe a ko le gba ara wa la kuro lọwọ awọn nkan ti o n pa wa run ti Oun ko ba gba wa la.

Amọ ṣa o, ọtọ n ki a wa sọdọ Oluwa fun igbala, ọtọ ṣi tun ni ki a fi aye gba lati gba wa la patapata ati lati pa wa mọ titi lailai. Bawo ṣi ni eyi yoo ṣe ṣeeṣe? Yoo ṣeeṣe nipa fifi aye gba lati dari wa ninu gbogbo abala aye wa, lalai fi ọkankan pamọ fun. Gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, inu wa ni O n gbe, nitori pe tẹmipili rẹ ni a jẹ. Ṣugbọn pe O n gbe inu wa ko tunmọ si pe O n ṣe iṣakoso aye wa ati ọrọ aye wa. Pe O n gbe inu wa ko tunmọ si pe ko ni nilo lati kan ilẹkun awọn abala aye wa kan naa lati ri boya a o fi aye gba lati ṣe akoso wọn.

Gbogbo wa la mọ ara wa. Gbogbo wa ni a mọ boya a fi aye gba Jesu Oluwa wa lati ṣe akoso gbogbo aye wa tabi bẹẹ kọ. Gbogbo wa la mọ awọn abala aye wa ti a ti ti ilẹkun mọ patapata nitori pe a ko fẹ gbọ ohunkoun ti O fẹ sọ fun wa nipa wọn tabi nitori pe a gbagbọ pe a koju oṣuwọn lati moju to wọn. Nkan ti a wa le ma mọ ni pe Jesu Oluwa wa ko ku fun wa ki O ba le jẹ Oluwa lori awọn abala aye wa melokan. Dipo eyi, nṣe ni O ku fun wa lati jẹ Oluwa lori gbogbo abala aye wa.

Lafikun, Jesu Oluwa wa ko gba wa la lọwọ Eṣu ati awọn ogun rẹ ki O ba le jẹ Oluwa lori abala aye wa melokan. Dipo eyi, O gba wa la ki O ba le jẹ Oluwa lori gbogbo abala aye wa. Nitorina, ti a ko ba ni finufẹdọ gba a laaye lati jẹ alakoso gbogbo abala aye wa, ti a ba ti ilẹkun aye wa tabi ilẹkun awọn abala aye wa kan mọ, nitori pe ko ni ti ara rẹ mọ wa lọrun, nṣe ni ki a bẹrẹ si ni fojusọna fun awọn ọta ọkan wa ti O gba wa la lọwọ wọn lati lo anfaani yi lati pada wa sinu aye wa ati lati tun iṣẹ wọn ṣe. Awọn wọnyi ko wa ni kan ilẹkun tabi duro gba aye lọwọ wa ti wọn ba fẹ wọlẹ. Nṣe ni wọn yo wọlẹ boya a fun wọn ni aye tabi a ko fun wọn ni aye.

Iwọ naa wo nkan ti Jesu Oluwa wa sọ nipa eyi: “Nigba ti ẹmi buburu kan ba jade lara eniyan, a maa rin ni aṣalẹ, a maa wa ibi isinmi, ko si ni ri i. Nigba naa ni ẹmi yoo wi pe, ‘Emi yoo pada si ara ọkunrin ti emi ti wa.’ Bi o ba si pada, ti o si ba ọkan ọkunrin naa ni ofifo, a gba a mọ, a si ṣe e ni ọsọ. Nigba naa ni ẹmi esu naa yoo wa ẹmi meje miiran ti o buru ju oun lọ. Gbogbo wọn yoo si wa si inu rẹ, wọn yoo maa gbe ibẹ. Igbẹyin ọkunrin naa a si buru ju ti iṣaaju lọ; Bẹẹ gẹgẹ ni yoo ri fun iran buburu yii pẹlu.” (Matiu 12:43-45) Njẹ o ri bayẹn? Nṣe ni Eṣu ati awọn ẹmikẹmi rẹ ma n fi gbogbo igba wa bi isinmi. Idi kan ṣoṣo ti wọn ko si fi ni ri aye fi aye wa tabi abala aye wa kankan ṣe ile tabi ibi isinmi ni ki wọn ri pe Jesu Oluwa wa ti n gbe ibẹ, ti O si tun n ṣe akoso ibẹ.

Ṣugbọn ti wọn ba wa bẹ aye wa wo, ti wọn ri pe wọn ṣofo tabi pe awọn abala kan ninu wọn ṣofo, ti wọn ko si si ni abẹ iṣakoso ẹnikan ṣoṣo ti O ni aṣẹ ati agbara lori wọn, wọn ko ni fi akoko ṣofo rara lati ko ara wọn jọ lati gba iṣakoso abala aye wa yi. Nṣe wa ni nkan yoo bẹrẹ si ni buru si fun wa ni abala aye wa naa. Ti a ba si tun wa lọra lati tete jẹ ki Oluwa wọle, ki O si gba iṣakoso rẹ, ko ni pẹ rara ti iṣẹ ibi awọn ẹda buburu yi yoo fi tan de awọn abala aye wa miran.

Wayi o, boya iru ipo ti o wa niyi. Dipo ki nkan ma san si fun ọ ni awọn abala aye rẹ ti o ti n ba idojukọ pade, ko ki ṣe wipe o kan n buru si nikan, nṣe ni ibajẹ naa tun ti wa n tan wọnu awọn abala aye rẹ yoku ti o ti wa ni alaafia tẹlẹ. O wa yẹ ki o yẹ ara rẹ wo lati mọ boya o ti ti Jesu sita kuro ninu awọn abala aye rẹ kan. Ti eyi ba si ri bẹ, ọna abayọ kan ṣoṣo ti o wa fun ọ naa ni ki o ronupiwada, ki o si ṣi ilẹkun fun lalai fi akoko ṣofo, ki O ba le ṣe nkan ti o jẹ wipe Oun nikan naa ni O le ṣe, ki O si da alaafia ati ayọ rẹ pada. Ṣugbọn ti o ba ṣe orikunkun, ti o si duro lori pe o ni i fi aye gba iṣakoso rẹ lori gbogbo aye rẹ, nṣe ni ki o mura lati tẹwọgba pupọ iṣẹ Satani si ninu aye rẹ ati lori ọrọ aye rẹ, boya o fun ni aye tabi o ko fun ni aye.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọn kò ní dúró bèrè àyè tàbí gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 27, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 30 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 4:12-31 | ỌJỌ́RÚ 23, BELU 2022

DOWNLOAD E-COPY HERE

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ, a ri wipe ipo ọmọ ni Ọlọrun to gbogbo awa ti a gba Jesu Kirisiti gbọ si dipo ipo ẹru. Nitorina, a gbọdọ yago fun ohunkohun ti o ba le fi wa si abẹ igbekun-ki-gbekun ti Ọlọrun ko fi wa si. Boya ofin Mose ni o tabi awọn asa, iṣeṣe tabi eewọ ajogunba ni, a ko gbọdọ gba wọn laye lati fi wa si abẹ isinru mọ, debi pe awọn ni yoo wa ma dari aye wa dipo ẹmi Ọlọrun. Niwọn igba ti a ti di ọmọ Ọlọrun, O ti fi Ẹmi mimọ rẹ sinu wa lati ṣe wa ni ọmọ ninu ero wa ati lati ma dari aye wa. Ọwọ wa lo wa ku si lati fi aye gba Ẹmi yi lati dari wa ati lati ma tun ṣe fi ara wa si abẹ igbekun ti Ọlọrun ko fi wa si.

MÁ ṢE MÚ OLÓTÍTỌ́ NÍ Ọ̀TA
Wayi o, Pọọlu tẹsiwaju ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi lati ran wọn leti iha ti wọn kọ si i ati si iyinrere ti o mu tọ wọn wa nigba ti wọn kọkọ gbagbọ ati lati jẹ ki wọn mọ bi ọrọ ikuna wọn ninu irinajo igbagbọ wọn ṣe ka lara si. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:

“Ara, mo bẹ yin, ẹ da bi emi nitori emi da bi yin: ẹyin ko ṣe mi ni ibi kan. Ṣugbọn ẹyin mọ pe ninu ailera ara mi ni mo waasu iyin-rere fun yin ni ibẹrẹ. Eyi ti o si jẹ idanwo fun yin ni ara mi, oun ni ẹyin ko kẹgan, bẹẹ ni ẹ ko si kọọ; ṣugbọn ẹyin gba mi bii angẹli Ọlọrun, ani bi Kirisiti Jesu. Njẹ ayọ yin igba naa ha da? Nitori mo gba ẹri yin jẹ pe, bi o ba ṣe e ṣe ẹyin i ba yọ oju yin jade, ẹ ba si fi wọn fun mi. Njẹ mo ha di ọta yin nitori mọ sọ otitọ fun yin bi?” (Gàlátíà 4:12-16)

Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ nibiyi, akọkọ, a ri wipe oun ati awọn ara Galatia ko ni ija ti tẹlẹ. Iyi tunmọ si pe pẹlu ifẹ ati ayọ ni wọn dijọ n lo pọ nigba ti o kọkọ wa sọdọ wọn. Bi a si ti ri ninu ọrọ rẹ, pẹlu ailera ara ni o fi wa sọdọ wọn lati waasu Jesu fun wọn. Irufẹ ailera wo ni o ni ni akoko yi? A ko le sọ. Awọn kan n jẹ ki o ye wa pe ojú didun ni ailera ti o n sọrọ nipa. Ni iwoye ti wọn, ti ko ba ṣe pe ojú n dun, ko ni sọ ninu lẹta yi pe wọn fẹ le yọ ẹyin oju wọn fun nigba ti o wa sọdọ wọn ati pe oun kọ lẹta yi ni gbàgàdà-gbagada si wọn (Galatia 4:15&6:11).

Ṣugbọn ko si ibi kankan ninu lẹta rẹ yoku tabi ninu iwe Iṣe Awọn Apọsiteli ti a ti ri ohunkohun ti o jọ eyi tabi ti a fi idi rẹ mulẹ. Nkan ti Pọọlu kan n gbiyanju lati sọ ni pe bi o tilẹ jẹ pe oun ni awọn ailera kan nigba ti o n wa si ọdọ wọn, ti wọn si ni anfaani lati fi oju alailera wo oun, wọn ko ṣe bẹ ẹ rara. Dipo eyi, nṣe ni wọn gba tọwọ-tẹsẹ, bi igba ti o jẹ wipe angẹli Ọlọrun ni, ti wọn si gbagbọ ninu Jesu Kirisiti, ẹni ti o ran an niṣẹ. Nibi ti wọn si fẹran rẹ ati tọju rẹ de nigba ti o wa laarin wọn, wọn fẹ le yọ ẹyin oju wọn fun. Eyi n jẹ ki o ye wa pe iṣẹ ọwọ Ẹmi Ọlọrun ni atunbi ati isọdọmọ awọn ara Galatia yi. Ko ki i ṣe iṣẹ ọpọlọ, ọgbọn, oye, ijafafa tabi iwunilori eniyan rara.

Ki lo wa ṣẹlẹ si wọn lẹyin igba ti o kuro lọdọ wọn tan? Ki lo wa fa ti oun ti wọn ti fi igbakanri gba tọwọtẹsẹ wa fẹ di ẹni aìjírí fun wọn? Bawo lo ṣe wa sare di ọta wọn? Awọn Juu kan ti wọn tọ wọn wa ni o wa nidi ọrọ naa. Awọn ni wọn fẹ sọ apọsiteli yi di ọta wọn nipa iyinrere odi, iyinrere ti ki i ṣe iyinrere rara ti wọn mu tọ wọn wa. Awọn ni wọn fẹ ko da bi ẹni pe Pọọlu yan wọn jẹ ni, bi ẹni pe ko ba wọn sọ otitọ ọrọ rara nipa igbala ati didi ẹni idalare wọn niwaju Ọlọrun. Ṣugbọn ẹlẹtan ni awọn Juu yi. Nṣe ni wọn kan wa ọmọlẹyin fun ara wọn nipa kikọ ẹyin awọn Keferi ti o gbagbọ si otitọ Jesu ati si awọn apọsiteli otitọ rẹ.

A si ma n ri iru eyi ni igba miran laarin awọn ọrẹ, laarin lọkọ-laya tabi laarin awọn ọmọ Ọlọrun. Ṣa dede ni awọn ti wọn ti n ṣe daradara si ara wọn tẹlẹ, ti wọn n kẹ ara wọn, ti wọn si tun n gẹ ara wọn yoo bẹrẹ si ni ba ara wọn ja tabi yan odì. Ti a ba wa bẹrẹ si ni ṣe iwadi, a o ri pe ẹnikan tabi awọn kan ni o ko si wọn laarin, awọn kan ti ilara tabi owu jijẹ n yọ lẹnu. Awọn yi ko si fẹ rere fun wọn rara. Wọn kan fẹ fi iyapa si arin wọn ni, ki wọn ba le ma ṣe ti wọn. Ti awọn naa ba wa ya alainironu bi awọn ara Galatia, ifẹ ati ete awọn alakoba eniyan yi di dandan ki o wa si imuṣẹ. Eyi yo wa jẹ ki wọn mu oloore wọn, ololufẹ wọn tabi ẹni ti Ọlọrun ran si wọn lati fi otitọ ọrọ rẹ ti yoo ṣe aye wọn ni rere ni ọta.

Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ nipa nnkan wọnyi:

“Wọn n fi itara wa yin, ṣugbọn ki i ṣe fun rere; wọn fẹ lati ya yin kuro lọdọ mi, ki ẹyin le maa wa wọn. Ṣugbọn o dara lati maa fi itara ṣe rere nigba gbogbo, ki i si i ṣe nigba ti mo wa pẹlu yin nikan. Ẹyin ọmọ mi ọwọn, ẹyin ti mo tun n rọbi rẹ titi ẹyin o fi dabi Kirisiti. Iba wu mi lati wa lọdọ yin nisinsinyi, ki emi si yi ohun mi pada, nitori pe mo daamu nitori yin.” (Gàlátíà 4:17-20)

Njẹ o ri bayi? Ilepa awọn Juu ẹlẹkọ eke yi ni lati jẹ ki awọn ara Galatia ni itara fun wọn, bi wọn ti ṣe ni itara fun Pọọlu. Amọ, bi apọsiteli ṣe wa sọ siwaju si, itara wa gbọdọ jẹ fun nkan rere dipo nkan buburu. Ọna ti itara wa ko si fi ni wà fun nnkan buburu ni ki a fi imọ ati oye kun. Ko ki i ṣe gbogbo awọn ti o fẹ ki a ma fi itara tẹle wọn tabi ba wọn lopọ naa ni a le ni nnkan kan tabi omiran i ṣe pẹlu.

Ti a ko ba ni gbagbe, Abusalomu ni asiko kan bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati yi ọkan awọn ọmọ Isiraẹli pada kuro lọdọ baba rẹ nitoripe oun naa fẹ jẹ ọba le wọn lori. Aṣeyọri rẹ wa jẹ ki o ye wa pe pupọ ninu awọn ọmọ orilẹ-ede yi ni ko le da inu ro. Ki ni Abusalomu ṣe fun wọn ti wọn fi ro wipe oun ni o yẹ ki o wa ni ipo ọba ti baba rẹ wa? Ṣe o ti jagun-ṣẹgun fun wọn ri ni tabi ṣe oun ni o gba wọn lọwọ awọn ọta wọn ti o si fun wọn ni isinmi? Rara o. Ko si nkan rere gbogi kan ti wọn le tọka si pe o ti ṣe fun awọn. Amọ nitori arekereke ati ẹtan ọwọ rẹ, o ṣe aṣeyọri lati ya awọn eniyan baba rẹ kuro labẹ iṣedari rẹ. Ti ko ba wa jẹ pe Ọlọrun da si ọrọ naa ni, nnkan ti a n sọ yi kọ ni a ko ba ma sọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 15-18)

Nitorina, ẹnikẹni ti ibaṣepọ ti o fẹ ki a ni pẹlu oun bati tako ifẹ Ọlọrun tabi ọrọ rẹ ko yẹ ni ẹni ti a n tẹle rara. Ẹnikẹni ti o ba si n gbiyanju nipa ọrọ tabi iṣe rẹ lati ba awọn ibaṣepọ wa ti o nitunmọ, ti o si duro lori otitọ Jesu jẹ, ko ki i ṣe ẹni ti a gbọdọ fi ara wa jin fun. Aṣinílọ́nà ni iru ẹni naa jẹ. A si gbọdọ yẹra fun. Eyi gan si ni Pọọlu fẹ ki awọn ara Galatia mọ.

Nṣe wa ni o dabi ẹni pe Pọọlu tun ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni rọbi lori wọn lati tun wọn bi ninu Kirisiti Jesu, ki wọn ba le pada si bi wọn ṣe n ṣe latẹyin wa papọ. O tilẹ tun woye pe nṣe ni o dabi pe ki oun wa pẹlu wọn ni akoko ti o n kọ lẹta yi, ki o ba le ba wọn sọ otitọ ọrọ, ki wọn si ri pe ko ki i ṣe ọta wọn rara. O wa tẹsiwaju lati fi nnkan ti iwe mimọ sọ fun wa nipa ipo awọn ti o wa labẹ ofin ati ti awọn ti ko si labẹ ofin ti o si gba Jesu gbọ niwaju Ọlọrun han wọn nipa sisọ eyi:

“Ẹ wi fun mi, ẹyin ti n wa labẹ ofin, ẹ ko ha gbọ ohun ti ofin wi bi? Nitori a ti kọ ọ pe, Aburahamu ni ọmọ ọkunrin meji, ọkan lati ọdọ ẹru-binrin, ati ọkan lati ọdọ ominira-obinrin. Ṣugbọn a bi eyi ti i ṣe ti ẹru-binrin nipa ti ara: ṣugbọn eyi ti ominira-obinrin ni a bi nipa ileri. Nnkan wọnyi jẹ apẹẹrẹ: nitori pe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeeji, ọkan lati ori oke Sinai wa, ti a bi ni oko-ẹru pẹlu, ti i ṣe Hagari. Nitori Hagari yii ni oke Sinai Arabia, ti o si duro fun Jerusalẹmu ti o wa nisinsinyi, ti o si wa ni oko-ẹru pẹlu awọn ọmọ rẹ. Ṣugbọn Jerusalẹmu ti oke jẹ ominira, eyi ti i ṣe iya wa. Nitori a ti kọ ọ ninu iwe-mimọ pe, Maa yọ, iwọ agan ti ko bimọ: bu si ayọ ki o si kigbe soke, iwọ ti ko rọbi ri; nitori awọn ọmọ obirin naa ti a kọ silẹ yoo pọ ju ti abilekọ lọ. Njẹ ara, ọmọ ileri ni awa gẹgẹ bi Isaaki. Nitori pe, bi eyi ti a bi nipa ti ara ti ṣe inunibini nigba naa si eyi ti a bi nipa ti Ẹmi, bẹẹ si ni nisinsinyi. Ṣugbọn ki ha ni iwe-mimọ wi? Le ẹru-binrin naa jade ati ọmọ rẹ: nitori ọmọ ẹru-binrin ki yoo ba ọmọ ominira-obinrin jogun pọ. Nitori naa, ara, awa ki i ṣe ọmọ ẹru-binrin, bi ko ṣe ti ọminira-obinrin.” (Galatia 4:21-31)

Ki ni koko nkan ti apọsiteli yi n sọ ninu awọn ẹsẹ lẹta rẹ yi? Oun naa ni pe majẹmu ti o mu ofin Mose wa yatọ si eyi ti o sọ wa di ọmọ Ọlọrun. Majẹmu ti ofin Mose n ba ṣiṣẹ fi awọn ti a fun ni ofin yi ni ori oke Sinai si abẹ isinru. Idi si ni pe ijẹgbadun Ọlọrun wọn da lori bi wọn ba ṣe mu ofin yi ni ọkunkundun si. Amọ majẹmu ti o sọ wa di ọmọ Ọlọrun jẹ eyi ti o wa nipa ileri ti Ọlọrun ṣe fun Aburahamu lati bukun fun gbogbo araye nipasẹ iru-ọmọ rẹ. Nitorina isọdọmọ wa ko ni nkankan ṣe pẹlu boya a pa ofin kan mọ tabi a ko pa mọ; dipo eyi, o ni i ṣe pẹlu igbagbọ wa ninu Jesu Kirisiti, iru ọmọ-Aburahamu.

Nkan wọnyi ni Pọọlu wa gbiyanju lati ṣe alaye nipa lilo bi a ti ṣe bi awọn ọmọkunrin meji ti a bi fun Aburahamu lati ṣe akawe tabi apejuwe. Ọmọ eyi ti a bi nipasẹ iṣẹ ọwọ tabi ilakaka Aburahamu jẹ ọmọ ẹru-binrin rẹ, Hagari. Nitorina, ipo ẹru ni a to o si, eyi ti ko fun ni aye lati jẹ ajogun ini baba rẹ Aburahmu. Ṣugbọn ọmọ ekeji ti a bi fun ọkunrin yi jẹ eyi ti a bi nipasẹ ileri Ọlọrun fun oun ati aya rẹ, Sara. Oun si wa ni ajogun ini rẹ ati pe nipasẹ rẹ ni Jesu Kirisiti ti ṣe wa.

Eyi si njẹ ki o ye wa pe awọn ti wọn ba ro pe ilakaka awọn tabi bi awọn ṣe duro ṣinṣin ninu ofin Mose tabi ofin ara ẹni si ni yoo jẹ ki wọn di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun kan n tan ara wọn jẹ ni. Ipo ẹru ni wọn yoo ma fi gbogbo igba wa niwaju rẹ. Ṣugbọn awọn ti o ba gba Ọlọrun ati ohun ti O sọ nipa igbala ọkan wọn gbọ, ti wọn si tẹle, yoo ri aanu gba, a o si jẹ ki wọn fi iṣọdọmọ ṣe ere jẹ. Ṣe inu awọn ti o wa n lakaka lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ọwọ wọn, ti ko si bọ si, yoo wa dun si eyi bi? Ko le dun si rara. Idi niyi ti awọn ti o gbọkanle iṣẹ ọwọ wọn ṣe ma n fi ọpọ igba ṣe inunibini awọn ti o di ẹni idalare nigba igbagbọ wọn ninu Kirisiti dipo iṣẹ ọwọ wọn.

ỌRỌ IPARI
A le mu awọn ti Ọlọrun yan lati ṣe aye wa ni aṣẹpe niwaju rẹ, paapaa julọ ninu ijọ rẹ, ni ọta ti a ko ba ni imọ ati oye ọrọ rẹ ti o ye kooro, ki a si tun ma ṣe aṣaro ninu rẹ. Ṣe eyi yoo wa ṣe wa ni oore bi? Rara o! Dipo bẹẹ, nṣe ni yoo fi wa si ipo ẹni ti wọn tun gbọdọ bẹrẹ iṣẹ isọdọmọ ati iduroṣinṣin ninu igbagbọ le lori.

IBEERE

  • O yẹ ki a farabalẹ ki a to bẹrẹ si ni fi itara tẹle ẹnikẹni. Ṣe alaye.
  • Kini o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 4:12-31 | ỌJỌ́RÚ 23, BELU 2022 Read More »

Pẹlu-pẹlu iṣipẹ wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 20, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 29

Olufẹ: kaabọ sinu ọṣẹ miran ninu oṣu Belu 2022. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma ṣe jẹ ki ọkan rẹ tẹwọgba oríkunkun yowu ti yoo ṣi ṣi ilẹkun aye rẹ silẹ fun iparun ti ko ni ṣi atunṣe fun, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọrọ Ọlọrun sọ wipe, “Ẹni ti o si n ṣori kunkun lẹyin ọpọlọpọ ibawi yoo parun lojiji laisi atunṣe.” (Ìwé Òwe 29:1) O wa ṣeni laanu pe ọpọ loni, pẹlupẹlu ninu ijọ, ni o jẹ olorikunkun. Awọn wọnyi ko ki i fi igba kankan ṣetan lati gba ibawi. Nitorina, ko si nkan ti o sọ fun wọn nipa ẹṣẹ tabi ikuna wọn, wọn ko ni ronupiwada. Awọn miran lara wọn ko tilẹ fẹ gbọ tabi wo ohun yowu ti o fẹ sọ lori aṣiṣe wọn. Idi si ni pe wọn ni agigdi, wọn si jẹ olorikunkun.

Wayi o, pẹlu nkan ti Solomọni sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, nkan ẹyọkan ṣoṣo ti iru awọn eniyan yi le ma reti gẹgẹ bi ere fun orikunkun wọn naa ni iparun ojiji, eyi ti ko ni ni atunṣe rara. Eyi tunmọ si pe ko si nkan ti ẹnikẹni yoo le ṣe fun wọn tabi ṣe lati gba wọn la nigba ti iparun ba de. Dandanlá ni fun wọn lati parun.

Bẹẹni, otitọ ni pe Ọlọrun ko fẹ iku ẹlẹsẹ ṣugbọn ironupiwada ati igbala wọn (Iṣikiẹli 18:32). Otitọ si tun ni pe O ma n mu suuru fun ẹlẹṣẹ, ki wọn ba le ṣe amulo awọn anfaani ti O n mu tọ wọn wa lati ronupiwada (2Peteru 3:9). Ṣugbọn ti ẹlẹṣẹ ba wa ya olorikunkun nkọ, ti ko si fẹ lati ronupiwada, ki ni ki Ọlọrun ṣe? Ṣe yoo tunbọ ma fi ara da radarada ti wọn n ṣe ni? Irọ o! Nigba ti o ba ya, nṣe ni yoo jẹ ki wọn jẹ ere ẹṣẹ wọn lẹkunrẹrẹ.

O wa seeṣe ki ẹnikan sọ wipe, “Ti a ba wa ri alagbawi fun olorikunkun eniyan nkọ, ẹni ti o n gbadura si Ọlọrun lati ṣaanu fun un? Ṣe Ọlọrun yoo si jẹ ki a pa wọn run sibẹsibẹ?” Lotitọ, Ọlọrun tikararẹ ti sọ wipe bi o tilẹ jẹ pe alagbawi kan ṣoṣo ni o n gbadura fun ẹlẹṣẹ kan tabi orilẹ-ede kan, Oun yoo bu ọla fun alagbawi naa, Oun yoo si yipada lati ma pa orilẹ-ede naa run (Isikiẹli 22:30). A si ri apẹrẹ eyi ni bi O ti se tẹti si iṣipẹ Wolii Amosi fun orilẹ-ede Isiraẹli. Ẹmeji ọtọọtọ ni eniyan Ọlọrun yi bẹ ẹ lati ma pa Isiraẹli run. O si gbọ tirẹ (Amosi 7:1-6). Egbe wa ni fun ọkunrin naa, obinrin naa tabi orilẹ-ede naa ti ko ni ẹnikẹni lati ṣipẹ adura fun. Idi si ni pe o ṣeeṣe ki iparun bori rẹ lairotẹlẹ.

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ma n bọwọ fun iṣipẹ awọn eniyan rẹ fun awọn ẹlẹṣẹ, ti awọn ẹlẹṣẹ ba wa kọ lati ronupiwada nkọ, akoko n bọ ti wọn yoo nilo lati tẹwọgba ere ẹṣẹ wọn. Ti akoko naa ba wa de, iṣipẹ yowu ti a ba n ṣe fun wọn yoo kuna, iparun ti wọn si ti n bọ ninu rẹ yoo wa sori wọn lojiji ati lalai si ọna abayọ. Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe o tẹramọ iṣipẹ fun orilẹ-ede Isiraẹli, nigba ti o to asiko kan, Ọlọrun sọ fun Amosi pe Oun ko ni dariji wọn mọ — Oun gbọdọ pa wọn run. Ki ni idi? Wọn ya olorikunkun. (Wo: Amosi 7:7-9)

Lafikun, a ri bi Aburahamu ṣe fi itara ṣipẹ fun ilu Sodomu ati Gomora ninu bibeli. Ọkunrin yi duro si arin awọn ara ilu meji yi ati ibinu Ọlọrun, o si n bẹbẹ fun aanu fun wọn, bi o tilẹ jẹ wipe olododo mẹwa pere ni a ri ninu wọn. Ọlọrun si gbọ tirẹ. Ṣugbọn ṣe O wa ri olododo mẹwa ninu wọn? Rara o! Dipo eyi, idile kan ṣoṣo ti ko ni ju eniyan mẹrin lọ ni o ri ninu wọn. Nitorina, pẹlupẹlu iṣipẹ Aburahamu fun wọn, O pa Sodomu ati Gomora run nigba ti wọn ko reti iparun, O si da kiki Lọọti ati idile rẹ si. (Wo: Jẹnẹsisi 18&19)

O wa jẹ nkan ibanujẹ pe a ri awọn eniyan loni ti wọn n ṣiwawu, ti wọn si tun gbọkanle iṣipẹ awọn obi wọn tabi ti awọn eniyan Ọlọrun kan. Nkan ti wọn ko mọ ni pe ti wọn ko ba yi iwa wọn pada, ki wọn si dẹkun orikunkun wọn, akoko n bọ ti iparun wọn ko ni sun mọ ṣugbọn ti yoo bori wọn lojiji. Nigba naa ni wọn yoo parun lalai si atunṣe ati pẹlupẹlu iṣipẹ awọn eniyan Ọlọrun. Ti iwọ naa ba wa ri bayi, ti iwọ naa ba ya olorikunkun ati ẹni ti ko ṣetan lati gba ibawi, bi o ti wu ki o mọ niwọn to, afaimọ ki o ma jẹ wipe nṣe ni o n pese ara rẹ silẹ fun iparun ojiji – iparun ti ko ni ni atunṣe. Nitorina, ronupiwada nisisiyi ki o to pẹju. Ki Ọlọrun si ran ọ lọwọ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Pẹlu-pẹlu iṣipẹ wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 20, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 29 Read More »

Àkókò díẹ̀ náà ni yóò gbà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Belu 13, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 28

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesus Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2022. Mo si gbadura pe ki a ya ọkan rẹ ya oniruuru agabagebe ninu irin rẹ pẹlu Ọlọrun, ki a ma ba ṣe afihan rẹ lọja kan gẹgẹ bi eke onigbagbọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Oniwaasu kan sọ eyi ninu ipade kan ti mo wa nibẹ: “Baba mi ninu Oluwa sọ fun pe ko si nkan ti o n lepa ninu iṣẹ iranṣẹ ti o ko ni ri. Ti o ba jẹ owo ni o n lepa, iwọ yoo ri. Ti o ba jẹ obirin ni o n lepa, iwọ yoo ri wọn. Ti o ba jẹ iyi ni o n lepa, iwọ yoo ri. Ti o ba si jẹ pe Ọlọrun naa ni o n lepa, iwọ yoo ri pẹlu. Ohunkohun ti o ba ri ni i ṣe pẹlu ohun ti ọkan rẹ n wa.” Mo wa gbagbọ pe otitọ ni eleyi jẹ lọna ti o pọ. Ohun ti awọn eniyan ba n lepa ninu ijọba Ọlọrun naa wọn yoo fẹ ẹ ri.

Amọ ṣa o, ṣe ohun ti wọn ba ri yoo ka oju wahala, akoko, okun ati nkan ini ti wọn ti ko sori rẹ? Ṣe yoo fun ọkan wọn ni itẹlọrun ti wọn n wa? Ṣe ohun ti wọn ri yi yoo fun wọn ni oriyin lọdọ Ọlọrun tabi idalẹbi ni yoo fun wọn lọdọ rẹ?

Pọọlu, nigba ti o n kọwe si awọn ara Filipi, sọ eyi: “Otitọ ni pe awọn ẹlomiran tilẹ n fi ija ati ilara waasu Kirisiti, ṣugbọn awọn ẹlomiran si n fi inu rere ṣe e.” (Filipi 1:15) Nitorina, lati igba aye apọsiteli yi ni a ti n ri ninu ijọ awọn eniyan ti o n sin Ọlọrun pẹlu ẹmi ilara ati ìfagagbága. Ko wa yẹ ki o ya ọ lẹnu ti o ba ri ninu ijọ awọn ti o n ṣe ilara iwulo rẹ ninu ijọ ati ti wọn n lakaka lati fi han awọn miran pe awọn sàn ju ọ lọ tabi lati gba aye rẹ. Awọn baba-nla wọn ninu ijọ naa ti ṣe iru ẹ sẹyin.

Lafikun, Peteru naa, ninu lẹta rẹ keji, sọrọ lori awọn idi melokan ti awọn eniyan ṣe ma wa ninu ijọ ati ti wọn ṣe ma n fi ara wọn han gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun. Bi o ti ṣe fi han wa, awọn miran wa ninu ijọ nitori ojukokoro, awọn wọnyi ri iṣẹ iranṣẹ fun Ọlọrun gẹgẹ bi ọna lati sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀. Awọn miran, ẹwẹ, wa ninu ijọ nitori agbere. Awọn wọnyi ri inu ijọ gẹgẹ bi ibikan ti anfaani pọ si jaburata lati tan awọn alaimọkan obinrin ati ọkunrin jẹ ati lati ba aye wọn jẹ ninu iṣekuṣe. (Cf. 2Pétérù 2)

Ni kukuru, idi yowu ti iwọ ko ba a fi wa ninu ijọ ati ti iwọ ko ba a fi fi ara rẹ jin lati ṣin Ọlọrun, akoko yoo fi han. Nkan ti mo n sọ ni pe akoko ko ni pẹ ṣe afihan idi gan ti o fi wa ninu ijọ fun gbogbo eniyan lati ri. Mi o si sọrọ nipa nkan ti yoo ṣẹlẹ ni ọjọ idajọ; ṣugbọn mo n sọrọ nipa nkan ti yoo ṣẹlẹ lori ilẹ-aye yi.

Ranti Gehasi. Ranti pe akoko diẹ naa lo gba ti o fi han daju pe ni gbogbo igba ti o fi n tẹle Eliṣa, eniyan Ọlọrun, kaakiri, ọrọ̀ aye yi ni o n wa. Si tun ranti Judasi Isikariọtu. Ranti pe bi o tilẹ fi ojukokoro inu rẹ pamọ fun awọn eniyan fun ọdun mẹta ati aabọ ti o fi n tẹle Jesu lọsiwa ati lọsẹyin, akoko kan de ti ojukororo inu rẹ fi ara han fun gbogbo eniyan lati ri. Ṣe awọn ọkunrin yi wa ri itẹlkaọrun ti wọn n wa kiri nipasẹ awọn nkan wọnyi ti wọn ri gba? Rara o! Nkan ti Gehasi ri ni ẹtẹ. Nkan ti Judasi Isikariọtu si ri ni iku. (Wo: 2Awọn Ọba; Johanu 13)

Nibakanna, ti ọkan iwọ naa ko ba tọ ninu iṣẹ sin rẹ si Ọlọrun, ti ohun ti o si n wa ninu ijọ ko ki i ṣe Ọlọrun funrarẹ, ohun yowu ti o ba ri gba ko ni fun ọ ni itẹlọrun. Ohun yowu ti o le jẹ, kiba ṣe owo ni, iyi ni, ipo ni, obinrin ni, ọkunrin ni, iṣẹ ni tabi iwosan ni, ko le fun ọ ni itẹlọrun. Dipo eyi, o tilẹ le wa jẹ wipe nkan yi gan ni yoo pada ke lori rẹ bi ẹsan, ti yoo si pa ọ run. Nitorina, ṣọ ara rẹ, ki o si ri daju pe ete rẹ ninu ijọba Ọlọrun ati lori iṣẹ isin rẹ fun un tọna. Njẹ ki Oun tikararẹ ṣe ọkan rẹ yẹ pẹlu rẹ lati iṣinsinyi lọ ati titi lailai, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọṣẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkókò díẹ̀ náà ni yóò gbà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Belu 13, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 28 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 4:1-11 | ỌJỌ́RÚ 09, BELU 2022

DOWNLOAD E-COPY

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ wa ti o gbẹyin ninu iwe Galatia, a ri idi ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ Isiraẹli ni ofin lati ọwọ Mose. Ki si ni idi naa? Idi naa ni ki o ba le jẹ olukọni tabi atukọ fun wọn ninu ifẹ rẹ titi iru-ọmọ Aburahamu ti yoo gba araye la yoo fi de lati sọ wọn di ẹni irapada ati idalare niwaju Ọlọrun. Iru-ọmọ Aburahamu ti a si n sọ yi ni Kirisiti ti O wa lati ku fun ẹṣẹ araye, ki ileri ibukun Ẹmi Ọlọrun ba le jẹ ti wa. Niwọn igba ti Kirisiti si ti wa, iṣẹ ofin ti pari. Iṣẹ igbagbọ ni o ku ba yi, iṣẹ igbagbọ ninu Kirisiti ti a ran wa fun igbala ati isọdọmọ gbogbo araye. Bi Pọọlu ṣe fi ye wa, nipa igbagbọ ninu Ọlọrun ni Aburahamu ṣe ri ileri bibọ Kirisiti gba. Awọn ti o ba wa fẹ di ajogun ileri ibukun Ẹmi Ọlọrun ti a ṣe fun Aburahamu lati ipasẹ Kirisiti naa gbọdọ fi igbagbọ wọn ninu rẹ han. Ti wọn ba si ti fi igbagbọ yi han, wọn yoo di ẹni irapada, ẹni idalare ati ọmọ Ọlọrun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun, yala Juu niwọn tabi Keferi, ọkunrin ni wọn tabi obinrin, ọmọde ni wọn tabi agbalagba.

ỌMỌ DÍPÒ ẸRÚ

Pọọlu, ninu abala lẹta yi ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi, tun wa tẹsiwaju lati tẹ ẹ mọ awọn ara Galatia leti pe wọn ti di ọmọ Ọlọrun, wọn ko si nilo lati ba a lopọ bi ẹru mọ. O wa fi ọna ti awọn ọmọde, ti wọn jẹ arole tabi ajogun nkan ini awọn obi wọn ṣe ma n de ipo wọn gẹgẹ bi ajogun nitootọ, ṣe apejuwe bi awa, yala Juu niwa ni o tabi Keferi, ṣe di ajogun ileri ati ipese Ọlọrun fun wa. Nkan ti o sọ niyi:

“Njẹ mo wi pe, niwọn igba ti arole naa ba wa ni ewe, ko yatọ ninu ohunkohun si ẹru bi o tilẹ jẹ oluwa ohun gbogbo; Ṣugbọn o wa labẹ olutọju ati iriju titi fi di akoko ti baba ti yan tẹlẹ. Gẹgẹ bẹẹ si ni awa, nigba ti awa wa ni ewe, awa wa labẹ ide awọn ẹmi agbaye: Ṣugbọn nigba ti akoko kikun naa de, Ọlọrun ran ọmọ rẹ wa, ẹni ti a bi ninu obinrin, ti a si bi labẹ ofin, Lati ra awọn ti n bẹ labẹ ofin pada, ki a le di ọmọ Ọlọrun. Ati nitori ti ẹnyin ti n ṣe ọmọ, Ọlọrun ti ran Ẹmi ọmọ rẹ wa sinu ọkan yi, ti n ke pe, Aba! Baba! Nitori naa iwọ ki i ṣe ẹru mọ, bi ko ṣe ọmọ; bi iwọ ba si jẹ ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kirisiti.” (Gàlátíà 4:1-7)

Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ silẹ yi, nkan akọkọ ti a ri ni wipe ifẹ Ọlọrun ni pe ki gbogbo eniyan wa ni ipo ọmọ rẹ. A si ri awọn abala bibeli ti o tilẹ fi ye wa pe Ọlọrun ti yan wa lati jẹ ọmọ rẹ ati ajogun rẹ ki a to fi ipile aye yi lọlẹ (Efesu 1:3-6). Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti ṣe mọ, ko ki ṣe ọjọ ti a ba bimọ naa ni ọmọ naa yoo bẹrẹ si ni ṣe akoso nkan ini wa ti a fẹ fi silẹ fun gẹgẹ bi ogun rẹ. Ọmọ naa gbọdọ dagba naa, ki o si to oju bọ ki o to di pe a o fi akoso ogun tabi ini rẹ le lọwọ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o ṣe ara rẹ leṣe tabi ki o ba nkan jẹ, bi itan ọmọ oninakuna ti Jesu sọ ti ṣe fi ye wa (Luuku 15:11-32).

Wayi o, ni akoko ti ọmọ yi ba n dagba, a o fi si abẹ isakoso oniruuru olukọ, ti yoo maa tọ sọna, ti yoo si ma ṣe idari rẹ titi yoo fi to oju bọ lati le ṣe akoso ohunkohun ti a ba fa le lọwọ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ. Nitorina, ni akoko ti eyi ba n ṣẹlẹ, ọmọ yi ko yatọ si ẹru. Pọọlu wa n jẹ ki o ye wa pe bi o ti ri gẹlẹ fun awa naa ni eyi. Bi o tilẹ jẹ wi pe ipo ọmọ ati ajogun ni Ọlọrun to wa si ni ọkan rẹ, ko le sọ wa di ọmọ ati ajogun rẹ nitootọ ti a ko ba san gbogbo gbesẹ ẹṣẹ wa. Nitorina, O fi awa ti a jẹ Kerefi silẹ gẹgẹ bi ẹru  labẹ oniruuru aṣa, ilana, èèwọ̀, ìṣẹ̀ṣe ati ironu ti awọn ẹmikẹmi agbaye yi fi lọlẹ fun wa. Bakan naa, O fi awọn Juu silẹ sabẹ ofin ati ilana Mose gẹgẹ bi alakoso igbe aye wọn. O si jẹ ki eyi ki o wa bẹẹ titi akoko yoo fi too fun iru-ọmọ obinrin, ti si i tun ṣe iru-ọmọ Aburahamu, ti O fẹ ti ipasẹ rẹ san gbese ẹsẹ wa yoo fi de (Jẹnẹsisi 3:14-15). 

Nigba ti akoko si to, Kirisiti ti a n sọrọ rẹ yi de, O ku fun ẹsẹ wa ki a ba le bọ lọwọ gbogbo awọn nkan ti o mu wa ni ẹru, O si tun ra awọn ọmọ Aburahamu ti o wa labẹ ofin Mose naa pada, ki a ba le sọ awọn naa di ọmọ Ọlọrun nitootọ. Gbogbo awa ti a wa gbaagbọ, yala Juu niwa ni o tabi Heleni, ni a ti tun bi, ti a si ti sọ di ọmọ Ọlọrun. Idi si niyi ti Ọlọrun ṣẹ ran Ẹmi rẹ sinu wa lati ṣe wa ni ọmọ ninu ọkan wa. Nitorina ni ko ṣe jẹ kayefi fun wa lati pe ara wa ni ọmọ Ọlọrun – Ẹmi ọmọ rẹ n gbe inu wa, O si n mu wa ni ọkan le lati pe ni ‘Aba, Baba’, eyi ti o tunmọ si ‘Baba, Baba mi’.

Oju wo ni o wa yẹ ki a fi ma wo ara wa bayi? Oju ọmọ Ọlọrun ni! Oju arole ati ajogun ohun gbogbo ti Ọlọrun ni, paapaa julọ awọn ini rẹ ti ko ki i dibajẹ, ni o yẹ ki a ma fi wo ara wa. A ko gbọdọ tun wo ara wa bi ẹru mọ tabi ki a tun gbiyanju lati fi ara wa sabẹ ofinkofin tabi ilanakilana tabi aṣakaṣa gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun tabi lati jẹgbadun ipese rẹ fun wa. Ajogun awọn ini rẹ ni a jẹ. Nitorina, a kan nilo lati bere ati lati nawọ gan ohun ti o jẹ ti wa ni aye yi ni, ki a si bẹrẹ si ni jẹgbadun rẹ.

Ailoye eyi ni o wa fa ti ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun fi ro wipe boya nipasẹ adura gbigba wọn, awẹ gbigba wọn, ififunni wọn tabi igbe aye iwa mimọ wọn ni awọn yoo ṣe di ẹni idalare niwaju Ọlọrun tabi ri nkan gba lọwọ rẹ. Ṣugbọn awẹ gbigba, adura gbigba, sisan idamẹwa ati ọrẹ tabi igbe aye iwa mimọ kankan ko le jẹ ki o lẹtọ si ogun ti ko ba ki i ṣe tirẹ. Awọn ti o ba jẹ ọmọ ẹni ti o ni ogun nikan ni o lẹtọ si ogun rẹ. Nitorina, nkan ti a nilo lati jẹ igbadun ipese Ọlọrun fun awọn ọmọ rẹ, boya ni aye yi ni o tabi ninu ayeraye ti o n bọ, ni ki a jẹ ọmọ rẹ.

Idi si niyi ti o fi jẹ pe nkan akọkọ ti Ọlọrun ṣe fun wa lati mu wa yẹ lati jẹ alabapin ogun awọn ọmọ rẹ ni pe O sọ wa di ọmọ rẹ nipa titun wa bi (Kolose 1:12). Gbogbo awa ti a si jẹ ọmọ rẹ ni a tun jẹ ajogun ini rẹ. Ohun ti a wa nilo ni ẹkọ lori awọn nkan ti o jẹ ti wa ati ẹkọ lori bi a ṣe le ṣe amulo wọn fun igbaye-gbadun wa. Ko ki i ṣe ofin Mose tabi ilana adayeba kankan ni a nilo. A si ti wa fun wa ni Ẹmi Mimọ lati fun wa ni imọ ati oye awọn nkan wọnyi (1Kọrinnti 2:7-16). Ọwọ wa lo wa ku si lati kẹkọ labẹ Ẹmi yi ati lati ṣẹ amulo ohunkohun ti O ba kọ wa.

Awọn nkan wọnyi ni o fa a ti Pọọlu ṣe wa tẹsiwaju lati sọ eyi fun awọn ara Galatia:

“Ṣugbọn nigba naa ti ẹyin ko tii mọ Ọlọrun ẹyin ti n sinru labẹ awọn ẹda ti ki i ṣe Ọlọrun. Ṣugbọn nisinsinyi, nigba ti ẹyin ti mọ Ọlọrun tan, tabi ki a kuku wi pe, nisinsinyi ti Ọlọrun ti wa yin ri, ee ha ti ri ti ẹ fi tun yi pada lati maa sinru fun awọn alailera ati alagbe ẹda ti aye yii? Ẹyin n kiyesi ọjọ, ati oṣu, akoko ati ọdun. Ẹru n ba mi, ki o ma baa ṣe pe lasan ni gbogbo laalaa ti mo ti ṣe lori yin.” (Gàlátíà 4:8-11)

Apọsiteli  yi n woye pe ṣe ko ki i ṣe pe laalaa rẹ lori awọn ara Galatia yi yoo ja si asan pẹlu bi wọn ti ṣe n ba ọrọ igbagbọ wọn lọ. Idi si ni pe wọn tun ti pada bẹrẹ si ni kiyesi awọn ọjọ, oṣu, akoko ati awọn ọdun kan, gẹgẹ bi a ti la a kalẹ ninu ofin Mose. Ṣugbọn wọn ti pa gbogbo awọn nkan ti o farapẹ iwọnyi, ti o si sọrọ mọ ẹsin abalaye wọn ti tẹlẹ, nigba ti wọn gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala wọn. Ki wa ni wọn n reti lati jere nipa pipada sori wọn? Ṣe awọn nkan wọnyi ni yoo sọwọn di ọmọ Ọlọrun ni tabi ṣe awọn ni yoo jẹ ki wọn ri nkan gba lọwọ rẹ?

O si wa ṣeni laanu pe iru ipo ti ọpọ awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun loni wa ni yi. Bi o tilẹ jẹ pe a jẹ ọmọ rẹ, a ko mu ipo wa gẹgẹ bi ọmọ rẹ ni pataki. A ṣi lero pe titẹle ofin Mose ati awọn nkankan ti a ba ṣe ni yoo jẹ ki a di ẹni itẹwọgba niwaju rẹ tabi ti yoo jẹ ki a di ajogun ipese rẹ. Yatọ si eyi, ọpọlọpọ wa ni ko i ti gbe awọn aṣa, eewọ ati ilana atọwọdọ ti a ba laye, ti ko si ni ere kankan lori ju danu. A si tun n jẹ ki awọn nkan wọnyi dari aye wa ati ibaṣepọ wa pẹlu eniyan ati Ọlọrun. Ki wa ni Jesu ku fun wa fun? Ki wa ni O sọ wa di ọmọ Ọlọrun ati ajogun rẹ fun? Njẹ iku ati laalaa rẹ lori wa ko ni jasi asan bayi?

ỌRỌ IPARI

Wiwa Jesu lati ku fun wa ati lati sọ wa di ọmọ Ọlọrun ni opin ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ofin Mose ati awọn ẹsin ati aṣa abalaye wa. Nitorina, nkan ti o yẹ ki a gbajumọ ni bi a o ṣe mọ awọn ohun ti o jẹ ti wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, ti a o si bẹrẹ si ni ṣe amulo wọn lati gbe igbe aye olododo ati ẹni ti a ti da lare niwaju rẹ.

IBEERE

–              Ṣiṣe iṣẹ lati jẹ agojun ipese Ọlọrun ati lati di ẹni idalare niwaju rẹ ko le sọ wa di ajogun ini rẹ. Ṣe alaye.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 4:1-11 | ỌJỌ́RÚ 09, BELU 2022 Read More »

Sìn-ín pẹ̀lú ìjáfáfá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 06, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 27

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Belu 2022. Mo gbadura pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba sin Ọlọrun pẹlu ijafafa ati tọkantọkan, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ko fẹ ki awọn eniyan rẹ kan sin-in nikan; O tun fẹ ki ijafafa tabi imura-kankan ma farahan ninu iṣẹ isin wọn. Ko fẹ ki o gba wọn ni ayeraye lati pa ọkan pọ lati sin-in tabi lati bẹrẹ si ni ṣiṣẹ sin-in. Ki ni idi? Idi ni pe ti a ko ba jafafa lati ṣe awọn nkan ti O fẹ ki a ṣe, awọn kan ti O fẹ ti ipasẹ wa bukunfun le lailai padanu ibukun rẹ lẹyin-ọ-rẹyin. Ti eyi ba si waye, yatọ si pe O le da seria fun wa nitori pe a jẹ ki awọn miran padanu ibukun rẹ, awa gan paapaa yoo padanu ohun yowu ti ko ba jẹ ere fun wa ka sọ wipe a ṣe kankan lati ṣe ifẹ rẹ ni.

Nitorina, ma lọ ro wipe o ni gbogbo akoko laye yi lati pese ara rẹ lati ṣin Ọlọrun. O ko ni. Ti o ko ba si tete gbajumọ ohun yowu ti O ba sọ fun ọ lati ṣe fun tabi ti ọwọ rẹ ba ba lati ṣe fun, asiko naa n bọ ti yoo ti pẹ ju fun ọ lati ṣe ohun naa ti o ko ba ti ṣe fun. Ranti pe Jesu sọ wipe, “Awa ni lati ṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, niwọn igba ti o ba ti jẹ ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ.” (Johanu 9:4) Njẹ iwọ wa fẹ duro ki oru de ba ọ nibi ti o ti n wọ ẹsẹ rẹ nilẹ nidi iṣẹ Oluwa bi?

Nitemi o, mi o fẹ ki o ri bẹ fun mi. Dipo eyi, mo fẹ tẹle awọn apẹrẹ ti a fun wa ninu bibeli nipa awọn ti o jafafa lati ṣe idamọ bi Ọlọrun ṣẹ fẹ ki wọn sin Oun, ti wọn si tun jafafa lati bẹrẹ si ni ṣin in. Mo mọ daju, fun apẹẹrẹ, pe o ti gbọ nipa ọkunrin were ara Gadara kan ti a mẹnuba ninu bibeli ati bi Jesu Oluwa ṣe tu ṣilẹ kuro lọwọ arun ọpọlọ. Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, ni kete ti ọkunrin yi ri pe a ti wo oun san ni o ti bẹrẹ si ni bẹ Jesu lati jẹ ki oun tẹle lọ si ibi yowu ti O ba n lọ. Ṣugbọn Oluwa sọ fun pe ki o ma tẹle Oun, amọ ki o lọ sọ fun awọn ẹbi rẹ bi Ọlọrun ti ṣe ṣaanu fun to. (Wo: Máàkù 5:1-19)

Ṣe ọkunrin yi wa ṣe bi Oluwa ti pasẹ fun bi tabi ko ṣe bẹẹ? O ṣe bẹẹ gẹgẹ. O tilẹ tun ṣe ju nkan ti a sọ fun lọ. Lalai fi akoko ṣofo rara, o jade lọ kaakiri agbegbe kan ti a n pe ni ‘Dekapolisi’, eyi ti o tunmọ si ‘Ilu mẹwa’, o si n sọ ẹri rẹ fun gbogbo ẹni ti o ba bikita lati gbọ ọ (Máàkù 5:20). Nkan ti a n pe ni ijafafa ni sisin Oluwa niyẹn. Eyi si ni a n pe wa lati ṣe awokọse rẹ.

Lafikun, bibeli tun sọ fun nipa arabinri oniṣowo kan ni ilu Filipi ti a n pe ni Lidia ati nipa bi o ti se di atunbi lati ipasẹ iṣẹ-iransẹ Pọọlu Apọsiteli (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:13-15). Bi a tun ṣe wa sọ siwaju si nipa rẹ, ọjọ gan ti o di atunbi naa ni o bẹrẹ si ni sin Oluwa pẹlu Pọọlu ati awọn akẹgbẹ rẹ. O fi ilegbe ọ̀fẹ́ lọ wọn ninu ile rẹ lọjọ yi kanna, o si duro le ọrọ rẹ lori pe wọn gbọdọ tẹwọgba ile naa, ti o ba jẹ pe wọn gba nitootọ pe oun ti di atunbi. Abalajọ ti Pọọlu, nigba ti o n kọ lẹta si ijọ Filipi, fi sọ eyi nipa wọn, “Ninu gbogbo adura mi fun-un yin, emi n fi ayọ gbadura, nitori idapọ yin ninu iyin rere lati ọjọ kin-in-n wa titi di isinsyinyii.” (Fílípì 1:4-5)

Wayi o, irufẹ ijafafa ninu iṣẹ-iransẹ ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe awokọṣe rẹ ni eyi. O fẹ ki a jafafa lati waasu ọrọ rẹ, ki a jafafa lati gbadura fun awọn ẹlomiran, ki a jafafa lati fifun iṣẹ rẹ, ki a si tun jafafa lati mojuto awọn eniyan rẹ. Irufẹ iṣẹ isin yi ni o si dun mọ ninu, ti O si ma n pin ere fun awọn eniyan le lori, iṣẹ-isin ti a ṣe pẹlu ijafafa. Adura mi wa ni pe ki a kọ ọkan rẹ, ki a si tun fun ni okun lati ma fi igba gbogbo jafafa lati ṣe ohunkohun ti Ọlọrun ba fẹ ki o ṣe lati sin-in, ki o ma ba tun lailai padanu ere iṣẹ isin rẹ mọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Sìn-ín pẹ̀lú ìjáfáfá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 06, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 27 Read More »