Ranti lati ṣe oore fun wọn | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ọpẹ 12, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 32

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ọpẹ 2021. Mo si gba adura pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ ninu ọsẹ naa lati ri ohun rere gbogbo ti o yẹ ki o ṣe fun awọn eniyan ninu ọdun yi ti o ko i ti ṣe, ki O si tun ṣe ọ ye lati ṣe lalai fi akoko ṣofo, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun ọ. Eyi tunmọ si pe, gẹgẹ bi o ti ṣe jẹ ifẹ rẹ ni pe ki gbogbo awọn ti o yẹ ki wọn ṣe ọ loore lọdun yi ranti lati ṣe e, bẹẹ gẹẹ naa si ni o tun ṣe jẹ ifẹ rẹ pe ki iwọ naa ranti gbogbo awọn ti o yẹ ki o ṣe ni oore lọdun yi, ki o ṣi ṣe ohun rere gbogbo ti o yẹ ki o ṣe fun wọn tabi si wọn. Nitorina, erongba wa ko gbọdọ da lori ki awọn miran ranti lati ṣe wa loore nikan; dipo bẹẹ, o tun gbọdọ da lori bi awọn naa yoo ṣe ranti awọn miran lati ṣe wọn ni oore. Awọn eniyan si wa ni tootọ ti Ọlọrun n reti wa lati ranti ṣe loore. O le jẹ nitori awọn ipa pataki kan ti awọn wọnyi tabi awọn ẹbi wọn ti ko ninu aye wa sẹyin. O si tun le jẹ nitoripe awa nikan naa ni a wa ni ipo ẹni ti o le ran wọn lọwọ.

Fun apẹẹrẹ, eyi ni nkan ti a kọ silẹ nipa Dafidi lori ọrọ yi: “Dafidi si beere pe, Ọkan ninu awọn ẹni ti i ṣe idile Sọọlu ku silẹ bi? Ki emi ki o le ṣe oore fun un nitori Jonatani.” (2Samuẹli 9:1) Ki ni idi ti o ṣe bere ibeere yi? Idi ni pe o ranti Jonatani, ọrẹ rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, Jonatani kọja ọrẹ lasan fun un; arakunrin rẹ ni o jẹ pẹlu. Nigba ti o si wa laye, o nifẹ rẹ pẹlu gbogbo ọkan rẹ, o si tun ṣe ohun gbogbo ti o wa ni ipa rẹ lati daabo bo o kuro lọwọ baba rẹ Sọọlu, ẹni ti o jẹ ika ati ojowu.

Amọ ṣa o, ọkunrin yi ku nitori awọn ẹṣẹ baba rẹ, a si gba ijọba kuro lọwọ idile wọn, a gbe le Dafidi lọwọ. Nitorina, ni akoko ti Dafidi n bere ibeere yi, ko si ẹnikẹni ti o n kọbiara si nkan ti o n ṣẹlẹ ni idile Sọọlu ati awọn ọmọ rẹ mọ. Ọrọ wọn ti di itan fun gbogbo eniyan. Ti Dafidi ko ba wa gbe igbesẹ kankan lati mọ boya ẹnikẹni tilẹ ku lara wọn ti o le ṣoore fun ni, boya wọn ko ba ma ti ri iranwọ kankan ti o nitunmọ gba ni ilẹ naa mọ. Nipa bibere ibeere yi, ẹwẹ, o jẹ ki o ṣeeṣe fun lati mọ pe Jonatani ni ọmọkunrin aarọ kan nitootọ, ẹni ti o fẹrẹ jẹ pe gbogbo eniyan ni o ti pati sẹgbẹ kan. Bi a si ṣe fa ọdọmọkunrin yi, Mẹfiboṣeti, kuro ni ipo itiju ati aini niyi si inu iṣerere ati igbadun ọba. (Wo: 2Samuẹli 9)

Wayi o, bi a ko tilẹ sọ fun wa ọna ti Ọlọrun gba san Dafidi lẹsan fun nkan ti o ṣe yi, akọsilẹ bibeli fi ye wa pe, lẹyin ọdun melokan si lẹyin iṣẹlẹ yi, nigba ti o n sa a lọ nitori ọtẹ ọmọ rẹ, Abusalomu, iranṣẹ Mẹfiboṣeti yi, Siba, jẹ ọkan lara awọn ti Ọlọrun lo lati pese ounjẹ fun oun ati awọn eniyan rẹ. Ti Dafidi ko ba wa ti jẹ ki Ọlọrun lo oun lati fa awọn wọnyi kuro ninu iṣẹ ati itiju ni akoko ti o ṣe bẹẹ nkọ, njẹ ọkunrin yi ko ba ni nkankan lati ran an lọwọ ni ọjọ idamu rẹ bi? Ti wọn ba tilẹ ni nkan ti wọn fi le ran an lọwọ, njẹ wọn o tilẹ ranti rẹ rara, niwọn igba ti o jẹ wipe oun gan ko ranti wọn tabi ṣe wọn ni oore kankan nigba ti o wa ni ikawọ rẹ lati ṣe bẹ? Mi o ro bẹ. (Wo: 2Samuẹli 16:1-4)

Nitorina, ti awọn eniyan ba wa ti o wa ni ipo lati ran lọwọ tabi ṣe oore fun ni kiakia bayi, irufẹ awọn eniyan bẹẹ yoo si wa, ma ṣe fi akoko ṣofo rara lati ran wọn lọwọ ni ọnakọna ti o ba le gba ṣe bẹẹ. Idi si ni pe o ko le sọ ọna ti Ọlọrun yoo gba san ọ lẹsan fun oore ti o n ṣe fun wọn loni tabi akoko ti oore ti o n ṣe bayi yoo ṣi ilẹkun fun iwọ naa lati ri awọn ojurere kan ti owo tabi ipo ko le ra gba.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *