Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 1:11-24 | ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ | ỌJỌ́RÚ 21, ÒWEWÉ 2022

DOWNLOAD THE PDF FILE HERE

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ ninu iwe Galatia, a ri wipe lẹta ibawi ni lẹta yi ti Pọọlu kọ si awọn ara Galatia jẹ. Ki ni o si fa? Nkan ti o fa naa ni wipe ko pẹ si igba ti apọsiteli yi kuro ni ọdọ awọn ara Galatia yi ti wọn fi pa iyinrere ti o mu tọ wọn wa, ti wọn si gbagbọ, ti si ẹgbẹ kan, ti wọn si wa dirọ mọ iyinrere miran ti ko ki i ṣe iyinrere rara. Ki si ni iyinrere ti wọn dirọ mọ yi da le lori? Bi a o ti ṣe ri ninu lẹta yi, o da leri pipa awọn abala ofin Mose kan mọ, paapaa julọ eyi ti o ni ṣe pẹlu kikọ ilá abẹ́. Pọọlu wa n jẹ ki o ye wọn pe kikọ iyinrere Jesu Kirisiti ti a mu tọ wọn wa silẹ ko yatọ si kikọ Jesu Kirisiti Oluwa wa funrarẹ silẹ ati wipe egbe ni fun ẹnikẹni ti o ba wa nidi ki a ma polongo iyinrere miran ti o yatọ si eyi ti o fi Jesu han bi ẹnikan ṣoṣo ti Ọlọfun fa kalẹ fun igbala ati iṣelogo awọn ọmọ eniyan.

ẸRI IGBALA PỌỌLU
Ninu ẹkọ eyi ti a wa mu yi, ẹwẹ, Pọọlu jẹ ki o ye awọn ara Galatia ti o kọ iwe yi si irufẹ iyinrere ti o n tan kalẹ ni ibi gbogbo ti o n lọ ati ọna ti o gba gba iyinrere yi. O tun jẹ ẹri ranpẹ lori igbala rẹ ati iha ti awọn ti o mọ ọn tabi gbọ nipa rẹ ki o to di ẹni igbala kọ si iṣẹlẹ igbala rẹ ati awọn igbesẹ ti o bẹrẹ si ni gbe lẹyin ti o di ẹni igbala. Iwọ naa wo awọn nkan ti o sọ:

“Ṣugbọn, ara, mo fẹ ki ẹ mọ pe iyinrere ti mo ti waasu kii ṣe nipa ti eniyan. Nitori kii ṣe lọwọ eniyan ni mo ti gba a, bẹẹ ni a ko fi kọ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kirisiti. Nitori ẹyin ti gburo igbe-aye mi ti atijọ, nigba naa ti mo n tẹle ẹsin awọn Juu, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ eniyan Ọlọrun re kọja ala, ti mo si ba a jẹ. Mo si ta ọpọlọpọ awọn ojugba mi yọ ninu ẹsin awọn Juu laarin awọn ara ilu mi bakan naa, mo ni itara ọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn Baba mi. Ṣugbọn nigba ti o wu Ọlọrun, ẹni ti o ya mi sọtọ lati inu iya mi wa, ti o si pe mi nipa oore-ọfẹ rẹ, Lati fi ọmọ rẹ han nipasẹ mi ki emi le maa waasu rẹ laarin awọn Keferi loju kan naa emi ko ba ara ati ẹjẹ gbimọ pọ. Bẹẹ ni emi ko goke lọ si Jerusalẹmu tọ awọn ti ṣe Apọsiteli ṣaaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arebia, mo si tun pada wa si Damasiku. Lẹyin ọdun mẹta, mo lọ si ilu Jerusalẹmu lati lọ ki Peteru, mo si gbe ọdọ rẹ fun ọjọ mẹẹdogun. Ṣugbọn emi ko ri awọn Apọsiteli miiran, bi ko ṣe Jemisi arakunrin Oluwa. Otitọ ni awọn ohun ti mo n kọ si yin wọnyi, kiyesi i, Niwaju Ọlọrun emi ko ṣeke. Lẹyin naa ni mo si lọ si ẹkun Siria ati ti Siliṣia; Awọn ijọ ti o wa ninu Kirisiti ni Judia ko si mọ oju mi: Kiki ohun wọn-ọn-ni ti awọn eniyan n sọ ni wọn ti gbọ wi pe Ẹni ti o ti n ṣe inunibini si wa ri, ti n waasu igbagbọ naa nisinsinyi ti oun n bajẹ nigba kan ri. Wọn si yin Ọlọrun logo nitori mi.” (Galatia 1:11-24)

Pẹlu awọn nkan ti Pọọlu sọ silẹ yi, akọkọ, a ri dimu pe ẹnikẹni ko kọ tabi ṣalaye iyinrere ti o n waasu fun. Jesu Oluwa wa funrarẹ ni O fi awọn nkan wọnyi han an, ti O si fi oye wọn ye e. Ara idi niyi ti o fi sọ wipe lẹyin igba ti oun gbagbọ tan, oun ko lọ ba ọkankan lara awọn ti o jẹ apọsiteli ṣaaju rẹ. Dipo eyi, nṣe ni o gba Arebia lọ. Lẹyin ọdun melokan si lo to ṣẹ ẹ lọ ki Peteru ati Jemisi, arakunrin Jesu Oluwa.

Nitorinaa, awọn ti o ti jẹ apọsiteli ṣaaju Pọọlu kọ ni o kọ ni iyinree ti o n tan kalẹ. Awọn kọ ni wọn ṣe alaye igbagbọ, ireti ati ifẹ ninu Jesu fun. Awọn kọ ni wọn kọ ni bi a ti ṣe le di olododo, ki a si tun ma gbe igbe aye olododo. Awọn kọ ni wọn ṣalaye fun nipa iku, ajinde ati igbasoke Jesu. Awọn kọ ni wọn kọ nipa ipadabọ Jesu ati igbasoke awọn ayanfẹ rẹ. Bẹẹ si ni awọn kọ ni wọn ṣalaye fun nipa ounjẹ alẹ Oluwa ati awọn nkan ti o ṣẹlẹ lalẹ ọjọ ti a kọkọ jẹ ounjẹ yi. A si ri pe o mọ gbogbo awọn nkan wọnyi daju, o si tọka si wọn ninu awọn lẹta rẹ si ijọ Ọlọrun. Bawo lo ṣe wa mọ wọn? Nipasẹ ifihan Jesu Kirisiti ni! (Wo: 1Kọrinnti 15:3-7; 2Kọrinnti 12:1-4)

Ṣe nkan ti Jesu wa fi han apọsiteli yi, ti O si tun kọ lodi tabi yatọ si awọn nkan ti O ti kọ ati fi han awọn aṣiwaju rẹ ninu igbagbọ? Rara o! Nitorina, ẹnikẹni ti o ba n sọ wipe a fi awọn nkankan han oun nipa igbagbọ ninu Jesu tabi lori iyinrere rẹ gbọdọ ri daju pe ohun ti a fi han wa ni ibamu pẹlu awọn nkan ti Jesu fa le awọn aṣiwaju wa ninu igbagbọ lọwọ. Aijẹbẹ, irọ pata-porongodo ni ohun yowu ti a fi han an.

Nkan keji ti Pọọlu tun mẹnuba ninu awọn ẹsẹ lẹta rẹ yi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni ẹri igbala rẹ. Ki si ni idi? O fẹ ki o ye awọn ara Galatia ti o kọ iwe yi si pe ohun funra oun ti kọkọ gbe ẹsin awọn Juu ka ori nigbakan ri, ti oun si tayọ gidigidi ninu rẹ ju awọn ti o jẹ akagbẹ rẹ lọ. Yatọ si eyi, o tun ti ṣe inunibini awọn ọmọ Ọlọrun ti o gbagbọ ninu Jesu ri, ti o si mura tan lati pa igbagbọ ninu Jesu run.

Ki lo wa fa ti o fi pa gbogbo nkan wọnyi ti, ti o si bẹrẹ si ni waasu ni ijẹri nkan ti o ti fẹ parun tẹlẹ? Ifarahan Jesu Kirisiti si ni o fa. Jesu, ni ọjọ kan ti ọkunrin yi n lọ si Damasiku lati tun lọ ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa nibẹ mọle, fi ara rẹ han lati jẹ ki o mọ wipe igbe aye ti a ya a sọtọ lati inu iya rẹ wa lati gbe kọ ni o n gbe. A ya a sọtọ lati inu iya rẹ ki o ba le fi Jesu han si gbogbo araye gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, iyẹn ninu ọrọ, ninu iwa ati ninu iṣe rẹ. Eyi si lo fa ti oun naa fi bẹrẹ si ni fi gbogbo okun ati agbara rẹ jẹ ki awọn eniyan mọ pe ko si igbala ninu ẹlomiran, ayafi ninu Jesu. Nṣe si ni inu gbogbo awọn ti o mọ tẹlẹ, ti wọn si gbọ si ọrọ yi bẹrẹ si ni dun, ti wọn si n gbe orukọ Ọlọrun ga lati ara rẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 9:1-30, 22:1-21; 26:1-32)

Njẹ awọn ti o mọ awa naa tẹlẹ tilẹ ni idi loni lati ma gbe orukọ Ọlọrun ga nipasẹ wa bi? Njẹ wọn tilẹ le sọ daju-ṣaka pe iyatọ wa gedegbe laarin igbe aye ti a n gbe ki a to di atunbi ati igbe aye ti a n gbe nisinsinyi ti a sọ wipe a ti di atunbi? Awọn eniyan n fi ogo fun Ọlọrun nitori aye tuntun ti Pọọlu n gbe lẹyin ti o ti di atunbi. Ti ko ba wa si ẹni ti o n fi ogo fun Ọlọrun lori aye wa, nṣe ni o yẹ ki a yẹ ara wa wo.

Wayi o, ti Pọọlu ba wa n jẹ ki o ye awọn eniyan pe Jesu ti to fun igbala wọn ati wipe wọn ko nilo lati pa ohunkohun ninu ofin Mose mọ ki wọn to di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun, o mọ nkan ti o n sọ. Ko sọ eyi nitori pe ko ni imọ rara tabi imọ to ninu ofin Mose. O ni imọ ti o jinlẹ ninu ofin Mose. O tilẹ ti fi igba kan jẹ ọkan lara awọn Farisi ri (Iṣe Apọsiteli 23:6-8; Filipi 3:5). Ṣugbọn Ọlọrun ti jẹ ki o ni oye ti o jinlẹ ninu ọmọ rẹ Jesu Kirisiti. Idi si ni yi ti o fi n lo gbogbo itara lati jẹ ki o ye awọn eniyan, paapaa julọ awọn Juu pe wọn ko nilo lati pa abala ofin Mose kankan ma lati di ẹni igbala ati ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Jesu Kirisiti ati iṣẹ ti Ọlọrun ran wa ṣe ti to fun wọn.

O wa ṣeni laanu pe awọn ara Galatia, ni akoko ti a kọ lẹta yi si wọn, ko ni oye awọn nkan wọnyi. Nitorina, wọn ti gbe igbagbọ ninu Jesu gẹgẹ bi ọna lati jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun ju si ẹgbẹ kan, wọn si ti bẹrẹ si ni tẹle ofin Mose ati awọn ilana ti o wa ninu rẹ. Pọọlu wa nilo lati mu wọn pada wa sinu otitọ pẹlu lẹta yi, ki wọn ma ba di ẹni itanu ni ikẹyinkẹyin.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Bi o ti ṣe ri pẹlu awọn ara Galatia ni akoko ti Pọọlu kọ lẹta si wọn naa ni o ti ṣe ri pẹlu ọpọ ijọ Ọlọrun loni. Awọn naa ti gbe igbagbọ ninu Jesu gẹgẹ bi ọna lati di ẹni igbala ati ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun ju sẹgbẹ kan, wọn si ti dirọ mọ ofin Mose. Nkan ti ko si ye wọn ni pe ti ofin Mose ba le fun awọn eniyan ni igbala pipe, ki o si sọ wọn di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun, iwasaye Jesu, iku rẹ ati ajinde rẹ ko ni itunmọ niyẹn. Amọ awọn nkan yi ni itumọ ti o ga, ti a si gbọdọ dirọmọ. Aijẹbẹ, bi awọn ara Galati ṣe tipasẹ ailoye otitọ ọrọ Ọlọrun kẹyin si Jesu naa ni awa naa yoo ṣe kẹyin si, bi o tilẹ jẹ wipe a n ṣe oniruuru nkan ni orukọ rẹ. Boya a tilẹ ti kọ ẹyin si?

IBEERE

  • Bawo ni ijẹri igbala awọn ọmọ Ọlọrun ṣe wulo si?
  • Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 1:11-24 | ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ | ỌJỌ́RÚ 21, ÒWEWÉ 2022 Read More »

Lílé ìṣẹ́ kúrò nínú ìjọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal |Ọjọ́: Owéwè 11, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owéwè 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ti o peye lati rin pẹlu awọn ọmọ rẹ ti o wa ninu aye rẹ pẹlu ifẹ ati oye, ki ibaṣepọ rẹ pẹlu wọn ba le ma fi gbogbo igba yọri si iwuri ati ìṣoríire fun wọn dipo ikoro. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko si talaka kankan ninu ijọ ni awọn ọjọ wọnni. Ki si ni idi? Luuku sọ fun wa pe idi ni pe, lati igba de igba, awọn ọmọ ijọ ti wọn ni nkan ini n ta wọn, wọn si n mu owo ti wọn pa nidi rẹ wa fun awọn Apọsiteli Oluwa lati pin fun awọn ti o ṣe alaini. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe ipade akanṣe adura ati awẹ tabi ipade ìfowólọ́lẹ̀ ni o fọ ìṣẹ́ danu kuro laarin awọn ọmọ Ọlọrun ni igba yẹn. Dipo eyi, nipasẹ lilawọ ni a ṣe fọ ìṣẹ́ danu kuro laarin wọn. Ki lo si fa ti awọn ara ti wọn lawọ yi ṣe lawọ bi wọn ti ṣe lawọ? Ifẹ Kirisiti ninu wọn ni o fa. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 4:34-35; 2Kọ́rínntì 5:14)

Ṣugbọn ṣe lilawọ nikan to lati fọ ìṣẹ́ danu kuro laarin awọn ọmọ Ọlọrun tabi ni ibikibi? Rara o! Ti awọn eniyan ko ba fi iṣẹ́ ọwọ́ ti o ni itunmọ kun irufẹ ififunni yowu ti wọn ba ri gba, o ṣeeṣe ki ififunni na ma ja mọ nkankan ninu aye wọn. Nṣe ni wọn yoo kan ma ko nkan ti a n fun jẹ lasan dipo ki wọn ma sọ di pupọ si. Idi si ni yi ti o fi jẹ wipe ko ki i ṣe fifi funni nikan ni awọn apọsiteli igbaani kọ awọn ara; wọn tun kọ wọn lati jẹ oṣiṣẹ ti o mura ṣiṣẹ, ti o si n ṣiṣẹ takuntakun pẹlu. Wọn tilẹ mu ni ọranyan pe ẹnikẹni ti ko ba ni ṣiṣẹ ko gbọdọ jẹun. Idi si ni pe wọn ko fẹ ki awọn ti o n gba iranwọ ninu ijọ fi iranwọ ti wọn n gba ṣofo tabi ki wọn sọ ara wọn di bukuta ti ko nidi si ọrun awọn miran. (Wo: Ìṣe àpọ́sítélì 20:34-35; Éfésù 4:28; 1Tẹsalóníkà 4:11-12; 2Tẹsalóníkà 3:6-10)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ loni ti o fẹ ki ijọ ran wọn lọwọ ni ko ṣetan lati mu iṣẹ kankan ti o ni itunmọ, ti yoo si jẹ ki wọn le sọ iranwọ yowu ti wọn ba ri gba di gbigboro si ṣe. Nṣe ni wọn kan fẹ ki ijọ ma gbe bukata ti awọn funralara wọn ko mura tabi ṣetan lati gbe. Eyi ko si le ṣiṣẹ. Eyi gan paapaa jẹ ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu awọn ijọ wa loni ko fi ni alakalẹ ti o lojutu kankan fun iranlọwọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o kudiẹ-kaato fun. Iriri ti kọ wọn pe ọpọ ti o n fẹ iranwọ lati ọwọ ijọ ni o jẹ ọlẹ tabi alainikanṣe eniyan, ti wọn kan n wa aye lati ṣi oore-ọfẹ Ọlọrun lo. O tilẹ di dandan ki awọn miran lara awọn wọnyi parẹ́ ni kete ti wọn ba ti ri iranwọ ti wọn fẹ gba. Nitorina ti o ba fẹ ki ijọ ran ọ lọwọ ni ọna kan tabi omiran, o nilo lati fi han daju ṣaka pe o ko ni lu ijọ Ọlọrun ni jibiti ati wipe iwọ yoo jẹ ki iranwọ ti o ba ri gba ja mọ nkan.

Nkan miran ti o jẹ ki lilawọ awọn eniyan mimọ igbaani yi ṣe aṣeyọri lati le ìṣẹ́ kuro laarin wọn ni pe lilawọ wọn ko fi si apa kan. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe wipe awọn ti wọn n fifunni n fifunni lati sọ awọn kan di ọlọrọ nigba ti awọn n da otoṣi. Lafikun, ko ki i ṣe pe awọn ti wọn n fifunni nikan naa ni wọn n fifunni, gẹgẹ bi ko si ki i ṣe pe awọn ti wọn ri gba naa kan n fi gbogbo igba tẹwọgba ififunni awọn miran. Dipo eyi, nṣe ni ẹkọkọọkan n kopa ninu riran ara wọn lọwọ ni ibamu pẹlu bi nkan ini wọn ti pọ to ati ni ibamu pẹlu aini wọn. (Wo: 2Kọrinnti 8:13-15)

Ki lo wa fa ti eyi ko ṣe ri bẹ ni ọpọ ijọ wa loni? Idi ni pe awọn adari wa ko ma kọ wa lati ma jẹ alanikanjọpọn ninu ibaṣepọ wa pẹlu ara wa bi awọn apọsiteli igbani ti ṣe kọ awọn ará wọn. Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Fílípì: “Ki olukuluku yin ki o ma ṣe wa ohun tirẹ nikan, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.” (Fílípì 2:4) Njẹ o ri bayi? A kọ awọn ara yi lati ma mọ ti ara wọn nikan, lati ma fi ọkan si kiki nkan ti wọn le ri gba lati ọwọ awọn ẹlomiran ṣugbọn lati tun fi ọkan si nkan ti awọn naa le ṣe fun awọn miran tabi fun wọn. Ṣugbọn ọpọ ninu ijọ loni ni o jẹ wipe kiki nkan ti wọn yoo ri gba lọwọ awọn miran ni wọn ma n wa, wọn ko ki i wa nkan ti awọn naa le ṣe fun awọn miran. Niwọn igba ti a ba si ri bayi, ko si ni ki iṣeṣi wa ma rin awọn ti wọn n ran wa lọwọ lara, ki awọn naa ṣi wa yi iṣeṣi wọn si wa pada to ba ya.

Nitorina ti a ba fẹ fọ ìṣẹ́ danu kuro ninu awọn ijọ wa, a gbọdọ kọbiara si awọn nkan mẹta yi, yatọ si pe ki a fi ọkan wa tẹ Ọlọrun lati pese fun aini wa gbogbo. Àkọ́kọ́, a gbọdọ jẹ ki ifẹ mu wa lọkan le lati lawọ si ara wa. Èkejì, gbogbo awa ti ara ati ọkan wa pe perepere ni a gbọdọ wa iṣẹ kan ti o ni itunmọ ṣe, ki a ma ba di bukata aye wa le ẹnikẹni lori lalai ni idi. Ẹ̀kẹta, ko gbọdọ jẹ kiki nkan ti a fẹ ri gba lọwọ ijọ tabi lọwọ awọn miran ni ko ma wa ni ọkan wa ṣugbọn nkan ti awa naa le fun awọn miran pẹlu. Ki Ẹmi Ọlọrun ṣi jẹ ki a ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Lílé ìṣẹ́ kúrò nínú ìjọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal |Ọjọ́: Owéwè 11, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 20 Read More »

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òwewè 2022. Adura mi si ni pe ohunkohun ko ni di ọkankan lara awọn nkan daradara ti Ọlọrun ti pese silẹ fun igbadun rẹ ninu oṣu naa lọwọ lati jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ti a ba n sọ wipe awọn eniyan n ni iriri idilọwọ, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o jẹ wipe Satani ni o wa nidi rẹ. Ni igba miran, Ọlọrun funrarẹ gan ni O ma n wa nidi rẹ. Ki wa ni idi ti Ọlọrun, ti o fẹ araye to bẹ gẹẹ ti O fi fi ọmọ bibi rẹ kan ṣoṣo fun wọn, le fẹ di ọkunrin tabi obinrin kan lọwọ lati ma ni itẹsiwaju laye? Igberaga lo ma n fa a.

Ati Jemisi ati Peteru ni wọn jọ dijọ sọ fun wa ninu episiteli wọn pe Ọlọrun a ma kọ oju-ija si agberaga ṣugbọn a si fi oore-ọfẹ fun onirẹlẹ (Jémìsì 4:6; 1Pétérù 5:5). Nitorina, ti o ba gberaga, o yẹ ki o ma reti Ọlọrun lati di ilọsiwaju rẹ lọwọ ni awọn abala aye rẹ kan tabi ni gbogbo abala aye rẹ. Ọna kan ti a si ma n ṣaba gba fi igberaga han ninu aye wa, lalai tilẹ mọ, ni nipa kikọ lati tẹriba fun awọn alaṣẹ.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn eniyan wa ti Ọlọrun ti pa aṣẹ fun wa lati tẹriba fun. Fun apẹẹrẹ, awọn obi wa, awọn ọkọ wa, awọn agbaniṣiṣẹ ati ọga wa, awọn adari ilu wa ati awọn adari ijọba wa wa lara awọn ti O fẹ ki a ma tẹriba fun. Ko fẹ ki a tabuku awọn wọnyi tabi ki a ṣe aigbọran si wọn, niwọn igba ti awọn aṣẹ wọn ko ba ti tako ọrọ rẹ ati ilana rẹ fun igbe aye ododo. Ti a ba wa kọ eti didi si eyi, ti a si bẹrẹ si ni tabuku wọn, nṣe ni a n rin ninu igberaga; o si di dandan ki a bẹrẹ si ni ri iṣẹ Ọlọrun lodi si ilọsiwaju wa. Oun nikan lo si wa mọ iye awa ti a n ni idaduro ati idilọwọ laye nitori eyi. (Wo: Róòmù 13:1-5; Éfésù 5:22; Éfésù 6:1-3; 1Pétérù 2:13-14; 1Pétérù 3:1-2)

Siwaju si, ninu ijọ, Oluwa kọ wa lati tẹriba fun awọn adari wa ni ibọwọ fun Kirisiti. Eyi tunmọ si pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe ibi ti o ti le ma gun ejika, ki o si tun ma ṣe bo ba ti ṣe wu ẹ. Awọn eniyan wa nibẹ ti Ọlọrun ti yan si ori rẹ lati ṣọna lori ọkan rẹ ati lati mojuto ọ, ki o ba le da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da. O wa ṣe pataki ki o tẹriba fun awọn wọnyi, ki o si ma jẹ ki o ṣoro fun wọn lati dari rẹ, niwọn igba ti ko ba ki i ṣe pe wọn fẹ dari rẹ kuro ninu otitọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, bi bibeli ti ṣe fi ye wa, ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Dandan ni ki Ọlọrun ba ọ wi ni ibamu pẹlu igberaga rẹ. (Wo: Hébérù 13:17)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu ijọ loni ni igberaga kọ jẹ ki wọn fi ara balẹ kọ awọn nkan ti yoo ṣe wọn ni anfaani tabi ti yoo jẹ ki wọn ni iriri ẹkunrẹrẹ didara Ọlọrun ti ko ba jẹ ti wọn nipasẹ awọn adari wọn. Awọn wọnyi dabi awọn gbajumọ aarin awọn ọkunrin Tẹ́kóà ti a mẹnuba ninu iwe Nehemáyà, ti wọn kọ lati teriba fun awọn adari wọn ni akoko ti gbogbo awọn eniyan n tun odi Jerusalẹmu mọ (Nehemáyà 3:5). Iru awọn eniyan yi n ma n di ilọsiwaju iṣẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan rẹ lọwọ laimọ. Nitorina, Oun naa a si din ọwọ iṣẹ rẹ ku ninu aye wọn.

Ṣe o wa ri bayi pe iṣọtẹ si awọn alaṣẹ ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Nitorina, ri daju pe o mojuto irufẹ igberaga yowu ti o le wa ninu rẹ, ti o si n jẹ ki o ṣe orikunkun si awọn ti Ọlọrun ti yan gẹgẹ bi adari fun ọ. Ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18 Read More »

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òwewè 2022. Adura mi si ni pe ohunkohun ko ni di ọkankan lara awọn nkan daradara ti Ọlọrun ti pese silẹ fun igbadun rẹ ninu oṣu naa lọwọ lati jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ti a ba n sọ wipe awọn eniyan n ni iriri idilọwọ, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o jẹ wipe Satani ni o wa nidi rẹ. Ni igba miran, Ọlọrun funrarẹ gan ni O ma n wa nidi rẹ. Ki wa ni idi ti Ọlọrun, ti o fẹ araye to bẹ gẹẹ ti O fi fi ọmọ bibi rẹ kan ṣoṣo fun wọn, le fẹ di ọkunrin tabi obinrin kan lọwọ lati ma ni itẹsiwaju laye? Igberaga lo ma n fa a.

Ati Jemisi ati Peteru ni wọn jọ dijọ sọ fun wa ninu episiteli wọn pe Ọlọrun a ma kọ oju-ija si agberaga ṣugbọn a si fi oore-ọfẹ fun onirẹlẹ (Jémìsì 4:6; 1Pétérù 5:5). Nitorina, ti o ba gberaga, o yẹ ki o ma reti Ọlọrun lati di ilọsiwaju rẹ lọwọ ni awọn abala aye rẹ kan tabi ni gbogbo abala aye rẹ. Ọna kan ti a si ma n ṣaba gba fi igberaga han ninu aye wa, lalai tilẹ mọ, ni nipa kikọ lati tẹriba fun awọn alaṣẹ.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn eniyan wa ti Ọlọrun ti pa aṣẹ fun wa lati tẹriba fun. Fun apẹẹrẹ, awọn obi wa, awọn ọkọ wa, awọn agbaniṣiṣẹ ati ọga wa, awọn adari ilu wa ati awọn adari ijọba wa wa lara awọn ti O fẹ ki a ma tẹriba fun. Ko fẹ ki a tabuku awọn wọnyi tabi ki a ṣe aigbọran si wọn, niwọn igba ti awọn aṣẹ wọn ko ba ti tako ọrọ rẹ ati ilana rẹ fun igbe aye ododo. Ti a ba wa kọ eti didi si eyi, ti a si bẹrẹ si ni tabuku wọn, nṣe ni a n rin ninu igberaga; o si di dandan ki a bẹrẹ si ni ri iṣẹ Ọlọrun lodi si ilọsiwaju wa. Oun nikan lo si wa mọ iye awa ti a n ni idaduro ati idilọwọ laye nitori eyi. (Wo: Róòmù 13:1-5; Éfésù 5:22; Éfésù 6:1-3; 1Pétérù 2:13-14; 1Pétérù 3:1-2)

Siwaju si, ninu ijọ, Oluwa kọ wa lati tẹriba fun awọn adari wa ni ibọwọ fun Kirisiti. Eyi tunmọ si pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe ibi ti o ti le ma gun ejika, ki o si tun ma ṣe bo ba ti ṣe wu ẹ. Awọn eniyan wa nibẹ ti Ọlọrun ti yan si ori rẹ lati ṣọna lori ọkan rẹ ati lati mojuto ọ, ki o ba le da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da. O wa ṣe pataki ki o tẹriba fun awọn wọnyi, ki o si ma jẹ ki o ṣoro fun wọn lati dari rẹ, niwọn igba ti ko ba ki i ṣe pe wọn fẹ dari rẹ kuro ninu otitọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, bi bibeli ti ṣe fi ye wa, ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Dandan ni ki Ọlọrun ba ọ wi ni ibamu pẹlu igberaga rẹ. (Wo: Hébérù 13:17)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu ijọ loni ni igberaga kọ jẹ ki wọn fi ara balẹ kọ awọn nkan ti yoo ṣe wọn ni anfaani tabi ti yoo jẹ ki wọn ni iriri ẹkunrẹrẹ didara Ọlọrun ti ko ba jẹ ti wọn nipasẹ awọn adari wọn. Awọn wọnyi dabi awọn gbajumọ aarin awọn ọkunrin Tẹ́kóà ti a mẹnuba ninu iwe Nehemáyà, ti wọn kọ lati teriba fun awọn adari wọn ni akoko ti gbogbo awọn eniyan n tun odi Jerusalẹmu mọ (Nehemáyà 3:5). Iru awọn eniyan yi n ma n di ilọsiwaju iṣẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan rẹ lọwọ laimọ. Nitorina, Oun naa a si din ọwọ iṣẹ rẹ ku ninu aye wọn.

Ṣe o wa ri bayi pe iṣọtẹ si awọn alaṣẹ ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Nitorina, ri daju pe o mojuto irufẹ igberaga yowu ti o le wa ninu rẹ, ti o si n jẹ ki o ṣe orikunkun si awọn ti Ọlọrun ti yan gẹgẹ bi adari fun ọ. Ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Má sọ ààyè rẹ nù | Pásítọ̀ J.O. Lawal | LTB | Ògún 28, 2022

Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ tayọtayọ si ọjọ Isinmi ti o kẹyin oṣu yi, oṣu Ògún 2022. Mo si gbadura pe a ko ni gbe ipo rẹ ninu ijọba Ọlọrun ati Baba wa fun ẹlomiran, ni orukọ Jesu. Amin.

Lẹyin igbasoke Jesu Oluwa wa, awọn ọmọ ẹyin rẹ korajọpọ si Jerusalẹmu, wọn si ṣe ipade lati yan ẹnikan lati rọpo Judasi Isikariọti. Luuku, ninu akọsilẹ rẹ lori eyi, sọ wipe Peteru sọ bayi, “Nitori a ṣaa ti kọ nipa rẹ ninu iwe Saamu pe, ki ibujoko rẹ di ahoro, ki ẹnikẹni ki o ma si ṣe gbe inu rẹ, ati ipo rẹ, ni ki ẹlomiran gba.” (Iṣe Apọsitei 1:20) Njẹ o ri bayẹn? Peteru, ni asiko ti a n wi yi, pe akiyesi awọn ọmọ ẹyin yoku si nkan ti Iwe Mimọ sọ lori Judasi ati lori bi elemoran ṣe gbọdọ gba ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ki wa ni idi ti ẹlomiran ṣe gbọdọ gba ààyè ti o tọ si arakunrin yi? Idi ni wipe o sọ ààyè naa nu. Ki lo ṣi jẹ ki o padanu ààyè rẹ? Ojukokoro ni o jẹ ki o padanu rẹ.

Nibakanna, ọmọ Ọlọrun kọọkan ni o ni ààyè ninu ijọba Ọlọrun, ààyè ti Baba wa funrarẹ pese ni pataki silẹ fun. Jesu Oluwa wa tilẹ sọ fun wa pe awọn eniyan yoo wa lati ibi gbogbo ni agbaye lati gba ààyè ti Baba wa ti pese silẹ fun ẹnikọọkan wọn ninu ijọba rẹ (Matiu 8:11). Amọ ọtọ ni ki eniyan gba ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun nigba ti o wa ninu ayé yi; ọtọ tun si ni ki o di ààyè yi mu titi de opin ohun gbogbo.

Judasi, bi awọn ọmọlẹyin Jesu Oluwa yoku, naa fi igba kan wa lati gba ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn o padanu rẹ ni ikẹyinkẹyin. Ọlọrun nikan ni o si mọ iye awọn ti o ti padanu ààyè wọn ninu ijọba rẹ, ti awọn miran si ti gba mọ wọn lọwọ. Nitorina, ko to fun wa lati mọ pe a ni ààyè pẹlu Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa ninu ijọba wọn. O tun ṣe pataki ki a ma padanu ààyè wa pẹlu wọn.

Peteru, ninu episiteli rẹ keji, sọ eleyi fun wa: “Nitori naa ẹyin olufẹ, bi ẹyin ti mọ nnkan wọnyi tẹlẹ, ẹ maa kiyesara, ki a ma ba fi iṣina awọn eniyan buburu fa yin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ni iduro ṣinṣin yin.” (2Peteru 3:17) Ṣe o ri bayẹn? Ti a ko ba kiyesara, a le ṣubu kuro ni aaye wa ti o daju ninu ijọba Ọlọrun. Ojukokoro mu ki Judasi ṣubu. O si le mu ki awọn naa pẹlu ṣubu. Ti eyi ko be tilẹ mu wa ṣubu, igberaga, ifẹkufẹ, iṣọtẹ, ówu tabi arankan nkọ? Njẹ ọkan lara awọn nkan wọnyi ko ni bi wa ṣubu bi?

Ti Judasi Isikariọti ba ti kiyesara fun ojukokoro ni, ko ba ma ti ṣubu bi o ti ṣe ṣubu. Si wa ranti pe Oluwa ti kọ wọn lati kiyesara fun oniruuru ojukokoro (Luuku 12:15). O wa ṣeni laanu pe ko kọbiara si nkan yi. Nitori eyi, o ṣubu, o si sọ ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun nu. Ti awa naa ba si kọ lati fiyesi awọn nkan ti O n ba wa sọ lori awọn nka ti o yẹ ki a kiyesara fun, o ṣeeṣe ki awa na pari irinajo wa bi ti Judasi.

Bẹẹni, a le rin irin-ajo kaakiri agbaye ni orukọ Jesu Oluwa, ki a si tun ṣe oniruuru iṣẹ nipasẹ agbara rẹ, gẹgẹ bi o ti ṣe ri fun Judasi Isikariọti. Ṣugbọn gbogbo awọn nkan wọnyi ko ni jamọ nkankan lẹyin-ọ-rẹyin, ti a ba padanu ààyè wa ninu ijọba rẹ. Adura mi si ni pe ki a mu ọkan wa duro ṣinṣin ninu otitọ ni gbogbo igba, ki a ma ba fi aye gba ohunkohun ti yoo jẹ ki a padanu ààyè wa ninu ijọba ayeraye Baba wa. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má sọ ààyè rẹ nù | Pásítọ̀ J.O. Lawal | LTB | Ògún 28, 2022 Read More »

Ki ni o fẹ gbọ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Ògún 21, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògún 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba tẹri ọkan rẹ ba niwaju rẹ, ki o ba le tẹwọgba ọ̀rọ̀ rẹ fun ìgbéró, ìgbéga ati ìgbàlà ojoojumọ rẹ. Amin.

Pọọlu, nigba ti o n kọ iwe si Timoti ninu lẹta kan, sọ fun pe, “Nitori pe akoko kan yoo de, ti wọn ki yoo le fetisi ẹkọ ti o yẹ kooro; ṣugbọn bi wọn ti jẹ ẹni ti eti n rin, wọn o lọ ko awọn olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹẹ ara wọn. Wọn o si yi eti wọn pada kuro ninu otitọ, wọn o si yipada si itan asan.” (2Timoti 4:3-4) Awọn wo ni apọsiteli yi n tọka si ni ibi yi? Ṣe awọn alaigbagbọ ni bi? Rara o! Awọn kan ti wọn pe ara wọn ni Kirisitiẹni ni o n tọka si, awọn kan ti wọn n pariwo wi pe awọn ti di atunbi nipa igbagbọ ninu Kirisiti Jesu.

Ki wa ni Pọọlu sọ nipa wọn eniyan wọnyi? O sọ wipe iha ti wọn kọ si otitọ Jesu Oluwa wa ko dara rara. Lọna wo wa ni iha ti wọn kọ si otitọ Jesu ko gba dara? Akọkọ, bi o ti ṣe fi ye wa, wọn kọ lati faramọ otitọ naa. Eyi tunmọ si pe, wọn korira rẹ, wọn ko si fẹ tẹwọ gba. Pọọlu tilẹ sọ wipe wọn yi eti wọn pada kuro lati ma gbọ otitọ ti a n mu tọ wọn wa. Ki si ni idi? Idi ni pe o n bi wọn ninu, o si n pa wọn lara. Ki lo wa fa ti o ṣe n bi wọn ninu, ti o si n pa wọn lara? Idi naa ni pe o lodi si igbe aye wọn.

Boya iwọ naa gan tilẹ korira lati gbọ otitọ nipa Ọlọrun tabi nipa ara rẹ tabi nipa aye lapapọ. Boya nṣe ni iwọ naa n fi gbogbo igba kọ eti ikun si otitọ nigba ti a ba mu tọ ọ wa. Nkan ti eyi n fi han daju naa ni pe aye rẹ lodi si, o ko si fẹ gba bẹ ẹ. Nitorina, o ko le lailai bọ kuro lọwọ nkan yowu ti o gbe ọ de, ti o si n pa ọ run, nitori pe otitọ nikan ni o ma n sọ eniyan di ominira (Johanu 8:32).

Nkan miran ti Pọọlu tun sọ nipa awọn ti wọn pe ara wọn ni Kirisitiẹni yi pe wọn a ma ko ọpọlọpọ awọn olukọ jọ ti yoo ṣọ nkan ti eti ti o n rìn wọn fẹ gbọ fun ara wọn. Eyi tunmọ si pe awọn wọnyi mọ nkan ti wọn fẹ gbọ. Ṣugbọn ko ki i ṣe otitọ ni. La ti si tẹ ifẹ ara wọn lọrun, wọn le ṣe ohunkohun lati wa awọn ti yoo sọ nkan ti wọn fẹ gbọ fun wọn. Bi wọn si wa nilo lati san ọpọlọpọ owo lati ṣe eyi, wọn yoo ṣe.

Ko wa jẹ iyalẹnu rara pe a ni ọpọlọpọ oniwaasu loni ti wọn ti fi otitọ Jesu silẹ lati ma kọ irọ, itan-atẹnudẹnu ati awọn isọkusọ miran ti o fi ara pẹ wọn. Ki o si wa ma wo o, awọn naa ni ọpọlọpọ eniyan ti o n tẹle wọn lọ si ibikibi ti wọn ba dorikọ.

Wayi o, boya iwọ naa ni awọn nkan ti o fẹ gbọ lati ẹnu Ọlọrun tabi awọn adari ijọ rẹ ti o yatọ si otitọ. O le jẹ pe awọn nkan kan wa ti o fẹ ti ẹnu Ọlọrun gbọ lori owo, ibalopọ, ifarajin Kirisitiẹni ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o si yatọ si nkan ti O fẹ sọ fun ọ. Mo fẹ ki o mọ pe o ko le lailai bọ kuro ninu pakutẹ ẹṣẹ ati iku ayafi ti o ba rẹ ara rẹ silẹ lati gbọ ati lati tẹwọgba otitọ ti O n sọ fun ọ. Bẹni, o le lọ lati ori-oke adura de ori-oke tabi lati lati ọdọ wolii de ọdọ wolii. Ṣugbọn niwọn igba ti o ba jẹ wipe nkan ti o fẹ gbọ ko ki i ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ sọ fun ọ amọ nkan ti eti ti o n rin ọ fẹ gbọ, o ko le lailai ni iriri igbala tabi igbega ti o n wa kiri.

Nitorina, ki ni o fẹ gbọ? Ṣe otitọ Ọlọrun ti yoo mu ominira to peye wa sinu aye rẹ ni tabi irọ ati itan arosọ awọn eniyan ti ko ni agbara lati fun ọ ni iranwọ ti o dangajia kankan? Nitemi o, otitọ Ọlọrun ni mo fẹ ma fi gbogbo igba gbọ. Idi si ni yi ti mo fi darapọ mọ Abakuku lati sọ wipe, “Lori ile iṣọ mi ni emi o duro, emi o si gbe ara mi ka ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yoo sọ fun mi, ati esi ti emi o fọ, nigba ti a ba n ba mi wi.” (Ábákúkù 2:1)

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ki ni o fẹ gbọ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Ògún 21, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 15 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 5:12-13

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ

AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 5:12-13

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Lẹta akọkọ Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika jẹ eyi ti a kọ lati fun ijọ wọn ni oriya ni gbigbe igbe aye Kirisitiẹni ati ni mimura silẹ de Jesu Kirisiti Oluwa wa. Bi a ti ṣe ri ninu ọrọ akọsọ rẹ, ijọ awọn ara Tẹsalonika jẹ awokọṣe rere fun gbogbo awọn ijọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wọn ati awọn ti wọn n gburo wọn. Ki si ni idi? Idi ni wipe igbagbọ wọn, ifẹ wọn ati ireti wọn ninu Kirisiti jẹ alaiṣẹtan ati eyi ti o munadoko. Awọn ijọ Tẹsalonika ko ki i ṣe kòṣeku-kòṣẹyẹ, kògbóná-kòtutù. Nṣe ni wọn duro ṣinṣin ninu Jesu lati igba ti wọn ti yipada kuro ninu ibọriṣa lati ma sin Ọlọrun ati lati ma fojusọna fun ijọba ayeraye rẹ. Nitorina, Pọọlu ko kọ lẹta yi si wọn lati ba wọn wi ṣugbọn lati gba wọn niyanju lati tẹramọ igbe aye ti o wu Ọlọrun ti wọn n gbe ati lati ma fi ojoojumọ ṣọna ati wa ni aisun de Jesu Oluwa wa, ẹni ti O n bọ lati gba wa la.

ÌHÀ TÍ Ó TỌ́ SÍ ÀWỌN ADARÍ ÌJỌ

Wayi o, ki Pọọlu to wa pari lẹta yi, o tun gbiyanju lati ba awọn ara ijọ Tẹsalonika sọrọ lori iha ti o yẹ ki wọn kọ si awọn ti o jẹ adari laarin wọn, iyẹn awọn bi pasitọ ati olukọ, wolii, ajinhinrere, diakoni ati bẹẹ bẹẹ lọ ni arin wọn. Wo nkan ti o sọ: “Ṣugbọn awa n bẹ yin, ara, lati maa mọ awọn ti n ṣe laalaa laarin yin, ti wọn n si n ṣe olori yin ninu Oluwa, ti wọn si n kilọ fun yin; Ki ẹ si maa bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ, nitori iṣẹ wọn. Ẹ si maa wa ni alaafia laarin ara yin.” (1Tẹsalonika 5:12-13)

Ki ni awọn aradimu ninu ọrọ ti apọsiteli yi sọ silẹ yi? Akọkọ ni pe a gbọdọ da awọn adari ijọ wa mọ gẹgẹ bi adari wa. Eyi tunmọ si pe ni kete ti a ba n darapọ mọ ijọ Ọlọrun yowu ti a ba darapọ mọ ni a gbọdọ ṣe iwadi lati mọ awọn ti o jẹ adari ni ibẹ. O tunmọ si pe bi ẹnikẹni ba ṣe n darapọ mọ ijọ wa, yala lati ilu ti a wa ni tabi lati agbegbe miran tabi nipasẹ didi atunbi, ojuṣe awa ti a ba kọkọ gba wọn wọle ni lati jẹ ki wọn mọ awọn ti o jẹ adari ni aarin wa, ti wọn n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa, ti wọn n gbadura fun wa, ti wọn si n tọ wa sọna ki a ba le jẹ ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ, ki a si wa ni yiyẹ lati wa pẹlu rẹ ninu ijọba ayeraye rẹ. Ki wa ni idi ti o fi yẹ ki a da awọn adari ijọ wa mọ? Idi naa ni ki a le ba kọ iha ti o tọ si wọn. Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ko ki i fẹ ki ẹnikẹni fi awọn ojiṣẹ rẹ ti O ran lati dari awọn eniyan rẹ ṣere rara tabi ṣe ẹlẹya. Aijẹbẹ, ijiya ti ko ṣe e fẹnusọ le de ba ẹni naa. Fun apẹẹrẹ, a ri bi Miriamu, ẹgbọn Mose, ṣe di adẹtẹ nitoripe o ṣọrọ si pẹlu aibikita. A tun ri bi abo bíà meji ṣe fa awọn ọmọ kekeke mejilelogoji ya pẹrẹpẹrẹ nitori pe wọn fi wolii Eliṣa ṣe ẹlẹya. Ti awọn jagunjagun ọba Iṣiraẹli nkọ, ti ina sọkalẹ lati ọrun, ti o ṣi jo wọn run nitori pe wọn ko ba wolii Elija sọrọ pẹlu ọwọ? (Wo: Númérì 12:1-15; 2Àwọn Ọba 1; Àwọn Ọba 2:23-25) Lotitọ, Ọlọrun ko fẹ ki awọn ojiṣẹ rẹ ṣi aṣẹ ti O fun wọn lori awọn eniyan rẹ lo, aṣẹ ti O fun wọn lati gbe wọn ro dipo lati bi wọn lulẹ (2Kọ́rínntì 10:8&13:10). Ko fẹ ki wọn ma lo aṣẹ yi lati ṣepe, fi ẹnikẹni bu tabi sọ ọrọ odi sinu aye ẹnikẹni. Idi si ni pe eyi lodi si igbe aye ti Jesu pe wa lati gbe ati si ifẹ inu rere Ọlọrun ti O n fi ba awọn ọmọ eniyan lo lati gba wọn la ati lati ri wipe wọn ko parun (Lúùkù 9:51-56). Amọ ṣa o, ti a ko ba kọ bi a ti ṣe n ba awọn ti o jẹ adari wa tabi ojiṣẹ Ọlọrun lo pọ, bi wọn ko tilẹ sọ ọrọ odi si wa, a le ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun ti a ba ri wọn fin tabi ti a ko ba ṣe amojuto wọn bi o ti ṣe tọ.

A ri wipe Ananaya ati iyawo rẹ Safira ku iku ojiji nitori pe wọn pa irọ fun awọn apọsiteli nipa fififunni wọn (Ìṣe Àpọ́sítélì 5:1-11). Ọlọrun nikan lo wa mọ iye awọn ti o ti ku, ti o wa ni idibulẹ aiṣan tabi ti nkan ko lọ deede fun mọ nitori pe wọn n fi ẹtan tabi arekereke ba awọn adari ijọ wọn lo pọ. A tun ri wipe Ọlọrun sọ fun awọn eniyan rẹ lati ẹnu wolii rẹ, Malaki, wipe ọkan pataki lara idi ti ilẹkun ibukun rẹ ṣe ti mọ wọn, ti awọn ajẹnirun si n jẹ orilẹ-ede wọn run ni wipe wọn n fi ebi pa awọn ojiṣẹ rẹ ati awọn miran pẹlu ti O ti pa aṣẹ fun wọn lati ma tọju pẹlu idamẹwa ati ọrẹ wọn. Ọlọrun tilẹ sọ wipe ole ni gbogbo wọn ati wipe abẹ egun ni wọn wa nitori eyi. (Wo: Málákì 3:6-12)

Wayi o, a mọ daju ṣaka wipe a ko pa awọn aṣẹ ti a pa fun awọn Juu yi fun awọn awa ti a jẹ Kirisitiẹni nipa idamẹwa ati ọrẹ. A si tun mọ wipe a ko si ni abẹ egun kankan nitori iṣẹ irapada Jesu fun wa. Ṣugbọn awa naa le ti ilẹkun igbadun ibukun Ọlọrun mọ ara wa tabi ki a si ilẹkun aye wa silẹ fun awọn ajẹnirun lati jẹ wa run ti a ko ba mu aṣẹ ti Jesu pa fun wa lori titọju awọn ojiṣẹ rẹ si wa lo, bi o ti tọ ati bi o ti yẹ. (Wo: Luuku 10:1-7; 1Kọ́rínntì 9:13-14; Gàlátíà 6:6; Fílípì 4:14-19; 1Timoti 5:17-18)

Ni kukuru, Pọọlu sọ fun awọn ara Tẹsalonika pe o ṣe pataki ki wọn da awọn adari ijọ wọn mọ ki wọn ba le kọ iha ti o tọ si wọn. Irufẹ iha si ni o yẹ fun wọn lati kọ si wọn? Iha ẹni ti a n bu ọla fun gigigidi ni a gbọdọ kọ si wọn. Ki si ni idi? Ṣe nitori pe wọn ṣe pataki niwaju Ọlọrun ju wa lọ ni tabi ṣe nitoripe igbala ti wọn ṣe iyebiye loju Ọlọrun ju ti wa lọ ni? Rara o! Wọn ko ṣe pataki si Ọlọrun ju wa lọ, bẹẹ si ni igbala wọn ko ṣe iyebiye loju rẹ ju ti wa lọ. Amọ, gẹgẹ bi ọrọ Pọọlu, nitori iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun wọn lati ṣe laarin wa ati nitori wa, a gbọdọ bu ọla fun wọn gidigidi.

Bawo wa ni ki a ṣe ma bu ọla fun wọn? Ṣe ki a sọ wọn di oriṣa akunlẹbọ laarin wa ni? Rara o! A bi ṣe ki a gbe gbogbo iṣakoso aye wa le wọn lọwọ ni, ki a ma si le da inu ro tabi ṣe ohunkohun tí kò bá jẹ́ wípé wọn sọ pe ki a ṣe e? Rara o! O wa ṣeni laanu pe ọpọ loti ṣi eyi tunmọ, ti wọn si ti sọ awọn adari ijọ wọn di ọriṣa lori aye wọn, ti wọn n bọ wọn, ti wọn si n fi wọn si ipo ti o tọ si Ọlọrun nikan ninu aye wọn. Awọn ti o wa n ṣe eleyi ati awọn ti a n ṣe e si ko le ṣalai ma jẹ iya nkan ti wọn n ṣe lẹkunrẹrẹ, ni ibamu pẹlu idajọ Ọlọrun lori wọn.

Bibu ọla gidigidi fun awọn adari wa ni i ṣe pẹlu ki a kọkọ ma fi gbogbo igba bọwọ fun wọn. Eyi si gbọdọ farahan ninu iru ọrọ ti a o ma sọ si wọn tabi sọ nipa wọn. Ekeji, o ni i ṣe pẹlu ki a tẹriba fun wọn, ki a si ma tẹle ọrọ wọn, niwọn igba ti nkan ti wọn n kọ wa ba ti wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Ko ni itumọ ki a sọ wipe a bọwọ fun eniyan, ki a si ma mu ọrọ rẹ ni pataki. Itanraẹnijẹ lasan ni eyi. Nitorina, ti o ko ba ki i tẹle ọrọ Ọlọrun ti awọn adari rẹ ninu ijọ n ba ọ sọ, a jẹ wipe o ko si lara awọn ti o n bu ọla fun wọn niyẹn. Nṣe ni o n jẹ ki iṣẹ wọn nira si. Eyi ko si le gbe ọ rara. (Wo: Heberu 13:17)

Ẹkẹta, bibu ọla fun awọn adari ijọ wa ni i ṣe pẹlu ki a ma tọju wọn gẹgẹ bi aṣẹ Jesu Kirisiti fun wa. Ẹkẹrin, o ni i ṣe pẹlu ki a ma ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ. Ti a ba si gbagbọ lotitọ ninu wọn ati ninu iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun ran wọn lati ṣe, ko yẹ ki a nilo ẹnikankan lati ṣẹṣẹ ma kọ wa pe o ye ki a ma fi gbogbo igba wo ọna ti a fi le tọju wọn ati ti a fi le jẹ ki iṣẹ iranṣẹ wọn rọrun si fun wọn.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu ijọ loni ni oye nkan wọnyi ko ye. Nitorina, o rọrun fun wọn lati sọrọ sakala si awọn adari ijọ wọn tabi nipa wọn. O si tun rọrun fun wọn lati ma a wo wọn ki ebi ma a pa wọn, tabi ki iya ma a jẹ awọn ati ẹbi wọn. Ọpọ ninu ijọ lo tilẹ la oju wọn silẹ, ti wọn ko si ri nkankan ti wọn le ma mu ṣe lati tọju awọn adari ijọ wọn tabi lati ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ. Ko di igba ti awọn adari wa ba to sọ fun wa pe ki a fun wọn ni owo tabi ra aṣọ, ounjẹ, bata, ọkọ ati bẹẹbẹẹ lọ fun wọn ki a to mọ pe ojuṣe wa ni awọn nkan wọnyi. O ṣi yẹ ki a ma ṣe wọn ni ibamu pẹlu bi nkan ini wa ti ṣe pọ to. Ko si yẹ ko di igba ti wọn ba sọ fun wa pe ki a ba wọn fọ ọkọ ayọkẹlẹ wọn tabi tun ile tabi ọ́fìsì wọn ṣe tabi ba wọn kọ iwe tabi ba wọn wo awọn ọna ti iṣẹ iranṣẹ wọn ṣe le tan kalẹ si ki a to mọ pe ojuṣe wa ni lati ma ṣe awọn nkan wọnyi fun iranlọwọ iṣẹ iranṣẹ wọn.

Amọ, nitori pe ọpọ ninu awọn ijọ wa loni ni oye ko ye, dipo ki a ma bọwọ fun awọn adari wa, ki a si tun ma lakaka lati ri pe iṣẹ iranṣẹ wọn rọ wọn lọrun, nṣe ni a o ma lepa lati tabuku wọn ati lati fi wọn ṣe ẹlẹya. Awọn ti ko si tabuku tabi fi wọn ṣe ẹlẹya le ma ni nkankan pato ti wọn n ṣe lati ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ. Nitorina, awọn adari wọn ko sin wọn pẹlu inu didun, ayọ ati oriya. Abalajọ ti ọpọ ijọ Ọlọrun loni ṣe wa ni ipo iṣẹ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Abalajọ pẹlu ti ọpọ adari ijọ ṣe sọ ara wọn di ole, ọlẹ ati olojukokoro, ti wọn a si ma ṣe oniruuru nkan ti ko tọ lati pese fun ara wọn ati ile wọn. Amọ ṣa o, ijiya n bẹ fun adari naa tabi ọmọ ijọ naa ti o mọ ojuṣe rẹ ninu ijọ ti ko si ṣe tabi ti ko lepa lati mọ ojuṣe rẹ ki o ba le ṣe e. (Wo: Luuku 12:47-48)

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ

Iha ti awọn ọmọ Ọlọrun ba kọ si awọn adari wọn ninu ijọ ni ipa ti o ga lati ko lori idagbasoke ati ilọsiwaju nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Nitorina, o ṣe pataki ki a da awọn adari ijọ wa mọ, ki a si tun ma fi gbogbo igba kọ ati lepa lati kọ iha ti o tọ si wọn ati si iṣẹ iranṣẹ wọn. Aijẹbẹ, a le ma kuro ni ipo aràrá nipa ti ara ati nipa ti ẹmi titi Jesu Oluwa wa yoo fi de tabi ti akoko wa ni aye yi yoo fi wa si opin.

ÌBÉÈRÈ

Mẹnuba awọn ọna ti o ro wipe awọn ọmọ Ọlọrun le ma gba lati ran iṣẹ iranṣẹ awọn adari ijọ wọn lọwọ. – Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi? Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 5:12-13 Read More »

Ariwo irọ́ | Pst. J.O. Lawal | Ògún 7, 2022 | Vol. 11, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu inu didun ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu yi, oṣu Ògún 2020. Adura mi si ni pe ki a fun ọ ni okun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati yi pada kuro ninu ohunkohun ti ko wa ni ibamu pẹlu igbe aye tuntun ti a pe ọ lati gbe ninu Kirisiti Jesu. Amin.

Ninu lẹta Pọọlu keji si Timoti, o sọ eyi fun: “Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni edidi yi wipe, Oluwa mọ awọn ti iṣe tirẹ. Ati ki olukuluku ẹniti n pe orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.” (2Timoti 2:19) Kini awọn koko ti o jẹ jade ninu ọrọ iyanju yi? Akọkọ ni pe otitọ Ọlọrun ko ki i yi pada rara. Bakan naa ni yoo ma wa, bi o ti wu ki igba tabi ibi ti a wa ri. Nitorina, nkan ti Ọlọrun sọ nipa ododo ko ni lailai yi pada. Nkan ti O si tun sọ nipa ẹṣẹ naa ko ni lailai yi pada.  O wa ku si ọwọ wa lati yan lati duro lori ọrọ rẹ nipa awọn nkan wọnyi tabi lati tẹle ero ti ara wa.

Koko ekeji ti Pọọlu fẹ ki a di mu ni pe Ọlọrun mọ awọn ti o jẹ tirẹ ati awọn ti ko jẹ tirẹ daradara. Ko si igba ti ko le ya awọn tirẹ sọtọ laarin awọn ọpọ eniyan. Ranti pe ko ṣoro fun rara lati ya Noa ati idile rẹ sọtọ kuro laarin awọn ara aye igba tirẹ. Ko si tun ṣoro fun lati ya Lọọti ati idile rẹ sọtọ kuro laarin ilu Sodomu ati Gomora. Bẹẹ si ni, ko ṣoro fun lati ya ẹgbẹrun meje eniyan ti o jẹ tirẹ sọtọ fun ara rẹ ni akoko ti Ọba buruku ni, Ahabu, wa lori itẹ, bi o tilẹ jẹ pe gbogbo ilẹ naa ni ibọrisa ti gba kan ni igba naa. (Wo: Jẹnẹsisi 6; Jẹnẹsis 19; 1Awọn Ọba 19)

Nitorina, ko ki i ṣe iṣoro ni fun lati mọ awọn ti o jẹ tirẹ ni orilẹ-ede yi, bi o tilẹ jẹ wipe iye wa ti kọja igba miliọnu eniyan. Ti ko ba wa jẹ iṣoro fun Ọlọrun lati mọ eyi, o yẹ ki o mọ pe ko ki i ṣe iṣoro ni fun rara lati mọ iye awọn ti o jẹ tirẹ ninu ilu yi ati ninu ijọ yi. Ibere ti o kan yẹ ki a bere ni eyi: Njẹ Ọlọrun ri ọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ ninu ilu yi ati ninu ijọ yi? Njẹ iwọ gan tilẹ mọ ara rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ? Ọrọ yi si kọja ki o ma ṣe tokíní-tokéjì. Ti o ko ba ti mọ, a jẹ wipe o ko mọ naa niyẹn. 

Ki a ma fọrọgun, Ọlọrun mọ pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn n pe ara wọn ni Kirisitiẹni tabi ti wọn n lọ fun ipade ni sọọsi tabi ti wọn n fi ede fọ tabi ti wọn n sọ tẹlẹ tabi ti wọn n ṣiṣẹ iyanu naa ni wọn jẹ tirẹ. Jesu fi igba kan sọ fun awọn ti o wa gbọ iwaasu rẹ pe: “Ki iṣe gbogbo ẹniti npe mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣẹ ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun. Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi le awọn ẹmi eṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigbana li emi o si wi fun wọn pe Emi ko mọ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹṣẹ.” (Matiu 7:21-23) 

Njẹ o ri bayi? Ọpọ ti o n lọ si ipade sọọsi, ti o n jẹ orukọ ti a mu lati inu bibeli tabi ti o n ṣe oniruuru iṣẹ ni orukọ Jesu ni yoo ba ara wọn ka àánú nigba ti Oluwa wa ba de. Idi si ni pe ko mọ wọn gẹgẹ bi eniyan rẹ. Ki si ni idi? Idi naa ni pe wọn ko fi ara wọn jin fun ifẹ rẹ. Bi Pọọlu ti ṣe sọ fun wa ninu ọrọ iyanju rẹ si Timoti yẹn, gbogbo awọn ti o n ke pe orukọ Jesu ni o gbọdọ yipada kuro ninu iwa ika, ki wọn si fi ara wọn ji fun ododo. Eyi jẹ dandan fun wọn lati ṣe. Aijẹbẹ, ariwo irọ ni wọn n pa pe awọn jẹ ti rẹ.

Ṣe o wa le jẹ pe ariwo irọ ni awa naa n pa pe a jẹ ti Jesu bi? Ṣe o le jẹ wipe gbogbo igba ti Ọlọrun ba wo wa, oju ti O fi n wo wa ni oju awọn ti wọn n tan ara wọn jẹ, awọn ti wọn n tan ara wọn jẹ lori ifarajin wọn si? Oju ti O si fi n wo wa niyẹn, niwọn igba ti a ba kọ lati yi pada kuro ninu agbere, ojukokoro, igberaga, agabagebe, irọ pipa, iṣeṣo tabi iwa ika miran ti awọn eniyan ma n wu, bi o tilẹ jẹ wipe a n ke pe orukọ Jesu.

Wayi o, ọrọ Ọlọrun n tọ wa wa bayi, o si n sọ fun wa pe ki a dẹkun lati ma tan ara wa jẹ, ki a si dojukọ eyi ti n ṣe otitọ nipa ọrọ aye wa, ki Ọlọrun ba le gba wa la lotitọ kuro lọwọ awọn nkan ti o ti n pa aye wa run. Adura mi si ni pe ki a ya ọkan rẹ ya ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu itanra-ẹni-jẹ, ti o ba ṣe pe o n tan ara rẹ jẹ, ki o ba le jọwọ ara rẹ lotitọ fun Jesu Kirisiti Oluwa wa, ki o si ni iriri agbara igbala rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ ayọ.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ariwo irọ́ | Pst. J.O. Lawal | Ògún 7, 2022 | Vol. 11, No. 14 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ AYỌKA | ỌJỌ́RÚ 10, ÒGÚN 2022

ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 5:1-111

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ, a ri wipe ko tọ ki awọn Kirisitiẹni ma banujẹ bi awọn alaigbagbọ lori awọn eniyan ti o ba ku tabi ti o ti ku, paapaa julọ ti awọn ti a n sọ yi ba jẹ Kirisitiẹni. Eyi ko wa tunmọ si pe wọn ko lẹtọ lati banujẹ rara. Wọn lẹtọ lati banujẹ. Amọ wọn ko gbọdọ banujẹ bi awọn ti ko ni ireti bibọ Jesu ati bibọ awọn ti o sun ninu rẹ ni opin ohun gbogbo. Jesu n padabọ pẹlu awọn ti o ti sun ninu rẹ. Awa ti a si jẹ tirẹ ti a ba wa laye nigba ti O ba de yoo ri wọn, a o si gba wa soke lati darapọ mọ wọn titi lailai. Nkan ti bibeli fi ye wa ni eyi. Amọ, igba wo ni eyi yoo ṣẹlẹ? Bi ọpọ wa ti ṣe mọ, oniruuru awọn eniyan ni wọn ti dide ni oniruuru akoko, ti wọn si sọ wipe awọn mọ ọjọ ti Jesu n bọ wa. Ṣugbọn irọ ati ofo ni ipolongo ati isọtẹlẹ wọn jasi. Ki lo fa? Nkan ti o fa naa ni pe Jesu Oluwa wa funrarẹ ti jẹ ki a mọ wipe ko si ẹni ti o mọ ọjọ tabi akoko ti Oun yoo pada de. Nitorina, tiwa kọ ni ki a mọ igba ti yoo de; tiwa ni ki a mura silẹ de e, igbakugba ti O ba wu ki O de. (Wo: Matiu 24:36-44)

BI OLE LORU
Eyi wa ni Pọọlu tẹsiwaju lati ran awọn ara Tẹsalonika leti ninu abala lẹta rẹ ti a n gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:

“Nisinsinyii, ara, a ko nilo lati kọ iwe si i yin mọ nipa akoko ati igba, nitori ẹyin paapaa mọ wi pe ọjọ Oluwa yoo waa bi ole loru. Ni akoko gan an ti awọn eniyan yoo maa wi pe, “Alafia ati aabo,” nigba naa ni iparun ojiji yoo de sori wọn gẹgẹ bi irọbi obinrin ti o loyin, wọn ko si ri ibi aabo lati sa si. Ṣugbọn ẹyin ara, ko si ninu okukun nipa nnkan wọnyi ti ọjọ Oluwa yoo fi de ba yin bi ole. Nitori gbogbo yin ni ọmọ imọlẹ ati ọmọ ọsan gangan. Ẹ ki i ṣe ti oru tabi ti okunkun mọ.” (1Tẹsalonika 5:1-5)

Ki ni awọn nkan ti a ri dimu ninu ọrọ iyanju Pọọlu yi? Akọkọ ni pe ko si ẹni ti o mọ ọjọ tabi wakati ti Jesu yoo pada de pẹlu awọn ayanfẹ rẹ ti o ti sun ninu rẹ. Nitorina, ti ẹnikẹni ba jẹ ki ẹnikẹni tan oun jẹ lori ọrọ yi, a jẹ wipe o mọn-ọn-mọn kọ eti ikún si nkan ti a kọ silẹ ninu ọrọ Ọlọrun ni.

Bi Pọọlu ti ṣe fi ye, ọrọ Jesu Oluwa wa funrarẹ ni pe dide Oun yoo dabi dide ole loru. Ni akoko ti awọn eniyan ro pe ibalẹ-ọkan ti wa, ti wọn ro wipe wọn ti n rojutu ọrọ aye yi ni Oun yoo de, ti iparun yoo si wa sori wọn. Jesu Oluwa wa tilẹ fi ye wa pe bi nkan ti ṣe ri ni igba aye Noa ni yoo ti sẹ ri ni igba ti Oun naa ba pada de. Ko ni si nkan ti yoo fu awọn eniyan lara pe dide rẹ ti wa ni ẹnu ọna wọn. Awọn miran ti o gbagbọ gan yoo ti bẹrẹ si ni fi ẹnu wọn kẹgan ati sọ isọkusọ pe Jesu ko ni pada wa kankan, pe erémọdé lasan ni gbogbo nkan ti a n sọ (2Peteru 3:3-4). Ṣugbọn, boya wọn fẹ tabi wọn kọ, Jesu yoo pada wa lati mu awọn ayanfẹ rẹ, lati ṣe idajọ aye ati lati fi idi ijọba ayeraye Ọlọrun mulẹ ninu aye tuntun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa.

Nkan ekeji ti Pọọlu fẹ ki o yẹ awọn ara Tẹsalonika yi ati awa naa pẹlu ni pe bibọ Jesu ko ni lati dabi wiwa ole loru fun awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun. Lotitọ, a ko mọ ọjọ tabi akoko ti yoo de. Amọ O ti sọ fun wa pe o di dandan ki Oun pada wa lati mu wa sọdọ rẹ. O si tọ oniruuru iṣẹlẹ ti yoo ma ṣẹlẹ laye ti yoo ran wa lọwọ lati kiyesi pe O ti de tan. Nitorina, ti dide rẹ ba tun wa ba wa ni ojiji, a jẹ wipe a ko mọ nkan ti a n ṣe niyẹn.

Gẹgẹ bi alaye apọsiteli yi, awa ọmọ Ọlọrun ko si ninu okunkun rara lori ọrọ yi. Inu imọlẹ ni a wa. Ọmọ imọlẹ ati ọmọ ọsan gangan ni a si jẹ. Nitorina, awọn nkan ti yoo ṣẹlẹ si aye yi ati awọn ti o wa ninu rẹ ko ṣokunkun si wa rara. Bẹẹ si ni, awọn nkan ti yoo ṣẹlẹ si ọrun ti a n wo yi ati si ijọba Satani ati awọn ẹmikẹmi rẹ ko ṣokunkun si wa. A ti sọ wọn fun wa ki o ti di wipe wọn yoo bẹrẹ si ni ṣẹlẹ. Ti a ba si wa gba awọn nkan wọnyi gbọ, a gbọdọ bẹrẹ si gbe aye wa ni ibamu pẹlu wọn.

Nigba ti Ọlọrun kilọ fun Noa, ti O si sọ nkan ti yoo ṣẹlẹ si aye ati awọn ti o n gbe inu rẹ fun, ko kan fọwọ lẹran, ki o joko tẹtẹrẹ, ki o si ma woran. Nṣe ni o gbe igbese ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun lati gba ẹmi rẹ ati ẹmi awọn ara ile rẹ la. Nitorina, ti awa naa ba gba nkan ti Jesu ati awọn apọsiteli ati wolii rẹ igbani ba wa sọ lori bibọ rẹ ati lori opin ohun gbogbo, o di dandan ki a fi ojoojumọ bẹrẹ si ni murasilẹ de e. Eyi lo fa ti Pọọlu tun ṣe sọ eyi fun wa:

“Nitori naa, ẹ kiyesara yin ki ẹ ma ṣe sun bi awọn ẹlomiran. Ẹ maa ṣọna ki ẹ si maa pa ara yin mọ. Nitori awọn ti wọn n sun, a maa sun ni oru, awọn ẹni ti n mu amupara, a maa mu un ni oru. Ṣugbọn awa jẹ ti imọlẹ, ẹ jẹ ki a pa ara wa mọ, ni gbigbe igbagbọ wọ ati ifẹ bi awo igbaaya ni oru ati ireti igbala bi asibori. Nitoripe, Ọlọrun ko yan wa lati da ibinu rẹ gbigbona si ori wa, ṣugbọn o yan lati gba wa la nipasẹ Oluwa wa Jesu Kirisiti. Jesu ku fun wa ki a le ba a gbe titi laelae. Eyi yoo ri bẹẹ yala a sun tabi a wa laaye pẹlu rẹ. Nitori naa, ẹ maa gba ara yin niyanju, ki ẹ si maa gbe ara yin ro, gẹg bi e ti n ṣe.” (1Tẹsalonika 5:6-11)

Njẹ o ri bayi? Ojuṣe ẹnikọọkan awa ti a jẹ Kirisitiẹni ni lati ma a ṣọna ati lati ma a mura silẹ de Jesu Oluwa wa. A wa ni a gbọdọ ri wipe a ko sun lọ rara nipa fifi aye gba ẹṣẹ ati ainitara fun Ọlọrun laaye ninu aye wa. A si le ṣe eyi nipa diduro ṣinṣin ninu igbagbọ, ifẹ ati ireeti wa. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, Ọlọrun ko ya wa sọta lati da ibinu gbigbona rẹ le wa lori. Dipo eyi, nṣe ni o ya wa sọtọ lati gba wa la nipasẹ Jesu Oluwa wa, boya a wa laaye nigba ti O ba de tabi a ti sun ninu rẹ. Nitorina ni o ṣe yẹ ki a wa ni imurasilẹ de e, ki a si ma gba ara wa niyanju pẹlu awọn ọrọ itunu yi titi yoo fi de e.

ỌRỌ IPARI
Noa, nigba ti a kilọ fun nipa ohun ti o bọ wa sori aye ati awọn ọmọ eniyan, mura silẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o gbọ. Idi niyi ti ikun omi ko fi gbe oun ati awọn idile rẹ lọ. Ti ko ba wa mura silẹ, ti ikun omi si de ba a, njẹ yoo lẹtọ lati sọ wipe ojiji ni iparun de ba oun bi? Ko ni lẹtọ lati sọ eyi rara. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ri fun awa ti a jẹ Kirisitiẹni naa. Ipadabọ Jesi Oluwa wa ko gbọdọ ba wa ni ojiji rara. Idi si ni pe a ti sọ fun wa tẹlẹ pe O n bọ wa ati pe ki a mura silẹ de e. Nitorina, ojuṣe kan gbogi ti a ni bayi ni pe ki a ma fi gbogbo igba wa ni imurasilẹ de e, nitori a ko mọ igba tabi akoko ti O le de.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ AYỌKA | ỌJỌ́RÚ 10, ÒGÚN 2022 Read More »

Wọn bẹbẹ lati fífúnni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 7, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ògún 2022. Mo si gbadrua pe ki Ọlọrun jẹ ki o tayọ ninu ohun rere gbogbo ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ti ọdun yi yoo fi pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Pọọlu si awọn ara Kọrinnti nipa awọn ara Masidonia, eyi ti o wipe: “Pẹlupẹlu, ara, awa n sọ fun yin ni ti oore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun awọn ijọ Makedonia. Bi o ti jẹ pe a dan wọn wo nipa ipọnju, ọpọlọpọ ayọ ati idegongo aini wọn ti kun a kun wọ silẹ ninu ọrọ ilawọ wọn. Nitori mo jẹrii pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, wọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn. Wọn n fi ẹbẹ pupọ rọ wa ni ti ẹbun atinuwa yii, lati ba a le ni ipin ninu iṣẹ-iranṣẹ fun awọn eniyan mimọ. Ati eyi, ki i ṣe bi awa ti ro ri, ṣugbọn wọn tete kọ fi awọn funra wọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun.” (2Kọrinnti 8:1-5)

Kini idi ti Pọọlu fi sọ nkan wọnyi nipa awọn ara Masidonia fun awọn ara Kọrinnti? Idi ni pe o fẹ ki wọn fi wọn ṣe awokọṣe. Ki si ni o fẹ ki wọn ti ara awọn ara Masidonia yi kọ? Ohun naa ni ifarajin wọn lati lawọ si iṣẹ Oluwa. Dajudaju, akoko kan wa ti awọn ijọ Ọlọrun ti igba aye bibeli n ṣe ìkówójọ fun iṣẹ rẹ ati lati ran awọn eniyan rẹ kan lọwọ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe akoko yi jẹ akoko ọ̀dá burúkú fun awọn ara Masidonia, wọn si papa fifunni.

Ki a tilẹ sọ otitọ, nkan mẹta pataki ni Pọọlu sọ ninu ẹsẹ bibeli ti o wa ni oke yi nipa iha ti awọn ara yi kọ si fififunni ni akoko yi. Akọkọ, o sọ wipe wọn fifunni pẹlu ayọ akunwọsilẹ. Nitorina, aini wọn yọri si ìlawọ́ ti o jọjú. Eyi wa jẹ kayefi. Bawọ ni aini ṣe le yọri si lilawọ? Ni kukuru, bi Pọọlu ti ṣe fi han wa, nigba ti ẹniyan ba ni ayọ akunwọsilẹ, bi o tilẹ wa ni ipo aini, sibẹsibẹ yoo wa ọna lati lawọ ati lati fifunni. Nitorina, ti o ko ba lawọ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe ayọ Oluwa ninu rẹ ko kun tabi ki o ma ṣan wọ silẹ.

Ekeji, Pọọlu sọ wipe awọn eniyan yi fifunni kọja agbara wọn. Lotitọ, afiwe lasan ni eyi, nitori ko si ẹni ti o le fun eniyan ni ikan ti ko ba ni. Nitorina, nkan ti Pọọlu n sọ ni pe awọn ara yi ya gbogbo eniyan lẹnu nipa fififunni wọn. Wọn lawọ lati fifunni kọja nkan ti gbogbo awọn eniyan ro wipe wọn yoo ṣe, pẹlu bi asiko ti ṣe ri fun wọn. Eyi, lẹẹkansi, si ri bẹ nitoripe ọkan wọn kun fun ayọ akunwọsilẹ lati fifunni.

O wa bani-ninujẹ loni pe ọpọ ninu ijọ lo ma n fi gbogbo igba wa ọna lati fi nkan yowu ti wọn ba ri fun iṣẹ Ọlọrun, fun awọn adari wọn ati fun awọn ara wọn ti o wa ni ipo aini. Idi si ni pe fififunni ko wu wọn lori. Wọn ri gẹgẹ bi ajaga ti ko ni idi ti Ọlọrun kan mọn-ọn-mọn gbe le aye wọn lori. Boya nṣe ni iwọ naa ri lilawọ si iṣẹ Oluwa gẹgẹ bi ajaga ti ko ni idi. Awọn ara Masidonia ko ri bayi rara. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn ri gẹgẹ bi nkan ayọ lati fifun Oluwa ati awọn eniyan Rẹ. Bi o si ti yẹ ki o ri gan an ni eyi, nitori ti a ba ri bi nkan ayọ lati ri gba lọwọ Oluwa, nṣe ni o tun yẹ ki a ri bi nkan ayọ lati fifun un tabi fifun ẹni yowu ti O ba fẹ ki a fifun.

Nkan ẹkẹta ti Pọọlu mẹnuba nipa awọn ara Masidonia ni pe wọn pẹlu itara ni wọn ṣe fifunni. Gẹgẹ bi o ti fi ye wa, nṣe ni awọn ara yi n bẹbẹ ki a fun wọn ni anfaani lati fifunni ni akoko ti n sọ yi. NJẸ IWỌ TI WA BẸBẸ RI LATI FIFUN OLUWA? Ni kukuru, awọn ara yi bẹbẹ. Ki si ni idi ti wọn ṣe bẹbẹ lati fifunni? O ṣeeṣe ki o jẹ wipe apọsiteli yi ko fẹ ki wọn kopa ninu fififunni ni akoko yi nigba ti o wo bi nkan ṣe ri fun wọn. Ṣugbọn wọn ko fẹ ṣe alaikopa ninu ibukun ti o sorọ mọ fififunni ati ririgba. Nitorina, wọn bẹ ẹ lati jẹ ki awọn naa kopa ninu ọrọ naa. Nigba ti a si gba wọn laaye lati ṣe bẹ ẹ, wọn fifunni ni ọna ti o kọja ireti awọn eniyan.

O wa ṣeni laanu wipe ọpọ ninu wa loni ni yoo ṣe ohun yowu ti ba le ṣe lati ma kopa ninu fififunni ninu awọn ijọ wa. Fun apẹrẹ, ti aṣọna kan ba ṣèèṣì gbe apo ọrẹ kọja wa ninu ipade ijọ kan, o ti kọja lọ naa niyẹn – a ko ni fi nkankan silẹ fun iṣẹ Ọlọrun mọ. Nkan ti a ko wa mọ ni wipe bi a ti ṣe n wa ọna lati má kopa ninu lilawọ si iṣẹ Ọlọrun ati si awọn ti O fẹ ki a fifun, bẹẹ naa ni awọn àjẹmọ́nú ti o sorọ mọ fififunni yoo ṣe ma wa ọna lati yago fun wa. Ọrọ Ọlọrun wa n tọ wa wa bayi, o si n sọ fun wa pe ki a yi iwa wa pada, ki a si kẹkọ lara awọn ara Masidonia dipo ti a o fi ma fi gbogbo igba wa àwáwí lati ma kopa ninu fififun iṣẹ Oluwa. Bẹẹni, ni igba miran, o le ma rọrun fun wa lati fifunni, bi ko ti ṣe rọrun fun awọn ara Masidonia naa ni akoko ti a n sọ yi. Ṣugbọn ti ọkan wa ba tọ, bi ọkan ti awọn ara yi ṣe tọ, a o fifunni pẹlu ayọ ati ni ẹkunrẹrẹ. Ọlọrun yoo si tẹwọgba ẹbun wa ni ibamu pẹlu nkan ti a ni dipo ni ibamu pẹlu nkan ti a ko ni. Ki o ni ọsẹ aladun. Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọn bẹbẹ lati fífúnni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 7, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 14 Read More »