January 2026

Má sọ ìrètí nù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Erele 01, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 40

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ akọkọ ninu oṣu Èrèlé ọdun 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu aye re padabọsipo nibikibi ti o ba ti nilo imupadabọsipo ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn ọna lati ni iriri imupadabọsipo lati ọwọ Ọlọrun ni ki a ma sọ ireti, bi awọn nkan ti a n dojukọ laye ti wu ki o ri. Bibeli sọ wipe, “Nitoripe olõtọ a ṣubu nigba meje, a si tun dide: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu sinu ibi.” (Ìwé Òwe 24:16) Njẹ o ri bayẹn? Bi olododo tilẹ ni iriri ikuna lera-lera laye yi, yoo dide pada. Ki ni idi ti o ṣe le e dide pada? Idi ni pe ko sọ ireti nu ninu ara rẹ tabi ninu Ọlọrun.

O wa ṣeni laanu pe, ko ki i ṣe gbogbo olododo eniyan tabi ọmọ Ọlọrun ni a le sọ eyi nipa wọn. Ẹkan ṣoṣo ni awọn miran ṣubu ti wọn ko si dide mọ lailai. Ki ni idi? Wọn sọ ireti nu? Fun apẹrẹ, lẹyin iṣubu Samusoni, Ọlọrun fun ni anfaani miran lati ni iriri imupadabọsipo. Lọna wo? O jẹ ki irun ori rẹ, ti a o jẹ amin ipe ati agbara rẹ ninu aye rẹ, bẹrẹ si ni wu pada. (Wo: Onídájọ́ 16:21-22)

Ṣugbọn ṣe o wa ṣe amulo ti o peye anfaani fun imupadabọsipo yi? Rara o! Dipo bẹẹ, nṣe ni o lo anfaani naa lati gbẹsan. O gbadura si Ọlọrun pe ki o da okun oun pada fun oun lẹẹkan ṣi, ki oun ba a le gbẹsan lara awọn ọta oun fun oju oun ti wọn yọ. O tilẹ sọ fun Ọlọrun pe ki O jẹ ki oun ku pẹlu awọn ọta oun nigba ti o n ba n gbẹsan lara wọn. Ṣe Ọlọrun wa da lohun tabi ko da lohun? O da lohun. O fun ni nkan ti o bere fun. Nitorina, ni ọjọ kanna yi, o pa pupọ ninu awọn ọta rẹ nigba ti o n ku ju igba ti o wa laye lọ. (Wo: Onídájọ́ 16:26-30)

Njẹ bi Ọlọrun wa ṣe fẹ ki nkan pari fun Samusoni ni yi bi? Rara o! Ṣe Ọlọrun jẹ ki irun ori rẹ kun pada ki o ba a le ku pẹlu awọn ara Filisitini ni bi? Rara o! Ki wa ni idi ti O fi jẹ ki irun ori rẹ kun pada? O jẹ ki o kun pada ki o ba a le ni anfaani fun imupadabọsipo aye ati iṣẹ iranṣẹ rẹ. Nitorina, dipo ti o fi bere lọwọ Ọlọrun pe ki O jẹ ki oun ku pẹlu awọn ọta oun, nṣe ni ko ba sọ pe ki O ṣaanu fun oun, ki O fun oun ni oju tuntun, ki O si tun da oun pada si idi iṣẹ iranṣẹ oun. Ṣe Ọlọrun yoo wa da lohun, ti o ba ṣe eyi? Mo gbagbọ pe ko ba da lohun ti o ba ṣe bẹẹ.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igba kan wa ti o gbadura si Ọlọrun fun omi bi o ti n ku lọ, ti O si da lohun. O jẹ ki omi jade lati inu ilẹ wa fun un lati mu. Omi yi si di orisun omi ti awọn miran pẹlu bẹrẹ si ni jẹ igbadun rẹ lati igba naa lọ. Nitorina, ti o ba jẹ wipe o bere fun oju tuntun lọwọ Ọlọrun ni, ko ba da lohun tabi ki O fi ọna ti yoo gba gbe aye lati ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ han, bi o tilẹ jẹ wipe ko ni oju. (Wo: Onídájọ́ 15:18-19)

Ṣugbọn Samusoni ko sọ fun Ọlọrun pe ki O mu oun padabọsipo lọna yi. Nṣe ni o bere fun iku dipo eyi. Idi si ni pe o ti sọ ireti nu lori gbigbe aye lati da nkan Ọlọrun fẹ ki o da. Ti awa naa, bi tirẹ, ba sọ ireti nu lori ki a da nkan ti Ọlọrun fẹ ki a da laye yi nitori awọn idojukọ wa tabi nitori awọn iriri ikuna ti a ti ni, nṣe ni a o ma ti ilẹkun imupadabọsipo Ọlọrun mọ ara wa. Nipa bayi, ete rere rẹ fun aye wa ko ni lalai wa si imuṣẹ.

Nitorina, ma ṣe sọ ireti rẹ lori aye rẹ tabi ninu Ọlọrun nu fun idi kankan. Dipo eyi, nṣe ni ki o ma fi igba gbogbo ran ara rẹ leti ẹṣẹ Iwe mimọ ti o wa loke yẹn, ti o n sọ fun wa pe bi olododo eniyan ba tilẹ ṣubu ni igba meje, yoo dide pada. Iwo naa yoo dide pada, bi o ti wu ki awọn iriri iṣubu tabi ikuna ti o ti ni laye ri. Ranti pe idi ti arabinrin onisun-ẹjẹ yẹn ko ṣe ku si ipo ti o wa ni pe ko sọ ireti nu, bi o tilẹ jẹ wipe awọn dọkita ti wọn n mojuto yan-an jẹ lọna ti o buru jọjọ (Máàkù 5:25-34). Nitorina, iwọ naa ko gbọdọ sọ ireti nu. Njẹ ki a fun ọ ni okun ti o peye lati ma sọ ireti nu laye yi titi gbogbo ete rere Ọlọrun fun ọ yoo fi wa si imuṣẹ. Amin.

A kú oṣù Èrèlé 2026.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má sọ ìrètí nù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Erele 01, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 40 Read More »

Àkórí: Àlàáfíà wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 25, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 39

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, oṣu Sẹrẹ 2026. Adura mi ni pe ki alaafia Ọlọrun ti o kọja gbogbo oye eniyan ma a fi igba gbogbo jọba ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti yoo jẹ ki alaafia Ọlọrun jọba ninu aye rẹ ni ki o fi tọkan-tọkan tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ awọn adari ti O yan le ọ lori ninu ijọ rẹ. Ni igba kan ti Jesu Oluwa wa n ran awọn ọmọ ẹyin rẹ lati lọ waasu, O sọ eyi fun wọn:

“Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi. Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin. Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.” (Lúùkù 10:5-7)

Ki ni yoo jẹ ki alaafia awọn iranṣẹ Kirisiti sọkalẹ sori awọn ti wọn n waasu si ati ti wọn n gbadura fun? Iha ti awọn eniyan naa ba kọ si wọn ni! Iha wo si ni o yẹ ki wọn kọ si wọn? Nṣe ni o yẹ ki wọn fi tọkan-tọkan tẹwọgba wọn ati iṣẹ iranṣẹ wọn.

Bawo wa ni a ṣe le fi han pe a tẹwọgba enikan ati iṣẹ iranṣẹ ẹni naa tọkan-tọkan? Akọkọ, a le ṣe eyi nipa mimu ọrọ Ọlọrun ti ẹni naa n kọ wa ni ọkunkundun. Ti a ko ba mu ọrọ Ọlọrun ti ẹni naa n kọ wa ni ọkunkundun, a ko le sọ wipe a tẹwọgba irufẹ ẹni naa ati iṣẹ iranṣẹ rẹ.

Ekeji, a le fi han pe a tẹwọgba awọn iranṣẹ Kirisiti ti a ran si wa tọkan-tọkan nipa ṣiṣe ‘Amin’ si adura wọn. Bi Jesu ti ṣe fi han wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, gbolohun adura awọn iranṣẹ rẹ ko ni ṣadede ṣiṣẹ ninu aye wa, nitoripe wọn kan gbadura fun wa. Gbolohun adura wa yoo ṣiṣẹ ninu aye wa ni ibamu pẹlu bi a ba ti ṣe fi tọkan-tọkan ṣe ‘Amin’ si adura naa too. Aijẹbẹ, alaafia wọn, alaafia ti o n ba awọn adura wọn fun wa rin ko ni sọkalẹ sori aye wa.

Nitorina, ti o ba ri pe adura awọn adari ijọ rẹ ko ma ṣiṣẹ fun ọ rara tabi to, o le jẹ wipe ọkan rẹ ko tọ si wọn ni. Nse ni ki o wa ba ara rẹ sọrọ lori eyi, ki o si jẹ ki ọkan rẹ wa ni pipe pẹlu wọn lati le ma a fi igba gbogbo ri alaafia wọn gba, alaafia ti o n ba iṣẹ iranṣẹ wọn rin. Aijẹbẹ, wa ijọ miran lati darapọ mọ.

Nkan ikẹta ti yoo fi han pe a tẹwọgba awọn iranṣẹ Kirisiti ti O ran si wa ni ki a ma a fi nkan ini wa gbe wọn ni igbọnwọ. Bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli ti o wa loke yẹn, Jesu ṣe apejuwe ẹnikẹni ti o ba bọ awọn iranṣẹ rẹ, ti o si tun fun wọn ni ile gbe, gẹgẹ bi ẹni alaafia. Nitorina, ko ki i ṣe nipa ṣiṣe ‘Amin’ si adura awọn adari ijọ wa nikan ni a le gba jẹ ki alaafia Ọlọrun ti wọn n polongo sọkalẹ sori aye wa. A tun le jẹ ki o sọkalẹ sori aye wa nipa titọju wọn. Ibi ti a ba si ti n ṣe eyi, awọn adura ti wọn gba ni kẹlẹkẹlẹ ati ikọkọ paapaa yoo wa wa kan, yoo si ṣe wa loore.

Wayi o, ko si ẹnikẹni ti o le sọ bi iha ti a kọ si awọn iransẹ Kirisiti ti a ran si wa yoo ṣe ran alaafia ati iṣoriire re wa laye to si. Ka nkan ti a sọ lori arabinrin Ṣunemu ti o tọju Eliṣa ati lori bi ṣiṣe eyi ṣe ran idile rẹ lọwọ (2Àwọn Ọba 4&8). Eyi yoo la ọ lọyẹ lori bi alaafia Ọlọrun ti awọn iranṣẹ rẹ n pe sinu aye wa nipasẹ awọn iṣẹ iranṣẹ wọn ṣe le yi itan aye wa pada titi lailai. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni okun lati bẹrẹ si ni mu ọrọ yi ni ọkunkundun, ki ọkankan ninu awọn ohun rere ti O fẹ ki O ni laye yi ma ba a fo ọ ru, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àkórí: Àlàáfíà wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 25, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 39 Read More »

Àwọn ọlọ́lá Tẹ́kóà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 18, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, oṣu Sẹ́rẹ́ 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n di ọ lọwọ lati wulo fun un, ki o ma ba padanu ipo rẹ tabi ere rẹ ninu ijọba rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ru ọkunrin kan ti a n pe ni Nehemáyà soke ni asiko kan lati dari awọn eniyan Juda lati tun odi Jerusalẹmu mọ. Nigba ti o si ba wọn eniyan yi sọrọ nipa rẹ, gbogbo wọn bẹrẹ si ni ṣiṣẹ, ẹnikọọkan n ṣe iṣẹ yi ni ibi ti o ti sunmọ-ọn ju. Ki ni idi? Idi ni pe iṣẹ yi pe gbogbo wọn – iṣẹ yi wa fun anfaani gbogbo awọn eniyan Juda. (Wo: Nehemáyà 2&3)

Amọ ṣa o, awọn kan laarin wọn kọ lati darapọ mọ wọn lati ṣe iṣẹ yi. Wo nkan ti a sọ nipa wọn:

“Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn.” (Nehemáyà 3:5)

Ki ni idi ti awọn ọlọla Tẹkoa ko ṣe darapọ mọ awọn yoku lati tun odi Jerusalẹmu mọ? A ko fun wa ni idahun kankan si eyi ninu akọsilẹ naa. O le je igberaga ni o fa a. Tabi kẹ, o le jẹ wipe awọn naa n jere lati ara bi nkan ti ṣe ri fun odi yi ni asiko naa, ki wọn ma a jere lati ara idamu awọn eniyan wọn. A ko mọ idi ni pato.

Amọ ṣa o, a mọ odi Jerusalẹmu, a si tun pari rẹ ni kiakia, laarin ọjọ meji-le-ni-aadota (Nehemáyà 6:15). A pari awọn odi yi, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọta awọn eniyan Juda n gbogun ti wọn. Bẹẹni, a mọ awọn odi yi tan lalai si ọwọ awọn ọlọla Tẹkoa nibẹ. Ṣugbọn yoo wa ninu akọsilẹ titi lailai pe nigba ti awọn eniyan Ọlọrun n ṣiṣẹ lati tun odi ilu Ọlọrun, Jerusalẹmu, mọ ati lati fi opin si iriri ẹgan ti wọn n ni, awọn ọlọla Tẹkoa ko kopa nibẹ.

Wayi o, ẹkọ wo ni a ri kọ lati ara eyi? Ohun naa ni pe yala a dara mọ awọn eniyan Ọlọrun yoku, paapaa julọ awọn ti ijọ wa, lati ṣe iṣẹ Ọlọrun tabi a ko dara pọ mọ wọn, iṣẹ rẹ yoo jẹ ṣiṣe. Lotitọ, o le ni oniruuru idi tabi awawi lati ma ko ipa tirẹ ni ṣiṣe iṣẹ Ọlọrun. Iṣẹ rẹ yoo jẹ ṣiṣe, sibẹsibẹ. Amọ yoo wa ninu akọsilẹ pe o ko yọju nigba ti awọn yoku n ṣe iṣẹ rẹ.

Ṣe Ọlọrun, yoo wa pin ọ lere fun iṣẹ ti o ko ṣe fun un bi? Rara o! Nitorina, gbe gbogbo awawi ti o n ṣe lati ma ko ipa tirẹ ni ṣiṣe iṣẹ Ọlọrun ju sọnu, ki o si bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ naa tọkan-tọkan. Njẹ ki O ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ṣe iṣẹ rẹ ni ọna ti yoo gba pin ọ ni ere. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àwọn ọlọ́lá Tẹ́kóà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 18, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 38 Read More »

Àwọn ènìyàn tí o nílò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu ete rere rẹ fun aye rẹ fun ọdun yi ṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati bẹrẹ si ni gbadura pe ki Ọlọrun la ọna fun gbogbo awọn eniyan ti o nilo fun ete rere rẹ lati wa si imuṣẹ ninu aye rẹ lati bẹrẹ si ni tọ ọ wa lalai si idaduro. Aijẹbẹ, ọdun yii le kọja lọ, ti ete rẹ ko si ni wa si imuṣẹ ninu aye rẹ.

Ki ni o fa ti Dafidi fi le di ọba lori Isiraẹli, pẹlu gbogbo nkan ti Ọba Sọọlu ṣe lati doju ija kọ ati lati pa a run? Idi kan pataki fun eyi ni pe Ọlọrun la ọna fun awọn eniyan ti o tọ lati wọ inu aye rẹ wa ni asiko ti o yẹ. Fun apẹrẹ, ni kete ti o pa Goliati ni Jonatani wọ inu aye rẹ wa. Ọkunrin yi ṣi ṣetan lati ku ki o ba a le di ọba, bi o tilẹ jẹ wipe ọkan lara awọn arẹmọ Ọba Sọọlu ni oun funrarẹ jẹ.

Lafikun, bi a ti ṣe fi han wa ninu 1Kironika 11 ati 12, Dafidi ni oniruuru awọn akọni jagunjagun ti Ọlọrun ran si lati fi ẹsẹ rẹ mulẹ gẹgẹ bi ọba lori Isiraẹli. Awọn eniyan wọnyi si wa fi ara wọn jin fun debi wipe ti o ba kan da nkankan gẹgẹ bi aba, nṣe ni wọn yoo gba bi aṣẹ, ti wọn yoo si ṣiṣẹ le lori, bi o tilẹ jẹ wipe eyi le la ẹmi wọn lọ. Abalajọ ti ijọba Isiraẹli ṣe wa ni ailewu ni abẹ iṣedari rẹ, lẹyin igba ti Ọlọrun ti pada fi si ori itẹ.

Siwaju si, ki ni idi ti iyinrere Jesu Kirisiti si ṣe n lọ si ibi gbogbo ni agbaye loni? Idi ni pe lati ibẹrẹ-pẹpẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ ni Ọlọrun ti n fun ni awọn ọkunrin ati obinrin ti o ṣe fọkantan gẹgẹ bi ọmọlẹyin rẹ. A si ri lara awọn wọnyi awọn ti wọn ṣetan lati padanu ẹmi wọn ni mimu iyinrere rẹ lọ si opin aye, ki a ba a le tipasẹ rẹ gba ọpọ eniyan la.

Nitorina, fun ete Ọlọrun lati wa si imuṣẹ ninu aye wa lẹkunrẹrẹ, awọn eniyan kan ti O ti yan lati ran wa lọwọ gbọdọ tọ wa wa ni asiko, ki wọn si fi tọkan-tọkan ṣe ifẹ rẹ ninu aye wa. O wa ṣeni laanu pe ọpọ aye, ile, okowo ati ijọ ni ko ma a ni iriri imusẹ ete Ọlọrun ninu wọn loni nitori pe awọn eniyan ti o tọ ko si ninu wọn. Ti awa naa ko ba wa fẹ padanu imuṣẹ ete Ọlọrun ninu aye wa, a gbọdọ bẹrẹ si ni gbadura si i pe ki O la ọna fun gbogbo awọn oluranlọwọ ti O ti yan fun wa lati tọ wa wa ni kiakia. Mo si gbadura pe ki gbogbo irufẹ awọn eniyan yi bẹrẹ si ni wọle sinu aye rẹ lati mu ete Ọlọrun ṣẹ ninu rẹ ni kiakia, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àwọn ènìyàn tí o nílò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 37 Read More »

Má wá lọ́wọ̀ ò fò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 04, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 36

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kinni ninu oṣu kinni ọdun tuntun yi, ọdun 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o pọ si gidigidi ni iwulo ni ọwọ rẹ ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti awọn ọrọ Pọọlu kan ti o sọ wipe:

“Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro.” (1Kọ́ríntì 14:26)

Ki ni nkan ti a ri kọ lati ara nkan ti apọsiteli yi sọ nibiyi? Akọkọ, oun naa ni pe o yẹ ki ẹnikọọkan wa ni nkankan ti yoo fi bukun fun awa yoku nigbakigba ti a ba pade fun ipade ijọ wa. Eyi jasi pe ko yẹ ki a wa fun ipade ijọ kankan lati kan jẹ alabukun fun lati ipasẹ awọn miran ṣugbọn lati tun jẹ ẹni ti yoo bukun fun awọn miran pẹlu.

Nitorina, igbakugba ti o ba n bọ ni ipade ijọ kan tabi omiran ni ọdun yi, ri daju pe o ni nkankan pẹlu rẹ lati fi bukun fun awa yoku. O le jẹ ọrọ iwuri. O le jẹ ọrọ adura tabi isọtẹlẹ. O si le jẹ ẹbun kan tabi omiran. Ṣa a ri daju pe o ko wa ni ọwọ ofo ṣugbọn pẹlu nkan kan ti yoo jasi ibukun fun awa yoku. Ki Ọlọrun si fun ọ ni okun lati le jẹ olotitọ ni ṣiṣe eyi. Amin.

Nkan ekeji ti a kọ lati ara nkan ti Pọọlu sọ ninu ẹsẹ bibeli yẹn ni pe ohunkohun ti ẹnikẹni ninu wa ba ṣe ninu awọn ipade ijọ wa gbọdọ wa fun igbero awọn miran. Nitorina, a ko gbọdọ ri ọkankan ninu wa ti yoo sọ tabi ṣe ohunkohun ti yoo pa igbagbọ, aye tabi ile awọn miran lara tabi run ninu ọkankan ninu awọn awọn ipade wa. Dipo eyi, ohun gbogbo ti a o ma ṣe tabi sọ gbọdọ jẹ eyi ti a mọ-ọn-mọ sọ lati bukun fun awọn yoku wa ati lati gbe wọn ro. Ti ko ba si da ọ loju pe o ko ni sọ tabi ṣe ohunkohun ti ko ni pa ẹlomiran lara ninu awọn ipade wa, yoo ṣan ki o kuku joko si ile.

Wayi o, mo mọ pe ko ni wu ọ lati kan joko si ile ni igba yowu ti a ba n ni ipade gẹgẹ bi ijọ ni ọdun yi, ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun nitootọ. Dipo eyi, ti Ọlọrun ba fẹ, nṣe ni iwọ yoo fẹ lati wa ninu gbogbo ipade ti a ba ni. Nitorina, gbadura pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati le kopa ninu gbogbo ipade ti a o ma ni ni ọna ti ohun gbogbo ti iwọ yoo ma sọ tabi ṣe yoo fi jẹ eyi ti yoo bukun fun gbogbo wa. Yoo si ri bẹ ẹ fun ọ ni gbogbo ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

A ku ọdun tuntun o.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má wá lọ́wọ̀ ò fò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 04, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 36 Read More »