Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kinni ninu oṣu kinni ọdun tuntun yi, ọdun 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o pọ si gidigidi ni iwulo ni ọwọ rẹ ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti awọn ọrọ Pọọlu kan ti o sọ wipe:
“Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro.” (1Kọ́ríntì 14:26)
Ki ni nkan ti a ri kọ lati ara nkan ti apọsiteli yi sọ nibiyi? Akọkọ, oun naa ni pe o yẹ ki ẹnikọọkan wa ni nkankan ti yoo fi bukun fun awa yoku nigbakigba ti a ba pade fun ipade ijọ wa. Eyi jasi pe ko yẹ ki a wa fun ipade ijọ kankan lati kan jẹ alabukun fun lati ipasẹ awọn miran ṣugbọn lati tun jẹ ẹni ti yoo bukun fun awọn miran pẹlu.
Nitorina, igbakugba ti o ba n bọ ni ipade ijọ kan tabi omiran ni ọdun yi, ri daju pe o ni nkankan pẹlu rẹ lati fi bukun fun awa yoku. O le jẹ ọrọ iwuri. O le jẹ ọrọ adura tabi isọtẹlẹ. O si le jẹ ẹbun kan tabi omiran. Ṣa a ri daju pe o ko wa ni ọwọ ofo ṣugbọn pẹlu nkan kan ti yoo jasi ibukun fun awa yoku. Ki Ọlọrun si fun ọ ni okun lati le jẹ olotitọ ni ṣiṣe eyi. Amin.
Nkan ekeji ti a kọ lati ara nkan ti Pọọlu sọ ninu ẹsẹ bibeli yẹn ni pe ohunkohun ti ẹnikẹni ninu wa ba ṣe ninu awọn ipade ijọ wa gbọdọ wa fun igbero awọn miran. Nitorina, a ko gbọdọ ri ọkankan ninu wa ti yoo sọ tabi ṣe ohunkohun ti yoo pa igbagbọ, aye tabi ile awọn miran lara tabi run ninu ọkankan ninu awọn awọn ipade wa. Dipo eyi, ohun gbogbo ti a o ma ṣe tabi sọ gbọdọ jẹ eyi ti a mọ-ọn-mọ sọ lati bukun fun awọn yoku wa ati lati gbe wọn ro. Ti ko ba si da ọ loju pe o ko ni sọ tabi ṣe ohunkohun ti ko ni pa ẹlomiran lara ninu awọn ipade wa, yoo ṣan ki o kuku joko si ile.
Wayi o, mo mọ pe ko ni wu ọ lati kan joko si ile ni igba yowu ti a ba n ni ipade gẹgẹ bi ijọ ni ọdun yi, ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun nitootọ. Dipo eyi, ti Ọlọrun ba fẹ, nṣe ni iwọ yoo fẹ lati wa ninu gbogbo ipade ti a ba ni. Nitorina, gbadura pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati le kopa ninu gbogbo ipade ti a o ma ni ni ọna ti ohun gbogbo ti iwọ yoo ma sọ tabi ṣe yoo fi jẹ eyi ti yoo bukun fun gbogbo wa. Yoo si ri bẹ ẹ fun ọ ni gbogbo ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.
A ku ọdun tuntun o.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)