Àwọn ènìyàn tí o nílò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu ete rere rẹ fun aye rẹ fun ọdun yi ṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati bẹrẹ si ni gbadura pe ki Ọlọrun la ọna fun gbogbo awọn eniyan ti o nilo fun ete rere rẹ lati wa si imuṣẹ ninu aye rẹ lati bẹrẹ si ni tọ ọ wa lalai si idaduro. Aijẹbẹ, ọdun yii le kọja lọ, ti ete rẹ ko si ni wa si imuṣẹ ninu aye rẹ.

Ki ni o fa ti Dafidi fi le di ọba lori Isiraẹli, pẹlu gbogbo nkan ti Ọba Sọọlu ṣe lati doju ija kọ ati lati pa a run? Idi kan pataki fun eyi ni pe Ọlọrun la ọna fun awọn eniyan ti o tọ lati wọ inu aye rẹ wa ni asiko ti o yẹ. Fun apẹrẹ, ni kete ti o pa Goliati ni Jonatani wọ inu aye rẹ wa. Ọkunrin yi ṣi ṣetan lati ku ki o ba a le di ọba, bi o tilẹ jẹ wipe ọkan lara awọn arẹmọ Ọba Sọọlu ni oun funrarẹ jẹ.

Lafikun, bi a ti ṣe fi han wa ninu 1Kironika 11 ati 12, Dafidi ni oniruuru awọn akọni jagunjagun ti Ọlọrun ran si lati fi ẹsẹ rẹ mulẹ gẹgẹ bi ọba lori Isiraẹli. Awọn eniyan wọnyi si wa fi ara wọn jin fun debi wipe ti o ba kan da nkankan gẹgẹ bi aba, nṣe ni wọn yoo gba bi aṣẹ, ti wọn yoo si ṣiṣẹ le lori, bi o tilẹ jẹ wipe eyi le la ẹmi wọn lọ. Abalajọ ti ijọba Isiraẹli ṣe wa ni ailewu ni abẹ iṣedari rẹ, lẹyin igba ti Ọlọrun ti pada fi si ori itẹ.

Siwaju si, ki ni idi ti iyinrere Jesu Kirisiti si ṣe n lọ si ibi gbogbo ni agbaye loni? Idi ni pe lati ibẹrẹ-pẹpẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ ni Ọlọrun ti n fun ni awọn ọkunrin ati obinrin ti o ṣe fọkantan gẹgẹ bi ọmọlẹyin rẹ. A si ri lara awọn wọnyi awọn ti wọn ṣetan lati padanu ẹmi wọn ni mimu iyinrere rẹ lọ si opin aye, ki a ba a le tipasẹ rẹ gba ọpọ eniyan la.

Nitorina, fun ete Ọlọrun lati wa si imuṣẹ ninu aye wa lẹkunrẹrẹ, awọn eniyan kan ti O ti yan lati ran wa lọwọ gbọdọ tọ wa wa ni asiko, ki wọn si fi tọkan-tọkan ṣe ifẹ rẹ ninu aye wa. O wa ṣeni laanu pe ọpọ aye, ile, okowo ati ijọ ni ko ma a ni iriri imusẹ ete Ọlọrun ninu wọn loni nitori pe awọn eniyan ti o tọ ko si ninu wọn. Ti awa naa ko ba wa fẹ padanu imuṣẹ ete Ọlọrun ninu aye wa, a gbọdọ bẹrẹ si ni gbadura si i pe ki O la ọna fun gbogbo awọn oluranlọwọ ti O ti yan fun wa lati tọ wa wa ni kiakia. Mo si gbadura pe ki gbogbo irufẹ awọn eniyan yi bẹrẹ si ni wọle sinu aye rẹ lati mu ete Ọlọrun ṣẹ ninu rẹ ni kiakia, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *