Ṣe ojuṣe adura gbigba rẹ fun orilẹ-ede wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 16, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 7

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2024. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi ojoojumọ gba okun lati mu ojuṣe rẹ ni gbigbadura fun orilẹ-ede wa ni ọkunkundun, ki asiko itura ba a le tọ gbogbo wa wa lalai si idaduro. Amin.

Bi a ti ṣe sọ fun wa ninu bibeli, gbogbo awa ti a mọ Ọlọrun ni O ti paṣẹ fun pe ki a ma gbadura fun ilẹ wa ati fun awọn adari wa, bi o ti wu ki nkan buru to. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe ki a ba le ni iriri alaafia ati ilọsiwaju ni ilẹ naa. Ekeji, idi ni pe inu Ọlọrun dun si irufẹ adura bi eyi, O si le lo o lati gba ọpọ la. (Wo: 1Tímótì 2:1-3)

Nitorina, ti o ko ba i ti mu ojuṣe rẹ lati ma gbadura fun orilẹ-ede wa ni ọkunkundun, o ni lati bẹrẹ si ni ṣe bẹ. Lotitọ, nkan ti a n fi ojoojumọ ri ati gbọ le ma fun wa ni iwuri ti o peye lati ma gbadura fun orilẹ-ede wa. Awọn nkan wọnyi tilẹ le jẹ ki a ro wipe ifakoko-ṣofo ni gbigbadura fun orilẹ-ede wa jẹ. Laipẹ yi ni mo gbọ ti arabinrin kan n sọ lori redio wipe iṣoro orilẹ-ede wa ti wa kọja eyi ti adura le yanju bayi. Sibẹsibẹ oun naa n sọ wipe oun gbagbọ ninu adura gbigba.

Njẹ otitọ wa ni wipe awọn iṣoro orilẹ-ede wa ti kọja eyi ti adura le yanju? Rara o, ko ki i ṣe otitọ rara. Lotitọ, awọn nkankan wa ti a tun nilo lati ma ṣe yatọ si adura gbigba lati gba orilẹ-ede wa la. Amọ, lalai ba jẹ wipe a n gbadura si Ọlọrun fun un, ko si irufẹ ọgbọn tabi agbara ti a gbe kalẹ ti yoo le gba a kuro lọwọ iṣakoso eṣu ti a n ba finra lọwọlọwọ yi.

Nitorina, ti o ba wa lara awọn ti o ro wipe ifakoko-sofo ni gbigbadura fun orilẹ-ede yi, o ti ṣina, o si tun ti n fihan wipe o ko gbagbọ mọ ninu agbara Ọlọrun lati gbala ati lati wosan. O si nilo lati ronupiwada. O nilo lati ronipiwada nitoripe Ọlọrun yoo ba ọ wi lọjọ kan fun kikuna rẹ lati ṣe ojuṣe rẹ ni gbigbadura fun irapada ati alaafia orilẹ-ede rẹ. Ki wa ni iwọ yoo sọ fun un ni ọja naa?

Iwọ naa wo ọrọ Iwe Mimọ yi ati nkan ti o sọ nipa ojuṣe wa ni gbigbadura fun orilẹ-ede wa:

“Emi ti fi oluṣọ ranṣẹ sori odi rẹ iwọ Jerusalẹmu; wọn ki yoo le dakẹ tọsan toru. Ẹyin ti n ke pe Oluwa, ẹ ma ṣe fun ara yin ni isinmi, ati ki ẹ ma ṣe fun oun pẹlu ni isinmi titi ti yoo fi fi idi Jerusalẹmu mulẹ ti yoo si fi oun ṣe iyin ori ilẹ aye.” (Àìsáyà 62:6-7)

Ṣe o ri bayẹn? Gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni Ọlọrun funrarẹ ti gbin gẹgẹ bi iluṣọ sinu orilẹ-ede yi. Ara iṣẹ wa si ni lati ma gbadura fun un laarọ ati ni alẹ. A ko gbọdọ panumọ lori eyi. A ko gbọdọ fun ara wa ni isinmi lori rẹ. A ko si gbọdọ fun Ọlọrun paapaa ni isinmi titi yoo fi gba orilẹ-ede wa la, ti yoo mu bọ wa sipo ti yoo fi ẹsẹ rẹ mulẹ ninu iṣoriire ati ti yoo si tun sọ ọ di iyin fun gbogbo aye.

Eyi wa jasi pe titi a o fi ri eso adura wa fun orilẹ-ede wa, a ko gbọdọ dẹkun lati ma a gbadura si Ọlọrun fun un. Rara o, a ko gbọdọ fi aye gba awọn iroyin buburu ati iroyin irẹwẹsi ti a n gbọ lojoojumọ (a si n gbọ ọpọlọpọ wọn) lati da wa lẹkun lati ma gbadura fun un. Idi si ni pe Ọlọrun n gbọ adura wa, bi o tilẹ jẹ wipe ohun ti O n ṣe lati gba ilẹ wa la le ma ti han si ẹnikẹni ninu wa. Ṣugbọn O ti n ṣiṣẹ fun rere wa, ni idahun si adura awọn ọmọ rẹ ti wọn n gbadura si lotitọ, lọsan ati loru. Si wa wo ohun ti O sọ wipe yoo ṣẹlẹ lẹyin igba ti a ba mu ojuṣe adura gbigba wa fun orilẹ-ede wa lọkunkundu:

“Oluwa ti bura pẹlu ọtun rẹ ati nipa agbara apa rẹ: “Emi ki yoo jẹ ki horo rẹ di ounjẹ fun ọta rẹ bẹẹ ni awọn ajeji ki yoo mu waini tuntun rẹ moọ eyi ti iwọ ti ṣe laalaa fun; ṣugbọn awọn ti o ba koore rẹ ni yoo jẹ ẹ ti wọn o si yin Oluwa, ati awọn ti wọn ba ko girepu jọ ni wọn o mu un ninu agbala ile mimọ mi.” (Àìsáyà 62:8-9)

Njẹ o ko fẹran awọn ọrọ wọnyi bi? Emi fẹran wọn. Mo si mọ wipe awọn ni yoo jẹ ẹri wa ni ibi gbogbo ni orilẹ-ede yi. Nitorina, ji lati inu oorun rẹ, ki o si bẹẹ si ni ṣe ojuṣe rẹ ni gbigba adura fun orilẹ-ede yi. Ẹri wa yoo si ga, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ṣe ojuṣe adura gbigba rẹ fun orilẹ-ede wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 16, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 7 Read More »

Ó le è fi ọ̀nà láti wò ó sàn hàn ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 09, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 6

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji oṣu yi, iyẹn oṣu Òkúdù 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun fi adun rẹ pada sinu ohunkohun ninu aye rẹ ti esu ti bajẹ pẹlu ikoro, ki ohun naa ba a le wulo fun igbadun rẹ ati fun ogo rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lẹyin igba ti awọn ọmọ Isiraẹli ti ri iparun awọn ogun Farao ninu Okun Pupa, wọn kọkọ ri irin-ajo laarin aṣalẹ fun odidi ọjọ mẹta lalai fi oju kan omi. Nigba ti wọn wa de ibikan ti a n pe ni Mara, ti wọn si fẹ bẹrẹ si ni yọ wipe omi wa nibẹ, nṣe ni a tun ke ayọ wọn kuru nitoripe omi ti wọn ri nibẹ korò, ko si ṣe e mu. (Wo: Ẹ́kísódù 15:22-23)

Njẹ ki lo wa fa ti omi Mara fi koro? A ko sọ fun wa. Ṣugbọn daju-ṣaka ni pe Ọlọrun ko ni O sọ di kikoro, nitoripe daradara ni ohun gbogbo ti Ọlọrun da ni atetekọṣe (1Tímótì 4:4). Nitorina, nkankan gbọdọ ti ṣẹlẹ si omi yi ni asiko kan ti o fi ikoro sinu rẹ. Eyi si n fi han wa wipe pe Ọlọrun pese nkan ti o dara fun wa ko tunmọ si pe ikoro ko le wọ inu rẹ. Ikoro le wọ inu rẹ lati ipasẹ iṣẹ ọwọ Satani tabi iṣẹ ọwọ awọn eniyan. Idi si ni yi ti a fi gbọdọ ma fi gbogbo igba gbadura, ki a si tun ma ṣọra, ki a ma ba fi aye gba ikoro lati ba ohun rere yowu ti Ọlọrun ti fi fun wa jẹ.

Ki a ma fọ̀rọ̀gùn, nitori pe omi ti awọn ọmọ Isiraẹli ri ni Mara koro, ara wọn ko balẹ mọ, wọn si bẹrẹ si ni sọrọ si Mose fun bi o ti ṣe mu wọn jade lati Ijibiti lati parun saarin aṣalẹ. Ṣugbọn ni ọjọ mẹta saaju asiko yi, awọn eniyan kan naa yi ni o ri ọwọ agbara Ọlọrun fun itusilẹ wọn kuro ninu oko ẹru ọpọlọpọ ọdun ni Ijibiti. Wọn ri bi O ti ṣe la ọna fun wọn laari Okun Pupa, ti O si tun pa awọn ọta wọn ti o n lepa ẹmi wọn run sinu awọn omi okun yi. Ki wa lo de ti wọn ko ro wipe imojuto ikoro omi Mara ko le jẹ iṣoro fun un? Wọn ko ro eyi nitoripe itura wọn nikan ni o wa ni ọkan wọn; ọkan wọn ko si lori bi wọn ti ṣe le ṣiṣẹ lori ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. (Wo: Ẹ́kísódù 15:23)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ti o jẹ ọmọ Ọlọrun ninu aye loni ni o dabi awọn ọmọ Isiraẹli yi. Nkan ti awọn naa n mojuto ko kọja nkan ti Ọlọrun le ṣe lati tu wọn lara ati lati gbe wọn soke laye. Wọn ko kọbiara si bi wọn ti ṣe le ni ibaṣepọ ti o nitunmọ pẹlu rẹ. Nitorina, igbakigba ti wọn ba dojukọ iṣoro tuntun, wọn yoo gbagbe gbogbo awọn nkan rere ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn ṣẹyin patapata, wọn yoo si wa ma ṣaroye pe ko raye ti wọn rara tabi pe ipa ti awọn kan ninu aye wọn n ko ko to.

Ki lo wa fa ti awọn eniyan ṣe ma n ṣe bayi? Idi naa ni pe wọn ro wipe ti Ọlọrun ba wa pẹlu eniyan, ti O si n ṣetọju ẹni naa, ko yẹ ki O fi aye gba eṣinṣin kankan lati fi ọwọ kan iru ẹni bẹẹ. Ṣugbọn ko si ibi ti a kọ si ninu ọrọ Ọlọrun pe a ko ni ba idojukọ pade laye nitoripe Ọlọrun wa pẹlu wa tabi nitoripe O fẹran wa. Ọlọrun nifẹ Jesu gidigidi nigba ti O wa ninu aye yi, O si tun n fi gbogbo igba wa pẹlu rẹ. Ṣibẹsibẹ, iyẹn ko ni ki O ma dojukọ oniruuru idojukọ, pẹlupẹlu iku. Ṣe o wa ṣaroye nitori eyi? Rara o! Ki ni idi ti ko fi ṣaroye? Ko ṣaroye nitoripe O mọ wipe Ọlọrun, ti O fẹran rẹ, ti O si n fi igba gbogbo wa pẹlu rẹ, yoo fun ni iṣẹgun lori gbogbo awọn idojuko yi. Ṣe O si wa fun ni iṣẹgun lori wọn tabi ko fun un? O fun un.

Nibakan naa, bi O ti wu ki awọn idojukọ ti a n ko ni aye tile to, a ko gbọdọ fi igba kankan gbagbe pe Ọlọrun wa pẹlu wa ati wipe yoo fun wa ni iṣẹgun lori gbogbo wọn nitori pe O nifẹ wa. Nitorina, dipo ti a o fi ma kun si i tabi ti a o ma fi ẹ̀sùn kan awọn adari wa ninu ẹmi pe wọn ko gbadura to fun wa, nṣe ni ki a kọju si Ọlọrun ninu adura fun ọna iṣẹgun. Yoo si da wa lohun.

Bi a ti ṣe ri ni ti ọrọ awọn ọmọ Isiraẹli yẹn, nigba ti wọn bẹrẹ si ni kun si Mose ati si Ọlọrun, Mose ko ma darapọ mọ wọn lati kun. Dipo eyi, nṣe ni O siju pada si Ọlọrun fun ọna abayọ si iṣoro ti o wa nilẹ. Wo bi bibeli ti ṣe gbe ọrọ naa kalẹ: “Mose si ke pe Oluwa, Oluwa si fi igi kan han an, o si sọ igi naa sinu omi, omi naa si dun. Nibẹ ni Oluwa ti gbe ilana at ofin kalẹ fun wọn, nibẹ ni o si ti dan wọn wo…” (Ẹ́kísódù 15:25) Ṣe o ri bayẹn? Ẹni ti o kepe Ọlọrun ni O fi aṣiri ọna abayọ han. O fi ohun ti yoo ṣe lati wo omi Mara san kuro ninu okoro rẹ han. Nigba ti o si ṣe ohun ti Ọlọrun ni ki o ṣe, omi naa gba iwosan, o si di eyi ti awọn eniyan le mu.

Nitorina, Ọlọrun le fi ọna lati wo ohunkohun ti a ba ni, ti idibajẹ si ti de ba nipasẹ ikoro ti o wa ninu rẹ, san han wa. Ohun ti a nilo ko ju ki a kan kepe fun ifihan lori ohun ti a nilo lati ṣe lọ. Yoo si da wa lohun. Nigba naa ni a o rọpo ikoro ti a n ni iriri rẹ nipa lilo awọn ipese rẹ fun wa pẹlu adun. Ṣe iwọ yoo wa bẹrẹ si ni ba a sọrọ lori awọn nkan naa ninu aye rẹ ti ikoro ti bajẹ bi?

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ó le è fi ọ̀nà láti wò ó sàn hàn ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 09, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 6 Read More »

Yí Ó fi ààyè gbà ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 02, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 5

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Okúdù 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fi ààyè gba ọ lati gberu nibikibi ti o ba lọ tabi ti o ba ti ba ara rẹ ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun le fi aaye gba wa lati ṣe rere nibikibi, ko tunmọ si pe a ko ni ba idojukọ kankan pade. A ko le sa lọ fun idojukọ laye yi. Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe ninu aye yi a o ri ipọnju. Amọ ṣa o, o tun wa sọ fun wa pe ki a tujuka. Ki ni idi? Idi ni pe Jesu Kirisiti ti ṣẹgun aye fun wa. Niwọn igba ti O si ti ṣẹgun aye fun wa, O le dari wa lati iṣẹgun de iṣẹgun laye. (Wo: Jòhánù 16:33)

Siwaju si, ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe Ọlọrun ko ni lailai jẹ ki a koju awọn idojukọ ti o ga ju nkan ti a le mojuto lọ. Dipo eyi, asiko yowu ti a ba koju idojukọ, yoo ṣeto ọna iṣẹgun lori rẹ fun wa. Nitorina, igba yowu ti a ba koju idojukọ, a ko nilo lati ba ọkan jẹ tabi sọ ireti nu lori aye wa. Dipo eyi, a kan nilo lati gbadura si i ni pe ki O ṣi oju wa lati ri ọna iṣẹgun ti O ti pese fun wa, ki O si tun fun wa ni okun lati tọ ọ. (Wo: 1Kọ́ríntì 10:13)

Amọ ṣa o, kiki igba ti a ba n rin ninu ifẹ Ọlọrun nikan ni ofin yi le ṣiṣẹ fun wa. Nkan ti mo n sọ ni pe kiki igba ti a ba n rin ninu ifẹ Ọlọrun nikan ni a ko ni koju idojukọ ti o ga ju wa lọ. Ti a ko ba rin ninu ifẹ rẹ, o di dandan ki a koju idojukọ ti ko yẹ ki a koju rara laye. Ranti Lọti. Ranti pe aye ati igbagbọ oun ati ẹbi rẹ ko ba di piparun ni Sodomu, ti ko ba ṣe wipe Ọlọrun ṣaanu fun wọn. Ṣugbọn ṣe o yẹ ki wọn koju awọn idojukọ buruku ti wọn koju nigba ti wọn wa ni Sodomu bi? Rara! Ki lo wa fa a ti wọn fi koju wọn? Wọn koju wọn nitoripe irin wọn ko ṣe deede pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wọn. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 13&19)

Nitorina, ti o ko ba fẹ koju awọn idojukọ ti Ọlọrun ko ṣe ọ yẹ lati mojuto laye, duro ninu ifẹ rẹ. Lotitọ, Ọlọrun le e ṣaanu fun wa, ki O si daabo bo wa, bi a tilẹ yẹṣẹ kuro ninu ifẹ rẹ fun aye wa. Ṣugbọn awọn irora kan wa ti aanu Ọlọrun ko le pa wa mọ pe ki a ma ni wọn, niwọn igba ti a ko ba ti duro sinu ifẹ rẹ fun wa.

Ni kukuru, koko nkan ti mo n sọ ni pe Ọlọrun le e fi aye gba wa lati gberu nibikibi ti a ba wa, niwọn igba ti a ba ti wa ninu ifẹ rẹ. Nitorina, bi a tilẹ n koju awọn idojukọ ti o fẹ fa wa sẹyin tabi ti ko fẹ ka ni ilọsiwaju, a ko gbọdọ rẹwẹsi. Dipo eyi, nṣe ni a ki tẹsiwaju lati ma gbe ọkan le Ọlọrun fun iṣẹgun, ki a si tun ma lakaka lati tẹsiwaju ni oju ọna ilọsiwaju. Bopẹ-boya, a o ri pe gbogbo idena ni a ti fọ tuutu ni abẹ ẹsẹ wa.

Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ni O sọ fun Isaki lati duro si Gẹra, awọn eniyan ibẹ buru si, wọn si tun ṣe ohun gbogbo ti wọn le ṣe lati di iṣerere rẹ lọwọ. Ṣugbọn ko sọ ireti nu tabi ki o dawọ iṣẹ duro lati ṣoriire. Ki ni idi? Idi ni pe o mọ wipe inu ifẹ Ọlọrun ni o n wa ati wipe Ọlọrun wa pẹlu oun. Nitorina, Ọlọrun fi aaye gba lati gberu laarin awọn ọta rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 26)

Nibakan naa, Ọlọrun le fi aaye gba ọ lati gberu laarin wọn ọta rẹ. Nitorina, ma ṣe sọ ireti nu nitori awọn idojukọ ti o n ba pade. Ma ṣe rẹwẹsi nitori pe ọpọ eniyan n gbogun ti ọ. Dipo bẹẹ, nṣe ni ki o ma la kaka lati tẹsiwaju lati ṣe amulo gbogbo anfani ti Ọlọrun ba mu wa si oju ọna rẹ lati pọ si ni iwulo ati isesorere. Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, iwọ funrarẹ yoo ri pe ko si ohun ti o le da ọ duro nitoripe Ọlọrun wa pẹlu rẹ.

Ki o ni oṣu Okudu 2024 alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Yí Ó fi ààyè gbà ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 02, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 5 Read More »

Kò lọ pẹ̀lú ọwọ́-òfo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 26, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 4

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọkan rẹ ni okun lati ni itara ti o to lati ri awọn ipese rẹ fun ọ lati tayọ ati lati gbe igbe ninu isinmi ni gbogbo eyi ti o ku ni ọjọ aye rẹ gba ati lati jẹgbadun awọn ipese naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, ẹnikẹni ti yoo ba ri ohunkohun gba lọwọ Ọlọrun gbọdọ mura, ki o si tun ni itara lati ri gba. Eyi jasi pe, ko to fun wa lati sọ wipe a ni igbagbọ lati rigba lọwọ Ọlọrun; a tun gbọdọ fi imura ati itara kun igbagbọ wa ninu rẹ. Aijẹbẹ, a le ma ri nkan ti ọkan wa fẹ gba lọwọ rẹ.

Otitọ ni pe Ọlọrun ma n ṣe ọpọlọpọ nkan fun wa lalai duro de imura tabi itara wa lati rigba lọwọ rẹ. Ṣugbọn awọn nkankan wa ti a ko le rigba lọwọ rẹ, ti ọkan wa ko ba mura, ki o si tara lati ri wọn gba. Ki wa ni awọn nkan naa? Emi ko le sọ ni pato nkan ti wọn jẹ. Idi si ni pe, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ọpọ ni o n fi ojoojumọ gba oniruuru nkan daradara lati ọwọ Ọlọrun ti wọn ko si mu un ni pataki. Amọ ṣa o, irufẹ awọn wọnyi naa yoo si tun pada ri wipe awọn nkankan wa ti wọn ko le rigba lọwọ Ọlọrun lalai ba jẹ wipe wọn mura, ti wọn si tun tara lati ri wọn gba lọwọ rẹ.

Ni kukuru, niwọn igba ti a ko le sọ ni pato awọn nkan ti Ọlọrun yoo ṣe fun wa lọfẹ, lalai reti imura tabi itara lati ọdọ wa, yoo jẹ nkan ti o mọgbọn wa fun wa lati mura ati lati ni itara nigbakigba ti a ba nilo ohunkohun lati ọwọ rẹ. Bi bibeli si ṣe wa sọ, awọn ti o ba fi imura ati itara ṣafẹri rẹ ko ni lọ kuro lọdọ rẹ pẹlu ọwọ́-òfo. (Wo: Hébérù 11:6)

Fun apẹrẹ, a sọ fun wa ninu bibeli bi arabinrin Kenani kan ṣe gba itusilẹ ọmọdebinrin rẹ lọwọ Oluwa nipa igbagbọ, imura ati itara rẹ. Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, nigba ti obinrin yi gbọ pe Jesu wa ni agbegbe rẹ, o kọkọ lọ ṣe iwadi ibi ti O wa. O si wa ibi ti O wa kan, bi o tilẹ jẹ wipe ko fẹ ki ẹnikẹni mọ wipe O n wa nibẹ. A wa ni lati jẹ wipe itara ati imura arabinrin yi ga gan niyẹn. (Wo: Máàkù 7:24-26)

Siwaju si, lẹyin gba ti o ti wa ibi ti Jesu wa kan, arabinrin yi tọ ọ wa, o si bẹrẹ si ni bẹ ẹ lati wo ọmọdebinrin rẹ ti ẹmi aimọ n gbe inu rẹ san. Ṣugbọn Jesu ko gbọ tirẹ tabi da a lohun. O kan ṣe bi igba ti ko gbọ nkan ti o n sọ ni. Ki ni idi? Idi ni pe iṣẹ iranṣẹ rẹ laye ni asiko yii ko kọja ki O pe awọn iru ọmọ Aburahamu pada si ọdọ Ọlọrun, ko si ni i ṣe pẹlu ki O kan si awọn keferi. Awọn keferi ni a o pada pe lẹyin iku, isinku, ajinde ati igbasoke rẹ. (Wo: Mátíù 15:24)

Bi nkan tilẹ wa ri bayi, arabinrin yi ko ma sọ ireti nu. Ko pòṣé, ki o yi pada, ki o si ma fi oju agberaga ọkunrin wo Jesu. Dipo eyi, nṣe ni o tẹsiwaju lati ma a tẹle ati lati ma a bẹ ẹ pe ki O wo ọdọmọdebinrin oun san. Nigba ti Jesu si wa pada fun ni aye lati sọrọ, awọn ọrọ wọnyi ni O sọ fun un: “Ko tọ ki a gbe ounjẹ awọn ọmọ fun awọn aja.” (Mátíù 15:26) Njẹ o ri bayẹn? Oluwa pe arabinrin yi ati ọmọ rẹ ni aja, aja awọn ọmọ Isiraẹli. O tun sọ siwaju pe wọn ko yẹ lati jẹ igbadun ohun ti Ọlọrun n fun ọrilẹ-ede Isiraẹli.

Sibẹsibẹ, obinrin yi ko ma binu. Dipo ti yoo fi binu, nṣe ni o da Oluwa wa lohun wipe, “Bẹẹ ni, sibẹsibẹ awọn aja a maa jẹ eerun ti o ti ori tabili olowo wọn bọ silẹ.” (Mátíù 15:27) Eyi jasi pe, bi o tilẹ jẹ wipe aja wọn ọmọ Isiraẹli ni wọn jẹ, wọn si le kopa ninu awọn nkan ti awọn ọmọ Isiraẹli n jẹgbadun, pẹlupẹlu iwosan. Nitoripe o si sọrọ bi eyi, Oluwa da a lohun, O si sọ ọrọ naa ti o tu ọmọ rẹ silẹ. (Wo: Mátíù 15:28)

Njẹ ki wa ni idi ti arabinrin yi fi rigba lọwọ Oluwa, pẹlupẹlu awọn iyọnu ati èébú ti o gba? Idi ni pe o mura, o si tun tara nipa itusilẹ ọdọmọdebinrin rẹ. Ti o ba si wa jẹ wipe ki o farada awọn eebu diẹ ni yoo jẹ ki eyi waye, o ṣetan lati farada wọn. Nitorina, ko kuro pẹlu ọwọ́-òfo.

Nibakan naa, ti awa naa ba mura, ti a si tun tara lati ri ohun yowu ti a ba fẹ gba lọwọ Ọlọrun gba, a ko ni kọbiara si idenakidena loju ọna wa; a ko ni kọbiara si eebu tabi ọrọ odi awọn eniyan. Lafikun, a ko ni wo iye asiko tabi ọjọ ti a o lo lati gbadura si Ọlọrun lati ri nkan ti a fẹ gba lọwọ rẹ gba. Dipo eyi, nṣe ni a o tẹ oju wa mọ, ti a ko si ni gbe e kuro titi a o fi ri ohun ti a fẹ gba lọwọ rẹ gba. Amọ ṣe a wa ṣetan lati ṣe eyi? Ṣe a ṣetan lati mura ati lati tara nigbakigba ti a ba fẹ gba nkan lọwọ Ọlọrun? Mo wa gbadura pe a o ṣe ọkan wa yẹ lati ṣe eyi, ki ayọ wa ba a le kun ni gbogbo abala aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kò lọ pẹ̀lú ọwọ́-òfo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 26, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 4 Read More »

Àkórí: Ǹjẹ́ o ti ń rànmù kiri bí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 19, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 3

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia di ilọ̀po, ilọpo fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ṣe ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ebibi 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun, ti O ti gba wa kuro lọwọ ijọba okunkun, ti O si mu wa wa sinu ijọ ọmọ rẹ, fi opin si ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iriri ìraǹmù ninu aye rẹ, ki o ba le farabalẹ jẹgbadun aye rẹ bi O ti fẹ ki o jẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gbadura yẹn fun ọ nitoripe ko ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ranmu laye. Idi si ni pe igbe aye iranmu ko ki i ṣe igbe aye isimi otitọ. Ko ki i ṣe igbe aye igbadun otitọ. Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ fun Kaini, lẹyin igba ti o pa arakunrin rẹ, pe isansa ati alarinkiri ni yoo jẹ. Ki ni eyi tunmọ si? Ki a ma fọrọgun, o tunmọ si pe bi o ti wu ki ibi yowu ti o ba ara rẹ ti dara to, ko ni ni itẹlọrun tabi idunnu nibẹ. Ki ni idi? O le jẹ wipe iṣẹ ọwọ rẹ ko ni lọ deede nibẹ. Tabi ki o jẹ wipe awọn eniyan ti o wa nibẹ yoo korira rẹ. Nkankan yoo ṣaa wa nibikibi ti o ba wa ti yoo ja a lole itẹlọrun. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 4)

Nitorina, Kaini yoo nilo lati ma parọ ibi ti yoo ma gbe lore-koore. Niwọn igba ti o ba si ni parọ ilegbe rẹ lati igba-de-igba, ko ni i le fi ara lelẹ jẹgbadun awọn eso laala rẹ. Yatọ si iyẹn, ti awọn iyawo ati ọmọ rẹ ko ba ṣetan lati ma ba a ranmu kaakiri, ko tun ni le jẹ igbadun ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn naa. O yẹ ki o wa ri bayẹn pe igbe aye iranmu kiri ko ki i ṣe eyi ti o dara rara. Ọpọ igba ni o si ma n jẹ igbe aye adanikanṣe.

O wa ṣeni laanu pe igbe aye iranmu yi gan an ni ọpọ n gbe. Fun ọpọ ọdun, nṣe ni wọn n ranmu lati ibikan de ibikan, lati ibi iṣẹ de ibi iṣẹ, lati inu ijọ de inu ijọ ati pẹlupẹlu lati inu igbeyawo de inu igbeyawo. Sibẹsibẹ, wọn ko i ti ri itẹlọrun, alaafia ati isinmi ti wọn n wa laye. Ki ni idi? O ma a fẹrẹ ni lati jẹ wipe wọn ko mu Ọlọrun ni pataki ni tabi pe wọn ko kọbiara si ohun ti O n sọ fun wọn.

Ranti wipe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ni O mu awọn ọmọ Isiraẹli jade kuro ninu Ijibiti, ki O ba a le mu wọn wọ ilẹ isinmi ti O ti pese silẹ fun wọn, ọpọ ninu wọn ni o jẹ wipe nṣe ni wọn ranmu titi ninu aginju fun ogoji ọdun. Ṣibẹsibẹ wọn ko si tun papa de ibi isinmi ti a ti pese silẹ fun wọn. Ki ni idi? Idi ni wipe wọn ko mu Ọlọrun ni ọkunkundun. Wọn ko gbagbọ pe O le dari awọn sinu ibi isinmi ti O ti pese silẹ fun wọn. Nitorina, wọn fi ogoji ọdun aye wọn ṣofo lori riranmu kiri ninu aginju, ti wọn ko si le jẹgbadun aye bi wọn ko ba ti jẹgbadun rẹ. (Wo: Númérì 13&14; Hébérù 3:15-19)

Wayi o, o wa ṣeeṣe ki o jẹ wipe iwọ naa ti n ranmu kiri laye yi, ti o ko si le sọ wipe o ti figbakanri ni iriri isinmi ati itẹlọrun ni awọn ibi ti o ti gbe tabi lori awọn iṣẹ tabi okowo ti o ti ṣe. O nilo lati kọkọ gba wipe o ti n ranmu laye ati wipe opin gbọdọ de ba iranmu rẹ. Ekeji, o nilo lati gbadura si Ọlọrun pe ki O ṣaanu fun ọ, ki O si fi opin si ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iriri iranmu ninu aye rẹ, nkan yowu ti o le fa a wa sori aye rẹ. Yoo si da ọ lohun, yoo dari rẹ si ibi isinmi, yoo si tun fi ẹṣẹ rẹ mulẹ nibẹ.

Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu bibeli nipa ohun ti Ọlọrun ṣe fun awọn kan ti awọn naa ti fi igbakanri n ranmu kiri laye ri:

“Wọn n rin kaakiri ni aṣalẹ nibi ti ọna ko si: wọn ko ri ilu lati maa gbe. Ebi pa wọn, oungbẹ si gbẹ wọn, o rẹ ọkan wọn ninu wọn. Nigba naa, ni wọn kigbe pe Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ wọn. O si mu wọn jade nipa ọna titọ, ki wọn ki o le lọ si ilu ti wọn o maa gbe.” (Sáàmù 107:4-7)

Njẹ o ri bayẹn? Nigba ti awọn eniyan wọnyi ke pe Oluwa ninu iṣoro wọn, O da wọn lohun, O si tun tu wọn silẹ. Lọna wo? Nipa didari wọn si ibi isinmi ni. Yoo si ṣe ohun kanna fun ọ tabi fun ẹni naa ti o sunmọ ọ ti si n gbe igbe aye iranmu kiri, ti iwọ naa yoo ba kigbe si fun iranlọwọ. Ki wa ni o n duro de? Kigbe si fun iranlọwọ nibayi-bayi, o si dandan ki o ni ẹri ti o ga lati jẹ, lati ọsẹ yi lọ.

Ki ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Ǹjẹ́ o ti ń rànmù kiri bí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 19, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 3 Read More »

Àkórí: Ọ̀nà wo ni ó gba yí ọ padà? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 12, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 2

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di ilọpo-ilọpo si fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu gidigidi lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, oṣu Ebibi 2024, ati lati ki ọ kaabọ sinu ọdun ibabapọ ati iṣẹ-iranṣẹ miran gẹgẹ bi ijọ. Adura si ni pe Ọlọrun yoo ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ijọ wa laṣepe, yoo si tun mu ohun gbogbo ti o dun mọ ọn ninu wa si imuṣẹ ninu aye gbogbo wa, ki a ba le jẹ awokọse ninu ohun rere gbogbo fun gbogbo awọn eniyan rẹ kaakiri agbaye. Amin.

Bi gbogbo wa ti ṣe mọ, o pe ọdun mejila bayi ti a ti n pade gẹgẹ bi ijọ ninu ilu yi, Ẹdẹ. Nṣe si ni Ọlọrun wa fi gbogbo ọdun mejejila yi dara si wa. O n tọju wa ni gbogbo ọna. O si tun n jẹ ki a pọ si ninu ohun rere gbogbo ni ilọpo-ilọpo, laisi fi aye gba Satani lati ba ẹri wa jẹ gẹgẹ bi eniyan mimọ rẹ. Nitorina, o yẹ ki a fi imoore wa han si fun ohun gbogbo ti a ti jẹgbadun lati ọwọ rẹ ati fun ohun gbogbo ti yoo si tun ṣe fun wa, ninu wa ati nipasẹ wa ni awọn ọdun ti o n bọ niwaju.

Amọ ṣa o, bi a ti wa n yọ mọ Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti ṣe fun wa, ninu wa ati nipasẹ wa ni awọn ọdun mejila yi, o yẹ ki a tun bere lọwọ ara wa pe, “Ọna wo ni gbogbo awọn nkan ti O ti ṣe fun wa gba yi wa pada?” Bẹẹni, ni olorijori ati lapapọ, o yẹ ki a bere lọwọ ara wa pe, “Ọna wo ni ọrọ rẹ ti a ti n gbọ lati igba ti a ti darapọ mọ ijọ yi gba yi aye wa pada? Bawo ni iṣẹ Ẹmi rẹ ninu ijọ yi ti ṣe yi wa pada si? Ṣe o tilẹ farahan si wa ati si awọn miran ni ayika wa pe aye wa n gba iyipada kankan nipa jijẹ ọmọ ijọ yi?”

Woo, nkan ti o ṣe koko si Ọlọrun kọ ni iye ọdun ti a ti fi gbe ile aye gẹgẹ bi Kirisitiẹni aláfẹnujẹ́ tabi ti a ti lo ninu ijọ wa tabi ti a ti fi gbọ ọrọ rẹ tabi ti a ti fi ni iriri iṣẹ Ẹmi rẹ. Ohun ti O ṣe koko si i ni ipa ti awọn nkan wọnyi n ri ko lori aye wa. Fun apẹẹrẹ, wo nkan ti Jeremaya sọ fun awọn ara Juda lori iṣẹ-iranṣẹ ti Ọlọrun fun un laarin wọn:

“Fun odidi ọdun mẹtalelogun, bẹrẹ lati ọdun kẹtala Josaya, ọmọ Amoni Ọba Juda, titi di ọjọ yii, ọrọ Oluwa si tọ mi wa, mo si ti sọ ọ fun un yin lati igba de igba, amọ ẹyin ko feti silẹ.” (Jeremáyà 25:3)

Njẹ o ri bayẹn? Jeremaya n mu ọrọ Ọlọrun tọ awọn eniyan wọnyi wa lera-lera fun ọdun mẹta-le-logun. Njẹ wọn wa tẹti silẹ si i? Rara o! Ṣe ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wọn wa fun gbogbo awọn ọdun mẹta-le-logun wọnyi yi aye wọn pada? Irọ o! Ṣe ọrọ rẹ ti wọn gbọ le di wọn lọwọ lati ma papa lọ si oko ẹru? Irọ o! Ki ni idi? Idi ni pe wọn ko mu ọrọ rẹ ti o tọ wọn wa ni ọkunkundun.

Lafikun, wo awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose mu jade lati Ijibiti wa. Njẹ ọrọ Ọlọrun ti wọn gbọ lera-lera lati ẹnu Mose ṣe gbogbo wọn ni anfaani bi? Rara o! Ṣe gbogbo awọn iṣẹ iyanu ti wọn n ri ati ti wọn n jegbadun rẹ lojoojumọ ran wọn lọwọ bi lati tete gba ilẹ ti Ọlọrun ti ṣeleri lati fun wọn? Irọ o! Ki ni idi ti awọn nkan wọnyi ko ṣe ran wọn lọwọ tabi ṣe wọn ni anfaani? Idi ni pe wọn ko mu wọn ni ọkunkundun.

Ti o ba jẹ wipe wọn lọ mu ọrọ Ọlọrun ti a n fi ojoojumọ mu tọ wọn wa ati awọn iṣẹ iyanu ti Ọlọrun n fi ojoojumọ ṣe fun wọn ni ọkunkundun ni, nṣe ni igbagbọ wọn ko ba ma fi ojoojumọ pọ si. Iba si ma wa pẹ rara ti wọn yoo fi wọ ilẹ-ileri naa, ti wọn yoo si gba a. Ṣugbọn nitoripe wọ ko mu nkan ti Ọlọrun n sọ fun wọn ati ṣe fun wọn ni ọkunkundun, nṣe ni wọn pada rànmú fun ogoji ọdun lori aṣalẹ ilẹ. Ṣibẹsibẹ ọpọ ninu wọn ni ko si tun papa wọ ilẹ ileri naa.

Nitorina, wipe a ni anfaani lati ri ọrọ Ọlọrun ati oore-ọfẹ ati agbara rẹ gba fun ọdun mejila ninu ijọ yi kọ ni o ṣe pataki. Nkan ti o ṣe pataki gan ni bi anfaani ti a ni yi ṣe yọri si iyipada aye wa. Eyi si ni mo fẹ ki o ma ṣe aṣaro lori rẹ, bi a ti ṣe darapọ ni ọjọ isinmi oni yi fun ajọdun ọdun kejila ijọ wa. Mo si gbadura pe, bi o ti ṣe n ṣe bẹẹ, ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri awọn ibi ti itara rẹ ti ku diẹ-kaato ninu ibaṣepọ rẹ pẹlu rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

A ku ajọdun o!

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Ọ̀nà wo ni ó gba yí ọ padà? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 12, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 2 Read More »

Farabalẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 05, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 1

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2024. Adura mi si ni pe ki ọrọ Ọlọrun ti o n tọ ọ wa lọsọọsẹ ninu ijọ yi ma ṣe ja si asan ṣugbọn ki o fi gbongbo mulẹ ninu ọkan rẹ, ki o si ma fi ojoojumọ so eso awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ri ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kini idi ti ọrọ Ọlọrun ṣe nilo lati fi gbongbo mulẹ ninu ọkan wa? Idi naa ni ki o ba le dagbasoke, ki o si tun se eso ti Ọlọrun fẹ ri ninu aye wa. Ṣugbọn ki ni yoo jẹ ki ọrọ rẹ fi gbongbo mulẹ ninu ọkan wa? Irufẹ akiyesi ti a ba fun un ni.

Ti a ba farabalẹ nigba ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ wa wa, ti ọkan wa si ṣetan lati ṣe amulo rẹ, Ọlọrun funrarẹ yoo jẹ ki ọrọ naa ki o fi gbongbo mulẹ ninu ọkan wa, ki o si tun so irufẹ eso ti O fẹ ri. Ṣugbọn bi ara wa ko ba balẹ nigba ti ọrọ rẹ ba n tọ wa wa, ki ọkan wa si ṣetan lati ni oye nkan ti O n ba wa sọ ati lati ṣe amulo rẹ, ko si bi ọrọ rẹ ṣe fẹ fidimulẹ ninu ọkan wa tabi so eso ninu aye wa. Eyi si ni alaye fun bi a ti ṣe ri ọpọ kaakiri agbaye ti o n lọ si ipade ijọ wọn lọsọọsẹ ṣugbọn ti aye wọn ko fi taratara so esọ Ẹmi.

O wa jẹ nkan ibanujẹ pe ọpọ irufẹ awọn eniyan wọnyi ni ara ko tilẹ ki i ta pe aye awọn ko mu eso Ẹmi Ọlọrun jade bi o ti ṣe tọ. Nitorina, wọn ko ki i gbe igbesẹ kankan lati yi iha ti wọn n kọ si ọrọ Ọlọrun pada. Bawo wa ni eniyan yoo ṣe pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun, ti ko si ni bikita rara lori irufẹ eso ti aye rẹ n so? Eyi n fi han pe ẹni bẹ ni iṣoro lori oye ẹni ti o jẹ. Eyi tunmọ si pe ẹni naa ko i ti mọ nkan ti o tunmọ si lati jẹ ọmọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, iba ti mọ pe o yẹ ki oun fun ọrọ Ọlọrun ni akiyesi ti o peye, ki aye rẹ ba le mu eso jade ni ibamu pẹlu ọrọ naa.

Ni kukuru, koko ọrọ mi ni pe ti ọrọ Ọlọrun yoo ba fi gbongbo mulẹ ninu ọkan wa, ti yoo si ma so irufẹ eso ti Ọlọrun fẹ ri, a gbọdọ farabalẹ lati gbọ ọrọ yi ati lati ṣe amulo rẹ. A si nilo lati mọ pe Ọlọrun n wo ẹnikọọkan wa. Bẹẹni, O n wo irufẹ akiyesi ti a n fun ọrọ rẹ. Eyi si ni yoo so boya yoo busi nkan ti a n gbọ tabi ko ni busi.

Fun apẹrẹ, O fi igbakanri sọ eyi fun Isikiẹli nipa awọn iran kan ti O fẹ fi han: “Ọmọ eniyan, wo pẹlu oju rẹ ki o si gbọ pẹlu eti rẹ, ki o si farabalẹ si gbogbo ohun ti mo maa fi han ọ, nitori idi niyi ti a fi mu ọ wa sihin-in. Sọ gbogbo ohun ti o ba ri fun ile Isirẹli.” (Ìsíkẹ́lì 40:4) Ṣe o ri bayẹn? Ọlọrun ni lati sọ fun ọkunrin yi irufẹ akiyesi ti o nilo lati fun awọn nkan ti O fẹ fi han. Aijẹbẹ, idi ti O ṣe fẹ fi awọn nkan wọnyi han an yoo kan ja si pabo lasan ni.

Nibakanna, Ọlọrun fẹ ki awa naa fi ara balẹ gbọ ohunkohun ti O ba n mu tọ wa wa ninu ọrọ rẹ. Aijẹbẹ, ete ti O fẹ muṣẹ ninu aye wa nipasẹ ọrọ naa yoo kan ja si pabo ni. Boya eyi si ti n ṣẹlẹ si ọ lọwọlọwọ yi. Boya awọn nkan ti Ọlọrun fẹ tipasẹ ọrọ rẹ ṣe ninu aye rẹ ko i ti ma ṣẹlẹ nitoripe o ko farabalẹ lati ma gbọ nkan ti O n sọ fun ọ. A wa jẹ wipe iwọ gan ni ọta ara rẹ niyẹn. O si nilo lati yi iwa rẹ pada, ki o si ba ara rẹ wi lati bẹrẹ si ni fi ara balẹ gbọ nkan ti Ọlọrun n sọ. Aijẹbẹ, ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ le ma bu si aye rẹ lọna ti o peye titi Jesu yoo fi de.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Farabalẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 05, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 1 Read More »

Má ṣe paámọ́ fún wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Èbìbí 2024 pọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ naa, ki Ọlọrun ya ọ ya ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu anikanjọpọn ti ko jẹ ki O ri ọ lo lati fi didara rẹ han awọn ti o wa ni ayika rẹ. Amin.

Mo gba adura yi fun ọ nitoripe ọkan lara awọn idi ti Ọlọrun ko ṣe le lo ọpọ awọn eniyan rẹ, ti o n fi ojoojumọ jẹgbadun didara rẹ, lati fi oore-ọfẹ rẹ han awọn miran ti o wa ni ayika wọn ni pe wọn jẹ alanikanjọpọn. Ti awọn eniyan ba jẹ alanikanjọpọn, o ma n rọrun fun wọn lati tete gbagbe pe oore-ọfẹ Ọlọrun ti wọn n jẹgbadun kọja nkan ti ẹnikan ṣoṣo le e da jẹ tan. Ki a tilẹ sọ otitọ, oore-ọfẹ Ọlọrun kọja ohun ti gbogbo agbaye le jẹ tan. Oore-ọfẹ rẹ ko lodiwọn.

Nitorina, sisọ nipa oore-ọfẹ ati didara Ọlọrun fun awọn ti o wa ni ayika wa ko le di igbadun oore-ọfẹ yi ku ninu aye wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni yoo tun ṣi ilẹkun fun wa lati jẹgbadun rẹ siwaju ati siwaju si. Ṣugbọn ọpọ wa ni o ma n gbagbe ara wọn sinu igbadun oore-ọfẹ ati didara Ọlọrun debi wipe wọn ko ni ranti mọ pe ọpọ ni ayika wọn ni awọn naa nilo iriri oore-ọfẹ ati didara rẹ, ki a ba a le tu wọn silẹ kuro lọwọ awọn nkan ti o n lepa lati pa wọn run, ki wọn si tun ba a le ma gbe igbe aye ti o nitunmọ. Ti a ko ba si wa tete sọji, ki a si ma ṣe ohun ti o tọ, nkan le bajẹ si fun wọn, ki awa naa pẹlu si sọ iwulo wa gẹgẹ bi awọn ti Ọlọrun fẹ ki wọn duro bi i imọlẹ ati iyọ ninu aye yi nu.

Wayi o, a ni apẹrẹ kan ti o daju ninu bibeli lori bi Ọlọrun ti ṣe fẹ ki a ma ṣe pẹlu igbadun oore-ọfẹ ati didara rẹ ti a n jẹ. Eyi wa ninu 2Awọn Ọba 6 ati 7. Bi akọsilẹ naa ti lọ, iyan kan ti o lagbara, ti o si tari awọn kan lati ma pa awọn ọmọ wọn jẹ, fi igba kan mu ni ilu Samaria. Igba ti ọba to wa gbọ eyi ni o to ranti pe Eliṣa, eniyan Ọlọrun, ma wa ni ilẹ naa ati wipe wiwa rẹ ni ilẹ naa yẹ ki o jẹ ki nkan yatọ.

Ni kukuru, Eliṣa sọtẹlẹ pe iṣẹlẹ iyanu ipese lọpọ yanturu kan yoo ṣẹlẹ ni ilẹ naa, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo wọn gbagbe inira wọn ki ilẹ ọjọ keji to ṣu. Nkan si ri gẹgẹ bi o ti sọ wipe yoo ri. Lọna wo? Ki a ma deena pa ẹnu, Ọlọrun ṣẹruba awọn ọta wọn ti o fa iyan ti a n sọ yi pẹlu ariwo ẹgbẹ́ ogun nla kan ti wọn ko fojuri. Nitorina, wọn sa lọ, wọn si tun pa ohun gbogbo ti wọn ko wa lati gbogun ti ilu yi ti.

Ṣugbọn ko wa si ẹnikankan ninu ilu yi ti o mọ ohun ti o ṣẹlẹ, ayafi awọn adẹtẹ mẹrin kan ti wọn fi ẹmi wọn wewu lati wa ounjẹ lọ si ibi ti awọn ọta wọnyi tẹdo si lalẹ ọjọ kanna. Awọn ni o kọkọ kan ọpọ ounjẹ, aṣọ, fadaka, wura ati awọn meremere ọfẹ miran lojiji, eyi ti awọn ọta yi fi silẹ sẹyin nigba ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn. Nitorina, wọn fi ara balẹ ni alẹ ọjọ yi lati ko ọpọ nkan meremere ti ipa wọn ka fun ara wọn. Ni alẹ ọjọ yi kanna, bi o tilẹ jẹ wipe adeẹtẹ ni wọn, wọn di ọlọro.

Amọ ṣa o, bi wọn ti wa n fo lati agọ awọn ọta wọn kan sinu omiran, ti wọn si gbe ohun yowu ti wọn fẹ, o kan dede sọ si iye wọn pe awọn ma ti fẹ di alanikanjọpọn. Bẹẹni, o sọ si wọn ni iye pe awọn nkan rere ti o wa ni ibi itẹdo awọn ọta wọn ma pọ ju nkan ti awọn mẹrẹrin nikan le da jẹ lọ — nkan ti o yẹ ki ẹnikọọkan ni ilẹ wọn pin ninu rẹ, ki wọn si tun jẹgbadun ni. Nitorina, wọn sọ awọn ọrọ yi si ara wọn: “Awa ko ṣe ohun rere. Oni yii jẹ ọjọ iroyin rere awa si paamọ ara wa.Ti awa ba duro titi di afẹmọjumọ, ijaya yoo jẹ ti wa. Ẹ jẹ ki a lọ ni ẹẹkan ki a lọ royin eyi fun awọn ile ọba.” (2Àwọn Ọba 7:9)

Wayi o, nikete ti wọn fi ohun ti o sẹlẹ to ọba leti ni gbogbo ilu jade lati lọ ko oniruuru ohun rere fun ara wọn. Lojiji ni gbogbo wọn si gbagbe awọn inira ti wọn ni iriri rẹ ni asiko iyan naa, ni ibamu pẹlu ọrọ eniyan Ọlọrun. Ka wa sọ wipe awọn adẹtẹ yi ko tete sọji lati ṣe ohun ti o tọ nkọ? Nṣe ni Ọlọrun ko ba dari ẹlomiran ti yoo royin ohun ti o sẹlẹ fun ọba si ibẹ. Ki wa ni o ro wipe ọba yoo ṣe si wọn fun iwa anikankọpọn wọn? O ṣeeṣe ki o da ẹjọ iku fun wọn.

Nikukuru, koko ọrọ mi ni pe ko yẹ ki a maa pa iyin rere oore-ọfẹ Ọlọrun ti a n jẹgbadun mọ fun awọn ti o wa ni ayika wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni o yẹ ki a ṣa gbogbo ipa wa lati fi lọ wọn. Aijẹbẹ, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, a le tipasẹ eyi bẹrẹ si ni din iriri didara rẹ ku ninu aye wa, ki Oun naa si tun wa gbe awọn miran dide lati ṣe ohun ti o yẹ ki a ti ṣe. Nigbanaa ni iyin ati ere ti o yẹ ki o jẹ ti wa yoo si wa lọ si ọdọ wọn. Nitorina, bẹrẹ si ni fi iyin rere didara Ọlọrun si ọ lọ awọn ni o wa ni ayika rẹ laitiju. Njẹ ki o ma fi ojoojumọ gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati jẹ olododo ni ṣiṣe bẹẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe paámọ́ fún wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 52 Read More »

Jẹ́ kí ara rẹ yá gágá sí iṣẹ́ rere rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2024. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi ojoojumọ gba okun lati ṣe idamọ ti o peye awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe ninu aye rẹ ati ni ayika rẹ ati lati ma yin in nitori awọn nkan wọnyi, ki o ba le ni iriri agbara ati didara rẹ lọpọlọpọ si. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti gbogbo wa gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun gbọdọ kọ ni bi a ti ṣe ni yọ mọ ọn fun awọn iṣẹ rere rẹ. Bibeli sọ wipe, “Eniyan iba maa yin Oluwa nitori oore rẹ, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ, si awọn ọmọ eniyan. Si jẹ ki wọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki wọn ki o si fi orin ayọ sọrọ iṣẹ rẹ.” (Saamu 107:21-22) Njẹ o ri bayẹn? Fifi ọpẹ fun Ọlọrun wa ko gbọdọ duro sori awọn nkan ti O n ṣe tabi ti O ti ṣe ninu aye awa tikalara nikan; dipo eyi, o ti gbọdọ da lori awọn nkan ti a le ri wipe O n ṣe ninu aye awọn ti o wa ni ayika wa pẹlu.

Nitorina, o ṣe pataki ki a mura lati kiyesi awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe ninu aye awọn ti o wa ni ayika wa pẹlu, ki o si ma jẹ wipe kiki awọn nkan ti O n ṣe ninu aye wa nikan ni a o ma kiyesi. Ki a tilẹ sọ otitọ, pẹlu nkan ti olukọ Saamu yẹn sọ, a ri wipe ko ki i ṣe ẹ̀rí nkan ti Ọlọrun n ṣe ninu aye wa nikan ni O fẹ ki a ma jẹ; O tun fẹ ki a ma jẹri awọn nkan ti O n ṣe ninu aye ti o wa ni ayika pẹlu.

Ki ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? Akọkọ, o ṣe pataki nitori pe yoo jẹ ki ọpọ ti ko gba Ọlọrun gbọ le ni idi lati gba a gbọ. Ekeji, yoo jẹ ki awọn ti idojukọ wọn ti fi irẹwẹsi sinu igbagbọ wọn gba okun fun igbagbọ naa, nigba ti wọn ba gbọ ẹri ohun ti O n ṣe fun awọn miran. Nibikibi ti a ba si ti n gbe igbagbọ awọn eniyan ninu Ọlọrun ro lọna yi, ti a si tun n fi okun fun un, yoo le ma rin lalai si idiwọ laarin wọn lati ṣe awọn nkan ti o ga ju eyi ti O ti ṣe tẹlẹ lọ.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ wa ninu ijọ loni ni ko ki i dupẹ lọwọ Ọlọrun fun awọn nkan ti O n ṣe ninu aye wa, ka ma tilẹ wa sọ wipe ki a jẹri awọn nkan wọnyi fun awọn miran. Nigba ti a ba si tun gbọ ẹri awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe fun awọn miran ninu awọn ipade ijọ wa, ara wa ko ki i ṣaba ya gaga si. Nitorina, dipo ti a o fi ma gboriyin fun Ọlọrun ninu aye wọn ati ti a o fi ma yọ pẹlu ariwo ati orin iyin, nṣe ni a o kan joko tẹtẹrẹ sojukan, ti a o si ṣe bi igba ti a ko gbọ nkankan. Abalajọ ni a ko ki i fi ri ifarahan Ẹmi ati agbara Ọlọrun lọpọlọpọ ninu pupọjulọ awọn ipade ijọ wa.

Ṣe o ri, bi o tilẹ jẹ wipe ẹri ti ẹnikan ni lati jẹ ni wipe Ọlọrun wo ẹfọri rẹ san, nṣe ni ko jẹ ki ara rẹ ya gaga si i, ki O si tun ba wọn yọ ninu Oluwa lori rẹ. Ma sọ wipe, “Iru ẹri wo ni eleyi bayi o? Iwosan ẹfọri lasan! Ṣe nkan ti a wa sibiyi lati gbọ ni eyi?” Aijẹbẹ, nṣe ni o o fi irẹwẹsi si inu igbagbọ tirẹ gan alara, ti o o si tun kun afẹfẹ ẹmi ti o wa ayika ile-ijọsin ijọ rẹ pẹlu aigbagbọ ati aimoore. Ti iru awọn eniyan bi tirẹ ba wa lọ pọ ninu irufẹ ipade yi, o di dandan ki ẹ di iṣẹ agbara Ọlọrun lọwọ nibẹ tabi ki ẹ tilẹ fi opin si patapata.

Fun apẹrẹ, nigba ti Jesu lọ si ilu abinibi rẹ, ko le ṣe iṣẹ iyanu pupọ nibẹ. O kan wo perete lara awọn ti o n ṣaisan nibẹ san ni. Ki ni idi? Awọn ti o wa nibẹ ko yọ mọ tabi yọ lori iṣẹ ti Ọlọrun ti n ṣe lati ipasẹ rẹ! Lotitọ, ki O to wa si ibẹ, wọn ti gbọ oniruuru ẹri nipa iṣẹ rere rẹ. Dipo ki ara wa ya wọn, ki wọn si ma fi ogo fun Ọlọrun fun awọn nkan ti wọn gbọ, gẹgẹ bi awọn ti o wa ni awọn ibomiran ti o ti ṣe iṣẹ iranṣẹ ti ma n ṣe, nṣe ni wọn n bu, ti wọn si sọrọ rẹ laida. Nitorina, wọn kun afẹfẹ ẹmi ayika ilu wọn pẹlu aigbagbọ ati aimoore, wọn si tipasẹ eyi di iṣẹ agbara Ọlọrun lọwọ ni aarin wọn. (Wo: Maaku 6:1-6)

Nibakanna, nigba ti Jesu lọ si ile Jairu lati ji ọmọdebinrin rẹ kuro ninu oku, O kọkọ nilo lati le gbogbo awọn ti o wa nibẹ, ti wọn si n kun afẹfẹ ẹmi ayika ile ọkunrin yi pẹlu aigbọgbọ jade, ki wọn ma ba di iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ṣetan lati ṣe lọwọ. Igbesẹ ti O gbe yi si ṣiṣẹ. Ṣugbọn ṣe o wa yẹ ki awa naa bẹrẹ si ni le awọn ti ara wọn ko ya gaga lati yin Ọlọrun fun iṣẹ rere rẹ laarin wa jade kuro ninu awọn ipade ijọ wa? Ṣe eyi yoo ṣe e gbọ seti bi? (Wo: Maaku 5:35-43)

Nikukuru, koko ọrọ mi ni pe ti a ba fẹ ma a ri ifarahan agbara, ifẹ ati didara Ọlọrun ninu aye wa ati ninu awọn ipade wa lọpọlọpọ ati lọna ti o ga ju tatẹyinwa lọ, a gbọdọ kọ lati ma yọ ṣẹṣẹ lori ohun rere gbogbo ti O ba ṣe fun wa, bi o tilẹ jẹ wipe iwosan ẹfọri lasan ni. Nitoripe ọpọ ṣẹyin ni o ti tipasẹ ẹfọri lasan ku. Ti Ọlọrun ba si wa wo ẹfọri ẹnikan laarin wa san, nṣe ni o yẹ ki a yọ mọ fun gbigba ẹni naa kuro lọwọ iku. Bi a ti ṣe le ma la ọna fun niyi lati ma fi igba gbogbo rin lalai ni idiwọ laarin wa lati ṣe iṣẹ ti o ga, ti o si lagbara.

Ki o ni ọsẹ alayọ.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jẹ́ kí ara rẹ yá gágá sí iṣẹ́ rere rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 51 Read More »

Ni ìtara fún ìfarahàn re| Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 07, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 49

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mu dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji oṣu yi, iyẹn oṣu Igbe 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu ebi ati ipongbẹ ti o ga fun oniruuru ifarahan Ẹmi rẹ ninu aye rẹ ati ninu ijọ rẹ̀, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, ọkan lara idi ti Ọlọrun ṣe tu Ẹmi rẹ jade sori awọn eniyan ni ki O ba le ma fi ara rẹ han laarin wa nipasẹ oniruuru awọn ẹbun Ẹmi yi. Wo bi bibeli ti ṣe gbe eyi kalẹ:

“Ni ikẹyin ọjọ, Ọlọrun wi pe, Emi yoo tu Ẹmi mi jade sara eniyan gbogbo, awọn ọmọ yin ọkinrin ati awọn ọmọ yin obinrin yoo maa sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin yin yoo si maa riran, awọn arugbo yin yoo si maa la ala; ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obirnin, ni Emi yoo tu Ẹmi mi jade ni awọn ọjọ naa, wọn yoo si maa sọtẹlẹ.” (Iṣe Apọsiteli 2:17-18)

Tani O sọ wipe Oun yoo tu Ẹmi Oun sori gbogbo eniyan? Ọlọrun ni! Ṣe O si ti wa ṣe eyi? Bẹẹni, O ti ṣe e. O ṣe e ni ẹyin igbasoke Jesu Kiristi Oluwa wa ati ni ọjọ Pẹntikọsiti ti o tẹle. Ki wa tun ni Ọlọrun sọ wipe yoo ṣẹlẹ lẹyin ti O ba ti tu Ẹmi rẹ sori gbogbo eniyan? O sọ wipe awọn ọkunrin ati obinrin, awọn ọdọmọdekurin ati ọdọmọdebirin ati awọn arugbo lọkunrin ati lobinrin yoo bẹrẹ si ni sọtẹlẹ, ri iran, la awọn ala ti Ẹmi ati ni awọn oniruuru iriri ifarahan Ẹmi Ọlọrun miran ninu aye wọn.

Nitorina, gbogbo awa ti a gba Jesu Kiristi gbọ, ti a si ti gba itusilẹ Ẹmi rẹ sinu aye wa ni a le fojusọna lati ni awọn iriri ti Ọlọrun menuba yi. A le fojusọna lati sọtẹlẹ, lati fedefọ, lati ri iran, lati la awọn ala ti Ẹmi, lati wo awọn eniyan san, lati ṣe iṣẹ iyanu ati lati ṣe awọn nkan miran ti Ọlọrun sọ ninu Iwe Mimọ pe a o ma ṣe ni kete ti Ẹmi rẹ ba ti wọle sinu aye wa. (Wo:1Kọrinti 12:4-12)

O wa ṣeni laanu pe nkan ti a n ri ninu oniruuru ijọ Ọlọrun kaakiri agbaye jinna rere si eyi. A ko ki i fi tatatara ni iriri ifarahan awọn ẹbun Ẹmi lọna ti o ga ni aarin wa, ni ibamu pẹlu bi Ọlọrun ti ṣe wi. Ki ni idi? Idi kan pataki fun eyi ni pe a ko ni itara lati ri pe ohun ti O ti sọ wa si imuṣẹ ni aarin wa ati ninu aye wa.

Otitọ ni pe awọn eke ifarahan ẹbun Ẹmi wa. Bẹẹni, awọn eke isọtẹlẹ, eke ifedefọ, eke iwosan, eke iṣẹ iyanu ati eke ẹkọ wa. Ṣugbọn nibi ti a ba ti ri eke nkan, o di dandan ki ojulowo rẹ wa nibikan nitosi. A o wa ma yan ara wa jẹ ti a ba kọ lati lọ fun ojulowo nitori eke.

Nibakanna, niwọn igba ti awọn eke ifafarahan ẹbun Ẹmi Ọlọrun ti wa, o yẹ ki a mọ pe ojulowo ifarahan awọn ẹbun Ẹmi rẹ naa wa. Nkan ti a kan nilo lati ṣe ni pe ki a kọ lati inu Iwe mimọ bi a ti ṣe le da ojulowo ifarahan Ẹmi mọ yatọ si gbarufu rẹ, ki a ba le fi itara lọ fun eyi ti o jẹ ojulowo. Aijẹbẹ, nṣe ni a o kan ma ja ara wa lole awọn ibukun ti o yẹ ki a ma ni iriri wọn ni aarin wa ati ninu aye ti a wa nipasẹ iṣẹ awọn ẹbun daradara ti Ẹmi yi.

Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, ayọ kun ilu awọn ara Samaria kan ti Filipi wa waasu nibẹ (Ìṣe Àpọ́sítélì 8:5-8). Ki ni idi? Idi ni pe oniruuru ifarahan ẹbun Ẹmi ti ipasẹ rẹ waye nibẹ, bi o ti ṣe n waasu. Awa naa si wa le fojusọna fun awọn ile wa, agbegbe wa, ile-iwe wa ati ibi iṣẹ waa lati kun fun ayọ, nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba bẹrẹ si ni fi ara rẹ han nipasẹ wa ni oniruuru ọna. Ọlọrun si ti sọ wipe eyi yoo waye. A kan nilo lati fi itara pongbẹ fun iriri ohun ti O ti sọ wipe yoo waye ninu aye wa ati ni aarin wa ni.

Nitorina, bibeli sọ wipe, “Ẹ maa lepa ifẹ, ki ẹ si maa fi itara ṣafẹri ẹbun ti i ṣe ti Ẹmi, ṣugbọn ki ẹ kuku le maa sọ tẹlẹ.” (1Kọrinti 14:1) Njẹ o ri bayẹn? Akọkọ, a sọ fun wa pe ki a jẹ ki ifẹ jẹ ìpìlẹ̀ ohun gbogbo ti a ba n ṣe laye. A tun sọ fun wa pe ki a ma fi itara ṣafẹri awọn ẹbun Ẹmi. Ṣe o ti fi itara foju sọna fun nkankan ri laye rẹ, yala iranlọwọ ẹnikan ni tabi ayẹyẹ kan ti o fẹ lọ? Bawo ni itara rẹ ni asiko yi ṣe jẹ ki nkan ri lara rẹ? O fẹrẹ damiloju pe itara naa ko jẹ ki ara rẹ balẹ. Dibo eyi, nṣe ni o jẹ ki o ṣe ohun gbogbo ti o nilo lati ṣe lati gbaradi fun nkan naa.

Nibakanna, ti awa naa ba ni itara fun ifarahan Ẹmi Ọlọrun inu aye wa ati ninu awọn ijọ wa, a o ma ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki a ṣe lati ri pe o waye. A o ma ṣe aṣaro lori nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ nipa rẹ. A o ma gbadura pe ki o waye. A o si tun ma gbe igbesẹ igbagbọ lati ri pe o waye. Nitorina, bi a ti ṣe n lọ ni ọsẹ yi, nṣe ni ki a jẹ ki itara wa fun ifarahan Ẹmi Ọlọrun ninu aye wa ati ninu ijọ Ọlọrun sọ ji. Awọn nkan ayọ ti o ga ati ti ko ṣe fẹnusọ yoo si bẹrẹ si ni ṣẹlẹ ninu aye wa ati kaakiri ayika wa.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ni ìtara fún ìfarahàn re| Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 07, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 49 Read More »