Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 17
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, iyẹn oṣu Ogun 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ninu oṣu naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe n wọ inu ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti pe ifẹ Ọlọrun fun ọ ni pe ki o ma fi gbogbo igba gbe iṣiṣẹ rẹ laye lati inu ẹkunrẹrẹ Ẹmi Ọlọrun ti o n gbe inu rẹ. Eyi tunmọ si pe, O n fojusọna pe ki o ma fi igba gbogbo sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ Ẹmi Mimọ. Nipa bayi, ohunkohun ti o ba jẹ jade laye rẹ yoo jẹ ohun ti yoo dun mọ Ọlọrun ninu ati ti yoo gbe awọn ti o wa ni ayika rẹ ro.
Wayi o, wo nkan ti Pọọlu sọ nipa eyi fun wa:
“Nitori naa ẹ ma ṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ maa moye ohun ti ifẹ Oluwa ja si. Ẹ ma si ṣe mu waini ni amupara, nitori eyi yoo pa yin run; ṣugbọn ẹ kun fun Ẹmi Mimọ. Ẹ si maa ba ara yin sọrọ ninu saamu, ati orin iyin, ati orin Ẹmi, ẹ maa kọrin, ki ẹ si maa kọrin didun ni ọkan yin si Oluwa. Ẹ maa dupẹ nigba gbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa.” (Éfésú 5:17-19)
Ki ni nkan akọkọ ti Pọọlu sọ fun wa ninu ẹṣẹ yi? Ohun naa ni pe ki a ma jẹ omugọ tabi alailoye ṣugbọn ki a ni oye ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Nitorina, nkan omugọ ni fun wa lati ma mọ ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Bẹẹni, nkan omugọ ni fun wa lati ma ṣe awawi lori pe a ko mọ nkan ti Ọlọrun fẹ fun aye wa. Idi si ni pe a le mọ ifẹ rẹ fun aye wa ti a ba fẹ lati mọ ọn, ti a si tun n tiraka lati mọ ọn. Ti a ko ba si wa mọ ifẹ rẹ fun aye wa, ki a si ma gbe ni ibamu pẹlu rẹ, nṣe ni a o fi aye wa ṣofo.
Siwaju si, lẹyin igba ti o ti sọ pataki ki a mọ ifẹ Ọlọrun fun aye wa tan, Pọọlu tẹsiwaju lati sọ nkan kan fun wa nipa ifẹ Ọlọrun fun wa. Ki si ni eyi? Oun naa ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati má mu ọti-waini ni amupara ṣugbọn lati kun fun Ẹmi Mimọ. Ki ni idi ti o fi fi mumu ọti-waini ni amupara we kikun fun Ẹmi Ọlọrun? Idi ni pe ti awọn eniyan ba yo tan, wọn a sọ ara wọn nu si abẹ iṣakoso waini, wọn a si bẹrẹ si ni sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ ninu wọn. Nibakan naa, ti awọn eniyan ba kun fun Ẹmi Ọlọrun, wọn a sọ ara wọn nu sabẹ iṣakoso rẹ, wọn a si bẹrẹ si ni sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ ninu wọn. Ki wa ni o fẹ, ṣe ki ọti-waini ma ṣe akoso rẹ ni tabi ki Ẹmi Ọlọrun ma ṣe akoso rẹ?
Ni kukukuru, ifẹ Ọlọrun ni pe ki o fi aye gba Ẹmi Ọlọrun lati di ọ mu ati lati ma ṣe akoso ohun ti o n sọ ati eyi ti o n ṣe. Bawo si ni o ṣe le ṣe eyi? O le ṣe e nipa kikun ara rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun. Idi si ni pe ọkan ni ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi Ọlọrun. Ti o ba si kun ara rẹ pẹlu ọrọ rẹ, o di dandan ki o ma wuwa, sọrọ ati kọrin lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ rẹ ti o wa ninu rẹ pẹlu irọrun. Eyi si wa jasi pe ti o ko ba ki i wuwa, sọrọ tabi kọrin lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ Ọlọrun, o ko kun fun ọrọ rẹ niyẹn – nkan miran ni o kun fun.
Bi mo ti ṣe fihan tẹlẹ, ti awọn eniyan ba yo tabi kun fun ọti waini, wọn a ma sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ. Ṣugbọn ko ki i ṣe ọti waini nikan ni awọn eniyan le kun fun. Awọn eniyan le tun kun fun ikoro, ojukokoro, ibinu, ilara, igberaga tabi ifẹkufẹ. Ki a ma fọrọgun, ohun yowu ti wọn ba kun fun ni wọn yoo ma sọrọ, kọrin ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ.
Wayi o, lotitọ awọn eniyan le sọ wipe awọn kun fun Ẹmi Ọlọrun. Ṣugbọn nkan ti wọn sọ wipe awọn kun fun kọ ni o ṣe pataki bikoṣe ohun ti aye wọn n gbe jade. Njẹ o tilẹ mọ wipe nipa wiwo abala bi nkan ti ṣe n lọ (sitetọsi) Wasáàpù, Fesibúùkù tabi awọn opo ẹrọ-ayelujara miran awọn kan, o le sọ nkan ti wọn kun fun? Bẹẹni, o le sọ boya ọrọ ati ifẹ Ọlọrun ni wọn kun fun tabi ibinu, irẹwẹsi, iporuru, ẹtanu, ifẹkufẹ, owu, ikunsinu tabi igberaga ni wọn kun fun. Ṣugbọn ni tirẹ, nkan ti o gbọdọ kun fun ni ọrọ Ọlọrun. Bi o ba si ṣe n kun ara rẹ pẹlu ọrọ rẹ, nṣe ni o ri wipe o n gbe igbe aye ti o buyi kun Ọlọrun ati eyi ti o n bukun fun ayika rẹ pẹlu irọrun.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



