Ọjọ: Ebibi 16, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 2
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ebibi 2021, mo si tun gbadura pe, lati ọsẹ yi lọ, ki o bẹrẹ si ni iriri igbega iyanu ti awọn eniyan ko le gan tabi fẹnu tẹnbẹlu ju tatẹyinwa lọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti yoo jẹ ki o ṣeeṣe fun awọn eniyan lati ri igbega rẹ, ki wọn si ma fi ẹnu tẹnbẹlu rẹ ni ifarahan ọgbọn Ọlọrun ti o ṣe e fojuri ninu aye rẹ. Fun apẹẹrẹ, bible sọ eyi nipa Dafidi: “Dafidi a si maa lọ si ibikibi ti Sọọlu ran an, a maa huwa ọlọgbọn: Ṣọọlu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn eniyan, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Sọọlu.” (1Samuẹli 18:5) Njẹ o ri bayi? Bi o tilẹ jẹ pe ọdọmọde ni Dafidi nigba ti o darapọ mọ iṣinru ilu labẹ Ọba Sọọlu, a fi ṣe ọgagun lori awọn jagunjagun rẹ.
Ki wa ni idi ti a ṣe fi ọdọmọkunrin ṣe ọgagun lọna yi? Ṣe nitoripe o pa Golayati ni? Rara o! Abi ṣe nitoripe o jẹ ọrẹ ọmọ ọba, Jonatani, ẹni ti o jẹ ọmọ ọba alade ni akoko yi ni bi? Rara o! Lotitọ, Dafidi, lodi si ohun ti awọn eniyan ro, pa asaju jagunjagun awọn ara Filisitini, Golayati. Eyi ṣi sọ di olokiki eniyan. Lafikun, lotitọ ni o jẹ ọrẹ ọmọ ọba ti o lagbara, ti awọn eniyan si n waari fun, iyẹn Jonatani. Ṣugbọn gbogbo awọn nkan wọnyi ko wa ja si pe o dangajia to lati dari awọn jagunjagun ilẹ na, ọpọ ẹni ti wọn julọ, tabi lati fun wọn ni iwuri lati ṣe aṣeyọri.
Ti a ba wo daradara, ọrọ iṣedari awọn jagunjagun la n ṣo nibi yi, awọn ti a ti kọ lati doju kọ iku nigbakigba, lọjọkọjo ati nibikibi. Nitorina, Dafidi ni lati ju ọrẹ ọmọ-ọba alade lọ lati dari wọn. Siwaju si, o ni lati ju akikanju ologun lọ lati dari wọn. O nilo ibọwọfun wọn ki wọn to le tẹle. Ko si to le ri ibọwọfun wọn gba, o nilo lati fi han wọn pe oun koju osuwọn lati daabo bo wọn ati lati dari wọn lati ni iṣẹgun, bi o ti wu ki asiko ri.
Eyi gan wa si ni o ṣe. O huwa ọlọgbọn ninu gbogbo iṣẹ ti oluwa rẹ, Ọba Sọọlu, ran. Eyi tunmọ si pe gbogbo awọn jagunjagun ti wọn n kiyesi ri pe gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu eto ogun jija ati awọn jagunjagun ti a fa le lọwọ ni o mojuto pẹlu ọgbọn ati ori pipe. Nitorina, nigbati a fi ṣe ọgangun wọn, gbogbo wọn ni o gba pe ipo naa tọ si. Ko si ẹni ti o ro lara wọn pe ojusaaju ni o gbe de ipo na. Dipo eyi, nṣe ni gbogbo wọn tẹwọgba tayọtayọ, ti wọn si rẹ ara wọn silẹ labi iṣedari rẹ.
Wayi o, irufẹ igbesoke tabi igbega ti iwọ na nilo ninu aye rẹ ni eyi. Iwọ na nilo igbega ti awọn ti o korira rẹ gan yoo gba pe o tọ si ọ. Ki o si ba le ni iru igbega yi, iwọ naa, gẹgẹ bi Dafidi, nilo lati ma huwa bi ọlọgbọn nibikibi ti o ba wa, lalai fi ti ọjọ ori rẹ tabi ipo rẹ lawujọ ṣe. Nitorina, lati isinsinyi lọ, iṣẹkiṣẹ ti a ba fun ọ ni ibi iṣẹ rẹ, ile-iwe rẹ, adugbo rẹ, idile rẹ tabi ninu ijọ, ṣe daradara ati pẹlu ọgbọn ori dipo eyi ti wa fi ṣe jakujaku. Bẹẹni, ri daju pe ountẹ titayọ ati ọgbọn wa lara ohunkokun ti o ba ṣe.
Ki wa ni idi ti eyi fi ṣe pataki? O ṣe pataki nitoripe awọn eniyan n wo ọ ni gbogbo igba, boya o mọ tabi o ko mọ. Bi o ba si ṣe n mojuto nkan ti a fi si abẹ akoso rẹ si jẹ ọkan lara awọn nkan ti yo sọ boya wọn o ri ọ gẹgẹ bi ẹni ti ipo giga tọ si ni aye yi tabi bẹẹkọ. Lotitọ, Ọlọrun ko nilo ero awọn eniyan lati gbe ọ ga tabi fa ọ soke. O le gbe o ga boya wọn fi ọwọ si tabi wọn ko fi ọwọ si. Amọ ṣa o, ti o ba fẹ gbadun igbega rẹ, ki o si pọ si ni iwulo pẹlu rẹ, o ṣe pataki ki awọn ti o wa ni ayika rẹ ri ọ gẹgẹ bi ẹni ti ipo ti o wa tọ si. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o kabọmọ nikẹyinkẹyin pe o wa ni ipo giga yowu ti o ba wa, nigbati awọn ti o ye ki ẹ jọ ma ṣiṣẹ pọ tabi awọn ti o yẹ ki wọn ma fun ọ ni iwuri ba n gan ọ.
O wa jasi ọpẹ fun wa pe, nipasẹ Kirisiti Jesu, gbogbo wa ni ilẹkun gbogbo iṣura ọgbọn, imọ ati oye ṣi silẹ fun (1Korinnti 1:30; Col 2:2-3). Gbogbo nkan ti a si nilo lati ri ifarahan awọn nkan wọnyi ninu aye ko ju ki a fi ara wa jin si ọrọ Ọlọrun ati adura gbigba lọ. Nitorina, bi o ṣe n lọ ni ọsẹ yi, tun iṣẹ ṣe lori ifarajin rẹ si ọrọ rẹ ati adura gbigba. Yoo si ya ọ lẹnu bi ọgbọn rẹ yo ṣe farahan lọna ti o ṣe fojuri ninu aye rẹ ninu ohun gbogbo ti o ba ṣe ati bi awọn eniyan yoo ṣe bẹrẹ si ni tẹwọgba ọ, ti wọn o si ma ba ọ yọ nitori igbega rẹ.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
