O mu ṣiṣe olotitọ lọkunkundun | Pst. J.O. Lawal
Ọjọ: Sẹrẹ 09, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 36
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ọdun yi, ọdun 2022. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Mimọ ro ọ lagbara lati jẹ olotitọ ninu gbogbo iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe nkan ti a ṣe fun Ọlọrun nikan ni o jẹ ẹ logun; ọkan ti a fi ṣe ohunkohun ti a ba ṣe fun naa jẹ ẹ logun pẹlu. Nitorinaa, ere ti yoo ba fun wa ko ni da lori bi nkan ti a ṣe fun ti ṣe pọ to nikan ṣugbọn pẹlu lori bi a ṣe jẹ olotitọ si to ni ṣiṣe ohun na. Idi si ni yi ti o ko fi gbọdọ jẹ ki oju rẹ wa lara ṣiṣe eleyi tabi tọhun fun Ọlọrun nikan; dipo bẹẹ, jẹ ki o tun wa lori ṣiṣe ohunkohun ti o ba n ṣe fun pẹlu ọkan ti o ja fafa, ti o si tun jẹ olotitọ.
Ki ni idi ti a fi kọ ọrẹ Keeni silẹ? Idi ni pe ọkan rẹ ko dọgba pẹlu Ọlọrun. Lotitọ, ọpọ lo ti sọ pe idi ni pe ko mu ọrẹ ti o koju oṣuwọn wa fun Ọlọrun. Awọn miran si ti sọ pe idi ni pe ọrẹ rẹ ko ki i ṣe nkan ẹlẹjẹ. Ṣugbọn bibeli ko sọ ohunkohun to jọ mọ awọn nkan wọnyi fun wa. Ko sọ wipe Ọlọrun paṣẹ fun Keeni ati arakunrin rẹ Abẹli lori nkan ti wọn yoo mu wa fun Oun. Dipo eyi, o sọ fun wa pe awọn mejeji mu ọrẹ wa lati inu iṣẹ ọwọ wọn. Nitorina, o ni lati jẹ pe ọrẹ atọkanwa ni wọn mu wa fun un. (Wo: Jẹnẹsisi 4:3-5)
Ki a ma fọrọgun, bi o tilẹ jẹ pe awọn mejeji lo ṣe laala lati mu nkan wa fun Ọlọrun, Abẹli ati ọrẹ rẹ nikan ni Ọlọrun wo pẹlu ojurere; ko wo Keeni ati ọrẹ rẹ pẹlu ojurere. Nigba ti O si ri pe Keeni rẹwẹsi nitori eyi, O sọ fun kedere pe, “Ti iwọ ba n ṣe ohun ti o tọ, njẹ o ko ni jẹ ẹni itẹwọgba bi?” Nitorina, ọrọ yi ko fi taratara ni nkankan ṣẹ pẹlu ọrẹ rẹ bikoṣe pẹlu oun tikararẹ. O ti pẹ ti nkankan ko ti ṣe deede pẹlu ọkan rẹ. Ẹyi ni o si ba ọrẹ rẹ jẹ. Nigbati ti o si tun wa kọ lati gbọ ikilọ Ọlọrun, nkan naa ti o n yọ ọkan rẹ lẹnu papa wa sọ di apaniyan. (Wo: Jẹnẹsisi 4:6-8)
Nitorina, nkan ti Ọlọrun n wo kọja nkan ti a n ṣe fun un tabi ti a n fi fun un. O n wo ọkan wa pẹlu. Nkan ti O ba si ri ninu ọkan wa ni yoo sọ bọya yoo tẹwọgba nkan ti a n ṣẹ fun, ki O si tun pin wa lere lori rẹ tabi ko ni ṣe bẹẹ. Bi a tilẹ ti ṣe ri ninu bibeli, awọn igba wa ti O tilẹ ma n jẹ awọn eniyan niya lori pe wọn ko jẹ olotitọ si ninu iṣẹ iṣin wọn. Fun apẹẹrẹ, ni ọjọ kannaa, Nadabu ati Abihu, meji lara awọn ọmọkunri Aarọni, ni Ọlọrun ṣe idajọ iku fun nitoripe wọn lo ina ti ko tọna lati rubọ si. Lotitọ, wọn jade lati wa sin in ni. Ṣugbọn nikẹyinkẹyin nṣe ni wọn fi iku ṣe ifa jẹ nibi ti wọn ti n sin in dipo ki wọn gba oriyin ati ere lọwọ rẹ. (Wo: Lẹfitiku 10:1-3)
Ananaya ati Safira aya rẹ nkọ? Awọn mejeji ni Oluwa pa lọjọ kannaa nitori aiṣododo wọn ni fifi funni (Iṣe Apọsiteli 5:1-10). Nitorina, a nilo lati ma fi gbogbo igba mu iṣododo ninu iṣẹ isin wa si Ọlọrun ni ọkunkundun. Pọọlu, nigba ti o n sọrọ lori eyi, sọ wipe, “Oun kan naa ti o tọ fun iriju pẹlu, ni ki o jẹ oloootọ.” (1Kọrinnti 4:2) Njẹ o ri bẹyẹn? Ti a ba n sọrọ iṣẹ isin, iṣododo ṣe pataki; ko ṣe foju fo tabi foju rena.
Nitorina, bi o ṣe n lọ ninu ọdun yi, jẹ ki ododo jẹ akọmọna rẹ ninu gbogbo iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun. Eyi si ni yoo jẹ ki O lo iṣẹ iṣin naa lati mu ete rẹ ni rere ṣe ninu aye awọn eniyan. Lafikun, eyi yoo jẹ ki o gba oriyin ati ere lọwọ rẹ fun iṣẹ isin rẹ dipo ikọsilẹ tabi ibawi. Njẹ ki a kọ ọkan rẹ, ki a si tun fun ni okun lati jẹ olotitọ si ni gbogbo ọna ati ni gbogbo igba, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
O mu ṣiṣe olotitọ lọkunkundun | Pst. J.O. Lawal Read More »




