Kọ́kọ́ yanjú ìṣòro ti ara rẹ ná | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹna 01, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 44
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kẹta ọdun yi, oṣu Ẹrẹ́nà 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe atunṣe ohun gbogbo ti ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ninu aye rẹ, ki ifarahan ibukun rẹ ninu aye rẹ ma ba ni idena mọ. Amin.
Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe awọn asiko kan a ma wa ti awọn ibukun Ọlọrun kan le ma jẹyọ ninu aye wa nitoripe awọn nkan kan ti ko bojumu ninu aye wa nilo amojuto. A wa le ma kọbiara si awọn nkan ti ko bojumu wọnyi, ki a ba a le fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun lati mojuto wọn. Dipo bẹ, o le jẹ wipe awọn nkan ti ko bojumu ninu aye awọn miran ti o wa ni ayika wa ni oju wa yoo wa lara rẹ. Ti a ko ba si yi oju wa kuro lara awọn nkan ti ko bojumu ninu aye awọn miran si awọn nkan ti ko bojumu ninu aye waa, ki a ba a le mojuto wọn, ifarahan awọn ibukun Ọlọrun kan ko ni dẹkun lati ma fo wa ru.
Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ eyi fun wọn:
“Etiṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ ko kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ. Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.” (Mátíù 7:3-5)
Njẹ o ri bayẹn? A le mura si ṣiṣe agbeyẹwo iṣoro aye awọn miran, ki a si kuna lati kọkọ mojuto awọn iṣoro aye ti awa funralara wa, awọn iṣoro ti o ṣeeṣe ki o tobi ju ti wọn lọ. Agabagebe si ni a n pe eyi. Agabagebe ni nitori pe ti a ko ba kọkọ mojuto awọn iṣoro aye wa ti o ga, a ko le ran awọn miran lọwọ lati mojuto awọn iṣoro pẹẹ-pẹẹ-pẹẹ inu aye wọn.
Nitorina, dipo ti iwọ yoo fi ma fi asiko rẹ ṣofo lori gbigbe awọn nkan ti ko bojumu ninu aye awọn ti o wa ni ayika rẹ wo, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni ba Ọlọrun sọrọ lori awọn nkan ti ko bojumu ti o ti ri ninu aye ara rẹ. Bi o si ṣe n ṣe eyi, aanu rẹ yoo ṣan lọpọlọpọ si ọdọ rẹ fun imupadabọsipo rẹ.
Fun apẹrẹ, nigba ti Dafidi ati awọn eniyan rẹ n sa lọ fun Abusalomu, ọkunrin kan ti a n pe ni Ṣimei bẹrẹ si ni ṣepe fun ati oun ati awọn oṣiṣẹ ijọba rẹ, o si tun n lẹ wọn ni okuta. Nigba ti ọkan lara awọn jagungun rẹ si tọrọ fun aaye lati lo ge ori ọkunrin naa danu, Dafidi ba a wi. Ki ni idi? Idi ni pe Ṣimei ko ni ọlọtẹ ti o le jade kuro ni aafin rẹ. Ọmọkunrin rẹ gagan, Abusalomu, ni o le jade. Abusalomu si le e le jade kuro ni aafin rẹ lọna yi nitoripe o kuna gẹgẹ bi baba. (Wo: 2Sámúẹ́lì 16:5-13)
Ti a ba wa ri ẹnikẹnu ti Dafidi nilo lati mojuto ọrọ rẹ ni asiko naa, ara rẹ ni, ko ki i ṣe Ṣimei. Nkan ti o si ṣe gẹlẹ niyẹn. O gbajumọ rironu nipa ikuna ara rẹ gẹgẹ bi baba ati gbigbadura si Ọlọrun fun aanu. Ṣe Ọlọrun wa a da lohun tabi ko da lohun? O da lohun.
Nitorina, ti a ba fẹ ki aanu ati ojurere Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa lalai si idena, a nilo lati kọkọ gbajumọ amojuto awọn nkan ti o wa ninu aye wa ti ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, dipo ti a o fi gbajumọ sisọ ọrọ lori awọn nkan ti ko bojumọ ninu aye awọn miran. Njẹ ki ẹmi Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun wa ni okun ti a nilo lati ṣe eyi, ki ọkankan ninu awọn ibukun ti o yẹ fun aye wa ma ba a fo wa ru mọ. Amin.
Kí o ní oṣù Ẹrẹ́nà 2026 tí ó lárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)