Ariwo irọ́ | Pst. J.O. Lawal | Ògún 7, 2022 | Vol. 11, No. 14
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu inu didun ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu yi, oṣu Ògún 2020. Adura mi si ni pe ki a fun ọ ni okun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati yi pada kuro ninu ohunkohun ti ko wa ni ibamu pẹlu igbe aye tuntun ti a pe ọ lati gbe ninu Kirisiti Jesu. Amin.
Ninu lẹta Pọọlu keji si Timoti, o sọ eyi fun: “Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni edidi yi wipe, Oluwa mọ awọn ti iṣe tirẹ. Ati ki olukuluku ẹniti n pe orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.” (2Timoti 2:19) Kini awọn koko ti o jẹ jade ninu ọrọ iyanju yi? Akọkọ ni pe otitọ Ọlọrun ko ki i yi pada rara. Bakan naa ni yoo ma wa, bi o ti wu ki igba tabi ibi ti a wa ri. Nitorina, nkan ti Ọlọrun sọ nipa ododo ko ni lailai yi pada. Nkan ti O si tun sọ nipa ẹṣẹ naa ko ni lailai yi pada. O wa ku si ọwọ wa lati yan lati duro lori ọrọ rẹ nipa awọn nkan wọnyi tabi lati tẹle ero ti ara wa.
Koko ekeji ti Pọọlu fẹ ki a di mu ni pe Ọlọrun mọ awọn ti o jẹ tirẹ ati awọn ti ko jẹ tirẹ daradara. Ko si igba ti ko le ya awọn tirẹ sọtọ laarin awọn ọpọ eniyan. Ranti pe ko ṣoro fun rara lati ya Noa ati idile rẹ sọtọ kuro laarin awọn ara aye igba tirẹ. Ko si tun ṣoro fun lati ya Lọọti ati idile rẹ sọtọ kuro laarin ilu Sodomu ati Gomora. Bẹẹ si ni, ko ṣoro fun lati ya ẹgbẹrun meje eniyan ti o jẹ tirẹ sọtọ fun ara rẹ ni akoko ti Ọba buruku ni, Ahabu, wa lori itẹ, bi o tilẹ jẹ pe gbogbo ilẹ naa ni ibọrisa ti gba kan ni igba naa. (Wo: Jẹnẹsisi 6; Jẹnẹsis 19; 1Awọn Ọba 19)
Nitorina, ko ki i ṣe iṣoro ni fun lati mọ awọn ti o jẹ tirẹ ni orilẹ-ede yi, bi o tilẹ jẹ wipe iye wa ti kọja igba miliọnu eniyan. Ti ko ba wa jẹ iṣoro fun Ọlọrun lati mọ eyi, o yẹ ki o mọ pe ko ki i ṣe iṣoro ni fun rara lati mọ iye awọn ti o jẹ tirẹ ninu ilu yi ati ninu ijọ yi. Ibere ti o kan yẹ ki a bere ni eyi: Njẹ Ọlọrun ri ọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ ninu ilu yi ati ninu ijọ yi? Njẹ iwọ gan tilẹ mọ ara rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ? Ọrọ yi si kọja ki o ma ṣe tokíní-tokéjì. Ti o ko ba ti mọ, a jẹ wipe o ko mọ naa niyẹn.
Ki a ma fọrọgun, Ọlọrun mọ pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn n pe ara wọn ni Kirisitiẹni tabi ti wọn n lọ fun ipade ni sọọsi tabi ti wọn n fi ede fọ tabi ti wọn n sọ tẹlẹ tabi ti wọn n ṣiṣẹ iyanu naa ni wọn jẹ tirẹ. Jesu fi igba kan sọ fun awọn ti o wa gbọ iwaasu rẹ pe: “Ki iṣe gbogbo ẹniti npe mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣẹ ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun. Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi le awọn ẹmi eṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigbana li emi o si wi fun wọn pe Emi ko mọ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹṣẹ.” (Matiu 7:21-23)
Njẹ o ri bayi? Ọpọ ti o n lọ si ipade sọọsi, ti o n jẹ orukọ ti a mu lati inu bibeli tabi ti o n ṣe oniruuru iṣẹ ni orukọ Jesu ni yoo ba ara wọn ka àánú nigba ti Oluwa wa ba de. Idi si ni pe ko mọ wọn gẹgẹ bi eniyan rẹ. Ki si ni idi? Idi naa ni pe wọn ko fi ara wọn jin fun ifẹ rẹ. Bi Pọọlu ti ṣe sọ fun wa ninu ọrọ iyanju rẹ si Timoti yẹn, gbogbo awọn ti o n ke pe orukọ Jesu ni o gbọdọ yipada kuro ninu iwa ika, ki wọn si fi ara wọn ji fun ododo. Eyi jẹ dandan fun wọn lati ṣe. Aijẹbẹ, ariwo irọ ni wọn n pa pe awọn jẹ ti rẹ.
Ṣe o wa le jẹ pe ariwo irọ ni awa naa n pa pe a jẹ ti Jesu bi? Ṣe o le jẹ wipe gbogbo igba ti Ọlọrun ba wo wa, oju ti O fi n wo wa ni oju awọn ti wọn n tan ara wọn jẹ, awọn ti wọn n tan ara wọn jẹ lori ifarajin wọn si? Oju ti O si fi n wo wa niyẹn, niwọn igba ti a ba kọ lati yi pada kuro ninu agbere, ojukokoro, igberaga, agabagebe, irọ pipa, iṣeṣo tabi iwa ika miran ti awọn eniyan ma n wu, bi o tilẹ jẹ wipe a n ke pe orukọ Jesu.
Wayi o, ọrọ Ọlọrun n tọ wa wa bayi, o si n sọ fun wa pe ki a dẹkun lati ma tan ara wa jẹ, ki a si dojukọ eyi ti n ṣe otitọ nipa ọrọ aye wa, ki Ọlọrun ba le gba wa la lotitọ kuro lọwọ awọn nkan ti o ti n pa aye wa run. Adura mi si ni pe ki a ya ọkan rẹ ya ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu itanra-ẹni-jẹ, ti o ba ṣe pe o n tan ara rẹ jẹ, ki o ba le jọwọ ara rẹ lotitọ fun Jesu Kirisiti Oluwa wa, ki o si ni iriri agbara igbala rẹ. Amin.
Ki o ni ọsẹ ayọ.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ariwo irọ́ | Pst. J.O. Lawal | Ògún 7, 2022 | Vol. 11, No. 14 Read More »

