Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ Kínní | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:13-18 | ỌJỌ́RÚ 03, ÒGÚN 2022

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:13-18 ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika, a ri wipe o ṣe pataki ki ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni fi ara rẹ jin fun gbigbe igbe aye ti o wu Ọlọrun. Idi si ni wipe nkan ti a da wa fun ni eyi. Ṣugbọn ti a ko ba mọ awọn nkan ti o sorọ mọ gbigbe igbe aye yi, bi a tilẹ ni lọkan lati gbe e, a ko ni gbe e. Eyi si wa lara idi ti Pọọlu ati awọn yoku rẹ ninu iṣẹ iranṣẹ ṣe fi ara balẹ kọ awọn ara Tẹsalonika ni awọn nkan ti wọn nilo lati mọ nipa gbigbe igbe aye ti o wu Ọlọrun. Bi a si ti ri ninu lẹta yi, igbe aye ti o wu Ọlọrun jẹ igbe eye aileri, igbe aye ifẹ ati igbe aye ẹni ti o to oju bọ. Amọ ṣa o, aye yi kọ ni ohun gbogbo pari si fun Kirisitiẹni. Ijọba ayeraye Ọlọrun si n bọ wa fi idi mulẹ ni akoko ti O ti yan. Eyi si jẹ nkan ti ẹnikọọkan wa gbọdọ mura silẹ de. Ṣugbọn, niwọn igba ti a ko mọ ọjọ tabi akoko ti eyi yoo waye, ko si ni ki awọn ara wa kan ma sun ninu Oluwa ki akoko yi to de. Ọpọlọpọ ni o si tun sun ninu rẹ tabi ku fun oniruuru idi. Bawo wa ni o ṣe yẹ ki a tẹwọgba eyi, gẹgẹ bi Kirisitiẹni? Nkan ti Pọọlu n ba awọn ara Tẹsalonika sọrọ le lori ni eyi ninu abala lẹta rẹ ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. O si ṣe pataki ki a kọbiara si, ki a si ma ṣe amulo rẹ, ki gbogbo idamu, wahala ati iku ti o sọrọ mọ gbigbe aye yi ma ba fi irẹwẹsi sọkan wa, ki wọn si jẹ ki a yẹ ẹsẹ ninu irinajo igbagbọ wa.

MÁ ṢE ṢE BÍ ÀWỌN TÍ KÒ NÍ ÌRÈTÍ

Wayi o, ninu lẹta rẹ si awọn ara Éfésù, ori ikeji, Pọọlu jẹ ki o ye wa pe ẹnikẹni ti ko ba ni Jesu, ko ni ireti ifọkanbalẹ tabi igbadun kankan kọja aye ti a wa yi (Éfésù 2:12). Aye yi ni gbogbo igbadun, ifọkanbalẹ ati aye jijẹ rẹ mọ. Lẹyin eyi, idajọ ti o tọ si awọn ti ko mọ Ọlọrun ni yoo ba pade. Eyi yoo si yọri si ipọnju ati irora ayeraye, eyi ti ko ṣe fẹnusọ fun. Amọ bawo wa ni ti Kirisitiẹni ti ṣe jẹ? Ṣe inu aye yi naa ni gbogbo igbadun tabi ifọkanbalẹ rẹ mọ bi? Rara o! Aye yi kọ ni igbadun rẹ mọ. Ṣugbọn aye yi ni gbogbo irora, aibalẹọkan, ẹkun, ijakulẹ, oṣe ati idamu yowu ti o le ba pade mọ. Idi si ni pe Ọlọrun ti pese aye silẹ fun ninu ijọba ayeraye rẹ, eyi ti o n bọ wa. A sọ eyi nipa ijọba yi ninu iwe ifihan: “Mo si gbọ ohun nla kan lati ori itẹ ni wa, n wi pe, Kiyesi i, agọ Ọlọrun wa laarin awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbe, wọn o si maa jẹ eniyan rẹ, ati Ọlọrun tikararẹ yoo wa pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nu kuro ni oju wọn; ki yoo si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.” (Ìfihàn 21:4-5)

Nitori eyi, Kirisitiẹni ni gbogbo idi lati foju sọna fun ọjọ yi, ọjọ ti ilẹ yoo mọ, ti yoo si bọ sinu ile ayọ ayeraye ti Ọlọrun ti pese silẹ fun. Amọ ṣa o, niwọn igba ti o ba si wa ni aye yi, ti Jesu ko si ti de, ko si bi ko ṣe ni ba ara rẹ ni awọn asiko ti yoo sọrọ mọ pipadanu awọn ẹni ti o fẹran tabi ti o sunmọ gidigidi sọwọ iku, bi awọn wọnyi tilẹ jẹ Kirisitiẹni. O le jẹ nipasẹ aisan, ogun, ijamba, inunibini tabi ajalu. O tilẹ le jẹ wipe awọn ti a n sọ yi ti dagba, ti wọn si ti da arugbo ki wọn to kun. Ṣugbọn a ko le fẹ iru rẹ ku nitoripe aye ti a wa ninu rẹ jẹ eyi ti ko ni wa titi lailai. Bẹẹ si ni awa ti a wa ninu aye naa ko ni wa ninu rẹ titi lailai. O di dandan ki a kuro ninu rẹ lọjọ kan, boya nipasẹ iku ni o tabi nipasẹ bibọ Jesu. Ti a ba wa ri pe eniyan wa kan fi aye silẹ, ko yẹ ki a ṣe bi awọn ti ko mọ Ọlọrun ti ṣe n ṣe rara. Nṣe ni o yẹ ki a ṣe bi ẹni ti o ni imọ ati imoye nkan ti Ọlọrun ti sọ nipa ayeraye ti o n bọ, yala fun awọn ti o gba a gbọ tabi awọn ti ko gba a gbọ.

Eyi si ni Pọọlu fẹ ki o ye awọn ara Tẹsalonika ninu abala lẹta rẹ ti a n gbe yẹwo bayi. Wo nkan ti o sọ lori rẹ:

“Ṣugbọn awa ko fẹ ki ẹyin ko jẹ ope, ara, ni ti awọn ti o ti sun, pe ki ẹ ma banu jẹ gẹgẹ bi awọn yooku ti ko ni ireti. Nitori bi awa ba gbagbọ pe Jesu ti ku, o si ti ji dide, gẹgẹ bẹẹ ni Ọlọrun yoo mu awọn ti o ti sun pẹlu ninu Jesu wa pẹlu ara rẹ. Nitori eyi yii ni awa n wi fun yin nipa ọrọ Oluwa, pe awa ti o wa laye, ti a si ku lẹyin de atiwa Oluwa, bi o ti wu ki o ri, ki yoo ṣaaju awọn ti o sun lati pade rẹ. Nitori Oluwa tikararẹ yoo sọ kalẹ lati ọrun wa ti oun ti ariwo, pẹlu ipe Ọlọrun; awọn oku ninu Kirisiti ni yoo si kọ ji dide. Nigba naa ni a o si gba awa ti o wa laaye ti o si ku lẹyin soke pẹlu wọn sinu ikuukuu, lati pade Oluwa ni oju ọrun. Bẹ ni awa o si maa wa lọdọ Oluwa titi lae. Nitori naa, ẹ maa fi ọrọ wọnyi tu ara yin ninu.” (1Tẹsalóníkà 4:13-18)

Bi a ko tilẹ sọ ninu lẹta yi, o ṣeeṣe pe lara iroyin ti Timoti mu wa fun Pọọlu nipa ijọ yi ni pe wọn n ṣọfọ, wọn si n barajẹ gidigidi nitori awọn ara wọn kan ti wọn ku tabi ki a sọ wipe ti wọn sun ninu Oluwa. Ti a ko ba gbagbe, gẹgẹ bi akọsilẹ Luuku ninu Iṣe Awọn Apọsiteli, nigba ti arabinrin kan ti a n pe ni Dọkasi, ti o jẹ ọmọ ijọ Joopa, ku, awọn ọmọ ijọ rẹ, paapaa julọ awọn opo ijọ naa ti o ti ran lọwọ lọpọlọpọ, bẹrẹ si ni sukun, ti wọn si n ba ara jẹ pupọ. Ti ko ba wa ṣe pe Peteru wa si ọdọ wọn, ti Ọlọrun si lo lati ji arabinrin yi, o ṣeeṣe ki iku rẹ fi irẹwẹsi si ọkan ọpọ ninu awọn ọmọ ijọ rẹ ati awọn miran ti wọn mọ gẹgẹ bi ẹni ire. (Wo: Iṣe Apọsiteli 9:36-42)

Irufẹ irẹwẹsi yi lo wa fẹ dabi ẹni pe o n ba ijọ awọn ara Tẹsalonika yi finra ni akoko yi. Nitorina, Pọọlu gba wọn niyanju lori iha ti o yẹ ki wọn kọ si iku awọn onigbagbọ. Ki si ni awọn nkan ti o sọ lori eyi? Akọkọ, o fẹ ki wọn mọ pe awọn onigbagbọ ti o ba ku ninu aye yi kan sun ni. Eyi jasi pe nipa ti ara nikan ni wọn ti ku – nipa ti ẹmi wọn wa laaye. Eyi yoo si di mimọ daju fun wa nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada wa lati ko awa ti a jẹ ayanfẹ rẹ wa sọdọ rẹ.

Pọọlu wa tẹsiwaju lati ṣe alaye bi eyi yoo ti ṣe waye. O jẹ ki o ye wa pe gbogbo wa naa ko ni yoo ku ki Jesu to de. Awa kan yoo wa laaye ni akoko bibọ rẹ. Amọ ṣa o, awa ti a wa laaye kọ ni yoo kọkọ darapọ mọ. Awọn ti o ti ku ni yoo kọkọ darapọ mọ, ti yoo si gba agọ ara tuntun ti o dabi tirẹ (1Kọrinnti 15; Filipi 3:20). Bi a tilẹ ti ṣe ri ninu bibeli, awọn ti o ku ninu Kirisiti ti wa pẹlu rẹ lọwọlọwọ yi (2Kọrinnti 5:1-8; Filipi 1:21-25). Ṣugbọn nigba ti O ba de ni a to tun ri wọn. Awa naa yoo si wa gba agọ ara tuntun nigba ti a ba darapọ pẹlu wọn ati Jesu nigba ti O ba de.

Ki wa ni koko gbogbo nkan ti Pọọlu sọ yi? Oun naa ni pe ko si idi fun wa lati banujẹ tabi ṣọfọ bi awọn alaigbagbọ lori awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ wa ninu ijọ, ti wọn jẹ ẹbi wa tabi ti wọn jẹ ọrẹ wa ti wọn ti ku tabi ti wọn ba ku. Wa kiyesi eyi: Pọọlu ko sọ wipe ki a ma banujẹ rara tabi ṣọfọ rara lori awọn eniyan wa ti wọn ba sun ninu Kirisiti. Ti a ba tilẹ ka lẹta rẹ si awọn ara Roomu, o sọ nibẹ pe ki a ma ba awọn ti o n sukun sukun, ki a si ma ba awọn ti o n yọ yọ (Roomu 12:15).

Nitorina, ko ki i ṣe wipe Pọọlu fẹ ki a ro pe ko tọ fun Kirisitiẹni lati sọkun tabi ṣọfọ lori awọn eniyan tabi ọrẹ rẹ ti o ba ku. Jesu Oluwa wa gan sọkun nigba ti O de iboji Lasaru, iyẹn ki O to ji dide (Johanu 11:35). Ko wa si nkan ti o buru nibẹ ti awọn ọmọ ẹyin rẹ naa ba sukun nitori awọn eniyan wọn ti o ku. Nkan ti Pọọlu kan fẹ ki o ye wa ni pe ko yẹ ki a ma banujẹ tabi ṣọfọ lori wọn bi awọn alaiagbagbọ ti ko ni ireti ati ba Jesu jọba titi lailai.

Awa naa mọ bi awọn alaigbagbọ ṣe ma n ṣọfọ ati barajẹ lori awọn eniyan wọn ti o ba ku. Wọn le ma po ara mọlẹ tabi ki wọn ma gbe ara wọn ṣepe. Awọn miran tilẹ le pa gbogbo ojuṣe wọn si ara wọn ati si awọn miran ti o wa ninu aye wọn ti nitori pe wọn n ṣọfọ. A si ri awọn ti wọn ti jẹ ki aye wọn bajẹ patapata nitori pe wọn padanu awọn kan ninu aye wọn. Ṣugbọn eyi ko gbọdọ ri bẹ pẹlu awa ti a jẹ Kirisitiẹni. Lotitọ, ko si ẹni ti inu rẹ yo dun ti o padanu eniyan rẹ tabi ololufẹ rẹ, bi wọn tilẹ ti di arugbo. Amọ, niwọn igba ti awọn ti o ku yi ba ti ku sinu Kirisiti, a gbọdọ mọ lọkan wa pe oju a tunrari. A o tun pade lọjọ kan lọdọ Jesu. A ko si ni ya ara wa mọ lẹyin ipade yi.

Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ mọ pe bi eniyan tilẹ fi wa silẹ, Ọlọrun ko ni fi igba kankan fi wa silẹ. Gbogbo igba ni O ṣetan lati duro ti wa ati lati ri pe ààyè ẹni ti o fi wa silẹ ko ṣofo ninu aye wa. Tiwa kan ni ki a gba a laye lati tu wa ninu, nitoripe Baba itunu gbogbo ni Oun jẹ (2Kọrinnti 1:3-4). Awọn nkan wọnyi si ni Pọọlu sọ pe ki a ma lo lati gba ara wa niyanju ati lati tu ara wa ninu ti a ba padanu ẹnikẹni ninu Kirisiti, ki a ma ba ba ara jẹ kọja ala, ki a si sọ ara wa di idakuda.

ỌRỌ IPARI

O wa ṣeeṣe ki a ri ẹni ti yoo bere pe iha wo ni o wa yẹ ki a kọ si awọn ti o ku, ti ko si ki i ṣe Kirisitiẹni. Bi o tilẹ jẹ pe awọn wọnyi ko ni ireti ijọba ayeraye, niwọn igba ti wọn ti ku, ko si nkan ti a le ṣe lori ọrọ wọn mọ. Bi o ti wu ki a barajẹ to lori ọrọ wọn, ibarajẹ wa ko le yọ wọn kuro ninu ewu ọrun apadi. O ti bọ na. Awọn ti o ku laye nikan ni a le ran lọwọ ki awọn naa ma ba pari irinajo wọn si ibikanna. Nitorina, boya ẹni ti o ku jẹ ọmọ Ọlọrun tabi ọmọ Eṣu, a ko gbọdọ barajẹ tabi banujẹ lori wọn bi awọn ti ko ni oye ọrọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, nṣe ni ki a ma fi gbogbo mura silẹ lati jẹ alabapin ireti ogo ayeraye wa ti o n bọ, iyẹn Jesu Kirisiti Oluwa wa.

IBEERE – Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran oye rẹ lori iku ati ajinde lọwọ si?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ Kínní | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:13-18 | ỌJỌ́RÚ 03, ÒGÚN 2022 Read More »

Má jẹ́ aláìwúlò olùrànlọ́wọ́ | Pst. J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 31, 2022 | Vol. 11, No. 13

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, eyi ti ṣe ọsẹ akọkọ ninu oṣu Ògún ti ọdun 2022. Mo ṣi gbadura pe ki Ọlọrun, ẹni ti O ti n tọju wa latẹyin wa, tẹsiwaju lati ma pa wa mọn ni awọn akoko ewu yi, ki O si tun tẹsiwaju lati jẹ ki a ma pọ si ni iwulo, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni oniruuru asiko laye yi, Ọlọrun ma n mọnmọn gbin wa sinu aye oniruuru eniyan lati le jẹ oluranlọwọ tabi olutunu fun wọn. Eyi ko si ki i ṣe lati fi wa ṣe ẹru fun wọn rara, bi o tilẹ wa jẹ wipe a le ni lati ṣe awọn iṣẹ ti o jẹ mọ ti ẹru ni igba miran. Dipo eyi, O n ṣe eyi lati jẹ ki a le wa ni imurasilẹ fun awọn aye giga ti O fẹ gbe wa lọ tabi fun awọn iṣẹ nla ti O fẹ fun wa.Fun apẹrẹ, ki Josefu to di igbakeji fun Farao, o ti kọkọ jẹ iransẹ ati oluranlọwọ fun Pọtifa ati fun alakoso túbú ti a mu u lọ, iyẹn lẹyin igba ti iyawo Potifa ṣe akoba fun un. Awọn iriri ati ẹkọ ti o si ba pade nigba ti o n sin awọn eniyan yi si wa lara awọn nkan ti o ran an lọwọ nigba ti o bẹrẹ si ni dari orilẹ-ede Ijibiti.

Lafikun, ki Eliṣa to di olori awọn wolii yoku ti o wa ni orilẹ-ede Isiraẹli, o ti kọkọ sin Elija ni ọpọ ọna, ti o si tun ran an lọwọ. Akoko ti o si lo pẹlu eniyan Ọlọrun yi wa wa lara awọn nkan ti o ran lọwọ lati mọ bi a ti ṣe lo ọrọ Ọlọrun, paapaa julọ ni akoko ti nkan ko ba rọgbọ. (Wo: Jẹnẹsisi 39-41; 1Awọn Ọba 19 – 2Awọn Ọba 2)

Amọ ṣa o, o gbọdọ ye wa pe idi ti Josefu ati Eliṣa ṣe papa de ibi giga ti Ọlọrun fẹ ki wọn de, ti wọn si tun ṣe aṣeyọri ni ibẹ ni pe wọn fi ara wọn si ipo ẹni ti o wulo fun awọn ti o yẹ ki wọn sin ni akoko ti o yẹ ki wọn sin wọn. Fun apẹrẹ, ti o ba jẹ wipe Josefu ko wulo fun Pọtifa ni, ko ni fi gbogbo dukia rẹ si ikawọ rẹ. Tabi ka sọ wipe ko wulo fun alakoso tubu ti a mu lọ ni, o ṣeeṣe ki o ma ri anfaani ti o ri lati pade ọkunrin naa ti o pada yọ ọ jade.

Nitorina, nibikibi ti o ba wa, ripe o da awọn ti Ọlọrun fẹ ki O sin, ran lọwọ tabi tu lara mọ, ki o si fi ara rẹ si ipo ẹni ti o wulo jọjọ tabi ti iwulo rẹ ko ṣe fẹnu sọ fun wọn, dipo ti o o fi sọ ara rẹ di ajaga alainitunmọ fun wọn. Ma ṣe dabi awọn ọrẹ Joobu mẹta ti wọn wa lati tu u lara amọ ti wọn wa pada fi kun ipọnju rẹ. Iwọ naa wo ọrọ rẹ nipa wọn: “Ẹyin n fi eke pe otitọ, oniṣegun ti ko le wo ni san ni yin. O ṣe! Ẹ ba kuku pa ẹnu yin mọ patapata! Eyi ni iba ṣi ṣe ọgbọn yin.

“Yato si eyi, ma ṣe da bi Johanu Maaku, ẹni na ti o jẹ wipe, ni igba ti o ṣi jẹ ewe ninu iṣẹ iranṣẹ, o pa Pọọlu ati Banaba ti nigba ti wọn rin irin-ajo iṣẹ itankalẹ ihinrere akọkọ wọn. Gẹgẹ bi Luuku ti ṣe fi ye wa, ọkunrin yi tẹle awọn apọsiteli yi lati ran wọn lọwọ ni ọna yowu ti wọn ba ti nilo rẹ ni. Eyi tunmọ si pe o ṣeeṣe ki wọn nilo rẹ lati ba wọn mojuto ile wọn, ṣe eto fun iriin-ajo wọn, ba wọn kọ lẹta tabi pin lẹta, ba wọn mojuto sisan owo ori wọn ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn lalai si idi kan gbogi, o fi wọn silẹ nigba ti iṣẹ gan ṣẹṣẹ n bẹrẹ. Nitorina, iranṣẹ ti ko wulo rara ni o jẹ fun wọn ni akoko yi, bi o tilẹ jẹ wipe ẹbi Banaba ni o jẹ. Abalajọ ti Pọọlu ko ṣe fẹ ki wọn mu lọwọ nigba ti wọn fẹ rin irin-ajo iṣẹ ijinhinrere wọn lẹkeji. (Wo: Iṣe Apọsiteli 13:5&13; Iṣe Apọsiteli 15:36-41)A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe Maaku taji kuro loju orun rẹ lẹyin-ọrẹyin, o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ sipo ẹni ti o mọ ojuṣe rẹ ni sinsin awọn adari ijọ ti Ọlọrun fẹ ki o sin. Nitorina, nigba ti o ṣe diẹ si, Pọọlu sọ fun Timoti lati mu lọwọ wa si ọdọ oun nitori ti o ti di ẹni ti o wulo fun ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ (2Timoti 4:11).

Bi Ọlọrun si ṣe fẹ ki nkan ri fun gbogbo wa ni eyi. O fẹ ki a dagba soke si lati di ẹni ti o wulo gidigidi fun awọn ti o wa ninu aye wa, paapaa julọ awọn adari wa, boya ni ile ni o, tabi ninu ijọ tabi ni ibi iṣẹ.Ṣe o ri, awọn olori, pẹlupẹlu awọn obi wa, ko ki fẹ ki awọn eniyan ti o wa ni ṣakani wọn jẹ ajaga si wọn lọrun bikoṣe oluranlọwọ. Iṣẹ ti o wa ni ọwọ wọn pọ to fun wọn lati ṣe, wọn ko si fẹ awọn ọmọlẹyin tabi oṣiṣẹ ti yoo jẹ ki iṣẹ wọn le si afi awọn ti yoo jẹ ki iṣẹ naa rọrun si fun wọn. Nitorina, ti o ko ba ma mu ki iṣẹ awọn adari rẹ rọrun si fun wọn, ibi yowu ti o le wa, o ko wulo fun wọn. Niwọn igba ti iwọ ko ba si wulo fun wọn, awọn adari rẹ ko ni ri idi lati gbe o ga. Ọlọrun paapa ko ni ṣi ilẹkun fun ọ lati pọ si ni iwulo, ti o ko ba wulo fun awọn eniyan ti o fẹ ki o sin tabi ran lọwọ. Nitorina, ji kuro loju orun rẹ, gẹgẹ bi Maaku naa ti ṣe ji, ki o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ si ipo ẹni ti o wulo fun awọn ti Ọlọrun fẹ ki o sin. Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, ọpọlọpọ ilẹkun anfaani lati de ibi giga yoo bẹrẹ si ni ṣi fun ọ kaakiri-kaakiri.Ki o ni ọsẹ alarinrin.Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má jẹ́ aláìwúlò olùrànlọ́wọ́ | Pst. J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 31, 2022 | Vol. 11, No. 13 Read More »

Tají, kí o si ṣe iṣẹ́ rẹ | Pst. J.O. Lawal | Agẹmọ 24, 2022 | Vol. 11, No. 12

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ ku u kalẹ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Agẹmọ 2022. Adura mi si pe ki ọkan rẹ gba igboya ati oriya ti o peye lati gba aye rẹ ninu ijọba Ọlọrun ati ṣe gbogbo ojuṣe iranṣẹ rẹ. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si Timoti sọ fun pe, “Ṣùgbọ́n máa ṣe pẹ̀lẹ́ nínú ohun gbogbo, máa farada ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ ajínyìnrere, ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ láṣepé.” (2Timoti 4:5) Ki ni akotan aṣẹ ti Pọọlu pa fun Timoti nibi yi? Oun naa ni pe ki o ri daju pe ko fi ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ iranṣẹ rẹ silẹ lalai ṣe. Eyi tunmọ si pe o gbọdọ ri daju pe ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe ni o ṣe.

Ṣugbọn ki wa ni yoo jẹ ki Timoti ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe lorilẹ aye yi? Akọkọ, o gbọdọ ni imọ nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe lọna ti o peye ati ti o daju. Ko si bi o ṣe fẹ ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe ti ko ba mọ nkan ti iṣẹ iranṣẹ naa da le lori. Ekeji, o gbọdọ mọ ojuṣe rẹ ni tirẹ. Eyi jasi pe o gbọdọ ri iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, ki o si tun fi tọkantọkan fi ara rẹ jin lati ṣe. 

Nkan ẹkẹta ti Timoti nilo lati ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe ni amuyẹ lati ṣe. Eniyan le gba iṣẹ ti a fun ni iṣẹ rẹ, ki o si jẹ ẹni ti o ṣetan lati ṣe ojuṣe rẹ lori iṣẹ naa. Ṣugbọn ti ko ba ni amuyẹ ti o nilo lati ṣe iṣẹ ọhun, imura rẹ ati itara rẹ lati ṣe di dandan ki o ja si pabo. Nitorina, ko to fun Timoti lati ni lọkan lati ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe; o tun ṣe pataki fun ki o ni amuyẹ lati ṣe. Ọpẹ wa ni fun Ọlọrun pe ko ki i fun ẹnikẹni ni iṣẹ lalai pese ohun gbogbo ti ẹni naa yoo nilo lati ṣe iṣẹ naa fun un. (Wo: 2Kọrinnti 3:5-6; 2Timoti 3:16-17)

Amọ ṣa o, pe eniyan mọ nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe, ṣetan lati ṣe ojuṣe rẹ ati ni amuyẹ lati ṣe ojuṣe rẹ ko tunmọ si pe yoo ṣe. Ki wa lo le fa ki awọn nkan wọnyi pe sinu aye eniyan ki o si tun ma ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe? Ibẹru, fun apẹrẹ, le fa a. Nigba ti Ọlọrun kọkọ fi ara han Gidioni, O pe ni alagbara ọkunrin. O tilẹ sọ fun pe ki o lọ ninu agbara rẹ lati gba awọn eniyan rẹ la kuro lọwọ awọn ọta wọn. Ṣugbọn ọkunrin yi bẹru kọja ki o le ṣe ohunkohun ni akoko naa. Ọlọrun wa nilo lati ṣe aṣepe iṣẹ lori igbagbọ rẹ fun akoko kan ki o to di wipe o taji lati ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ. A si wa ri ọpọ ọmọ Ọlọrun loni ti awọn naa da bi ọkunrin yi. Eniyan takuntakun ninu ijọba Ọlọrunn ni wọn jẹ ninu ọkan wọn. Amọ o ṣeeṣe ki wọn pari igbesi aye wọn bi alaiwulo ẹda nitori ibẹru. Ọrọ tirẹ ko wa ni ri bẹ ni orukọ Jesu. Amin. (Wo: Onidajọ 6; Saamu 82:6)

Lafikun, irẹwẹsi le pa ina ẹmi eniyan, ki o si di lọwọ lati ṣe aṣepe awọn ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ. Fun apẹrẹ, ti eniyan ko ba ri irufẹ abajade ti o fọkan si nidi ṣiṣe ifẹ Ọlọrun tabi ti o ba n ba ọpọlọpọ idojukọ pade, o ṣeeṣe ki irẹwẹsi ba ọkan rẹ, ki o si pa iṣẹ rẹ ti. Mose fi igbakan woye pe iku ya ju ẹsin lọ fun oun nitori àjàgà iṣẹ iranṣẹ rẹ ti o fẹ ya a ni were. Ṣugbọn nigba ti o ba Ọlọrun ṣọrọ le lori, O sọ ohun ti o nilo lati ṣe ki àjàgà rẹ ba le fuyẹ. Nigba ti o si ṣe e, ko tun fi igba kankan rẹwẹsi mọ. Nitorina, ti irẹwẹsi ba ba ọkan rẹ lori iṣẹ iranṣẹ rẹ tabi lori ohunkohun laye yi, o kan nilo lati ba Ọlọrun sọrọ lori rẹ ni. Oun yoo si fi ipese rẹ lati mojuto àjàgà yowu ti o n fa irẹwẹsi fun ọkan rẹ han ọ. (Wo: Numeri 11)

Wayi o, mo mu awọn nkan wọnyi tọ ọ wa lati kan ran ọ leti pe, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, o ni iṣẹ iranṣẹ ninu ijọba rẹ ti iwọ naa gbọdọ ṣe ni aṣepe bi Timoti. Ti o ko ba si ti gbajumọ, o nilo lati taji were, ki O si gbadura si Ọlọrun lati fun ọ ni okun lati mojuto ohunkohun ti o ba n di ọ lọwọ lati ṣe iṣẹ naa, yala ailoye ni, imẹlẹ ni, ero àìkójúòṣùnwọ̀n ni, ibẹru ni, irẹwẹsi ni tabi iyọlẹnu awọn kan ni. Aijẹbẹ, wa fi oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa lori aye rẹ ṣofo nigbẹyin. Ko si wa si ẹni ti yoo fi oore-ọfẹ rẹ ṣofo ti a ko ni san lẹsan rẹ. Nitorina, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, taji, ki o si gbajumọ ohun ti a da ọ, ti a si tun pe ọ lati ṣe. Ki Ọlọrun ṣi pese ohun gbogbo ti o kudiẹ-kaato ni imura ati ifarajin rẹ lati ṣe aṣepe iṣẹ iranṣẹ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Tají, kí o si ṣe iṣẹ́ rẹ | Pst. J.O. Lawal | Agẹmọ 24, 2022 | Vol. 11, No. 12 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:1-12 | ỌJỌ́RÚ 20, AGẸMỌ 2022

AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:1-12 ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ ti a kọ pari ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika, a ri awọn ọna ti o gba ṣe pataki ki a mọ ipo ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa wa. Ninu ẹkọ eyi ti a mu yi, ẹwẹ, gbigbe igbe aye ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ni a fẹ ṣe agbeyẹwo. Bi Pọọlu ṣe fi ye wa, nigba ti wọn mu ọrọ Ọlọrun tọ awọn ara Tẹsalonika wa, wọn kọkọ kọ wọn bi a ti ṣe n gbe igbe aye ti o wu Ọlọrun, igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun. O ṣi ṣe koko ki a kọ ẹnikẹni ti o ba ṣẹṣẹ n fi aye rẹ fun Jesu ni bi a ti ṣe n gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun. Aijẹbẹ, a le ma ri iyatọ ninu igbe aye ti wọn n gbe tẹlẹ ati igbe aye ti wọn n gbe lẹyin igba ti wọn ti mọ Jesu. Idi niyi ti Pọọlu ṣe tun ran awọn ara Tẹsalonika leti ninu lẹta yi lara awọn nkan ti wọn kọ wọn nipa gbigbe igbe aye iwa mimọ, ki wọn ba tunbọ le tẹramọ. (Wo: 1Tẹsalonika 4:1)

ÌGBÉ AYÉ TÍ Ó TẸ́ ỌLỌ́RUN LỌ́RÙN

Irufẹ igbe aye wo ni o wa tẹ Ọlọrun lọrun? Gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, igbe aye ti o tẹ lọọrun jẹ:

– Ìgbé ayé àìléérí: Ninu lẹta yi, Pọọlu fi eyi han wa nipa ifẹ Ọlọrun fun gbogbo eniyan: “Nitori pe, ẹyin mọ aṣẹ ti a pa fun yin lati ọdọ Oluwa Jesu. Nitori ifẹ Ọlọrun ni pe ki ẹ jẹ mimọ, ki ẹ si yago kuro ninu ẹṣẹ agbere, ki ẹnikọọkan yin kọ lati sakoso ara rẹ ni ọna mimọ ati pẹlu ọla, ki i ṣẹ ni ifẹkufẹ gẹgẹ bi awọn alaikọla, ẹni ti ko mọ Ọlọrun; ati pe ninu ọrọ yi, ki ẹnikẹni yin ma ṣẹ kuna arakunrin rẹ nipa ohunkohun. Oluwa yoo jẹ eniyan niya fun gbogbo ẹṣẹ wọn, gẹgẹ bi a ti n sọ fun un yin tẹlẹtẹlẹ. Nitori Ọlọrun ko pe wa sinu aimọ, bi ko ṣe sinu igbe-aye mimọ. Nitori naa, ẹnikẹni ti o kọ ofin yii, ki i ṣe ofin eniyan ni ẹni naa kọ, bi ko ṣe ofin Ọlọrun ẹni ti o fi Ẹmi Mimọ rẹ fun ni.” (1Tẹsalonika 4:2-8) Bi apọsiteli yi ti ṣe la a kalẹ fun wa, a ri wipe igbe aye wa ko le tẹ Ọlọrun lọrun ti a ko ba yago fun agbere, pansaga, iwa eeri ati bẹẹbẹẹ lọ. Nitorina, ojuṣẹ ẹnikọọkan wa ni lati kọ bi yoo ṣe ko ara rẹ ni ijanu ni ọna ti o mọ, ti o si tun ni ọla, ko ki i ṣe ojuṣe Ọlọrun rara.

Bi itan Josẹfu ti lọ ninu bibeli, oun funrarẹ lo ko ara rẹ ni ijanu nigba ti iyawo oluwa rẹ, Pọtifa, bẹrẹ si ni fi ẹṣẹ agbere lọ ọ. Oun lo ba ara rẹ sọrọ pe ohun gbọdọ jina si arabinrin yi ati wipe oun gbọdọ sa fun ẹṣẹ agbere pẹlu rẹ, bi o ti wu ki nkan ri. Ọlọrun ran lọwọ lati jẹ ki eyi ṣeeṣe lotitọ. Amọ idi ti Ọlọrun fi ri ran lọwọ ni pe oun funrarẹ ti pinu lati ṣe ohun ti o tọ pẹlu agọ ara rẹ, ki o si ma ṣẹ si Ọlọrun ati ṣi ọga rẹ. Eyi n jẹ ki o ye wa pe awa naa gbọdọ pinu ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa lati takete tabi sa fun ẹṣẹ agbere nipa ki a ma fi aye gba ifẹkufẹ ninu ọkan wa ati nipa ki a ma fi anfaani silẹ fun ibaṣepọ ti ko tọ pẹlu awọn ti ko ki i ṣe aya tabi ọkọ wa. (Wo: Jẹnẹsisi 39; 1Kọrinnti 6:18)

Lotitọ, aye ti a wa yi jẹ eyi ti o kun fun oniruuru iwa idibajẹ. Idi si ni pe ọpọ lo fẹran iwa ibajẹ ati oniruuru iṣekuṣe. Wọn a si tun ma wa ọna lati mu awọn miran kunra ninu idibajẹ wọn, pẹlupẹlu ninu ijọ. Ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ba wa fi si ọkan pe iṣekuṣe, agbere, pansaga ati awọn iwa eeri miran ti o fara pẹ wọn lodi si ifẹ Baba wọn ti O pe wọn, ti O si fi Ẹmi Mimọ rẹ sinu wọn, ko si ni ki wọn ma ba ara wọn jẹ pẹlu awọn idibajẹ aye yi. Ẹni ti o ba si ba ara rẹ jẹ ni ọna yi di dandan ki o ba ijiya pade lati ọwọ Ọlọrun nigba ti akoko ba to.

– Ìgbé ayé ìfẹ́: Yatọ si pe ki a ma fi iṣekuṣe ba ara wa jẹ, a tun gbọdọ fi ara wa jin lati fi ifẹ han si gbogbo awọn ti o ba wa ninu aye wa tabi ti a ba n ni ajọṣepọ pẹlu, lọna kan tabi omiran. Igbe aye ti ko ba si kun fun ifẹ Ọlọrun si awọn eniyan ko tẹ ẹ lọrun rara. Ki a tilẹ sọ otitọ, igbe aye asan, igbe aye ti ko lere ni igbe aye ti ko ba kun fun ifẹ Ọlọrun jẹ (1Kọrinnti 13). Idi si ni pe Jesu funrarẹ ti jẹ ki o ye wa pe nipa rinrin ninu ifẹ ni awọn eniyan yoo ṣe mọ wa gẹgẹ bi ọmọ ẹyin rẹ nitootọ (Johanu 13:34-35). Bi a ti ṣe mọ, a ri awọn ti ko gba Jesu gbọ rara ti ko ki i gbe igbe aye iṣekuṣe tabi agbere rara. Ki wa ni yoo jẹ iyatọ laarin iru awọn wọnyi ati awọn ọmọ Ọlọrun? Igbe aye ifẹ ni! Nitorina, awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun gbọdọ mọ pe ko to ki a yẹra fun ifẹkufẹ ati iwa eeri ninu aye yi; a tun gbọdọ tẹramọ igbe aye ifẹ. Pọọlu si fi eyi han wa ninu nkan ti o sọ fun awọn ara Tẹsalonika pe, “Ṣugbọn nipa ifẹ ara, a o ni lati tun kọwe si i yin, idi ni pe, Ọlọrun paapaa n kọ yin lati fẹran ara yin. Nitootọ, ẹ ni ifẹ fun awọn arakunrin ti o wa kaakiri Makidonia. Sibẹsibẹ awa n bẹ yin, ara, pe ki ẹyin ki o maa tẹsiwaju ninu rẹ.” (1Tẹsalonika 4:9-10) Bi a ti ṣe ri ninu ọrọ rẹ, Ọlọrun funrarẹ ni O kọ awọn ara Tẹsalonika lati ma rin ninu ifẹ nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ ti O fi fun wọn. O ṣi ṣetan lati kọ awa naa lati ma a rin ninu ifẹ nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ, ti a ba fi ara wa jin fun.

– Igbe aye ẹni ti o tojubọ: Nkan miran ti Pọọlu tun sọ fun wa ninu lẹta si awọn ara Tẹsalonika nipa igba aye ti O tẹ Ọlọrun lọrun ni pe o jẹ igbe aye ẹni ti o wulo, ẹni ti o to oju bọ, ti ko si nilo lati ko bukata aye rẹ le ẹnikẹni lori. Iwọ naa wo nkan ti o sọ nipa eyi: “Ẹ jẹ ki eyi jẹ ifẹ ọkan yin lati gbe jẹẹ ati lati mọ ti ara yin ati ki olukuluku kọju si iṣẹ rẹ, gẹgẹ bi a ti wi fun yin. Eyi yoo mu ki awọn ti ki i ṣe Kirisitẹni gbẹkẹle yin ati lati bu ọla fun yin pẹlu. Bi ẹ ba ṣe bẹẹ, ẹ ko ni maa wo oju ẹnikẹni lati fun yin ni owo ti ẹ o fi san gbese.” (1Tẹsalonika 4:11-12) Ki ni eyi n fi ye wa? Oun naa ni pe igbe aye aláìní, igbe aye onigbese, igbe aye atọrọjẹ ko ki i ṣe ifẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ rẹ. Ko wu u tabi tẹ ẹ lọrun rara. Ko si fẹ ki a ma sọ wipe nitori Jesu ni aye wa ṣe ri bayi. Idi si niyi ti ko fi fẹ ki a ya ọlẹ, afàjọ̀ọ̀ tabi alainikanṣe. Dipo bẹẹ, O fẹ ki a yago fun abosi, igbesi aye imẹlẹ, ki a tẹra mọ iṣẹ wa, ki a si ma ṣe ni ọna ti a o fi ni anito ati aniṣẹku. Eyi jasi pe Ọlọrun ni lọkan lati bukun fun wa lọpọ yanturu, ti a ba tẹra mọ iṣẹ wa, ti a si n ṣe pẹlu ọgbọn ati oye ti o peye. Pọọlu si tun wa jẹ ki o ye wa pe ti a ba gbe aye wa lọna yi, a ko ni nilo lati ma woju ẹnikẹni fun ounjẹ tabi fun owo lati ṣe ojuṣe wa. Dipo eyi, nṣe ni awọn ti o wa ni ayika wa yoo ma bọwọ fun wa.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ

Iwọ naa wo igbe aye ti o n gbe. Njẹ o ba ifẹ Ọlọrun mu bi? Ṣe igbe aye aileeri, igbe aye ifẹ ati igbe aye ẹni ti o toju bọ ni bi? Abi igbe aye iṣekuṣe, ikorira ati alaiwulo ni? Mọ lọkan rẹ pe Ọlọrun fẹ ki gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ mọ irufẹ igbe aye ti O tẹ ẹ lọrun, ki a si tun tẹramọ ati ma a gbe. Ẹnikẹni ti ko ba wa mọ eyi, ki o si mu ni pataki n fi ara rẹ han bi ẹni ti ko i ti ba Jesu pade rara tabi ti ko ni oye nkan ti a n pe ni igbe aye Kirisitiẹni.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:1-12 | ỌJỌ́RÚ 20, AGẸMỌ 2022 Read More »

Fún ànfààní rẹ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 17, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 11

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2022. Ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba pese fun gbogbo aini rẹ lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ ologo rẹ ninu Kirisiti Jesu. Amin.

Wayi o, Pọọlu ni o kọkọ gba adura yi ninu lẹta rẹ si awọn ijọ Filipi. Ki si ni idi ti o fi gba a fun wọn? Idi naa ni pe wọn mu inu rẹ dun jọjọ pẹlu awọn ẹbun kan ti wọn fi ṣọwọ si i. Bi o ti wa tọka si ninu lẹta rẹ si wọn, ko fi inu didun rẹ han nitoripe ti ko ba ri ẹbun wọn ko le wa ni ifọkanbalẹ. O le wa ni ifọkanbalẹ lalai ri ẹbun wọn. Idi si ni pe o jẹ ẹnikan ti Ọlọrun ti kọ ni bi a ti ṣe n gbe aye gbadun bi o ti wu ki asiko ri, yala owo pọ lọwọ rẹ ni tabi ko pọ. (Wo: Filipi 4:10-13)

Nitorina, bi ko ba tilẹ si ẹnikankan ninu awọn ti Ọlọrun ti lo o lati fi idi wọn mulẹ ninu otitọ Jesu ti yoo ran an lọwọ, yoo si tun wa ni ifọkanbalẹ. Ọlọrun yoo ri daju pe o wa ni ifọkanbalẹ. Ranti wipe Ọlọrun ti lo ẹyẹ ìwò, ẹyẹ aimọ, ri lati gbe ounjẹ wa fun iranṣẹ rẹ Elija, laarọ ati ni irọlẹ, ni akoko iyan, ni akoko ti ko si ẹnikẹni ti o ri tirẹ ro. Nibakanna, O le tọju gbogbo awọn iranṣẹ rẹ ti wọn ba gbẹkẹle, boya awọn eniyan fi aye silẹ lati mojuto wọn tabi wọn ko ṣe bẹ ẹ. (Wo: 1Awọn Ọba 17:2-6)

Amọ ṣa o, bi Pọọlu tun ṣe jẹ ki o yẹ wa ninu lẹta rẹ si awọn ara Filipi yi, fun anfaani wọn ni ti wọn ba fi fun un lati ara nkan ini wọn. Ki si ni idi? Akọkọ, nipa ṣiṣe eyi, wọn yoo ma mu ifẹ Ọlọrun fun aye wọn ṣẹ. Ọlọrun ti paṣẹ pe ki gbogbo awọn ti o n waasu ihinrere ma ti ipasẹ rẹ gbọ bukata ara wọn. Nitorina, ẹnikẹni ti o ba n kopa ninu iṣẹ iranṣẹ wọn, ti o si n tipasẹ rẹ di alabukunfun gbọdọ ma kopa ninu aini wọn pẹlu. (Wo: Luuku 10:5-7; Filipo 4:14; 1Kọrinnti 9:14; Galatia 6:6)

Siwajusi, bi Pọọlu ti ṣẹ fi han awọn ara yi, nipa pipin lara nkan ini wa fun awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ Ọlọrun, nṣe ni a n to ìṣura jọ sinu àpò-ìṣura wa ti o wa lọdọ Ọlọrun. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe eniyan ni a n fi fun un, niwọn igba ti a ba ti fi fun wọn pẹlu ọyaya ati lalai kun sinu, Ọlọrun funrarẹ yoo gba ẹbun wa bi ọrẹ ati ẹbọ olóòórùn-dídùn, eyi ti o tẹẹ lọrun, ti o ṣi tun jẹ itẹwọgba si i. Niwọn igba ti O ba si ti gba ẹbun wa lọna yi, a le mọ daju pe yoo pin wa ni ere fun un ni akoko ti o tọ ati ni ọna ti o yẹ. (Wo: Galatia 6:6-10; 2Kọrinnti 9:6-8; Filipi 4:18-19)

Yatọ si awọn nkan wọnyi, nigba ti a ba mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ lori aye wa nipa fi fifun awọn ojisẹ rẹ si wa, yatọ si wipe a o jẹ ki wọn kun fun ọpẹ si Ọlọrun nitori wa, a o tun ru wọn soke lati fi tọkantọkan gbadura fun ire wa, bi Pọọlu ti ṣe ṣe fun awọn ara Filipi ninu lẹta rẹ si wọn. Ta lo si wa mọ iru ipa ti irufẹ awọn adura ti a ba gba lọna yi le ko lori aye wa? (Wo: 2Kọrinnti 9:12-14)

Wayi o, ti o ko ba wa ti fi ara rẹ jin fun pipin lara awọn nkan daradara ti o ni fun awọn ojiṣẹ ti Ọlọrun n lo fun ọ, mọ wipe o ti ma rin ninu ifẹ rẹ fun ọ ni ọna ti o peye ati wipe o tun n ja ara rẹ lole awọn nkan kan ti ko ba ti jẹ tirẹ. Nitorina, ji ọkan rẹ lati mu ọrọ yi ni ọkunkundun. Si pinu lori ọna ti iwọ naa yoo gba lati ma fi igba gbogbo ran wọn lọwọ ni ibamu pẹlu bi Ọlọrun ti ṣe bukun fun ọ pẹlu owo. Ki Ọlọrun si fun ọ ni okun lati tayọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin. Ma gbadun!

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fún ànfààní rẹ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 17, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 11 Read More »

Má fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú wọn | J.O. Lawal | Agẹmọ 10, 2022 | Vol. 11, No. 10

Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Agẹmọ 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ gba okun ati iwuri lati ma fi gbogbo igba fi igbekẹle rẹ si inu rẹ. Amin.

Ni awọn ọjọ melokan ṣẹyin, oniruuru ìfọ̀rọ̀-jomitoro-ọ̀rọ̀ ni o n lọ lori tani o yẹ ki o jẹ olori orilẹ-ede yi ti o n bọ tabi ta ni o yẹ ki a dibo fun. Niwọn igba ti o si tọ fun ẹnikọọkan lati tẹle ẹri ọkan rẹ lori ọrọ yi, o tun ṣe pataki ki a ma kọ eti didi si ọrọ ti Ọlọrun ṣọ fun wa nipa fifi igbẹkẹle wa sinu eniyan. Aijẹbẹ, a ni ye lugbadi awọn nkan ti a fi ọwọ ara wa yan.

Ki si ni ọrọ Ọlọrun si wa lori ọrọ yi? Oun naa ni o sọ pe, “Ẹ ma ṣe gbẹke yin le awọn ọmọ alade, ani le ọmọ eniyan, lọwọ ẹni ti ko si iranlọwọ.” (Saamu 146:3) Ki ni aṣẹ ti a pa fun wa nibi yi? Oun naa ni pe ki a ma fi igbẹkẹle wa sinu ẹlẹran ara, bi o ti wu ki wọn gbajumọ, jẹ olododo tabi ni agbara to ni oju wa. Ki wa ni idi? Bi onisaamu yi ti ṣe wi, idi ni pe wọn ko ni agbara lati gba wa la tabi fa wa lọwọ soke.

Lotitọ, eniyan le ni lọkan lati ṣoore fun wa, gba wa la tabi fa wa lọwọ soke. Ṣugbọn pe a ni lọkan lati ṣe nkan ko tunmọ si pe a ni agbara lati ṣe, bi idojukọ tilẹ wa. Ọlọrun nikan ni O ni agbara lati ṣe ohun yowu ti O ba gbero lati ṣe, boya aye fẹ tabi wọn kọ. Ti ko ba si wa ro eniyan ni agbara lati ṣe ohun ti o n gbero lọkan rẹ, bi o ti wu ki nkan naa dara to, erongba rẹ, ete rẹ ati akitiyan rẹ di dandan ki o ja si pabo (Saamu 127:1-2; Owe 19:21). Nitorina, a ko gbọdọ fi ireti wa fun igbe aye ọtun tabi fun orilẹ-ede ọtun sinu eniyan afi sinu Ọlọrun. Idi si ni pe ti Ọlọrun ko ba fun wọn ṣe, gbogbo ileri ati ero rere wọn lati mu ku aye dẹrun si fun wa di dandan ki o ja si asan.

Idi miran ti a ko fi gbọdọ fi igbẹkẹle wa sinu eniyan ni pe wọn jẹ àràmọ̀ndà. Eyi tunmọ si pe, wọn le pe pa iwa tabi iṣe da. Iyipada yi ṣi le jẹ fun rere tabi fun buburu, o le jẹ si daradara si tabi si idibajẹ si. Nitorina, ti Ọlọrun ba tilẹ yan eniyan lati ṣe awọn oore kan fun wa, o ṣi ṣeeṣe ki ẹni naa ma ṣe oore naa lẹyin-ọ-rẹyin. Akoko kan le de, ki wọn yi pada fun igba diẹ tabi patapata kuro ninu ifẹ Ọlọrun lati ṣe ti ara wọn.

Fun apẹrẹ, bibeli jẹ ki o ye wa pe Jeroboamu, iyẹn ọba akọkọ ti apakan orilẹ-ede Isiraẹli ti o wa ni iha ariwa, jẹ ayoo Ọlọrun. Ọlọrun lo yan pẹlu ami-ororo lati jọba lori awọn eniyan rẹ, lati tu wọn lara ati lati dari wọn sinu ifarajin ti o tọ si i. Ṣugbọn nigba ti ọkunrin yi fi idi mulẹ tan gẹgẹ bi ọba, ko lepa lati ṣe ifẹ Ọlọrun fun ara rẹ tabi fun awọn eniyan rẹ rara. Dipo eyi, nṣe ni o yipada patapata kuro ninu ijọsin Ọlọrun lati ma bọ awọn oriṣan miran, awọn oriṣa ti oun tikararẹ da. O si tun dari awọn eniyan rẹ lati ṣe bakanna. (Wo: 1Kings 11-14)

Njẹ eyi wa ya Ọlọrun lẹnu bi? Rara o! Iru awọn nkan wọnyi ko ki ya a lẹnu rara. Idi si ni pe O mọ pe aramọnda ni a jẹ. O mọ pe Oun da wa lati le yi pada. Boya iyipada si rere wa ni o tabi si buburu, ko si ẹyi ti ipa rẹ ko ka ninu rẹ. Amọ, ni ọpọ igba, awa ni a ko ki i wa ni igbaradi lati koju iyipada awọn eniyan. Nitorina, ti wọn ba ti yipada, ti wọn si ja wa kulẹ, nṣe ni a ko ni mọ nkan ti o yẹ ki a ṣe mọ, ti a o si yọnda ara wa fun irufẹ asiko ti ko rọọrun yowu ti iyipada wọn ba bi fun wa. Idi kan pataki si ni yi ti orilẹ-ede wa fi wa ni ibi ti o wa loni.

Ni kukuru, Ọlọrun tun wa n bawa sọrọ lẹkan si, O si n sọ fun wa pe ki a ma fi igbẹkẹle wa sinu eniyan afi sinu rẹ, bi a tun ṣe n wọ asiko idibo miran lọ. Idi si ni pe Oun ko ki i yipada kuro ninu ododo ṣiṣe (2Timoti 2:13). Nitorina, a le gbẹkẹle ni gbogbo igba lati ṣe wa ni ire, bi awọn eniyan tilẹ ja wa kulẹ. Yatọ si eyi, O tun ni agbara lati wo ilẹ wa san, yọ wa kuro ninu ẹrọfọ ẹgan ti a wa ati fi ẹsẹ wa mulẹ sori apata ti o le koko.

Si wa wo nkan ti onisaamu ẹkan sọ siwaju si nipa Ọlọrun fun wa:

“Ibukun ni fun ẹni ti o ni Ọlọrun Jakọbu ni oluranlọwọ rẹ; ireti ẹni ti n bẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ. Ẹni ti o da ọrun oun aye, okun ati ohun gbogbo ti o wa ninu wọn: ẹni ti o pa otitọ mọ titi aye: Ẹni ti o n ṣe idajọ ododo fun ẹni ti a ni lara: ẹni ti o n fi ounjẹ fun ẹni ti ebi n pa. Oluwa tu awọn ara ẹwọn silẹ: Oluwa gbe awọn ti a tẹ lori ba dide; Oluwa fẹ awọn olododdo: Oluwa pa awọn alejo mọ; o tu awọn alaini baba ati opo lara, ṣugbọn ọna awọn eniyan buburu ni yoo yipo.” (Saamu 146:5-9)

Adura mi ni pe ki awọn nkan wọn ati eyi ti o pọ ju bẹẹ lọ jẹ iriri wa kaakiri orilẹ-ede yi ni awọn oṣu ati ọdun ti o n bọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ologo.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú wọn | J.O. Lawal | Agẹmọ 10, 2022 | Vol. 11, No. 10 Read More »

Ikú tó farasin | Pst. J.O. Lawal | Agẹmọ 03, 2022 | Vol. 11, No. 9

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Agẹmọ 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun, ninu aanu rẹ, ma fi gbogbo igba pa iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ mọ kuro ninu gbogbo ewu pakute Eṣu ti o farasin. Amin.

Bi akọsilẹ bibeli ti ṣe lọ, igba meji ọtọọtọ ni ọba Isiraẹli, Sọọlu, ba Dafidi sọrọ lori ki o fi ọmọ rẹ ṣaya. Igba akọkọ, Merabu, ọmọbinrin rẹ agba, ni o kọkọ fi lọ ọ. Ṣugbọn ọdọmọkurin yi kọ jalẹ. O sọ fun pe awọn eniyan oun ko lowo tabi ni iyi to lati jẹ àna ọba. Nitorina, Sọọlu jami lẹnu ọrọ naa, o si fi ọmọ rẹ fun elomiran. (Wo: 1Sámúẹ́lì 18:17-19)

Lẹyin igba ti o ṣe diẹ si, ẹwẹ, awọn iranṣẹ Ṣọọlu tun sọ fun pe ọmọbirin rẹ kekere, iyẹn Mikali, ti yo ifẹ fun Dafidi. Nitorina, lẹsẹkẹsẹ ni o sọ fun wọn pe ki wọn ba Dafidi sọrọ lẹkan si pe anfaani miran tun ti ṣi ṣilẹ fun lati di àna ọba ati wipe nkan kanṣoṣo ti o nilo lati ṣe ni ki o mu ọgọ́rùn-ùn nkan ọmọkunrin awọn ara Filisitini wa – loba pari. Eyi wa tunmọ si pe Dafidi kọkọ gbọdọ pa ọgọ́rùn-ún ọmọkọrun Filisitini ki o to le ri nkan ọmọkunrin wọn. (Wo: 1Samuẹli 18:20-25)

Ki gan wa lo fa ti Sọọlu ṣe taku lori fifi ọkan lara awọn ọmọbinrin rẹ fun Dafidi gẹgẹ bi aya? Ṣe oun nikan ni ọkunrun ti o dangajia to lati fẹ awọn ọmọ rẹ ni? Rara! Abi ṣe inu rẹ lo dun to bẹẹ si Dafidi ti o fi fẹ ki o jẹ àna rẹ ni dandan? Rara! Bibeli jẹ ki o ye wa pe Ṣọọlu n jowu Dafidi ni akoko yi nitori aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi jagunjagun ati nitori iyi ti o ni laarin awọn eniyan. Nitorina, ko ki i ṣe nitoripe inu rẹ dun si lati ni gẹgẹ bi àna ni o ṣe fẹ ki o fẹ ọkan lara awọn ọmọbinrin rẹ; dipo eyi, nitoripe o fẹ lo ọrọ igbeyawo naa gẹgẹ bi pakute iku fun un ni. Ti ko ba wa jẹ pe Ọlọrun wa pẹlu rẹ, nṣe ni ko ba di oku nibi ti o ti n ṣe akitiyan lati di ana ọ̀ba. (Wo: 1Sámúẹ́lì 18:29-27)

Ki wa ni koko ọrọ yi? Oun naa ni pe awọn igba ma n wa ti ojurere awọn eniyan kan si wa tabi ti awọn nkan ti wọn n tọrọ lọwọ wa le jẹ oògùn iku, iparun tabi ẹsin ti a fi ewe ṣúgà pọn. Ti Ọlọrun ko ba si ṣi wa ni oju lati ri nkan ti awọn eniyan wọnyi n gbero lati ṣe si wa, ki O si fi ọna abayọ han wa, o ṣeeṣe ki a lugbadi ete ibi wọn. Nitorina, a ko gbọdọ fi igba kankan lero pe a o wa ni ipamọ nitori pe iwa wa dara si awọn ti o wa ni ayika wa, nitoripe a wa ni mimọ niwaju Ọlọrun tabi nitoripe a ma n fi gbogbo igba ṣọraṣe ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn elomiran. Dipo eyi, nṣe ni ki a ma fi gbogbo igba fa ara wa le Ọlọrun lọwọ fun ipamọ. Nitoripe ti Oun ko ba pa wa mọ, a ko le wa ni ipamọ, bi o ti wu ki a ni ifura to tabi bi awọn igbesẹ wa lati wa ni ipamọ ṣe le munadoko to (Saamu 127:1).

Ranti Ùráyà, ọkan lara awọn jagunjagun Dafidi. Ranti pe oun funrarẹ ni o mu lẹta idajọ iku rẹ lọ sọdọ awọn ti o ṣeto iku rẹ. Bẹẹ si ni ko mọ nkankan titi o fi parun. Bawo ni ko ba tilẹ ṣe mọ pe ọba ti o fi ọkan tan, ti o si ṣetan lati ku fun ni ọjọkọjọ ati ni akokokakoko le fi idajọ iku pamọ sinu lẹta ti o gbe le e lọwọ? Tabi ba wo ni o ṣe fẹ mọ pe gbogbo ojurere ati aanu ti ọba n fi han fun ni awọn wakati ikẹyin rẹ laye jẹ ete lasanlasan lati jẹ ki o gba ọmọ-àlè gẹgẹ bi ọmọ? Ko si bi o ṣe fẹ mọ awọn nkan wọnyi ti o ko ba ṣe pe a ba fun ni iṣipaya wọn. Nitorina, o ṣegbe nitoripe ko ni iṣipaya awọn nkan ti o le jẹ ki o gbaradi, ki o si bọ ninu iku ti o n bọ wa mu lọ. (Wo: 2Sámúẹ́lì 11)

Eyi jẹ ki o ye wa pe awọn eniyan daradara, awọn olootọ eniyan ati awọn olododo eniyan le lugbadi iwa ika awọn eniyan, pẹlupẹlu awọn ti wọn fi ọkan tan, ti Ọlọrun ko ba ṣaanu fun wọn, ki O si tun daabo bo wọn. Nitorina, mo n sọ fun ẹ lẹẹkan si pé kí o kọ́ lati ma fi gbogbo igba fa ara rẹ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ le Ọlọrun lọwọ fun ipamọ dipo ki o gbójúlé didara tabi jijafafa rẹ. Adura mi si ni pe ki Oun, ninu ẹkunrẹrẹ aanu rẹ, ma fi gbogbo igba fi gbogbo pakute ọta ti o farasin han ọ, ki O si tun ma ko ẹṣẹ rẹ yọ kuro ninu wọn. Amin.  

Ki o ni oṣu Agẹmọ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ikú tó farasin | Pst. J.O. Lawal | Agẹmọ 03, 2022 | Vol. 11, No. 9 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:17-3:13

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Ninu ẹkọ ti a kọ ṣẹyin ninu lẹta Pọọlu si ijọ Ọlọrun ti o wa ni Tẹsalonika, a ri daju wipe iha ti a ba kọ si ọrọ Ọlọrun ti a mu tọ wa wa ati si iṣẹ iranṣẹ awọn ti a ba ran si wa ni ipa ti o ga lati ko lori igbala ati idagbasoke wa ninu ẹmi. Gẹgẹ bi Pọọlu ti jẹ ki o ye wa ninu lẹta yi, awọn ara Tẹsalonika yi tẹwọgba ọrọ Ọlọrun ti a mu tọ wọn wa gẹgẹ bi ọrọ rẹ tootọ. Wọn ko foju tẹnbẹlu rẹ bi ọrọ lasan tabi ọrọ ẹlẹran ara. Idi si ni yi ti ọrọ naa ṣe bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ninu aye wọn, ti o si n so eso rere nibẹ (1Tẹsalonika 2:13). Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ti awa naa ko ba ri ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wa wa gẹgẹ bi ọrọ eniyan ṣugbọn bi ọrọ rẹ, o di dandan ki o ṣiṣẹ gidigidi ninu aye awa naa, ki o si so eso ti o yẹ ki o so. Amọ niwọn igba ti a ko ba ti kọbiara si ọrọ rẹ tabi ti a ri bi ọrọ lasan, aye wa ko ni gba iyipada ọtun ti o yẹ ki o gba. Pataki lara awọn nkan ti yoo si jẹ ki a gba ọrọ Ọlọrun bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ ni ki a gba awọn iransẹ rẹ ti O n ra si wa gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ tootọ. Ti a ko ba gba wọn gẹgẹ bi iransẹ rẹ, yoo nira fun wa lati gba ọrọ yowu ti wọn ba n sọ fun wa gbọ. Yoo si tun nira fun wa pẹlu lati fi aye gba iṣẹ yowu ti Ọlọrun ba fẹ tipasẹ wọn ṣe fun wa. Idi kan gbogi si ni yi ti ọpọ ko ṣe ni itẹsiwaju ninu irin-ajo igbagbọ wọn, ti wọn ko si ma gbadun Ọlọrun bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ti wọn ko ba si ronupiwada, ki wọn si bẹrẹ si ni kọ iha ti o tọ ati ti o yẹ si iṣẹ iranṣẹ awọn ti a ran si wọn ati si ọrọ Ọlọrun ti wọn n mu tọ wọn wa, aye wọn ati irin-ajo igbagbọ wọn ko ni lọ bi o ti ṣe yẹ ki o lọ.

PÀTÀKÌ MÍMỌ IPÒ ÀWỌN ỌMỌ ỌLỌ́RUN

Bi a ti ṣe wa ri ninu lẹta Pọọlu yi, aye awọn ọmọ ijọ Tẹsalonika n lọ bi o ti ṣe yẹ ki o lọ ninu irina-ajo igbagbọ wọn pẹlu Kirisiti Jesu, bi o tilẹ jẹ wipe awọn apọsiteli yi ko duro pẹ lọdọ wọn. Bawo ni wọn ṣe wa mọ pe aye awọn onigbagbọ yi n lọ bi o ti ṣe yẹ ki o lọ nigba ti o jẹ wipe wọn ko si pẹlu wọn? Nipasẹ Timoti, ẹni ti o ṣe ibẹwo si wọn, ni wọn ṣe mọ. Eyi tilẹ wa jẹ ki Pọọlu mẹnuba diẹ lara pataki ki gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun, paapaa julọ awọn adari wa, ma fi gbogbogb igba mọ ipo awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n jọsin papọ, ti a jọ n gbe papọ, ti wọn jẹ ẹbi wa tabi ti wọn wa ni abẹ isakoso wa. Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, igba meji ọtọọtọ ni o tikararẹ gbiyanju lati yọju si awọn ara Tẹsalonika yi, lẹyin igba ti inunibini ti jẹ ki wọn kuro ni ilu wọn, ki o ba le mọ ipo wọn. Wo alaye rẹ lori ọrọ yi:

“Ṣugbọn ara, awa ti a ya nipa kuro lọdọ yin fun saa kan nipa ti ara, kii ṣe ni nipa ti ẹmi. Pẹlu ọpọlọpọ itara ni awa ṣe aniyan ti a si fẹ gidigidi lati ri oju yin. Nitori awa fẹ lati tọ yin wa, ani emi Pọọlu lẹẹkinni ati lẹẹkeji, Satani si de wa ni ọna.” (1Tẹsalonika 2:17-18)

Pọọlu ko salaye lẹkunrẹrẹ ninu lẹta yi ọna ti Satani gba di oun ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ lọwọ lati yọju si awọn ara Tẹsalonika yi. Ṣugbọn pẹlu nkan ti o sọ yi, a ri daju pe Satani le di ọmọ Ọlọrun lọwọ lati ṣe ifẹ rẹ. O le lo ọ̀dá owo, inunibini, aisan, ijamba, ajalu, ofin ailojutu ati bẹẹbẹẹ lọ lati di wọn lọwọ. Ti a ko ba wọn ni imọ eyi, a ko ni gbe igbesẹ ti o loorin lati doju ija kọ oun ati awọn iṣẹ ibi rẹ pẹlu awọn ohun ija ti Ọlọrun ti fun wa, ki a si rin ni iṣẹgun lori wọn.

Ni kukuru, Satani di Pọọlu ati awọn iyoku rẹ lọwọ lati de Tẹsalonika nitori pe o mọ pataki ki wọn yọju si awọn onigbagbọ yi, ki wọn si mọ ipo ti wọn wa. Ki wa ni pataki ki a mọ ipo awọn onigbagbọ ti o wa labẹ iṣakoso wa tabi ninu aye wa? Lara rẹ ni iwọnyi, gẹgẹ bi Pọọlu ti jẹ ki o ye wa:

– Fun ifẹsẹmulẹ awọn ọmọ Ọlọrun ninu igbagbọ (1Tẹsalonika 3:1-4): Ki a di atunbi kọ ni opin ohun gbogbo ninu irin-ajo Kirisitiẹni; ipilẹ lasan ni o jẹ. Ṣugbọn ọpọ ni eyi ko ye. Nitorina eṣu gba wọn danu lẹyin ti wọn ti di atunbi tan, ko si jẹ ki wọn fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wọn. O wa le jẹ nitoripe wọn ko fi aye silẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun ti òye ye lati ṣe amojuto aye wọn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ni eyi ṣe waye tabi ki o jẹ wipe awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wọn ko ni oye pe ojuṣe wọn ni lati jẹ olutọju fun awọn ara wọn. Amọ òye eyi ye Pọọlu daradara. O mọ wipe oniruuru idojukọ ni awọn ti o ba gbagbọ ninu Jesu yoo ba pade ninu aye yi ati nitori igbagbọ wọn. O si ti tẹnumọ eyi fun awọn ara Tẹsalonika nigba ti o wa lọdọ wọn. Idi niyi ti oun ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ ṣe lepa pẹlu itara lati yọju si awọn ara yi, ki wọn ba le tu wọn ninu, fi ọrọ Ọlọrun bọ wọn ati fun wọn ni oriya lati ṣe amulo oore-ọfẹ Kirisiti Jesu lati fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wọn, bi o ti wu ki idojukọ ati inunibini ti wọn n ba pade pọ to. Ti awa naa ba fẹ ki awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n jọsin pọ tabi ti o wa ninu aye wa fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wọn, a gbọdọ ma fi gbogbo igba lepa lati mọ ipo ti wọn wa ati lati ṣe ohun yowu ti Ọlọrun ba fun wa ni oore-ọfẹ lati ṣe ki igbagbọ wọn ba le duro ṣinṣin.

– Ki laala awọn adari tabi olusọ awọn ọmọ Ọlọrun ma ba ja si asan (1Tẹsalonika 3:5-9): Pọọlu ati awọn yoku rẹ ti ṣiṣẹ karakara laarin awọn ara Tẹsalonika ki wọn to fi wọn silẹ. Ṣe o wa yẹ ki laala wọn lori awọn ara yi jasi asan bi? Ṣe o wa yẹ ki wọn de ijọba ayeraye Ọlọrun ki wọn si ma ba awọn eniyan yi nibẹ? Ko yẹ ki o ri bẹ. Ṣugbọn, gẹgẹ bi owe ti o sọ wipe, “Kí ojú má rí ibi, gbogbo ara lòògùn rẹ̀,” ti wọn ko ba gbe igbesẹ lati mọ ipo awọn ara yi, ki wọn si mọ bi wọn ti ṣe n ṣe deede si ninu irin-ajo igbagbọ wọn, o ṣeeṣe ki laala ti wọn ti ṣe lori wọn ja si asan. Idi si niyi ti wọn fi ṣe ran Timoti lati yọju si wọn, nigba ti wọn ri pe ko ṣeeṣe fun gbogbo wọn lati lọ. Ti awa naa ko ba fẹ ki gbogbo laala wa, adura wa, fififunni wa ati awọn ọrọ iyanju wa si awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa tabi ti a fi si abẹ akoso wa ja si pabo, a gbọdọ ri daju pe a mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye wọn ati pe a ko jina si wọn rara. Eyi yoo jẹ ki Ọlọrun le lo wa lati daabo bo wọn kuro lọwọ iṣẹ ati akitiyan Eṣu lati bi wọn lulẹ. Ti a ba wa ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki a ṣe fun awọn eniyan, ti wọn si papa wa ṣegbe, Ọlọrun funrarẹ yoo mọ wipe a ṣe iwọn ti a le ṣe, yoo si pin wa ni ere ti o tọ fun iṣẹ wa. Amọ ṣe a le fọwọ ṣoya pe a n ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki a ṣe ki laala wa lori awọn ọmọ rẹ ma ba ja si asan bi?

– Ki a le mu atunṣe tabi aṣepe ba kudiẹ-kudiẹ yowu ti o ba sọrọ mọ igbagbọ awọn ọmọ Ọlọrun (1Tẹsalonika 3:10): Pe a fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wa ninu Kiristi ko tunmọ si pe a ti di pipe patapata ni iwa, ero, iṣe, iwa-mimọ, ifẹ ati awọn eso tabi ẹbun ẹmi yoku. Nitorina, a nilo ibaṣepọ ti o loorin pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran bi tiwa, ti awọn naa duro ṣinṣin, ki Ọlọrun ba le ti ipasẹ wọn ṣe aṣepe awọn nkan ti o ku-diẹ-kaato ninu irin-ajo igbagbọ wa. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, awọn Ijọ Tẹsalonika jẹ awokọsẹ rere fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wọn. Idi si ni pe igbagbọ, ifẹ ati ireti wọn ninu Kirisiti Jesu munadoko. Sibẹsibẹ, apọsiteli yi mọ wipe o ṣeeṣe ki a si ri awọn kan lara wọn tabi awọn abala aye wọn kan ti nkan ko ti ṣe deede to ninu irin-ajo igbagbọ wọn. Fun apẹẹrẹ, bi lẹta rẹ keji ti ṣe fi ye wa, a ri awọn ọlẹ ati onimẹlẹ eniyan laarin wọn, awọn ti wọn n titori pe awọn n duro de Jesu kọ lati ṣiṣẹ ati lati wulo fun ara wọn ati fun awọn miran (2Tẹsalonika 3). Nitorina, o ri wipe o ṣe pataki ki oun yọju si wọn lati mọ ipo wọn, ki o ba le mojuto awọn kudiẹ-kudiẹ yowu ti o ba foju gáání ni aarin wọn. Awa naa wa gbọdọ fi eyi ṣe ẹkọ, ki a si ma fi gbogbo igba kiyesi awọn nkan ti a ba woye pe ko dara to ninu aye awọn ara wa, ki a ba le ṣe atunṣe wọn pẹlu ọgbọn Ẹmi mimọ.

– Awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba tipasẹ wa duro ṣinṣin yoo jẹ ade ogo ati ayọ fun wa nigba ti Jesu ba de (1Tẹsalonika 2:19-20): Bi o tilẹ jẹ wipe koko yi gan ni Pọọlu kọkọ mẹnuba ninu lẹta yi gẹgẹ bẹ ọkan pataki lari idi ti a ṣe gbọdọ ma fi gbogbo igba mọ ipo awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni abẹ iṣakoso wa tabi ti o wa ninu aye wa, ki a si ran iduro-ṣinṣin wọn lọwọ, oun ni yoo jẹ iriri ti a o ni kẹyin. Iriri yi ko si ni waye ninu aye yi bikoṣe ninu ijoba ayeraye ti Ọlọrun yoo fi lọlẹ ni akoko tirẹ. Ki ni nkan ti a n sọ? Oun naa ni wipe gbogbo awọn ti Ọlọrun ba lo wa lati jẹ ki wọn duro ṣinṣin ninu igbagbọ de opin ni yoo jẹ ade ogo ati ayọ fun wa nigba ti Jesu ba de. Ọpọ ọmọ Ọlọrun ni o n wa ogo wọn ti o sọnu kaakiri loni nitori pe oye nkan ti a n pe ni ogo ko ye wọn. Fun apẹẹrẹ, ki ni ogo Òrùn? Ogo Òrùn ni ki o tan imọlẹ kaakiri aye. Nitorina, ogo Kirisitiẹni ni ki ó gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki o gbe, ki o si ṣe awọn iṣẹ ti O fẹ ki o ṣe lẹkunrẹrẹ. Ara awọn iṣẹ ti O si fẹ ki ó ṣe ni ki ó mojuto awọn ọmọ rẹ ti ó wa ninu aye rẹ tabi ti o wa ni abẹ akoso rẹ, Ti o ba si ṣe iṣẹ yi debi pe awọn eniyan yi de ijoba ayeraye rẹ, o didan ki o ri ere gba lọwọ Ọlọrun. Ere yi ni Pọọlu ati Peteru pẹlu pe ni ade ogo ti ki i ṣa (1Peteru 5:1-4). Njẹ iwọ ha nifẹ si ade yi bi? Ti o ba nifẹ si, ripe o ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ fun iduro ṣinṣin awọn ọmọ Ọlọrun de opin ni aṣepe.

ỌRỌ IPARI

Ni ipari, Pọọlu gba adura pe ki Ọlọrun la ọna ti Satani di fun wọn lati le de ọdọ awọn ara Tẹsalonika yi, ki wọn ba le mu ifẹ rẹ ṣẹ lori aye wọn (1Tẹsalonika 3:11). O si tun gba adura fun awọn ara yi naa pe ki Ọlọrun mu wọn pọ si ninu ifẹ rẹ, ki O si tun fi okun fun ọkan wọn lati wa ni alailabuku ati ni mimọ nigba ti Jesu Oluwa wa ba farahan (1Tẹsalonika 3:12-13). Awa na si gbọdọ kọ lati ma gba irufẹ awọn adura yi. A gbọdọ ko lati ma gbadura pe ki Ọlọrun la ọna fun wa lati ṣe ifẹ rẹ ni igbakigba ti a ba woye pe Satani n gbogun lati di wa lọwọ. A tun gbọdọ ma fi gbogbo igba gba a ladura pe ki Ọlọrun fi okun fun ọkan wa lati wa ni alailabuku ati ni mimọ nigba yowu ti Jesu Oluwa wa ba de. Aijẹbẹ, ipa wa ati akitiyan wa lati ṣe ifẹ rẹ ati lati duro ni pipe niwaju rẹ ni gbogbo igba di dandan ki o ja wa kulẹ.

IBEERE – Ọpọ ọmọ Ọlọrun ni ko ni oye pe Satani le di wọn lọwọ lati ṣe ifẹ Ọlọrun. Ki ni idi?

– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:17-3:13 Read More »

Ọ̀tá ara rẹ | Pst. J.O. Lawal | Òkúdù 26, 2022 | Vol. 11, No. 8

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Tayọtayọ ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Òkúdù 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n di ifarahan ibukun rẹ lọna ti o peye ninu aye rẹ lọwọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu ààlọ́ ti Jesu pa lori ọkunrin kan ti o fun awọn iranṣẹ rẹ ni owo kan lati fi ṣiṣẹ, a ri ẹkọ atigbadegba kan ti o ṣe pataki dimu. Oun naa si ni pe ẹnikẹni ti ko ba ni fi ọpọlọ pipe ṣe amulo awọn ibaṣepọ, amuyẹ, anfaani tabi oore-ọfẹ ti Ọlọrun fun laye yi ko ni pọ si ni iṣẹ rere ati ni awọn nkan daradara ti aye yi. Kiki awọn ti o ba n lo ọpọlọ wọn lati fi gbogbo igba ṣe amulo awọn nkan ti Ọlọrun fun wọn ni yoo tẹsiwaju lati ma pọ si ni iṣẹ rere ati ni nkan daradara. 

Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, ọkunran kan ti o n lọ si irin-ajo jinjin pinnu lọkan rẹ lati fun awọn ọmọ ọdọ rẹ kan ni diẹ lara owo rẹ, ki wọn ba le fi ṣiṣẹ. Eyi jasi pe ko fẹ ki owo rẹ kan joko kalẹ sinu kolo rẹ, ki eruku ma bo mọ ibẹ nigba ti ko ba si nile. Nitorina, o fun awọn iranṣẹ rẹ lara rẹ lati ṣiṣẹ, gẹgẹ bi ipa ẹnikọọkan wọn ti mọ. O fun ẹnikan ni talẹnti marun-un. O fun elomiran ni talẹnti meji. O si tun fun elomiran ẹwẹ ni talẹnti kan.

Wayi o, lẹyin ọjọ pipẹ, ọkunrin yi pade lati irin-ajo rẹ, o si bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo nkan ti awọn ọmọ ẹyin rẹ ṣe pẹlu owo ti o fun wọn. Si iyalẹnu rẹ, meji pere lara wọn ni o ṣiṣẹ pẹlu owo ti o fun wọn, ti wọn si sọ di pupọ si. Ọkunrin ti o gba talẹnti marun-un jẹ ere talẹnti marun-un miran pẹlu owo ti a fun. Bẹẹ si ni pẹlu, ọkunrin ti o gba talẹnti meji naa jẹ ere talẹnti meji miran pẹlu owo ti a fun. Amọ awawi lasan ni ọkunrin ti a fun ni talẹnti kan mu wa. Ko ṣe nkankan pẹlu talẹnti ti a fun. Nitorina ko jẹ ere kankan pẹlu rẹ. 

Ki wa lo fa ti ọkunrin yi ko fi ṣe nkankan pẹlu talẹnti tirẹ? Idahun ti awọn eniyan ṣaba ma n fun ibere yi ni pe ọkunrin yi ko ṣe nkankan pẹlu talẹnti tirẹ nitoripe o woye pe o ti kere ju, ti a ba ṣe afiwe re pẹlu eyi ti a fun awọn yoku. Ṣugbọn eyi ko ki i ṣe idi ti ko fi lo rara. Lakọkọ, oluwa wa fun ẹnikọọkan wọn ni owo ti o fun un ni ibamu pẹlu ipa rẹ. Nitorina, nkan ti ipa iranṣẹ yi ka ni a fun. Ekeji, awọn olukọtan jẹ ki o ye wa pe talẹnti kan ni akoko yi dabi ki a ko owo iṣẹ ojumọ alagbese kan jọ fun bi ogun ọdun. Nitorina, ọpọlọpọ owo ni a fun ọkunrin yi.  

Eyi wa jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe nitoripe owo ti a fun kere ni ko ṣe ṣe nkankan pẹlu rẹ. Dipo bẹẹ, gẹgẹ bi ọrọ oun funrarẹ, nitoripe ẹru lati padanu owo naa n ba a ni ko ṣe ṣe nkankan pẹlu rẹ (Matiu 25:25). Ṣugbọn bi oluwa rẹ ti ṣe sọ fun, ti o ba jẹ wipe o fi owo yi si ile ifowopamọsi ni, nṣe ni ko ba gba a pada pẹlu èlé lori rẹ. Nitorina, ẹ̀rù ko to gẹgẹ bi idi fun lati ma ṣe nkankan pẹlu aduru owo nla yi. O ni iṣoro miran, eyi si ni imẹlẹ. O tunmọ si pe nitoripe ọkunrin yi ya ọlẹ ninu ọpọlọ rẹ ati pẹlu ọwọ rẹ ni ko ṣe gbiyanju rara lati wo ọna ti o le gba sọ owo ti a fun di pupọ si. Nitori eyi, o wa papa jẹ ki nkan ti oluwa rẹ ko fẹ ki o ṣẹlẹ ṣẹlẹ — o jẹ ki owo rẹ kan wa ni ojukan laipọsi.

Ki a ma fa ọrọ gun, yatọ si ijiya ti a fun ọkunrin ọlẹ ati alailere yi, oluwa rẹ tun paṣẹ pe ki a gba owo ti a fun kuro lọwọ rẹ, ki a si fun ọkan lara awọn iransẹ ti wọn ti fi ara wọn han gẹgẹ bi ẹni ti o dangajia lati ri nkan gba si lọwọ ọga wọn. Ni ipari, Jesu Oluwa wa wa sọ wipe bi nkan ti ṣe ri gẹlẹ niyi ninu ijọba Ọlọrun. Awọn ti o ba kọbiara si nkan ti Ọlọrun fun wọn – eniyan, dukia, amuyẹ, ẹbun, ẹkọ, ipo ati bẹẹbẹẹ lọ – bi o ti wu ki awọn nkan yi kere tabi ki wọn ma ṣe pataki to – ti wọn si n ṣe amulo to peye wọn nikan naa ni yoo  tẹsiwaju lati maa gbe ga ati lati jẹ ki wọn ma pọ si ni nkan rere. Ṣugbọn awọn ti ko ṣe nkankan pẹlu nkan ti O fun wọn ko ni ireti mi ju pe ki a tun gba nkan ti a fun wọn kuro lọwọ wọn, bi o ti wu ki nkan naa kere to. Eyi si ni alaye fun bi awọn otoṣi eniyan ni ọpọ igba ṣe ma n toṣi si ati ti awọn olowo ati gbajumọ eniyan ni ọpọ igba ṣe ma n di olowo ati ilumọọka si. 

Nitorina, ti o ko ba ma ṣe amulo awọn nkan ti Ọlọrun fun ọ tabi tí Ó ti jẹ ki o ri gba nipa oore-ọfẹ rẹ, nṣe ni o n fi ara rẹ han bi alailere ati bi ẹni ti ibi giga ko tọ si laye yi. Iwọ gan an wa ni ọta ara rẹ lori ọrọ yi, bi awawi rẹ ṣe wu ko ri. Iwọ ni o n de ara rẹ lọna, ti o si tun n ja ara rẹ kulẹ. Nitorina, ma ṣe reti ki nkan dara si fun ọ nigba ti o jẹ pe yoo buru si ni.

Wayi o, adura mi ni pe ki nkan ma fi gbogbo igba dara siwaju ati siwaju fun ọ dipo ko ma buru si. Ṣugbọn gbigbadura nipa rẹ nikan ko to. Iwọ na nilo lati ji kuro ninu oorun rẹ, ki o ye wa awawi fun ikuna tabi ìṣẹ́ rẹ mọ, ki O si ṣe ìdámọ̀ ati àmúlò ohun gbogbo ti Ọlọrun fun ọ ti o le lo lati pọ si ni iwulo, iṣẹ rere ati dukia ni aye yi. Bi o ba si ṣe n ṣe eyi, iyalẹnu ni yoo jẹ fun ọ nigba ti o ba ri bi awọn iIbukun Ọlọrun ti o ti farasin ninu aye ṣe bẹrẹ si ni farahan ni ẹkunrẹrẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀tá ara rẹ | Pst. J.O. Lawal | Òkúdù 26, 2022 | Vol. 11, No. 8 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ. | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:13-16 | ỌJỌ́RÚ 08, ÒKÚDÙ 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ ti a kọ pari ninu lẹta Pọọlu kinni si ijọ Ọlọrun ti o wa ni Tẹsalonika, a ri irufẹ iṣẹ iranṣẹ ti o le mu ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ laarin alaigbagbọ ati laarin awọn ti o gbagbọ pẹlu. Eyi si jẹ iṣẹ iranṣẹ ti afojusun rẹ duro lori bi yoo ṣe gba oriyin Ọlọrun dipo oriyin eniyan ati eyi ti ko ki i wo bi nkan ba ti ṣe rọrun si ki o to fi ara rẹ jin fun ifẹ Ọlọrun. Amọ ṣa o, pe iṣẹ iranṣẹ ojiṣẹ Ọlọrun kan munadoko ko wa tunmọ si pe o di dandan ki o so eso rere ninu aye awọn ti o ba tọ wa tabi ti o n waasu si. Iha ti awọn ti a mu ọrọ Ọlọrun tọ wa ba kọ si ọrọ ti a mu tọ wọn wa naa ni ipa pataki lati ko lori irufẹ eso ti aye wọn yoo so. 

Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe iṣẹ iranṣẹ Mose munadoko, ti o si jẹ eyi ti Ọlọrun funrarẹ tẹwọgba, ko so eso rere ninu aye ọpọ awọn ọmọ Isiraẹli ti o ko jade lati ilẹ Ijibiti. Gẹgẹ bi a ti fi ye wa ninu bibeli, ọpọlọpọ wọn ni ko wọ ilẹ ileri ti a mu wọn jade lati wọ. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko kọ iha ti o tọ si iṣẹ iranṣẹ Mose ati awọn ọrọ Ọlọrun ti o mu tọ wọn wa. Nitorina, ọtọ ni ki ojiṣẹ Ọlọrun ja fafa, ki o si mu iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun ni pataki ati pẹlu ọkan ti o pe; ọtọ si tun ni ki awọn ti a ran si naa mu ọrọ Ọlọrun ti o mu tọ wọn wa ni pataki, ki wọn si gba pẹlu ọkan ti o pe. Aijẹbẹ, ete Ọlọrun ko ni wa si imuṣẹ lori aye wọn. 

Wayi o, a n sọ eleyi kí á ma bà rò wípé òjíṣẹ́ Ọlọrun naa ni a gbọdọ da ẹbi le lori ti awọn ọmọ ijọ rẹ ko ba dagba soke ninu ẹmi tabi ki wọn ma rin ni pipe niwaju Ọlọrun, bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ọpọ ninu ijọ ni ko dagba soke bi o ti ṣe tọ loni nitoripe awọn funra wọn ko kọ iha ti o tọ si iṣẹ iranṣẹ awọn ti a ran si wọn. Ọpọ ni o si wa ni ipo aigbagbọ loni pẹlu, ti Eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ n pọn loju nitoripe wọn kọ lati ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun ti a n mu tọ wọn wa lojoojumọ tabi loorekoore.

Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ wipe, “Ẹni ti o ba gba wolii ni orukọ wolii, yoo jẹ ere wolii; ẹni ti o ba si gba olododo ni orukọ olododo yoo jẹ ere olododo.” (Matiu 10:41) O si sọ eyi nitoripe ọpọ awọn eniyan rẹ, iyẹn awọn Juu ti O ni anfaani lati jẹ igbadun iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ko jẹ igbadun rẹ. Ki si ni idi? Idi ni wipe wọn ko gbaagbọ tabi gba ọrọ Ọlọrun ti O mu tọ wọn wa gbọ. Nitorina, ọrọ rẹ ko so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so ninu aye wọn. Ti iṣẹ iranṣẹ Jesu ba wa kuna lati so eso rere ninu aye ọpọ ti o ni oore-ọfẹ lati gbọ ọrọ rẹ, o yẹ ki a mọ pe ko si ara kankan ti iranṣẹ rẹ kankan le da ti awọn ti a ran si ba kuna lati gba ọrọ rẹ gbọ, ki wọn si ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu rẹ. (Wo: Johanu 1:10-13; Johanu 15:18-25)

ÌHÀ TÍ Ó TỌ́ SÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Nkan ti a n sọ nipe ko si bi iṣẹ iranṣẹ awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti o n tọ wa wa ṣe le munadoko to, ti a ko ba tẹwọgba wọn ati ọrọ Ọlọrun ti wọn n mu tọ wa wa bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ, iṣẹ iranṣẹ wọn ko ni so eso rere ninu aye wa. Gẹgẹ bi Pọọlu ti sọ siwaju ninu lẹta yi, iṣẹ iranṣẹ rẹ so eso rere ninu aye awọn ara Tẹsalonika to bẹẹ gẹẹ ti iroyin igbagbọ wọn ṣe n tan kalẹ kaakiri gbogbo ilu ati awọn agbegbe ti o yi wọn ka. Ki lo si fa? Iha ti wọn kọ si iṣẹ iranṣẹ apọsiteli yi ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ni o fa. Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi:

“Nitori eyi ni awa ṣe n dupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu ni aisinmi. Pe nigba ti ẹyin gba ọrọ ti ẹyin gbọ lọdọ wa, ani ọrọ Ọlọrun, ẹyin ko gba a bi ẹni pe ọrọ eniyan. Ṣugbọn ẹ gba a gẹgẹ bi o ti jẹ nitootọ, bi ọrọ Ọlọrun, eyi ti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹyin ti o gbagbọ pẹlu.” (1Tẹsalonika 2:13)

Njẹ o ri bayi? Awọn ara Tẹsalonika yi ko ri ọrọ Ọlọrun ti a mu tọ wọn gba gẹgẹ bi ahesọ ṣugbọn wọn ri gẹgẹ bi otitọ ọrọ Ọlọrun. Lotitọ, ko ki i ṣe bi ẹnu oniwaasu ba ṣe dun si tabi bi o ba ṣe mọ ọrọ gbe kalẹ si ni yoo ṣokunfa igbagbọ awọn ti o ba gbọ ọrọ rẹ. Iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati jẹ ki awọn eniyan ri ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi otitọ ninu ọkan wọn, ki wọn si gbe igbesẹ ti o tọ lori rẹ (Johanu 16:8-11; 1Kọrinnti 12:3). Amọ ẹni ti o ba ni lọkan lati ṣe ifẹ Ọlọrun tẹlẹ ni yoo kọbiara si oye ti Ẹmi Ọlọrun fẹ fi ye lori otitọ ọrọ rẹ (Jọhanu 7:17). Ẹni ti ko ba fẹ ṣe ifẹ Ọlọrun ko ni kọbiara si ọrọ rẹ, bi o tilẹ mọ ninu ọkan rẹ pe otitọ ni.

Awọn ara Tẹsalonika, ti wọn ti fi igba kan ri jẹ abọriṣa gba ọrọ Ọlọrun ti Pọọlu mu tọ wọn wa gẹgẹ bi otitọ. Eyi si fi ye wa pe awọn ti o gbagbọ yi ti ni lọkan lati mọ otitọ ati lati ṣiṣe le lori ki wọn to ṣe alabapade iṣẹ iranṣẹ Pọọlu. Niwọn igba ti wọn si ti gbagbọ, ọrọ Ọlọrun ti wọn gbọ bẹrẹ si ni ṣisẹ ninu aye wọn, o si bẹrẹ si ni so eso ti Ọlọrun fẹ ko so nibẹ, to bẹẹ gẹ ti Pọọlu ṣe tẹsiwaju lati sọ nipa wọn pe, “Nitori, ara, ẹyin ṣe afarawe awọn ijọ Ọlọrun ti n bẹ ni Judia, ninu Kirisiti Jesu. Idi ni pe ẹyin pẹlu jiya ju wọn lọ lọwọ awọn ara ilu yin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jiya lọwọ awọn Juu.” (1Tẹsalonika 2:14)

Nibakanna, ti awa naa ba fẹ ṣe ifẹ Ọlọrun, ti a ba ni lọkan lati pilẹ aye wa ati ohun gbogbo ti a n ṣe lori otitọ, o di dandan ki a gba ọrọ otitọ rẹ gbọ nigba yowu ti o ba tọ wa wa. Ti a ba si gba ọrọ otitọ rẹ gbọ, o di dandan ki o ṣiṣẹ ninu aye wa, ki o si so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so. Ti a ba wa woye pe aye wa ko so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so tabi pe ko lọ ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, nṣe ni o yẹ ki a kọkọ wo iha ti a kọ si ọrọ rẹ dipo ti a o fi ma da awọn ojiṣẹ rẹ ti a ran si wa lẹbi. 

Ọpọ ni o n lọ lati inu ijọ kan de inu ijọ miran loni, bi ọpọ miran si tun ṣe n lọ lati ori oke kan de ori oke miran. Ki lo si fa? Wọn ko ni igbagbọ to ninu iṣẹ iranṣẹ awọn alufa tabi adari ijọ wọn. Amọ bi mo ti ṣe sọ siwaju, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o jẹ wipe iṣẹ iransẹ awọn ti a ran si wa ti ko munadoko to ni ko jẹ ki aye wa dagba soke tabi lọ siwaju bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ. Niwọn igba ti a ko ba ti kọ iha ti o tọ si iṣẹ iranṣẹ wọn, ko si ni bi aye wa yoo ṣe jere iṣẹ iranṣẹ naa.

ỌRỌ IPARI

Ọrọ Ọlọrun lagbara lati ṣiṣẹ ninu aye wa fun imuṣẹ ifẹ rẹ. Amọ ti a ko ba kọ iha ti o tọ si, ki a si gba ọrọ rẹ bi ọrọ rẹ dipo bi ọrọ eniyan, ko ni so eso rere ninu aye wa, bi o ti wu ki awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ munadoko to.

IBEERE

–    Ki ni o ro pe o fa ti ọpọ ko ki fi gba ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi ọrọ rẹ ninu ijọ loni?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ. | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:13-16 | ỌJỌ́RÚ 08, ÒKÚDÙ 2022 Read More »