Ọjọ: Ebibi 09, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 1
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ebibi 2021. Mo gbadura pe ki Ọlọrun, nipa agbara iyanu rẹ, mu gbogbo erongba rẹ ni rere fun ọsẹ na wa si imuṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọsẹ yi ni o pe ọdun mẹsan gbako ti a bẹrẹ si ni pade gẹgẹ bi ijọ ninu ilu yi. Nitorina, lakọkọ, o yẹ ki a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi O ṣe pe wa jade kuro ninu okunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ, ki a ba le ma ba Oun ati Ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti, ṣe papọ. A tun gbọdọ dupẹ lọwọ rẹ fun bi O ṣe fi wa ṣe aṣoju ijọba ainipẹkun rẹ ninu aye okunkun yi. Ki orukọ mimọ rẹ jẹ gbigbega titi lailai. Amin.
Wayi o, bi a ṣe bẹrẹ ọdun miran papọ ninu ibadapọ pẹlu Ọlọrun ati ọmọ rẹ Jesu Kirisiti, ati pẹlu ara wa, o ni awọn nkan meji kan ti mo fẹ ki o mu ni ọkunkundun. Akọkọ, mu ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun ni ọkunkundun. Ma ṣe gbagbe pe nkan ti o ṣe wa yẹ lati jẹ ọmọ ijọ yi ni ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun. Bẹẹni, nitoripe gbogbo wa jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ṣe n ba ara wa ṣepọ gẹgẹ bi ẹbi kan, ti a si n jẹgbadun ifẹ rẹ ati ifẹ ara wa.
Nitorina, ju ohun gbogbo lọ, o gbọdọ mọ ibaṣepọ ati ibadapọ rẹ pẹlu Ọlọrun ni ọkunkundun. Niwọn igba ti o ko ba mu ni pataki bi o ṣe yẹ ki o mu, ko si bi ẹnikankan lara wa ṣe fẹ jẹ alabukunfun nipasẹ ibaṣepọ wa pẹlu rẹ bi o ṣe yẹ ki o ri. Nitorina, fi Ọlọrun ṣiwaju ohun gbogbo. Si fi eyi han nipa lilepa lati gbẹkẹle fun ohun gbogbo ti o nilo ati lati ṣe ohun ti o dun mọ ọn ninu ninu ohun gbogbo. Bi o ba si ṣe n ṣe eyi, Oun naa yoo ri daju pe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni O ṣe ni aṣepe ati wipe o ko ṣe alaini ohunkohun ti o nilo lati gbe igbe aye eleso ati igbe aye ti o ni itunmọ. (Wo: Matiu 6:33)
Siwaju si, mo tun fẹ ki o mu gbogbo awọn eniyan ti Ọlọrun ti gbin sinu aye rẹ ni pataki, lati ori awọn ara ile rẹ. Ki ni idi ti eyi fi ṣe pataki? O ṣe pataki nitoripe ifẹ Ọlọrun ni o jẹ fun ọ. Ti o ba ka iwe mimọ daradara, o ko ni ṣe alairi pe ọrọ awọn eniyan ati bi wọn ṣe n ṣe ma n fi gbogbo igba jẹ Ọlọrun logun (Saamu 8:3-8). Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ni Oun jẹ, ti ko si ni tu irun kankan lara rẹ ti O ba pinnu lati pa wa ti tabi lati ma ni nkankan ṣe pẹlu wa, sibẹsibẹ, O ka wa si pataki niwaju rẹ, O si ma n fẹ fi gbogbo igba ṣe wa daradara. Idi si ni pe O ni ifẹ wa, O si ma wa nkan ti o san julọ fun wa ni gbogbo igba.
Nitorina, niwọn igba ti a jẹ ọmọ rẹ, a ko gbọdọ wuwa yatọ si i. Eyi jasi pe awa naa gbọdọ jẹ olufẹ awọn eniyan, bi Ọlọrun ṣe jẹ olufẹ wọn. A si tun gbọdọ fi tọkankan jẹ ki ọrọ wọn jẹ wa logun, paapaa julọ awọn ti O ti gbin sinu aye wa, ki a si ma fi gbogbo igba wa bi a ṣe le ṣe wọn ni ire. Aijẹbẹ, ko si bi a ṣe fẹ jẹ iranṣẹ Jesu Kirisiti daradara.
Mo woye pe o yẹ ki o mọ pe iṣẹ iranṣẹ kọja sinsin Ọlọrun; o tun ni i ṣe pẹlu sinsin awọn eniyan pẹlu. Ka tilẹ sọ otitọ, nitoripe Ọlọrun fẹ ki a sin awọn eniyan ni O ṣe bukun fun wa pẹlu awọn ẹbun Ẹmi rẹ ti a ni ati pẹlu awọn nkan ini miran ti o wa ni arọwọto wa gẹgẹ bi ijọ rẹ (1Korinnti 12:4-7). Nitorina, a ko le sọ pe a n sin in, nigbati a ko ba sin awọn eniyan. A ko si le sin awọn eniyan ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ, ti ọrọ wọn ati awọn nkan ti o n lọ ninu aye wọn ko ba jẹ wa logun. Njẹ o tilẹ mọ pe a ko le tọju awọn ọkọ, aya, ọmọ, obi ati ara wa bi o ṣe yẹ, ti a ko ba ni ifẹ otitọ si itẹsiwaju aye wọn?
Nitorina, yatọ si igbẹkẹle rẹ ninu Ọlọrun, nkan pataki miran ti yoo jẹ ki o di iranṣe Jesu Kirisiti daradara ni ifẹ aiṣẹtan ti o ba ni si ilọsiwaju awọn eniyan. Bawọ ni aye ati itẹsiwaju awọn ẹbi rẹ ṣe jẹ ọ logun si? Bawo ni aye ati ilọsiwaju awọn ọmọ ijọ yi, ti o n ba darapọ ni ọsọọsẹ, ṣe jẹ ọ logun si? Bawo si ni aye ati ilọsiwaju awọn eniyan yoku ti o sunmọ ọ lọnakan tabi omiran ṣe jẹ ọ logun si? Bi ọrọ awọn wọnyi ba ṣe jẹ ọ logun si naa ni o o ṣe mura si lati wa oju Ọlọrun lori ọrọ aye wọn ati lati ṣe amulo awọn amuyẹ ati nkan ini ti Ọlọrun fun ọ lati ran wọn lọwọ.
Ti o ba wa kiyesi pe ọrọ awọn eniyan ko ki i ka ọ lara rara, o nilo lati bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun gidigidi lori rẹ. Idi ni pe eyi n fihan pe o ko fi aye gba ifẹ Ọlọrun lati ṣan bi odo lainidiwọ ninu aye rẹ niyẹn. Ifẹ, ifẹ ti Ọlọrun, ni o n jẹ ki a mu ọrọ ati igbayegbadun awọn eniyan lọkunkundun. Ibi ti eleyi ko ba si ti ma ṣan lainidiwọ, bintin bayi ni ọrọ awọn eniyan yoo ri loju wa. Gbadura, nitori eyi, pe ki Ọlọrun jẹ ki ifẹ rẹ ma ṣan bi odo lainidiwọ ninu aye rẹ, gẹgẹ bi o ṣe tọ, ki O ba le lo ọ lati bukun fun gbogbo awọn ti O ni lọkan lati tipasẹ rẹ sọ di alabukunfun.
Lẹkan si, mo ki ọ kaabọ sinu ọdun ibadapọ ti o ga pẹlu Ọlọrun ati pẹlu ara wa miran. Mo si gbadura pe ki gbogbo wa pọ si ni siso eso rere ati ni iwulo ju tatẹyin wa lọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
