Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Agẹmọ 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ma a fi igba gbogbo rẹ ara rẹ silẹ lati tẹwọgba ẹkọ to ye kooro nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti Jesu, ki o ma ba a lugbadi irọ eṣu ni abala aye rẹ kankan, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti a sọ fun wa ninu bibeli nipa awọn ọjọ ikẹyin ni pe wọn jẹ ọjọ ninu eyi ti ọpọ ti o n pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ko ni fẹ fi aaye gba ẹkọ to ye kooro. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi:
“Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan.” (2 Tímótì 4:3-4)
Njẹ o ri bayẹn? Awọn ọjọ ikẹyin jẹọjọ ninu eyi ti awọn eniyan ko ni fẹ fi ara da ẹkọ to ye kooro. Wọn jẹ ọjọ ninu eyi ti awọn eniyan yoo yi eti wọn kuro lọdọ otitọ lati gbọ awọn itan ti ko ni ṣe aye wọn lanfaani. Wọn si tun jẹ awọn ọjọ ninu eyi ti a o ti ri ọpọ olukọ bibeli ti wọn yoo ma a kọ awọn eniyan ni nkan ti eti ti o n rin wọn fẹ gbọ, ti wọn yoo si ma a fun wọn ni nkan ti wọn fẹ dipo nkan ti wọn nilo, gẹgẹ bi Arọni ti ṣe si awọn ọmọ Isiraẹli ninu aginju. (Wo: Ẹ́kísódù 32)
Ki wa lo le fa ti awọn ti a mọ si Kirisitiẹni ko ni fẹ fi aaye gba ẹkọ ti o ye kooro tabi ti wọn yoo fi ma a sa fun otitọ ti o yẹ lati tu wọn silẹ? Nkan kan pataki ti o n fa ni pe ọkan wọn ko pe pẹlu Ọlọrun. Nitorina, wọn ko ma a sin-in nitoripe wọn ti mọ daju pe nkan ti o tọna fun awọn lati ṣe ni eyi. Dipo bẹẹ, wọn n sin-in nitori awọn nkan ti wọn lero pe awọn o le ri gba lọwọ rẹ. Idi ni yi ti wọn fi ma n lọ lati ijọ kan si ijọ miran ati lati ori-oke adura kan si ori-oke adura miran.
Njẹ eyi yoo wa jẹ ki aye wọn dara si bi? Rara o! Ko ni jẹ ki aye wọn dara si nitoripe nkan ti wọn n ṣe jẹ eyi ti yoo pada fun Satani ni anfaani si lati ba aye wọn jẹ nipasẹ awọn oluṣọ-aguntan, wolii, ajinyinrere ati apọsiteli eke. A si ri ọpọ ti wọn ti lugbadi ni ọna yi, ti wọn ko si ni igboya to lati sọ awọn iriri buburu ti wọn ti ni.
Ni kukuru, ti o ko ba fẹ lugbadi irọ ati iwa ika eṣu bi ti awọn wọnyi, má sálọ fun otitọ. Lotitọ, otitọ ko ki i fi igba gbogbo dun lati gbọ. Ṣugbọn ti a ba tẹwọgba, ti a si ṣiṣẹ tọ ọ, yoo pada jẹ ki aye dun fun wa. Mo wa gbadura pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun ọ ni okun lati tẹwọgba otitọ rẹ, bi o ti wu ki o koro to ni eti rẹ, ki a ba a le fi adun si ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ. Amin.
Kí o ní oṣù Agẹmọ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)