Tí o bá fẹ́ èrè tí ó suwọ̀n ju tàtẹ̀yìnwá lọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 12, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 37
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Sẹrẹ 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun dari rẹ nipasẹ Ẹmi rẹ lati gbe gbogbo igbesẹ ti o tọ fun ọ lati tayọ ni gbogbo ọna rẹ ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, ni ibẹrẹ ọdun bi eyi, nkan ti o wopọ ni ki awọn eniyan ma pongbẹ lati gbe igbe aye ti o suwọn si ati lati ri ere ti o suwọn ju ti atẹyinwa lọ lori awọn akitiyan wọn. Ko si si nkan ti o buru ninu eyi. Amọ ṣa o, pe a n pongbẹ lati gbe igbe aye ti o suwọn si ko to fun wa lati gbe igbe aye ti o suwọn si. Nibakanna, pe a n pongbẹ lati ri ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ laye ko to fun wa lati ri ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ. Ti a ko ba ma a ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki a gbe igbe aye ti o suwọn si ati ti yoo jẹ ki a ri ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ lori awọn akitiyan wa lọna ti o peye, a ko ni gbe igbe aye ti o suwọn si tabi ri ere ti o suwọn si.
Bibeli sọ wipe, “Ki a ma ṣe tan yin jẹ; a ko le gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan ba funrugbin, ohun ni yoo si ka.” (Gàlátíà 6:7) Ki ni eyi tunmọ si? Nkan ti o tunmọ si ni pe Ọlọrun ti fi ofin kan kalẹ ti o sọ wipe ohun ti eniyan ba gbin laye yi ni yoo ka. Nitorina, lakọkọ, o ko le kore ohun ti o ko ba gbin. Ekeji, o ko le yi ikore ohun ti o ba ti gbin pada – ohun ti o ba gbin naa ni o o ka.
Nitorina, ti o ba fẹ gbe igbe aye ti o suwọn si, ti o si tun fẹ je ere ti o suwọn si lori awọn akitiyan rẹ lọdun yi, ibere akọkọ ti o gbọdọ bere lọwọ ara rẹ ni pe, “Njẹ mo n gbin ohunkohun rara ti o le jẹ ki n gbe igbe aye ti o suwọn si ati ti o le jẹ ki n jere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ?” Ti o ko ba gbin nkankan sinu aye yi, ko yẹ ki o reti ikore kankan lori ohun ti o ko gbin. Kiki awọn ti o ba n gbin nkan ni o ni anfaani lati ma foju sọna fun ikore nkan ti wọn n gbin.
Ibere keji ti o nilo lati bere lọwọ ara rẹ ni pe, “Irufẹ irugbin wo ni mo n gbin?” Bi mo ti ṣe sọ siwaju, o ko le yi ikore irugbin yowu ti o ba ti gbin pada. Nkan ti o ba gbin naa ni iwọ yoo ka. Nitorina, ti o ba fẹ igbe aye ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ, ti o si tun fe ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ lọdun yi, o ṣeeṣe ki o nilo lati parọ irugbin ti o n fun. Fun apẹrẹ, ti o ba jẹ pe irugbin ti ibẹru, imẹlẹ, anikanjọpọn, ẹtanu, ikunsinu tabi ọrọ buburu ti fi idibajẹ si ni o n fun, o gbọdọ parọ rẹ si irugbọin igbagbọ, ifẹ, iṣẹ-aṣekara, iṣoore, adura gbigba ati ọrọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, ko si bi o ti ṣe tiraka to lọdun yi, o ko le gbe igbe aye ti o suwọn si tabi jẹ ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ. Dipo bẹẹ, o ṣeese ki nkan tun wa buru si fun ọ.
Siwaju si, bi o tilẹ wa jẹ wipe irugbin igbagbọ, ifẹ, iṣẹ-aṣekara, iṣoore, adura gbigba ati ọrọ Ọlọrun ni o n fun, o tun nilo lati fun ọpọlọpọ awọn irugbin yi si, ki o ba a le ni ikore wọn lọna ti o pọ si lati ara igbe aye ti suwọn si ati ere ti o suwọn si. Ranti pe nkan ti o ba gbin naa ni o o ka. Lotitọ, Ọlọrun le fun ọ ni ikore irugbin ti o gbin ni ilọpo-ilọpo lọna ti o ga. Amọ ṣa o, nkan ti o ba gbin nikan naa ni O le sọ di ilọpo fun ọ, ko si ṣe eyi ti o ko ba gbin. Nitorina, ti o ba jẹ ọgọrun irugbin ni o fun, ọgọrun irugbin yi naa ni yoo sọ di ilọpo-ilọpo fun ọ. Ti o ba si jẹ ẹgbẹrun irugbin ni o fun, ẹgbẹrun kan yi naa ni yoo sọ di ilọpo-ilọpo fun ọ. Ko si ojuṣaaju pẹlu rẹ.
Nitorina, ti o ba n fẹ lati ni iriri iṣorire ati ijẹgbadun ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ ninu ọdun yi, ṣetan lati fun irugbin rere ti o pọ ju tatẹyinwa lọ. Bi o si ti ṣe n ṣe eyi, mo gbadura pe ki Ọlọrun sọ ere ilakaka rẹ di ilọpo-ilọpo fun ọ, ki O si tun fun ọ ni isinmi ni gbogbo ayika rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)




