Akori: Bawo ni o ti ṣe n lọ pẹlu rẹ? | Lati ọwọ: J.O. Lawal Ọjọ: Erele 27, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa ọwọn. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ pẹlu rẹ ninu ọsẹ naa ati titi Jesu Oluwa wa yoo fi pade de. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti ẹni ti o kọ iwe Heberu tẹnumọ ninu gbogbo oju-ewe iwe naa ni pataki ki ijọ Ọlọrun kọọkan ma fi oju ṣọ awọn ọmọ ijọ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ki wọn ma ba ṣina ṣako lọ kuro ninu ifẹ Ọlọrun fun aye wọn ati ki wọn ma ba ba ilera ijọ jẹ tabi pa a lara. Nitorina, ti ọmọ ijọ rẹ kankan ba ṣiju si ọrọ aye rẹ, ti o si tun n bere awọn ibere ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ati igbagbọ rẹ lọwọ rẹ, ma fi ṣe ibinu tabi ki o bẹrẹ si ni bu wọn. Nṣe ni wọn n mu ofin Kirisiti ṣe lori aye rẹ (Galatia 6:2).

Wayi o, mi o wa sọ pe gbogbo awọn ti o wa ninu ijọ rẹ naa ni wọn loye to lati mọ awọn nkankan nipa aye rẹ tabi lati ṣe amulo ti o peye nkan ti o ba sọ fun wọn nipa ara rẹ. Mi o si tun so pe gbogbo ẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni naa ni o le fi ọrọ aye rẹ han. Ẹnikẹni, gẹgẹ bi ọrọ iwe mimọ, ti igbe aye igbagbọ rẹ ko ba han kedere si ọ lati ri, ki o ba le sọ daju pe ko ni ṣe ọ ni ijamba, fi idibajẹ saye rẹ tabi yan ọ jẹ, jẹ ẹni ti o yẹ ki o ṣọra fun. Ti o ba si wa woye pe ko si ẹnikẹni ninu ijọ rẹ ti o loye to lati mọ ohun ti o n lọ laye rẹ tabi lati ma fi oju ṣọ ẹ, nṣe ni ki o kuro nibẹ ki o si gba ijọ miran lọ ti iwọ yoo ti le turuka. Aijẹbẹ, ko ni pẹ ti o o fi pa igbagbọ tabi aye rẹ lara. (Wo: 2Kọrinnti 7:2)

Nitorina, fun anfaani ara rẹ, duro sinu ijọ ti o ba ti mọ pe o le turuka nibẹ fun awọn ara rẹ lati mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ ati lati ma fi oju ṣọ ọ. Lafikun, fun ilera ijọ Ọlọrun, o ṣe pataki ki o fi bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ han awọn ara rẹ, ki o si tun jẹ ki wọn darapa mọ ọrọ ayẹ rẹ lọna ti o peye, ki wọn ba le ma fi gbogbo igba ran ọ lọwọ lati gbajumọ ṣiṣe ifẹ Ọlọrun.

Ki lo fa ti a ṣe ni ọpọlọpọ Kirisitiẹni ti igbagbọ wọn ko mọkun ati ti ko gboriduro ni ọpọ ijọ wa loni? Ki si ni idi ti a ti fi ri ọpọ ijọ wa ninu eyi ti awọn ara ti n ṣe ẹtanu ara wọn tabi ti wọn n fi gbogbo igba ja lori nkankan tabi omiran? Idi kan pataki fun eyi ni pe ọpọ wa ko fẹ ki awọn ara wa mọ nkan ti o n lọ ninu aye wa tabi ki wọn tun aye wa to? Nkan ti a fẹ ni ki a ma gbe aye wa bi o ti ṣe wu wa, lalai si ilọwọsi tabi idasi ẹnikẹni. Eyi ko si dara rara fun wa tabi fun ilera ijọ Ọlọrun.

Fun apẹẹrẹ, ẹni ti o kọ iwe Herebu sọ eyi fun wa: “Ẹ ma kiyesara ki ẹnikẹni ki o ma ṣe kuna oore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbongbo ikoro kan ki o ma baa hu ṣoke ki o si yọ yin lẹnu, ọpọlọpọ a si ti ipa rẹ di aimọ; Ki ẹnikẹni ma baa di alagbere tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Isọ, ẹni ti o ti itori okele ounjẹ kan ta ogun ibi rẹ.” (Heberu 12:15-16) Bawo ni a ṣe le kiyesara lati ri pe ọkankan ninu wa ko kuna oore-ọfẹ Ọlọrun, ti a ko ba mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye gbogbo wa? Bawo ni a ṣe le ri pe ikoro tabi iyapa ko ṣẹlẹ laarin wa, ti a ko ba mọ nkan ti o n ṣẹlẹ laarin wa? Tabi bawo ni a ṣe le ma jẹ ki awọn ara wa bọ sinu panpẹ agbere tabi ẹṣẹ miran ti o le ba aye tabi igbeyawo wọn jẹ, ti a ko ba mọ ohun ti o n lọ ninu aye wọn? Ko le ṣeeṣe fun wa.

Wo o, igba ti a ba ni oye ti o peye nkan ti o lọ ninu aye wa ni a le ran ara wa lọwọ lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ ni ọna ti o peye. Bẹẹ si ni, igba ti a ba ni imọ ti o ye kooro awọn nkan ti o n lọ laarin ijọ wa ni a to le mojuto ilera ijọ Ọlọrun lọna ti o peye. Fun apẹẹrẹ, nigba ti ijọ bẹrẹ si ni pọ si ni iye ni awọn ọjọ wọnni, awọn apa kan lara wọn bẹrẹ si ni woye pe awọn aṣoju wọn ninu pipin ounjẹ ko mojuto awọn opo wọn bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ki wa ni wọn ṣe lori eyi? Wọn sọ fun awọn apọsiteli nipa rẹ, a si ri pe wọn mojuto ọrọ naa ni kiakia, ijọ si duro ṣinṣin si. Ka wa sọ pe wọn dakẹ lori ọrọ yi nkọ? Ko ni pẹ rara ti ikoro, ibinu, ikorira ati owu jijẹ yoo fi gba gbogbo ijọ kan, ti yoo si ba a jẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 6:1-7)

Nitorina, fun ilẹra rẹ ninu ẹmi ati fun ilera ijọ Ọlọrun, jẹ ki bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ ati pẹlu awọn ibaṣepọ rẹ jẹ mimọ si awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ. Ma si ṣe rin pẹlu erokoro ‘Ọrọ aye mi ko ki ṣe ẹjọ ẹnikankan’ tabi pẹlu ironu pe ko si ẹni ti ọrọ rẹ le ye tabi ti o le ran ọ lọwọ ti o ba tilẹ jẹ ki wọn mọ bi o ti ṣe n lọ. Ẹjọ gbogbo wa ni ọrọ aye rẹ. Ẹjọ tirẹ si ni lati ri pe a mọ ati pe a tun ni oye bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣe ọ ye lati ni oye ati lati ma rin ninu imọlẹ ọrọ yi ni gbogbo igba, ki o ma ba bọ sinu pakute Eṣu nikẹyinkẹyin tabi ki o di irinṣẹ rẹ lati pọn ijọ Ọlọrun loju.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Akori: Bawo ni o ti ṣe n lọ pẹlu rẹ? | Lati ọwọ: J.O. Lawal Ọjọ: Erele 27, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 43 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Bawo ni o ti ṣe n lọ pẹlu rẹ? | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Erele 27, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa ọwọn. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ pẹlu rẹ ninu ọsẹ naa ati titi Jesu Oluwa wa yoo fi pade de. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti ẹni ti o kọ iwe Heberu tẹnumọ ninu gbogbo oju-ewe iwe naa ni pataki ki ijọ Ọlọrun kọọkan ma fi oju ṣọ awọn ọmọ ijọ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ki wọn ma ba ṣina ṣako lọ kuro ninu ifẹ Ọlọrun fun aye wọn ati ki wọn ma ba ba ilera ijọ jẹ tabi pa a lara. Nitorina, ti ọmọ ijọ rẹ kankan ba ṣiju si ọrọ aye rẹ, ti o si tun n bere awọn ibere ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ati igbagbọ rẹ lọwọ rẹ, ma fi ṣe ibinu tabi ki o bẹrẹ si ni bu wọn. Nṣe ni wọn n mu ofin Kirisiti ṣe lori aye rẹ (Galatia 6:2).

Wayi o, mi o wa sọ pe gbogbo awọn ti o wa ninu ijọ rẹ naa ni wọn loye to lati mọ awọn nkankan nipa aye rẹ tabi lati ṣe amulo ti o peye nkan ti o ba sọ fun wọn nipa ara rẹ. Mi o si tun so pe gbogbo ẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni naa ni o le fi ọrọ aye rẹ han. Ẹnikẹni, gẹgẹ bi ọrọ iwe mimọ, ti igbe aye igbagbọ rẹ ko ba han kedere si ọ lati ri, ki o ba le sọ daju pe ko ni ṣe ọ ni ijamba, fi idibajẹ saye rẹ tabi yan ọ jẹ, jẹ ẹni ti o yẹ ki o ṣọra fun. Ti o ba si wa woye pe ko si ẹnikẹni ninu ijọ rẹ ti o loye to lati mọ ohun ti o n lọ laye rẹ tabi lati ma fi oju ṣọ ẹ, nṣe ni ki o kuro nibẹ ki o si gba ijọ miran lọ ti iwọ yoo ti le turuka. Aijẹbẹ, ko ni pẹ ti o o fi pa igbagbọ tabi aye rẹ lara. (Wo: 2Kọrinnti 7:2)

Nitorina, fun anfaani ara rẹ, duro sinu ijọ ti o ba ti mọ pe o le turuka nibẹ fun awọn ara rẹ lati mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ ati lati ma fi oju ṣọ ọ. Lafikun, fun ilera ijọ Ọlọrun, o ṣe pataki ki o fi bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ han awọn ara rẹ, ki o si tun jẹ ki wọn darapa mọ ọrọ ayẹ rẹ lọna ti o peye, ki wọn ba le ma fi gbogbo igba ran ọ lọwọ lati gbajumọ ṣiṣe ifẹ Ọlọrun.

Ki lo fa ti a ṣe ni ọpọlọpọ Kirisitiẹni ti igbagbọ wọn ko mọkun ati ti ko gboriduro ni ọpọ ijọ wa loni? Ki si ni idi ti a ti fi ri ọpọ ijọ wa ninu eyi ti awọn ara ti n ṣe ẹtanu ara wọn tabi ti wọn n fi gbogbo igba ja lori nkankan tabi omiran? Idi kan pataki fun eyi ni pe ọpọ wa ko fẹ ki awọn ara wa mọ nkan ti o n lọ ninu aye wa tabi ki wọn tun aye wa to? Nkan ti a fẹ ni ki a ma gbe aye wa bi o ti ṣe wu wa, lalai si ilọwọsi tabi idasi ẹnikẹni. Eyi ko si dara rara fun wa tabi fun ilera ijọ Ọlọrun.

Fun apẹẹrẹ, ẹni ti o kọ iwe Herebu sọ eyi fun wa: “Ẹ ma kiyesara ki ẹnikẹni ki o ma ṣe kuna oore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbongbo ikoro kan ki o ma baa hu ṣoke ki o si yọ yin lẹnu, ọpọlọpọ a si ti ipa rẹ di aimọ; Ki ẹnikẹni ma baa di alagbere tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Isọ, ẹni ti o ti itori okele ounjẹ kan ta ogun ibi rẹ.” (Heberu 12:15-16) Bawo ni a ṣe le kiyesara lati ri pe ọkankan ninu wa ko kuna oore-ọfẹ Ọlọrun, ti a ko ba mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye gbogbo wa? Bawo ni a ṣe le ri pe ikoro tabi iyapa ko ṣẹlẹ laarin wa, ti a ko ba mọ nkan ti o n ṣẹlẹ laarin wa? Tabi bawo ni a ṣe le ma jẹ ki awọn ara wa bọ sinu panpẹ agbere tabi ẹṣẹ miran ti o le ba aye tabi igbeyawo wọn jẹ, ti a ko ba mọ ohun ti o n lọ ninu aye wọn? Ko le ṣeeṣe fun wa.

Wo o, igba ti a ba ni oye ti o peye nkan ti o lọ ninu aye wa ni a le ran ara wa lọwọ lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ ni ọna ti o peye. Bẹẹ si ni, igba ti a ba ni imọ ti o ye kooro awọn nkan ti o n lọ laarin ijọ wa ni a to le mojuto ilera ijọ Ọlọrun lọna ti o peye. Fun apẹẹrẹ, nigba ti ijọ bẹrẹ si ni pọ si ni iye ni awọn ọjọ wọnni, awọn apa kan lara wọn bẹrẹ si ni woye pe awọn aṣoju wọn ninu pipin ounjẹ ko mojuto awọn opo wọn bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ki wa ni wọn ṣe lori eyi? Wọn sọ fun awọn apọsiteli nipa rẹ, a si ri pe wọn mojuto ọrọ naa ni kiakia, ijọ si duro ṣinṣin si. Ka wa sọ pe wọn dakẹ lori ọrọ yi nkọ? Ko ni pẹ rara ti ikoro, ibinu, ikorira ati owu jijẹ yoo fi gba gbogbo ijọ kan, ti yoo si ba a jẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 6:1-7)

Nitorina, fun ilẹra rẹ ninu ẹmi ati fun ilera ijọ Ọlọrun, jẹ ki bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ ati pẹlu awọn ibaṣepọ rẹ jẹ mimọ si awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ. Ma si ṣe rin pẹlu erokoro ‘Ọrọ aye mi ko ki ṣe ẹjọ ẹnikankan’ tabi pẹlu ironu pe ko si ẹni ti ọrọ rẹ le ye tabi ti o le ran ọ lọwọ ti o ba tilẹ jẹ ki wọn mọ bi o ti ṣe n lọ. Ẹjọ gbogbo wa ni ọrọ aye rẹ. Ẹjọ tirẹ si ni lati ri pe a mọ ati pe a tun ni oye bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣe ọ ye lati ni oye ati lati ma rin ninu imọlẹ ọrọ yi ni gbogbo igba, ki o ma ba bọ sinu pakute Eṣu nikẹyinkẹyin tabi ki o di irinṣẹ rẹ lati pọn ijọ Ọlọrun loju.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Bawo ni o ti ṣe n lọ pẹlu rẹ? | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Kọkọ wo didangajia rẹ | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Erele 20, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 42

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o gbẹyin gbogbo ọṣẹ inu oṣu yi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba ṣe ọ yẹ pẹlu ohunkohun ti o nilo lati ṣe amulo ti o peye awọn Ibukun rẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Nipasẹ owe ti Jesu Kirisiti Oluwa wa sọ lori ọkunrin kan ti o fa lara awọn nkan ini rẹ le awọn iranṣẹ rẹ melokan lọwọ, a ri kọ wipe Ọlọrun wa jẹ Ọlọrun ti o ma n wo awọn amuyẹ awọn eniyan ki O to fa ohunkohun le wọn lọwọ. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun ko ni fi akoko kan fa nkankan le ọ lọwọ ti ko ba ṣe pe O ti fun ọ ni agbara lati le ṣe amojuto rẹ, ki o si tun ṣe aṣeyọri pẹlu rẹ. Lotitọ, a le ma ṣe amojuto nkan ti O fun wa bi o ti tọ tabi ṣe rere pẹlu rẹ, bi Oluwa tun fi ṣe ye wa ninu owe yi. Ṣugbọn eyi ko ni jẹ nitoripe a ko dangajia to lati ṣe amojuto rẹ tabi lati ṣe orire pẹlu rẹ; dipo bẹẹ, yoo jẹ nitori pe a ya ọlẹ, alaiṣododo tabi alainigbagbọ. (Wo: Matiu 25:14-30)

Niwọn igba ti ọrọ si wa ri bayi pẹlu Ọlọrun, awa ti a jẹ ọmọ rẹ naa yẹ ki a ṣe afarawe rẹ, ki a si ma ṣiṣẹ pẹlu ironu kan naa. Eyi tunmọ si pe awa naa gbọdọ kọ lati ma wo didangajia wa lati ṣe amojuto nkan tabi eniyan ati lati ṣe aṣeyọri pẹlu wọn, ki a to nawọ gan wọn. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe, nigbẹyingbẹyin, ki a ba nkan ti a lọ fun tabi ti wọn fun wa jẹ, ki a ba ara wa loju jẹ tabi ki a ba aye wa paapaa jẹ.

Ki ni iṣoro ọmọ oninakuna gan? Ki ni idi ti o fi di radarada laye? Ṣe nitori pe o kuro nile baba rẹ pẹlu ogun rẹ ni? Rara o! Lotitọ, ko ba ma ti kuro lọdọ baba ti o fẹran rẹ, ti o si tun n ṣe ikẹ rẹ gidigidi. Amọ iyẹn gan kọ ni iṣoro rẹ o. Iṣorẹ rẹ ni pe o dawọ le nkan ti ipa rẹ ko ka, nkan ti ko ni agbara lati ṣe amojuto rẹ ati lati ṣe aṣeyọri pẹlu rẹ. Nitorina, o jẹ iya ati ewe iya nitori eyi. Diẹ gan lo ku ki o sọ ẹmi rẹ nu lori ọrọ naa. Ti baba rẹ ko ba wa jẹ ẹnikan ti o nifẹ rẹ, ti o si ni ọkan idariji ni, nṣe ni arakunrin yi ko ba ku sinu iya, irora ati itiju siwaju akoko rẹ. (Wo: Luuku 15:11-32)

Nitorina, ki o tọ dawọ le ohunkohun laye yi, ki o tilẹ to bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun fun ohunkohun ninu aye yi, kọkọ wo bi o ṣe koju osuwọn to lati ṣe amojuto rẹ. Woo, Ọlọrun, gẹgẹ bi Baba ti O fẹran wa, ko ni fi igba kankan fun wa ni ohunkohun ti O ba mọ pe a ko dangajia to lati ṣe amojuto rẹ. Ko ni fun wa ni akeeke gẹgẹ bi ounjẹ, bi a tilẹ bere fun, tabi fun wa ni ejo dipo ẹja. Kiki nkan ti O mọ pe a le ṣe amojuto rẹ, ki a si tun ṣorire pẹlu rẹ, ni yoo fun wa, bi a ko tilẹ bere fun un. (Wo: Matiu 7:9-11)

Amọ ṣa o, ti a ba yọọ lẹnu pẹ titi lati fun wa ni nkan ti ko fẹ fun wa tabi ti a ba pinnu lati gba ọna ẹburu yowu ti a ri lati ri nkan ti a fẹ gba, O ṣeeṣe ki O gba wa laye latii ṣe ifẹ inu wa. Ṣugbọn, gẹgẹ bi ọmọ oninakuna, bopẹ-boya awa naa yoo ri pe irora, ibanujẹ, iyọnu ati iku ni o n duro de ẹnikẹni ti o ba nawọ gan nkan ti Ọlọrun ko fun tabi ti Ọlọrun ko fun ni amuyẹ tabi ipa lati ṣe amojuto rẹ. (Wo: Numeri 11)

Nitorina, lẹẹkansi, mo n sọ pe ki o to lọ fun iṣẹ yẹn, ki o to buwọ lu iwe igbọraẹniye okowo naa tabi ki o to nawọ gan ile yẹn, kọkọ wo didangajia rẹ lati ṣe amojuto rẹ. Bẹẹ si ni pẹlu, ki o to bẹrẹ ẹkọ ni ile-iwe yẹn, ki o to dawọ le akanṣe iṣẹ yẹn tabi ki o to bẹrẹ ere ifẹ yẹn, ri daju pe o dangajia to lati tayọ pẹlu rẹ. Lafikun, ki o to ya owo yẹn, awọn igba si ma n wa ti awọn eniyan le nilo lati ya owo ki wọn ba le ṣe awọn nkan kan laye wọn, kọkọ wo bi o ṣe dangajia to lati ṣe amulo ti o peye rẹ ati lati da a pada ni akoko ti o yẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o sọ aye ara rẹ ati tawọn miran ti o sunmọ ọ pẹlu di radarada nigbẹyin nitori eyi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun mi ti O kun fun ifẹ ma fi gbogbo igba jẹ ki o pọ si ni ipa ati agbara lati le ṣe orire ti o ga pẹlu ohunkohun ti O ba ko le ọ lọwọ laye yi, ki aye rẹ ba le ma fi ojoojumọ fa ohun rere sọdọ lọpọlọpọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kọkọ wo didangajia rẹ | Paitọ J.O. Lawal Read More »

APỌSITELI | Paito J.O. Lawal | ỌJỌRU 16, ERELE 2022

Gba Eda Tie

AYỌKA: 2KỌRINNTI 12:11-12

AKỌSORI: “O si fi awọn kan fun ni bii apọsiteli…” (Efesu 4:11)

ỌRỌ AKỌSỌ
Lara awọn ti Ọlọrun n yan fun ijọ rẹ lati ṣiṣẹ fun idagbasoke ati pipọsi ni iwulo awọn ọmọ rẹ ninu Kirisiti Jesu ni awọn ti a n pe ni apọsiteli jẹ. Bawo wa ni a ṣe le da wọn mọ? Awọn apẹẹrẹ apọsiteli wo ni a ri ninu bibeli? Njẹ a tilẹ tun ni apọsiteli ninu ijọ loni bi? Iha wo ni o yẹ ki a kọ si wọn? Bawo ni ti awọn eke apọsiteli ṣe jẹ? Ọna wo ni a le gba da wọn mọ? Awọn nkan wọnyi ati awọn miran ti o fara pẹ wọn ni a fẹ ṣe agbeyẹwo ninu ẹkọ yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun fi imọ ifẹ rẹ ati oye rẹ ti o peye fun wa nipasẹ ẹkọ naa, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Amin.

TANI APỌSITELI?
Ni ibamu pẹlu ede Giriki ti a fi kọ pupujọlọ ninu awọn iwe bibeli ti abala majẹmu tuntun, apọsiteli jẹ aṣoju ti a ran lati ṣoju ẹni ti o ran ni ibi yowu ti o ran an lọ. Eyi jasi pe o jẹ ẹni ti ẹni ti o pe ti o si ran niṣẹ ṣe yẹ, ti o si fun ni ohun gbogbo ti yoo nilo lati ṣoju rẹ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ ni ibi ti o ran an lọ. Fun apẹẹrẹ, Mose ni ẹni akọkọ ti a le pe ni apọsiteli tabi aṣoju fun Ọlọrun ti o kọkọ jẹyọ ninu bibeli. Iwe Heberu, ori ikẹta, lati ẹsẹ ikinni sọ eyi nipa rẹ: “Nitori naa, ẹyin ara mimọ, alabaapin ipe ọrun, ẹ gba ijẹwọ wa nipa Jesu ro, ẹni ti i ṣe Apọsiteli ati Olori Alufaa wa. Ẹni ti o ṣe oloootọ si ẹni ti o yan an, gẹgẹ bi Mose pẹlu ti ṣe oloootọ ninu iṣẹ rẹ gbogbo ninu ile Ọlọrun.” (Heberu 3:1-2)

Pẹlu nkan ti ẹni ti o kọ iwe yi sọ ninu awọn ẹsẹ yi, a ri wipe Jesu Oluwa wa funrarẹ jẹ Apọsiteli Ọlọrun. Eyi tunmọ si pe aṣoju Ọlọrun ni o jẹ ati pe gbogbo nkan ti O ṣe nigba ti O wa ninu aye yi jẹ awọn nkan ti Ọlọrun funrarẹ n ṣe. Ranti wipe O sọ eyi fun awọn adari ẹsin Juu lakoko kan: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, ọmọ ko le ṣe ohunkohun fun ara rẹ, bi ko ṣe ohun ti o ba ri pe Baba n ṣe: nitori ohunkohun ti o ba n ṣe, wọnyi ni ọmọ n ṣe bẹẹ gẹẹ. Nitori baba fẹran ọmọ, o si fi ohun ti oun tikararẹ n ṣe han an: oun o si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ han an, ki ẹnu ki o le ya yin. Nitori pe gẹgẹ bi Baba ti n ji oku dide, ti o si n sọ wọn di aaye; bẹẹ ni ọmọ si n sọ awọn ti o fẹ di aaye. Nitori pe Baba kii ṣe idajọ ẹnikẹni. Ṣugbọn o ti fi idajọ le ọmọ lọwọ. Ki gbogbo eniyan ki o le ma fi ọla fun ọmọ gẹgẹ bi wọn ti n fi ọla fun Baba. Ẹni ti ko ba fi ọla fun ọmọ, ko fi ọla fun Baba ti o ran an.” (Johanu 5:19-23)

Nitorina, Apọsiteli ni Jesu Oluwa wa funnrarẹ jẹ si Ọlọrun Baba rẹ ti O ran. Bẹẹni, aṣoju ti a ṣe yẹ lẹkunrẹrẹ ni O jẹ si i. Ko kan dede wa funrarẹ tabi ki O ma ṣe awọn iṣẹ ti O n ṣe ni ibamu pẹlu ifẹ ti ara rẹ. O wa nitoripe Ọlọrun ran an ni. O ṣi ṣe awọn iṣẹ ti O ṣe nitoripe Ọlọrun wa pẹlu rẹ, ti O si tun ṣe e yẹ lati ṣe wọn. Idi si niyi ti idajọ yoo fi wa lori ẹnikẹni ti ko ba gbaagbọ, ki o si bu iyi ti o tọ si Ọlọrun fun un. (Wo: Johanu 8:29; Johanu 20:21; Iṣe Apọsiteli 10:38; Kolose 1:19)

Amọ bi mo ti ṣe sọ siwaju, Jesu kọ ni ẹni akọkọ ti yo jẹ apọsiteli fun Ọlọrun. A ti kọkọ ni Mose gẹgẹ bi apọsiteli rẹ naa. Idi ni yi ti a fi lo iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi afiwe fun iṣẹ iranṣẹ Jesu. Bi a ti ri ninu bibeli, Ọlọrun funrarẹ lo fi ara rẹ han Mose, ti O ṣe yẹ, ti O si tun ran lati mu awọn eniyan rẹ, awọn ọmọ Isiraẹli, jade pẹlu ọwọ agbara kuro ni Ijibiti ati lati mu wọn wọ ilẹ Kenani ti O ti ṣe ileri fun awọn baba nla wọn (Ẹkisodu 3-4). Nitorina, aṣoju Ọlọrun lọ si Ijibiti ni ọkunrin yi jẹ. Gbogbo ọrọ ti o si sọ ati awọn iṣẹ ti o ṣe jẹ awọn nkan ti Ọlọrun funrarẹ fẹ sọ ati ṣe lati tu awọn eniyan rẹ silẹ. Idi niyi ti Ọlọrun ṣe sọ fun pe, “Wo o, emi fi ọ ṣe bi Ọlọrun fun Farao: Aarọni arakunrin rẹ ni yoo si maa ṣe wolii rẹ.” (Ẹkisodu 7:1) A si ri wipe Ọlọrun duro ti ọkunrin yi lati mu gbogbo ọrọ ti o sọ wa si imuṣẹ ati lati jẹ ki o le ṣe oniruuru iṣe ami ati iyanu ti o yọri si itusilẹ awọn eniyan rẹ ati ipese wọn fun ilẹ-ileri ti O n mu wọn lọ.

Nitori eyi, ti a ba n sọrọ nipa apọsiteli Ọlọrun, a n sọrọ nipa ẹni naa ti Ọlọrun fi ara rẹ ati agbara rẹ han, ti O si ṣe yẹ lati le ran jade lọ gẹgẹ bi aṣoju rẹ si ibi yowu tabi awọn yowu ti O ni lọkan. Ọlọrun a si wa pẹlu irufẹ ẹni bẹ lati ri pe o ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ yowu ti O ba gbe le e lọwọ, niwọn igba ti igbagbọ rẹ ninu rẹ ati igbọran rẹ ko ba ti yẹ.

APỌSITELI JESU
Nibakan naa, ti a ba pe ẹnikẹni ni apọsiteli Jesu Kirisiti, a jẹ wipe ẹni naa jẹ ẹnikan ti Jesu funrarẹ pe, ti o si tun ṣe yẹ lati jẹ asọju rẹ nibi yowu tabi si awọn yowu ti O ba pinnu lọkan rẹ lati ran an si.

Fun apẹẹrẹ, bibeli sọ eyi nipa awọn apọsiteli mejila akọkọ ti Jesu pe, awọn ti a mọ si apọsiteli ọdọ aguntan: “O si gun ori oke lọ, o si n pe ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ: wọn si tọ ọ wa. O si yan awọn mejila, ki wọn ki o le maa gbe ọdọ rẹ, ati ki o le maa ran wọn lọ lati waasu, ati lati ni agbara lati wo arunkarun san, ati lati le awọn ẹmi Eṣu jade.” (Maaku 3:13-14) Ki ni a ri dimu ninu nkan ti a sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yi? Akọkọ ni pe bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọlẹyin ni Jesu ni nigba ti O wa ninu aye yi, ko ki i ṣe gbogbo wọn naa ni o jẹ apọsiteli fun. Awọn mejila pere ni O yan laran wọn lati jẹ apọsiteli rẹ. Nkan ekeji ti a ri dimu ni pe Jesu ṣe awọn ti O yan gẹgẹ bi apọsiteli rẹ yẹ ki O to bẹrẹ si ni lo wọn gẹgẹ bi aṣoju rẹ. O kọkọ mu wọn sọdọ rẹ, ki wọn ba le ma gbe pẹlu rẹ lati kẹkọ ati lati gba agbara ati aṣẹ ti wọn nilo lati ṣe iṣẹ ti O fẹ ki wọn ṣe.

Iṣẹ wo si ni Jesu fẹ ki awọn ti O yan wọnyi gẹgẹ bi aṣoju tabi apọsiteli rẹ ṣe? Awọn iṣẹ ti Oun funrarẹ n ṣe ni. Awọn iṣẹ wo si ni O n ṣe? Akọkọ, O n wasu ijọba Ọlọrun fun awọn eniyan, ki wọn ba le wọ inu rẹ, ki wọn si ma gbe igbe aye ọtun, igbe aye ti Ọlọrun tẹwọgba. Ekeji, O n wo oniruuru aisan ati arun san. Ẹkẹta, O n le awọn ẹmi eṣu jade kuro ninu aye ati agọ ara awọn eniyan ti wọn n pọn loju. Isọri mẹta yi ni a le pin iṣẹ Jesu si ni aarin awọn Juu si. Eyi wa jasi pe idi pataki ti O fi yan awọn mejila ti O yan gẹgẹ bi apọsiteli ni ki iṣẹ rẹ ba a le gbooro si. Gẹgẹ bi eniyan, ko si bi O ṣe fẹ wa ni ibi meji ọtọọtọ ni igba kannaa lati le ṣe irufẹ iṣẹ kannaa. Ṣugbọn ti O ba ni awọn aṣoju tabi iriju ti O ti ṣe yẹ, awọn wọnyi yoo le lọ ṣoju rẹ ni awọn ibi yowu ti O ba fẹ. Wọn o si tun le ṣe ifẹ inu rẹ ni ibi yowu ti O ba ran wọ lọ.

Ṣe o wa ri bẹ fun awọn apọsiteli mejila yi tabi ko ribẹ? O ribẹ fun wọn nitoripe Jesu ṣe wọn yẹ lati le wasu ihinrere, lati le wo arunkarun san ati lati le le awọn ẹmi Eṣu jade. Wo diẹ lara nkan ti a kọ silẹ nipa iṣẹ iriju wọn nigbati ti a ran wọn jade lọ: “Wọn si jade lọ, wọn si waasu ki awọn eniyan le ronupiwada. Wọn si le ọpọ awọn ẹmi Eṣu jade, wọn si fi ororo kun ọpọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, wọn si mu wọn larada. Hẹrọdu ọba si gburoo rẹ; (nitori ti okiki orukọ rẹ kan yika) o si wi pe, Johanu Batisi jinde kuro ninu oku, nitori naa ni iṣẹ agbara ṣe n ṣe lati ọwọ rẹ wa.” (Maaku 6:12-14)

Njẹ o ri bayi pe gbogbo awọn apọsiteli yi ni o ṣe awọn iṣẹ ti Jesu ti O ran wọn n ṣe nigba ti O ran wọn jade lọ? Ṣe o si tun ri pe nigba ti wọn bẹrẹ si ni ṣe awọn iṣẹ yi okiki Jesu tan jake-jado ilẹ naa, to bẹẹ gẹẹ ti ọba Hẹrọdu gan fi kiyesi pe nkankan n ṣẹlẹ ni ilẹ rẹ? Ni kukuru, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ni i ṣe pẹlu mimu iṣẹ Jesu gbooro si. Ti a ba si ṣe iṣẹ yi bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ, o di dandan ki okiki rẹ tan kaakiri. Nitorinaa, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni apọsiteli loni, ti ko si mu ki iṣẹ Jesu gbooro si ati ki okiki rẹ tan kalẹ si ko ki i ṣe apọsiteli otitọ. Eyi ko jasi pe ko ki i ṣe Kirisitiẹni nitootọ o. O le jẹ Kirisitiẹni nitootọ. Amọ a ko ṣe yẹ gẹgẹ bi apọsiteli Jesu. Yoo si dara ki o jawọ ninu pipolongo ara rẹ gẹgẹ bi apọsiteli.

Ṣe awọn wọnyi nikan wa ni apọsiteli Jesu ni bi? Rara O. A tun darukọ awọn miran ninu bibeli gẹgẹ bi apọsiteli rẹ. Fun apẹẹrẹ, a darukọ Mataya, Pọọlu, Banaba, Apolo, Adronikusi ati Juniasi gẹgẹ bi apọsiteli rẹ (Iṣe Apọsiteli 1:20; Roomu 16:7; 1Kọrinnti 3:1-9; 1Kọrinnti 9:1-6).

AMUYẸ APỌSITELI
Bawo ni eniyan ṣe le mọ pe apọsiteli ni oun? Ki si ni awọn amuyẹ ti yoo ri ninu aye rẹ? Pataki julọ ninu awọn nkan ti o ma n jẹ ki eniyan mọ pe oun jẹ apọsiteli Jesu ni iwọnyi:

Ifarahan Ọlọrun
Akọkọ lara awọn nkan ti o le jẹ ki eniyan mọ pe apọsiteli Ọlọrun ni oun ni ifarahan Ọlọrun si. Njẹ eyi wa tunmọ si pe gbogbo awọn ti Ọlọrun ba fi ara rẹ han lọna kan tabi omiran naa ni apọsiteli rẹ? Rara o. Wolii, oluṣọ-aguntan, ajinhinrere tabi ẹnikẹni ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun naa le ri ifarahan Ọlọrun fun oniruuru idi. Ṣugbọn ifarahan ti a n sọrọ nipa nibi ni i ṣe pẹlu iṣẹ ti Ọlọrun fẹ gbe le eniyan lọwọ ati awọn nkan ti yoo soro mọ. Eyi tunmọ si pe ki ẹnikẹni to le pe ara rẹ ni apọsiteli, o gbọdọ jẹ pe Jesu ti fi ara han lati sọ fun pe Oun fẹ lo gẹgẹ bi aṣoju Oun.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ki Mose to di apọsiteli Ọlọrun si awọn ọmọ Isiraẹli, Ọlọrun ti kọkọ fi ara rẹ han lati pe ati lati sọ iru iṣẹ ti Oun fẹ gbe le lọwọ fun un. Lẹyin igba ti O tun mu awọn ọmọ Isiraẹli yi jade lati Ijibiti tan, Ọlọrun tun pe si ori oke Sinai, nibi ti O tun ti fi ara rẹ han, ti O si fi ọpọlọpọ nkan han nipa ifẹ rẹ fun awọn eniyan rẹ. O tilẹ sọ kedere lọjọ kan fun awọn ẹgbọn rẹ, iyẹn Aarọni ati Miriamu, pe Mose kọja wolii lasan – apọsiteli Oun ni o jẹ. Wo nkan ti O sọ lọjọ naa: “Ẹ gbọ ọrọ mi nisinsinyi: bi wolii Oluwa ba n bẹ ninu yin, emi Oluwa yoo farahan fun un ni ojuran, emi o si ba a sọrọ ni oju ala. Mose iransẹ mi ko ri bẹẹ, oloootọ ni ninu gbogbo ile mi. Oun ni Emi n ba sọrọ ni ẹnu ko ẹnu ati ni gbangba, kii si i ṣe ni ọrọ ti o ṣe okunkun; apẹẹrẹ Oluwa ni oun o si ri: njẹ nitori kin ni ẹyin ko ṣe bẹru lati sọrọ odi si Mose iranṣẹ mi? (Numeri 12:6-8) Nitorina, ifaharan Ọlọrun ti Mose ni ṣe iyatọ rẹ si awọn wolii Ọlọrun miran. Nipasẹ awọn ifarahan yi si ni o ṣe le ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe le e lọwọ, eyi ti o kọja ki a kan sọ tẹlẹ lasan.

Lafikun, bi mo ti ṣe fi han tẹlẹ, Jesu Oluwa wa naa sọ eyi nipa ara rẹ ati ibasepọ rẹ pẹlu Ọlọrun: “Nitori baba fẹran ọmọ, o si fi ohun ti oun tikararẹ n ṣe han an: oun o si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ han an, ki ẹnu ki o le ya yin.” (Johanu 5:20) Eyi n fi han wa pe ifarahan Ọlọrun ti Jesu ni ni O ṣe le ṣe irufẹ iṣẹ ti O ṣe, ti O si fi lọlẹ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lati tan kalẹ de gbogbo agbaye.

Njẹ awọn apọsiteli rẹ naa ni irufẹ ifarahan yi bi? Bẹẹni! Niwọn igba ti wọn ti wa pẹlu Jesu ọmọ Ọlọrun, ti O si ti pe wọn, ti O si tun yan wọn lati fi Ọlọrun, ara rẹ ati ifẹ rẹ han wọn, awọn naa wa ni ipo lati ṣe oju rẹ nibikibi ti O ba ran wọn lọ gẹgẹ bi apọsiteli rẹ. Wo nkan ti O sọ lori eyi nigba ti Filipi, ọkan ninu awọn apọsiteli rẹ sọ wipe ki O fi Ọlọrun Baba rẹ han awọn: “Bi akoko ti mo ba yin gbe ti pẹ to yii, iwọ ko si tii mọ mi sibẹ, Filipi? Ẹni ti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wi pe, Fi Baba han wa? Iwọ ko ha gba pe, Emi wa ninu Baba, ati pe Baba wa ninu mi? ọrọ ti emi n sọ fun yin, emi ko da a sọ; Ṣugbọn Baba ti n gbe inu mi, oun ni n ṣe iṣẹ rẹ.” (Johanu 14:9-10)

Lẹyin eyi, O tun sọ eyi fun wọn: “Emi ko pe yin ni ọmọ-ọdọ mi; nitori ọmọ-ọdọ ko mọ ohun ti Oluwa rẹ n ṣe: Ṣugbọn emi pe yin ni ọrẹ; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ lati ọdọ Baba mi wa; mo ti fi han fun yin.” (Johanu 15:15) Eyi n jẹ ki o yẹ wa pe gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu ifarahan Ọlọrun ti Jesu ni nipa iṣẹ ti O fẹ ki O ṣe ni aye yi ti awọn apọsiteli rẹ yi ni lati mọ lati le ṣe oju rẹ ni ọna ti o peye ni O fi han wọn. Aijẹbẹ ni, wọn ko ba ti le tẹsiwaju pẹlu iṣẹ yi, ki wọn si fi idi ijọ rẹ mulẹ laye yi, bi wọn ti ṣe ṣe. A si ri pe nigba ti wọn fẹ yan ẹni ti yoo rọpo Judasi gẹgẹ bi apọsiteli, ọkan lara nkan ti Peteru la kalẹ gẹgẹ bi amuyẹ ti wọn yoo lo ni pe ẹni naa ti gbọdọ ba wọn rin, ki o si jẹ ẹlẹri ohun gbogbo ti wọn ti ri ati ti wọn ti gbọ lati igba ti Jesu ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ titi a fi gba a soke sọdọ Ọlọrun. (Wo: Iṣe Apọsiteli 1:21-26)

Bawo wa ni ti awọn miran ti a tun ka si apọsiteli ninu bibeli? Njẹ awọn naa ni irufẹ ifarahan Ọlọrun yi bi? Bẹẹni! bi o tilẹ jẹ pe a ko ni akọsilẹ ifarahan ti gbogbo wọn ni, a ni diẹ lara ti Pọọlu ninu iwe mimọ. Fun apẹẹrẹ, Luuku kọ eyi silẹ nipa apọsiteli yi ati nkan ti o sọ nipa ara rẹ fun awọn adari ẹsin Juu ni akoko kan:

“Ẹnikan si tọ mi wa, Ananaya, ọkunrin olufọkansi gẹgẹ bi ofin, ti o ni orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Juu ti o n gbe ibẹ. O si duro ti mi, o si wi fun mi pe, Sọọlu arakunrin, riran. Ni akoko kan naa, mo si siju soke wo o. O si wi fun mi pe, Ọlọrun baba wa ti yan ọ lati mọ ifẹ rẹ ati lati ri Oloootọ nni ati lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ. Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹrii rẹ fun gbogbo eniyan, nipa oun ti iwọ ti ri, ti iwọ si ti gbọ.” (Iṣe Apọsiteli 22:12-15)

Njẹ o ri bayi? Ọlọrun mọ-ọn-mọ ya Pọọlu sọtọ ni lati ri Jesu ati lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ. Ki si ni idi? Ki o ba le jẹ asoju rẹ ti o peye fun gbogbo eniyan nibikibi ti O ba ran an lọ. Njẹ o wa ri Jesu tabi ko ri bi? O ri Jesu gẹgẹ bi a ti ṣe sọ fun. O si tun gbọ ọrọ lẹnu rẹ pẹlu. Yatọ si eyi, oniruuru nkan ni Jesu fi han an nipa iṣẹ irapada ti O ṣe, ijọba rẹ, ijọ rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, eyi ti o jẹ ki o ṣeeṣe fun lati waasu ihinrere pẹlu oye ti o pe ati lati fi idi ijọ Ọlọrun mulẹ ṣinṣin nibikibi ti o lọ. A si wa ri ninu akọsilẹ Pọọlu pe, bi o tilẹ jẹ pe ko wa pẹlu awọn apọsiteli yoku nigba ti wọn n ṣe wọle-wọde pẹlu Jesu, oye ẹni ti Jesu jẹ ati ohun ti o ni ṣe pẹlu ijọba rẹ ti o ni ko kere rara si ti wọn. (Wo: Iṣe Apọsiteli 22:37-21 & 26:12-18; 1Kọrinnti 9:1, 11:23-26 & 15:1-10; 2Kọrinnti 12:1-5; Galatia 1:11-17&2:1-10)

Koko nkan ti a n sọ naa ni pe ẹnikẹni ti o ba jẹ apọsiteli nitootọ, yoo le sọrọ nipa ifarahan Ọlọrun si ati nipa irufẹ iṣẹ ti o gbe fun. Ẹnikẹni ti ko ba si ni ifarahan yi, ifarahan ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ ijọba Ọlọrun ati ọna ti Ọlọrun fẹ ki o gba ṣoju rẹ ni ṣiṣe iṣẹ yi, ko ki i ṣe apọsiteli Oluwa tootọ.

Pipolongo gbogbo ifẹ Ọlọrun
Yatọ si pe ki a ni ifarahan Ọlọrun, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ki a to le sọ pe apọsiteli Jesu ni wa nitootọ, ifarahan wa gbọdọ da lori mimu ki iṣẹ ijọba Ọlọrun gbooro si nipasẹ iwaasu ati fifi idi igbagbọ awọn ọmọ Ọlọrun mulẹ, ki wọn ba le dagba soke ninu ẹmi, ki wọn si tun pọ si ni iwulo. Eyi jasi pe a gbọdọ mọ ifẹ Ọlọrun ni ọna ti o ye kooro, ki a si tun le fi ye awọn ọmọ rẹ nipasẹ ọrọ rẹ ni bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ. Apọsiteli Ọlọrun ko ni anfaani lati ṣe ẹyọ awọn abala ifẹ Ọlọrun ti yoo ma kọ awọn eniyan. Rara o. Ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ Ọlọrun ni o gbọdọ fi ye wọn, ti yoo si ma lepa la ti fi ye wọn, ki o ba le fi wọn han si Jesu Oluwa gẹgẹ bi pipe ni igbẹyin ohun gbogbo. (Wo: Iṣe Apọsiteli 0:17-27; Efesu 4:11-16; Kolose 1:24-29)

Nitorina, ti a ba sọ pe apọsiteli ni enikan, o kọja ẹni ti o n riran si awọn eniyan tabi ẹni ti Ọlọrun lo lati da ọpọ ijọ rẹ silẹ; o gbọdọ jẹ ẹni ti o ni oye ifẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ rẹ ti o ye kooro, ti o si n fi gbogbo igba lepa lati ri pe wọn mọ ifẹ rẹ ati wipe wọn duro ṣinṣin ninu ifẹ naa.

Agbara lati ṣe iṣẹ iyanu ati aṣẹ lori awọn ẹmi eṣu
Bi tun ṣe ri ninu bibeli, ara awọn nkan ti o tun ma n jẹyọ lara ẹnikẹni ti o ba jẹ apọsiteli Ọlọrun nitootọ ni ifarahan agbara Ọlọrun lati ṣe iṣe iyanu ati iwosan ati aṣẹ lati le awọn ẹmi eṣu jade. Lotitọ, gbogbo ọmọ Ọlọrun ni agbara rẹ n gbe inu wọn, ti o si ni ore-ọfẹ lati ṣe amulo agbara rẹ. Bẹẹ si ni, gbogbo ọmọ Ọlọrun ni o ni aṣẹ lori awọn ẹmi eṣu bi a ti ṣe ri ninu bibeli. Amọ ifarahan agbara rẹ ninu wọn lati ṣe iṣẹ iyanu, wo alaisan san tabi le ẹmi ẹṣu jade ko ki i ṣaba farahan ninu aye wọn bi o ti ṣe ma n farahan ninu aye awọn ti o ba jẹ apọsiteli.

Fun apẹẹrẹ, a ri pe Mose, gẹgẹ bi apọsiteli Ọlọrun, ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu lati fi idi ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ iranṣẹ rẹ mulẹ laarin awọn ti a ran si. Awọn iṣẹ ti o si ṣe dojuti gbogbo awọn oriṣa Ijibiti ati iṣẹ afọsẹ wọn. A si tun ri pe Jesu Oluwa wa naa ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu lati fi idi ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ iranṣẹ rẹ mulẹ laarin awọn Juu ti a ran si nigba ti O wa ni aye yi. Bẹẹ si ni O tun ṣe le ẹmi eṣu jade kuro ninu ọpọlọpọ eniyan ati agbegbe, ki ifẹ Ọlọrun ba le wa si imuṣẹ ninu aye wọn ati ni aagọ ara wọn.

Bi a tun ṣe wa sọ tẹlẹ ninu ẹkọ yi, ara idi ti Jesu fi yan awọn mejila laarin awọn ọmọ ẹyin rẹ ni ki o ba le fun wọn ni agbara lati wo arunkarun san ati lati le awọn ẹmi eṣu jade (Maaku 3:13-15). Nitorina, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ko ki lọ lalai fi idi ọrọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ mulẹ nibikibi ti a ba ti n ṣe nipasẹ oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ati lile awọn ẹmi eṣu jade. Idi si ni yi ti Pọọlu ṣe sọ nipa ara rẹ pe, “Nitootọ, emi ti ṣe iṣẹ ami, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara ti o yẹ laarin yin gẹgẹ bi Apọsiteli ninu suuru gbogbo.” (2Kọrinnti 12:12) Ti a ba si tun wo awọn akọsilẹ ti a ri nipa iṣe awọn apọsiteli igbaani, a o ri pe gbogbo wọn patapata ni Ọlọrun tipasẹ wọn ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iyanu, ti O si tun tipasẹ wọn le awọn ẹmi eṣu jade kuro ninu aye ọpọ eniyan. Awọn igba kan tilẹ tun wa ti O lo wọn fun idajọ awọn ti ko rin deede ninu ijọ ati awọn ti o n gbiyanju lati di itankalẹ ọrọ Ọlọrun lọwọ. (Wo: Iṣẹ Apọsiteli 5:1-16, 14:1-3 & 19:11-12)

Eyi n jẹ ki o ye wa pe ti a ba sọ pe apọsiteli ni eniyan, Ọlọrun ti o n ṣoju yoo fun ni agbara lati ma ṣe awọn iṣẹ ti yoo jẹ ki awọn eniyan kọbiara si iṣẹ iranṣẹ rẹ. Ẹnikẹni ti o ba wa pe ara rẹ ni apọsiteli, ti oniruuru iṣẹ ami ati iyanu ati lile awọn ẹmi aimọ jade ko ma farahan lọpọlọpọ ninu iṣẹ-iranṣẹ rẹ ko ki i ṣe apọsiteli. Eyi ko wa tunmọ si pe gbogbo awọn ti o ba n ṣe iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu naa ni apọsiteli. Filipi ajinhinrere ṣe oniruuru iṣẹ iyanu ati ami. O si tun le awọn emi eṣu jade naa lọpọlọpọ. Bẹẹ si ni ko ki i ṣe apọsiteli. Idi si nipe ko ni awọn amuyẹ miran ti a ti mẹnuba ti awọn apọsiteli ma n ni. (Iṣe Apọsiteli 8:5-7)

IWULO IṢẸ IRANṢẸ APỌSITELI
Bi a ti ṣe sọ siwaju, aṣoju ni awọn apọsiteli jẹ fun Ọlọrun ati Jesu ọmọ rẹ. O si ma n ṣe wọn yẹ lati waasu ọrọ rẹ fun ifidimulẹ ijọba rẹ, lati ṣe iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ati le awọn ẹmi eṣu jade. Ṣugbọn awọn ibo gan ni iṣẹ iranṣẹ wọn ti wulo? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ma n wulo pupọ julọ ni awọn agbegbe tabi orilẹ-ede tabi laarin awọn ẹya eniyan ti imọlẹ otitọ Ọlọrun ati Jesu ọmọ rẹ ko i ti fi de rara tabi fi taratara de ati ni awọn ibi ti akitityan Eṣu ti jẹ ki awọn eniyan gbagbe Ọlọrun ati agbara rẹ lati gba wọn la ati lati fun wọn ni isinmi. (Wo: Roomu 15:17-22)

Fun apẹẹrẹ, a ri wipe awọn ọmọ Iṣiraẹli ti fẹrẹ gbagbe Ọlọrun ati agbara rẹ patapata ki O to ran Mose si wọn. Iya ti jẹ wọn to bẹẹ gẹẹ ti wọn kan fi n fi gbogbo igba kerora lasan ni; wọn ko reti igbala lati ọdọ ẹnikankan. Eyi si wa lara idi ti Ọlọrun fi ṣe Mose yẹ lati le ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ti yoo jẹ ki wọn gbaagbọ ati lati tun le kọ wọn, ki o si tun fi idi wọn mulẹ ninu ifẹ rẹ. (Wo: Ẹkisodu 2-4)

Bi a tun ṣe ri ninu bibeli, ki Pọọlu ati awọn awọn alabaṣiṣẹ rẹ ninu Oluwa to lọ si agbegbe Masidonia lati bẹrẹ si ni waasu ni awọn ilu wọn, o kọkọ ri iran kan ninu eyi ti ara Masidonia kan ti n bẹẹ pe ki o rekọja wa si Masidonia lati wa ran awọn lọwọ. Eyi tunmọ si pe okunkun gbilẹ gan ni agbegbe yi to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi nilo iṣẹ iranṣẹ apọsiteli fun itusilẹ wọn ati fun ifilọlẹ wọn ninu ifẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kirisiti ni kankan. (Wo: Iṣe Apọsiteli 16:6-10)

Lafikun, a ri wipe pataki iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi apọsiteli si awọn Juu nigba ti O wa ninu aye yi ni lati tan imọlẹ si okunkun wọn, ki O si fun wọn ni ireti irapada ayeraye Ọlọrun. Lotitọ, wọn ni awọn adari ẹsin ati olukọ ọrọ Ọlọrun loriṣiriṣi ni akoko yi. Amọ, iṣẹ iranṣẹ awọn wọnyi ko pa iṣẹ Eṣu run lọna ti o peye laarin wọn tabi fi idi ifẹ Ọlọrun mulẹ bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Jesu funrarẹ rẹ gan pe akiyesi awọn ọmọ ẹyin rẹ si eleyi ni akoko kan, nigba ti O ri pe awọn eniyan naa dabi aguntan ti ko ni olusọ, ti ọpọ ninu wọn si n wọ ọ tẹle kaakiri gbogbo ibi ti O ba lọ. Nitorina, wọn nilo apọsiteli ti yoo ran wọn leti otitọ Ọlọrun ati agbara rẹ nipa kikọ wọn ati ṣiṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu laarin wọn. Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu si ṣe laarin wọn ki O to di pe O fi ẹmi rẹ silẹ fun irapada gbogbo araye. (Wo: Matiu 4:12-17 & 9:35-38; Luuku 4:16-21; Iṣe Apọsiteli 1:1-2)

Nitorina, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli wulo pupọ fun titan imọlẹ Ọlọrun sinu okukun awọn eniyan ati fun didari wọn sinu igbagbọ ninu agbara rẹ dipo agbara eṣu. Ko wa si nkan ti o buru nibẹ ti a ba bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun lati gbe awọn apọsiteli dide fun gbogbo awọn agbegbe, orile-ede ati aṣa agbaye ti imọlẹ rẹ ati ti agbara rẹ ko i ti tan si tabi ti awọn ọmọ rẹ ti o wa nibẹ ti gbagbe rẹ patapata, ti wọn si ti gba ki okunkun gbilẹ laarin wọn ati lori wọn.

AALA APỌSITELI
Njẹ iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ma n ni aala bi? Bẹẹni, iṣẹ iransẹ apọsiteli ma n ni aala. Eyi tunmọ si pe, yatọ si Jesu Oluwa ti Ọlọrun ran gẹgẹ bi apọsiteli si gbogbo eniyan, ko si ẹnikẹni ti o le jẹ asoju Ọlọrun si gbogbo awọn ti o wa ni aye. Idi si ni pe iṣẹ ijọba Ọlọrun kọja nkan ti ẹyọ ẹnikan le ṣe. Jesu gan, nigba ti o wa ni aye yi, ko ṣiṣẹ gẹgẹ bi apọsiteli si gbogbo eniyan. Ọpọ igba ni O fi ye awọn eniyan pe awọn Juu nikan ni a ran si ni akoko yi. Nitorina, nigba ti O n kọkọ ran awọn apọsiteli rẹ jade, a ri wipe awọn Juu nikan naa ni O ran wọn si. Ẹyin igba ti O ku, ti O si tun jinde ni O to ran wọn lọ si gbogbo aye lati waasu ihinrere fun gbogbo ẹda. (Wo: Matiu 10:1-5 & 28:16-20; Maaku 16:15; Iṣe Apọsiteli 22:17-21; 1Kọrinnti 9:1; Galatia 2:8)

Pe Jesu wa sọ fun awọn apọsiteli rẹ pe ki wọn lọ si gbogbo aye, ki wọn si ma a waasu ihinrere fun gbogbo ẹda ko wa tunmọ si pe gbogbo awọn gbọdọ lọ si ibi kanna tabi ẹnikọọkan wọn gbọdọ lọ kaakiri agbaye ki wọn to mu iṣẹ iranṣẹ wọn yẹ. Dipo eyi, nṣe ni O ma yan ibi ti ẹnikọọkan wọn yoo lọ fun wọn, ti yoo si tun fi aala iṣẹ iranṣẹ rẹ han. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu pe ara rẹ ninu iwe rẹ si awọn ara Galatia ni apọsiteli si awọn Heleni ati Peteru ni apọsiteli si awọn Juu. Njẹ eyi wa tunmọ si pe iṣẹ iranṣẹ rẹ ko bukunfun awọn Juu kankan ayafi awọn Heleni? Rara o! Tabi ṣe o wa tunmọ si pe iṣẹ iransẹ Peteru ko bukunfun awọn Heleni kankan ayafi awọn Juu? Rara o!
(Galatia 2:1-10)

Nkan ti Pọọlu fẹ ki o ye wa ni pe awọn Heleni ni a diidi ran oun si. Nitorina, iṣẹ iranṣẹ rẹ gbooro laarin wọn ju ti awọn Juu lọ. Jesu tilẹ ti sọ fun tẹlẹ pe awọn Juu ko ni tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ rẹ. Idi si niyi ti O fi ran an lọ si aarin awọn Keferi. A si ri pe ni gbogbo ibi ti o ti lọ waasu, awọn Juu ni o yọ ọ lẹnu ju. Awọn gan ni o jẹ ki o di ero inu tubu. Nibakan naa, Jesu lo Peteru naa laarin awọn ti ko ki i ṣe Juu. Oun gan tilẹ ni ẹni akọkọ ti o waasu si awọn Heleni, ti Ọlọrun si tipasẹ rẹ sọ lara wọn di atunbi. Amọ ṣa o, aarin awọn Juu ni iṣẹ iranṣẹ rẹ ti gbooro ju. (Wo: Iṣe Apọsiteli 10 & 22:17-21)

Siwaju si, laarin awọn Heleni paapa, iṣẹ iranṣẹ Pọọlu naa tun ni aala. Fun apẹẹrẹ, o sọ eyi fun awọn ara Kọrinnti: “Bi emi ko tilẹ i ṣe Apọsiteli fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn dajudaju Apọsiteli ni emi i ṣe fun yi: itori edidi iṣẹ Apọsiteli mi ni ẹyin i ṣe ninu Oluwa.” (1Kọrinnti 9:2) Eyi tunmọ si pe Pọọlu mọ wipe oun ko ki i ṣe apọsiteli si gbogbo eniyan afi awọn ti Ọlọrun fun oun ni ore-ọfẹ lati ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laarin wọn. Yatọ si eyi, o tun sọ nibomiran pe, “Awa ki yoo ṣogo rẹkọja ara wa, ṣugbọn ero wa ni lati duro ni ala naa, ti Ọlọrun ti pin fun wa, ani lati de ọdọ yin. Nitori awa ko kọja aaye wa rara, bi ẹni pe awa ko de ọdọ yin. Nitori awa tilẹ de ọdọ yin pẹlu ninu iyinrere Kirisiti. Awa ko ṣogo rekọja ala wa, lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ yin ti n dagba si, ki ala wa laarin yin pẹlu maa dagba soke si i.” (1Kọrinnti 10:13-15)

Awọn ẹsẹ bibeli yi n jẹ ki o ye wa pe bi eniyan ba jẹ apọsiteli, yoo ni awọn ti a ran ṣi. O le jẹ orilẹ-ede kan ni a ran si tabi ẹya eniyan kan tabi agbegbe kan, lati pe wọn si ọdọ Ọlọrun nipasẹ Jesu, ki o si tun fi idi wọn mulẹ ninu gbogbo otitọ Jesu ti wọn nilo lati mọ nipa kikọ wọn ni ọrọ Ọlọrun ati oniruuru iṣẹ ami ati iyanu. Aarin awọn ti a wa ran si yi ni iṣẹ iranṣẹ rẹ yoo ti mulẹ ju, bi o tilẹ jẹ pe o si le ṣiṣẹ iranṣẹ ni ibomiran ati laarin awọn ọmọ Ọlọrun miran pẹlu. Bẹẹ si ni pẹlu, aarin awọn ti a ran si yi nikan ni o ti gbọdọ gbiyanju lati ma lo aṣẹ rẹ gẹgẹ bi apọsiteli Kirisiti. O wa ṣeeṣe, bi Pọọlu ti ṣe sọ fun awọn ara Kọrinnti, ki Ọlọrun fẹ oju aala iṣẹ iranṣẹ rẹ si. Amọ o gbọdọ ma fi gbogbo igba fi aala iṣẹ iranṣẹ rẹ sọkan, ki o ma ba lo ṣe nkan ti yoo jẹ ki o tẹ laarin awọn ọmọ Ọlọrun miran.

APỌSITELI EKE
Njẹ awọn apọsiteli eke wa bi? Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, wọn wa. Ibikibi ti a ba ti ri awọn ọmọ Ọlọrun ati iransẹ Ọlọrun otitọ, o ṣeeṣe ki awọn eke naa wa nibẹ pẹlu. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinnti ninu iwe rẹ kan si wọn:

“Ṣugbọn ohun ti mo n ṣe ni emi o si maa ṣe, ki emi ki o le fopin si iyagan awọn ti n fọnnu pe iṣẹ kan naa ti awọn n sogo ninu rẹ ni awa naa n ṣe pẹlu, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa. Nitori iru awọn eniyan bẹẹ ni awọn eke Apọsiteli, awọn eni i n ṣiṣẹ ẹtan, ti n pa ara wọn da di Apọsiteli Kirisiti. Kii ṣii ṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ n pa ara rẹ da bi angẹli imọlẹ. Nitori naa, kii ṣe ohun iyalẹnu mọ bi awọn iranṣẹ rẹ pẹlu ba pa ara wọn da bi awọn iranṣẹ ododo; awọn ẹni ti igbẹyin wọn yoo ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.” (2Kọrinnti 11:12-15)

Eyi jasi pe ni akoko awọn apọsiteli igbani gan awọn eke apọsiteli naa wa pẹlu. Awọn ti wọn n yi ara wọn pada gẹgẹ bi apọsiteli Ọlọrun naa wa nigba naa pẹlu. Pọọlu pe awọn wọnyi ni iranṣẹ Satani. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun kọ ni o ran wọn. Ba wo wa ni a wa ṣe le mọ wọn? Akọkọ, a le mọ wọn nipa titẹle ọrọ Jesu Oluwa wa lori bi a ṣe le mọ iranṣẹ rẹ otitọ yatọ si awọn eke. O sọ fun wa pe nipa eso ti awọn eniyan ba n so ni a o fi mọ boya iranṣẹ Oun niwọn lotitọ tabi bẹẹkọ (Matiu 7:15-20).

Nitorina, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni apọsiteli Jesu, ti awọn eso Ẹmi Kirisiti ko si farahan laye rẹ ko ki i ṣe apọsiteli otitọ tabi ki o jẹ apọsiteli ti o ti ṣubu sinu ẹsẹ, ti o si nilo ironipiwada ati imupadabọsipo. O wa ṣeeṣe ki ẹni bẹẹ ma ṣe oniruuru iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami. Eyi ko tunmọ si pe ko ki i ṣe eke. Awọn eniyan le lo ẹmi oṣo tabi ti ajẹ lati ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami gẹgẹ bi ọrọ bibeli (2Tẹsalonika 2:9-10). Idi si ni yi ti a ko fi le sọ daju pe apọsiteli Jesu ni ẹnikan nitori pe o n ṣe iṣẹ ami ati iyanu tabi nitoripe o n da ijọ silẹ kaakiri nikan. Ti igbe aye rẹ ko ba ti dọgba pẹlu ọrọ Ọlọrun, ti ko si duro siwaju awọn ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi apẹẹrẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ẹ ri ni aye wọn, ko ki i ṣe apọsiteli otitọ.

Ọna kẹji ti a tun fi le mọ eke apọsiteli ni ki a wo irufẹ iṣẹ ti o n ṣe. Bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, a ko le sọ pe apọsiteli ni eniyan nitori awọn iṣẹ ti o n ṣe nikan. Amọ ṣa o, ẹni ti iṣẹ iranṣẹ rẹ naa ko ba wa ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli lori iṣẹ iranṣẹ apọsiteli naa ko ki i ṣe apọsiteli otitọ. O le ma fọn ẹnu, ki o si ma sogo lori awọn nkankan ti o n ṣe, bi awọn ti Pọọlu sọrọ wọn ninu iwẹ rẹ si awọn ara Kọrinnti. Ṣibẹsibẹ, ko ki i ṣe apọsiteli otitọ. Iru wọn ni wọn ki mọ ala iṣẹ iranṣẹ wọn, ti wọn o si ma gbiyanju lati paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn ba ri tabi ti wọn ba fi aye gba wọn. Awọn wọnyi ma n ba iṣẹ Ọlọrun jẹ kẹyin naa ni ti wọn ko ba tete ronupiwada.

IHA WO NI O YẸ KI A KỌ SI WỌN?
A wa gbọdọ yẹra fun ẹnikẹni ti a ba ti fidi rẹ mulẹ, ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli, pe ko ki i ṣe apọsiteli Kirisiti. Jesu yin awọn ijọ Efesu fun eyi ninu lẹta rẹ si wọn ti o wa ninu iwe ifihan, eyi ti o sọ wipe: “Emi mọ iṣẹẹ rẹ ati laalaa rẹ, ati ifarada rẹ, ati bi ara rẹ ko ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti n pe ara wọn ni apọsiteli, ti wọn kii ṣi i ṣe bẹẹ, ti iwọ si rii pe elekee ni wọn.” (Ifihan 2:2-3)

Njẹ o ri bayi? Ki a to le mọ iru iha ti o yẹ ki a kọ si ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni apọsiteli, a kọkọ gbọdọ dan an wo naa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Ti a ba si ri pe olotitọ ni, nṣe ni o yẹ ki a gba a tọwọ-tẹsẹ gẹgẹ bi a ti a ti ṣe gba Jesu fun ara rẹ, ki a ba le jẹ ere iṣẹ iranṣẹ rẹ. Eyi jasi pe niwọn igba ti a ba ti mọ pe apọsiteli otitọ ni ẹnikan ti Ọlọrun fun wa ni anfaani lati pade tabi lati pin ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ, a gbọdọ lepa lati ran oun ati iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli. Eyi si lere lori pupọ fun wa. (Wo: Matiu 10; Luke 10:1-12; 1Kọrinnti 9:1-14; Filipi 4:10-19)

Amọ ti a ba ri pe eke ni ẹni naa ti o n pera rẹ ni apọsiteli fun wa, a gbọdọ yẹra fun, ki a si tun kilọ fun awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni sakani wa lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a kopa ninu ẹṣẹ rẹ tabi ki a ko sinu panpẹ rẹ ti o dẹ lati ba aye wa jẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 20:29-31; 2Johanu 10-11)

ỌRỌ IPARI
Iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ṣe pataki pupọ, paapaa julọ lati tan imọlẹ sinu aye awọn eniyan ni awọn agbegbe, ẹya ati orilẹ-ede ti ko i ti fi aye gba ihinrere Jesu tobẹ jubẹ lọ. Amọ ṣa o, awọn ti Jesu funrarẹ ba ṣe yẹ nikan ni o lẹ ṣe iṣẹ yi bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ. Nitorina, ti a ba mọ ẹyakẹya tabi edekede tabi agbegbekagbegbe ti ihinrere Jesu ko i ti fi taratara mulẹ nibẹ tabi ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa nibẹ ti ku patapata ninu ẹmi, ẹtọ wa ni lati gbadura si Ọlọrun ki o gbe apọsiteli dide fun irufẹ agbegbe naa, ki a ba le ri ikore awọn ọmọ rẹ lati ibẹ.

IBEERE

  • Njẹ a ri awọn ti a le pe ni apọsiteli ninu ijọ Ọlọru loni? Ki ni o jẹ ki o ro pe apọsiteli ni wọn?
  • Bawọ ni ẹkọ yi ṣe ran imọ ati oye ti o ni nipa iṣẹ iranṣẹ apọsiteli lọwọ si?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

APỌSITELI | Paito J.O. Lawal | ỌJỌRU 16, ERELE 2022 Read More »

Ranti aya Lọọti |Pst. J.O. Lawal |Erele 13, 2022 |Vol. 10, No. 41

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Erele 2022. Adura mi fun ọ si ni pe ki o ma fi gbogbo igba gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati jẹ olotitọ si ati lati ma ṣe bojuwẹyin rara titi di opin igba yi. Amin.

Gẹgẹ bi Jesu Oluwa wa ti ṣe fi ye we yekeyeke, kiki awọn ti o ba duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn de opin ni yoo ni iriri igbala ayeraye (Matiu 24:13). Yatọ si eyi, awọn apọsiteli rẹ naa tun sọ nkankanna ninu awọn akọsilẹ wọn. Awọn naa fi han wa pe kiki awọn ti o ba duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn titi de opin ohun gbogbo ni onigbagbọ ododo ati alabapin ninu Kirisiti (Kolose 1:21-23; Heberu 3:6&14). Nitorina, irinajo wa pẹlu Ọlọrun ko yẹ ko jẹ foniku-fọlande tabi eyi ti a o rin fun igba diẹ. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki o jẹ eyi ti a o rin lati ibẹrẹ de opin. Eyi wa jasi pe a ko gbọdọ dẹyin tabi bojuwẹyin. Nṣe ni a gbọdọ ma tẹsiwaju ninu rẹ titi de opin ohun gbogbo.

Woo, ewu wa ninu ki a dẹyin ninu irinajo yi. Ewu si tun n bẹ ninu ka bojuwẹyin naa. Jesu Oluwa wa sọ pe, “Ranti aya Lọọti.” (Luuku 17:32) Ki ni ki a ranti nipa aya Lọọti? Dajudaju, ipe yi ko ki i ṣe fun wa lati ranti pe obinrin Lọọti ni arabinrin yi jẹ tabi pe o bi awọn ọmọbinrin melokan fun un. Dipo eyi, ipe naa ni fun wa lati ranti iṣẹlẹ kan ti o ṣẹlẹ laye rẹ, eyi ti o kọ wa lati ma bojuwẹyin lẹyin igba ti a ba ti dahun ipe lati ba Ọlọrun ni ajọṣepọ.

Aya Lọọti, gẹgẹ bi ọkọ rẹ pẹlu, ni a kilọ fun nipasẹ awọn angẹli ti Ọlọrun ran lati pa Sodomu ati Gomora run lati sa asala fun ẹmi rẹ ati lati ma ṣe bojuwẹyin fun idi kankan. Ọna ti Ọlọrun n gba lati fi aanu han arabinrin yi niyi, ki o ma ba di ẹni iparun pẹlu awọn ika eniyan Sodomu ati Gomora. Ṣugbọn arabinrin yi ṣe aigbọran si aṣẹ kekere yi, o si bojuwẹyin.

Wayi o, bibojuwẹyin rẹ ṣeeṣe ki o dabi nkan ti ko lewu rara fun un lati ṣe. Nkan ti mo n sọ ni pe bibojuwẹyin rẹ yi lati mọ nkan ti o ṣẹlẹ si Sodomu ati Gomora ko dabi ki o ma ba wọn kopa ninu ẹṣẹ agbere, ole-jija tabi ifẹkufẹ ti ko dọgba. Ṣibẹsibẹ, ṣiṣe bẹẹ mu ijiya lọwọ wa fun un. Lẹsẹkẹsẹ naa ni o di ọwọn iyọ, ti ko si le de ebute rẹ ti o n lọ mọ fun aabo. Nitorina, bibojuwẹyin fun aya Lọọti ko yatọ rara si kikopa ninu ẹṣẹ awọn ara Sodomu ati Gomora. (Wo: Jẹnẹsisi 19)

Ṣugbọn ki lo jẹ ko bojuwẹyin? A ko la a fun wa ninu bibeli. Ohun yowu ti o jẹ, nkan naa jẹ ki o padanu ẹmi rẹ, ki o si tun kuna lati de ebute aabo ti o n lọ. Nibakannaa, oniruuru nkan ni o le jẹ ki awa naa bojuwẹyin wo igbe ayẹ ẹṣẹ ati aigbọran si Ọlọrun ti a ti kọ silẹ. Ti a ba si wa fi aye gba ọkankan lara wọn lati jẹ ki a bojuwẹyin, o ṣeeṣe ki a di wa lọwọ lati tẹsiwaju ninu irinajo igbagbọ wa lati ni iriri igbala ayeraye.

Nitorina, a gbọdọ ma fi gbogbo igba pa ọkan ati aye wa mọ kuro lọwọ awọn ero ati awọn eniyan ti o ba n fi ọpọ igba fẹ jẹ ki a bojuwẹyin, ki a si tun pongbẹ fun igbe aye ofo atijọ ti a ti pati. Bẹẹni, a gbọdọ daabo bo ara wa kuro lọwọ ohunkohun tabi ẹnikẹni ti o ba n jẹ ki a fi gbogbo igba ṣafẹri igbe aye atijọ ti a ti kọ silẹ. Si ranti pe, gẹgẹ bi o ti ṣe ri ni ti aya Lọọti, bibojuwẹyin lati yọ lori igbe aye ẹṣẹ wa atẹyinwa le buru jọjọ bi ki a ma gbe ninu ẹṣẹ lọwọlọwọ yi. Ibikibi ti eyi ba si ti ri bẹ, awa naa le reti irufẹ ijiya ẹṣẹ ti awọn ti o n dẹṣẹ lọwọlọwọ ba n jẹ ninu aye wọn. Iru ijiya ti eyi wa le jẹ ni n ko le sọ fun ọ. Ṣugbọn mo le sọ fun ọ pe ki o ranti aya Lọọti.

Ki o ni ọsẹ aladun.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ranti aya Lọọti |Pst. J.O. Lawal |Erele 13, 2022 |Vol. 10, No. 41 Read More »

Mura lati fun ju bẹ lọ | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Erele 06, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 40

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu osu Erele 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki oore-ọfẹ rẹ pọ si fun ọ, ki o ba le ni anito ohun gbogbo ninu ohun gbogbo at ni gbogbo igba, ki o si pọ si ni iṣe rere gbogbo ni ọsẹ yi ati ninu gbogbo ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi Ọlọrun ba ṣe n jẹ ki a pọ si ninu ohun rere, nkan ti o tọ, ti o si mọgbọn wa fun wa ni pe ki awa naa pọ si ni fififunni si i. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ifẹ rẹ ni ki a tayọ ninu oore-ọfẹ fififunni (2Kọrinnti 8:7). Eyi jasi pe nkan ti Ọlọrun fẹ fun wa ni pe ni ki awa naa fi ipo titiraka lati fifun un tabi fifun ẹni yoowu ti O fẹ ka fifun silẹ lọ si ipo ẹni ti o n fifunni laiṣiregun, lọpọ yanturu ati pẹlu ayọ. Njẹ eyi wa tunmọ si pe eniyan ko le fifunni lọfẹ, lọpọlọpọ ati pẹlu ayọ ni ipo aini rẹ? Rara o! Abi ṣe o tunmọ si pe bi nkan ti a fifunni ba ti ṣe pọ to ni Ọlọrun yoo ṣan wa lẹsan? Rara o!

Fun apẹẹrẹ, bi Pọọlu ṣe sọ ninu lẹta rẹ si awọn ara Kọrinnti, igba kan wa ti awọn ọmọ ijọ Ọlọrun Makẹdonia fifun iṣẹ ihinrere ni ipo aini wọn. Sibẹsibẹ wọn fifunni lọpọlọpọ ati pẹlu ayọ. Ka tilẹ sọ otitọ, nṣe ni wọn bẹ apọsiteli yi lati fi aye gba wọn lati fifunni ni akoko naa. Lafikun, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ bibeli, opo kan wa ti o fifun Ọlọrun ninu aini rẹ. Sibẹsibẹ Jesu Oluwa sọ wipe obinrin yi fi owo silẹ ju gbogbo awọn yoku lọ ni ojọ naa, nitoripe ohun gbogbo ti o ni lọwọ ni o fi silẹ. (Wo: Maaku 12:41-44; Luuku 21:1-4; 2Kọrinnti 8:1-5)

Nitorina, ko si nkan ti o buru ninu ki a fifun Ọlọrun lati ninu aini wa, niwọn igba ti ọkan wa ba ti mọ. Amọ ṣa o, awọn ipo fififunni kan wa ti a ko le de, niwọn igba ti a ba wa ni ipo aini. Lotitọ, ọkan wa le yẹ, ki o si fẹ fifunni. Amọ a ko le fun ẹnikẹni ni nkan ti a ko ni, niwọn igba ti a ba wa ni ipo aini. A ko si le fifunni ni ọna ti o kọja afẹnusọ ti a ba wa ni ipo talaka. Ṣugbọn Ọlọrun fẹ ki a de ipo naa ni aye wa ti a o ti ma fifunni ni ọna ti o kọja afẹnusọ.

Fun apẹẹrẹ, nigba ti O sọ fun awọn ọmọ Isiraẹli pe ki wọn fun Oun ni ọrẹ fun kikọ agọ rẹ, wọn fifun ni ọna ti o kọja afẹnusọ. Bi bibeli ti ṣe fi ye wa, fififunni wọn yi ga to bẹẹ gẹ ti Mose, ni akoko kan, fi pasẹ pe ki ẹnikẹni ma mu ọrẹ wa fun Oluwa mọ, nitoripe eyi ti wọn ti mu wa gan ti pọ ju fun iṣẹ naa. Bi bibeli si tun ṣe fi han wa, ko si ẹni kankan ti a mu ni ọranyan lara wọn nigba naa lati fun Ọlọrun ni ohunkohun. Nitorina, kiki awọn ti o wa lati ọkan wọn, ti inu wọn si tun dun lati fifun nikan ni o mu ọrẹ wa. Sibẹsibẹ, wọn mu wa ju ohun ti wọn nilo lọ. (Wo: Ẹkisodu 35:20-36:7)

Njẹ ki wa lo fa ti wọn fi le ṣe eyi, bi o tilẹ jẹ wipe inu aginju ni wọn wa? Idi ni pe wọn pọ ni ọrọ ti aye yi. Wọn ko le fifun Ọlọrun bi eyi nigba ti wọn jẹ ẹru, ti wọn si wa ninu aini ni Ijibiti, bi wọn tilẹ fẹ ṣe bẹ. Ṣugbọn ni ọjọ kannaa ti Ọlọrun mu wọn jade lati Ijibiti ni O tun sọ wọn di ọlọrọ pẹlu ọrọ Ijibiti. Nitorina, nigba ti O wa sọ fun wọn pe ki wọn fun Oun ni ọrẹ, wọn ko dojuti. Dipo eyi, wọn fifun ju bi O ti ṣe bere lọ. (Ẹkisodu 12:33-36)

Nibakanna, awa naa le de ipo naa ninu aye wa ti a o ti ma fun Ọlọrun ju bi o ṣe fẹ lọ. Ṣugbọn ṣe a fẹ de ipo naa bi? Ibeere niyẹn o. Ṣe a fẹ kuro ni ipo ki a ma tiraka lati fifun Ọlọrun lọ si ipo ki a ma fifun, fifun awọn iranṣẹ rẹ ati fifun gbogbo awọn yowu ti O ba ka fifun ju bi O ti ṣe fẹ lọ. Ti a ba fẹ ṣe bẹ, njẹ o yẹ ki a ṣe agbeyẹwo adura Pọọlu yi fun awọn ara Kọrinnti, ki a si fi tọkantọkan ṣe ‘Amin’ si: “Njẹ ẹni ti n pese irugbin fun afunrugbin, ati akara fun ounjẹ, yoo pese irugbin fun yin, yoo si sọ ọ di pupọ, yoo si mu eso ododo yin bi si. Ẹyin o si di ọlọrọ ninu ohun gbogbo, ki ẹyin ki o le maa fi funni ni igba gbogbo; awọn eniyan yoo si maa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun ti wọn rigba nipasẹ wa.” (2Kọrinnti 9:10-11)

Ki o ni oṣu Erele alaṣeyọri.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mura lati fun ju bẹ lọ | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Erele 06, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 40 Read More »

Ko ki i ṣe ẹbun ẹmi rẹ nikan | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Sẹrẹ 30, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 39

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun 2022. Adura mi si ni pe, bi o ti ṣe n la ọsẹ yi kọja lọ, ki a ṣi oju rẹ lati ri awọn nkan ti o nilo lati fi ara rẹ jin si lọdun yi, ki o ba le pọ si ni iwulo ni ọwọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọna kan gbogi lati pọ si ni iwulo ni ọwọ Ọlọrun, yatọ si pe ki a ma gbadura si i, ni ki a mọ awọn ẹbun rẹ ti o wa ninu aye wa, ki a si ṣe amulo ti o peye wọn. Bi bibeli ti ṣe fi han wa, kiki awọn ti o ba n ṣe amulo ti o nitunmọ awọn nkan ti Ọlọrun fun wọn, yala nipa ti ẹmi ni tabi nipa ti ara, ni yoo fun ni nkan si, ki wọn ba le pọ si ni iwulo pẹlu wọn. Awọn ti ko ba ṣe nkan to jọju tabi ti ko ṣe nkankan pẹlu nkan ti O fun wọn ko ni ri afikun ifihan, amuyẹ, iṣura tabi anfaani gba si lọwọ rẹ. Ti wọn ko ba tilẹ ṣọ ara wọn, o ṣeeṣe ki o gba awọn nkan ti O ti fun wọn kuro lọwọ wọn. (Wo: Maaku 4:24-25; Luke 19:11-26)

Nitorina, ti a ba fẹ pọ si ni iwulo ninu ijọba Ọlọrun ninu ọdun yi, a gbọdọ fi ara balẹ wo aye wa lati ri awọn nkan ti O ti fun wa ti a le lo lati sin in tabi lati ṣe iṣẹ rẹ. Eleyi si kọja lilo ẹbun ẹmi wa lati sin in. O tun ni i ṣe pẹlu ki a lo awọn amuyẹ wa, ẹkọ wa, nkan ini wa ati ipo wa lati sin in.

Fun apẹẹrẹ, Luuku, ẹni ti o kọ ọkan lara awọn iwe ihinrere bibeli ati iwe ‘Iṣe Awọn Apọsiteli’, ni a ko mọ gẹgẹ bi apọsiteli, wolii, ajinhinrere tabi pasitọ. Dipo eyi, a mọ ọn gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ oniṣegun ilera. Ṣugbọn o ṣe amulo ẹkọ rẹ ati ifẹ ti o ni si itan sisọ lati sin Oluwa nipa kikọ akọsilẹ igbe aye Jesu Kirisiti Oluwa wa ati iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ẹsẹẹsẹ. O si tun ṣe amulo awọn nkan wọnyi ni fifun wa ni akọsilẹ ranpẹ itan ijọ ati itankalẹ ihinrere Jesu Kirisiti kaakiri gbogbo agbaye. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe oniwaasu, o fi ara rẹ si ipo iwulo fun Ọlọrun lati pa otitọ ihinrere Jesu Kirisiti mọ fun wa. (Wo: Luuku 1:1-4; Iṣe Apọsiteli 1:1-2; Kolose 4:14)

Yatọ si eyi, Dọkasi ko ki i ṣe oniwaasu tabi adari ijọ. Ṣugbọn o n fi gbogbo igba lo awọn nkan ini rẹ lati ran awọn alaini lọwọ, paapaa julọ awọn ti o wa ninu ijọ. Eyi si jẹ ki o di gbajumọ laarin awọn ara ijọ rẹ. Nitorina, nigba ti o ku, wọn kọ jalẹ lati faramọ iku rẹ. Ni kiakia ni wọn ranṣẹ si Peteru, ẹni ti o wa lati gbadura fun un ki o ba le pada si aye. Ọlọrun si dahun adura rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe O mọ pe ti oun ba fun arabinrin yi ni ọdun diẹ si lati gbe ile aye, ko ni fi ṣofo lori igbe aye alailere. Dipo bẹẹ, nṣe ni yoo lo awọn ọdun naa lati pọ si ni iwulo ati isesorere. (Wo: Iṣe Apọsiteli 9:36-42)

Nitorina, o ko nilo lati jẹ oniwaasu tabi ẹni ti o ni ẹbu iwosan ki o to wulo ninu ijọba Ọlọrun tabi ki o to le pọ si ni iwulo ninu ijọba rẹ. O kan nilo lati ma fi gbogbo igba ṣe amulo ti o peye ẹbun ẹmi yowu ti o ni ni. Yoo si ya ọ lẹnu awọn nkan ti Ọlọrun yoo tipasẹ rẹ ṣe. Siwaju si, bi o tilẹ wa woye pe o ko mọ ẹbun ẹmi pato ti o ni lọwọlọwọ yi, bẹrẹ si ni ro awọn ọna ti o le gba lo ẹkọ rẹ, awọn amuyẹ rẹ tabi nkan ini rẹ lati mu ki iṣẹ rẹ tẹsiwaju.

Fun apẹẹrẹ, ti o ba jẹ gbẹnagbẹna, wo nkan ti o le ṣe fun iwulo ijọ Ọlọrun tabi ki o wo awọn ọna ti o le gba lo awọn amuyẹ rẹ lati yọ ijọ kuro ninu awọn inawo ainitunmọ kan. Boya ounkọwe si ni iwọ tabi oniṣẹọna. Ronu si awọn ọna ti o le gba ma lo awọn amuyẹ yi lati ran ijọ lọwọ ati lati jẹ ki ihinrere gbooro si, dipo eyi ti o fi ma fi gbogbo igba ṣe awawi fun aiwulo rẹ fun Ọlọrun ni ọna kankan. O wa ṣeni laanu lọpọlọpọ pe ọpọ eniyan ninu awọn ijọ wa loni ni ko ki i fẹ lo awọn amuyẹ wọn lati sin Ọlọrun, ti ko ba ti ni yọ ere ti o pọ fun wọn. Otitọ tilẹ ni pe awọn kan ko kọ lati lu ijọ ni jibiti lori ọrọ yi. Idi si ni pe ifun wọn ni ọlọrun wọn. (Wo: Ẹkisodu 35:4-36:3; Filipi 3:18-19)

Wayi o, mo mọ pe nkan ti ko dara ni ki ijọ naa ma rẹ awọn ti o ba n baa ṣiṣẹ jẹ tabi ki o ma san owo ọya wọn pe, paapaa julọ nitoripe wọn jẹ ọmọ ijọ tabi onigbagbọ. Ti onigbagbọ kan ba fẹ din ijọ lowo lori ọja ti o ta tabi iṣẹ ti o ṣe fun ijọ, ko buru rara. Ṣugbọn o gbọdọ ti ọkan rẹ wa lati ṣe eyi ni, ko ki i ṣe pe ki a wa tan an jẹ, dẹruba tabi mu ni dandan lati ṣe e (2Kọrinnti 9:7). Sibẹsibẹ gbogbo wa ni a gbọdọ kọ lati ma lo ohunkohun ti a ni ti o wulo fun iṣẹ Ọlọrun lati ṣe iṣẹ rẹ ati lati pọsi ni iwulo ninu ijọba rẹ. Aijẹbẹ, afaimọ ki O ma pe wa ni iranṣẹ ọlẹ ati alailere ni ọjọ kan. Mo si gbadura pe ki nkan ma ṣe yọri si eyi fun iwọ ati emi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ko ki i ṣe ẹbun ẹmi rẹ nikan | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu |Pst. J.O. Lawal |Sẹrẹ 23, 2022 |Vol. 10, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Ṣẹrẹ 2022. Adura mi fun ọ si ni pe ki a kọ ọkan rẹ, ki a si tun fun ni okun lati ṣe amulo wiwa Ọlọrun ninu aye rẹ ni ọna ti o peye ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọjọ aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara awọn ọrọ bibeli ti o peni nija julọ ni eyi ti a ri ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Roomu ti o sọ wipe, “Bi Ọlọrun ba wa fun wa, ta ni yoo le kọju ija si wa?” (Roomu 8:31) Njẹ Ọlọrun wa fun wa bi? Njẹ iha wa ni o wa bi? Ti O ba wa fun wa, lotitọ O si wa fun wa, ta wa ni o le doju ija kọ wa? Ko si! Nkan ti mo n sọ ni pe ko si ẹni naa ti o lagbara to lati pọn wa loju tabi ṣe wa ni ibi lori nkan yowu ti ko ba jẹ, niwọn igba ti Ọlọrun wa fun wa. A kan nilo lati jẹ ki ọrọ yi gba ọkan wa kan ni, ki a si tun ma rin ni ibamu pẹlu rẹ.

Fun apẹẹrẹ, nitori pe Ọlọrun wa pẹlu Aburahamu, Isaki ati Jakọbu ko si ẹnikẹni ti o ṣe aṣeyọri lati rẹ wọn jẹ tabi pọn wọn loju. Bibeli sọ wipe, “Oun ko jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ibi: Nitootọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn. Pe, Ẹ ma ṣe fi ọwọ kan ẹni ororo mi; ẹ ma si ṣe awọn wolii mi ni ibi.” (Saamu 105:14-15) Iwọ naa ro wo. Ọlọrun ko gba ki ẹnikẹni pọn awọn wọnyi loju nitori pe eniyan rẹ ni wọn jẹ. O si tun ṣetan lati fi iya jẹ wọn tabi pa wọn run, iyẹn ẹnikẹni ti o ba gbiyanju lati ṣe bẹẹ.

Ko wa jẹ iyalẹnu pe nigba ti Mose n dari awọn ọmọ Isiraẹli wọ inu Ilẹ-ileri lọ, ko bere ọrọ, ounjẹ, omi tabi aabo lọwọ Ọlọrun fun awọn eniyan naa. Dipo eyi, o bere fun wiwa rẹ pẹlu wọn. Kedere ni o tilẹ sọ fun pe ti ko ba ni wa pẹlu awọn titi wọn yoo fi wọ Ilẹ-ileri naa, ki o ma wulẹ jẹ ki awọn goke lọ. Ki ni idi? Idi ni pe o mọ pe wiwa Ọlọrun pẹlu wọn ni kiki ohun ti wọn nilo. Eyi tunmọ si pe o mọ pe niwọn igba ti Ọlọrun ba wa pẹlu wọn, gbogbo ounjẹ, omi, ọrọ, ilera ati aabo ti wọn nilo ati ju bẹẹ lọ pẹlu ni wọn yoo ni. (Wo: Ẹkisodu 33:12-17)

Wayi o, awa ko nilo lati bere fun wiwa Ọlọru pẹlu wa. Idi si nipe a ti ni wiwa rẹ pẹlu wa nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu Kirisiti Oluwa wa. Oun ti wa pẹlu wa, ninu wa ati fun wa. Bibeli tilẹ sọ pe, “…Ọlọrun tikararẹ ti wi pe, Emi ko jẹ fi ọ silẹ, bẹẹ ni emi ko jẹ kọ ọ silẹ. Nitori naa ni awa ṣe n fi igboya wi pe, Oluwa ni oluranlọwọ mi, emi ki yoo bẹru; kin ni eniyan le ṣe si mi?” Njẹ o ri bayi? Ọlọrun funrarẹ ti sọ pe Oun ko jẹ fi igba kankan fi wa silẹ tabi kọ wa silẹ. Eyi tunmọ si pe gbogbo igba ni oju rẹ yoo ma wa pẹlu wa.

Iha wo wa ni o yẹ ki a kọ si ọrọ yi? Ni kukuru, bi a ti tun ṣe fi han wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, nṣe ni o yẹ ki a fi igboya ma sọ pe, “Emi ki yoo bẹru. Ki ni nkan ti ẹnikẹni le fi mi ṣe?” Iṣẹ ta ni lati ma fi igboya sọ pe emi ki yoo bẹru? Iṣẹ mi ni. Iṣẹ rẹ ni. Isẹ ta si tun ni lati ma fi igboya sọ pe ko si nkankan ti ẹnikẹni le fi mi ṣe? Iṣẹ mi ni lati sọ bẹẹ. Iṣẹ rẹ ni lati sọ bẹẹ.

Amọ ko ki i ṣe pe ki a wa ma sọ awọn nkan yi nitoripe a fẹ ki awọn eniyan woye pe a laya. Dipo eyi, nṣe ni ki a ma sọ wọn nitoripe a mọ pe Ọlọrun wa pẹlu wa ni gbogbo ọna lati ri daju pe a tọju wa ni ọna ti o peye ati pe a da aabo bo wa kuro lọwọ ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ipọniloju Satani tabi ti eniyan. Ti iwọ ba wa mọ eyi, nṣe ni o yẹ ki o bi gbogbo ẹru rẹ danu. Bẹẹni, bi gbogbo ẹru rẹ danu, ẹru awọn iṣẹlẹ tabi eniyan ti o n dun mọhuru-mọhuru mọ ọ, ti o n yan ọ jẹ tabi ti o n pọn ọ loju. Idi si ni pe Ọlọrun yoo ba wọn wi fun ọ ati pe yoo tun gba ohun ti o jẹ tirẹ fun ọ.

Ranti pe O ba awọn ọba wi, pẹlupẹlu awọn ọba ti awọn ẹmi aimọ ti oṣo ati ti ajẹ n dari, fun awọn eniyan mimọ rẹ igbaani. Nitorina, ko ja mọ nkankan fun lati ba wọn wi fun iwọ naa, ohunkohun tabi ẹnikẹni ti o n ṣe ilodi si ibalẹ-ọkan, ilera tabi ilọsiwaju rẹ, bi o ti wu ki iru ẹni bẹẹ ma fi ẹmi okunkun paṣẹ to. Iwọ ṣa ri daju pe oun fi gbogbo igba ran ara rẹ leti pe O wa pẹlu rẹ. O o si ma fi gbogbo igba ri ifarahan agbara rẹ ti o ga lori ọrọ rẹ.

Ki o ni ọsẹ aladun.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu |Pst. J.O. Lawal |Sẹrẹ 23, 2022 |Vol. 10, No. 38 Read More »

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu. | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Sẹrẹ 16, 2022 | Atẹlera: Latori tabili | Nọmba: Vol. 10, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ṣere 2022. Adura mi si pe ki a fi gbogbo igba ṣe ọ yẹ ati fun ọ ni okun lati rin ni iṣẹgun lori gbogbo awọn nkan ti o n gbogun ti ọkan rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o n fi gbogbo igba gbogun ti ọkan wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ni agbere. O si wa wọpọ loni tobẹ gẹẹ ti o fi jẹ pe ko fẹrẹ si ibi ti o le lọ tabi dojukọ ti o ko ti ni ri nkankan ti yoo pa pe ọ lati kopa ninu rẹ. Ti o ba wa kọ lati ṣe nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ lori rẹ, afaimọ ki o ma ya ara rẹ lẹnu nipa ṣiṣe nkan ti o ko fi igbakankan ri lero pe o le ṣe. Eyi ti n ṣẹlẹ si ọpọ ninu awọn ọmọ Ọlọrun lọwọlọwọ yi. Si iyalẹnu wọn, wọn ti turasilẹ fun ẹṣẹ agbere, ni eyi ti wọn ti fi igbakan gbe oju agan si, ti wọn si sọ pe ko sunwọn. Ti wọn ko ba si pada lati lọ bẹrẹ si ni ṣe nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ lori agbere, wọn ko ni bọ lọwọ rẹ.

Ki o ba le mọ bi nkan ti mo n sọ ti ṣe buru si, laipe yi, mo ri stetọsi (bi o ti ṣe ri lọkan mi lọwọlọwọ) ti ẹnikan ti o pe ara rẹ ni Kirisitiẹni fi si ori ẹrọ ayelujara, eyi ti o ti n sọ pe oun ṣa fẹ ba ẹnikan sun, eni yowu ti o le jẹ. Lẹyin eyi ni o tun wa fi stetọsi miran sori ẹrọ yi, eyi ti o n fi awọn onigbagbọ kan ti wọn nkọrin nipa iye ayeraye ti a ni ninu Kirisiti Jesu han. Mo wa bere lọwọ ara mi pe, “Njẹ ọmọkunrin yi gbadun bi? Lati ori agbere sori ijọsin Kiristiẹni – bawọ ni wọn ṣe jọ ara wọn?”

Afi bi igba ti mi o ti ri nkankan, niwọn akoko yi naa ni mo tun ri stetọsi ti ẹlomiran ti oun naa pere rẹ ni onigbagbọ tun fi sori ẹrọ ayelukara yi. Nkan ti oun si n sọ ni pe ti ẹnikẹni ba ṣeesi ri oun ninu awọn sinnima iṣekuṣe, eyi ti wọn pe ni sinnima awọn to ti balaga, ki wọn mọ pe iṣẹ owo lo gbe oun de ibẹ – ki wọn ma fi ṣe ibinu rara. Lotitọ, lẹsẹkẹsẹ naa ni mo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si lati bere boya o gbadun. Ṣugbọn awọn nkan wọnyi n tọka si nkankan ni o, eyi si nipe aye ti a wa ninu rẹ yi jẹ eyi ti iṣekuṣe ti gbilẹ, ti o ti di tọrọfọnkale. Nitorina, ti awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ko ba ṣọ ara wa, a o kan dede ri lọjọ kan pe a ya ara wa lẹnu pẹlu ikopa wa ninu iwa ati nkan eeri ni.

Awọn nkan ti a si wa n sọ yi kọja pe ki a kan ma gbadura si Ọlọrun pe ki O pa wọn mọ kuro ninu ẹṣẹ agbere. O tun ni i ṣe pẹlu pe ki a ma ṣe amulo awọn nkan ti O sọ fun wa nipa ẹṣẹ yi. Ki si ni O sọ fun wa nipa rẹ? O sọ wipe, “Ẹ maa sa fun agbere…” (1Kọrinnti 6:18) Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ni agbara lati daabo bo wa kuro lọwọ gbogbo iṣoro, O wa n sọ fun wa pe ọna ti Oun la kalẹ fun ipamọ wa kuro ninu ẹṣẹ agbere ni ki a sa a fun. Bẹẹni, yoo fun wa ni okun, yoo si tun ri pe ọna lati sa fun ẹṣẹ yi wa fun wa. Amọ ojuṣe wa ni lati sa a fun. Aijẹbẹ, afaimọ ki a ma jọ ara wa loju nigba ti a ba ba ara wa ninu rẹ.

Wo Josefu igba aye bibeli. Bawo ni ko ṣe ko sinu panpẹ ẹṣẹ agbere pẹlu iyawo ọga rẹ? Ṣe nipa jijoko lati ba fomijomitoro ọrọ ni bi? Rara o! O ti kọkọ gbiyanju lati ba fi ọrọ jomitoro ọrọ, ṣugbọn ko ṣiṣẹ. Idi si nipe ifọrọjomitoro-ọrọ ko ki i ṣiṣẹ rara nibiti ara awọn eniyan ba ti n pongbẹ fun ibalopọ. Idi si ni yi ti a fi ri awọn kan ti wọn ti gbeyawo tabi wa nile ọkọ, ti ile wọn n dun, ti wọn ko si ni idi kankan lati ma ṣe agbere, ti wọn si n tun n ṣe e. Nigba ti awọn wọnyi ba to pa ile wọn run tan ni wọn yoo ṣẹṣẹ wa bẹrẹ si ni bere lọwọ ara wọn pe, “Kini mo ṣe yi? Ki lode ti mi o ba ara mi fọrọjomitoro-ọrọ ki n to lọ ṣe iru aṣiṣe yi?”

Nitorina, ma ṣe ro pe ifọrọjomitoro ọrọ, ọgbọn inu tabi ọkan-akin le pa ọ mọ kuro ninu ẹṣẹ agbere. Ko si ikankan ninu wọn ti o ni agbara lati pa ọ mọ kuro ninu rẹ. Ẹnikan ṣoṣo ti o le pa ọ mọ kuro ninu rẹ naa ni Ọlọrun. O si n sọ fun wa lọwọlọwọ yi pe, “Niwọn igba ti o ba ti ni i ṣe pẹlu ẹṣẹ agbere, sa asala fun ẹmi rẹ.” Nkan ti Josẹfu ṣe ni eyi. Akọkọ, o ri daju pe oun ko fi igba kankan da wa pẹlu iyawo ọga rẹ. Nigba ti obinrin yi si wa ri anfaani lati fa a sinu agbere, nṣe ni o fi ere ge e, lalai wo pe ko yẹ ki oun fi aṣọ ti o gba lọrun oun silẹ fun un. Lotitọ, inu tubu loti ba ara rẹ nitori ọrọ yi. Amọ ko ba iwa mimọ rẹ jẹ. Ọlọrun ṣi da a lare nigba ti o ya. (Wo: Jẹnẹsisi 39:6-15)

Nibakan naa, nṣe ni ki iwọ naa ri daju pe o jinna rere si ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o ba le fi aye gba agbere ninu aye rẹ. O ko nilo lati wa pẹlu ọkunrin tabi obinrin yowu ti o ba ma n fẹ ti ọ sinu agbere pẹlu ọrọ eeri tabi ifọwọkan ti ko boju mu. O ko si nilo lati wo sinnima yẹn tabi ki o fi ohun amuṣiṣẹ foonu yowu ti o ba n fi gbogbo igba pe ọ si ẹṣẹ agbere si ori foonu rẹ. Nitorina, ṣe ohun ti o tọ, ki o si fere ge, ti ọkan rẹ ba ṣe iyebiye si ọ, ti o ko si fẹ ko parun. Njẹ ki o ma fi gbogbo igba kun fun okun, igboya ati ọgbọn ti o nilo lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu. | Paitọ J.O. Lawal Read More »

ITARA ATI IMỌ NI SINSIN ỌLỌRUN | AYỌKA: ROOMU 10:1-2

AKỌSORI: “Ṣugbọn o dra lati maa fi itara ṣe rere nigba gbogbo, ki i ṣi i ṣe nigba ti mo wa pẹlu yin nikan.” (Galataia 4:16)

ỌRỌ AKỌSỌ
Nkan meji ti o ṣe pataki julọ ni biba Ọlọrun rin ni imọ ati itara. O wa ṣeeṣe ki eniyan ni imọ nkan ti Ọlọrun fẹ ki o si ma ni itara lati ṣe tabi ki o ni itara fun Ọlọrun ki o si ma ni imọ iru ẹni ti o jẹ ati nkan ti o fẹ. O tilẹ ṣeeṣe ki eniyan ma ni mejeeji. A si ri ọpọ laye loni ti wọn ko ni imọ Ọlọrun tabi itara lati sin in tabi lati ṣe ohunkohun fun. Ki wa ni awọn anfaani ti o wa nidi ki a ni imọ Ọlọrun ati ki a si tun fi itara ṣe amulo imọ naa ti a ni? Ki si ni ewu ti o sorọ mọ ki a mọ ni imọ rẹ ati itara fun un? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ ṣe agbeyẹwo wọn ninu ẹkọ yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣi oju wa lati ri awọn nkan ti O fẹ ki a tipasẹ ẹkọ naa ri, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo wọn. Amin.

IDI FUN IMỌ ỌLỌRUN ATI IMỌ IFẸ RẸ
Bi mo ti ṣe sọ siwaju, imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ṣe pataki pupọ fun ẹnikẹni ti o ba fẹ ba a rin. Ki si ni idi? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iwọnyi ni pataki julọ lara idi ti a fi nilo imọ Ọlọrun ati ti ifẹ lati le ba a rin:

  • Ki a ba le fi ara wa jin lati sin in: Ki ni idi ti awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti fi ni ọpọlọpọ isoro lati ba Ọlọrun rin? Idi ni pe wọn ko mọ ọn daju. Lotitọ, wọn ti gbọ ọpọlọpọ nkan nipa rẹ ati nipa agbara rẹ lati ẹnu awọn baba wọn ati awọn baba nla wọn. Yatọ si eyi, awọn naa tun ni oniruuru iriri agbara rẹ lọwọ igba ti O bẹ wọn wo ni Ijibiti, ti O si tun ko wọn jade. Ṣugbọn wọn ko ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti a le pe ni tiwọn. Eyi lo si fa ti wọn ko fi le fi ara wọn jin fun lati sin in tọkantọkan. Fun apẹẹrẹ, lẹyin ọjọ melokan ti Mose fi wọn silẹ lati lo gba iwe ofin lati ọwọ Ọlọrun fun wọn, wọn ba ara wọn sọrọ pe ki wọn gbagbe nipa rẹ ati nipa Ọlọrun ti o lọ ba pade, ki wọn si gbe ere kalẹ fun ara wọn, ti yoo ṣe amọna wọn lọ si ilẹ-ileri ti Ọlọrun fẹ mu wọn lọ (Ẹkisodu 32:1-6). Njẹ iyalẹnu ati kayefi kọ ni eyi jẹ bi? Pẹlu gbogbo iṣẹ iyanu ti wọn ri, ṣe o yẹ ki wọn tun ronu lati ni ọlọrun miran lẹyin Oluwa? Ko yẹ rara. Ṣugbọn nitoripe awọn funra wọn ko mọ Ọlọrun daju ninu ọkan wọn, ko jamọ nkankan loju wọn rara lati sare wa oriṣa ti yoo gba ipo rẹ ninu aye wọn. Nitori eyi ni bibeli ṣe sọ pe, “O fi ọna rẹ han fun Mose, iṣe rẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli.” (Saamu 103:7) A si ri ọpọ loni naa to jẹ wipe foniku-fọlande ni wọn ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Ijọsin ti wọn si Ọlọrun ko dawọ lilọ si ile alawo tabi ile alufa ẹlẹṣin yowu ti wọn ba ri duro. Awọn wọnyi ko i ti ni imọ Ọlọrun. Nitorina wọn ko le fi ọkan tabi ara wọn jin fun patapata. Ka wa kiyesi eyi: wipe eniyan n ni iriri agbara Ọlọrun ko tunmọ si pe o mọ Ọlọrun tabi pe yoo ba Ọlọrun jọba titi ayeraye.
  • Ki a ma ba ti ara rẹ kọsẹ: Ọpọ igba ni awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti ti ara Ọlọrun kọsẹ, ti wọn si ba ijiya pade. Pọọlu tilẹ sọ fun wa ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti pe inu Ọlọrun ko dun si ọpọ ninu awọn eniyan yi. Nitorina, O pa wọn run ninu aṣalẹ ti wọn wa. Ki lo fa? Idi ni pe wọn ko ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ fun wọn. Oye ko ye wọn pe Ọlọrun ti O mu wọn jade lati Ijibiti jẹ Ọlọrun daradara, ti O si jẹ pe ohun gbogbo ti O n ṣe wa fun ilọsiwaju, ayọ ati ifọkanbalẹ wọn. Aiwa ni imọ yi jẹ ki wọn ṣi ọrọ sọ, ki wọn si tun ṣi iwa wu ni ọpọ igba, eyi ti o si ja si iparun fun ọpọ ninu wọn. Nibakanna, ọpọ loni ni o n ṣi ẹṣẹ gbe, ti o si n sọ ọrọ odi si Ọlọrun nitoripe wọn ko mọ ọn. Ti awọn wọnyi ko ba si ri aanu gba, ko si ni ki aini imọ Ọlọrun yi ma yọri si iparun fun wọn bopẹboya. (Wo: Numeri 11; 1Kọrinnti 10:1-5)
  • Ki ijọsin wa ba le ṣe itẹwọgba: Jesu sọ fun arabinrin kan ni ọjọkan pe, “Ẹyin n sin ohun ti ẹyin ko mọ, awa n sin ohun ti awa mọ…” (Johanu 4:22) Pọọlu naa, nigba ti o n ba awọn ara Atẹni sọrọ lori ihinrere Jesu pe akiyesi wọn si ọkan lara awọn pẹpẹ wọn ti o ni akole ti o ka bayi: “Si Ọlọrun aimọ.” Bawo wa ni eniyan ṣe fẹ sin Ọlọrun ti ko mọ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ? Ko le e ṣeeṣe rara. Gẹgẹ bi ọrọ Jesu Oluwa wa, Ọlọrun ti o yẹ ki a ma sin jẹ ẹmi, ẹmi ti ko ṣe fojuru ṣugbọn ti o wa. Nitorina, ẹnikẹni ti yoo ba sin gbọdọ mura lati sin ninu ẹmi ati pẹlu otitọ. Ka ma tilẹ fọrogun, Jesu sọ wipe awọn ti yoo sin Ọlọrun ninu ẹmi ati ninu otitọ ni O n wa kiri. Awọn wọnyi nikan si ni iṣẹ isin wọn le jẹ itẹwọgba, ti wọn yoo si ri oriyin gba fun isin wọn. (Wo: Johanu 4:22-24; Iṣe Apọsiteli 17:22-23)

IDI FUN ITARA NI SISIN ỌLỌRUN
Siwajusi, bi o ti ṣe jẹ pataki fun wa lati ni imọ Ọlọrun naa ni o tun jẹ pataki fun wa lati ni itara fun un ati lati sin in. Pataki lara idi ti o si ṣe yẹ ki a ni itara fun un ni iwọnyi:

  • Awọn onitara ni Ọlọrun ma n fi ara rẹ han: Bibeli sọ wipe, “Nigba naa ni ni awa o mọ, bi a ba tẹramọ ọna lati mọ Oluwa…” (Hosia 6:3). O tun sọ siwaju pe, “Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ, yoo mọ niti ẹkọ naa, bi o ba jẹ ti Ọlọrun, tabi emi ba n sọ ti ara mi.” (Johanu 7:17) Ki ni eyi fi n ye wa? O n fi ye wa pe nini itara lati mọ Ọlọrun ati lati mọ ifẹ rẹ wa lara awọn nkan ti O ma n wo lati fi imọ ati oye otitọ rẹ han eniyan. Ara idi ti Mose ṣe mọ ọn bi o ti ṣe mọ ọn nipe o ni itara ti o ga lati mọ (Ẹkisodu 33:12-23). Pọọlu naa n kọ? Ki ni idi ti o fi ni imọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ ti o ga bi o ṣe ni? Yatọ si pe, Ọlọrun nifẹ lati fi ara rẹ han, oun naa ni itara ti o ga lati mọ (Filipi 3:10-15). Ti a ba wa woye pe a ko mọ Ọlọrun to tabi pe a ko ma fi gbogbo igba pọ si ninu imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti a ni, a ni lati yẹ ara wo fun itara. Njẹ itara wa fun koju osunwọn to? A si le mọ eyi nipa iha ti a kọ si ọrọ rẹ, adura gbigba, ibadapọ pẹlu awọn ọmọ rẹ ati iṣẹ isin ninu ijọba rẹ.
  • Awọn onitara ni Ọlọrun ma n pin ni ere: Bibeli sọ pe, “Ṣugbọn ni aisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wu Ọlọrun: nitori ẹni ti o ba n tọ Ọlọrun wa ko le ṣaigbagbọ pe o n bẹ, ati pe oun ni oluṣẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wa a.” (Heberu 11:6) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun jẹ oluṣẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wa a. Awọn wo ni yoo fi ara balẹ wa a? Awọn onitara ni yoo fi ara balẹ ati tọkantọkan wa. Ọna wo ni yoo wa gba san wọn lẹsan? Oun nikan naa ni O le sọ eyi. Ṣugbọn a fi ye wa daju ninu bibeli pe gbogbo awọn ti o ba fi itara ọkan ati otitọ inu wa Ọlọrun tabi ṣe iṣẹ rẹ ni o ma n jere ṣiṣe bẹ. Nitorina, ti o ba dabi ẹni pe a ko ma fi taratara gbadun Ọlọrun ninu aye wa, o yẹ ki a wo irufẹ itara ti a ni lati mọ ọn daju, lati mọ ifẹ rẹ ati lati ṣiṣẹ sin in.
  • Awọn onitara ni o ma n mu ki iṣẹ Ọlọrun tẹsiwaju, ki o si tun fi idi mulẹ: Awọn ti ko ba ni itara fun Ọlọrun ati lati mọ ifẹ rẹ ko ki i ṣaba fi taratara busi iṣẹ rẹ, boya akoko wọ fun wọn tabi ko wọ. Awọn ti o ni itara fun un ni o ma n fi gbogbo lepa lati ri pe iṣẹ rẹ n tẹsiwaju ati pe o n so eso ti o yẹ ki o so, bi o tilẹ lewu lati ṣe bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, ki lo fa ti Ọlọrun fi lo Pọọlu ni ọna ti o gba lo? Idi kan pataki ni pe o ni itara ti o ga lati mọ ọn, lati mọ ifẹ rẹ ati lati ri pe ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye ọpọ eniyan. Lara awọn nkan ti o sọ nipa ara rẹ ni eyi: “Nitori pe bi mo ti n waasu iyinrere, emi ko ni ohun ti emi o fi ṣogo: nitori pe aigbọdọ-ma ṣe wa lori mi; ani, mo gbe! Bi emi ko ba waasu iyinrere.” (1Kọrinnti 9:16) Ọrọ onitara ni eyi. Ọrọ ẹni ti o ṣetan lati ṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fun ni amuyẹ ati anfaani lati ṣe ki iṣẹ rẹ ba le tẹsiwaju ni yẹn. A tun ri apẹẹrẹ miran ninu Jesu Oluwa wa nigba ti O le awọn ti wọn ra ati awọn ti wọn n ta jade kuro ninu tẹmpili Ọlọrun ti o wa n Jerusalẹmu. Bibeli ṣi jẹ ki o ye wa pe itara fun ile Ọlọrun ni o jẹ ki o ṣe eyi. Awọn ti o ba ni itara fun ilera ijọ Ọlọrun tabi fun idagbasoko iṣẹ rẹ ko ni ma woran ki nkan bajẹ ki wọn to gbe igbesẹ lati ṣe ohun ti o tọ. Irufẹ awọn wọnyi si ni Ọlọrun ma n fi si ipo adari ati alatunṣe ninu ijọba rẹ. (Wo: Numeri 25; Nehemaya 13; Jeremaya 20:9; Johanu 2:13-17&9:4)

EWU TI SORỌ MỌ ITARA TI KO NI IMỌ
Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe ṣalaye siwaju, o lewu lati ni atara fun Ọlọrun lalai ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti o jinlẹ. Lara awọn ewu ti o si sọrọ mọ ni iwọnyi:

  • Ṣiṣe laala lori irọ: Ti a ko ba fi imọ kun itara wa fun Ọlọrun, o ṣeeṣe ki laala wa lati mu inu rẹ dun tabi lati ṣe iṣẹ sin in ja si asan. Fun apẹẹrẹ, ọjọ kan wa ti Jesu de Mata ati arabinrin rẹ Maria ni alejo, gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli. Mata si mura gidigidi ni ọjọ yi lati tọju Jesu ati awọn ti o wa pẹlu rẹ. Nigba ti o si n sare siwa ati sẹyin, Maria joko ti Jesu lati kẹkọ lẹsẹ rẹ. Eyi bi Mata ninu tobẹ gẹẹ ti o fi pe akiyesi Jesu si ọrọ naa. Ṣugbọn Jesu jẹ ki o ye wipe bi o tilẹ jẹ pe o n ṣe laala lotitọ lati tọju Oun, laala rẹ ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Oun ni akoko naa. Eyi jasi pe Mata ko ba kọkọ farabalẹ tẹti si Jesu lati mọ nkan ti O n fẹ ki o to ma sare kaakiri. Maria ko sare kaakiri bi Mata lati tọju Jesu. Ṣugbọn Jesu sọ wipe jijoko rẹ lati kẹkọ mọ ifẹ Oun lere lori, o si tun ṣe iyebiye ju gbogbo laala ti Mata n ṣe kaakiri lọ. A tun ri apẹẹrẹ miran ni ti awọn Juu ti ko ri igbala gba bi o tilẹ jẹ pe wọn ni itara ti o ga fun Ọlọrun. Ki si ni idi? Idi ni pe itara wọn jẹ eyi ti ko ni oye ifẹ Ọlọrun. Nitorina, bi o ti wu ki itara wa ga to, niwọn igba ti ko ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko nitunmọ. Laala yowu ti a ba si tipasẹ eyi ṣe ko le lere lori. (Wo: Luuku 10:38-42; Roomu 10:1-3)
  • Biba iṣẹ Ọlọrun jẹ: Yatọ si pe laala awọn ti itara wọn ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun le ja si asan, awọn gan tun le ba iṣẹ Ọlọrun jẹ. Pọọlu fi igba kan nṣe laala lati pa ijọ Jesu run nitoripe ko ni oye nkan ti o n ṣe (Galatia 1:13-14). Ọpọ losi dabi rẹ loni, ti awọn naa n fi itara ti ko ni imọ ba iṣẹ Ọlọrun jẹ tabi ṣe awọn ọmọ Ọlọrun ni ijamba. Ọjọ ti oju wọn ba si ṣi nkan ti wọn n ṣe ni wọn yoo to gba pe igbe aye basejẹ ni awọn ti n gbe. Boya awa naa tilẹ ti n ba nkan jẹ ninu ijọ Ọlọrun ti a wa tabi ni awujọ wa nitori itara wa fun un. A nilo lati fi ara balẹ kẹkọ lọdọ rẹ, ki a si fi imọ kun itara wa. Aijẹbẹ, awọn nkan ti a ni lọkan lati ṣe ni rere fun le yọri si idibajẹ ti ko ni lere lori fun wa. (Wo: Johanu 16:2)
  • Ṣiṣi ilẹkun aye wa fun idajọ Ọlọrun: O tun gbọdọ ye wa pe itara ti ko ni imọ Ọlọrun ninu le ko iya jẹ wa tabi awọn ti o sunmọ wa. Fun apẹẹrẹ, a ri ka ninu bible pe akoko kan wa ti Ọba Sọọlu gbiyanju lati pa awọn ara Gibioni run nitori itara rẹ fun ilẹ Isiraẹli. Ṣugbọn itara rẹ yi lodi si ifẹ Ọlọrun. Eyi si jẹ ki iyan ọdun mẹta mu ni ilẹ naa ni akoko ti Dafidi jẹ ọba. Ki iyan yi si ba le wa si opin, a ni lati pa ọkunrin meje lati idile Sọọlu, awọn ti ko mọwọ ti ko mẹsẹ. Lafikun, Ọba Dafidi naa ṣe aṣiṣe ni igbakan nitori itara ti ko ni imọ. Eyi si yọri si iku ọmọkunrin kan ti a n pe ni Uṣa. Nitorinaa, itara ti ko ni imọ le ko iya jẹ ọpọlọpọ, pẹlupẹlu awọn alaiṣẹ. Idi si ni yi ti a fi gbọdọ ṣọra ṣe ninu iṣẹ isin wa si Ọlọrun, ki a ma ba tipasẹ itara wa da wahala silẹ fun ara wa ati fun awọn miran pẹlu. (Wo: 2Samuẹli 6:1-19 & 21:1-14; 1Kironika 13&15)

EWU TI O SORỌ MỌ IMỌ TI KO NI ITARA
Nibakannaa, o lewu ki a ni imọ ifẹ Ọlọrun ki a si ma wa ni itara lati ṣiṣẹ tọ ọ. Pataki lara awọn ewu ti o sọrọ mọ eyi ni iwọnyi:

  • Aidagbasoke ninu ẹmi: Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ti o ba ni imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti ko si ni itara lati ṣe amulo rẹ ko le dagbasoke ninu ẹmi. Idi si ni pe ilana Ọlọrun ni pe awọn ti o ba n ṣe amulo imọ rẹ tabi ipese rẹ nikan ni o lẹtọ lati ri nkan gba si ni ọwọ rẹ. Awọn wọnyi nikan ni Ọlọrun yoo fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han si ni ọna ti o pọ. Ṣugbọn awọn ti ko ni itara lati mọ ọn tabi ifẹ rẹ si ko ni kuro loju kan. Idi si niyi ti a fi ri ọpọ ninu ijọ loni ti ko dagbasoke ninu nkan ti ẹmi tabi pọ si ni iwulo ninu ijọba Ọlọrun. Aye awọn miran ko tilẹ dabi pe wọn mọ Jesu rara. Idi si ni pe ko si itara ti o kojuosuwọn ninu wọn lati mọ ọn si. Boya awa naa ti wa ni ojukanna fun igba diẹ tabi fun ọpọ ọdun ninu ijọ wa. O yẹ ki a kiyesi itara wa, ki o ma ba wa jẹ pe awọn ọmọ inu wa ninu ẹmi ni yoo pada di olukọ fun wa. (Wo: Maaku 4:24-25; Heberu 5:11-14)
  • Iku ti ẹmi: Ewu miran ti o sọrọ mọ aifi itara kun imọ Ọlọrun ti a ni lo ni i ṣe pẹlu iku ti ẹmi. A ri ka ninu iwe Heberu pe awọn ti a ti la loju pẹlu imọ Ọlọrun, ti wọn si ti jẹgbadun didara rẹ, ti wọn ba kọ lati ma gbe igbesẹ itara lati dagbasoke wa labẹ ewu iku ti ẹmi ati iparun. Idi si ni pe ti a ko ba ma fi gbogbo igba tun itara wa fun Ọlọrun ṣe, o ṣeeṣe ki a ba ara wa ni akoko tabi igba ti ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ rẹ yoo fi ọkan wa silẹ, ti a o si pada sẹyin. A si ri awọn ti o wa ni ipo yi loni. Ko si nkan ti ẹ fẹ ba wọn sọ lati inu ọrọ Ọlọrun ti wọn ko i ti fẹ gbọ ri. Ṣugbọn nitori pe wọn sọ itara wọn nu, Eṣu ri aye wọ inu aye wọ lọ lati yi ọkan wọn pada lẹyin Jesu. Bi o si ti ṣe ri fun Judasi ni o ma n pada ri fun iru awọn eniyan bẹ. Nitorina, a nilo lati kiyesara, ki a si ri pe gbogbo igba ni itara wa fun Ọlọrun n pọ si. Aijẹbẹ, ‘Ewu n bẹ loko Longẹ’. (Wo: Heberu 6:1-8)
  • Ijiya alailere: Bibeli sọ wipe, “Nitori naa ẹni ti o ba mọ rere ṣe ti ko si ṣe e, ẹṣẹ ni fun un.” (Jemisi 4:17) O tun sọ wipe, “Ati ọmọ-ọdọ naa ti o mọ ifẹ Oluwa rẹ, ti ko si mura silẹ, ti ko si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ, oun ni a o naa pupọ.” (Luuku 12:47) Ki ni idi ti eniyan yoo fi mọ nkan ti o tọ lati ṣe ti ko si ni i ṣe? Ọkan lara rẹ ni aini itara fun rere ṣiṣe. Bi a si tun ṣe wa ri ninu bibeli, ara idi ti a ṣe sọ wa di atunbi, ti a wẹ wa mọ, ti a si ṣe wa yẹ ni ki a ba le jẹ onitara lati ṣe iṣẹ rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa lati ṣe. Ti a ko ba wa ma fi itara ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe, a je wipe a n ṣilẹkun silẹ fun ijiya tabi ibawi niyẹn nitoripe a n fi ipese ati amuyẹ rẹ ṣofo. Boya idi ti a ti ṣe padanu awọn ipese tabi anfaani kan ti Ọlọrun fun wa ni pe a ti ṣọ itara wa fun un nu. A nilo lati ronupiwada, ki a si gbadura si ki O sọ itara wa ji, ki a ba le bẹrẹ si ni fi tọkantọkan ṣe ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, nkan le buru si fun wa ju bi o ti ṣe wa bayi lọ. (Wo: Luuku 19:11-27; Efesu 2:10; Titu 2:14)

ỌRỌ IPARI
A nilo lati fi itara kun imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti a ni ti a ba fẹ ma fi gbogbo igba pọ si ni isesorere ati iwulo ninu ijọba rẹ. Aijẹbẹ, laipẹ, o ṣeeṣe ki a ba ara wa labẹ oniruuru ewu, pẹlupẹlu ewu iku nipa ti ẹmi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun tun wa ṣe ni gbogbo ibi ti a ba ku si niti imọ ati niti itara fun un ati fun ijọba rẹ. Amin.

IBEERE

  • Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe pataki to fun ijọ Ọlọrun?
  • Ki ni o ṣe iyebiye si ọ julọ ninu awọn nkan ti o kọ ninu ẹkọ bibeli yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE | ỌJỌRU 12, ṢẸRẸ 2022

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ITARA ATI IMỌ NI SINSIN ỌLỌRUN | AYỌKA: ROOMU 10:1-2 Read More »