Sìn-ín pẹ̀lú ìjáfáfá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 06, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 27

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Belu 2022. Mo gbadura pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba sin Ọlọrun pẹlu ijafafa ati tọkantọkan, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ko fẹ ki awọn eniyan rẹ kan sin-in nikan; O tun fẹ ki ijafafa tabi imura-kankan ma farahan ninu iṣẹ isin wọn. Ko fẹ ki o gba wọn ni ayeraye lati pa ọkan pọ lati sin-in tabi lati bẹrẹ si ni ṣiṣẹ sin-in. Ki ni idi? Idi ni pe ti a ko ba jafafa lati ṣe awọn nkan ti O fẹ ki a ṣe, awọn kan ti O fẹ ti ipasẹ wa bukunfun le lailai padanu ibukun rẹ lẹyin-ọ-rẹyin. Ti eyi ba si waye, yatọ si pe O le da seria fun wa nitori pe a jẹ ki awọn miran padanu ibukun rẹ, awa gan paapaa yoo padanu ohun yowu ti ko ba jẹ ere fun wa ka sọ wipe a ṣe kankan lati ṣe ifẹ rẹ ni.

Nitorina, ma lọ ro wipe o ni gbogbo akoko laye yi lati pese ara rẹ lati ṣin Ọlọrun. O ko ni. Ti o ko ba si tete gbajumọ ohun yowu ti O ba sọ fun ọ lati ṣe fun tabi ti ọwọ rẹ ba ba lati ṣe fun, asiko naa n bọ ti yoo ti pẹ ju fun ọ lati ṣe ohun naa ti o ko ba ti ṣe fun. Ranti pe Jesu sọ wipe, “Awa ni lati ṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, niwọn igba ti o ba ti jẹ ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ.” (Johanu 9:4) Njẹ iwọ wa fẹ duro ki oru de ba ọ nibi ti o ti n wọ ẹsẹ rẹ nilẹ nidi iṣẹ Oluwa bi?

Nitemi o, mi o fẹ ki o ri bẹ fun mi. Dipo eyi, mo fẹ tẹle awọn apẹrẹ ti a fun wa ninu bibeli nipa awọn ti o jafafa lati ṣe idamọ bi Ọlọrun ṣẹ fẹ ki wọn sin Oun, ti wọn si tun jafafa lati bẹrẹ si ni ṣin in. Mo mọ daju, fun apẹẹrẹ, pe o ti gbọ nipa ọkunrin were ara Gadara kan ti a mẹnuba ninu bibeli ati bi Jesu Oluwa ṣe tu ṣilẹ kuro lọwọ arun ọpọlọ. Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, ni kete ti ọkunrin yi ri pe a ti wo oun san ni o ti bẹrẹ si ni bẹ Jesu lati jẹ ki oun tẹle lọ si ibi yowu ti O ba n lọ. Ṣugbọn Oluwa sọ fun pe ki o ma tẹle Oun, amọ ki o lọ sọ fun awọn ẹbi rẹ bi Ọlọrun ti ṣe ṣaanu fun to. (Wo: Máàkù 5:1-19)

Ṣe ọkunrin yi wa ṣe bi Oluwa ti pasẹ fun bi tabi ko ṣe bẹẹ? O ṣe bẹẹ gẹgẹ. O tilẹ tun ṣe ju nkan ti a sọ fun lọ. Lalai fi akoko ṣofo rara, o jade lọ kaakiri agbegbe kan ti a n pe ni ‘Dekapolisi’, eyi ti o tunmọ si ‘Ilu mẹwa’, o si n sọ ẹri rẹ fun gbogbo ẹni ti o ba bikita lati gbọ ọ (Máàkù 5:20). Nkan ti a n pe ni ijafafa ni sisin Oluwa niyẹn. Eyi si ni a n pe wa lati ṣe awokọse rẹ.

Lafikun, bibeli tun sọ fun nipa arabinri oniṣowo kan ni ilu Filipi ti a n pe ni Lidia ati nipa bi o ti se di atunbi lati ipasẹ iṣẹ-iransẹ Pọọlu Apọsiteli (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:13-15). Bi a tun ṣe wa sọ siwaju si nipa rẹ, ọjọ gan ti o di atunbi naa ni o bẹrẹ si ni sin Oluwa pẹlu Pọọlu ati awọn akẹgbẹ rẹ. O fi ilegbe ọ̀fẹ́ lọ wọn ninu ile rẹ lọjọ yi kanna, o si duro le ọrọ rẹ lori pe wọn gbọdọ tẹwọgba ile naa, ti o ba jẹ pe wọn gba nitootọ pe oun ti di atunbi. Abalajọ ti Pọọlu, nigba ti o n kọ lẹta si ijọ Filipi, fi sọ eyi nipa wọn, “Ninu gbogbo adura mi fun-un yin, emi n fi ayọ gbadura, nitori idapọ yin ninu iyin rere lati ọjọ kin-in-n wa titi di isinsyinyii.” (Fílípì 1:4-5)

Wayi o, irufẹ ijafafa ninu iṣẹ-iransẹ ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe awokọṣe rẹ ni eyi. O fẹ ki a jafafa lati waasu ọrọ rẹ, ki a jafafa lati gbadura fun awọn ẹlomiran, ki a jafafa lati fifun iṣẹ rẹ, ki a si tun jafafa lati mojuto awọn eniyan rẹ. Irufẹ iṣẹ isin yi ni o si dun mọ ninu, ti O si ma n pin ere fun awọn eniyan le lori, iṣẹ-isin ti a ṣe pẹlu ijafafa. Adura mi wa ni pe ki a kọ ọkan rẹ, ki a si tun fun ni okun lati ma fi igba gbogbo jafafa lati ṣe ohunkohun ti Ọlọrun ba fẹ ki o ṣe lati sin-in, ki o ma ba tun lailai padanu ere iṣẹ isin rẹ mọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Sìn-ín pẹ̀lú ìjáfáfá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 06, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 27 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:15-29

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ

ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:15-29

ỌJỌ́RÚ 02, BELU 2022

DOWNLOAD E-COPY HERE

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ sẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri wipe nipa igbagbọ ninu Ọlọrun ati ọrọ rẹ ni eniyan ṣe n di olododo ati ẹni idalare niwaju rẹ. Aburahamu si ni a lo gẹgẹ bi apẹẹrẹ bi eniyan ṣe n ti ipasẹ igbagbọ ninu Ọlọrun da ẹni idalare niwaju rẹ. Aburahamu gba Ọlọrun gbọ. Ọlọrun si ka igbagbọ rẹ si ododo fun un. Ti awa na ba gba a gbọ, ti a si tẹle ọrọ rẹ si wa lori bi a ti ṣe le di ẹni igbala ati olododo, awọn naa yoo di olododo ati ẹni idalare niwaju rẹ. Ṣugbọn ti a ko ba gba a gbọ, ti a si wa ro wipe iṣẹ ọwọ wa tabi awọn ofin kan ti a n tẹle ni yoo sọ wa di ẹni idalare niwaju rẹ, a jẹ wipe a kan n tan ara wa jẹ ni.

Gẹgẹ bi Pọọlu ṣe jẹ ki o ye wa ninu abala lẹta rẹ yi ti a wo kẹyin, nipasẹ ofin Mose kọ ni Aburahamu ṣe di olododo niwaju Ọlọrun bikoṣe nipaṣẹ igbagbọ. Ko tilẹ si ohun ti o n jẹ ofin Mose ni akoko yi, nitori a ko i ti bi Mose. Yatọ si eleyi, ileri ti Ọlọrun ṣe fun Aburahamu pe Oun yoo bukun fun gbogbo araye nipasẹ iru-ọmọ rẹ ko wa nipasẹ pe o pa ofin kankan mọ. Dipo eyi, o wa nipasẹ igbagbọ. Ofin Mose tilẹ ni akude nitori ti o fi awọn arọmọdọmọ Aburahamu ti a fi fun si abẹ egun. Eyi ko si jẹ ki Ọlọrun le ti ipasẹ wọn bukunfun gbogbo awọn araye bi O ti ba Aburahamu baba nla wọn da majẹmu. Nitorina, yatọ si pe wọn nilo irapada kuro ninu ẹsẹ wọn, wọn tun nilo ki a yọ wọn kuro labẹ egun ofin. Idi si ni yi ti a fi kan Jesu mọ agbelebu, ki a ba le gba wọn kuro labẹ egun ofin, ki ileri Ẹmi mimọ ba le jẹ ti wọn ati ti gbogbo awọn ti o ba gbagbọ ninu rẹ.

ÌWÚLÒ ÒFIN MÓSÈ
Wayi o, Pọọlu wa tẹsiwaju ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi lati ṣe alaye siwaju si idi ti yala awọn Juu ni tabi awọn Keferi ni ko ṣe nilo ofin Mose fun igbala tabi fun idalare wọn niwaju Ọlọrun. O si tun ṣe alaye pẹlu idi ti a fi fun awọn Juu ni ofin Mose. Iwọ naa kọkọ wo diẹ lara ọrọ rẹ:

“Ara, emi n sọrọ bi eniyan; Bi o tilẹ jẹ pe majẹmu eniyan ni, bi a ba ti fi idi rẹ mulẹ, ko si ẹni ti o le sọ ọ di asan, tabi ti o le fi kun un mọ. Njẹ fun Aburahamu ati fun iru-ọmọ rẹ ni a ti ṣe awọn ileri naa. Oun ko si wi pe, Fun awọn iru-ọmọ rẹ, bi ẹni pe ọpọlọpọ iru-ọmọ rẹ, ṣugbọn bi eni pe ọkan, ati fun iru-ọmọ rẹ, eyi ti i ṣe Kirisiti. Eyi ni mo n wi pe, majẹmu ti Ọlọrun ti fi idi rẹ mulẹ niṣaaju, ofin ti o de lẹyin ọgbọn-le-nirinwo ọdun ko le sọ ọ di asan tabi ki o sọ ileri naa di alailagbara. Nitori bi ogun naa ba wa nipa ṣiṣe gẹgẹ bi ofin, ki i ṣe ti ileri mọ: ṣugbọn Ọlọrun ti fi i fun Aburahamu nipa ileri. Njẹ ki a ni ofin? A fi kun un nitori irekọja titi oru-ọmọ ti a ti ṣe ileri fun yoo fi de; a si ti ipasẹ awọn angẹli ṣe ilana rẹ lati ọwọ onilaja kan wa. Njẹ onilaja ki i ṣe alarina ti ẹnikan, ṣugbọn ọkan ni Ọlọrun.” (Gàlátíà 3:15-20)

Ki ni Pọọlu fẹ ki o ye wa ni ibi? Ohun naa ni pe ileri ti Ọlọrun ṣe fun Aburahamu lati bukun fun gbogbo araye nipasẹ iru-ọmọ rẹ ko ti ipasẹ ofin Mose wa. O si yẹ ki o ye wa irufẹ ibukun ti a n sọrọ nipa. Bi a ti ṣe ri ninu alaye ti apọsiteli yi ṣe siwaju, ileri ibukun ti a ṣe fun Aburuhamu ni i ṣe pẹlu irapada ati idalare awọn eniyan kuro ninu ẹsẹ, kuro labẹ ibinu Ọlọrun ati gbigba ẹbun Ẹmi mimọ rẹ lati tun wa bi ati lati ma gbe inu wa titi lailai. Eleyi kọja ki a ni owo lọwọ, ni ile lori, ra mọto rẹpẹtẹ, bi ọmọ, ri iwosan gba tabi di gbajumọ. Bi o tilẹ jẹ wipe ibukun Ọlọrun ma n farahan nipasẹ awọn nkan wọnyi, wọn ko ki i ṣe ibukun ayeraye ti ko ni parun rara. Ibukun ogun ayeraye ti ko ni parun tabi dibajẹ ni Ọlọrun ṣeleri fun Aburahamu lati fun awọn eniyan lati ipasẹ iru-ọmọ rẹ.

Pọọlu wa n jẹ ki o ye wa pe mọ ofin Mose ti a fifun awọn ọmọ Isiraẹli lẹyin irinwo ọdun le ni ọgbọn ko le yi majẹmu ti Ọlọrun ba Aburahamu da pada. Bi a ti ṣe mọ, laarin awọn eniyan, ti a ba ti da majẹmu pẹlu ẹnikan, ti a si fi idi rẹ mulẹ, ko si nkankan ti o le yi pada. Bẹẹ gẹgẹ naa ni o si ṣe ri pẹlu Ọlọrun. Majẹmu rẹ ni pe Oun yoo ti ipasẹ iru-ọmọ Aburahamu bukun fun gbogbo araye. Ko si sọ pe ki Aburahamu ṣe nkankan lati ri imuṣẹ eyi. Oun lo ṣe ileri. Ọwọ rẹ lo si wa lati mu u ṣẹ, ko ni nkankan ṣe pẹlu ohun ti Aburahamu ṣe tabi ti ko ṣe. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3 & 22:15-18)

Amọ eyi ko ribẹ pẹlu ofin Mose. Awọn angẹli ni o ko ofin yi jọ pọ, gẹgẹ bi Pọọlu ṣe jẹ ki o ye wa, ti a si gbe le Moṣe lọwọ lati fi fun awọn ọmọ Isiraẹli. Ki a to gbe ofin yi le Mose lọwọ fun wọn, Ọlọrun ti kọkọ ba wọn sọrọ lori nkan ti O fẹ ati eyi ti ko fẹ, ki ibukun rẹ to jẹ ti wọn ni ilẹ ti O n mu wọn lọ. Wọn si dahun wipe nkan ti O sọ ba awọn lara mu. Nitorina, O ba wọn da majẹmu pe ibukun Oun yoo jẹ ti wọn, nigbọn igba ti wọn ba pa ofin ati ilana Oun mọ. Ṣugbọn ko ni jẹ ti wọn niwọn igba ti wọn ko ba pa a mọ. Wọn si sọ pe awọn faramọ. Mose wa ni o duro gẹgẹ bi ẹlẹri tabi alarina laarin awọn ati Ọlọrun ni ọjọ ti a da majẹmu yi, ti a si gbe iwe rẹ le wọn lọwọ. (Wo: Ẹ́kísódù 24:1-9; Iṣe Apọsiteli 7:53)

Eyi wa n jẹ ki o ye wa pe majẹmu ti Ọlọrun da pẹlu Aburahamu yatọ patapata si eyi ti o da pẹlu awọn ọmọ Isiraẹli. Majẹmu ti O da pẹlu Aburahamu ni i ṣe pẹlu bi yoo ṣe bukun fun gbogbo araye nipasẹ iru-ọmọ rẹ. Majẹmu yi ko si ni tabi-ṣugbọn ninu. Ṣugbọn eyi ti O da pẹlu awọn ọmọ Isiraẹli ni i ṣe pẹlu igbaye-gbadun wọn ni ilẹ ileri ti O fun wọn, iyẹn ilẹ Kenani. Majẹmu eyi wa ni tabi-ṣugbọn ninu. Amọ, ko ni agbara lati pa ti eyi ti O da pẹlu Aburahamu lara lọna kankan.

Siwaju si, Pọọlu tun jẹ ki o ye wa pe imuṣẹ Majẹmu ti Ọlọrun da pẹlu Aburahamu yi gan ko ni ti ipasẹ gbogbo iru-ọmọ rẹ waye. Idi si ni pe iru-ọmọ rẹ kan ṣoṣo ni Ọlọrun sọ wipe Oun yoo ti ipasẹ rẹ bukun fun gbogbo araye, ko ki i ṣe awọn iru-ọmọ rẹ. Ta wa ni iru-ọmọ rẹ ti a n sọ yi? Kirisiti ni. O si ti wa lati sọ gbogbo awọn ti o ba gbaagbọ di alabukunfun.

Ki wa ni iwulo ofin Mose gan? Abi ṣe ofin yi tako awọn ileri Ọlọrun si Aburahamu ati iru-ọmọ rẹ? Idahun Pọọlu si awọn ibere yi lọ bayi:

“Nitori naa ofin ha lodi si awọn ileri Ọlọrun bi? Ki a ma ri i. Nitori iba ṣe pe a ti fi ofin kan fun ni ti o lagbara lati sọ eniyan di alaaye, nitoootọ ododo iba ti ti ipasẹ ofin wa. Ṣugbọn iwe-mimọ ti fi ye wa pe, gbogbo eniyan ni n bẹ labẹ ide ẹṣẹ, ki a si le fi ileri nipa igbagbọ ninu Jesu Kirisiti fun awọn ti o gbagbọ. Ṣugbọn ki igbagbọ to de, a ti pa wa mọ labẹ ofin, a si ṣe wa mọ de igbagbọ ti a n bọ wa fihan. Nitori naa ofin ti jẹ olukọni lati mu eniyan wa sọdọ Kirisiti, ki a le da wa lare nipa igbagbọ. Ṣugbọn lẹyin igba ti igbagbọ ti de, awa ko si labẹ olukọ mọ. Nitori pe ọmọ Ọlọrun ni ẹyin n ṣe, nipa igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Nitori pe iye ẹyin ti a ti batisi sinu Kirisiti, ti gbe Kirisiti wọ. Ko le si Juu tabi Heleni, ẹru tabi ominira, ọkunrin tabi obinrin nitori pe, ọkan ni gbogbo yin jẹ ninu Kirisiti Jesu. Bi ẹyin ba si jẹ ti Kirisiti, njẹ ẹyin ni iru-ọmọ Aburahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri.” (Gàlátíà 3:21-29)

Njẹ o ri bayi? Ofin Mose ko lodi si ileri ibukun igbala, idalare, atunbi ati isọdọmọ Ọlọrun ti Ọlọrun ṣe fun iru-ọmọ Aburahamu rara. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, idi ti a ṣe fun awọn ọmọ Isiraẹli ni ofin ni ẹsẹ, ti o ti fi gbogbo eniyan si abẹ ide iparun. Eyi jasi pe a ko fun wọn ni ofin yi lati sọ wọn di olododo ṣugbọn a fun wọn ki o ba le ṣe akoso wọn ninu ifẹ Ọlọrun titi iru-ọmọ Aburahamu ti yoo gba wọn la ati sọ wọn di ọmọ Ọlọrun yoo fi de. Eyi tunmọ si pe Juu ti o ba fi tọkantọkan tẹle ofin Mose ko ni ṣe alaigbagbọ ninu iru-ọmọ Aburahamu, iyẹn Kirisiti, nigba ti O de.

Niwọn igba ti Kirisiti si ti de, ofin Mose ti pari iṣẹ rẹ. Igbagbọ ninu Kiristi ni o ku ti awọn ti o ba fẹ di alabapin ninu ibukun Aburahamu gbọdọ fi han. Gbogbo awọn ti o ba si ti fi igbagbọ han ninu rẹ fun igbala ati idalare wọn ni o ti di ọkan pẹlu rẹ, ti wọn si ti gbe wọ. Awọn wọnyi si ti da ọmọ Ọlọrun ati iru-ọmọ Aburahamu ati arole rẹ pẹlu rẹ, yala Juu ni wọn ni o tabi Heleni, ẹru niwọn ni o tabi ominira, ọkunrin ni wọn ni o tabi obinrin.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ileri Ọlọrun lati bukun fun gbogbo aye nipasẹ Aburahamu ko da lori ofin Mose rara. A fun awọn ọmọ Isiraẹli ni ofin Mose lati ṣe amọna wọn titi akoko yoo fi to fun Ọlọrun lati mu ileri ti O ṣe fun Aburahamu ṣẹ ni. Niwọn ti O si ti mu ileri yi ṣe nipa riran Jesu Kirisiti, iru-ọmọ Aburahamu ti a ṣe ileri fun lati bufun fun gbogbo araye nipasẹ rẹ, ofin Mose ti pari iṣẹ rẹ. Kiki ki awọn eniyan gba iru-ọmọ Aburahamu yi gbọ loku fun wọn lati di alabakunfun, ọmọ Ọlọrun ati ajogun iye ayeraye.

ÌBÉÉRÈ

  • Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran oye rẹ nipa ofin Mose ati iwulo rẹ lọwọ si?
  • Ki ni o ṣe pataki si ọ julọ ninu ẹkọ naa?

Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:15-29 Read More »

Ya ayé rẹ ya àwọn ǹkan wọ̀nyí | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 26

DOWNLOAD E-COPY

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran, eyi ti o jẹ ọsẹ àbájá oṣu Belu lati inu oṣu Ọ̀wàrà 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ojurere rẹ bori aye rẹ ni gbogbo awọn ọjọ ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Peteru ti o sọ wipe, “Nitori naa, ẹ fi arankan gbogbo silẹ ni apakan, ati ẹtan gbogbo, ati agabagebe ati ilara, ati sisọ ọrọ buburu gbogbo.” (1Peteru 2:1) Awọn nkan wo ni Peteru ni ki a yago fun nibi? Awọ iṣẹ ẹran ara ni. O si fun wa ni apẹẹrẹ awọn iṣẹ ẹran ara naa ti a nilo lati ya ara wa ya. O darukọ arankan, ẹtan, agabagebe, ilara ati ifọrọbatẹnijẹ. Awọn iṣẹ ẹran ara wa pọ ti apọsiteli yi le lo gẹgẹ bi apẹẹrẹ. Ṣugbọn o lo awọn wọnyi, ni igbagbọ temi, nitoripe wọn jẹ pataki lara awọn iṣẹ ẹran ara ti o ma n ṣaba ba ajọṣepọ awọn Kirisitiẹni jẹ, ba ijọ Ọlọrun jẹ ati di igbasoke ati imunadoko rẹ lọwọ.

Fun apẹẹrẹ, bi agbere ati ibọriṣa ti ṣe buru to, wọn ki i ṣaba yọri si pinpinya tabi titu ijọ. Ṣugbọn ti a ko ba tete mojuto arankan (didi ẹlomiran sinu), ẹtan, ilara ati ibanilorukọjẹ, wọn le tu ìjọkíjọ laarin ọsẹ melokan, ki wọn si tun kun awọn ọmọ ijọ ti ọrọ ba kan pẹlu ẹtanu ti o le ma fi wọn silẹ ni gbogbo iyoku ọjọ aye wọn. Ara idi si niyi ti Ọlọrun ni ẹkọkọkan fi ma n ṣe idajọ awọn ẹṣẹ yi laarin awọn eniyan rẹ pẹlu ọdaju.

Ṣe o ranti ọrọ Ananaya ati Safira? Ki ni idi ti Ọlọrun ṣe daju ṣe idajọ wọn bi O ti ṣe ṣe? Ki ni idi ti O ṣe pa tọkọtaya yi ni ọjọ kanna lai tilẹ ṣẹju pẹkẹ? Nitori ẹtan ati agabagebe ni. Awọn eniyan yi n gbiyanju lati tan ijọ Ọlọrun jẹ lori ọrẹ wọn nipa jijẹ ki awọn eniyan ro wipe nkan ti wọn n fi ṣilẹ pọ ju nkan ti wọn silẹ gan lọ. Nitorina, Ọlọrun ṣe idajọ wọn pẹlu iku ki o to di wipe wọn o ri aye fi igbe aye ẹtan le awọn ọmọ ijọ miran lọwọ (Iṣe Apọsiteli 5:1-11).

Nkan ti eyi si n fi han wa ni pe Ọlọrun n mojuto ijọ rẹ ati wipe ko ni kawọ gbera lati ma wo ki ẹnikẹni fi idibajẹ sinu rẹ tabi pa a run, nitori ijọ ni tẹmipili rẹ. Pọọlu ti lẹ sọ fun wa pe Ọlọrun yoo pa ẹnikẹni run ti o ba ba tẹmipili rẹ jẹ. Idi ni yi ti a fi gbọdọ mu ọrọ iyanju Peteru si wa ninu akọsilẹ ti o wa loke yẹn ni pataki. A nilo lati ya aye wa oniruuru ẹtan, arankan, ilara, agabagebe ati ibanilorukọjẹ, bi a ti ṣe n ba ara wa lo ninu awọn ijọ wa. Aijẹbẹ, a le fa idajọ Ọlọrun sori ara wa. (Wo: 1Kọrinnti 3:16-17)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni oye awọn nkan wọnyi ko ye. Nitorina, wọn n fi aye gba arankan, agabagebe, owu, ẹtan ati ibanilorukọjẹ lati gbilẹ ati lati tan kalẹ ninu aye wọn ati laarin wọn. Ko wa jẹ ki o yani lẹnu pupọ pe ọpọ ninu awọn ijọ Kirisitiẹni kaakiri loni ni o n ba oniruuru aisan, ìṣẹ́ ati inira ti ko ni lọ, bi o ti wu ki wọn gbadura tabi awẹ to, finra. Nkan ti awọn wọnyi si ni lati ṣe ko ju ki wọn ya ara wọn ya awọn iṣẹ ẹran ara buburu ti wọn ti faye gba ninu aye wọn yi lọ. Iwosan Jesu yoo si bẹrẹ si ni jẹyọ ninu aye wọn.

Wayi o, boya idi ti iwọ naa fi n dojukọ awọn iṣoro kan ti wọn ti kọ jalẹ lati kuro ninu aye rẹ ni pe o ti fi aye silẹ fun ikorira, arankan, ilara, ibanilorukọjẹ ati agabagebe ninu aye rẹ. O ti fi aye gba Eṣu lati ma lo ọ ni ikọkọ tabi ni gbangba lati pa ijọ Ọlọrun lara. O nilo lati ronupiwada lọwọlọwọ yi ki a ba le wo aye rẹ san, ki a si tun mu larada. Aijẹbẹ, nkan le bajẹ ju bayi lọ fun ọ. Adura mi ni pe ki a tẹri ọkan rẹ ba lati ṣe ohun ti o tọ lalai fi akoko ṣofo, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ya ayé rẹ ya àwọn ǹkan wọ̀nyí | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 26 Read More »

Ifẹ rẹ ko ti da tutu bi? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 23, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 25

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun pupọ lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Òwewè 2022. Mo gbadura pe ki Ọlọrun pa ọ mọ lati wa ni ailabawọn ati ailẹbi, lẹmi, lọkan ati lara ni igba ti Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa ba fi ara han. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti Oluwa sọ pe yoo ṣẹlẹ ni awọn ọjọ ikẹyin ni pe ifẹ ọpọlọpọ yo di tutu. Ki si ni idi ti eyi yoo ṣe ṣẹlẹ? Idi ni pe iwa ika yoo di pupọ si ninu aye. Njẹ eyi ko wa jẹ otitọ bi loni? Njẹ iwa ika ko ma fi ojoojumọ pọ si ni gbogbo ayika wa? (Wo: Matiu 24:12)

Wo orilẹ-ede wa, fun apẹrẹ. Wo bi idigunjalu, ijinigbe, igbesunmọnmi, agbere, iṣẹ gbajuẹ, iṣeṣo owo, ipaniyan ati lilu owo ilu ni ponpo ṣe n fi ojoojumọ pọ si. Lafikun, tun wo bi lilo ogun oloro ṣe wa di tọ́rọ́-fọ́nkálé laarin awọn ọdọ wa. Sibẹsibẹ awọn adari wa ko tilẹ ri awọn nkan wọnyi ro rara.

Nitorina, ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni o ti pa igbe aye ododo ti patapata. Wọn wa n gbe aye wọn bi igba ti Oluwa ko gba wọn la rara. Ọpọ ni ko tilẹ fẹ ki ẹnikẹni sọ fun wọn pe o jẹ dandan fun wọn lati gbe igbe aye ti o tọ mọ. Sibẹsibẹ wọn n pe ara wọn ni Kirisitiẹni. Eyi si wa ni ibamu pẹlu nkan ti Oluwa wa sọ nipa bi pipọsi iwa ika yoo ṣe jẹ ki ifẹ pupọjulọ awọn onigbagbọ di tutu ni awọn ọjọ ikẹyin yi.

Ibere wa ni pe, “Ṣe ifẹ rẹ fun Oluwa ko ti da tutu nitori pipọsi iwa ika ti aye yi n ba finra ni ojoojumọ?” Ti ara rẹ ko ba ya gaga si ọrọ Ọlọrun ati adura mọ, a jẹ wipe ifẹ rẹ fun un ti di tutu niyẹn. Ti biba awọn ọmọ Ọlọrun ṣe pọ ba ti su ọ, ti o ko si fojusọna si mọ, ifẹ rẹ ti da tutu. Ti inu ba ma n bi ọ nigbakugba ti a ba mu otitọ tọ ọ wa, ifẹ rẹ ti di tutu. Lafikun, ti o ba ti di alanikanjọpọn, ti o si ma n ni ọ lara lati fi fun Ọlọrun ati lati ran awọn miran lọwọ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe ifẹ rẹ fun Oluwa ti di tutu.

Wayi o, ti ifẹ rẹ fun Oluwa ba ti da tutu nitoripe agbara iwa ika ti ni ipa lori rẹ, a jẹ wipe o wa labẹ ewu ki a gba ọ danu pẹlu awọn ika eniyan niyẹn. Ranti pe Oluwa sọ wipe kiki awọn ti o ba duro ṣinṣin de opin ni a o gbala (Matiu 24:13). Eyi tunmọ si pe awọn ti o jẹ onigbagbọ otitọ ninu rẹ ko ni fi igba kankan pa rinrin ninu ifẹ ati ododo rẹ ti. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn a duro ṣinṣin de opin, ti wọn a si ti ipasẹ eyi di ẹni igbala. Ṣugbọn awọn ti o pa rinrin ninu ododo ati ifẹ rẹ ti n fi han pe igbagbọ wọn ko fi igbakankan ri jẹ otitọ. Nitorina, dipo ki wọn ri igbala, nṣe ni wọn yoo ṣegbe.

Idi si niyi ti ọrọ Ọlọrun ṣe sọ wipe: “Nitori naa, ara ẹ tubọ maa ṣe aisinmi lati sọ ipe ati yiyan yin di dajudaju: nitori bi ẹyin ba n ṣe nnkan wọnyi, ẹyin ki yoo ṣubu. Nitori bayii ni a o pese fun yin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kirisiti.” (2Peteru 1:10-11) Njẹ o mọ itumọ eyi bi? Ni kukuru, o tunmọ si pe iṣẹ wa ni lati ma fi ojoojumọ fi idi rẹ mulẹ pe a ti di ẹni igbala nitootọ nipa diduro ṣinṣin ninu ifẹ Ọlọrun. Eyi ni yo jẹ ki a gba awa naa, bi a ti ṣe gba Stefanu, sinu ijọba ayeraye rẹ pẹlu ayẹsi ti o ga (Iṣe Apọsiteli 8:54-60).

Ṣugbọn ti a ba ti kọ igbe aye ti a pe wa lati gbe silẹ, a jẹ wipe asán, eyi ti ko ni gbe wa de ibikankan ni iṣẹ-isin yowu ti a ro wipe a n ṣe. Adura mi ni pe igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun ati ifẹ rẹ fun un ko ni jamọ oku ati alaiwulo ni oju rẹ nikẹyinkẹyin, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ifẹ rẹ ko ti da tutu bi? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 23, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 25 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:6-5

ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ | ỌJỌ́RÚ 26, ÒWÀRÀ 2022

ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:6-5

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri awọn nkan ti o pe akiyesi wọn si nipa bi wọn ti ṣe bẹrẹ irina-ajo wọn pẹlu Ọlọrun ninu Kirisiti ati awọn ọna ti wọn gba ṣe aṣiṣe. O si pe akiyesi wọn si awọn nkan wọnyi lati jẹ ki wọn mọ pe aiṣe amulo ọpọlọ ti Ọlọrun fun wọn lati ṣe agbeyẹwo awọn ẹkọ odi ti a mu tọ wọn wa ni o jẹ ki wọn pa Jesu ti lati tẹle ofin Mose. Gẹgẹ bi o ti se sọ fun wọn, niwọn igba ti Ọlọrun ko kọ lati sọ wọn di ẹda titun, lati fun wọn ni Ẹmi Mimọ rẹ ati lati ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu laarin wọn nitoripe wọn ko tẹle ofin Mose, o yẹ ki wọn mọ pe wọn ko nilo lati pa ofin yi mọ lati di ẹni idalare niwaju rẹ. O wa jẹ iyalẹnu pe ọpọ loni naa ni o n rin ni ipasẹ ijọ Galatia, ti awọn naa ko woye pe wọn ko nilo lati pa ofin Mose mọ lati di ẹni idalare niwaju Ọlọrun, niwọn igba ti ko ki i ṣe nipasẹ ofin yi ni Ọlọrun ṣe tun wọn bi. Ti awọn naa ko ba si fẹ kuna oore-ọfẹ Ọlọrun lẹkan si, wọn nilo lati fi ara balẹ ka awọn nkan ti Pọọlu kọ sinu lẹta yi si awọn ara Galatia, ki wọn si bẹrẹ si ni ṣe amulo wọn.

BÍ A TÍ ṢE Ń DI ẸNI ÌDÁLÁRE
Lati wa fi idi nkan ti o kọ awọn ara Galatia ninu lẹta yi mulẹ gidigidi, Pọọlu tẹsiwaju latii fi Aburahamu ṣe apẹẹrẹ bi eniyan ṣe n di ẹni idalare niwaju Ọlọrun fun wọn. Iwọ naa wo lara awọn nkan ti o sọ lori eyi:

“Gẹgẹ bi Aburahamu ti gba Ọlọrun gbọ, ti a si ka a si olododo eniyan. Bẹẹ ni, ki ẹyin ki o mọ pe, awọn tii ṣe tii igbagbọ, awọn naa ni i ṣe ọmọ Aburahamu. Bi iwe-mimọ si ti wi tẹlẹ pe, Ọlọrun yoo da awọn keferi lare nipa igbagbọ, Ọlọrun ti waasu iyinrere yii ṣaaju fun Aburahamu, pe, nipasẹ rẹ ni oun yoo bukun gbogbo eniyan. Gẹgẹ bẹẹ ni awọn ẹni ti o gbagbọ pẹlu jẹ alabakun-fun pẹlu Aburahamu olododo. Nitori pe iye awọn ti o gbẹkẹle iṣẹ ofin n bẹ labẹ egun: nitori ti a ti kọ ọ ninu iwe mimọ pe, Ọlọrun yoo fi ẹnikẹni ti ki i ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin bu. Nitori o damiloju pe, a ko da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa ṣiṣe gẹgẹ bi ofin nitori pe, olododo yoo ye nipa igbagbọ. Ofin ki i ṣi i ṣe ti igbagbọ ṣugbọn ẹni ti n ṣe wọn yoo ye nipasẹ wọn. Kirisiti ti ra wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹni ti a fi ṣe egun fun wa nitori ti a ti kọ ọ ninu iwe-mimọ pe, Ẹnikẹni ti a gbe kọ sori igi n bẹ labẹ egun Ọlọrun: Ki ibukun naa, eyi ti Ọlọrun ṣe ileri rẹ fun Aburahamu le jẹ ti awọn Keferi nipa Kirisiti Jesu; ki awa ki o le gba ileri Ẹmi nipa igbagbọ.” (Gàlátíà 3:6-14)

Ki ni awọn koko ti Pọọlu fẹ ki awọn ara Galatia ati awa naa pẹlu dimu pẹlu awọn nkan ti o sọ nibiyi? Akọkọ ni pe Aburahamu ti o jẹ baba nla awọn Juu, ti o si jẹ apẹẹrẹ ẹni idalare niwaju Ọlọrun di ẹni idalare niwaju rẹ nipa igbagbọ dipo nipa ofin tabi nipa iṣẹ rere rẹ. Bibeli sọ wipe, “Aburamu si gba Ọlọrun gbọ, a si ka a si ododo fun-un.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:6) Njẹ o ri bayi? Ko ki ṣe iṣẹ rere Aburahamu ni Ọlọrun wo lati tẹwọgba tabi lati ka si olododo tabi ẹni idalare niwaju rẹ. Lotitọ, Aburahamu ni awọn iṣẹ rere ti a le tọkasi tabi ti o le fọnnu nipa wọn. Amọ awọn eleyi ko jamọ nkankan niwaju Ọlọrun. Yatọ si eyi, Aburahamu naa tun ni awọn aiṣedede ati aiṣodo tirẹ, ti a tilẹ kọ sinu bibeli fun ẹkọ wa. Ti Ọlọrun ba wa ṣe idajọ rẹ lori awọn nkan wọnyi, ko ni i ka si olododo rara. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 12; Jẹ́nẹ́sísì 16; Jẹ́nẹ́sísì 20; Róòmù 4:1-3)

Amọ Ọlọrun ka Aburahamu si olododo. Ki si ni idi? Idi ni pe o gba ọrọ Ọlọrun gbọ. Nibakana, ẹnikẹni ti Ọlọrun yoo ba tẹwọgba gẹgẹ bi olododo tabi ka si ẹni idalare gbọdọ gba ọrọ rẹ gbọ lori igbala ọkan rẹ. Ki si ni ọrọ rẹ lori igbala ọkan wa? Ohun naa ni pe ki a gba Jesu ni Oluwa wa, a o si gba wa la, a o si tun sọ wa di ẹni itẹwọgba niwaju rẹ (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:29-31; Róòmù 10:9-10). Awọn ti o ba si wa ṣe bẹẹ gẹgẹ ni Pọọlu tọka si gẹgẹ bi ọmọ Aburahamu tootọ.

Koko ẹkọ keji ti Pọọlu n fi ye wa ninu awọn ẹsẹ bibeli yi ni pe nitori igbagbọ Aburahamu, Ọlọrun ba da majẹmu pe nipasẹ rẹ ni Oun O ti ṣe bukun fun gbogbo araye (Jẹ́nẹ́sìsì 12:1-3 &22:15-18). Eyi wa tunmọ si pe gbogbo awọn ti o ba jẹ ọmọ Aburahamu ni o jẹ ẹni ibukun ti Ọlọrun yoo lo lati ma bukun fun gbogbo awọn ti o ba wa ni ayika wọn. Ṣe eyi wa jasi pe gbogbo awọn Juu ti o jẹ arọmọdọmọ Aburahamu ni ọrọ yi n tọka si bi? Rara o!

Lotitọ, arọmọdọmọ Aburahamu ni awọn Juu jẹ. Awọn ni o si tọ si lati jẹ ere ileri Ọlọrun yi. Ṣugbọn ofin Mose ti a fun wọn ti ba nkan jẹ. Idi si ni pe ofin Mose fi wọn si abẹ egun, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa. Ofin Mose sọ gbangba-gbangba pe egun ni fun ẹnikẹni ti ko ba pa gbogbo nkan ti o wa ninu iwe ofin yi mọ (Ditarónómì 27:26). Niwọn igba ti ko si si ẹni naa ti o le pa gbogbo awọn nkan ti a kọ sinu iwe ofin Mose mọ, lalai yẹsẹ, a jẹ wipe gbogbo awọn ọmọ Isiraẹli ni o wa labẹ egun niyẹn.

Bawo wa ni awọn ọmọ Isiraẹli yoo ṣe wa wa labẹ egun ofin Mose ti Ọlọrun yoo si tun lo wọn lati bukun fun gbogbo araye? Ko ṣeeṣe. Ayafi ti a ba yọ wọn kuro labẹ egun yi nikan ni eyi yoo ṣe ṣeeṣe. Idi niyi, bi Pọọlu ṣe fi ye wa, ti a fi kan Jesu mọ agbelebu fun wa. Jesu, gẹgẹ bi ẹbọ fun ẹṣẹ gbogbo araye, le gba oniruuru ọna ku. Ṣugbọn iku ori igi agbelebu ni o ku. Awọn Juu gan funran wọn ni wọn sọ fun Pilatu pe nṣe ni ki o kan an mọ agbelebu. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun fẹ ki O di egun fun wọn, ki wọn ba le bọ kuro labẹ egun ofin Mose.

Ofin Mose sọ eyi fun wa nipa ẹnikẹni ti a ba gbe kọ sori igi: “Bi ọkunrin kan ti o jẹbi ẹsun ba ni lati ku ti o si ku, ti a si gbe oku rẹ kọ sara igi, o ko gbọdọ fi oku rẹ silẹ sara igi ni gbogbo oru. Gbiyanju lati sin in ni ọjọ naa gan an, nitori ẹni ti a ba gbekọ sori igi wa labẹ egun Ọlọrun. O ko gbọdọ ba ilẹ ti Oluwa Ọlọrun rẹ fun ọ gẹgẹ bi ogun jẹ.” (Ditarónómì 21:23) Ṣe o ri bayi? Nigba ti a kan Jesu mọ ori igi, ara nkan ti o ṣẹlẹ si ni pe o di egun fun gbogbo awọn Juu ti o wa ni abẹ egun ofin Mose. Eyi si ni o jẹ ki o ṣeeṣe fun Ọlọrun lati tu ibukun Ẹmi mimọ rẹ lẹyin iku, ajinde ati igbasoke rẹ sori awọn ti o gbagbọ, akọkọ awọn Juu ati lẹyin eyi awọn Keferi.

Nkan ti a n sọ ni pe, niwọn igba ti Ọlọrun ko i ti mu egun ofin Mose kuro lori awọn ọmọ Isiraẹli, ko le tipasẹ wọn bukun fun ẹnikẹni laye yi. Ṣugbọn ni kete ti O mu egun yi kuro nipa iku Jesu lori igi agbelebu, a ri wipe O tu Ẹmi mimọ rẹ sori awọn Juu ti o jẹ ọmọlẹyin Jesu. Lati igba naa lọ si ni o ti bẹrẹ si ni ti ipasẹ wọn bukun fun awọn Keferi ti o ba gbọgbọ nipa fifun wọn ni ẹbun ọfẹ Ẹmi mimọ rẹ lati tun wọn da ati lati ma gbe inu wọn titi lailai. Gbogbo awọn ti o si wa tipasẹ eyi di alabukunfun naa ni o wa ni ipo ẹni ti Ọlọrun le lo lati bukun fun awọn yowu ti o ba wa ni ayika wọn ti wọn ba gbagbọ.

Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, ko wa yẹ ki a ri Kirisitiẹni kankan, yala Juu ni tabi Keferi, ti yoo tun mura tan lati fi ara rẹ si abẹ egun ofin Mose. Amọ o ṣeni laanu pe ailoye nkan wọnyi ti jẹ ki ọpọ fi ara wọn si abẹ egun ti Ọlọrun ko fi wọn si, ti wọn si wa fi aye silẹ fun Satani lati ma pọn wọn loju ati lati jẹ ki o ṣoro fun wọn lati gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun. Boya iwọ na tilẹ wa lara awọn ti o fi ara wọn si abẹ egun ofin Mose nipa fifẹ pa awọn abala ofin yi kan mọ. Aṣiṣẹ nla gba ni eyi jẹ nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe amulo ofin Mose gbọdọ ṣe amulo gbogbo rẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni yoo fi ara rẹ si abẹ egun ofin naa, ti ko si ni wulo fun Ọlọrun lati lo lati mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Nitorina, yọ ara rẹ kuro labẹ egun ti Ọlọrun ko fi ọ si, ki o si jẹ ki igbagbọ rẹ ninu Jesu ati iku, ajinde ati igbasoke rẹ to fun ọ.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Igbagbọ ninu Ọlọrun ati ọrọ rẹ nikan ni o le sọ wa di ẹni igbala ati idalare niwaju rẹ. Ọna ti Aburahamu gba di ẹni idalare ni eyi. Ọna yi kanna si ni gbogbo awọn ti o ba gbagbọ ninu Ọlọrun ati ninu ọmọ rẹ Jesu Kirisiti, ẹni ti o ku fun ẹṣẹ wa, yoo ṣe gba di ẹni igbala ati idalare, gẹgẹ bi Aburahamu. Kirisitiẹni ti o ba wa kọ ọna yi silẹ lati tẹlẹ ofin Mose n fi ara rẹ si abẹ egun ofin yi ni, egun ti Jesu ti ku lati mu kuro lori awọn Juu ti a gbe ofin yi le lọwọ. O si di dandan ki iru ẹnibẹ ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Ọlọrun, ki o si di iṣẹ Ẹmi mimọ ninu ati lori aye rẹ lati sọ di ẹni ti Ọlọrun fẹ ki o jẹ lọwọ.

ÌBÉÈRÈ

  • Bawo ni ẹkọ yi ṣe wulo si fun awọn ọmọ Ọlọrun loni ti oye iha ti o yẹ ki wọn kọ si ofin Mose ko ye?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:6-5 Read More »

Ǹjẹ́ o wúlò fún wọn bí? | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 16, 2022 | Vol. 11, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki o pọ si ni iwulo fun un ati fun awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu lẹta Pọọlu keji si Timoti, o sọ eyi fun un nipa Johanu Maaku: “…mu Maaku wa pẹlu rẹ: nitori o wulo fun iṣẹ-iransẹ.” (2Timoti 4:11) Ṣugbọn igba kan wa ti Pọọlu ko fẹ mu Maaku kanna yi lati rin irinajo kankan pẹlu rẹ ni ṣiṣe ojuṣẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ. Idi si ni pe o ti fi igba kan ri kọ oun ati Banaba silẹ ni akoko ti wọn nilo rẹ gidigidi. Nitorina, Pọọu ri bi ẹni ti ko wulo fun un ninu iṣẹ iranṣẹ. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 13:13; Ìṣe Àpọ́sítélì 15:36-41)

Ṣugbọn Maaku ko duro sojukan gẹgẹ bi ẹni ti ko wulo fun Ọlọrun tabi fun awọn iransẹ rẹ titi lailai. Oun naa dagba soke si ninu nkan ti ẹmi. Nigba ti o to asiko kan, oun naa ṣe idamọ awọn iwa ati aṣa ti o n mu ki o jẹ alaiwulo fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ, o si mojuto wọn nipasẹ agbara Ẹmi Ọlọrun. Nitorina, lẹyin ọdun melokan si, Pọọlu sọ fun Timoti pe o jẹ dandan fun lati wa Maaku, ki o si mu wa si ọdọ oun, nitori ti o wulo fun ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ.

A tun ri ọdọmọkunrin kan ninu bibeli ti itan tirẹ naa fẹ fi ara pẹ eyi. Oun naa ti fi igba kan ri jẹ alaiwulo fun olowo rẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe ‘Mowúlò’ ni itunmọ orukọ rẹ. O wa jẹ ẹnikan ti ko wulo, ti ko si ni nkan ṣe to bẹẹ gẹẹ ti o fi sa kuro ni ọdọ oluwa rẹ. Ṣugbọn nigba ti o pade Pọọlu, o di atunbi. Lati igba yi lọ wa ni aye rẹ ti bẹrẹ si ni gba ọna ara ọtọ, ti o si bẹrẹ si ni gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu orukọ rẹ, ‘mowúlò’. O wa wulo to bẹẹ gẹẹ fun Pọọlu ti o fi gbero lọkan rẹ lati jẹ ki o wa pẹlu oun titi lailai. Ṣugbọn nitoripe o fẹ ki olowo rẹ ri bi Ọlọrun ti ṣe yi aye rẹ pada, ki o dárí gbogbo nkan buburu ti o ti ṣe si ji i, ki o si tun gbadun iwulo rẹ, o ran an pada lọ si ọdọ rẹ. Ọrọ ẹni ti mo si n ṣọ ko ju ti Onesimu, iranṣẹ Filemoni, lọ. (Filemoni 1)

A wa ri aridaju bayi pe Ọlọrun ni agbara lati sọ awọn ti ko wulo di ẹni ti o wulo ati awọn alainikanṣe eniyan di ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ, ti wọn ba fi aye wọn jin fun. O si fẹ sọ iwọ naa di ẹni ti o wulo ati ẹni ti o mọ ojuṣe rẹ ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ. Ṣugbọn ṣe iwọ funrarẹ fẹ wulo, ki o si jẹ ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ si Ọlọrun ati ninu gbogbo awọn ibaṣepọ rẹ? Ayafi ti o ba ṣetan lati wulo siwaju ati siwaju si, o ni oju nkan ti Ọlọrun le ṣe fun ọ. Awọn ti wọn ba ṣetan lati wulo nikan ni Ọlọrun le ṣe yẹ lati le ṣe awọn nkan ti o tọ fun wọn lati ṣe lati jẹ ẹni ti o wulo ninu aye wọn ati ti o n fi igba gbogbo pọ si ni iwulo. 

Ni kukuru, gẹgẹ bi Pọọlu, awọn adari ijọ Ọlọrun kọọkan naa nilo awọn eniyan ti o wulo lati ran wọn lọwọ ninu iṣẹ iranṣẹ wọn ati lati jẹ ki iṣẹ wọn ma tẹsiwaju. Wọn nilo awọn ti wọn le gbe ara le lati ran wọn lọwọ pẹlu asiko wọn, ẹbun ẹmi wọn, owo wọn, amuyẹ wọn ati ohunkohun ti wọn ba ni. Ṣe o wa jẹ ọkan lara awọn wọnyi bi? Ṣe o wulo fun awọn adari ijọ rẹ ni ọna kankan? Ti wọn ba n ronu nipa awọn ti wọn le gbe ara le lati ṣe awọn iṣẹ kan, ṣe orukọ rẹ yo tilẹ wa si wọn lọkan bi? Ti eyi ko ba ri bẹ, a jẹ wipe o ko wulo fun wọn niyẹn. Ti o ko ba si wulo fun awọn adari ijọ rẹ, afaimọ ki o ma jẹ wipe o ko wulo fun Ọlọrun ti O yan wọn le ọ lori naa pẹlu.

Ṣe o wa fẹ duro si ipo ẹni ti ko wulo fun wọn ni tabi o fẹ di ẹni ti o wulo? Eyi jẹ ibere ti o nilo lati dahun bi o ti ṣe doju kọ ọsẹ tuntun yi. O si wa kọja ki o ma bere lọwọ wọn, “Ọna wo ni mo le gba wulo fun yin?” O tun ni i ṣe pẹlu ki o fi awọn ọna ti o le gba wulo fun wọn han wọn pẹlu iṣe rẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun dari rẹ kuro ninu ohun gbogbo ti o n ṣe ọ ni alaiwulo fun un ati fun awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ eleso rere.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ǹjẹ́ o wúlò fún wọn bí? | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 16, 2022 | Vol. 11, No. 24 Read More »

Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́ láìsi mọ nkànkan | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 09, 2022 | Vol. 11, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ọwara 2022. Mo gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun lo ọrọ rẹ ti o n tọ ọ wa ninu ijọ yi lati fọ wọn danu kuro ninu aye rẹ ohun gbogbo ti o n di isesorere rẹ lọwọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si Timoti, sọ eyi nipa awọn kan ninu ijọ ti ko gbọdọ ni nkankan ba ṣe pọ: “Nitori ninu iru eyi ni awọn ti n rako wọ inu ile, ti wọn si n di awọn obinrin alailọgbọn ti a di ẹṣẹ ru ni igbekun, ti a si n fi oniruuru ifẹkufẹẹ fa kiri. Wọn n fi igba gbogbo kẹkọọ, wọn ko si le de oju imọ otitọ.” (2Timoti 3:6-7) Pẹlu nkan ti apọsiteli yi sọ nibiyi, a ri wipe ọkan lara awọn idi ti o fi sọ fun Timoti lati ma ni nkankan ba awọn ara wọnyi ṣe pọ ni pe ọga ni wọn ninu ki a ma jẹ awọn eniyan mọlẹ, paapaa julọ awọn obinrin, ati ki a ma tan wọn jẹ.

Ki wa ni o jẹ ki o ma fi ọpọ igba rọrun fun wọn lati tan awọn eniyan jẹ ati lati tun gba akoso aye wọn? Idi ni pe awọn ti o n fi igba gbogbo kẹkọọ ṣugbọn ti imọ otitọ ko wọle si lori ni wọn ma n ṣaba lọ fun. Eyi tunmọ si pe wọn ki fojusun gbogbo eniyan. Dipo eyi, awọn ti wọn lọra lati ni oye otitọ nkan ti ẹmi ati lati mu wọn lo ni wọn ma n fojusun.

Mo gbọ ni igbakan pe wolii kan ni aṣa ki o ma ba awọn abilekọ ti o ba wa sọdọ rẹ fun adura nipa iṣoro aye wọn sun. Ki lo fa ti ọkunrin yi fi n ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe eyi? Idi naa ni pe awọn ti o n lugbadi rẹ gba igbakugba. Ki lo si fa ti wọn fi gba igbakugba? Idi naa ni pe wọn kọ lati tẹwọgba otitọ Ọlọrun ti wọn n kọ. 

Ṣe wọn ko mọ ifẹ Ọlọrun lori agbere ni? A bi ṣe ko si ẹnikẹni ti o fi igba kankan kọ wọn pe nini ibaṣepọ pẹlu ẹni ti eniyan ko fẹ kọ tọna ni? A ti gbọdọ kọ wọn ni awọn nkan wọnyi lera-lera, paapaa julọ ti wọn ba jẹ Kirisitiẹni. Ṣugbọn ọtọ ni ki awọn eniyan ma kọ otitọ lati ọdọ Ọlọrun; ọtọ si tun ni ki otitọ ti wọn n kọ ye wọn, ki wọn si mọ ibi ti o ti ba aye ti wọn n gbe lojoojumọ mu. 

Ti awọn eniyan ba kọ lati ni oye iwulo otitọ ti wọn n kọ ninu ijọ, o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe amulo rẹ. Irufẹ awọn wọnyi si ni wọn ma n di eran ijẹ fun awọn eke olukọ ati eke wolii. Iru awọn eniyan yi ni wọn ma n tete ṣubu sinu ẹtan Eṣu, ti wọn a si fi idibajẹ ṣinu aye wọn, rẹ wọn jẹ tabi ṣe wọn ni ijamba.

Iwọ naa wa bere lọwọ ara rẹ, “Njẹ mo n kọ nkankan bi lati ara awọn nkan ti a n kọ mi ninu awọn ipade ijọ wa?” O n wa lọsọọsẹ fun ipade ijọ lati gbadura, lati sin Ọlọrun ati lati kọ ọrọ rẹ. Ṣugbọn ṣe o n kọ nkankan bi? Ṣe o n ni imọ-kun-imọ ninu otitọ Jesu nipasẹ awọn nkan ti o n kọ? Ṣe o si n ri bi o ti yẹ ki o ṣe amulo awọn otitọ ti o n kọ yi ninu aye re?

Ti idahun rẹ si awọn ibere yi ko ba ki i ṣe ‘Bẹẹni’, a jẹ wipe ọkan lara awọn ti o ma n fi gbogbo igba kẹkọọ ṣugbọn ti imọ otitọ ko ki wọ ọkan wọn ni o jẹ niyẹn. Nitorina, a ko le ni igbekele ninu rẹ lati ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun ti o n kọ. Bẹẹ si ni  adura wa le ma le daabo bo ọ kuro lọwọ awọn ti o n lepa lati yan ọ jẹ ati lati pa aye rẹ run. Adura mi fun ọ wa ni pe ki Ọlọrun ma kun ọkan rẹ pẹlu oye ọrọ rẹ ti o peye ni igbakigba ti o ba ti gbọ ọrọ naa, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣiṣẹ tọ ọrọ ti o ba gbọ, ki o ma ba tun ṣe fi igba kankan jẹ ẹran ijẹ fun awọn opurọ tabi ẹlẹtan yowu ti Satani le ran lati ba aye rẹ jẹ mọ, ni orukọ Jesu. Amin. 

Ki o ni ọsẹ atata.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́ láìsi mọ nkànkan | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 09, 2022 | Vol. 11, No. 23 Read More »

Máṣe fà ṣẹ́yìn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 25, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia lalai lodiwọn jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Alabakunfun Olurapada wa. Mo ki ọ kaabọ pẹlu ayọ sinu oṣu Ọwara 2022. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi ojoojumọ oṣu naa gba okun lati sin Ọlọrun tọkantọkan, ki o ba le fi ẹsẹ mulẹ ni ibi ipese rẹ fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara ẹkọ ti itan Ọba Sọọlu ti o wa ninu bibeli kọ wa ni pe fifasẹyin tabi riroju lati ṣe ifẹ Ọlọrun ni ẹkunrẹrẹ ko yatọ rara ni buburu si aigbọran patapata si aṣẹ rẹ. Eyi ṣi le jẹ ki a sọ aye wa nu ninu eto rẹ. Bi itan naa ti ṣe lọ, Ọlọrun, nipasẹ Samuẹli, pa aṣẹ taarataara pe ki Ọba Sọọlu lọ kọlu awọn ara Amaleki, ki o si pa awọn ati awọn nkan ini wọn run patapata. Ṣe o wa lọ tabi ko lọ? O kuku lọ. O lọ lati ba awọn ara Amaleki ja ati lati pa awọn ati gbogbo nkan ini wọn run.

Amọ ṣa, nigba ti o de ibẹ, o kuna lati pa aṣẹ Ọlọrun mọ ni ẹkunrẹrẹ. Iwọ naa wo bi bibeli ṣe ṣe alaye ọrọ naa: “Sọọlu si kọlu Amaleki lati Hafila titi de Ṣuri, ti o wa ni apa keji Ijibiti. O si mu Agagi Ọba Amaleki laaye, o si fi oju ida run gbogbo awọn eniyan naa. Ṣugbọn Sọọlu ati awọn eniyan naa da Agagi si ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu maalu, ati ohun eyi ti o dara tobẹẹ ninu wọn, ati ọdọ agutan abọpa, ati gbogbo nnkan ti o dara; wọn ko si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nnkan ti ko dara ti koo si nilaari ni wọn parun patapata.” (1Samuẹli 15:7-9)

Njẹ o ri bayi? Ṣọọlu ati awọn jagunjagun rẹ fa ṣeyin lati pa gbogbo awọn ẹran ọsin awọn ara Amaleki run nitori ojukokoro. Lotitọ, wọn pa gbogbo awọn eniyan yi ati gbogbo awọn ẹran ọsin wọn ti ko nilari ati ti o ya abirun run. Ṣugbọn wọn ko ṣetan lati pa awọn ẹran ọsin wọn ti o dara julọ run. Bawo si ni Ọlọrun ṣe da ẹjọ eyi? O da gẹgẹ bi ẹjọ aigbọran patapata ati iṣọtẹ si i. Nitorina, O gba ijọba Sọọlu kuro lọwọ rẹ ati kuro lọwọ awọn arọmọdọmọ rẹ, O si fi le ẹlomiran lọwọ.

Nibakanna, ti awa naa ba n fa sẹyin lati ṣe ifẹ Ọlọrun de oju oṣuwọn ni abala aye wa kan tabi omiran, O le ri gẹgẹ bi aigbọran si ni gbogbo ọna. Eyi tunmọ si pe aigbọran diẹ si Ọlọrun ko yatọ rara si aigbọran patapata si i. Eyi si le jẹ ki a padanu awọn ààyè tabi igbega kan ti O ti ya sọtọ silẹ fun wọn. Nitorina, ti a ba ri abale aye rẹ kankan ninu eyi ti o ti n fa ṣẹyin tabi lọra lati ṣe ifẹ Ọlọrun fun ọ, nṣe ni ki o tun ọna rẹ ṣe, ki o si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ ki o to pẹ ju.

Gẹgẹ bi ẹnikan, mo mọ itunmọ ki eniyan mọ nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe, sibẹsibẹ ki o ma fẹ lati ṣe e. O le jẹ nitori awọn igbadun ranpẹ ti o n jẹ nipasẹ lilodi si ifẹ Ọlọrun ni tabi nitori ibẹru awọn eniyan tabi nitori ifẹ oriyin awọn eniyan. Ohun yowu ti idi naa le jẹ, fifasẹyin lati ṣe ifẹ Ọlọrun di dandan ki o ko wa sinu iyọnu lẹyin-ọ-rẹyin.

Jesu Oluwa, ninu lẹta rẹ si ijọ Tiatira, sọ eyi nipa ọkan lara awọn obinrin wọn: “Emi si fun un ni akoko ti o to lati ronupiwada; ko si fẹ ronupiwada kuro ninu agbere rẹ. Kiyesi i, Emi o gbe e sọ sori ibusun aisan, ati awọn ti n ṣe pansaga pẹlu rẹ ni Emi o fi sinu ipọnju nla, bi ko ṣe pe wọn ba ronupiwada kuro ninu agbere wọn pẹlu rẹ. Emi o si pa awọn ọmọ rẹ; gbogbo ijọ ni yoo si mọ pe, Emi ni ẹni ti n wadii inu ati ọkan: Emi o si fifun olukuluku yin gẹgẹ bi iṣẹ yin.” (Ifihan 2:21-23) Njẹ o ri bayẹn? Oluwa fẹ fi iya jẹ arabinrin yi ati awọn ti o n rin nipa ọna agbere ati ibọriṣa rẹ pẹlu aisan ati iku. Ki ni idi? Idi ni pe oun fa sẹyin lati ronupiwada, ki o si ṣe ifẹ rẹ.

Nitorina, ko si ẹni ti o le sọ pato ọna ti Oluwa yoo gba ṣe idajọ fifasẹyin lati ṣe ifẹ rẹ ni abala aye wa yowu ti a ba ti fa sẹyin lati ṣe ifẹ rẹ. Boya O tilẹ ti n ṣe idajọ wa fun fifasẹyin wa lati fi tọkantọkan ṣe ifẹ rẹ ni awọn abala aye wa kan. A le ma mọ eleyi titi lailai, ti ko ba jẹ wipe O fi ohun ti O n ṣe han wa. Ṣugbọn yala a mọ tabi a ko mọ, ohun ti o ṣe pataki ni pe kí á má fi àkókò ṣòfò rara lati ṣe ohun ti O fẹ ki a ṣe ni gbogbo abala aye wa. Aijẹbẹ, nkan le bajẹ si fun wa ju bi wọn ti ṣe wa yi lọ. Mo wa gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ ni ibi yowu ti o ba ti n fa ṣẹyin lati ṣe ifẹ rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ ki o to pẹ ju. Amin.

Ki o ni oṣu Ọwara 2022 ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Máṣe fà ṣẹ́yìn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 25, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 22 Read More »

ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 28, ÒWEWÉ 2022 ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (ÌJỌ ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ) ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 28, ÒWEWÉ 2022 ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ

ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 2:1-10

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri awọn nkan ti a le pe ni ẹri igbala apọsiteli yi. Gẹgẹ bi o ti ṣe fi ye wa, oun tikararẹ ti fi igbakanri gbogun ti awọn ọmọ Ọlọrun ati iyinrere Jesu nitori itara rẹ fun ẹsin awọn Juu ati ofin Mose. Ti oun yi kanna, ti o ti kọkọ fi gbogbo okun ati agbara gbiyanju lati pa iyinrere Jesu run, ba wa n lọ kaakiri lati polongo iyinrere ti o ti fi igbakanri tiraka lati parun, o yẹ ki a mọ pe o gbọdọ ni idi. Idi naa si ni pe o ti ba Jesu pade, o si ti di ẹni igbala. Iyinrere ti Jesu si wa gbe le lọwọ ni o n waasu kaakiri ibi gbogbo ti o ba lọ. Iyinrere yi naa ni o waasu si awọn ara Galatia ti wọn fi di ẹni igbala. Ṣugbọn, bi o ti jẹ ki o ye wa ninu lẹta rẹ yi si wọn, awọn Juu kan ti wa sọdọ wọn, wọn si ti bu ẹnu atẹ lu iyinrere otitọ ti wọn tẹwọgba, ti o si sọ wọn di ẹni igbala ati olododo niwaju Ọlọrun. Awọn yi n jẹ ki o ye wọn pe ayafi ti wọn ba pa awọn abala ofin Mose kan mọ, paapaa julọ eyi ti o n sọrọ nipa ikọla abẹ, wọn ko ni di ẹni igbala, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ti gba Jesu gbọ. Eyi ni o fa ti Pọọlu fi kọ lẹta yi si wọn, ki o ba le pe wọn pada sọdọ Jesu, ẹni ti o gba wọn la.

ÌFÌDÍMÚLẸ̀ ÌYÌNRERE ÒTÍTỌ́ Ki Pọọlu ba wa le fi idi otitọ iyinrere ti o n waasu mulẹ fun awọn ara Galatia yi, o tẹsiwaju ninu lẹta yi lati jẹ ki wọn mọ lara awọn igbesẹ ti o ti gbe sẹyin lori rẹ. Irufẹ igbesẹ wo ni o gbe? O fi akoko kan ṣe ipade pẹlu awọn ti o ti jẹ apọsiteli ṣiwaju rẹ, ti wọn si jẹ opomulero laarin awọn apọsiteli yoku lati fi iyinrere ti o n waasu laarin awọn Keferi han wọn. Ki wa ni idi ti o fi ṣe eyi? Ṣe ẹru n ba pe iyinrere ti o n waasu ko dangajia to ni, ti o si nilo alaye ti o peye si i lati ọdọ wọn? A bi ṣe o fẹ oriyin lati ọdọ wọn ni? Bi o ti ṣe fi han wa ninu lẹta yi, ko ki i ṣe nitori pe ẹru n ba tabi nitori ki wọn ba le gbe oriyin fun ni o ṣe tẹ́ koko iyinrere ti o n waasu siwaju wọn. Idi mẹta pataki ni o ṣe ṣe eyi, bi a ti ri ninu awọn ọrọ wọnyi:

“Lẹyin ọdun mẹrinla, nigba naa ni mo tun lọ si ilu Jerusalẹmu pẹlu Banaba, mo si mu Titu lọ pẹlu mi. Mo si lọ nitori ohun ti Ọlọrun fi han mi, mo si fi iyinrere naa ti mo n waasu laarin awọn Keferi ye awọn ti o jẹ ẹni nla ninu wọn, ẹyiini ni ikọkọ, ki emi ma baa sare, tabi ki o ma baa jẹ pe mo ti sare lasan. Ṣugbọn a ko fi agbara mu Titu ti o wa pẹlu mi, ẹni ti i ṣe ara Heleni, lati kọla: Ati nitori awọn eke arakunrin ti wọn yọ wọ aarin wa gẹgẹ bi amí lati mọ eredi ominira eyi ti a ni ninu Kirisiti Jesu, ki wọn ki o le mu wa wa sinu ide ilana ẹsin Juu. Awọn ẹni ti a ko fun ni anfaani lati gbọ ọrọ wọn fun iṣẹju kan; ki ẹyin o le maa tẹ siwaju ninu otitọ iyinrere naa. Ṣugbọn ni ti awọn ti wọn dabi ẹni-nla, ohunkohun ti o wu ki wọn jẹ, ko jẹ nnkan kan fun mi: Ọlọrun kii ṣe ojusaaju ẹnikẹni: ani awọn ti o dabi ẹni-nla naa, ko kọ mi ni nkankan.” (Gàlátíà 2:1-6)

Pẹlu akọsilẹ Pọọlu yi, a ri pe idi akọkọ ti o ṣe lọ ṣe ipade ikọkọ pẹlu awọn ti o jẹ bi opomulero laarin awọn ti o jẹ apọsiteli saaju rẹ ni pe Ọlọrun kọ si lati ṣe bẹẹ. O sọ wipe oun lọ ni ibamu pẹlu ifihan ti Ọlọrun fun oun. Ki wa lo le fa a ti Ọlọrun fi sọ fun apọsiteli yi lati la ṣe ipade pẹlu awọn apọsiteli Oluwa miran, ki o si tẹ iyinrere ti o n waasu kaakiri kalẹ fun wọn lati ṣe agbeyẹwo rẹ? Nkan kan ti o le fa ni pe Ọlọrun fẹ ki wọn wa ni iṣọkan; Ọlọrun fẹ ki gbogbo wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ọkan ninu Kirisiti. Niwọn igba ti o jẹ wipe Jesu Kirisiti kan naa ni wọn jọ gbagbọ fun igbala ẹmi wọn, ti o si tun jẹ wipe iyinrere rẹ kan naa ni wọn dijọ n polongo, ko si nkan naa ti o ni ki wọn ma wa ni irẹpọ.

Yatọ si eyi, ko si iyapa ninu Kirisiti. Ara kan naa ni gbogbo awọn ti o gbagbọ ninu rẹ. Nitori naa, bi awa ti a gbagbọ ninu rẹ ko tilẹ si ni ilu kan naa tabi ki a dijọ ma jọsin papọ, eyi ko tunmọ si pe iyapa wa laarin wa tabi pe a ko ki i ṣe ara kan naa mọ. A wa gbọdọ jẹ ki eyi ki o ye wa daradara, ki a si ma sọ ara wa di ọta awọn ọmọ Ọlọrun miran nitori pe wọn ko jọsin pẹlu wa tabi nitori pe wọn ko tẹle awọn adari kan ti awa n tẹle. (Wo: 1Kọrinnti 3 & 12)

Idi keji ti Pọọlu tun ṣe lọ ni wipe oun funrarẹ fẹ ri aridaju pe iyinrere ti o n waasu kaakiri ko yatọ tabi lodi si eyi ti awọn ti o ti di apọsiteli Oluwa ṣaaju rẹ n waasu. Bi o ti ṣe fi ye wa ninu abala lẹta yi ti a n gbe yẹwo ati eyi ti a ti gbe yẹwo sẹyin, ko si ẹnikẹni ti o kọ ni iyinrere ti o n waasu; Jesu funrarẹ ni O fun ni ifihan iyinrere yi, ti O si tun kọ ọ ni awọn nkan ti o n ṣe, ti o si n sọ. Nitorina, o mọ daju-ṣaka pe iyinrere otitọ ni o n waasu. Amọ ẹru tun n ba ni ọna kan pe ti awọn ti o jẹ apọsiteli ṣaaju rẹ ba ti lọ pa iyinrere ti Jesu gbe le wọn lọwọ ti ṣegbẹ kan, ti wọn si n waasu adamọdi iyinrere rẹ, o ṣeeṣe ki laala rẹ laarin awọn Keferi ja si asan. Idi si ni wipe yoo rọrun fun awọn eniyan lati gba awọn ti o jẹ apọsiteli Oluwa saaju rẹ gbọ ju lọ. Eyi si le jẹ ki gbogbo iṣẹ ti o ti ṣe silẹ parun, bi o tilẹ jẹ wipe o ṣe awọn iṣẹ yi lori otitọ Jesu. Nibakan naa, o yẹ ki awa na kọbiara si ohunkohun ti o le pa iṣẹ iranṣẹ wa lara, ki a si mojuto. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a ṣe laala lasan ninu ijọba Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe ori ododo ni iṣẹ ti a n ṣe da le.

Idi kẹta ti Pọọlu ṣe tun ṣe ipade pẹlu awọn apọsiteli yi ni lati fi opin si gbogbo awuyewuye awọn Juu ti wọn n lọ sọdọ awọn Keferi ti o gba Jesu gbọ, ti wọn si n gbiyanju lati fi wọn si abẹ ide ilana ẹsin awọn Juu (Iṣe Apọsiteli 15:1-34). Nkan ti o wa lọkan rẹ si ni pe ki o fi idi rẹ mulẹ pe awọn apọsiteli Jesu yoku ko lọwọ si fifi awọn Keferi ti o gbagbọ si abẹ ilana ẹsin awọn Juu, bi o tilẹ jẹ wipe Juu ni awọn naa. Niwọn igba ti o ba si ti fi idi eyi mulẹ, awọn Keferi ti o gbagbọ yoo le mu iduro wọn ninu Jesu ṣinṣin, wọn ko si ni gba ibọde awọn Juu yi ti o n tiraka lati sọ iyinrere Jesu di alailagbara. Eyi si jẹ ki o ye wa pe iduro-ṣinṣin awọn ti o gbagbọ ninu Jesu jẹ Pọọlu logun gidigidi. Idi si ni yi ti ko fi fi akoko kankan fi aye gba awọn ti o gbiyanju lati fi ẹnu tẹnbẹlu tito Jesu fun igbala awọn eniyan ati fun itẹwọgba wa niwaju Ọlọrun.

Wayi o, bawo wa ni ipade Pọọlu pẹlu awọn apọsiteli ti o pade yi ṣe lọ? Didun ni ọsan ipade naa so, gẹgẹ bi akọsilẹ rẹ. Akọkọ, o jẹ ki o ye wa pe bi o tilẹ jẹ wipe oun mu Titu lọwọ, ẹni ti o jẹ Keferi ti o gbagbọ, awọn apọsiteli yi, Jemiisi, Peteru ati Johanu, ko fi tipa-tipa mu un lati kọ ila abẹ. Eyi si n fi han pe awọn kọ ni o ran awọn Juu ti o n lọ kaakiri lati sọ wipe awọn Keferi ti o gbagbọ gbọdọ kọ ila abẹ, ni ibamu pẹlu ofin Mose, ki wọn to di ẹni igbala.

Siwaju si, o tun sọ eyi nipa ipade naa: “Ṣugbọn kaka bẹẹ, nigba ti wọn rii pe Ọlọrun ti fi iṣẹ iyinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi iṣẹ iyinrere ti awọn ikọla le Peteru lọwọ. Nitori Ọlọrun, ẹni ti o ṣiṣẹ ninu iṣẹ iranṣẹ Peteru gẹgẹ bi Apọsiteli si awọn Juu, oun kan naa ni o ṣiṣẹ ninu iṣẹ iranṣẹ mi gẹgẹ bi Apọsiteli si awọn alaikọla. Jakọbu, Peteru ati Johanu, awọn ẹni ti o dabi ọwọn, fun emi ati Banaba ni ọwọ ọtun idapọ nigba ti wọn ri oore-ọfẹ ti a fi fun mi, wọn si gba pe ki awa naa tọ awọn alaikọla lọ, nigba ti awọn naa lọ sọdọ awọn Juu. Ohun gbogbo ti wọn beere fun ni wi pe ki a maa ranti awọn talaka, ohun kan naa gan-an ti mo n lakaka lati ṣe.” (Galatia 2:7-10)

Pẹlu nkan ti o sọ yi, daju-ṣaka ni pe awọn apọsiteli yi ti Pọọlu pẹlu Banaba ba ṣe ipade tẹwọgba wọn tọwọ-tẹsẹ. Nigba ti wọn gbọ iyinrere ti Pọọlu waasu, wọn ri wipe ko yatọ rara si nkan ti Jesu gbe le wọn lọwọ. O tilẹ gbọdọ ya wọn lẹnu pe ọkunrin yi ti ko wa pẹlu wọn nigba ti Jesu wa ninu aye yi mọ gbogbo nkan ti awọn mọ, titi kan nkan ti o ṣẹlẹ ni alẹ ọjọ ti a mu Jesu, ti a si kan mọ agbelebu. Ni kukuru, wọn fi tayọtayọ gba Pọọlu gẹgẹ bi apọsiteli Oluwa ti a ran si awọn Keferi. Wọn si gba oun ati Banaba ni iyanju lati tẹramọṣẹ ati lati maa ranti awọn alaini ni ibi gbogbo ti wọn ba lọ.

Nitorina, iyinrere Pọọlu ko yatọ rara si iyinrere awọn apọsiteli Jesu yoku. Peteru tilẹ sọ eyi lati kin ọrọ Pọọlu lẹyin ninu lẹta rẹ keji, ori ikẹta, lati ẹsẹ ikarundinlogun: “Ki ẹ si maa ka a si pe, suuru Oluwa wa igbala ni; bi Pọọlu pẹlu arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si yin gẹgẹ bi ọgbọn ti a fi fun un. Bi o ti n sọrọ nnkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ gbogbo ninu eyi ti ohun miiran ṣoro lati ye ni gbe wa, eyi ti awọn ope ati awọn alaiduro nibikan ń lọ́, bi wọn ti n lọ iwe-mimọ iyoku , si iparun ara wọn.” (2Peteru 3:15-16)

Njẹ o ri bayi pe awọn apọsiteli yoku gba Pọọlu gẹgẹ bi apọsiteli otitọ, wọn si tun gba ọrọ rẹ gẹgẹ bi otitọ ọrọ Ọlọrun. Ti a ba ri ẹnikẹni loni, bi a ti ri ni igba aye Pọọlu, ti o sọ pe ti Pọọlu bawo, a jẹ wipe ope ni ẹni naa, gẹgẹ bi ọrọ Peteru. O ṣi wa ṣeni laanu pe a ri irufẹ awọn wọnyi kaakiri inu awọn ijọ wa loni, ti wọn ro wipe ọrọ Pọọlu tako ọrọ Jesu ati ọrọ awọn apọsiteli yoku. Eṣu ni o si n ya awọn wọnyi lo lati di iyinrere Jesu lọwọ ati lati fi awọn ọmọ Ọlọrun si abẹ igbekun ẹsin awọn Juu ati awọn nkan miran ti o fara pẹ ẹ. A ko wa gbọdọ fi aye gba wọn lati fiwa tabi lati fi awọn ọmọ Ọlọrun miran ti a jọ n ṣepọ sinu ide wọn.

ỌRỌ IPARI Pọọlu tiraka, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, lati fi idi rẹ mulẹ nigba ti o wa laye pe oun ati awọn apọsiteli Jesu yoku ko tako ara wọn lọna kankan lori iyinrere Jesu ati igbagbọ ninu rẹ. Awa naa wa gbọdọ ri daju pe igbagbọ wa, iwaasu wa ati iṣẹ iṣin wa, bi o ti wu ki o dawa loju to, ko tako tabi yatọ si nkan ti awọn apọsiteli yi gbe kalẹ fun wa lọna kankan. Aijẹbẹ, a ti rin jin na si Jesu. Ti a ko ba si ṣọra, ki a si pada ni kiakia sọdọ rẹ, ere ije igbagbọ wa di dandan ki o ja si asán.

IBEERE – Bawo ni o ṣe ṣe pataki si fun wa lati ri daju pe igbagbọ wa ninu Kirisiti ati iṣẹ isin wa ninu rẹ wa ni ibamu pẹlu alakalẹ awọn apọsiteli rẹ ti o ti kọja lọ?

Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 28, ÒWEWÉ 2022 ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ Read More »

Má ṣe jà wọ́n lólè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owéwè 25, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 21

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Òwewè 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun pa ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ati ohun gbogbo tí Ó ti yàn fun igbadun rẹ lọdun yi mọ fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Mo gba adura yi fun ọ nitori pe o wa ni ibamu pẹlu ọrọ Dafidi ninu Saamu rẹ ti o wi pe, “Oluwa ni ipin ini mi, ati ti aago mi: iwọ ni o mu ipin mi duro.” (Saamu 16:5) Tani o pa ipin Dafidi mọ fun un? Ọlọrun! Ta si ni ẹnikan ṣoṣo naa ti o le pa ipin wa, èrè wa, iṣẹ́ wa, ipò wa, ayọ̀ wa, alaafia wa, ibaṣepọ wa ati aye wa mọ fun wa? Ọlọrun! Idi si ni yi ti a fi gbọdọ kọ lati ma fi ojoojumọ ko ohun gbogbo ti a ni ati ti o jẹmọ aye wa le lọwọ.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe n fi igbekẹle wa sinu Ọlọrun lati pa ipin wa ninu aye yi mọ fun wa ati lati ri pe a ko ja wa lole tabi yan wa jẹ, awa naa gbọdọ ri daju pe a ko ma ji nkan awọn miran tabi ja wọn lole. Ọrọ Ọlọrun sọ wipe, “Ki ẹni ti n jale ma ṣe jale mọ: ṣugbọn ki o kuku maa ṣe laalaa, ki o maa fi ọwọ rẹ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki oun ki o le ni lati pin fun ẹni ti o ṣe alaini.” (Efesu 4:28) Nitorina, ti o ba n ja awọn ti o wa ni ayika rẹ lole lọnakọna, o ni lati fi opin si.

O si yẹ ki o mọ pe a ko nilo lati gbe ibọn ki a to ji nkan awọn eniyan. Igbakigba ti a ba mu fun ara wa ohunkohun ti a ko fun wa ni aye, aṣẹ tabi oore-ọfẹ lati mu lati ọdọ elomiran, nṣe ni a n jale. Lafikun, igbakigba ti a ba kọ lati san owo ọya awọn eniyan, ile-iṣẹ tabi ijọba fun nkan ti wọn ba wa ṣe tabi iṣẹ ti wọn ṣe fun wa, nṣe ni a n ja wọn lole. O si di dandan ki awọn nkan wọnyi pa ipamọ awọn nkan ti o jẹ ti wa lara ni ọna kan tabi omiran.

Siwaju si, bi a ti ṣe n fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun lati pa ipin wa mọ fun wa, a tun nilo lati ṣo ara wa lati ma ja a lole. Bawo ni a ṣe le ja Ọlọrun lole? Ṣe nipa mimu owo fun ara wa ninu apo ọrẹ ni tabi nipa fifọ ilẹ ijọsin, ki a si ko owo tabi awọn ohun elo ti a ba ba nibẹ lọ ni? Bẹẹni, nṣe ni a n ja Ọlọrun lole ti a ba ṣe ọkankan ninu awọn eyi. Eyi yoo si pa ipamọ wa ati ipamọ awọn nkan ini wa lara. Ṣugbọn, jija Ọlọrun lole le ju awọn nkan wọnyi lọ. Jija Ọlọrun lole tun ni i ṣe pẹlu ki a fi awọn nkan ti o yẹ ki a fun awọn iranṣẹ rẹ ti O ran si wa lati tọju wa pamọ fun ara wa.

Ki ni idi ti Ọlọrun fi pe awọn Juu igba aye Málákì ni ole? Ṣe nitori pe wọn fọ ilẹ iṣura Tẹmpili ni, ti wọn si ji awọn nkan ti o wa nibẹ? Rara! Idi ni pe wọn kọ lati fun awọn alufa Ọlọrun ti o n tọju wọn ni idamẹwa ati ọrẹ ti o yẹ fun itọju wọn. Ki wa ni idi ti a fi sọ fun wọn pe ki wọn ma fun awọn alufa yi ni idamẹwa ati ọrẹ wọn? Idi ni pe Ọlọrun ko fun wọn ni ipin kankan ni ilẹ wọn ati wipe O ti pa a laṣẹ fun wọn lati fi ara wọn jin lati sin awọn eniyan yi. Nitorina, nipa kikọ lati fun awọn alufa yi ni awọn nkan ti o tọ si wọn, awọn eniyan wọnyi n ja wọn lole ni, wọn si tun n ja Ọlọrun ti O yan wọn lati sin wọn lole pẹlu. Abalajọ ti awọn ati awọn nkan ini wọn ko ṣe wa ni ipamọ kuro lọwọ iṣẹ awọn ajẹnirun.

Ni bakan naa, Oluwa ti pa a laṣẹ fun awa naa lati tọju awọn ti O ran lati mojuto wa pẹlu nkan ini wa. Nitorina, nigba ti O n ran awọn apọsiteli rẹ jade lati waasu, ko fun wọn ni owo kankan lati mu lọwọ lọ. Lafikun, ko fi owo kankan silẹ fun wọn nigba ti O n goke wọn inu awọn ọrun lọ. Idi si ni pe O n reti ki awọn ti wọn yoo ṣiṣẹ sin lati tọju wọn. Ọrọ rẹ ni eyi: “Owo ọya alagbaṣe tọ si.” Nitorina, ti awọn ti wọn n ṣiṣẹ sin ko ba tọju wọn, a jẹ wipe wọn n ja wọn lole niyẹn. O si di dandan, bi Oluwa wa ti sọ siwaju, ki eyi ma jẹ ki awọn Ibukun ti o sorọ mọ iṣẹ iranṣẹ wọn sọkale ni kikun sori aye wọn. (Wo: Luuku 10:1-7; 1Kọrinnti 9:14; Galatia 6:6)

Nitorina, ti a ko ba mu fifi fun awọn iranṣẹ Ọlọrun wa lati gbe wọn ro ni ọkunkundun (AWỌN PERETE NI WỌN SI SABA MA N MU EYI NI ỌKUNKUNDUN NI ỌPỌ AWỌN IJỌ WA), nṣe ni a n ja wọn lole, ti a si tun n ja Ọlọrun lole pẹlu. Bawo wa ni a ṣe fẹ reti pe ki awọn Ibukun iṣẹ iranṣẹ wọn ṣiṣẹ ni kikun ninu wa tabi reti pe ki awọn nkan ti Ọlọrun fun wa wa ni ipamọ kuro lọwọ awọn ajẹnirun? Eyi gan si jẹ alaye fun bi awọn ọmọ Ọlọrun ko ki ṣe fi taratara di ọlọrọ ninu awọn ijọ ti wọn ki ti i fi tayọtayọ tọju awọn adari wọn ni ọna ti o peye. Irufẹ awọn ara yi le fi ara wọn jin lotitọ lati takete si ẹṣẹ ati lati ma rin ninu ododo. Ṣugbọn wọn ko ni lu aluyọ bi awọn ọmọ Ọlọrun miran ti wọn ko fi ara wọn jin lati ma gbe igbe aye ododo bi ti wọn ṣugbọn ti wọn fi ara wọn jin fun titọju awọn adari wọn.

Ni kukuru, kokọ nkan ti a n sọ ni pe ti o ba n ja Ọlọrun lole nipa jija awọn iranṣẹ rẹ lole awọn nkan ti o yẹ ki o ma a fifun wọn tabi ṣe fun wọn, yoo pa ifarahan ati ipamọ iṣoriire rẹ lara ni ọna ti ko dara. Nitorina, ronupiwada bayi, ki o si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ. Aijẹbẹ, Satani ko ni ye ri anfaani lati ja iwọ naa lole.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó lárinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe jà wọ́n lólè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owéwè 25, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 21 Read More »