Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu yi, oṣu Èrèlé 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo jẹ ki ọkan rẹ wa ni ipo irẹlẹ lati tẹwọgba ọrọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ọrọ ibawi ni, ki ete rẹ fun aye rẹ ba a le wa si imuṣẹ ni kikun. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti o ṣoro fun wa ju lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ni ọrọ ibawi. Ko ki i ṣaba nira fun wa lati tẹwọgba ọrọ ibukun tabi oriyin rẹ. Ṣugbọn ti O ba wa pinnu lati ba wa wi, a le binu si tabi binu si awọn ti O n lo lati ba wa wi. Eyi si di dandan ki o di imuṣẹ ete rẹ inu aye wa lọwọ tabi ki o ṣi aye wa silẹ fun idajọ.
Bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, Ọlọrun ko ki i ba wa wi nitoripe o kan wu u lati ma a bu ẹnu atẹ lu wa tabi lu iṣẹ ọwọ wa. Dipo eyi, nṣe ni O ma n ba wa wi nigba ti a ba kuna. O si n ba wa wi ki a ba a le ronupiwada, ki a si ma ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun idajọ rẹ. Iha ti a ba wa kọ si ibawi rẹ ni yoo sọ boya ọrọ ibawi naa yoo ṣe aye wa lore tabi ko ni ṣe e lore.
Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọba Asa jẹ ọba oniwa-bi-Ọlọrun, nigba ti Ọlọrun ba a wi fun fifi igbẹkẹle rẹ sinu eniyan dipo sinu rẹ, o binu. O binu si Ọlọrun debi wipe o fi wolii ti Ọlọrun ran si sinu atimọle, o si tun pọn melokan lara awọn eniyan ilẹ rẹ loju. Nitorina, ọrọ ibawi ti a ran si ko le ṣe ni ire, ki o si yi pada kuro ni oju ọna iparun. Abalajọ ti o fi ku sinu aisan ati ṣaaju asiko rẹ. (Wo: 2Kíróníkà 16)
Amọ ṣa o, si iyalẹnu eniyan, nigba ti Ọlọrun ran ọrọ ibawi rẹ nipasẹ Wolii Elija si Ọba Ahabu, ọba ika yẹn, o tẹwọgba pẹlu irẹlẹ. Ọrọ naa rẹ ọkan rẹ silẹ debi wipe o fa aṣọ rẹ ya, o gba awẹ, o si n lọ kaakiri pẹlu irẹlẹ. Nitorina, dipo ti Ọlọrun yoo fi ṣe idajọ rẹ lẹsẹkẹsẹ, O sun idajọ rẹ siwaju di asiko ọmọ rẹ. (Wo: 1Àwọn Ọba 21)
Ṣe o wa ri bayi pe a le mọ eniyan si olododo eniyan, ki o si tun jẹ ẹni ti o n kọ iha ti ko dara si ibawi. A si wa le mọ eniyan gẹgẹ si ika tabi alaiwulo eniyan, ki o si wa kọ iha ti o dara si ibawi. Nibi ti eyi ba ti si ti wa ri bẹ, ẹni ti a n pe ni alaida eniyan naa yoo ni iriri aanu Ọlọrun fun idariji ati ipamọ. Ṣugbọn iwọ, pẹlu gbogbo ododo rẹ, yoo padanu didara rẹ nitori agidi ati iha ti ko dara ti o n kọ si ọrọ ibawi rẹ.
Nitorina, igbakigba ti Ọlọrun ba n ba ọ wi fun ṣiṣe ohun ti ko dara tabi ti ko tọna, tẹwọgba ibawi naa pẹlu irẹlẹ. Ma ṣe jiyan. Ma ṣe gbiyanju lati wi awijare. Lotitọ, ẹni ti Ọlọrun n lo lati ba ọ wi le sọrọ lile si ọ. Sibẹsibẹ, tẹwọgba ọrọ ibawi ti o n tọ ọ wa, niwọn igba ti o ba ti jẹ otitọ. Ti o ba tilẹ si wa ro wipe aigbọraẹniye ni o waye, si rẹ ara rẹ silẹ to lati kọkọ gbọ ọrọ ibawi ti o n tọ ọ wa ki o to ṣalaye ara rẹ. Nipa ṣiṣe bayi, o ko ni fi ara rẹ han gẹgẹ bi alagidi eniyan, ki o si ṣi ilẹkun aye rẹ silẹ fun idajọ Ọlọrun.
Wa ranti wipe o ko mọ gbogbo nkan. Ko si ẹnikẹni ninu wa ti o mọ gbogbo kan. Ọlọrun nikan ni O mọ gbogbo nkan. Ti yoo ba si le mu ete rere rẹ ṣẹ ninu aye wa, a gbọdọ ma a kọ iha ti o tọ si ibawi. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a pari aye wa bi Ọba Asa. Njẹ ki eyi ma ṣe jẹ ipin wa laye, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)