Ọ̀nà láti jẹ́ pípamọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 05, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 40
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Èrèlé 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun pa ọ mọ kuro ninu gbogbo ibi awọn ọjọ ikẹyin yi ti o n pa igbagbọ ati aye awọn eniyan run. Amin.
Mo gba adura yi si Ọlọrun fun ọ nitoripe mo mọ pe ifẹ rẹ ni lati pa gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ mọ kuro ninu idibajẹ ati awọn ibi ti o wa ninu awọ ọjọ ikẹyin yi. Bibeli tilẹ sọ fun wa pe a le gbẹkẹle lati pa wọn mọ nitori olododo Ọlọrun ni o jẹ (1Tẹsalóníkà 5:23-24). Ṣugbọn ọtọ ni ki Ọlọrun mura giri lati pa aye ati igbagbọ wa mọ; ọtọ tun si ni ki awa naa fi ara wa si ibi ti yoo ti le ṣe bẹ ẹ. Ti o ko ba fi ara rẹ si ibi ti Ọlọrun ti le pa aye ati igbagbọ rẹ mọ, o ko le wa ni ipamọ. Eyi ko si ki ṣe epe. Otitọ pọnbele ni.
Bawo wa ni o ṣe le fi ara rẹ si ibi ti Ọlọrun ti le pa ọ mọ kuro ninu awọn idibajẹ awọn ọjọ ikẹyin yi? O le ṣe eyi nipa fifi ara rẹ jin fun ọrọ otitọ rẹ, yala o rọrun fun ọ lati tẹwọgba tabi ko rọrun fun ọ lati tẹwọgba. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si Timoti, sọ eyi:
“Nitori naa mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kirisiti Jesu, ẹni ti yoo ṣe idajọ alaaye ati oku, ati nitori ifarahan rẹ ati ijọba rẹ. Waasu ọrọ naa, ṣe aisinmi ni akoko ti o wọ, ati akoko ti ko wọ; baniwi, ṣe itọni, gbani niyanju pẹlu ipamọra ati ẹkọ gbogbo. Nitori pe igba yoo de, ti wọn ki yoo le gba ẹkọ ti o ye kooro, ṣugbọn bi wọn ti jẹ ẹni ti eti n rin, wọn o lọ ko olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Wọn o si yi eti wọn pada kuro ninu otitọ, wọn o si yipada si itan asan.” (2Tìmótíù 4:1-4)
Ki ni Pọọlu sọ fun Timoti ninu akọsilẹ yi? Akọkọ, o sọ fun pe ki o ma waasu ọrọ Ọlọrun dipo ti yoo fi ma fi ero ọkan tirẹ, ero ọkan awọn eniyan ti o gbaju-gbaja lawujọ, itan adugbo tabi iṣeṣe ṣe iwaasu. Ekeji, o sọ fun pe ki o ma wa ni igbaradi lati tọ awọn ọmọ Ọlọrun sọna, lati ba wọn wi ati lati gba wọn niyanju, yala o rọrun fun tabi ko rọrun fun. Ṣugbọn ṣe ko yẹ ki Timoti ti mọ awọn nkan wọnyi tẹlẹ ni, paapaa julọ niwọn igba ti o jẹ wipe pasitọ awọn pasitọ ni o jẹ? O yẹ ki o ti mọ wọn.
Ki wa lo de ti o fi nilo ẹnikan lati ṣeṣẹ ma pasẹ fun lati fi ara rẹ jin fun ṣiṣe awọn nkan wọnyi? Bi a ti ri ninu akọsilẹ yi, idi ni pe akoko kan n bọ (akoko naa si ti de bayi) ti ọpọ awọn ti o pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ko ni fi ara mọ ẹkọ ti o ye kooro ṣugbọn ti wọn yoo wa awọn ti yoo ma sọ nkan ti eti ti o n rin wọn fẹ gbọ fun wọn. Pọọlu tilẹ tẹsiwaju lati sọ wipe awọn wọnyi yoo yi eti wọn pada kuro lọdọ otitọ ki wọn ba le ma gbọ awọn itan abalaye ati irọ. Nigbati ti eyi ba si ṣẹlẹ, o ṣeeṣe ki Timoti bẹrẹ si ni ro wipe boya oun ti fe le mọ wọn ju, ki o si wa titori eyi bẹrẹ si ni yi iwaasu rẹ pada lati tẹ ifẹ wọn lọrun. Nitorina, Pọọlu kilọ fun niwaju Ọlọrun ati niwaju Jesu Kirisiti lati ma ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, yoo pa iṣẹ iranṣẹ rẹ run, yoo si tun padanu ere rẹ.
Nibakanna, ọpọ ninu ijọ loni ni ko fẹ fi ara mọ otitọ mọ, iyẹn ti wọn ba tilẹ ti fi igban kankan tẹlẹ fi ara mọ ọn. Idi si niyi ti wọn fi n gba inu ijọ kan de inu ijọ miran, ti ko si jẹ fi idi mọlẹ si ibi kankan. Awọn adari bi Aarọni ti yoo fun wọn ni ohunkohun ti wọn ba fẹ, bi o tilẹ jẹ ere wura ni, tẹ awọn wọnyi lọrun ju awọn adari ti yoo koju wọn pẹlu otitọ nipa aye wọn ati nipa ifẹ Ọlọrun fun wọn. (Wo: Ẹ́kísódù 32)
Wayi o, otitọ ti o wa nibẹ ni pe Ọlọrun ko le pa irufẹ awọn eniyan bi eyi mọ kuro ninu idibajẹ tabi ko wọn yọ ki eṣu ma ba ṣi wọn lọna tabi pa wọn run. Ti iwọ naa ko ba si fẹ ki opin aye rẹ ri bi ti wọn, ti o ba fẹ ki Ọlọrun ko ọ yọ ni awọn ọjọ ikẹyin yi, ki O si tun jẹ ki igbagbọ rẹ duro deede, nṣe ni ki o ya fi ara rẹ jin fun ọrọ rẹ ti o ye kooro ati fun itọni ti Ẹmi, dipo eyi ti iwọ yoo fi ma wa awọn ti yoo ma fi ọwọ ra ọ lori ti o o fi ṣegbe kiri. Mo si tun fẹ ki o mọ eyi daju: awa kan si wa ti a ko ni yi iwaasu wa pada lati tẹ ọ lọrun. Bẹẹni, awa kan si wa ti a ko jẹ fun ọ ni ere wura kankan lati bọ, ohun yowu ki o sọ nipa wa tabi ki o ro nipa wa. Idi si ni pe iwọ kọ ni a o jiyin fun bikoṣe Ọlọrun ti O ran wa niṣẹ. Njẹ ki Ọlọrun fun ọ ni ọkan ti yoo ma fi igba gbogbo wa ni irẹlẹ lati tẹwọgba ọrọ otitọ rẹ lalai jiyan. Amin.
Kí o ní oṣu Èrèlé 2023 tí ó ga.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)





