Ìdí tí o ṣe yẹ kí o máa rìn nínú òdodo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 27
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọ yanturu lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu osu Belu, iyẹn oṣu kọkanla ọdun yi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun aye rẹ ninu oṣu naa pẹlu oniruuru ohun rere gbogbo ti yoo jẹ ki o gbagbe inira tabi adanu yowu ti o le ti ni iriri rẹ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu tuntun naa, mo fẹ gba ọ niyanju lati fi ara rẹ jin siwaju ati siwaju si lati maa ni rin ninu ododo. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe Ọlọrun ma n tẹ awọn ti o ba n rin ninu ododo lọrun pẹlu ohunkohun ti wọn ba nilo laye, bi o ti wu ki nkan le to nibi ti wọn wọn wa. Jesu sọ wipe, “Alabukun fun ni awọn ti ebi n pa, ti oungbẹ si n gbẹ fun ododo, nitoripe a o tẹ wọn lọrun.” O tun sọ wipe, “Ẹ kọkọ maa wa ijọba Ọlọrun naa, ati ododo rẹ; gbogbo awọn nnkan wọnyi ni a o si fi kun fun yin.” (Wo: Mátíù 5:6 & 6:33)
Nitorinaa, ti o ba fi ara rẹ jin fun ododo, Ọlọrun yoo ri daju pe o ko ṣe alaini ohunkohun ti o dara, bi o ti wu ki nkan buru to nibi ti o ba wa. Lotitọ, iwọ naa gbọdọ kọ bi a ti n tẹwọgba ipese Ọlọrun nipasẹ adura, ijẹwọ ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ-afọkanṣe. Amọ o le fọkanbalẹ lori pe Ọlọrun ko ni fi ohunkohun ti o nilo dun ọ, ti o ba fi ara rẹ jin lati ma rin ninu ododo.
Idi keji ti o ṣe yẹ ki o fi ara rẹ jin lati ma rin ninu ododo ni pe Ọlọrun yoo pa ọ mọ bi o ba ti n ṣe bẹ ẹ. Ọkan lara awọn idi ti awọn eniyan ko ki i fẹ fi ara wọn jin fun igbe aye ododo ni ibẹru inunibini. Bi a si ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ti o ba fẹ gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu yoo ba inunibini pade (2Tímótì 3:12). Amọ ṣa o, bibeli tun fi han wa pe aabo wa fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba fi ara wọn jin fun rinrin ninu ododo kuro lọwọ inunibini. Wọn kan nilo lati kan si Ọlọrun fun un ni.
Fun apẹrẹ, nitori ifarajin Daniẹli fun ododo ni mimojuto iṣẹ rẹ, iyẹn gẹgẹ bi adari ijọba, awọn akẹgbẹ rẹ, ọpọ awọn ẹni ti o jẹ oṣo, ṣe inunibini rẹ gidigan-an. Nigba ti wọn si ri wipe awọn ko le sasi tabi ri aleebu ninu itayọ iṣẹ-iriju rẹ, wọn dẹ pakute fun un. Nitorina, a sọ ọ ninu iho awọn kiniun. (Wo: Dáníẹ́lì 6:1-18)
Njẹ Ọlọrun wa pa a ti bi? Rara o! Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O ran angẹli kan lati pa awọn kiniun ti o wa pẹlu rẹ lẹnu mọ. Nitorina, wọn ko le e pa a lara. Nigbẹyingbẹyin, awọn ti o ditẹ mọ ọn, ati awọn aya ati awọn ọmọ wọn, ni o pada di jijẹ fun awọn kininu ti ebi n pa yi i. (Wo: Dáníẹ́lì 6:19-24)
Wayi o, eyi wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o sọ wipe:
“Nitori yoo fi aṣẹ fun awọn angẹli nipa tirẹ lati pa ọ mọ ni gbogbo ọna rẹ; Wọn yoo gbe ọ soke ni ọwọ wọn, nitori ki iwọ ma ba a fi ẹṣẹ rẹ gun okuta. Iwọ yoo rin lori kinniun ati paramọlẹ, iwọ yoo tẹ kinniun nla ati ejo ni iwọ yoo fi ẹsẹ tẹ mọlẹ. “Nitori ti ifẹ rẹ si mi, Emi yoo gba ọ, emi yoo pa ọ mọ, nitori iwọ jẹwọ orukọ mi.”” (Sáàmù 91:11-14)
Nitorina, ma lailai tun bẹru pe a o ṣe inunibini rẹ mọ nitoripe o n ṣe nkan ti o dara ati ti o tọ niwaju Ọlọrun. Idi si ni pe iwọ yoo ri aabo rẹ gba. Eyi yoo si yọri si igbega rẹ ati si idojuti fun awọn ọta rẹ, gẹgẹ bi o ti ri fun Daniẹli.
Ki o ni oṣu Belu 2024 alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)





