Idi ti aarẹ ko fi mu ọkan wa

J.O. Lawal | Ojo: Erele 21, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafi jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ si ọjọ Aiku ti o kẹyin oṣu Erele 2021. Adura mi si ni pe ki o gba okun lati rin ni pipe ninu ifẹ Ọlọrun fun ọ ninu gbogbo oṣu Ẹrẹna ti a fẹ wọle si ninu ọsẹ tuntun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

read this article

Njẹ, bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, jẹ ki n gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Pọọlu ti o sọ pe, “Nitori naa, gẹgẹ bi awa ti ri iṣẹ-iranṣẹ yii gba nipa aanu Ọlọrun, aarẹ ko mu wa.” (2Korinnti 4:1) Pẹlu nkan ti o sọ nibiyi, kedere ni a ri pe awọn naa ba awọn akoko kan pade ti o le jẹ ki aarẹ mu ọkan wọn, awọn asiko ti o le jẹ ki wọn sọ ireti nu lori aye yi, lori aye ara wọn ati lori Ọlọrun gan paapaa. Nitorina, ti o ba n dojukọ akokokakoko ti o fẹ ya ọ ni were tabi ti o fẹ jẹ ki Ọlọrun, igbe aye iwa mimọ tabi ọrọ aye rẹ su ọ, ko jẹ tuntun rara.

Lotitọ, oniruuru nkan ni o n ṣẹlẹ ninu aye loni ti o le jẹ ki aarẹ mu ọkan wa, ki aye gan funrarẹ si su wa. Fun apẹẹrẹ, o kere tabi o pọ ni, gbogbo wa na ni o n dojukọ idagiri, aini, airiṣẹ, iyanjẹ, iṣedari buburu, ipọniloju, iṣekuṣe ati inunibini ẹsin. Gbogbo igba ti a ba si n wo bi awọn nkan wọnyi ṣe n fina mọ wa ni a n dan wa wo lati sọ ireti nu lori aye yi tabi lori Ọlọrun, ki a si wu iwa agọ lati tu ara wa lara tabi lati sa lọ patapata kuro sakani awọn nkan yi.

Ṣugbọn bi mo ṣe pe akiyesi wa si tẹlẹ, ko si ọkankan ninu awọn nkan ti a n dojukọ yi ti o jẹ tuntun tabi ti o ṣe ajoji (1Peteru 4:12). Awọn onigbagbọ miran kaakiri agbalaaye na n ni iriri awọn nkan ti o fara jọ wọn. Nigba aye Pọọlu gan, ẹwẹ, oun ati awọn arakunrin rẹ ninu iṣẹ iranṣẹ na dojukọ awọn nkan ti o jọ mọ iwọnyi. Sibẹsibẹ o sọ pe awọn ko ṣaarẹ ninu ọkan wọn. Ki wa ni idi? Ki ni aṣiri wọn? Laifọrọgun, o sọ pe aṣiri wọn ni iṣẹ-iranṣẹ kan. Iṣẹ-iranṣẹ kẹ? Iru iṣẹ-iranṣẹ wo ni eyi le jẹ? Iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun ni.

Siwaju ninu lẹta ti o ti sọ awọn nkan wọnyi fun awọn ara Korinnti, o ṣalaye awọn nkankan fun wọn nipa iṣẹ-iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun, ti O n ṣiṣẹ ninu onigbagbọ lati yi aye rẹ pada lati da irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki o jẹ ati lati tun jẹ ki o peye lati ṣe iṣẹrere-kiṣẹrere ti O ba fẹ ki o ṣe, ki o si tun ṣẹgun idojukọ yowu ti o le de ba (2Korinnti 3). Eyi wa ja si pe gbogbo awọn ti o ni Ẹmi Ọlọrun ninu ko ni awawi kankan lati ṣe aarẹ ọkan. Nkan ti wọn nilo lati ṣe ni ki wọn gba a laye lati ṣe iṣakoso aye ati ọrọ wọn, ki wọn si tun kọ lati ma gba iwuri, igboya ati agbara ti wọn nilo lati rin ni iṣẹgun lori akoko yowu ti o le fẹ jẹ ki wọn sọreti nu.

Ibeere wa ni pe, “Njẹ iwọ ni Ẹmi Ọlọrun ninu rẹ tabi o ko ni?” Ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun, a jẹ pe o ni Ẹmi Ọlọrun ninu rẹ niyẹn. Oun si ṣetan lati jẹ ohunkokun ti o ba nilo fun ọ lati ṣẹgun gbogbo idojukọ aye rẹ. Nitorina, ma ṣe bẹru awọn igba ti o n dun mọhurumọhuru mọ ọ lati gba ẹmi rẹ tabi lati sọ ọ di radadrada. Ma si ṣe gbe ara rẹ le awọn asiko ti o n gbiyanju lati ya ọ ni were ati lati jẹ ki Ọlọrun ati aye rẹ su ọ lọwọ. Dipo eyi, fa ohunkohun ti o ba nilo lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun, yala igboya ni, okun ni, imisi ni, aabo ni ati bẹẹbẹẹlọ, nipasẹ adura gbigba ati ijẹwọ ọrọ Ọlọrun. Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, gbogbo ẹru ati aniyan rẹ ni yo ti fi ọ silẹ lọ, ti ọkan rẹ yo si fi gbogbo igba ni okun lati dojukọ ohunkohun.

Ki o ni ọsẹ ti o larinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *