Ohun gbogbo wà ní àkọsílẹ̀ | Láti ọwọ́: Ọmọtọla Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 14, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 07

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ma a fi ojoojumọ gbe aye pẹlu afiyesi pe a o ṣe idajọ ọrọ rẹ ati iṣẹ ọwọ rẹ ni ọjọ kan, ki o ba a le fi ara rẹ jin lati ma a gbe igbe aye ti o buyi kun un. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ inu bibeli ti o sọ pe:

“Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.” (Málákì 3:16)

Ki ni eyi n sọ fun wa? Oun naa ni pe Ọlọrun n ṣe akọsilẹ ohun gbogbo ti a n ṣe. Gbogbo ọrọ wa, iṣe wa, ẹbọ tabi ifarada wa, adura wa ati iṣẹ isin wa ni O n ri, ti ko si le e gbagbe. Ọpọ ni o lero wipe niwọn igba ti awọn eniyan ko ti ri awọn nkan ti wọn n ṣe, ohun yowu ti wọn ba ṣe ko ja mọ nkankan. Ṣugbọn bibeli kọ wa pe Ọlọrun ri ohun gbogbo ati wipe yoo mu ohun gbogbo wa si abẹ idajọ.

Oníwàásù 12:14 sọ wipe, “Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.” Eyi ja si pe ati iṣẹ rere wa ati iṣẹ ti ko dara wa ni o wa ninu akọsilẹ niwaju Ọlọrun. Ko si nkankan ti oju rẹ foru.

Lafikun, Mátíù 12:36 sọ wipe, “Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.” Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo ọrọ ti a n sọ ni o wa ninu akọsilẹ. Nitorina, awọn onigbagbọ gbọdọ ṣọra ṣe pẹlu ọrọ, iwa ati ibaṣepọ wọn pẹlu awọn miran. Idi si ni pe a o mu wọn jiyin rẹ ni ọjọ kan.

Iroyin ayọ wa ni pe Ọlọrun n ṣe akọsilẹ iṣododo, adura, ififunni ati laala wa ninu ijọba rẹ naa pẹlu. Hébérù 6:10 sọ wipe, “Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀…” Nitorina, ti o ba n ti sin Ọlọrun lotitọ, ti o si dabi ẹni pe awọn eniyan ko ka ọ si, ma jẹ ki o su ọ. Ohun gbogbo ni o wa ninu akọsilẹ niwaju Ọlọrun. Yoo si pin gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ti o jẹ olododo lere ni asiko tirẹ.

Niwọn igba ti ohun gbogbo si wa ni akọsilẹ bi eyi, nṣe ni o yẹ ki a ma a gbe igbe aye iwa mimọ, ki a ma a sin Ọlọrun pẹlu ọkan ti o tọ, ki a si duro ṣinṣin gẹgẹ bi olododo. Ọlọrun ti o n ṣe akọsilẹ iṣẹ gbogbo ko ni ṣalai pin gbogbo awọn olododo lere, ki o si ṣe idajọ iṣẹ kọọkan ni ibamu pẹlu idajọ-ododo rẹ ti o peye.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ohun gbogbo wà ní àkọsílẹ̀ | Láti ọwọ́: Ọmọtọla Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 14, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 07 Read More »

Gbàdúrà fún orílẹ̀-èdè wa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okudu 07, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 06

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. O fun mi idunnu ti o ga lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Òkúdù 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun tẹsiwaju lati ma jẹ ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ lugbadi awọn ibi awọn ọjọ ikẹyin yi. Amin.

Ọkan lara awọn aṣẹ ti Ọlọrun pa fun awọn eniyan rẹ ni pe ki wọn ma a fi igba gbogbo gbadura fun alaafia ati iṣoriire ibikibi ti wọn ba n gbe. Ko ba wa jẹ pe ilu abinibi ni wọn wa tabi ile okere, niwọn igba ti o ba ti jẹ wipe ibẹ ni wọn n gbe, Ọlọrun fẹ ki wọn ma a gbadura fun-un. Ki ni idi? Idi ni pe iṣoriire ati alaafia ti wọn naa da le lori ni iwọn kan tabi omiran.

Fun apẹrẹ, eyi ni Ọlọrun sọ fun awọn Juu ti a mu lẹru lọ si ilẹ Babiloni ni asiko Ọba Nebukadinesari:

“Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.” (Jeremáyà 29:7)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe a ko awọn Juu wọnyi ni igbekun lọ si Babiloni lodi si ifẹ wọn, sibẹsibẹ Ọlọrun pa a lasẹ fun wọn lati wa alaafia ibẹ ati lati ma gbadura fun un. Ki ni idi? Idi ni pe odiwọn alaafia ati iṣoriire ti wọn yoo jẹgbadun ni ibẹ da lori bi ibẹ ba ṣe wa ni alaafia si ati bi o ba ṣe ṣoriire si.

Nibakana, ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu wa ko ṣe ma jẹ igbadun alaafia ati iṣoriire ti o ga ju eyi ti a n jẹ lọwọlọwọ yi ni pe orilẹ-ede wa ko wa ni ipo alaafia ati iṣoriire to bi o ti ṣe yẹ. Ti ko ba si ṣe pe Ọlọrun da si ọrọ wa, ti O si mojuto ohun gbogbo ti o n di alaafia ati iṣoriire orilẹ-ede naa lọwọ, ọpọ ninu wa ko ni kuro ni ipo ainilọsiwaju ati ibanujẹ titi lai.

Nitorina, ko to fun ọ lati ma a gbadura fun ara rẹ; o tun ṣe pataki ki o ma gbadura fun orilẹ-ede yi pẹlu. Adura rẹ fun orilẹ-ede naa ko si gbọdọ jẹ ẹkọọkan; dipo bẹẹ, o gbọdọ jẹ eyi ti iwọ yoo ma a gba ni gbogbo igba. Idi si ni pe ti orilẹ-ede naa ba a wa ni alaafia, ti o si tun n ṣoriire, iwọ naa yo jẹ igbadun alaafia ati iṣoriire rẹ.

Amọ ṣa o, ti o ba jẹ wipe o ya ọlẹ ni gbigbadura fun ara rẹ, bawo ni a ṣe le lero pe iwọ yoo ma gbadura fun orilẹ-ede naa? Tabi ti o ba jẹ wipe o ya amọtara-ẹni-nikan ninu igbe-aye adura gbigba rẹ tabi ti o jẹ wipe ọrọ alaafia ati iṣoriire ara tirẹ nikan ti o jẹ o logun ti o ba n gbadura, bawo ni a ṣe le lero pe ki o mu adura gbigba fun orilẹ-ede yi lọkunkundun?

Ni kukuru, ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa bayi, o si n sọ fun ọ pe ki o mu adura gbigba fun orilẹ-ede wa ni ọkunkundun, dipo ti o o fi tẹwọgba ainilọsiwaju ti o n fi kọ ọ lọrun tabi ti o o fi ma a fi igba gbogbo ronu bi iwọ yoo ṣe salọ si orilẹ-ede miran. Ranti pe awọn eniyan kan ni wọn sọ awọn orilẹ-ede ti o n ronu lati salọ di giga. Iwọ naa si le wa lara awọn ti yoo sọ orilẹ-ede wa di giga nipa adura pẹlu itara ti o ba n gba fun un. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati mu ọrọ yi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Gbàdúrà fún orílẹ̀-èdè wa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okudu 07, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 06 Read More »

Ọlọ́run tí a jogún | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 31, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 05

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi, eyi ti o jẹ ọsẹ akọkọ ninu oṣu Okudu 2026. Mo gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ jẹ olotitọ si i titi de opin, ki o ma ba a padanu ohun yowu ti o yẹ ki o jẹ ere rẹ fun sisin in, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe rẹ ninu bibeli, o ṣeeṣe ki awọn ti o sọ wipe awọn n sin Ọlọrun ma sin in tọkan-tọkan. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, wọn le padanu ọkan wọn tabi ki wọn padanu ere iṣẹ isin wọn. Gbogbo rẹ da lori irufẹ aiṣododo wọn tabi bi aiṣododo wọn ṣe tobi to ninu iṣẹ isin wọn si i.

Fun apẹrẹ, nkan ti a kọ sinu bibeli nipa ọba Juda kan niyi:

“ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Amasiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jehoaddani ti Jerusalemu. O si ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe pẹlu ọkàn pipé.” (2 Kíróníkà 25:1-2 (YOR)

Njẹ o ri bayẹn? Ọba Amasiah ṣe ohun ti o tọna niwaju Ọlọrun, ṣugbọn ko ki i ṣe pẹlu ọkan ti o pe. Lọna wo? Ni kukuru, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ ijọba rẹ ti o wa ninu bibeli, Amasiah bẹrẹ pẹlu igbọnran si Ọlọrun. O tilẹ gbọran si Ọlọrun nigba ti ko rọrun fun un lati ṣe bẹ ẹ. (Wo: 2 Kironika 25:1-12)

Amọ ṣa o, lẹyin igba ti o ti ṣẹgun awọn ara Edomu tan loju ogun, o ko awọn oriṣa wọn wa si ilẹ Juda, o si bẹrẹ si ni ṣin wọn. Ki lo fa ti o ṣe ṣe eyi? Ki ni o n ro gan an? Bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ naa, ki o to lọ ba awọn ara Edomu ja ni Ọlọrun ti ran wolii kan si lati sọ nkan ti o yẹ ki o ṣe ki o ba le ṣẹgun fun un. Nigba ti o si ṣe e, o ṣẹgun nitootọ. Ki wa lo fa ti o ṣe wa kọ ẹyin rẹ si Ọlọrun?

Yatọ si eyi, o yẹ ki ọpọlọ rẹ gan sọ fun pe yiyan awọn oriṣa Edomu gẹgẹ bi ọlọrun fun ara rẹ jẹ igbesẹ oponu patapata gba a. Idi si ni pe awọn oriṣa wọnyi ko le e gba awọn ara Edomu funralara wọn lọwọ rẹ. Ki wa lo fa ti o fi ro wipe awọn gan an ni ọlọrun ti o tọ fun un lati ma sin in?

Ni kukuru, ki a sọ otitọ, iṣoro Amasiah ni pe ko fi igba kankan ni ifihan otitọ nipa Ọlọrun, iyẹn Ọlọrun awọn baba nla rẹ. Fun ọkunrin yi, Ọlọrun yi ko kọja Ọlọrun ti o jogun lati ọwọ awọn baba nla rẹ. Nitorina, ko sin in nitoripe o gbagbọ ninu rẹ lotitọ. Dipo eyi, nṣe ni o n sin in nitoripe nkan ti awọn ti o tọ ọ dagba sọ fun pe ki o ma a ṣe niyẹn.

Ṣugbọn lẹyin igba ti o ti ṣegun awọn ara Edomu tan, o wa bẹrẹ si ni woye pe agbara oun ni o jẹ ki oun ṣegun wọn, ko si ki i ṣe Ọlọrun. Nitorina, o gba ninu ọkan rẹ pe o ti to asiko fun oun lati yan awọn ọlọrun ti oun funralara oun. Lati igba naa lọ, ẹwẹ, ni o ti bẹrẹ si ni ṣiṣe titi o fi yanju ara rẹ. (Wo: 2 Kíróníkà 25:14-28)

Ki wa ni koko itan yi? Oun naa ni pe a nilo lati mọ Ọlọrun lotitọ lati le e sin in tọkan-tọkan. Lotitọ, a le bi wa sinu idile Kiristiẹni. Iyẹn ko wa jasi pe a ti mọ Ọlọrun ati Jesu Kirisiti bi o ti ṣe yẹ ki a mọ wọn. Nkan ti a mọ nipa wọn kan le jẹ nkan ti a jogun lati ọdọ awọn obi wa tabi nkan ti awọn ti o wa ni ayika wa fi ṣọwọ si wa. Nibi ti eyi ba si ti ri bẹẹ, asiko kan le e de ninu eyi ti imọ ti a ni ko ni peye to lati jẹ ki a tẹsiwaju lati je olotitọ si Ọlọrun. A wa le bẹrẹ si ni ṣiwawu, ki a si ma a ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki a padanu ọkan wa tabi ohun yowu ti o yẹ ki o jẹ ere wa fun sisin in.

Nitorina, o nilo lati ri daju pe ijọsin Ọlọrun rẹ jẹ eyi ti o jẹyọ lati ara idaniloju ninu ọkan rẹ pe Ọlọrun ni nitootọ. O si tun nilo lati ri daju pe igbagbọ rẹ ninu Jesu Kirisiti Oluwa wa jẹ eyi ti o jẹyọ lati ara idaniloju ninu ọkan rẹ pe Oluwa ni nitootọ. Aijẹbẹ, nkan ti o n pe ni igbagbọ ninu rẹ le ma ju irọ lasan-lasan lọ. Adura mi wa ni pe eyi ko ni jẹ ipin rẹ, lẹyin-ọ-rẹyin. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ọlọ́run tí a jogún | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 31, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 05 Read More »

Ìlara le è gba ìṣàkóso | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 24, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 04

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati ifẹ jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o gbẹyin oṣu yi, oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fi okun fun ọ lati fi ara rẹ jin lẹkunrẹrẹ lati sin in, ki awọn ọmọ rẹ miran ba a le gba iwuri lati sin in pẹlu nipasẹ rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, a le fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ni ayika wa ni iwuri lati fi ara wọn jin lati sin in nipasẹ ododo ati ifarada wa ni ṣiṣe iṣẹ rẹ. Fun apẹrẹ, Pọọlu, ninu iwe rẹ si awọn ara Filipi, sọrọ nipa bi ọpọ eniyan Ọlọrun ṣe gba iwuri lati waasu iyinrere Jesu Kirisiti pẹlu igboya nipasẹ ifarajin ati ifarada tirẹ ni wiwaasu iyinrere naa debi wipe a tilẹ sọ sinu atimọle nitori rẹ. (Wo: Fílípì 1:12-14)

Nitorina, bi a ba fi ara wa jin fun sinsin Ọlọrun, a le ma a le sọ ọna ti o le gba wu awọn eniyan ti o wa ni ayika wa lori lati sin in. Mo gbọ nigba kan si nkan ti pasitọ kan ṣe nigba ti o gbọ pe pasitọ miran kan da nikan gbe gbogbo owo ti wọn fi ṣe iṣọji itagbangba kan. Ki wa ni o ṣe? Akọkọ, o mu owo ti o jọju kan lati fun pasitọ naa lati mọ riri nkan ti o ṣe ni gbigbe inawo iṣọji naa. Lẹyin eyi, o wa sọ fun pasitọ naa pe oun fun ni owo naa pẹlu ọkan adura pe ki Ọlọrun ran oun naa lọwọ lati ṣe nkan ti o farapẹ nkan ti ẹni naa ṣe lọjọkan.

Njẹ pasitọ ti o gbe inawo iṣoji yẹn wa mọ wipe nkan ti oun ṣe yoo wu ẹnikẹni lori ni ọna yi bi? Rara O! O kan ṣe nkan ti o ṣe nitoripe ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣe e. Nipa ṣiṣe e, ẹwẹ, elomiran gba iwuri lati sin Ọlọrun pẹlu ododo siwaju si i.

Amọ ṣa o, o tun wa ṣeeṣe fun ẹnikan lati ri nkan ti ẹlomiran n ṣe fun Ọlọrun, ki o si ma binu tabi ṣe ilara ẹni naa, dipo ti oun naa yoo fi gba iwuri lati sin Ọlọrun pẹlu ododo. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn adari ẹṣin Juu ṣe ilara Jesu nitori awọn nkan ti O n ṣe ninu ijọba Ọlọrun, dipo ti wọn yoo fi jẹ ki iṣẹ rẹ wu awọn naa lori lati sin Ọlọrun pẹlu otitọ funralara wọn. Nitorina, wọn pada pa a. (Wo: Mátíù 27:18)

Lafikun, a ri wipe awọn Juu ti o wa ni ibi kan ti a n pe ni Antioku ti Pisidia ṣe ilara Pọọlu ati Banaba nigba ti wọn ri nkan ti wọn n ṣe fun ijọba Ọlọrun ati bi awọn keferi ṣe n da wọn lohun. Ki ni idi ti wọn ṣe ṣe ilara wọn? Wọn ṣe ilara wọn nitoripe bi o tilẹ jẹ wipe awọn naa ni ọrọ Ọlọrun pẹlu wọn, wọn ko ma a polongo rẹ ni otitọ si awọn keferi. Dipo eyi, ni ọpọ igba, nṣe ni wọn n fi oju alaimọ ati ẹni ti ko lẹtọ si oore-ọfẹ Ọlọrun wo awọn keferi wọnyi.

Ṣugbọn nigba ti Pọọlu ati Banaba de ọdọ wọn, ti wọn bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti awọn kọ lati ṣe, ti wọn si ri ipa ti iṣẹ wọn n ko ninu aye awọn keferi, wọn bẹrẹ si ni ṣe ilara wọn, wọn n bu wọn, wọn si tun fẹnu tabuku iwaasu wọn. Nigbẹyin-gbẹyin, wọn le wọn kuro ni ibẹ nigba ti wọn ri wipe awọn ko le da iṣẹ rere ti Ọlọrun n tipasẹ wọn ṣe lọwọ duro. (Wo: Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 13:13-52)

Ki ni eyi n sọ fun wa? Oun naa ni pe ti a ko ba fi ara wọn jin lati sin Ọlọrun tabi ki a fi aaye gba awọn nkan rere ti awọn ti o wa ni ayika wa n ṣe fun ijọba rẹ lati wu awa naa lori lati sin in daradara, ibinu ati ilara le gba isakoso ọkan wa. Nibi ti eyi ba si ti ri bẹ, dipo ti Ọlọrun yoo fi ri wa lo bi O ti ṣe n lo awọn miran, Satani ni yoo ma a lo wa. Eyi yoo wa jẹ ki a ri wipe nṣe ni a n pa iṣẹ Ọlọrun ti o jẹ wipe awa ni o yẹ ki o ma a ṣe run. Irufẹ idajọ ti eyi yoo si mu wa sori wa le kọja afẹnusọ.

Nitorina, ti o ko ba fẹ ki ilara gba ọkan rẹ ati ki o sọ ọ di alaiwulo ninu ijọba Ọlọrun, ri daju pe o fi ara rẹ jin lati sin in ni ọnakọna ti o ba le gba a sin in. Ti o ba si ri awọn miran ti wọn n sin in dadaradar ju ẹ lọ, kẹkọ lara wọn ki iwọ naa ba a le bẹrẹ si ni ṣe daradara ju tatẹyin wa lọ ninu iṣẹ isin rẹ si i. Nipa ṣiṣe bayi, a o le fi oore-ọfẹ ti o ga si fun ọ lati ọdọ rẹ wa lati pọ si ni iwulo.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìlara le è gba ìṣàkóso | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 24, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 04 Read More »

Ọdún ìbádàpọ̀ míràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 17, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 03

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, iyẹn oṣu Ebibi 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ninu ọsẹ naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe mọ, a n ṣe ayẹyẹ ọdun kẹrinla ti a ti n pade ninu ilu yi gẹgẹ bi ijọ loni. Ni akọkọ, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti jẹ si wa, ti O ti ṣe fun wa, ti O ti ṣe ni aarin wa ati ti O ti ṣe nipasẹ wa ninu awọn ọdun wọnyi. Ki iyin jẹ ti orukọ rẹ ti o logo titi lailai.

Lafikun, mo tun fẹ dupẹ lọwọ gbogbo awa ti a ri ara wa gẹgẹ bi ojulowo ọmọ ijọ yi fun fifi aye gba Ọlọrun lati fi ọwọ tọ ọkan wa lati darapọ mọ ara wa ninu ibadapọ pẹlu rẹ, Mo si tun dupẹ lọwọ wa fun fifi aaye gba a lati tọ wa lati kọpa lọna ti o peye ninu ohun gbogbo ti o n mu ijọ naa tẹsiwaju. Adura ni pe ki Oluwa dardara tẹsiwaju lati ma a ṣiṣẹ ninu wa titi gbogbo ero rẹ si wa ni rere yoo fi wa si imuṣẹ ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun ibadapọ miran, mo fẹ gba wa niyanju lati fi ara wa jin siwaju si fun ọrọ rẹ, fun adura gbigba, fun ibadapọ pẹlu ara wa ati fun jijẹ ẹri didara Ọlọrun si wa fun awọn ti o wa ni ayika wa. Ki ni idi? Idi ni pe awọn nkan wọnyi ni awọn eniyan mimọ igbaani fi ara wọn jin fun. Nipa bi wọn si ṣe fi ara wọn jin fun awọn nkan wọnyi, Ọlọrun ri aaye lati gbe gbogbo wọn ro lati jẹ irinṣẹ ti o ga ni ọwọ rẹ ni yiyi aye ọpọ kaakiri agbaye pada. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 2:42-42 & 8;41)

Nitorina, niwọn igba ti awa naa fẹ ki Ọlọrun gbe ẹnikọọkan wa ro lati wulo gidigidi fun un ni fifi ọwọ kan aye ọpọ ni ayika wa, a wa gbọdọ fi ara wa jin fun ọrọ rẹ, adura gbigba, ibadapọ pẹlu ara wa ati ẹri jijẹ fun awọn ti o wa ni ayika wa ju tatẹyin wa lọ. Eyi, lotitọ, le ma rọrun, nitoripe ṣiṣe awọn nkan ti o n gbe eniyan ro ko ki i fi igba gbogbo wa pẹlu irọrun. Ṣugbọn ṣiṣe eyi yoo lere lori lọna ti o ga fun wa ati fun awọn ti o wa ni ayika wa.

Mo ki ọ kaabọ lẹkaansi sinu ọdun ibadapọ miran ninu oore-ọfẹ Ọlọrun. Mo si fẹ ki o foju sọna fun iriri didara Ọlọrun ti o ga ju tatẹyinwa lọ ninu aye rẹ ati ninu ijọ wa, bi gbogbo wa ṣe n fi ara wa jin siwaju si fun idari Ẹmi rẹ.

Kí Ọlọ́run kí ó bùkún fún ọ.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ọdún ìbádàpọ̀ míràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 17, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 03 Read More »

Ìkà àti ọ̀dájú ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 02

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun pa ọ mọ ninu ọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan nibikibi ti o ba ya si, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si awọn ara Tẹsalonika, sọ eyi:

“Ati ki a le gbà wa kuro lọwọ awọn eniyan buburu ati awọn ika eniyan: nitori pe kii ṣe gbogbo eniyan ni o gbagbọ́.” (2 Tẹsalóníkà 3:2)

Ki ni nkan ti a ni ki a gbadura fun? A ni ki a gbadura pe ki Ọlọrun gba wa lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan. Eniyan ja si pe a ni ninu aye yi awọn ika ati ọdaju eniyan. Irufẹ awọn wọnyi a ma a ṣetan lati gbe igbesẹ-ki-gbesẹ lati han ẹnikẹni ti o ba ṣẹ wọn leemọ, bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹṣẹ kankan ninu ọrọ yowu ti o wa nilẹ. Lafikun, irufẹ awọn wọnyi ko ki i ṣaba gbẹbẹ. Ti wọn ba ti pinnu lati ṣe ẹnikan ni ewu, o di dandan ki wọn ṣe bẹẹ gẹgẹ, bi eyi yoo tilẹ gba gbogbo asiko aye wọn tabi gbogbo owo wọn. Nitorina, ayafi ti Ọlọrun ba pa wa mọ kuro lọwọ wọn, a ko le bọ lọwọ iwa buburu wọn.

Fun apẹrẹ, ọkunrin kan ti a n pe ni Hamani ṣetan lati pa Mọdẹkai ati gbogbo awọn Juu ti o wa labẹ ijọba Ọba Ahasiwerusi nitoripe Mọdẹkai ri fin. Ṣugbọn ẹnikan ṣoṣo ni Mọdẹkai. Ki wa lo de ti Hamani fi fẹ pa gbogbo awọn Juu nitori tirẹ? Idi ni pe ika ati ọdaju eniyan ni. Ti Mọdẹkai ati awọn eniyan rẹ ko ba si lọ gbadura si Ọlọrun pe ki O da si ọrọ naa ni, ọpọlọpọ wọn ni ko ba padanu ẹmi wọn nitori iwa buburu Hamani. (Wo: Ésítà 3-9)

Ti Ọba Hẹrọdu nkọ? Ọkunrin yi ran awọn jagun-jagun rẹ lati lọ pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ọdun meji ati awọn ti ko to bẹẹ ti o wa ni Betilẹhẹmu nitoripe o ṣa fẹ pa Jesu nigba ti o wa ni ọmọ irinsẹ. Ki ni idi? Ko fẹ ki o dagba di ọba awọn Juu. Niwọn igba ti ko si wa mọ ọmọde naa ti a n pe ni Jesu, o ba kuku pinnu lati pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ti o wa ni Bẹtilẹhẹmu, nibi ti a ti bi Jesu, ti wa ni iwọn ọjọ ori rẹ. Ti Ọlọrun ko ba wa da si ọrọ naa ni, a ko ba ti pa Jesu ki o to di pe yoo tilẹ ni anfaani lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati ṣe. (Wo: Mátíù 2:1-18)

Ki ni koko ọrọ mi? Ohun naa ni pe awọn ika ati ọdaju eniyan bi Hamani ati Hẹrọdu si wa digbi ninu aye yi ati ni ayika wa. Satani si le lo wọn nigbakugba ati fun idi-ki-di lati kọlu wa. Ṣugbọn Ọlọrun le pa wa mọ kuro lọwọ wọn. Awa na, ẹwẹ, ko gbọdọ duro de igba ti eyi yowu ninu wọn yoo ma halẹ mọ wa ki a to kọ lati ma gbadura fun aabo Ọlọrun kuro lọwọ wọ. Aijẹbẹ, wọn le ti jẹ wa niya tan ki o to di pe a o ri aaye lati gbadura.

Nitorina, kọ bi a ṣe n gbadura lojoojumọ pe ki Ọlọrun ma pa ati iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ mọ ni gbogbo igba kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan ti o wa layika rẹ. Yoo si ri bẹ ẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìkà àti ọ̀dájú ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 02 Read More »

Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kaarun ọdun yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo pa ọ mọ, ki o ma ba a ṣe ohunkohun ti yoo ba a ninujẹ, ti yoo si jẹ ki O yi ọkan rẹ pada lori mumi awọn eto rẹ fun aye rẹ ṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o ṣeeṣe ki a mu inu Ọlọrun bajẹ. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki a ba a ninujẹ nipa bi a ṣe n gbe aye wa ati nipa iha ti a n kọ si ọrọ rẹ. Idi si ni pe O fẹran wa. Kiki awọn ti a ba fẹran, ti a si n kẹ, ni wọn le ba wa ninujẹ tabi mu ọkan wa poruru. Awọn ti a ko ba fẹran ko le ba wa ninujẹ, bi o ti wu ki iwuwasi wọn si wa buru to. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ ninu wa ni ko tilẹ ni fẹ fi aye gba ẹnikẹni ti a ko fẹran lati ṣe ohunkohun ti yoo mu wa karisọ.

Ṣugbọn ti ẹnikan ti a fẹran, ti o si tobi lọwọ wa, ba bẹrẹ si ni wu iwa aikanisi si wa, inu wa ko ni dun rara. Ti irufẹ ẹni bẹ ẹ ba si tun wa tẹsiwaju lati ma mu inu wa bajẹ lọna yi, a le yi ọkan wa pada lori rẹ, ki a si mu ifẹ ti a ni si wọn kuro lọkan wa. Lẹyin eyi, wọn ko tun ni le jẹ igbadun ibaṣepọ wọn pẹlu wa bi wọn ti ṣe ma n jẹ tẹlẹ mọ.

Nibakanna, nitoripe Ọlọrun fẹran wa, a le mu inu rẹ bajẹ. Ti a ba si wa fi mimu inu rẹ bajẹ ṣe aṣa, asiko naa le de ninu eyi ti yoo yi ọkan rẹ pada lori wa ati lori eto rẹ fun wa. Bawo wa ni a ko ṣe ni fi aye wa ṣofo tabi pa aye wa run, ti eyi ba lọ waye?

Fun apẹrẹ, a sọ eyi nipa idi ti Ọlọrun fi yọ Ọba Sọọlu kuro ni ipo rẹ gẹgẹ bi ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli:

“Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe, Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.” (1 Sámúẹ́lì 15:10-11)

Njẹ o ri bayẹn? Inu Ọlọrun bajẹ nitoripe O fi Sọọlu ṣe ọba lori Isiraẹli. Ki si ni idi? Idi ni pe ọkunrin naa sọ di aṣa lati ma tapa si aṣẹ rẹ. Nkan ti o tun wa buru ju iyẹn lọ ni pe ko tilẹ ni ẹmi ironupiwada rara. O ni i lara lati fi tọkan-tọkan roninupiwada ti a ba ba a wi tabi sọ pe ki o tun iwa rẹ ṣe. Nitorina, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, O si fi ẹlomiran rọpo rẹ.

Njẹ Sọọlu wa kaanu lori ọrọ yi bi, nigba ti Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, ki O si wa oju rẹ fun aanu? Rara o, ko ṣe bẹ ẹ. Nṣe ni o kan n ba iṣe rẹ lọ gẹgẹ bi ọba, bi igba ti ko si nkankan ti o ṣẹlẹ. Nitorina, o pada pa aye ara rẹ fun, o si sọ ohun rere yowu ti o ṣe fun orilẹ-ede Isiraẹli gẹgẹ bi ọba di asan.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ naa, Samuẹli ti ko ki i ṣe oun ni a rọ loye ko dẹkun lati ma kẹdun niwaju Ọlọrun fun ọkunrin yi. Lotitọ, nigba ti o tilẹ de ikorita kan, Ọlọrun ni lati sọ fun pe ki o ye kẹdun lori ọrọ Sọọlu mọ, ki o si lọ ta ororo si elomiran lori rọpo rẹ (1 Sámúẹ́lì 16:1). Ki wa lo fa ti o fi n kẹdun fun Sọọlu bi iyẹn? Idi ni pe o mọ babara ki a mu inu Ọlọrun bajẹ ati pataki ki a ronupiwada lotitọ ti a ba ti ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, a le pada fi aye wa ati oore-ọfẹ yowu ti a le ti ri gba lọwọ Ọlọrun ṣofo.

Eyi si wa ni idi ti a fi kilọ fun awa naa ninu Iwe Mimọ ni ọna yi:

“Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.” (Éfésù 4:30)

Njẹ o ri bayẹn? A gbọdọ ṣo ara wa ki a ma ba a fi ara wa jin fun ṣiṣe ohunkohun ti o le ba Ẹmi Ọlọrun ti O n gbe inu wa ninujẹ. Ti a ba si ti n ba ninu jẹ ni ọna kankan, nṣe ni ki a ronupiwada, ki a si wa oju rẹ fun aforiji ni kiakia. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi Ọba Sọọlu, awa naa le pada fi gbogbo ifẹ ati oore-ọfẹ ti O ti tu si ori wa lẹkunrẹrẹ ṣofo. Njẹ ki eyi ma jẹ ipin wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní oṣù Èbìbí 2026 alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01 Read More »

Ṣùgbọ́n adẹ́tẹ̀ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Èbìbí 2026 papọ. Adura mi ni pe ki Ọlọrun, ni kiakia, ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n mu akude ba didara rẹ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Mo gba adura yi fun ọ nitoripe a ma n ri awọn igba ti o jẹ wipe idi ti awọn nkan rere ti Ọlọrun n ṣe ninu aye awọn eniyan rẹ ko ki i fi ja mọ nkankan ni pe awọn nkan kan ninu aye wọn n mu akude ba wọn. Ti a ko ba si mojuto awọn nkan wọnyi, ko si nkan rere kankan ti O le ṣe fun wọn ti yoo fun wọn ni itẹlọrun ati isinmi ni aye.

Fun apẹrẹ, a ko eyi sinu bibeli nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Naamani:

“NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.” (2 Àwọn Ọba 5:1)

Ta ni o mu Naamani di ẹni nla, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? Ọlọrun ni. Oun ni O sọ di ẹni ti gbogbo eniyan ni orilẹ-ede rẹ, pẹlupẹlu ọba rẹ, ka si ẹni pataki ati ẹni-ọwọ. Ṣugbọn pẹlu gbogbo awọn nkan ti Ọlọrun ṣe fun-un wọnyi, ko ki ṣe ẹnikan ti inu rẹ dun, ti o si tun ni balẹ ọkan tan yanyan. Ki ni idi? Adẹtẹ ni. Eyi jasi pe, o jẹ ẹnikan ti wọn yo pada ya sọtọ kuro lọdọ gbogbo awọn ti o fẹran rẹ, ti yoo si wa ma a da gbe. Aijẹbẹ, wọn le ko ẹtẹ rẹ.

Ki wa ni titobi rẹ yoo ja mọ? Ki ni ọrọ rẹ yoo ja mọ? Ki si ni gbogbo awọn iṣẹ akikanju ti Ọlọrun ti tipasẹ rẹ ṣe yoo ja mọ? Gbogbo awọn nkan wọnyi ni ẹtẹ rẹ yoo pada sọ di asan. Ẹtẹ rẹ ko ni jẹ ki o jẹ igbadun wọn lẹkunrẹrẹ tabi fun igba pipẹ. Ero lori eyi nikan gan an ro lati sọ di onibinujẹ ẹniyan.

Awa dupẹ pe Ọlọrun lo ọdọmọbirin ẹru kan ti a mu wa si ile rẹ lati ilẹ Isiraẹli lati ran an lọwọ lati ri iwosan rẹ gba. Ọdọmọbinrin yi sọ fun un nipa Wolii Eliṣa ati bi Ọlọrun ṣe le lo o lati wo ẹtẹ rẹ san. Nigba ti o si lọ si ọdọ eniyan Ọlọrun yi, a wo ẹtẹ rẹ san nitootọ. Nitorina, lati ọjọ naa lọ, o bẹrẹ si ni sin Ọlọrun, o si tun bẹrẹ si ni jẹ igbadun ohun rere gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun pẹlu itẹlọrun ati laisi ibẹru.

Wayi o, Ọlọrun kanna ti O mojuto ẹtẹ Naamani le mojuto ohunkohun ti o n di ọ lọwọ lati jẹ igbadun didara rẹ ninu aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Nkan ti o kan nilo lati ṣe ni ki o ke pe e fun iranlọwọ. Bi o si ti n ṣe eyi, gbogbo ‘Ṣugbọn’ ti o n sọ didara rẹ di alainitunmọ ninu aye rẹ ni a o mojuto. Iwọ yoo si wa bẹrẹ si ni jẹ igbadun awọn ibukun rẹ pẹlu itẹlọrun.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ṣùgbọ́n adẹ́tẹ̀ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 52 Read More »

Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2026. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o lugbadi idajọ rẹ lori ọkankan ninu awọn ti o wa ninu aye rẹ tabi ni ayika rẹ. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe ko ki i ṣe gbogbo igba ti awọn eniyan ba ni iriri idajọ Ọlọrun naa ni o jẹ nitoripe awọn funrawọn buru ni. Igba miran wa ti awọn eniyan a ma a ni iriri idajọ Ọlọrun nitoripe wọn kuna lati lo aṣẹ wọn lati ṣe idajọ awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn. Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ eyi fun Samuẹli nipa alufa Eli:

“Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.” (1 Sámúẹ́lì 3:13)

Ki ni idi ti Ọlọrun ṣẹ fẹ ṣe idajọ idile Eli? Ṣe nitoripe ọkunrin naa buru ni? O ti o! Abi ṣe nitoripe awọn ọmọ rẹ kan buru ni? O ti o! Idi ti Ọlọrun fi fẹ ṣe idajọ idile rẹ ni pe o kuna lati mu awọn ọmọ rẹ so, bi o tilẹ jẹ wipe o mọ nipa ẹṣẹ wọn daadaa.

Ti Eli ko ba mọ nipa ẹṣẹ awọn ọmọ rẹ ni, Ọlọrun ko ma ba ti da lẹbi nitori wọn. Lafikun, ti Eli ko ba wa ni ipo ẹni ti o le da awọn ọmọ rẹ lẹkun ni, ki wọn ma ba a le ma ṣẹ si Ọlọrun bi o ti ṣe wu wọn, ko ba ma ti da a lẹbi nitori wọn. Ṣugbọn yatọ si pe o mọ nipa ẹsẹ wọn, o tun wa ni ipo lati da wọn lẹjọ ati lẹkun. Sibẹsibẹ, o kuna lati ṣe eyi. Nitorina, Ọlọrun sọ fun pe Oun yoo ṣe idajọ idile rẹ fun ẹṣẹ awọn ọmọkunrin naa.

Njẹ ki wa ni idi ti Ọlọrun fi kọkọ sọ fun un nipa idajọ rẹ ti o n bọ ṣaju asiko idajọ naa? Idi ni ki o ba a le ṣe ohun ti o tọ pẹlu ikanju. Ṣe o wa ṣe ohun ti o tọ? Rara o, ko ṣe e. Dipo eyi, esi ti o fọ ni pe aaye pọ fun Ọlọrun lati ṣe ohun yowu ti o ba tọ loju rẹ lori ọrọ naa. Eyi jasi pe, ni titiẹ, ko ṣetan lati tun yọ ara rẹ lẹnu lori nkan ti awọn ọmọkunrin rẹ n ṣe mọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 3:18)

Ki wa ni eyi n kọ wa, ki a ma fọrọgun? Oun naa ni pe ti Ọlọrun ba fi awọn eniyan si abẹ iṣakoso wa, ko reti pe ki a fi aye gba wọn lati ma a ṣe bi o ba ṣe wu wọn. Dipo eyi, nkan ti O n reti ni pe ki a ma a lo aṣẹ wa lati fi wọn si aaye wọn, ti wọn ba n ṣe radarada. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma da ẹṣẹ Eli. Ti eyi ba si ri bẹ, igbakugba ti Ọlọrun ba da si ọrọ naa lati ṣe idajọ iwa ika ti a kọ lati ṣe idajọ rẹ, o di dandan ki awa naa kopa ninu idajọ naa, ayafi ti a ba ṣaanu fun wa. Ta wa ni o mọ ọna ti Ọlọrun yoo gba ṣe idajọ?

Nitorina, ma ṣe da bi Eli ti o kọ lati ṣiṣẹ lori ikilọ Ọlọrun lati ṣe idajọ awọn ọmọ rẹ nitoripe radarada wọn su u. Dipo eyi, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni lo aṣẹ rẹ lati fi gbogbo nkan si aaye wọn nibikibi ti o ba ti ni aṣẹ lati ṣe bẹ ẹ. Nipa bayi, iwọ yoo le pa ara rẹ mọ lati ma kopa ninu idajọ awọn alaigbọran.

Siwaju si, ma ṣe jẹ ki inu bi ọ nigba ti awọn ti o ni aṣẹ lori rẹ ko ba fi aaye gba ọ lati ma ṣe radarada labẹ isakoso wọn. Idi si ni pe ifẹ Ọlọrun ni wọn nṣe. Yatọ si iyẹn, nipa bi wọn ko ṣe fi aaye gba ọ lati ma ṣiwawu labẹ isakoso wọn, nṣe ni wọn n pa ọ mọ kuro labẹ idajọ Ọlọrun. Nitorina, nṣe ni o yẹ ki o ma dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe jẹ adari ti o mọ ojuṣe wọn. Aijẹbẹ, o le ṣe ara rẹ leṣe nipasẹ idajọ Ọlọrun, ti o ba kọ lati gba ibawi. Mo gbadura pe iru eyi ko ni jẹ ipin rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51 Read More »

Ayé ò dọ́gba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 12, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 50

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodwiọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Adura mi ni pe ki Ọlọrun lo gbogbo ipokipo ti o le ba aye rẹ, bi o ti wu ki o buro loju to, lati mu ete rere rẹ ṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ki ni idi ti mo fi gba adura yi fun ọ? Idi ni pe mo mọ pe aye ko dọgba. Wo, fun apẹrẹ, nkan ti Solomọni sọ nipa eyi:

“Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11)

Njẹ o ri bayẹn? Aye ko kan ni funralara rẹ ṣiṣẹ fun ire ẹnikẹni, bi o ti wu ki awọn amuyẹ ẹni naa ga to. Idi ni yi ti a fi ni ọpọ eniyan ti wọn ni awọn amuyẹ ti o ga, ti wọn si tun n gbe igbe aye ailojutu. Awọn amuyẹ wcn ti o yẹ ki o gbe wọn leke laye ko wulo fun wọn lọna ti o nitunmọ kankan. Awọn amuyẹ wọnyi tilẹ tun le ma a ṣiṣẹ lodi si wọn.

Ki ni idi? Idi ni pe aye ko dọgba. Aye ko kan ni fun ọ ni aṣeyọri tabi ibalẹ-ọkan nitori awọn amuyẹ, ibaṣepọ tabi iṣẹ karakara rẹ. Nṣe ni o ni lati wa ni ibi ti o tọ, ni asiko ti ọ tọ, ki o si ma ṣe ohun ti tọ. Aijẹbẹ, gbogbo amuyẹ, ọgbọn, ẹkọ ati anfaani ti o ni le pada ja si pabo.

Bawo wa ni o ṣe le fi ara rẹ si ibi ti o tọ, ni asiko ti o tọ, ki o si tun ma ṣe ohun ti o tọ pẹlu nibẹ? Nipa fifa ara rẹ le ẹni ti o ni aye lọwọ ni. Ti o ba fa ara rẹ le ẹni ti o ni aye lọwọ, O le kọ ni ohun ti o dara julọ fun ọ, ki O si tun dari rẹ ni ọna ti o yẹ ki o tọ. (Wo: Àìsáyà 48:17)

Amọ ṣe iwọ yoo ṣe eyi bi? Ṣe iwọ yoo fa aye rẹ le Ọlọrun, ẹni ti o ni aye, lọwọ, ki O ba a le dari rẹ si ọna ti o yẹ ki o tọ laye, ki O si fi idi rẹ mulẹ ninu ododo, alaafia ati iṣerere? Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe aye ko ṣe ọ daada, ko ni le da ọ duro lati jẹ ẹni ti o yẹ ki o jẹ lorilẹ aye.

Ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe aye ko ṣe daada si Josefu, o si papa jẹ ẹni to yẹ ki o jẹ laye. Idi si ni pe o fa ara rẹ le Ọlọrun lọwọ. Nitorina, ma ṣaroye mọ pe aye ko ṣe ọ daada. Nṣe ni ko mura lati dojukọ aye lọna yowu ti o ba gba yọ si ọ, irufẹ ọda ti o le fi kun ara rẹ. Bẹẹni, o nilo lati ṣẹgun ninu aye, bi o ti wu ki nkan ma ṣe deede si ọ to. Ọna kan ṣoṣo lati ṣe eyi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni ki o fa ara rẹ le Ọlọrun lọwọ. Nitorina, fa ara rẹ lọwọ. Iwọ yoo si pada duro gẹgẹ bi aṣẹgun lẹyin-ọ-rẹyin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ayé ò dọ́gba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 12, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 50 Read More »