Ibadọrẹ pẹlu aye | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 47
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ jẹ ki ìfẹ́ rẹ ninu ọkan rẹ ma jo bi ina, ki o ba a le jẹ olotitọ si titi de opin. Amin.
Bi a ti ṣe n kojú ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ki ọ nilọ pẹlu awọn ọrọ Jemisi yi ti o sọ pe, “Ẹyin pansaga ọkunrin, ati pansaga obinrin, ẹ kọ mọ pe ibarẹ aye iṣọta Ọlọrun ni? Nitori naa ẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aye di ọta Ọlọrun.” (Jákọ́bù 4:4) Ki ni koko nkan ti Jemisi n sọ nibiyi? Oun naa ni pe ko si bi a ṣe le mu Ọlọrun ni ọrẹ wa, ki a si tun nifẹ aye pẹlu. Niwọn igba ti a ba ti le mu aye yi ni ọrẹ wa, a ti mu Ọlọrun ni ọta wa niyẹn. Ọna ti eyi yoo wa gba pa wa lara ni ko ki i ṣe ohun ti ẹnikẹni le e sọ. Ṣugbọn o di dandan ki o pa wa lara.
Wayi o, o wa ṣeni laanu pe ọpọ ti a n pe ni ọmọ Ọlọrun, ti awọn naa si n sọ wipe awọn nifẹ rẹ, ni wọn si tun wa ninu ifẹ pẹlu awọn nkan ti aye yi pẹlu. Wọn si tun n fẹ maa sọrọ ati mura bi awọn ti aye yi. Wọn si n fẹ lati ma ṣe ariya gẹgẹ bi wọn ti n ṣe ariya. Wọn si tun wa ninu ifẹ pẹlu awọn orin ati sinima wọn. Bawo gan ni wọn ṣe wa fẹ sọ wipe awọn si fẹran Ọlọrun nitootọ? Tabi bawo ni wọn ṣe fẹ sọ wipe awọn nkan ti aye yi ti awọn dirọ mọ ninu ifẹ ko pa ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun lara? Kiki ọpurọ eniyan ni yoo sọ eyi.
Wa ma ṣi mi gbọ. Mi o sọ wipe gbogbo nkan ti awọn ti aye yi n ṣe ni ko dara. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ nkan ti awọn ti o wa laye yi n ṣe ni o tọna, ti o si dara fun awọn ọmọ Ọlọrun pẹlu ati ti awọn ọmọ Ọlọrun le kẹkọ lara wọn. Ṣugbọn awọn nkan kan naa tun wa ti awọn ti aye yi ma n ṣe lati ba aye ara wọn ati ti awọn miran jẹ. Ọmọ Ọlọrun ṣi gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan wọnyi, ki o si ya ara rẹ ya wọn. Aijẹbẹ, bi o ti wu ki o sọ wipe oun fẹran Ọlọrun to, idibajẹ yoo wọnu aye rẹ, a o si sọ di ọta Ọlọrun.
Ranti awọn ọmọbinrin Lọti. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn kuro ni Sodom gẹgẹ bi wundia ninu agọ ara wọn, otitọ ibẹ ni wipe wọn ko ki i ṣe wundia ninu ọkan wọn. Ki ni idi? Idi ni wipe awọn nkan ti wọn ri ati ti wọn gbọ ni Sodomu fi idibajẹ sinu ọkan wọn. Ki a tilẹ sọ otitọ, o ṣeeṣe ki wọn ti ṣe gbogbo nkan ti wọn n ri ati ti wọn n gbọ ni Sodomu ninu ọkan wọn ki wọn to fi ibẹ silẹ. Nitorina, nigba ti o to asiko kan, ti wọn ko si le mu ara wọn duro mọ, wọn rọ baba wọn lọti yo, wọn si tun ba a sun. O ma ṣe o! (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 19)
Nibakanna, a le ro wipe awọn nkan ti a n ri ati ti a n gbọ nipasẹ ibadọrẹ wa pẹlu aye ko pa wa lara. Ṣugbọn nṣe ni a kan n parọ tan ara wa jẹ. Ko si bi a o ṣe ba aye dọrẹ ti idibajẹ inu rẹ ko ni wọ inu aye wa. Ti o ba si ti wọ inu aye wa, awa naa le ṣe bi awọn ọmọbinrin Lọti ti ṣe. A le ṣe aṣemaṣe.
Idi si wa niyi ti ọrọ Ọlọrun fi ki wa nilọ pe ki a yago fun ibadọrẹ pẹlu aye. Yoo kan sọ wa di ọta Ọlọrun ni. Ti ba si ti wa sọ wa di ọta Ọlọrun, ki ni yoo ṣẹlẹ pẹlu ireti wa ninu ijọba ayeraye rẹ? O le yọ bọrọ kuro lọwọ wa. Mo gbadura pe ireti wa ninu ijọba Ọlọrun ko ni lailai yọ jabọ kuro lọwọ wa. Amọ awa naa gbọ ṣọ ara wa.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)





