J.O. Lawal | Ojo: Erẹna 07, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 44
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji oṣu Ẹrẹna 2021. Mo si gbadura pe ohunkohun ko ni di aye rẹ lọwọ lati fi didara ati agbara Ọlọrun han lẹkunrẹrẹ nibikibi ti o ba ti ba ara rẹ lọsẹ na. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti a kọ ninu itan bibeli ti ọkunrin weere ara Gadara ni pe ẹnikọọkan ti o ba ti ni iriri didara Ọlọrun ni ojuṣe lati tan iroyin na de ọdọ awọn miran, ki awọn na ba le tọ ọ wa. Oun na yoo wa yi iriri ibanujẹ, itiju ati irora wọn pada si ti ayọ, iṣelogo ati itura (Maaku 5:1-20).
Wayi o, bi akọsilẹ itan na ṣe lọ, ọkunrin yi ni a ri pe awọn ogunlọgọ ẹmikẹmi gba ijọba aye rẹ. Awọn ẹmikẹmi yi si sọ aye rẹ di radarada to bẹẹ gẹ ti o fi ya weere. Amọ weere tirẹ ko kan ki i ṣe eyi ti yo jẹ ki o ma rin kaakiri ni ihoho tabi ti yoo jẹ ki o ma rẹrin lodilodi si gbogbo eniyan. Dipo eyi, weere tirẹ jẹ eyi ti o sọ di elewu ati onijamba eniyan fun gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ ati fun oun tikararẹ. Ọrọ rẹ si buru to bẹẹ gẹ ti awọn eniyan fi dẹkun a ti ma fi ẹwọn so o mọlẹ, nitori pe o ti lagbara ju ẹni ti wọn le de mọlẹ pẹlu ohunkohun lọ. Nitorina, gbogbo eniyan pa a ti. Oun naa si wa bẹrẹ si ni gbe ninu iboji, o si tun n fi tọsantoru kigbe rara ati fi okuta ya ara rẹ. Iwọ na wa wo bi awọn ẹmikẹmi ti o n gbe inu rẹ ṣe sọ aye ọkunrin yi di radarada to.
Lọna kanna, awọn eniyan wa loni ti a ti sọ aye wọn di radarada nipasẹ awọn ẹmi eṣu. Awọn wọnyi le ma ma sare kaakiri ni ihoho bi weere. Ṣugbọn aye wọn ko fi taratara yatọ si ti ẹni ti o ti ya weere. Idi si ni pe awọn nkan ti wọn n fi gbogbo igba ṣe ni awọn nkan ti yo pa wọn lara si tabi pa wọn run ati ti yoo si tun mu ki aye wọn ma a run si eniyan. Abi bi o ti ri pẹlu awọn weere kọ ni yẹn? Bẹe ni o ṣe ri. Awọn nkan ti wọn n jẹ ati ti wọn n mu, ibi ti wọn n gbe ati ti wọn n sun, irin ti wọn n rin kaakiri ati awọn aṣọ ti wọn n wọn, ti wọn ba tilẹ wọ nkankan rara, kan tun le pa aye wọn lara si ni, ki wọn si tun jẹ ki wọn ma a run lọpọlọpọ si si eniyan ati ki ẹnikẹni ma ba fẹ ba wọn ṣe nkankan pọ.
Laifọrọgun, ọjọ kan de ti ọkunrin weere ara Gadara yi ba Jesu Kirisiti Oluwa pade. Ọjọ na si ni o ni iriri aanu Ọlọrun, ti a si tun gba a la kuro lọwọ awọn ika ẹmi aimọ ti wọn ti pinu lati pa aye rẹ run patapata. Idande rẹ si jẹ iyalẹnu to bẹẹ gẹ ti awọn ti o ri ko fẹ le gba oju wọn gbọ, nitori pe nṣe ni o joko pẹlu aṣọ daradara ati ori pipe. Siwajusi, nitoripe ọkunrin yi mọ oore Ọlọrun ati wipe inu rẹ dun gidigidi nitori idande rẹ, o bẹ Jesu ki o gba a laye lati tẹle lọ si ibikibi ti O ba fẹ ẹ lọ. Ṣugbọn Oluwa sọ fun pe, “Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ara ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o ti ṣaanu fun ọ.” (Maaku 5:19)
Iwọ naa gbe eyi yẹwo. Kedere ni Oluwa sọ fun ọkunrin yi pe ko di igba ti o ba to n tẹle Oun kaakiri ki o to sin Ọlọrun. Nkan ti o nilo lati ṣe ni ki o tọ awọn eniyan rẹ lọ, gbogbo awọn ti o pa a ti tẹlẹ, ki o si sọ fun wọn bi nkan ti Ọlọrun ṣe fun ṣe ga to. Ṣe o wa lọ tabi ko lọ? O kuku lọ si ọdọ awọn ẹbi rẹ lati fun wọn ni iroyin didara Ọlọrun si. Ṣugbọn o ṣe ju eyi lọ. O tun lọ kaakiri ibi kan ti a n pe ni ‘Ilu nla Mẹwa’, o si n sọ fun gbogbo awọn ti o ba pade nibẹ bi nkan ti Jesu ṣe fun ṣe ga to. (Woo: Maaku 5:20)
Njẹ Oluwa ti wa ṣe iwọ na ni rere kankan bi? Ti o ba jẹ bẹ, taani o ti sọ fun nipa rẹ? Ṣe Oluwa tilẹ n bukunfun ọ loni nipasẹ iṣẹ iranṣẹ ọrọ rẹ tabi ti awọn eniyan mimọ rẹ kan? Ti o ba jẹ bẹ, taani o n sọ fun nipa rẹ? Ọlọrun le ma nilo rẹ lati jẹ oniwaasu ki o to le e sin in. Ṣugbọn O nilo rẹ lati ma fi gbogbo igba wa anfaani lati fi ojoojumọ sọ nipa didara rẹ si ọ tabi si awọn miran fun awọn eniyan. Idi si ni ki wọn ba le gba imisi lati wa si ọdọ rẹ fun igbala tabi itusilẹ. Si wa ranti pe ọpọ ni ayika wa ni aye wọn ko yatọ si ti weere, ti wọn si nilo idande ni kiakia, ti wọn ko ba ni i parun. Iru awọn wọnyi nilo ki a ba wọn sọrọ lori didara ati ṣiṣeefọkantan Ọlọrun, ki awọn naa ba le wa a tọ ọ wo. Adura mi si ni pe ki a fọ aye wa mọ kuro ninu anikanjọpọn yowu ti o le wa ninu wa lori ọrọ yi, ki a si tun fun wa ni igboya lati ṣe ohun ti o tọ.
Ki o ni ọsẹ ti o kun fun ẹri rere
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
