Author name: CyberHawk

AKỌRI: ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ AYỌKA: 1Timoti 5:3-16

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI AWỌN TI AYE | Paito J.O. Lawal

ỌJỌRU 06, ỌWARA 2021 | AYỌKA: JOHANU 16:7-11

AKỌSORI: Nitori naa mo fẹ ki ẹ mọ pe, ko si ẹni ti n sọrọ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ki o wi pe, Ẹmi ifibu ni Jesu: ati pe, ko si ẹni ti o le wi pe, Oluwa ni Jesu n ṣe, bi ko ṣe nipasẹ Ẹmi mimọ.”

ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ẹmi mimọ jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun ati Jesu Kirisiti (1John 5:7). O ti wa pẹlu Ọlọrun lati atetekọse (Jẹnẹsisi 1:2). O jẹ Ẹmi ti o n ti ọdọ Ọlọrun funrarẹ jade (Johanu 16:26; Ifihan 5:6). Nipasẹ rẹ si ni Ọlọrun da ohun gbogbo (Joobu 33:4; Saamu 104:30). Oun gan ni O n jẹ ki wiwa, imọ ati agbara Ọlọrun jẹ mimọ fun awọn eniyan. Ṣugbọn, iwe mimọ jẹ ki o ye wa pe awọn alaigbagbọ ko mọ Ẹmi yi, bi o tilẹ jẹ pe a ri lara wọn ti wọn n ni ibaṣepọ pẹlu awọn ẹmi okunkun (Johanu 14:16-17). Nitorina, wọn ko le gba nkan ti Ẹmi Ọlọrun n sọ fun wọn (1Kọrinnti 2:14). Igba ti wọn ba si to gba nkan ti O n sọ fun wọn, ti wọn si ṣe amulo rẹ ni wọn to le ni iriri igbala, iwẹnumọ ati itunnibi sinu ijọba Ọlọrun (Titu 3:5). O wa yẹ ki awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun mọ ipa ti Ẹmi yi n ko tabi iṣẹ ti O n ṣe lati ri pe ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu awọn eniyan ki a ma ba di i lọwọ tabi ba iṣẹ rẹ jẹ. Eyi si ni ẹkọ yi da le lori.

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI TI AYE
Ki wa ni koko iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun si awọn ti aye yi? Gẹgẹ bi a ti ri ninu bibeli, iṣẹ iranṣẹ rẹ ni i ṣe pẹlu awọn nkan iwọnyi:

  • Fifi oye ye wọn: Jesu, nigba ti akoko rẹ lati fi ara rẹ silẹ fun igbala araye sunmọ tan, sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ: “Ṣugbọn otitọ ni emi n sọ fun yin; Anfaani ni yoo jẹ fun un yin bi emi ba lọ: nitori bi emi ko ba lọ Olutunu ki yoo tọ yin wa: Ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o ran an si yin. Nigba ti oun ba si de, yoo fi oye ye araye ni ti ẹṣẹ, ati ni ti ododo, ati ni ti idajọ. Ni ti ẹṣẹ nitori ti wọn ko gba mi gbọ. Ni ti ododo, nitori ti emi n lọ sọdọ Baba, ẹyin ko si ri mi mọ; Ni ti idajọ, nitori ti a ti ṣe idajọ alade aye yii.” (Johanu 16:7-11) Pẹlu nkan ti Oluwa sọ nibi yi, a ri wipe Ẹmi mimọ nikan ni o le fe oye ẹṣẹ araye han wọn. Eyi tunmọ si wipe Oun nikan ni o le ba wọn wi, ki O si jẹ ki wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ẹlẹsẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Opọ ni ko mọ pe olori ẹṣẹ eniyan ni aigba Jesu gbọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ti a ran lati fun araye ni iye ainipẹkun. Wọn ro pe irọ pipa, eke ṣiṣẹ, iwa eeri, agbere ati bẹẹbẹẹ lọ nikan ni ẹṣẹ ati pe ẹni ti ko ba ti ṣe awọn nkan wọnyi ko ni iṣoro kankan pẹlu Ọlọrun. Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ pe ẹṣẹ ni awọn nkan wọnyi nitootọ, ti Ọlọrun yoo ṣi ṣe idajọ awọn eniyan nitori wọn, idi ti ọpọ yoo fi ku ati jiya fun wọn ni pe wọn kọ lati gba ẹbun ọfẹ ọmọ Ọlọrun, Jesu gbọ, gẹgẹ bi ẹni ti Ọlọrun fa kalẹ lati ku fun awọn ẹṣẹ yi ati lati da awọn ti o ba gbaagbọ lare. Amọ, nipasẹ iṣẹ iranṣẹ Ẹmi mimọ, awọn eniyan le mọ awọn nkan wọny ni ọkan wọn.

Yatọ si eyi, iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati jẹ ki oye ododo ti Ọlọrun tẹwọgba ye awọn eniyan. O si n ṣe eyi nipa pipe akiyesi wọn si igbasoke Jesu si ọwọ ọtun Ọlọrun. Ki ni o fa ti Ọlọrun fi gba Jesu ti o ku fun wa soke sọdọ rẹ? Idi ni wipe Oun nikan ni ododo rẹ peye niwaju rẹ. Ẹnikẹni ti o ba wa fẹ wa pẹlu Ọlọrun titi ayeraye bi Jesu naa gbọdọ gbagbọ ninu rẹ, ki O si fi ṣe ipilẹ ododo rẹ. Ọpọ lo n tẹle awọn ti ododo wọn ko peye niwaju Ọlọrun ati awọn ti wọn ko tilẹ mọ ibi ti wọn yoo pari igbesi aye wọn si. Awọn wọnyi yoo kabamọ nigbẹyin ni ayafi ti Ẹmi Ọlọrun ba fi ye wọn pe Jesu nikan ni O le ṣe wa yẹ lati duro niwaju Ọlọrun gẹgẹ bi olododo ki o to pẹ ju. (Wo: Johanu 14:1-6; Efesu 1:20-22; Heberu 1:3)

Siwaju si, iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati jẹ ki oye idajọ Ọlọrun ye awọn eniyan. Ọpọ ni ko gbagbọ pe ọjọ idajọ Oluwa n bọ wa, ti ko si ni yẹ. Ṣugbọn ọjọ idajọ yi n bọ ni tootọ, ti Ọlọrun yoo ṣi ṣe idajọ gbogbo awọn oniṣẹ ẹṣẹ nipasẹ ọmọ rẹ Jesu (Iṣe Apọsiteli 10:42 & 17:30-31). O si ti fi apẹẹrẹ eyi han nipa ṣiṣe idajọ Eṣu ti o jẹ alade aye yi. Niwọn igba ti Ọlọrun ti ṣe idajọ Ẹsu ti o jẹ alade yi ati awọn angẹli rẹ, ti O si ti pese ina ainipẹkun fun wọn, o yẹ ki o ye wa pe bẹẹ gẹgẹ naa ni yoo ṣe ṣe idajọ gbogbo awọn ti o dẹsẹ, ti yoo si sọ awọn naa sinu ina ayeraye nigba ti akoko ba to. Ṣugbọn oye awọn nkan wọnyi ko le ye awọn eniyan, oye ewu ti o rọ dẹdẹ le wọn lori ko le ye wọn ti ko ba ṣe pe Ẹmi Ọlọrun ba fi ye wọn. Eyi lo fa ti awọn miran ṣe ma n fi ọrọ idajọ Ọlọrun ṣe ẹfẹ tabi ki wọn fi da apara. Ṣugbọn ojo idajọ Ọlọrun ṣu si ori wọn, o si di dandan ki o rọ ni akoko rẹ. (Wo: Matiu 25:31-46)

  • Mimu wọn wa si ironipiwada ati igbagbọ ninu Kirisiti: Ọtọ ni ki Ẹmi Ọlọrun fi oye ipo ti eniyan wa han; ọtọ tun si ni pe ki ẹni naa ṣiṣẹ tọọ nkan ti a fi han an. Ọpọ loni lo mọ pe igbe aye ti awọn n gbe ko nitunmọ, ti o si di dandan ki a pa aye wọn run nikẹyinkẹyin. Ṣugbọn ṣe wọn wa ti gbe igbesẹ atunṣe bi? Rara o! Ọpọ ni o si ti ipa aigbe igbesẹ lakoko ti o wọ lori igbala aye wọn ṣegbe. Nitori idi eyi, ko ki i ṣe gbogbo awọn ti o wa ni ayika wa ti ko gbagbọ ninu Jesu Kirisiti naa ni ko mọ pe o yẹ ki awọn fi igbagbọ wọn sinu rẹ. Awọn miran mọ, sugbọn ti o jẹ wipe ibẹru, ifẹ aye, ilọra ati bẹẹbẹẹ lọ ni ko i ti jẹ ki wọ gbe igbesẹ ti o tọ. Ti Ẹmi Ọlọrun ko ba wa pari iṣẹ rẹ lori awọn wọnyi, ki O si mu wọn wa si ironipiwada, wọn ko ni ronupiwada titi wọn yoo fi ṣegbe. Idi niyi ti Jesu fi sọ wi pe, “Ko si ẹnikẹni ti o le wa sọdọ mi, bi ko ṣe pe Baba ti o ran mi fa a…” (Johanu 6:44) Oun naa lo si fa ti Pọọlu fi sọ wipe, “Nitori naa mo fẹ ki ẹ mọ pe, ko si ẹni ti n sọrọ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ki o wi pe, Ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, ko si ẹni ti o le wi pe, Oluwa ni Jesu n ṣe, bi ko ṣe nipasẹ Ẹmi Mimọ.” (1Kọrinnti 12:3) Nitori naa, gbogbo awa ti a gbagbọ ninu Jesu loni gbagbọ nitoripe Ẹmi Mimọ ṣiṣẹ lori aye wa lati sọ wa ji, ki a ba le gbagbọ ni, ko ki i ṣe nitoripe a gbọn tabi nimọ ju awọn ti ko gbagbọ lọ. Idi niyi ti a ko fi le ṣogo lọna kankan lori igbala tabi igbagbọ wa — ẹbun Ọlọrun nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ ni awọn nkan wọnyi jẹ fun wa. Ti oye yi ba si ye wa, a ko ni ro wipe akitiyan wa le sọ ẹnikẹni di onigbagbọ ninu Kirisiti. Dipo eyi, nṣe ni a o ma fi gbogbo igba fa ọkan awọn ti a ba n waasu si le Ọlọrun lọwọ, ki O ba le tipasẹ Ẹmi rẹ yi wọn pada sọdọ rẹ. (Wo: Efesu 2:1-9)
  • Sisọ wọn di atunbi: Yatọ si awọn nkan ti a ti mẹnu ba nipa iṣẹ Ẹmi Ọlọrun laarin awọn ti aye yi, iṣẹ rẹ tun ni lati sọ awọn eniyan di atunbi. Ranti wipe, Jesu, ninu iwaasu rẹ kan si Nikodemu, sọ wipe, “Bi ko ṣe pe a fi omi ati Ẹmi bi eniyan, oun ko le wọ ijọba Ọlọrun.” (Johanu 3:6) Nitori naa, iṣẹ Ẹmi Mimọ ni lati sọ eniyan di atunbi, lati sọ di eda tuntun, lati yọ ọkan okuta kuro ninu rẹ, ki O si fi ọkan ẹran dipo rẹ. Laisi jẹ pe O ba tun eniyan bi, ẹni naa ko le di ọmọ Ọlọrun tabi ero ijọba rẹ. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi: “Nitori awa pẹlu ti jẹ omugo nigbakan ri, alaigbọran, aṣako, ẹni ti n ṣin oniruuru ifẹkufẹẹ ati adun aye, a n gbe ninu arakan ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si n koriira awọn ọmọnikeji wa. Ṣugbọn nigba ti iṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ si eniyan farahan, Kii ṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo, ṣugbọn gẹgẹ bi aanu rẹ ni o gba wa la, nipa iwẹnu, atunbi ati isọdi tuntun Ẹmi Mimọ, Ti o da si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kirisiti Olugbala wa.” (Titu 3:3-6) Njẹ o ri bayi pe Ẹmi Ọlọrun ni O ma n yi eniyan pada, ti O si ma n sọ aye wọn di ọtun. Laisi jẹ pe O ba ṣe eyi, gbogbo akitiyan ati ọrọ ẹnu wa lati yi ẹnikẹni pada di dandan ki o jasi pabo.
  • Sisọ wọn di ẹya ara Kirisiti: Wayi o, niwọn igba ti o jẹ wipe Ẹmi Ọlọrun ni o ma n tun eniyan bi, o wa jasi pe Oun nikan naa ni O le sọ wa di ọmọ ijọba Ọlọrun, ki O si tun sọ wa di ẹya ara Kirisiti, Ẹni ami ororo Ọlọrun. Pọọlu sọ eyi fun wa lori ọrọ yi: “Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọkan, ti o si ni ẹya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹya ara ti i ṣe pupọ jẹ ara kan; bẹẹ si ni Kirisiti pẹlu. Nitori pe ninu Ẹmi kan ni a ti batisi gbogbo gba sinu ara kan, ibaa ṣe Juu, tabi Heleni, ibaa ṣe ẹru, tabi ominira; a si ti fun gbogbo wa ni Ẹmi kan.” (1Kọrinnti 12:12-13) Njẹ o ri bayi? Ẹmi Ọlọrun ni O ma n sọ awọn eniyan di alabapin ninu Kirisiti ati alabapin ninu ogun awọn eniyan mimọ Ọlọrun. Nitori naa, didarapọ mọ awọn ọmọ Ọlọrun kan tabi omiran kọ ni o n sọ eniyan di alabapin ninu Kirisiti; Ẹmi Mimọ ni O ma n sọ eniyan di ọkan pẹlu rẹ. Ẹni ti Ẹmi Ọlọrun ko ba si ti i ṣọ di ara Kirisiti, ko si irufẹ nkan ti a le ṣe fun wọn tabi ipo ti a le fun wọn ninu ijọ Ọlọrun ti o le sọ wọn da.

ỌRỌ IPARI
Ki wa ni koko gbogbo awọn nkan ti a ṣe agbeyẹwo wọn yi nipasẹ iṣẹ Ẹmi Ọlọrun laarin awọn ti aye yi? Koko rẹ naa ni pe o yẹ ki awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun mọ daju ṣaka pe a ko le da ohunkohun ṣe lati jẹ ki awọn ti aye yi ri igbala ninu Jesu Kirisiti. Ohun ti Ẹmi Ọlọrun ba ṣe funrarẹ tabi ti o ba tipasẹ wa ṣe nikan naa ni o le yọri si igbala wọn. Njẹ eyi wa tunmọ si pe ki a fọwọ lẹran, ki a si ma woye igba ti Ẹmi rẹ yoo gbera lati ṣiṣẹ ninu aye awọn alaigbagbọ bi? Rara o! Dipo bẹẹ, nkan ti eyi n sọ fun wa ni pe ki a fi sọkan pe a gbọdọ gbe gbogbo ọkan ati ara wa ati akitiyan yowu ti a ba n ṣe lori igbala awọn eniyan le Ọlọrun lọwọ, pẹlu oye pe awọn ti O ba gbala nikan naa ni yoo di ẹni igbala.

IBEERE

  • Awọn ọna wo ni ẹkọ yi gba ran oye ti o ni lori iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Mimọ lọwọ?
  • Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI AWỌN TI AYE | Paito J.O. Lawal Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Oluwa wa pẹlu rẹ | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owara 03, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Nkan ayọ ti o ga ni o jẹ fun mi lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Owara 2021. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba rin pẹlu afiyesi diduro ṣinṣin Ọlọrun pẹlu rẹ, ki o ma ba ba sọ ireti nu tabi ba ọkan jẹ, bi o ti wu ki asiko ri fun ọ. Amin.

Iwọ na mọ pe awọn igba ma n wa ti awọn idojukọ aye wa le sun wa debi ti a o ti ro pe Ọlọrun ti pa wa ti ati pe awa nikan la n da dojukọ awọn nkan ti o n lepa lati pa wa run. Ṣugbọn eyi ko jẹ tuntun. A ri awọn eniyan mimọ igbaani ti awọn naa ro bẹẹ gẹgẹ ni awọn akoko kan ni igba aye wọn. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Angẹli Oluwa kọkọ farahan Gidioni, ti O si sọ fun pe, “Oluwa wa pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara,” idahun rẹ ni wipe, “Ti Oluwa ba pẹlu wa, ki lo wa fa ti a fi wa ni ipo radarada yi, ki si ni o fa ti ko fi ṣe iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu oniruuru fun ominira wa, bi O ti ṣe ṣe fun awọn baba nla wa? O daju ṣaka pe O ti kọ wa silẹ” (Wo: Onidajọ 6:11-13)

Iwọ naa gbe yẹwo. Ọlọrun tikararẹ n ba ọmọkunrin yi sọrọ lojukoroju wipe Oun wa pẹlu rẹ. Sibẹsibẹ o ni i lara lati gba a gbọ. Ki ni idi? Idi ni pe o n wo bi igba ṣe ri fun aye rẹ ati fun orilẹ-ede rẹ. Ko ye rara idi ti Ọlọrun fi le wa pẹlu wọn, ki O si tun fi aye gba ki gbogbo nkan lọjupọ fun wọn bi o ti ṣe ri ni akoko naa. Ṣugbọn Ọlọrun ko ni O wa nidi bi nkan ṣe lojupọ fun aye wọn. Awọn ni o fa a. Awọn ni o kọ Ọlọrun silẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni rin ninu ọgbọn ara wọn. Nitorina, O fi wọn silẹ lati ri atunbọtan kikọọ silẹ lati rin ni ọna ti ara wọn.

Ṣugbọn nigba ti wọn kigbe pe nitori inira wọn, O da wọn lohun nipa bibẹ Gidioni wo ati nipa jijẹ ki o mọ pe Oun ko fi igba kankan fi wọn silẹ. Ṣugbọn ẹṣẹ wọn ni o n di ifarahan wiwa rẹ pẹlu wọn lọwọ. Pẹlu awọn ẹri ma jẹmi niso melokan, O misi ọmọkunrin yi, O si tun fun ni iwuri lati dari awọn eniyan rẹ lati ni iriri ominira kuro lọwọ awọn ti o n niwọn lara. (Wo: Onidajọ 6-8)

Nibakan naa, ti awa naa ba kan tẹjumọ idojukọ aye wa nikan, o ṣeeṣe ki a sọ wipe Ọlọrun ko si pẹlu wa tabi pe ko tilẹ naani ibi ti ọrọ wa ba ja si. Ṣugbọn Ọlọrun ko ki i fi igba kankan fi awọn ọmọ rẹ silẹ tabi kọ wọn silẹ. Idi si ni pe O ti ṣeleri pe Oun ko ni fi igba kankan fi wa silẹ tabi kọ wa silẹ. Niwọn igba ti ko ki si kuna lati pa ọrọ rẹ mọ, a le fi ọkan balẹ pe O wa pẹlu wa, bi o ti wu ki igba ri fun aye wa. (Wo: Heberu 13:5-6)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun wa pẹlu wa, a le ma ni iriri ifarahan agbara rẹ lati yi asiko pada fun wa tabi lati gba wa kuro lọwọ awọn asiko kan. Nkan meji pataki ni o si le fa eyi. Akọkọ ni ẹṣẹ. Ti awa naa, bi awọn ọmọ Isiraẹli aye igba Gidioni, ba fi aye gba ẹṣẹ lati kọ ẹyin wa si Ọlọrun, a le ba ara wa labẹ ipọniloju Eṣu, bi o tilẹ jẹ wipe iwaju Ọlọrun gan an la wa, ti Oun ko si ni ṣe nkankan lori rẹ. Ṣugbọn ti a ba tun wa rẹ ara wa silẹ, bi awọn naa ṣe rẹ ara wọn silẹ nigba to ya, ti a si ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wa, Oun yoo dari ji wa, yoo ṣaanu fun wa, yoo si tun jẹ ki a ni iriri idande rẹ. Eyi, bi mo ṣe gbagbọ, ni gbogbo wa nilo lati ṣe ni kankan ni orilẹ-ede yi, ti a ba fẹ ni iriri ominira tootọ kuro lọwọ awọn nkan ati awọn eniyan ti wọn n pọn wa loju lọwọlọwọ yi.

Nkan keji ti o le diwa lọwọ la ti ni iriri agbara Ọlọrun lori awọn idojukọ wa ni ki a tẹjumọ awọn idojukọ naa dipo ki a tẹjumọ Ọlọrun. Ti o ba jẹ awọn iṣoro aye wa ni a tẹjumọ, o ṣeeṣe ki wọn papa pa wa run, bi a ko tilẹ gbe ninu ẹṣẹ. Ṣugbọn ti o ba jẹ pe Ọlọrun ni a tẹjumọ, Ọlọrun ti O wa pẹlu wa, ti O wa fun wa, ti O wa ninu wa, ti O si tun ni agbara lori asiko aye wa gbogbo, o di dandan ki a ni iriri agbara ati iṣẹgun rẹ lori awọn nkan ti o n lepa lati han wa ni eemọ tabi pa wa run.

Pọọlu so wipe a n ri nipa igbagbọ dipo nkan ti a fojuri (2Kọrinnti 5:7). Ṣugbọn ko ki i ṣe gbogbo wa naa ni a le sọ eyi, nitori pe ko ki i ṣe gbogbo wa naa ni o n ri nipa igbagbọ dipo nkan ti a fojuri. Rinrin nipa igbagbọ ni i ṣe pẹlu pe ki a ma gbe aye wa lori gbedeke nkan ti Ọlọrun sọ fun wa dipo lori gbedeke nkan ti a fojuri, feti gbọ tabi mọ lara. Niwọn igba ti o ba si jẹ pe a n gbe aye wa lori gbedeke nkan ti O sọ fun wa nipa ara rẹ, ara wa ati aye yi lapapọ, a ko ni fi igba kankan ba idojuti pade, bi gbogbo ọrun apadi tilẹ dide gbogun ti wa. Adura mi si wa ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba gboju kuro lara idojukọ rẹ lati tẹjumọ Ọlọrun, Baba rẹ, ti o lagbara lori ohun gbogbo, ki o ma ba tun fi igba kankan padanu ifarahan agbara rẹ ninu aye rẹ mọ.

Alaafia ni fun ọ.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Oluwa wa pẹlu rẹ | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Ti ọrọ rẹ ba n bukun fun ọ | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Owewe 26, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 21

Olufẹ: O jẹ nkan ayọ nla fun mi lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Owewe 2021. Njẹ ki oore-ọfẹ Ọlọrun alailodiwọn ati ifẹ Kirisiti ti ko ki i jani kulẹ raga bo aye ati ile rẹ ni oṣẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ki o si jẹ ki o rin irin iṣẹgun ni gbogbo igba, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti pe ti aye rẹ ba n jẹ alabukunfun nitootọ nipasẹ ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ninu ijọ yi, ojuṣe rẹ ni lati dari awọn elomiran lati ni irufẹ iriri ti o n ni. O ko si nilo lati mọ ọpọlọpọ ẹsẹ Iwe mimọ ki o to le ṣe eyi, yala ni o nilo lati jẹ sọrọsọrọ. Nkankan ti o kan nilo naa ni ikaanu fun awọn ti o wa ni ayika rẹ ti aye wọn le di yiyi pada lọna ti o ga, ti awọn naa ba ni anfaani lati ma gbọ iru ẹkọ inu Iwe mimọ ti o n ri gbọ. Lo ba tan.

Nkan ti mo n sọ ni pe ti o ka ba jẹ alanikanjọpọn ṣugbọn onikaanu fun awọn ti o wa ni ayika rẹ ti aye wọn ti polukumusu nitoripe wọn ko ma gbe wọn ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun, o di dandan ki o lo ẹnu rẹ, owo rẹ, foonu rẹ tabi ohunkohun ti o ba wa ni ikawọ rẹ lati fi ọrọ Ọlọrun ti o n yi aye rẹ pada lọ awọn naa pẹlu. Bi bibeli ti ṣe fi ye wa, lẹyin igba ti Filipi ti gbọ ọrọ lati ẹnu Jesu tan, ara rẹ ko balẹ mọ titi o fi wa Nataniẹli kan, ẹni ti o ṣeeṣe ki o jẹ ọrẹ rẹ, ti o si sọ fun pe oun ti ri Mesaya. Bi o tilẹ wa jẹ pe o nira fun Nataniẹli lati gba pe nkan rere kankan le ti Nasarẹti, eyi ti i ṣe ilu Jesu, jade wa, Filipi si ri wipe oun rọọ lati wa ri bi nkan ṣe ri funrarẹ. Bi oun naa si ṣe di apọsiteli Jesu Kirisiti Oluwa niyẹn. (Wo: Johanu 1:43-51)

Njẹ Filipi wa jẹ oniwaasu saaju akoko yi bi? Rara o! Boya ni o tilẹ lero ni akoko naa pe oun yoo pada di apọsiteli. Ṣugbọn nitoripe o mọ daju ṣaka lọkan rẹ iru ẹni ti Jesu jẹ ati pe o fẹ ki ọrẹ rẹ naa di ọmọlẹyin rẹ, o ṣawari rẹ, o si mu tọ Oluwa wa. Ti iwọ naa ba mọ daju ṣaka pe Oluwa n bẹ ni aarin wa ati pe ọrọ rẹ ti o n yi aye wa pada naa le yi aye awọn aladugbo rẹ, ọrẹ rẹ, ẹbi rẹ, akẹgbẹ rẹ ni ibi iṣẹ tabi ile-iwe ati bẹẹbẹẹ lọ pada, iwọ naa yoo dari wọn lati ni iru iriri ti o n ni. Wayi o, bi Nataniẹli, wọn le ma kọkọ gbagbọ pe ere kankan wa fun wọn lati ara nkan ti o n ba wọn sọ. Ṣugbọn iwọ naa kan nilo lati ṣe bi Filipi ni, ki o si ni ki awọn dan ọrọ rẹ wo. Bẹẹni, sọ wipe ki wọn tọọ wo, ki wọn si ri pe rere loluwa (Saamu 34:8).

Ojuṣe rẹ miran, ti o ba jẹ pe lotitọ ni ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ni aarin wa n bukun fun ọ, ni ki o ma pin awọn nkan daradara fun awọn ti o n kọ ọ. Pọọlu sọ eyi si awọn ara Galatia: “Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa ṣe alabaapin ohun rere gbogbo ti o ni fun ẹni ti n kọ ọ.” (Galatia 6:6) Njẹ o ri bayi? Pipin oniruuru ohun rere lara nkan ini rẹ fun awọn ti o n kọ ni ọrọ Ọlọrun ti o njẹ ki aye rẹ lọ siwaju tabi dara si jẹ nkan ti Ọlọrun pa laṣẹ fun ọ lati ṣe. Eyi ki i ṣe ọrọ iyanju rara. Aṣẹ ni o jẹ.

Nitorina, bi ọsẹ ṣe n gori ọsẹ, ti o si n di alabukunfun si pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ni aarin wa, nṣe ni o yẹ ki o ma ronu nipa awọn nkan rere ti o o pin fun awọn ti Ọlọrun n lo lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Eyi si gbọdọ jẹ ṣiṣe ni ibamu pẹlu nkan ti o ni dipo nkan ti o ko ni (2Korinnti 8:12). Bi o ba si n ṣe n ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni igbọran si aṣe Ọlọrun, o di dandan ki o ri ere gba lọwọ rẹ, ni ọrun nikan kọ ni o ṣugbọn ni aye yi pẹlu, fun ṣiṣe bẹẹ. Ọna ti yoo wa gba pin ọ lere nikan ni mi o le sọ. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti ṣe fihan wa ninu Iwe mimọ, ere rẹ fun igbọran si aṣẹ rẹ ma n fi gbogbo igba ka eniyan laya, o si tun ma n kọja afojusun tabi ero awọn eniyan.

Fun apẹẹrẹ, nitori pe obinrin opo kan gbọran si lẹnu, ti o si fun Elija ni ounjẹ ti ko ba jẹ ounjẹ ikẹyin fun oun ati ọmọ rẹ, Ọlọrun ri wipe ounjẹ ko tan ninu ile rẹ fun gbogbo ọdun mẹta ati aabọ ti iyan fi wa ni orilẹ-ede Isiraẹli ati wipe ọmọ rẹ ko ku iku aitọjọ (1Awọn Ọba 17). Siwaju si, nitoripe Maria, arabinrin Lasaru, fi odidi agbe ororo oloorundidun oniyebiye kun ara rẹ, Oluwa sọ fun pe nibikibi ti a ba ti waasu ihinrere, o didan ki a darukọ rẹ ati ohun ti o ṣe (Maaku 14:3-8; Johanu 12:1-8). Ọrọ naa si n ri bẹ titi di akoko yi. Nitorina, ti iwọ na ba mu aṣẹ rẹ lori ṣiṣe itọju awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ rẹ ni ọkunkundun, iwọ naa ko ni ṣe alaigbere rẹ. Adura mi si pe ki a mu ọkan rẹ ro lati rin ninu igbọran lori ọrọ yi ati lori ọrọ miran yowu ti Ọlọrun ti n fẹ ki o gbọran, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ adun o.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ti ọrọ rẹ ba n bukun fun ọ | Paito J.O. Lawal Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

O ko ni kuna ni ṣiṣe ojuṣe rẹ | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owewe 19, 2021 | Atẹlera: Latori tabili | Nọmba: Vol. 10, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki a kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi. Mo si gbadura pe o ko ni kuna ninu ọkankan lara awọn ojuṣe ti Ọlọrun gbe le ọ lọwọ ninu aye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki wa ni idi ti adura ti mo gba yi ṣe ṣe pataki fun iwọ ati emi? Akọkọ, o ṣe pataki nitoripe Ọlọrun nikan ni O le ṣi oju wa si awọn nkan ti o jẹ ojuṣe wa ni tootọ, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe wọn. Ki ni idi ti awọn eniyan ṣe ma n gbe igbe aye alainikanṣe? Lọpọ igba, idi ni pe ojuṣe wọn ko ye wọn rara tabi pe wọn ko ni amuyẹ lati ṣe awọn nkan naa ti wọn mọ gẹgẹ bi ojuṣe wọn.

Nitorina, ti a ko ba fẹ kuna ninu ọkankan lara awọn nkan ti o jẹ ojuṣe wa, a gbọdọ mu gbigba adura si Ọlọrun looreekoore lati ma ṣi oju wa si ohun gbogbo ti o jẹ ojuṣe wa laye yi gẹgẹ bi iṣẹ. Lafikun, a gbọdọ ma gbadura si i ni gbogbo igba lati ṣe wa yẹ pẹlu ohun gbogbo ti a nilo lati ṣe gbogbo ojuṣe wa si i, si ara wa, si awọn ẹbi wa, si ijọ Ọlọrun ati si aye ti a wa ninu rẹ, ni ibamu pẹlu nkan ti a nilo lojoojumọ. Aijẹbẹ, ko si aridaju pe a ko ni ja a kulẹ ni gbogbo abala aye wa tabi ni ọpọ abala aye wa.

Idi miran ti adura yi ṣe ṣe pataki ni pe awọn nkan ti o jẹ ojuṣe ti Ọlọrun fa le wa lọwọ nikan naa ni yoo fun wa ni ere fun; ko ni i fun wa ni ere fun awọn nkan ti ko fa le wa lọwọ gẹgẹ bi ojuṣe wa. Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ti o n ṣiwawu pọ ni Isiraẹli ni igba aye Alufa Eli, Ọlọrun ko da a lẹjọ nitori iṣiwawu gbogbo wọn. Dipo eyi, O da a lẹjọ nitori iṣiwawu awọn ti o jẹ ọmọ tirẹ nikan. (Wo: 1Samuẹli 2&3)

Nibakanna, ninu owe ti Oluwa sọ nipa ọkunrin kan ti o fun awọn iranṣẹ rẹ ni owo lati fi ṣiṣẹ, ọkunrin yi ko ṣe agbeyẹwo ẹnikankan ninu awọn iranṣẹ yi lori oṣuwọn owo ti ko fun wọn. Dipo bẹẹ, gbogbo agbeyẹwo wọn ti o ṣe da lori nkan ti o fun wọn. Idi si ni yi ti ko tilẹ fi bikita lati mọ nkan ti iranṣẹ rẹ ti ko ṣe nkankan pẹlu owo ti o fun lo akoko ti ko fi si nile lati ṣe. Ohun miran yowu ti o le ma ṣe ni akoko naa, boya ni rere ni o tabi ni buburu, ko kan an. Eyi ti o kan ni pe ki ọkunrin yi lo owo ti o fun, ki o si tun ṣe aṣejere pẹlu rẹ. Niwọn igba ti ko si ti ṣe aṣejere pẹlu owo na, ko si ere kankan fun – ijiya nikan ni o ri gba. (Wo: Matiu 25:14-30; Luuku 19:11-29)

Nitorinaa, akoko yowu ti Ọlọrun ba fẹ pin wa ni ere fun awọn nkan ti a n gbeṣe laye yi, nṣe ni oju rẹ yo wa lori ọwọ ti a fi mu awọn nkan ti o jẹ ojuṣe wa, ko si ni si lori ọwọ ti a fi mu awọn nkan ti ko ki i ṣe ojuṣe wa. Ti gbogbo nkan ti a si wa mu ni pataki tabi ti a n ṣe aṣejere lori wọn ba jẹ eyi ti Ọlọrun ko ka si ojuṣe wa, ko ni fun wa ni oriyin lori wọn tabi ki o titori wọn gbe wa ga, bi o ti wu ki ilakaka wa lori awọn nkan wọnyi pọ to. Eyi yoo wa jasi pe nṣe ni a kan da ara wa laamu lasan lori wọn. Adura mi ni pe Ọlọrun yoo ma fi gbogbo igba pa wa mọ lati ma da ara wa laamu lori awọn nkan ti ko nitunmọ ati ti ko lere dipo ti a o fi fi ara wa jin lati kẹkọ lati mọ awọn nkan ti o jẹ ojulowo ojuṣe wa, ki a si ma ṣe wọn. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

O ko ni kuna ni ṣiṣe ojuṣe rẹ | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Onidajọ ododo | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owewe 12, 2021 | Atẹlera: Latori tabili | Nọmba: Vol. 10, No. 19

Olufẹ: ki oore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2021. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ri daju pe o gba idajọ ododo lọsẹ yi ni gbogbo abala aye rẹ ti a ti n yan o jẹ lọwọlowọ bayi, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti ṣe mọ, aye ti a n gbe ninu rẹ yi jẹ ọkan ti o kun fun oniruuru aiṣododo. Ko si fẹrẹ si ibi naa ti a wa, bi o tilẹ jẹ ile wa gan, ti a ko ti ni ba aiṣododo kan tabi omiran pade. Eyi si n pa awujọ wa lara, nitoriti o n fi aye silẹ fun awọn ti ko yẹ lati jẹgbadun tabi ṣakoso awọn nkankan ti ko tọ si wọn. Ibikibi ti ọrọ ba ti wa ri bayi, ko si ni ki yanpanyarin ma ṣẹlẹ nibẹ.

Nitorina, ti a ko ba fẹ ki yanpanyarin fa awọn ile wa, adugbo wa, ibi iṣẹ wa, ile-iwe wa, ile ijọsin wa ati awujọ wa lapapọ ya, a gbọdọ bẹrẹ si ni fi idi idajọ ododo mulẹ. Bẹẹni, ẹnikọọkan wa gbọdọ pinnu lati lo ipo rẹ tabi nkan ini rẹ lati fi idi ododo lẹlẹ nibikibi ti a ba wa. Eyi tunmọ si pe a gbọdọ ri daju saka pe nkan ti o tọ si awọn eniyan ni a n fun wọn dipo ki a ma fun wọn ni nkan ti wọn ko ni amuyẹ fun tabi fun wọn ni nkan ti o kere jọjọ si amuyẹ wọn.

O wa ṣe ni laanu pe, ni ọpọ igba, eyi ko ri bẹ pẹlu wa. Ọpọ eniyan ti o wa ni ipo ti wọn ti le gbe idajọ ododo ro, ki wọn si fi idi rẹ mulẹ, ni ko ṣetan lati ṣe bẹ ẹ. Ti awọn eniyan ba si ba wọn wijọ tabi fi ehonnu han tabi gba ile ẹjọ lọ fun idajọ ododo, ko si aridaju pe wọn yoo ri idajọ ododo gba rara tabi nigba ti o ba yẹ. Idi si ni yi ti ọpọ ni orilẹ-ede wa, fun apẹẹrẹ, ko ṣe ti ni itẹsiwaju ninu aye yi bi o ṣe tọ. Idi si tun niyi ti ọpọ miran ti ba ọkan jẹ, ti gbigbe igbe aye ododo si ti su wọn. Awọn wọnyi lo ti wa bẹrẹ si ni ti ọwọ bọ awọn ti wọn ti fi igba kan sọ wipe ko dara (Oniwaasu 8:11).

Boya iwọ na tilẹ ti pa igbe aye ododo ti tabi nṣe ni o n gbero lati pa a ti nitori iyanjẹ ti o ti fi ara gba lati ọwọ awọn eniyan. Ṣiṣe eyi ko yatọ rara si fifi aye gba ibi lati bori rẹ. Ṣugbọn bibeli sọ wipe, “Ma ṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi iṣẹ rere rẹ ṣẹgun buburu.” (Roomu 12:21) Nitorinaa, ma ṣe pa igbe aye ododo ti nitori aiṣoodo ti inu aye yi. Dipo eyi, tẹsiwaju lati ma gbe igbe aye ododo nibikibi ti o ba ti ba ara rẹ. Lafikun, tẹramọ gbigba adura si Ọlọrun pe ki O ṣe idajọ ododo fun ọ ati fun gbogbo awọn ti a n yanjẹ nilẹ yi. Yoo si dahun adura rẹ.

Bibeli sọ wipe, “Ọpọlọpọ eniyan ni o n wa ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ eniyan ni o n ti ọdọ Oluwa wa.” (Owe 29:26). Njẹ o ri bayi? Ọdọ ẹnikan ṣoṣo ti a ti le ri idajọ ododo gba ni aye yi ni Ọlọrun. Ti ko ba si fun wa ni idajọ ododo, ko si iye awọn alagbara tabi ọlọla eniyan ti a le lọ ba tabi fi ẹhonu han si, a ko ni ri i gba. Ṣe eyi wa jasi pe ki a ma wulẹ lọ ba eniyan kankan fun idajọ ti o tọ ni? Rara o! A ni anfaani lati lọ ba ẹnikẹni ti a ba ri pe o wa ni ipo lati fun wa ni idajọ ododo lori ohunkohun ti o ba n dun wa lọkan. Amọ a ko gbọdọ gbagbe pe ti Ọlọrun funrarẹ ko ba ru ẹni naa lọkan soke, ki O si tun fun un ṣe lati fun wa ni idajọ ododo, o le ma fun wa titi lailai.

Nitorina, nibikibi ninu aye rẹ ti o ba ti woye pe a ti rẹ ọ jẹ tabi ja o lole, ẹni akọkọ ti o yẹ ki o fi ọrọ naa lọ ni Ọlọrun. Ti o ba si ti ṣe eyi, ti awọn eniyan ba tilẹ kọ lati fun ọ ni idajọ ododo, o didan ki Oun ṣe ohun ti o tọ ati ti o yẹ fun ọ lalai fi akoko ṣofo. Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ wipe, “Ọlọrun ki yoo ha si gbẹsan fun awọn ayanfẹ ti n fi ọsan ati oru kigbe pe e, ti o si mu suuru fun wọn. Mo wi fun yin, yoo gbẹsan wọn kankan. Ṣugbọn nigba ti ọmọ-eniyan ba de, yoo ha ba igbagbọ ni aye bi?” (Luke 18:7-8) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun ko ni fi igba kankan ti wa danu, ti a ba wa oju rẹ fun idajọ ododo. Ṣugbọn ṣe a o wa oju rẹ? Njẹ iwọ yoo wa oju rẹ? Mo gbadura pe ki a mu igbagbọ wa le lati ma fi gbogbo igba wa oju Ọlọrun nibikibi ninu aye wa ti a ti nilo idajọ ododo, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Onidajọ ododo | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Mu suuru pẹlu rẹ. | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Owewe 05, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia di pipọsi fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun ninu oṣu Owewe 2021. Adura mi fun ọ si ni pe ki o ma fi gbogbo igba ni iriri igbega Ọlọrun titi o o fi fi ẹsẹ mulẹ gidigidi ninu ete rẹ fun aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọna kan pataki lati ma padanu imuṣẹ ete Ọlọrun fun aye wa ni ki a ma ba a rin pẹlu suuru. Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, wipe Ọlọrun ni eto rere fun eniyan ko tunmọ si pe ọsankan-orukan naa ni gbogboo eto yi yoo wa si imuṣẹ. Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun yan Dafidi gẹgẹ bi ọba ni ipo Sọọlu. Ṣugbọn ko fi ọdọmọkunrin yi sori itẹ ni ọjọ kannaa ti O yan. Bi a tilẹ ṣe ri, o to iwọn ọdun mẹtala si ki O to fi si ori itẹ.

Ki wa lo fa ti Ọlọrun ko ṣe fi Dafidi si ori itẹ ni ọjọ kannaa ti O ta ororo le lori gẹgẹ bi ọba? Idi ni pe ko i ti di ọmọkunrin to fun ipo naa. Wiwa ni ipo ọba ko ni i ṣe pẹlu ka kan ma a yọtọmi lasan; ojuṣe ti o sorọ mọ ọn pọ jaburata. Ti eniyan ko ba si gbọn to ati ki o si tun lagbara to lati ṣe awọn ojuṣe yi, yoo kuna gidigidi gẹgẹ bi ọba. Lafikun, ti eniyan ko ba ni awọn alatilẹyin ti wọn jẹ olootọ, ti wọn gbọn, ti wọn koju oṣuwọn, ti wọn si tun lagbara to lati ba a fi idi ijọba rẹ mulẹ, o ṣeeṣe ki awọn ikooko apanijẹ ijọba rẹ fi ṣe ifa jẹ.

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki Dafidi wa lori itẹ Isiraẹli nitoripe o jẹ ẹnikan ti ọkan rẹ dirọ mọ ọn, O nilo lati fun ni akoko si lati kẹkọ, lati mura ati lati ṣe ara rẹ giri fun ipo naa ki O to fi si ibẹ. Aijẹbẹ, ki ijọba rẹ to bẹrẹ gan ni yoo ti wa si opin. Awọn akọsilẹ inunibini ti o ba pade lati ọwọ Sọọlu si to lati fi idi eyi mulẹ.

Lọna kannaa, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ni eto ti o ga fun aye wa, ti ọkan rẹ si wa nibẹ lati mu awọn eto naa ṣẹ, ko ni ṣe ohunkohun ti yoo wa pa wa run nigbẹyingbẹyin tabi ki O fun wa ni ohunkohun ti a ko ni amuyẹ lati ṣe amulo rẹ, lati tọju rẹ ati lati ma lo o lati pa ara wa run. Ṣugbọn ti a ko ba ni suuru, a le binu si pe ko mu awọn ileri rẹ ṣẹ lori wa bi a ṣe fẹ, ki a si gbe igbagbọ wa ninu rẹ ju sọnu. Ṣiṣe eleyi, ẹwẹ, yoo kan jẹ ki a padanu imuṣẹ ete rẹ fun aye wa patapata ni.

Iwọ naa wo nkan ti O ti ẹnu Mose sọ fun awọn ọmọ Isiraẹli ki O to mu wọn wọ ilẹ ileri: “Oluwa Ọlọrun rẹ yoo ti awọn orilẹ ede naa jade diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ma ṣe run wọn tan lẹẹkan, ki ẹranko igbẹ ma baa pọ si ọ.” (Ditaronomi 7:22) Njẹ o ri bayi? Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ṣetan lati le gbogbo awọn orilẹ ede ti o jẹ ọta awọn eniyan rẹ kuro niwaju wọn, ki wọn ba le gba ilẹ naa ti o n ṣan fun wara ati fun oyin ti O ti ṣeleri fun wọn, ipinnu rẹ kọ ni lati le gbogbo wọn danu lẹẹkan ṣoṣo. Ki si ni idi? Ṣe nitoripe ko ni agbara to lati ṣe bẹẹ ni? Rara o! Dipo bẹẹ, idi ni pe ṣiṣe bẹ ko le rọgbọ fun awọn eniyan rẹ.

Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu ọrọ rẹ, awọn ọmọ Isiraẹli yi ko i ti pọ to lati gba gbogbo ilẹ naa, ki wọn si tun ṣe amojuto rẹ, ni akoko yi. Nitorina, ti a ba fa gbogbo ilẹ naa le wọn lọwọ lẹẹkan ṣoṣo, ko ni i pẹ rara ti awọn ẹranko buburu yoo fi gbilẹ mọ wọn lọwọ, ti wọn yoo si bẹrẹ si ni pa wọn jẹ. Eleyi ko si ni dara rara. Nitorina, ninu ọgbọn rẹ, Ọlọrun pinnu lati ma le awọn ọta wọn danu diẹdiẹ titi wọn yoo fi pọ ati lagbara to lati gba gbogbo ilẹ naa. O si tun n ṣe bẹẹ gẹgẹ loni naa. A maa mu ete rẹ ṣẹ fun awọn ọmọ rẹ diẹdiẹ, ni iwọn bi agbara wọn ba ṣe to lati ṣe amulo ipese ati igbega rẹ. Tiwọn kan ni pe wọn gbọdọ mu suuru pẹlu rẹ, ki wọn si tun tẹramọ ṣiṣe ifẹ rẹ, pẹlu oye pe O ṣe e fi gbogbo ara gbọnkan le, O si tun lagbara to lati mu ete rẹ lori wọn wa si imuṣẹ (1Tẹsalonika 5:24; Heberu 10:35-39)

Nitorina, ti o ba n woye pe Ọlọrun ko ṣe nkankan lati mu ete rẹ ṣẹ lori aye rẹ tabi pe O lọra lati mu ete rẹ ṣẹ lori aye rẹ, Ẹmi rẹ n ba ọ sọrọ lọwọlọwọ yi pe, “Mu suuru, ki o si tun tẹramọ ṣiṣe ifẹ Ọlọrun.” Idi si ni pe o le jẹ pe nṣe ni O n duro de ọ ki o fi ni okun ati ọgbọn to lati ṣe amulo nkan ti O fẹ fun ọ. Adura mi si nipe ki a pese lẹkunrẹrẹ fun ọ ohunkohun ti o ba ku diẹ kaato ninu igbagbọ, ọgbọn ati agbara rẹ lati ṣe amulo ipese Ọlọrun fun ọ, ki iriri igbega ati igbara rẹ ti o yẹ ki o ni ma ba ni idaduro mọ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mu suuru pẹlu rẹ. | Paito J.O. Lawal Read More »

Orisun rẹ jẹ ẹ loogun pẹlu | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 29, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki a kaabọ si ọjọ isinmi ti o kẹyin oṣu Ogun 2021. Mo si gbadura pe ki Oluwa ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ọrọ aye rẹ ninu oṣu naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni aipẹ yi, mo ni itakurọsọ pẹlu ọdọmọbinrin kan ti ọkan rẹ n poruru nitori eto iṣuna ile rẹ ati nitori pe nkan ko lọ deede fun wọn gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ. Bi o si ṣe sọ fun mi, ọkan rẹ poruru lori ọrọ yi to bẹẹ gẹẹ ti o fi bẹrẹ si ni ronu ni akoko kan lati di ‘Ọmọ yahuu.’ A si wa mọ pe awọn ti a n pe ni ‘Ọmọ yahuu’ yi ko yatọ si gbajuẹ ati ole. Yatọ si pe gbajuẹ ati ole ni wọn, wọn tun jẹ aṣeṣo. Eyi tunmọ si pe ọpọ wọn, ti ko ba tilẹ jẹ gbogbo wọn, ni wọn ni nkan kan tabi omiran ni i ṣe pẹlu awọn iwin tabi ẹmi aimọ lati ni owo. Ti wọn ko ba si ronupiwada, o di dandan ki wọn parun ki aye wọn gan an to bẹrẹ.

Ṣugbọn ki wa lo fa a ti arabinrin yi fi ronu lati da ‘Ọmọ yahoo’? Ibeere ti mo si bere lọwọ rẹ gan an niyi. Mo ni, “Kirisitiani ni ọ, eyi ti o si ni iṣẹ lọwọ. Ki lo wa fa a ti o fi gbero lati ṣe iru nkan yi?” Idahun rẹ si jọ ni loju diẹ. O jọ ni loju nitoripe, gẹgẹ bi o ti ṣe wi, o ti ṣe alabapade awọn ‘Ọmọ Yahuu’ ninu ipade sọọsi lọpọ, o si n wo bi wọn ṣe n nawo ninu awọn ipade yi ati bi awọn kan ti a n pe ni adari ijọ ṣe n yin wọn, pọn wọn le ati gbadura fun wọn. Eyi si jẹ ki o ni ero pe wọn n ṣe fọrifọri fun oun ati pe oun ati ọkọ oun naa nilo lati ṣe nkankan lori eto isuna wọn.

A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun nitoripe, bi o tilẹ jẹ pe arabinrin yi gbero lati tọwọ bọ iṣẹ ibi yi, Ẹmi Mimọ ko gba fun. Ṣugbọn koko ọrọ gan ni pe ọpọ ni o wa ninu sọọsi loni ti wọn n ṣe oniruuru iṣẹ ti ko ba ofin mu, ti ara wọn si balẹ laarin wa nitoripe ko si ẹni ti o n ba wọn wi tabi kilọ fun wọn. Bi o si ti wa wu ki wọn fi fun sọọsi to tabi ki awọn kan kọrin yin wọn to, iṣẹ wọn ati ọrẹ wọn jẹ irira si Ọlọrun.

Nitorina, yatọ si pe wọn ko ni ri ere kankan gba lọwọ rẹ fun nkan ti wọn n ṣe, Oun yoo tun ba wọn wi ni akoko ti ọ tọ fun awọn iṣẹ ibi ti wọn n ṣe ati fun igboya ti wọn ni lati ro pe awọn le fun Ọlọrun ni abẹtẹlẹ pẹlu ere iwa ika. Ni abẹ majẹmu atijọ, Ọlọrun sọ fun awọn eniyan rẹ pe, “Ki agbere ki o ma ṣe si ninu awọn ọbinrin Isirẹli, tabi oniwa Sodomu ninu awọn ọmọkunrin Isiraẹli. Iwọ ko gbọdọ mu owo ọya agbere, tabi owo aja, wa sinu ile Oluwa Ọlọrun rẹ fun ẹjẹkẹjẹẹ: nitori pe irira ni ani awọn mejeeji si Oluwa Ọlọrun rẹ.” (Ditaronomi 23:17-18)

Njẹ o ri bayi? Nkan ti a n ṣẹ fun ounjẹ oojọ wa jẹ Ọlọrun logun. Ọna ti owo n gba wọle si wa lọwọ jẹ ẹ logun. Ti a ba si n ṣe ohun ti O korira, ki a ya ma mu owo tabi ọrẹ wa fun lati ipasẹ rẹ. Idi si ni pe bi eniyan ko ba mọ nkan ti a n dan an wo, Oun mọ nkan ti a n dan an wo, yoo si pin wa lere bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ. Si wa wo o, ko ki i ṣe awa nikan ni yoo da jẹ iya radarada ti a n ṣe yi; gbogbo awọn adari ijọ ti o n ki wa laya tabi ran wa lọwọ lati ṣe e naa yoo ba wa nipin ninu ijiya naa lọna ti o ga.

Ki ni idi ti Ọlọrun fi papa pa Balaamu ariran run? Idi ni wipe o fẹran ere iṣẹ ibi. O jẹ ọkunrin kan ti o ṣetan lati sọtẹlẹ fun ẹnikẹni, gbadura fun ẹnikẹni tabi fi ẹnikẹni gegun ti a ba fun ni owo ti o to owo, lalai wadi nkan ti irufẹ ẹni bẹ gan n ṣe. Nitorina, Ọlọrun pa a run, gẹgẹ bi o ṣe di dandan fun un lati pa gbogbo awọn oniwaasu ti wọn n tọ isisẹ rẹ arun pẹlu, ti awọn naa ba fi akoko ṣofo lati ronupiwada. (Wo: Numeri 22-24 & 31:8)

Nitorina, ma fi gbogbo igba ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki a lawọ si Oun, ibi ti awọn nkan ti a n fun un ti n wa jẹ ẹ logun pẹlu. Idi si ni yi ti o ko gbọdọ lọwọ si ohun aimọ kankan tabi ki o gba ki ẹnikẹni ti ọ lati lọwọ si (Efesu 4:28). Aijẹbẹ, nṣe ni o o kan ma fi gbogbo nkan ti o n fun Ọlọrun tabi sọọsi ṣofọ — iparun rẹ ko si ni sun lọ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Orisun rẹ jẹ ẹ loogun pẹlu | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Ohun buburu kan | Paitọ J.O. Lawa

Ọjọ: Ogun 22, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ tuntun miran ninu oṣu Ogun 2021. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun ma fi gbogbo igba di ọ lọwọ lati ma fẹ tabi ṣe ohun kankan ti yoo ṣi aye silẹ fun idajọ Ọlọrun lati wa si ori rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, adura yi le ma fi taratara dabi adura kan to nipọn tabi loorin loju ọpọlọpọ. Ṣugbọn Pọọlu gba iru rẹ fun awọn ara Kọrinnti nigba ti o sọ bayi, “Njẹ awa n gbadura si Ọlọrun ki ẹyin ki o ma ṣe ṣe ohun buburu kan…” (2Korinnti 13:7) Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe adura yi dabi ọkan ti ko lowura lọtiti, adura ti o ba ọrọ iwe mimọ mu ni gbogbo ọna ni. Niwọn igba ti o si ti ba ọrọ iwe mimọ mu, gbigba rẹ le jasi iyatọ laarin iye ati iku tabi laarin igbesoke ati ijakulẹ fun wa.

Fun apẹẹrẹ, Rubẹni ko gba egun baba rẹ nitoripe o jẹ ọdọmọkunrin onijagidijagan kan, ẹni ti o ma n fi gbogbo igba da wahala ati irora silẹ. Dipo eyi, o gba egun sori rẹ nitori nkan buburu ẹyọkan ṣoṣo ti o ṣe. O ba iyawo baba rẹ lopọ. Idi ti o ṣe ṣe eleyi ni a ko sọ fun wa ninu bibeli. Boya nṣe ni arabinrin yi tilẹ fi arekereke mu, bi aya Potifa naa ṣe fẹ fi arekereke mu Josefu. A ko mọ. Ṣugbọn ẹṣẹ ẹyọkan ṣoṣo yi jẹ ki oun ati awọn arọmọdọmọ rẹ sọ aye titayọ wọn nu ninu aye yi. (Wo: Jẹnẹsisi 35:21-22 & 43:3-4)

Lafikun, ki ni o pa Nadabu ati Abihu, meji ninu awọn ọmọ Aaroni, ni ọjọ kanna ati ni akoko kanna? Igbesẹ odi kan ṣoṣo ti wọn ma gbe ni. Eniyan daadaa si ni wọn o. Yatọ si eyi, alufa ti Ọlọrun fi amin ororo yan tun ni wọn pẹlu. Amọ nigba ti wọn fi ajeji ina rubọ niwaju Ọlọrun, ina ti ọdọ rẹ jade si wọn, o si jo awọn mejiji run lẹsẹkẹsẹ. A ko tilẹ fun wọn ni ikilọ tabi aye ati ronupiwada. Nitorina, nkan buburu ẹyọkan bayi le ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun idajọ kiakia tabi fun ọjọ aye ti o fi ojoojumọ kun fun iyọnu. (Wo: Lẹfitiku 10:1-2)

Wo o, awọn eniyan le ma ṣe oniruuru nkan ti ko dara, ki a si ma jẹ wọn niya lẹsẹkẹsẹ tabi ni ọna kan ti o lagbara tabi ti o ṣe fojuri. Ṣugbọn ti wọn ba kan lọ gbe igbesẹ aidara kan si, eyi ti o tilẹ le ma dabi ẹni ti o buru to ti awọn eyi ti wọn ti n gbe tẹlẹ, wọn le ba ara wọn ninu babanla iyọnu pẹlu Ọlọrun. Nkan ti o ṣẹlẹ si ọba Bẹliṣasari ni eyi. Ọlọrun ko lu pa tabi gba ijọba lọwọ rẹ fun ọkankan lara gbogbo awọn nkan buruku ti o ti n ṣe ki o to di ọjọ ti oun ati awọn eniyan rẹ woye pe ki awọn lo awọn nkan iṣura tẹmpili Ọlọrun fun awẹjẹwẹmu wọn. Ṣugbọn lọjọ ti o ṣe eyi, a paṣẹ idajọ iku fun. A si pa a, a si tun fa ijọba rẹ le ẹlomiran lọwọ. (Wo: Daniẹli 5)

Nibakanna, eniyan le ti ma ṣe ohun gbogbo daradara niwaju Ọlọrun, ki o si ma gba oriyin lati ọdọ rẹ. Ṣugbọn iwa aidara kan ti o ba wu bayi le jẹ ki o padanu ẹmi rẹ, iṣẹ iranṣẹ rẹ tabi aye rẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ranti Mose. Iwa aida ẹyọkan pere naa lo wu ti o si padanu iṣẹ iranṣẹ didari awọn ọmọ Isiraẹli wọ ilẹ ileri. Nitorina, nkan buburu kan le ba ohun gbogbo jẹ fun wa. (Wo: Numeri 20:1-13)

Idi niyi ti mo si fi ri adura Pọọlu fun awọn ara Kọrinnti gẹgẹ bi eyi ti o ṣe pataki pupọ si mi ati pẹlupẹlu si gbogbo ọmọ Ọlọrun. Ki si ni adura naa? Ohun na ni pe ki a ṣọ wa lati ma ṣe ṣe ohun aidara kankan, boya eyi ti yoo yọri si iku fun wa ni o tabi eyi ti yoo yọri si ijakulẹ, iparun, ibanujẹ tabi igbe aye radarada fun wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ohun buburu kan | Paitọ J.O. Lawa Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Idajọ ẹtan | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 15, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ pipọsi fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ogun 2021. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati rin ninu ifẹ ati otitọ inu pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ, ki o ma ba ṣilẹkun aye rẹ silẹ fun idajọ Ọlọrun dipo ki o ma gbadun ẹkunrẹrẹ ayọ ibaṣepọ Kirisitiẹni si Kirisitiẹni. Amin.

Bibeli sọ wipe, “Ẹ ma si ṣe purọ fun ẹnikeji yin, ẹyin sa ti bọ ogbologbo ara ẹṣẹ ni silẹ ati iṣẹ buburu rẹ; Ẹ si ti gbe ara tuntun ni wọ, eyi ti a sọ di tuntun gẹgẹ bi aworan ẹni ti o da a, sinu imọ kikun.” (Koloso 3:9-10) Njẹ o ri bayi? Irọ pipa, eke ṣiṣe tabi ẹtan jẹ ọmọ iṣẹda iku ti Ọlọrun yọ danu kuro ni aye wa nigba ti a di atunbi. Nitorina, a ko gbọdọ gba a laye ninu aye wa tabi ninu ibaṣepọ wa pẹlu ara wa. Aijẹbẹ, a o ma ṣilẹkun aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun. Tani o si mọ ọna ti O le gba dawa lẹjọ? Ko si!

Fun apẹẹrẹ, ti Ananaya ati Safira iyawo rẹ ba lero pe Ọlọrun le fun wọn ni idajọ iku lori pe wọn fi ẹtan ba awọn awọn eniyan rẹ lo pọ ni, o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe bi wọn ṣe ṣe nigba yẹn. Ṣugbọn nitori pe wọn ko ni lọkan rara pe O le e ṣe bẹ, wọn parọ nipa fi fifunni wọn, a si da seria fun wọn lẹsẹkẹsẹ. Awọn mejeeji si ni Ọlọrun da lẹjọ, ti O si tun pa ni ọjọ kannaa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 5:1-11)

Wayi o, ẹnikan wa le sọ wipe, “Ṣebi ọpọ laarin awọn ọmọ Ọlọrun lo si ma n wuwa ẹlẹtan loorekoore. Sibẹsibẹ, ko ki i ṣe gbogbo igba ti wọn ba ṣe eleyi ni Ọlọrun n lu wọn pa. Ki lo wa fa ti ọrọ ti Ananaya ati ti iyawo rẹ ṣe yatọ niwaju rẹ?” Lakọkọ, a gbọdọ jẹ ki o ye wa pe wipe Ọlọrun ko ṣe idajọ iku fun awọn eniyan lẹsẹkẹsẹ nitori pe wọn wuwa ẹtan tabi ṣe nkan buburu miran ko tunmọ si pe ko ma ṣe idajọ fun wọn rara. O ni ọpọ ọna ti O fi n ṣe idajọ awọn eniyan. Ti wọn ko ba si ni ifura, wọn le ma fi akoko kankan mọ pe a n ṣe idajọ wọn.

Ekeji, a nilo lati jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe pe Ọlọrun fi ojusaaju bọ ọrọ Ananaya ati iyawo rẹ. Nkan ti o ṣẹlẹ ni pe O kan pinnu lati fi wọn jofin ni, ki wọn ba le jẹ arikọgbọn fun awọn miran ti wọn le fẹ ma rin nipasẹ wọn. Adura mi si ni pe o ko ni gbe igbesẹ kankan ti yoo jẹ ki Ọlọrun fi ọ se arikọngbọn ọna ti O n gba ṣe idajọ ibi fun awọn eniyan. Amin. Ṣugbọn ki gan an lo fa ti Ọlọrun fi lo Ananaya ati Safira gẹgẹ bi arikọgbọn fun awọn miran? Idi ni wipe wọn gbiyanju lati fi ẹtan lọlẹ ninu ijọ rẹ. Awa naa si gbọdọ kiyesara lori irufẹ awọn nkan ti a n filọlẹ ninu ijọ Ọlọrun, nitori pe O n wo wa, yoo si pin wa lere gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wa ba ṣe ri.

Ni kukuru, bi akọsilẹ bibeli ṣe fi ye wa, nkan ti o ṣẹlẹ si Ananaya ati aya rẹ ṣẹlẹ ni akoko ti ifẹ Kirisiti n jọba lotitọ ninu aye awọn eniyan rẹ ati lori ọrọ aye wọn. Ifẹ yi si gbakoso aye wọn to bẹẹ gẹẹ ti awọn ti wọn ni awọn nkan ini to lowura bẹrẹ si ni ta wọn, ti wọn si n mu owo ti wọn pa nibẹ wa fun awọn apọsiteli lati pin fun awọn ti o ṣe alaini ni aarin wọn. Eyi gan an lo le iṣẹ jade kuro laarin wọn, nitoripe bibeli sọ wipe, “Ko si alaini kankan ni aarin wọn ni akoko yi.” (Wo: Iṣe Apọsiteli 4:32-35)

Nitorina, gbogbo awọn ara ni akoko yi, iye yowu ti wọn jẹ, ni wọn n ba ara wọn lo pẹlu otitọ ati ifẹ. Bi Ọlọrun si ṣe fẹ ki o ri ni eyi, nitoripe eyi ni yoo jẹ ki awọn ti aye yi mọ pe ọmọlẹyin Kirisiti Jesu Oluwa ni wọn nitootọ. O wa ṣe ni laanu pe, ni akoko kannaa yi, Satani ṣe aṣeyọri lati mu ki Ananaya ati iyawo rẹ bẹrẹ si ni ronu yatọ ati wuwa yatọ. Bi wọn ṣe pẹ to lori eleyi ni a ko mọ. Ṣugbọn a mọ pe, ni akoko kan, awọn naa, gẹgẹ bi awọn ara yoku, ṣeleri lati ta ilẹ wọn kan ati lati mu owo rẹ wa sinu ijọ. Wọn si ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Amọ ṣa o, wọn ko ṣetan lati mu gbogbo owo ti wọn pa nidi ilẹ ti wọn ta naa wa siwaju Ọlọrun. Nitori naa, wọn fi diẹ lara rẹ pamọ fun ara wọn. Njẹ eyi jẹ nkan ti o buru bi? Rara o! Awọn ni o ni owo yi lakọkọ, bi Peteru ṣe sọ fun wọn lẹyinọrẹyin. Nitori naa, wọn ni aṣẹ lati sọ bi wọn ṣe fẹ ẹ lo o. Ṣugbọn lati wa gbiyanju lati tan awọn eniyan Ọlọrun yoku jẹ, awọn eniyan rẹ ti wọn nifẹ wọn, ti ọrọ aye wọn si jẹ wọn logun, ki wọn si jẹ ki o dabi ẹni pe owo ti wọn fi silẹ ju iye ti wọn fi silẹ lọ jẹ eyi ti ko ṣe itẹwọgba ni ọwọ Ọlọrun. Idi niyi ti O ṣe ṣe idajọ ẹtan wọn, ti O si lo eyi lati fun awọn miran bi tiwọn ni anfaani lati kẹkọ ati lati ronupiwada.

Ni bakanna, ti awa naa ko ba ni rin pẹlu ifẹ ati ọkan otitọ pẹlu awọn ara wa ninu oluwa, boya nipa awọn ọna ti a n gba lo nkan ini wa tabi ẹbun ẹmi wa ni tabi nipa awọn ọna ti a n gba ṣe awọn nkan miran, a le ma ṣi ilẹkun silẹ fun idajọ Ọlọrun, eyi ti o si le ja si iku ti ara. Nitorina, ẹ jẹ ki a fi aye gba ọrọ Ọlọrun lati fọ wa mọ kuro ninu aiṣododo ati agabagebe gbogbo, nigba ti eyi si ṣeeṣe. Ki Ẹmi Ọlọrun si ran iwọ ati emi lọwọ lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ adun o.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Idajọ ẹtan | Paitọ J.O. Lawal Read More »

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 11, OGUN 2021

AKỌRI: PASITỌ AYỌKA: JOHANU 21:15-17

AKỌSORI: AKỌSORI: “Ẹ kiyesara yin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmi Mimọ fi yin ṣe alabojuto rẹ, lati maa bọ ijọ Ọlọrun, ti o fi ẹjẹ rẹ ra.” (Iṣe Awọn Apositeli 20:28)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, apọsiteli Pọọlu sọ eyi nipa Jesu: “O si ti fi awọn kan fun ni bii apọsiteli; ati awọn miiran bii wolii ati awọn miiran bii ẹfanjẹlisiti ati wọn miiran bii olusọ-aguntan ati olukọni; Lati pese awọn eniyan mimọ silẹ fun iṣẹ iranṣẹ, fun imudagba ijọ, ti i ṣe ara Kirisiti.” (Efesu 4:11-12) Pẹlu nkan ti o sọ yi, kedere ni a ri pe lara awọn ti Jesu Oluwa wa funrarẹ yan fun ijọ awọn eniyan rẹ fun imuyẹ fun iṣẹ iranṣẹ ati fun idagbasoke wọn ni a ti ri awọn ti a n pe ni oluṣọ-aguntan ati olukọni. Awọn wọnyi naa si ni ọpọ mọ si pasitọ loni. Awọn wo gan wa ni a le pe ni pasitọ? Ki ni awọn amuyẹ ti a n i lati ri ninu eniyan ki a to le tọka si gẹgẹ bi pasitọ? Ki ni ojuṣe pasitọ? Njẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ ni aala bi? Iha wo ni o yẹ ki ijọ Ọlọrun kọ si awọn pasitọ wọn? Wọnyi ni awọn ibeere ti a o ma tipasẹ ẹko yi ti o da lori iṣẹ iranṣẹ pasitọ dahun. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun lo ẹkọ naa lati wẹ aimọkan yowu ti a ba ni lori iṣẹ iranṣẹ pasitọ danu kuro ninu aye wa, ki a ba le ma ba awọn pasitọ ijọ wa lo ni ọna ti o yẹ ati ki awa yowu ti a jẹ pasitọ naa le mu iṣẹ iranṣẹ wa lọkunkundun, ki a si tun ṣe atunṣe nibi ti o ba ti yẹ. Amin.

TANI PASITỌ?
Ọpọ loni ni a n pe ni pasitọ ti wọn ko si ki i ṣe pasitọ rara – inagijẹ laṣan ni apẹle yi jẹ fun wọn. A n pe awọn kan ni pasitọ nitoripe wọn ma n fi gbogbo igba gbe bibeli kaakiri tabi waasu si awọn ti o wa ni ayika wọn. A si n pe awọn miran ni pasitọ nitoripe wọn ti lọ si ile-ẹkọ bibeli kan tabi omiran, ti wọn si n wọ aṣọ ẹgbẹjọda onikọla ati ti wọn si wa lori ijọ Ọlọrun kan tabi omiran gẹgẹ bi adari. Awọn miran ẹwẹ ni a n pe ni pasitọ nitori iṣedeede wọn ninu ijọ wọn. Sugbọn eniyan ko ki i ṣe pasitọ tabi olusọ-aguntan nitori awọn nkan wọnyi. Eniyan jẹ pasitọ nitori pe Ọlọrun yan an, O si tun fun ni awọn ẹbun Ẹmi Mimọ ti o ṣe pataki lati duro gẹgẹ bi olusọ-aguntan ati olukọni fun awọn ọmọ rẹ.

Nkan ti a n sọ ni wipe, gẹgẹ bi Pọọlu ṣe fi ye wa ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu ti o wa loke, pasitọ jẹ ẹnikan ti Jesu Oluwa wa yan, ti O si tun ṣe yẹ lati jẹ oluṣọ-aguntan, alabojuto ati olukọni fun awọn ọmọ Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, lẹyin ajinde rẹ, Jesu fi ara han diẹ lara awọn ọmọ ẹyin rẹ lọjọ kan, a si kọ eyi silẹ nipa nkan ti O sọ fun Peteru:

“Lẹyin igba ti wọn jẹun owurọ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi ju awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun un pe, Oluwa; Iwọ mọ pe mo fẹran rẹ, O wi fun un pe, Maa bọ awọn ọdọ-agutan mi. O tun wi fun un nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun un pe, Bẹẹ Oluwa; iwọ mọ pe mo fẹran rẹ. O wi fun un pe, Maa bọ awọn agutan mi. O wi fun un nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹran mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitori ti o wi fun un nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹran mi bi? O si wi fun un pe, Oluwa, iwọ mọ ohun gbogbo; iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ. Jesu wi fun un pe, Maa bọ awọn agutan mi.” (Johanu 21:1l5-17)

Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi, Jesu funrarẹ ni O yan Peteru lati ṣe amujoto awọn aguntan rẹ. Oun ko wa ni yan ẹnikẹni lati ṣe ohunkohun ti ko ba ṣetan lati mu ẹni naa yẹ lati ṣe e. Nitori eyi, nipa sisọ fun Peteru lati bọ tabi tọju awọn aguntan rẹ, o tunmọ si pe O ti pinnu lọkan rẹ lati ṣe arakunrin yi yẹ fun iṣẹ naa niyẹn. Awọn wo wa ni aguntan rẹ ti O n tọka si nigba ti O n ba Peteru sọrọ? Gbogbo ijọ awọn ti o gbagbọ ninu rẹ, awọn eniyan mimọ rẹ, ni aguntan rẹ. (Cf. Luuku 12:32; Johanu 10:1-16)

Ni kukuru, pasitọ jẹ ẹni kan ti Jesu yan, ti O si mu yẹ lati ṣe amujoto awọn ọmọlẹyin rẹ nibi yowu ti wọn le wa ati iye yowu ti wọn le jẹ, ki ifẹ rẹ ba le wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Iru awọn ẹni bẹẹ ni a si tun tọka si ninu bibeli gẹgẹbi alagba tabi biṣọọbu. Boya wọn wa jẹ pasitọ lori ijọ Ọlọrun kekere tabi pupọ kọ ni koko. Koko ni pe Jesu yan wọn, O si ṣe wọn yẹ lati ṣe amojuto awọn ọmọ rẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 19:1-7; 1Timoti 1:3; Titu 1:5)

KI NI AWỌN AMUYẸ PASITỌ?
Ki wa ni awọn nkan ti o gbọdọ wa ninu eniyan ki a to le ri gẹgẹ bi ẹnikan ti Jesu ti yan lati jẹ pasitọ tabi oluṣọ-agutan fun awọn ọmọ rẹ? Pọọlu mẹnuba pataki lara awọn nkan wọnyi ninu lẹta rẹ akọkọ si Timoti, eyi ti o ka bayi:
“Otitọ ni ọrọ naa, bi ẹnikan ba fẹ lati jẹ biṣọọbu, iṣẹ rere ni o n fẹ. Nitori bisọọbu gbọdọ jẹ alailẹgan, alaya kan, ẹni ti o lee ko ara rẹ ni ijanu, ẹni ti n fi ọgbọn ṣe ohun gbogbo, olorukọ rere, olufẹ alejo ṣiṣe, ẹni ti o ni oore-ọfẹ lati kọ awọn eniyan. Ẹni ti kii ṣe omuti, tabi oniwahala, bi ko ṣe onisuuru, kii ṣe onija, tabi olufẹ owo; Ẹni ti o lee ṣe akoso idile rẹ daradara, ti awọn ọmọ rẹ si le gbọ tirẹ pẹlu itẹriba ni ohun gbogbo; (Nitori bi ọkunrin kan ko ba mo bi oun o ti ṣe ikawọ idile ara rẹ, oun o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?) Ki o ma ṣe jẹ ẹni tuntun ninu igbagbọ, ki o ma baa gberega, ki o si ṣubu gẹgẹ bi Eṣu ti ṣe. O si yẹ ki o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn alaigbagbọ: ki o ma baa bọ sinu ẹgan ati sinu idẹkun Eṣu.” (1Timoti 3:1-7)

Bi mo ti ṣe sọ siwaju, ni igba aye awọn apositeli Pọọlu, ara awọn apele ti a tun le lo fun pasitọ tabi oluṣọ-aguntan ni biṣọọbu tabi alagba. Nitorina, awọn amuyẹ ti Pọọlu sọ pe eniyan gbọdọ ni ki Timoti to le fi ṣe biṣọọbu tabi alamojuto fun awọn ọmọ Ọlọrun naa ni pasitọ gbọdọ ni. Lotitọ Ọlọrun nikan naa ni o le yan eniyan, ki O si tun ṣe yẹ lati jẹ pasitọ. Amọ ko digba ti Ọlọrun ba kọ si wa lati ọrun pe pasitọ ni ẹnikan ki a to mọ boya pasitọ ni tabi pasitọ kọ. Ti a ba ti kiyesi awọn amuyẹ ti Pọọlu sọrọ nipa wọn ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yi ninu aye eniyan, a le sọ daju boya a ṣe e yẹ lati jẹ pasitọ tabi bẹẹ kọ.

Gẹgẹ bi a si ti ṣe ri, awọn amuyẹ naa ko ni nkankan ṣe pẹlu pe ki a lọ si ile ẹkọ bibeli tabi ki a so kọla funfun mọ ọrun tabi ki a de ade biṣọọbu. Dipo eyi, lakọkọ, wọn ni i ṣe pẹlu ki eniyan jẹ ọmọ Ọlọrun ti aye rẹ n ti n so eso ẹmi fun akoko ti o kojuosuwọn, ti a si le jẹri nipa rẹ. Ki si ni idi? Idi ni wipe pataki iṣẹ pasitọ ni ki o ṣe amojuto awọn ọmọ Ọlọrun lati jẹ ki aye wọn ri bi Ọlọrun ṣe fẹ ki wọn ri. Ti aye tirẹ gan ko ba wa jẹ apẹẹrẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ri ninu aye awọn ọmọ rẹ, ti oun funrarẹ ko ma so eso ẹmi fun igba ti o ṣe diẹ to lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe dajudaju ọmọ Ọlọrun tootọ ni o jẹ, bawo ni o ṣe le jẹ pasitọ tootọ ati rere?

Ekeji, awọn amuyẹ ti Pọọlu n sọrọ nipa ni i ṣe pẹlu ki eniyan ni ẹbun ẹmi lati kọ ọrọ Ọlọrun. Gẹgẹ bi a si tun ṣe ri ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, akopọ ni Jesu fi iṣẹ pasitọ ati olukọni ṣe. Idi si ni pe ko si bi eniyan ṣe fẹ jẹ pasitọ to dangajia ti ko ba le kọ awọn eniyan ni ọrọ Ọlọrun. Bawo ni o ṣe fẹ fi ifẹ Ọlọrun han si awọn ti o n ṣedari, ti ko ba le kọ wọn ni ọna ti o ye kooro? Nitorina, ẹnikẹni to ko ba le fi arabalẹ kọ awọn eniyan ni ọrọ Ọlọrun pẹlu suuru ati lẹsẹẹsẹ ko ki i ṣe pasitọ, bi o tilẹ n wọ kọla tabi bi o tilẹ ti lọ si ile-ẹkọ bibeli kan tabi omiran.

Wayi o, ẹni ti yo wa kọ eniyan ni ọrọ Ọlọrun naa gbọdọ mọ Ọlọrun ati ọrọ rẹ daju. O gbọdọ ni oye gbogbo ifihan Ọlọrun ti o wa ninu bibeli ati bi awọn ifihan yi ṣe gbọdọ tọ iṣiṣẹ aye awọn eniyan. Bẹẹni o gbọdọ le sọ daju bi Pọọlu ṣe sọ fun awọn alagba ijọ Efesu pe, “Emi ko fa sẹyin lati sọ ohunkohun ti o le ṣanfani fun yin ati lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun yin.” (Wo: Iṣe Apositeli 20:20&27) Aijẹbẹ, a ko le pe ni ẹni amuyẹ fun iṣẹ pasitọ. Idi ni yi ti a fi ni awọn eke pasitọ ati olukọ. Awọn wọnyi ni awọn apositeli igbaani kilọ fun wa lati kiyesara fun. Ko si soro lati mọ wọn. Idi ni si pe eso ti aye wọn n so yoo fi wọn han. Yatọ si pe wọn yoo jẹ ẹlẹkọ odi, ẹni ti o n tẹle ẹkọ awọn ẹmi eṣu, wọn o tun jẹ opurọ, oniṣẹkuṣe ati ẹni ti aye rẹ ko wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o ye kooro. Awọn wọnyi ni a gbọdọ yẹra fun, ki wọn ma ba a ṣi wa lọna, ki wọn si gba igbagbọ wa danu kuro lọwọ wa. (Wo: 1Timoti 4:1-5; 2Timoti 4:3; 2Peteru 2; Juudu)

Ẹkẹta, awọn amuyẹ ti Pọọlu n sọrọ nipa ni i ṣe pẹlu ki ẹni ti a n wo bi pasitọ ni ẹbun iṣakoso. Bawo ni a ṣe wa fẹ mọ boya ẹni naa ni ẹbun lati ṣe akoso tabi amojuto awọn ọmọ Ọlọrun? Pọọlu ni ki a wo bi o ṣe n ṣe akoso ile rẹ, gẹgẹ bi ẹni ti o ti gbeyawo, ti o si tun ti bimọ. Ti ko ba wa i ti gbeyawo tabi bi ọmọ nkọ? A le wo bi o ṣe n ṣe akoso awọn ti o wa labẹ rẹ ni bi iṣẹ rẹ tabi ki a dan wo fun igba diẹ pẹlu isakoso awọn eniyan Ọlọrun perete, ki a si wo bi yoo ṣe ṣe si. Nikukuru, a ko gbọdọ kanju fi ẹnikẹni si ipo pasitọ tabi adari ijọ, niwọn igba ti a ko ba i ti ri awọn amuyẹ ti bibeli tọka si ninu aye rẹ. (Wo: 1Timoti 3:10&5:22)

Amuyẹ miran ti a tun nilo lati ri ninu ẹnikẹni ti a le pe ni pasitọ ni ifẹ ati itara lati ṣe amujuto awọn ọmọ Ọlọrun, ki ifẹ rẹ ba a le wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Eyi tunmọ si pe pasitọ ko ki i ṣe ẹnikan ti a o ma mu ni ori tabi mu ni ọrun ki o to tara ṣaṣa mu ọrọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni abẹ akoso rẹ ni ọkunkundun. Dipo eyi o jẹ ẹni ti Ọlọrun ti fi ifẹ ati ṣe rere awọn ọmọ rẹ si ni ọkan, ti o si ṣetan lati fi ifẹ yi han ni igba ti o wọ ati igba ti ko wọ. (Wo: Johanu 10:11-13; Roomu 1:11; 2Tẹsalonika 2:17-3:5; 1Peteru 5:2)

KI NI IṢẸ TABI OJUṢE PASITỌ?
Pẹlu awọn nkan ti a ti gbeyẹwo lori amuyẹ pasitọ, ki wa ni awọn nkan ti a le pe ni ojuṣe rẹ? Ki gan ni idi ti Ọlọrun fi n yan pasitọ sori awọn ijọ rẹ? Idi ni pe ko fẹ ki awọn eniyan rẹ dabi aguntan ti ko ni olusọ. Mose, ki o to fi aye silẹ, gba adura yi si Ọlọrun: “Jẹ ki Oluwa, Ọlọrun ẹmi gbogbo eniyan, ki o yan ọkunrin kan sori ijọ. Ti yoo maa ṣaaju wọn jade lọ, ti yoo si maa ṣaaju wọn wole wa, ti yoo si maa sin wọn lọ, ti yoo si maa mu wọn bọ; ki ijọ eniyan Oluwa ki o ma baa dabi agutan ti ko ni olusọ.” (Numeri 27:16-17) Eyi n fi idi rẹ mulẹ fun wa pe a nilo olusọ-aguntan ninu aye wa ati pe a ko le da ṣe akoso aye wa funra wa (Jeremaya 10:23-24). Ẹni kan ṣoṣo ti o ṣi le se akoso aye wa lọna ti a o fi da ẹni ti o yẹ ki a da ninu Jesu Kirisiti. Idi niyi ti O fi pe ara rẹ ni Oluṣọ-aguntan rere ati alakoso ọkan wa (Johanu 10:11; 1Peteru 2:25).

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ pe Jesu gan ni olori oluṣọ-aguntan, ko si ni aye lọwọlọwọ bayi pẹlu wa. Ẹmi mimọ rẹ ni o wa pẹlu wa. Nitori eyi ni O ṣe ma n ṣe awọn eniyan bi ti wa yẹ nipasẹ Ẹmi mimọ rẹ lati ṣe lara iṣẹ rẹ gẹgẹ bi pasitọ gbogbo wa. Ki wa ni awọn iṣẹ tabi ojuṣe yi? Koko rẹ naa ni ṣiṣe amojuto awọn ọmọ Ọlọrun ki ete ati ifẹ rẹ ba le wa si imuṣẹ ninu ati lori aye wọn, ki wọn si pari ere ije wọn ninu aye yi si inu ijọba rẹ (Iṣe Aposteli 20:28; Kolose 1:28-29; 1Peteru 5:2). Eyi si ni i ṣe pẹlu awọn nkan wọnyi:

  • Mimojuto aye ara rẹ lati duro ṣinṣin ninu ifẹ Ọlọrun (Iṣe Apositeli 20:28; 1Timoti 4:15-16).
  • Diduro niwaju awọn ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi apẹẹrẹ ifẹ Ọlọrun (1Timoti 4:12; Titu 2:7-8; 1Peteru 5:3).
  • Kikọ awọn ọmọ Ọlọrun ni ife rẹ, ki wọn ba le mọ iyatọ laarin ohun ti o tọ ati eyi to ko tọ (Lẹfitiku 10:8-11; Malaki 2:7; Esikiẹli 44:23; 1Timoti; 2Timoti; Titu).
  • Adura gbigba fun iduro ṣinṣin awọn ọmọ Ọlọrun ninu ifẹ rẹ ati fun aabo kuro lọwọ awọn onigbagbọ eke ati ikẹkun Eṣu (Iṣe Apọsiteli 6:3-4; Kolose 4:12).
  • Ibawi ati itọsọna awọn ọmọ Ọlọrun, ki ijọ rẹ ba le wa ni ilera (1Korinnti 5; 1Timoti 1:3-7; Titu 1:5-16).
  • Imupada awọn ọkan ti o ṣako lọ (Iṣikiẹli 34:1-6; Galatia 6:1).

BAWO NI PASITỌ ṢE YẸ KI O ṢE IṢẸ RẸ?
Wayi o, ọtọ ni ki pasitọ mọ ojuṣe rẹ, ọtọ si ni ki o ṣe e. Ọtọ tun ni ki pasitọ ṣe ojuṣe rẹ, ọtọ tun si ni ki o ṣe ni ọna ti o ba ifẹ Ọlọrun mu. Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti, sọ wipe ki olukuluku ti o n ṣiṣẹ fun Ọlọrun kiyesara lori ọna ti o n gba a ṣe. Ki si ni idi? Idi ni pe ọna ti a ba gba ṣe iṣẹ rẹ ni yoo so boya yoo yọri si mimu ifẹ, ete ati ipinnu rẹ ṣẹ tabi bẹẹkọ. Yatọ si eyi, ọna ti a ba gba ṣe iṣẹ rẹ ni yoo so boya awa funrawa yoo ri ere gba lati ọwọ rẹ tabi bẹẹkọ. (Wo: 1Kọrinnti 3:5-15 & 9:24-27)

Idi si niyi ti Peteru ṣe gba awọn oluṣọ-aguntan ni iyanju pẹlu awọn ọrọ yi: “Awọn alagba ti n bẹ laarin yin ni mo gbaniyanju, emi ẹni ti i ṣe alagba bi ẹyin, ati ẹlẹrii iya Kirisiti, ati alabaapin ninu ogo ti a o fihan: Ẹ maa ṣe oluṣọ-aguntan awọn eniyan ti Ọlọrun fi sabẹ akoso yin, ẹ maa bojuto wọn, ki i ṣe afipaṣe, bi ko ṣe tifẹtifẹ, bẹẹ ni ki i ṣe ọrọ ere ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkan ti o mura tan. Bẹẹ ni ki i ṣe bi ẹni ti n lo agbara lori ijọ ti n bẹ labẹ akoso yin, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara yin ni apẹrẹ fun wọn. Nigba ti olori Oluṣọ-aguntan ba si de, ẹyin o gba ade ogo ti ki i sa.” (1Peteru 5:1-4)

Pẹlu nkan ti Peteru sọ yi, a ri wipe oluṣọ-aguntan lakọkọ gbọdọ mọ pe oun kọ ni o ni awọn ti o wa ni abẹ akoso rẹ – Ọlọrun ni o ni wọn. Nitorinaa, ko gbọdọ lo ipo ati aṣẹ rẹ lati rẹ wọn jẹ tabi ja wọn lole tabi mu wọn ṣubu tabi mu wọn parun. Dipo eyi, o gbọdọ ṣetan lati sin wọn pẹlu itara, tọkantọkan ati tifẹtifẹ. Yatọ si eyi, o gbọdọ fi gbogbo igba duro niwaju wọn gẹgẹ bi apẹẹrẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ri ninu aye wọn. Aijẹbẹ, Ọlọrun ko le ti ipasẹ rẹ mu gbogbo ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye awọn ọmọ rẹ. Bẹẹ si ni oun naa ko le ri ere gba lọwọ Ọlọrun fun iṣẹ iriju rẹ. (Wo: 2Kọrinnti 10:8&13:10)

Siwaju si, pasitọ gbọdọ gbe ọkan rẹ le Ọlọrun nikan fun amuyẹ ati aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi oluṣọ awọn aguntan Ọlọrun. Pọọlu sọ eyi fun wa: “Kii ṣe pe awa to fun ara wa lati ṣiro ohunkohun bi ẹni pe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn tito wa ti ọdọ Ọlọrun wa. Ẹni ti o fun wa ni agbara eyi ti o to lati jẹ iranṣẹ majẹmu tuntun naa; kii ṣe ti iwe, bi ko ṣe ti ẹmi: nitori iwe a maa pani, ṣugbọn ẹmi a maa sọni di aaye.” (2Korinnti 3:5-6) Peteru naa tun sọ wipe, “…bi ẹnikẹni ba n ṣe iṣẹ isin, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fi fun un…” (1Peteru 4:11) Eyi tunmọ si pe pasitọ tabi iranṣẹ Ọlọrun kankan ko gbọdọ gboju le ohun miran yatọ si Ọlọrun fun amuyẹ ati aṣeyọri rẹ. Ko gbọdọ gbojule imọ-ijinlẹ rẹ, ẹkọ rẹ, adura gbigba rẹ, ẹkọ bibeli tabi imọ bibeli rẹ, owo, eniyan, ẹgbẹ okunkun ati bẹẹbẹẹ lọ. Aijẹbẹ, yoo kuna gidigidi.

NJẸ IṢẸ IRANṢẸ PASITỌ NI AALA BI?
Ṣe iṣẹ iranṣẹ pasitọ wa ni alaa tabi gbedeke bi tabi ko ni? A bi ki a sọ pe ṣe ti eniyan ba jẹ pasitọ lotitọ, ṣe gbogbo ọmọ Ọlọrun naa ni o jẹ pasitọ fun? Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Korinnti: “Ṣugbọn awa ki yoo ṣogo rekọja ara wa, ṣugbọn ero wa ni lati duro ni ala naa, ti Ọlọrun ti pin fun wa, ani lati de ọdọ yin. Nitori awa ko koja aaye wa rara, bi ẹni pe awa ko de ọdọ yin. Nitori awa tilẹ de ọdọ yin pẹlu ninu iyinrere Kirisiti. Awa ko sogo rekọja ala wa, lori iṣẹ elomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ yin ti n dagba si, ki ala wa laarin yin pẹlu maa dagba soke si i.” (1Kọrinnti 10:13-15)

Ki ni eyi n fi ye wa? Oun fi ye wa pe boya pasitọ ni wa ni o tabi apositeli tabi ajinhinrere tabi wolii, iṣẹ iranṣẹ ẹnikọọkan wa ni aala, o ni ibi ti Ọlọrun pin fun wa lati ṣe iṣẹ rẹ. Nitorina, ibi ti aala iṣẹ iranṣẹ wa ba de ni o yẹ ki a ti mura lati lo aṣẹ tabi anfaani ti O ba fun wa. A ko lẹtọ lati lo awọn nkan yi lori tabi laarin awọn ọmọ Ọlọrun ti ko ko si abẹ akoso wa. O wa ṣeni laanu pe ọpọ iranṣẹ Ọlọrun ni ko mọ eyi. Nitorinaa, ọpọ igba ni wọn ma n fẹ ki awọn ti ko mọ wọn ri bu ọwọ fun wọn tabi ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ tabi tẹlẹ aṣẹ tabi imọran wọn nitoripe wọn jẹ pasitọ, wolii ati bẹẹbẹẹlọ. Nigba ti eyi ko ba si waye, wọn a sọ da ibinu. Eyi si le fa idajọ Ọlọrun wa si ori wọn, bi idajọ rẹ ṣe wa si ori Mose nitoripe ko fi ọwọ Ọlọrun wọ awọn eniyan rẹ ni ọjọ kan. (Wo: Numeri 20:1-12)

Nitori naa, ti o ba jẹ pasitọ, mọ awọn ti Ọlọrun yan ọ gẹgẹ bi pasitọ lori wọn, ki o si jẹ ki lilo aṣẹ rẹ tabi anfaani iṣẹ iranṣẹ rẹ mọ ni aarin wọn. Ti Ọlọrun si ba wa tun jẹ ki alaa iṣẹ iranṣẹ rẹ gbooro si, o tun le tẹsiwaju lati lo aṣẹ ati anfaani iṣẹ iranṣẹ rẹ lati ṣe amojuto awọn miran ti O ba tun fi si abẹ akoso rẹ. Ṣugbọn ma ṣe ṣe aṣiṣe lati ṣakoso aye awọn ti Ọlọrun ko fi si abẹ akoso rẹ. Eyi le ko ba ọ lọna ti ko ṣe e fẹnusọ.

IHA WO NI O YẸ KI A KỌ SI AWỌN PASITỌ WA?
Bi a ti ṣe ri, Ọlọrun lo ma n ṣe awọn eniyan yẹ lati jẹ pasitọ tabi oluṣọ-aguntan tun awọn ọmọ rẹ. Amọ, o tun wa yẹ ki o ye wa pe bi o ti wu ki Ọlọrun ṣe awọn eniyan yẹ to fun iṣẹ iranṣẹ yi, ti a ko ba kọ iha ti o tọ si wọn ati si iṣẹ iranṣẹ wọn, ifẹ, ete ati ipinnu Ọlọrun ko le fi taratara wa si imuṣẹ ninu aye wa, ti o ba tilẹ wa si imuṣẹ rara. Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe Mose jẹ oluṣọ-aguntan tootọ, ti Ọlọrun si ṣe yẹ lati ṣe amojuto awọn eniyan rẹ ati lati ṣe itọni wọn wọ ilẹ-ileri, meji pere ninu awọn agbagba ti o ko jade lati Ijibiti ni o wọ ile ileri naa. Ki ni o si fa? Iha ti wọn kọ si iṣedari rẹ lo fa. Ti awa naa ko ba si kọ iha ti o tọ si awọn ti Ọlọrun yan fun wa gẹgẹ bi oluṣọ-aguntan lati ṣe idari wa wo ile ogo rẹ lalai ni ailabawọn, o ṣeeṣe ki ifẹ, ete ati ipinnu rẹ ma wa si imuṣẹ lori aye wa, paapaa julọ ninu aye yi. (Wo: 1Korinnti 10:1-11)

Nitori naa, o yẹ ki a mọ iha ti o tọ lati kọ si awọn pasitọ wa. Ki wa ni awọn iha naa ti o yẹ ki a kọ si wọn? Akọkọ, a gbọdọ bọwọ fun wọn gidigidi gẹgẹ bi iriju Ọlọrun laarin wa. A ko gbọdọ ri wọn fin tabi ba wọn lopọ pẹlu ailoye. Eyi ko si ki i ṣe nitori pe wọn ṣe iyẹbibiye niwaju Ọlọrun ju wa lọ ṣugbọn nitori iṣẹ ti o gbe fun wọn fun idagbasoke, ipamọ ati iduro-ṣinṣin wa. (Wo: 1Tẹsalonika 5:12-13)

Ekeji, a gbọdọ gbọran si wọn lẹnu, niwọn igba ti ọrọ, irin ati iṣeṣi wọn ba ti wa ni ibamu pẹlu ọrọ ati ifẹ Ọlọrun. A gbọdọ mọ daju wipe Ọlọrun ti fun wọn ni aṣẹ lati ṣe amojuto wa fun idagbasoke, igbeniro ati iduro ṣinṣin ninu imọ Kirisiti ati ninu igbagbọ. Yatọ si eyi, Ọlọrun yoo bere lọwọ wọn bi wọn ba ṣe ṣe itọju ati amojuto wa si. Ko wa ni dara ki wọn ma ṣe iṣẹ wọn laarin wa pẹlu ikẹdun, omije, ibanujẹ tabi ẹru. Eyi ko ni yọri si ire tabi ayọ fun wa. Idi kan pataki si ni yi ti ọpọ ọmọ Ọlọrun ko ṣe ma ṣe orire, ki wọn si gberu si ninu igbagbọ wọn labẹ akoso awọn oluṣọ-aguntan wọn, bi o tilẹ jẹ pe wọn ti pẹ kanrikese ninu ijọ ti wọn wa. Oun naa ni o tun fa ti awọn miran ṣe ti ṣegbe laitọjọ ati lairotẹlẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn pasitọ wọn n gbadura fun wa kikan. Niwọn igba ti a ko ba si yipada, ki a si bẹrẹ si ni mu iṣedari awọn oluṣọ-aguntan wa ni ọkunkundun, nkan ko ni yipada fun wa ninu ọpọ awọn ijọ wa. (Wo: Luuku 13:6-9; 1Kọrinnti 16:10-11; 2Kọrinnti 10:8&13:10; Heberu 13:7&17)

Ẹkẹta, a ko gbọdọ gbagbe rara pe ẹlẹran ara ni awọn pasitọ tabi oluṣọ-aguntan wa naa. Nitori naa, wọn le ṣe aṣiṣe tabi kuna. Idi niyi ti a fi gbọdọ ma fi gbogbo igba tẹle ọrọ Pọọlu ti o sọ wipe, “Ẹ maa ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti n ṣe afarawe Kirisiti.” (1Korinnti 11:1) Eyi wa ja si pe niwọn bi awọn pasitọ wa ba ṣe tẹle Kirisiti ni ọrọ, iwa ati iṣe ni ki awa naa ṣe tẹle wọn. Ni ọnakọna ti wọn ko ba ti tẹle, awa naa ko gbọdọ tẹle wọn. Aijẹbẹ, a le tipasẹ eyi kuna tabi ṣubu ninu irinajo igbagbọ wa.

Ẹkẹrin, a gbọdọ mọ pe ojuṣe wa ni lati ran iṣẹ iranṣẹ awọn pasitọ wa lọwọ pẹlu ogbọn wa, nkan ini wa, oye wa, imọ-ijinlẹ wa ati bẹẹbẹẹ lọ. Ki ni idi? Aṣẹ Jesu Kirisiti ni pe ki a ṣe bẹ. Yatọ si eyi, ti awa gan ba mọ ohun ti o tọ fun wa, o yẹ ki oye ye wa pe ti eniyan ba n fi gbogbo igba fi ara rẹ jin lati ṣe itọju ati ikẹ wa, o yẹ ki a ma fi ẹmi imore han loore-koore. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe isoro ati aniyan wa nikan ni o yẹ ki a jẹ ki wọn jẹ alabapin ninu wọn; o tun yẹ ki a jẹ ki wọn jẹ alabapin iṣorire, ayọ ati ọpọ yanturu wa. Aijẹbẹ, a le ba ijiya Ọlọrun pade, gẹgẹ bi awọn ara igbaani ti ṣe ba pade. (Wo: Malaki 3:8-12; 1Kọrinnti 9:14; Galatia 6:6; Filipi 4:10-19)

ỌRỌ IPARI
Ni akotan, pasitọ ni ẹni naa ti Ọlọrun ṣe yẹ lati jẹ oluṣọ-aguntan fun awọn ọmọ rẹ. Ki a ba si le gbadun iṣẹ iranṣẹ rẹ, a gbọdọ mọ daju, ki a bọwọ fun, ki a ran iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ, ki a si gbọran si lẹnu ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun.

IBEERE

  • Bawo ni iṣẹ pasitọ ṣe ṣe pataki to ninu ijọ Ọlọrun?
  • Awọn kan a ma sọ wipe wolii ga ju pasitọ lọ ninu ijọ. Njẹ otitọ ni eyi tabi irọ ni?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 11, OGUN 2021
Read More »