Ọna lati di ọta Ọlọrun | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Ogun 08, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 14
Olufẹ: kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ogun 2021. Ki oore-ọfẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa, ifẹ ti Ọlọrun ati ibadapọ Ẹmi Mimọ wa pẹlu rẹ nisinsinyi ati titi lailai. Amin.
Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Apọsiteli Pọọlu, ti o sọ wipe, “Njẹ oju rere eniyan ni emi n wa ni tabi ti Ọlọrun? Tabi emi n fẹ lati wu eniyan, nitori pe, bi emi ba si n wu eniyan, emi ki yoo le ṣe iranṣẹ Kirisiti.” (Galatia 1:10) Njẹ eyi wa tunmọ si pe ko dara rara lati gba oriyin awọn eniyan tabi lati dun wọn ninu? Rara o! Dipo bẹẹ, o tilẹ ṣe pataki ki a kọ lati ma ṣe awọn nkan ti o dun mọ awọn eniyan ninu, paapaa julọ awọn ti a jọ n ṣepọ ninu aye wa. Idi si ni pe eyi yoo mu ki ifẹ, alaafia ati iṣọkan ti o wa ni aarin wọn siwa gbooro si.
Ki si ni Ọlọrun n fẹ laarin awọn eniyan? O n fẹ ifẹ, alaafia ati iṣọkan laarin wọn. Nitorina, nigba ti a ba n lepa lati tẹ awọn eniyan lọrun, ki a ba le mu awọn nkan wọnyi waye, inu Ọlọrun n dun si wa. Ẹnikẹni ti ko ba si ni kẹkọ, ki o si tun ma ṣiṣẹ lati dun awọn eniyan ninu ni ọna yi ko daju pe yoo le fi ara rẹ jin fun ikoraẹni-nijanu ti eniyan gbọdọ ni lati le dun Ọlọrun ninu.
Amọ ṣa o, a nilo lati ṣọra lati ma ṣe ṣẹ Ọlọrun nigba ti a ba n gbiyanju lati tẹ awọn eniyan lọrun. Eyi si ni koko ọrọ ti Pọọlu tẹ pẹpẹ rẹ silẹ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn. O fẹ ki a mọ pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ma n fẹ ti a tiraka lati tẹ awọn eniyan lọrun, ki ibaṣepọ wa pẹlu wọn ba le dan mọran, ki o si jẹ eyi ti o ni alaafia, ko fẹ ki a fi eleyi ba ibaṣepọ wa pẹlu rẹ jẹ.
Ki wa ni eyi tunmọ si? Ni kukuru, o tunmọ si pe Ọlọrun funrarẹ ni O gbọdọ sọ fun wa ọna ti a gbọdọ gba tẹ awọn eniyan lọrun. Lotitọ, awọn eniyan le fẹ ki a rin ni awọn ọna kan ki inu wọn ba le dun tabi yọ si wa. Ṣugbọn wọn ko ki i ṣe ẹlẹda wa, bẹẹ si tun ni wọn ko ki i ṣe ẹni ti yoo ṣe idajọ wa tabi pin wa ni ere fun awọn nkan ti a ba ṣe ni aye yi, boya rere ni tabi buburu. Nitori naa, bi o tilẹ jẹ wipe ko buru ki wọn fẹ ki a tẹ wọn lọrun ni ọna kan tabi omiran, igba ti nkan ti wọn n fẹ ba tẹ Ọlọrun nikan ni a gbọdọ ṣe. Ti nkan ti wọn n fẹ ko ba tẹ ẹ lọrun tabi wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, a gbọdọ kọ lati ṣee fun wa tabi lati fi le wọn lọwọ.
Njẹ eyi yo wa mu inu wọn dun bi? Ṣe ki a ṣe nkan ti ko dun mọ awọn eniyan ninu le mu ki inu wọn dun si wa bi? Rara o! Ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọ ti o mọ ojuṣe rẹ si Ọlọrun, pataki julọ ninu gbogbo ilepa wa ni aye yi ni ki a tẹ ẹ lọrun, ki a si tun mu inu rẹ dun, ko ki i ṣe ki a tẹ awọn eniyan lọrun ati ki a mu inu wọn dun (2Korinnti 5:9). Lotitọ, ni ọpọ igba, ti a be tẹ Ọlọrun lọrun, ti si mu inu rẹ dun, a o tẹ awọn eniyan lọrun ati mu inu wọn dun pẹlu. Ṣugbọn a ma n ri awọn igba miran ti o jẹ wipe jijẹ itẹwọgba niwaju rẹ yoo gbe wa kọlu awọn eniyan. Eyi yoo si jẹ nitori ikorira wọn fun ododo ati otitọ rẹ (Johanu 3:19-21).
Sibẹsibẹ, bi a ba tilẹ gbe wa kọlu eniyan nitoripe a fẹ tẹ Ọlọrun lọrun, a ko gbọdọ ba ọkan jẹ tabi ba ara jẹ. Idi si ni pe o ṣan pupọpupọ lati jẹ ọta eniyan, ki a si fi igba diẹ jiya ikọsilẹ, eebu ati inunibini wọn ju ki a jẹ ọta Ọlọrun, ki a wa sọnu titi ayeraye. Ti o ba ni awọn eniyan gẹgẹ bi ọta rẹ, Ọlọrun le gba ọ ni ọwọ wọn. Ṣugbọn ti o ba ni Ọlọrun gẹgẹ bi ọta ayeraye rẹ, tani yoo gba ọ lọwọ rẹ? Ko si!
Jemisi sọ wipe, “Ẹyin pansaga ọkunrin, ati pansaga obinrin, ẹ ko mọ pe ibarẹ aye iṣọta Ọlọrun ni? Nitori naa ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aye di ọta Ọlọrun.” (Jemisi 4:4) Njẹ o ri bayi? Ti o ba titori nkankan, boya ẹru, owo, igbadun, ipo tabi ifẹ si oriyin awọn eniyan, di ọrẹ aye, o ti di ọta Ọlọrun niyẹn o. Nkan ti yoo si ti ẹyin rẹ yọ ko ni dara fun ọ tabi fun ọ ni igbadun kankan, boya ni aye yi tabi ni eyi ti o n bọ.
Ranti Pilatu. Kini idi ti o fi tu ọdanran silẹ lati lọ tẹsiwaju ninu igbe aye ẹṣẹ rẹ ṣugbọn ti o da alailẹbi eniyan lẹbi iku? Idi ni pe o fẹ tẹ awọn eniyan lọrun (Maaku 15:15). Nitori naa, o di ọta Ọlọrun ati ọta otitọ ati idajọ ododo nitoripe o fẹ ṣe nkan ti o wu awọn eniyan. Mo wa n wo iru ẹjọ ti o fẹ ro fun un ni ọjọ idajọ, ti o ba jẹ pe ko ri igbala nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti Jesu ki o to ku. Mo si tun n wo nkan ti iwọ naa yoo ri wi fun ni ọjọ ti O ba bẹ ọ wo, ti o ba fi aye gba ara rẹ lati di ọta rẹ nitoripe o fẹ jẹ ọrẹ awọn alagbere, oniṣina, ole, gbajuẹ, oṣo tabi ika eniyan kan tabi omiran. Amọ ṣa o, adura mi ni pe ohunkohun ko ni ṣe aṣeyọri lati sọ ọ di ọta Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ọna lati di ọta Ọlọrun | Paito J.O. Lawal Read More »






