(AYỌKA: 1TẸSALONIKA 1:1-10)
ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Gẹgẹ bi a ti ri ninu iwe Iṣe awọn Apọsiteli, ilu Tẹsalonika jẹ ọkan lara awọn ilu ti Pọọlu ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ ninu ipolongo ihinrere Jesu ti waasu nigba ti o jade ni igba keji fun irinajo iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi apọsiteli ati olukọ ọrọ Ọlọrun. Akoko diẹ perete ni wọn si ni lati waasu ni ilu yi. Idi si ni pe awọn Juu ti o wa nibẹ ko fi wọn lara balẹ rara. Nṣe ni wọn ṣe inunibini wọn to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi nilo lati sa kuro ni ilu yi ni ọganjọ-oru. Wọn ko si tun fi wọn lọrun silẹ titi wọn fi ri wipe Pọọlu tun fi Beria, ilu miran ti wọn lọ nigba ti wọn kuro ni Tẹsalonika, silẹ fun wọn. Wọn si ṣe gbogbo eyi nitoripe wọn ko fẹ ki ihinrere Jesu Kirisiti tan kalẹ ni ibi gbogbo, ki o si sọ awọn ti o ba gbaagbọ di alabukunfun. (Wo: Iṣe Apọsiteli 17:1-15)
Amọ ṣa o, niwọn igba ti o jẹ wipe Pọọlu ati awọn arakunrẹ ninu iṣẹ-iranṣẹ ti ri oore-ọfẹ gba lọwọ Ọlọrun lati fun irugbin ọrọ rẹ sinu aye awọn kan ni Tẹsalonika, ko si inunibini kankan ti o le di irugbin yi lọwọ lati so eso rere. Lotitọ, Pọọlu gbiyanju, gẹgẹ bi a o ti ri ninu lẹta rẹ akọkọ si wọn, eyi ti a fẹ bẹrẹ si ni gbe yẹwo ninu ẹkọ yi, lati pada yọju si awọn ara yi. Ṣugbọn Sàtánì ko jẹ ki o ṣeeṣe fun. Idi si ni yi ti o fi wa pinu lati ran Timoti si wọn, ki o ba le bẹ wọn wo, ki o si mu iroyin wa nipa wọn. Nigba ti apọsiteli yi ati awọn yoku rẹ si wa pada bẹrẹ si ni gburo igbagbọ wọn, wọn ko le pa ayọ wọn mọ rara. Eyi lo si fa ti wọn ṣe kọ lẹta ti a fẹ gbe yẹwo yi si wọn lati gba wọn niyanju siwaju si ninu irinajo igbagbọ wọn.
`IJỌ ÀWÒKỌ́ṢE Wayi o, nkan akọkọ ti a ri ninu lẹta ni yi pe Pọọlu jẹ ki o ye wa ibi ti lẹta naa ti ṣe jade wa ati awọn ti a kọ ọ si nipa sisọ eyi: “Eyi ni iwe Pọọlu, Silifanu ati Timoti, ti a ko si ijọ awọn ara Tẹsalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kirisiti Oluwa: Ki Oore-ọfẹ ati alaafia Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ki o wa pẹlu yin.” (1Tẹsalonika 1:1) Bawo ni a ṣe ṣe apejuwe awọn onigbagbọ yi? A pe wọn ni olugbe ninu Ọlọrun Baba ati Jesu Kirisiti Oluwa. Eyi tunmọ si pe ibugbe nipa ti ara nikan ni Tẹsalonika jẹ fun awọn ara yi. Wọn tun ni ibugbe miran nipa ti ẹmi, eyi si wa ninu Ọlọrun ati ninu Ọmọ rẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ri fun gbogbo ọmọ Ọlọrun patapata. Ibi yowu ti a le wa ninu aye yi, ibugbe ti ara ni. Ṣugbọn a ni ibugbe miran ninu Jesu Kirisiti funrarẹ nipa ti ẹmi. Eyi si ni o fi wa si ipo lati lo aṣẹ ati agbara rẹ lati gbe igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun, ti o si tun nitunmọ ni ibi yowu ti a ba wa.
Nkan ekeji ti Pọọlu mẹnuba ninu lẹta yi ni i ṣe pẹlu nkan ti wọn n ranti awọn ara Tẹsalonika yi fun, eyi ti o si jẹ ki wọn ma dupẹ lọwọ Ọlọrun lori wọn. Iwọ naa wo nkan ti o sọ nipa wọn: “Awa n dupẹ lọwọ Ọlọrun nigba gbogbo nitori gbogbo yin, awa si n ranti yin ninu adura wa; Ni aisinmi ni awa n ranti iṣẹ igbagbọ, laalaa, ifẹ, suuru ati ireti yin ninu Oluwa wa Jesu Kirisiti, niwaju Ọlọrun ati Baba wa. Awa si mọ pe Ọlọrun ni o yan yin, ara olufẹ.” (1Tẹsalonika 1:1-4) Kini Pọọlu ati awọn yoku rẹ n ranti nipa awọn ara Tẹsalonika ninu Kirisiti? Wọn n ranti iṣẹ igbagbọ wọn. Eyi tunmọ si pe igbagbọ wọn ko ki i ṣe ti ẹnu lasan – wọn n ṣiṣẹ tọ ọ lẹyin. Wọn tun n ranti laalaa ifẹ wọn ati suuru ti ireti ti wọn ni fun bibọ Jesu bi sinu aye wọn. Eyi lo si fa ti wọn ṣe n fi gbogbo igba ranti wọn ninu adura, ti wọn si n ṣọpẹ niwaju Ọlọrun lori aye wọn, nitori pe wọn mọ daju pe ọmọ Ọlọrun tootọ ni awọn wọnyi jẹ.
Njẹ awọn ara wa ninu Oluwa naa le fọwọ sọya pe ọmọ Ọlọrun ni a jẹ nitooto? Ki tilẹ ni wọn a ma ranti nipa wa nigba ti a ko ba si pẹlu wọn tabi wa nitosi? Njẹ wọn n ranti wa gẹgẹ bi onigbagbọ ododo, olufẹ Ọlọrun ati eniyan ati ẹni ti o n mura silẹ de bibọ Jesu bi? Abi nṣe ni wọn n ranti wa gẹgẹ bi onijagidijagan, ọbayejẹ, alaigbọran, gbeborun, alagbere ati bẹẹbẹẹ lọ? Eyi ni yoo sọ irufẹ adura ti wọn yoo ma gba fun wa ati pe boya wọn yoo ma fi ọpẹ fun Ọlọrun lori aye wa tabi bẹẹkọ.
Lotitọ, bi apọsiteli yi tun ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, irufẹ ọrọ ihinrere Jesu ti awọn eniyan naa ba gbọ tabi ba n gbọ ni ipa pataki lati ko lori irufẹ igbagbọ ti wọn yoo ni ati bi yoo ti ṣe fi ẹṣẹ mulẹ to. Ni tiwọn, ihinrere ti wọn mu tọ awọn ara Tẹsalonika yi wa jẹ eyi ti o jade pẹlu Ẹmi Ọlọrun funrarẹ ati agbara rẹ ati pẹlu idaniloju ti o peye lati ọdọ awọn naa ti wọn n waasu. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ọrọ ihinrere ti yoo so eso rere ninu aye awọn eniyan gbọdọ jẹ eyi ti Ẹmi Mimọ tẹle ati eyi ti ẹni ti o n waasu naa ni idaniloju nipa iṣẹ ti o le ṣe ninu aye awọn ti o ba gbagbọ. Nitorina, ti ko ba da wa loju pe ihinrere Jesu ni agbara lati gbala ati lati mu ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye awọn eniyan, a ko lẹtọ lati ma polongo rẹ. Nkan ti ko si ni jẹ ki o da wa loju naa ni wipe ko i ti ṣiṣẹ ninu aye awa tikalara wa. (Wo: 1Tẹsalonika 1:5)
Nkan ẹkẹta ti Pọọlu mẹnuba ninu lẹta nipa awọn ara Tẹsalonika wọnyi da lori ọna ti igbagbọ wọn n gba ran awọn onigbagbọ ti o wa ni ibomiran lọwọ. Iwọ naa wo awọn nkan ti o sọ nipa wọn:
“Ẹyin ṣe afarawe wa, ati ti Oluwa, lẹyin ti ẹyin ti gba ọrọ naa ninu ọpọlọpọ ipọnju pẹlu ayọ Ẹmi Mimọ: Ti ẹyin si jẹ apẹẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ ni Masedonia ati Akaya. Nitori lati ọdọ yin lọ ni ọrọ Oluwa ti jade, kii ṣe ni kiki Masedonia ati Akaya nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni iyin igbagbọ yin si Ọlọrun tan kalẹ to bẹẹ ti awa ko ni iṣoro ohunkohun. Nitori pe awọn tikarawọn royin bi ẹ ti tẹwọ gba wa nigba ti a wa sọdọ yin, ati bi ẹyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ibọriṣa lati maa sin Ọlọrun alaaye ninu otitọ; Ti ẹ si n mura silẹ de bibọ ọmọ rẹ lati ọrun wa, ẹni ti o ji dide kuro ninu oku, ani Jesu naa, ẹni ti n gba wa kuro ninu ibinu ti n bọ.” (1Tẹsalonika 1:6-10)
Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ ninu lẹta yi, daju ṣaka ni pe awokọsẹ rere ni ijọ Tẹsalonika jẹ fun awọn ijọ Ọlọrun miran ti o wa laye ni akoko yi. Ki lo si jẹ ki o ri bẹ? Nkan ti o jẹ ki o ri bẹ ni wipe wọn kọkọ yipada kuro ninu ibọriṣa patapata lati maa sin Ọlọrun alaaye ninu otitọ. Eyi tunmọ si pe wọn ko ma ṣe igbagbọ ko-ṣeku-ko-ṣẹyẹ. Wọn ko ma sin Ọlọrun ni ẹgbẹ kan, ki wọn si tun ma bọ oriṣa ni ẹgbẹ miran. Wọn ko ma si Ọlọrun ni ẹgbẹ kan, ki wọn si tun ma gbe igbe aye iṣẹkuṣe, ole jija, ajinigbe tabi apaniyan ni ẹgbẹ miran. Dipo eyi, kedere ni o han si gbogbo awọn ti o wa ni ayika wọn pe wọn ti fi ara wọn jin patapata fun Ọlọrun.
Yatọ si iyẹn, awọn ara yi tun bẹrẹ si ni gbe igbe aye ti o fihan gbogbo eniyan pe wọn n mura silẹ de Jesu Kirisiti. Eyi jasi pe wọn ko jẹ ki nkan ti aye yi kankan gba ọkan wọn tabi jọba lori wọn. Dipo eyi, nṣe ni wọn n ṣe afarawe awọn apọsiteli ti o waasu fun wọn ati Jesu Kirisiti Ọmọ Ọlọrun ti a waasu rẹ fun wọn. Nitorinaa, Ọlọrun wa bẹrẹ si ni lo wọn gẹgẹ bi apẹẹrẹ igbagbọ otitọ fun awọn ọmọ rẹ yoku ti o wa ni ayika wọn ati awọn alaigbagbọ pẹlu.
Nkan ti eyi si fi n han wa ni wipe Ọlọrun ko kan fẹ ki a di atunbi ninu Jesu Kirisiti nikan; O tun fẹ ki a bẹrẹ si ni gbe igbe aye ti yoo jẹ awokọṣe fun gbogbo awọn ti o ba wa ni ayika wa. Ṣe bayi ni o si wa ri fun wa? Ṣe awokọṣe onigbagbọ tootọ ni a jẹ gẹgẹ bi ijọ tabi gẹgẹ bi ẹnikọọkan fun awọn ti o wa ni ayika wa? Abi ṣe a kan n gbe igbe aye ti o wu wa ni, igbe aye ti ko ni itunmọ, igbe aye ti ko jọ wipe a mọ pe ohun gbogbo ko pin si aye yi ati pe Jesu Oluwa wa n bọ ni ọjọ kan lati mu wa si ọdọ rẹ ati lati ṣe idajọ aye yi?
O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa ti a pe ara wa ni onigbagbọ loni ni a ko bikita rara nipa irufẹ igbe aye ti a n gbe ati ipa ti o n ko lori aye awọn ti o wa ni ayika wa. Ọpọ ninu wa si tun ni ko tilẹ fẹ gbọ pe Jesu n pada bọ wa rara. Eyi si n jẹ ki irufẹ igbagbọ ti a gba kọ eniyan lominu, yatọ si pe o n di itankalẹ ihinrere Jesu lọwọ laarin awọn alaigbagbọ.
Ọ̀RỌ́ ÌPARÌ Ni kukuru, lẹta yi n fi han wa pe ifẹ Ọlọrun fun wa ni pe ki a ma gbe igbe aye igbagbọ ti o n buyi fun orukọ Jesu, ti o n jẹ ki ihinrere Jesu wu awọn eniyan lati gbọ, ti o si tun ru awọn ọmọ Ọlọrun miran soke lati mu iduro ṣinṣin wọn ninu Kirisiti ni pataki.
ÌBÉÈRÈ – Kini pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
ALAYTHIA BIBLE CHURCH (ÌJỌ ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ) ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 01, ÒKÚDÙ 2022.