Author name: 23?Racing_Horse

Kíni ìdí tí a fi fi ipá báalòpọ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 25, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 8

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Okudu 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba pa ọ mọ ki ifẹ awọn ọna ti awọn ti aye yi n tọ ma ba gba ọkan rẹ, ki o ma ba ko ara rẹ sinu itiju tabi iparun, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, igba kan wa ti ọmọ-ọba kan ti a n pe ni Ṣẹkẹmu fi ipa ba Dina, ọmọbinrin Jakọbu, lo pọ. Lẹyin-ọ-rẹyin, eyi si wa jẹ ki awọn ẹgbọn rẹ, Lefi ati Simeoni, jade lati gbẹsan nipa pipa gbogbo ilu ọmọ-ọba yi run. Nitorina, ko ki i ṣe nkan tuntun ni ki awọn eniyan fi ipa ba eniyan lopọ. Ko si ki i ṣe nkan tuntun naa ni ki awọn eniyan gbe gbogbo igbesẹ ti wọn ni agbara lati gbe, eyi ti o le yọri si ki wọn pa gbogbo ẹbi, ilu tabi ẹya kan run, lati gbẹsan ẹṣẹ ẹnikanṣoṣo. Nitorina, ki o to ṣe ika fun ẹnikẹni, ma fi gbogbo igba ranti pe ko ki i ṣe gbogbo eniyan naa ni o ma n fi igbẹsan silẹ fun Ọlọrun. Awọn miran le lọ debi wipe ki wọn fi iya jẹ gbogbo idile rẹ nitori ẹṣẹ rẹ si wọn. (Wo: Jẹnẹsis 34)

Ṣugbọn ṣa, bawo ni Dina ṣe di ẹni ti ọkunrin yi n fi ipa balopọ? Bibeli dahun eyi fun wa nipa sisọ pe, “Dina ọmọbinirin Lia, ti o bi fun Jakọbu si jade lọ lati wo awọn ọmọbinrin ilu naa. Nigba ti Ṣẹkẹmu, ọmọ Hamori, ara Hifi, ọmọ ọba ilu naa ri i, o mu un, o fi ipa baa lo pọ, o si ba a jẹ, o sọ ọ di alaimọ.” (Jẹnẹsisi 34:1-2) A jẹ pe nkan ti o fi aye gba Ṣẹkẹmu lati ri nkan ṣe si Dina ni pe o fi ile baba rẹ silẹ lati lọ bẹ awọn ọmọbinrin ilẹ naa wo. Ti ko ba fi ile baba rẹ silẹ lati lọ da nkan pọ mọ awọn ọmọge ilẹ naa ni, ko ba ma ti lugbadi ifipabanilopọ.

Kini eyi n sọ fun ọ? Ohun naa ni pe o ye ki o mọ irufẹ ibi ti ori rẹ yoo jẹ ki ẹsẹ rẹ gbe ọ lọ. Ko ki i ṣe ibi gbogbo naa ni o wa ni ailewu fun ọ lati lọ. Ko ki i ṣe gbogbo ọrẹ tabi alabajọṣiṣẹpọ naa ni ko si ewu fun ọ lati bẹ wo. Nitorina, ki o to bẹrẹ si ni bẹ awọn eniyan wo tabi ba wọn jade, ri daju pe o mọ bi ibi ti wọn n mu ọ lọ ṣe jẹ ailewu fun ọ si. Ti o ko ba mọ daju pe ibi ti o n lọ ko ni wu ọ ni ewu, iyẹn ti ko ba si nkan miran n bẹ, o yẹ ki o mọ pe lilọ si ibẹ ko to nkan ti o yẹ ki gbẹmi ara rẹ le lori, ti ko ba ki i ṣe iyinrere Jesu ni o n gbe ọ lọ si ibẹ.

Njẹ o tilẹ mọ pe awọn ibi kan wa ti ko yẹ ki o mu iyinrere Jesu lọ, ti ko ba jẹ wipe o gba aṣẹ taara-taara lati ọdọ Oluwa lati ṣe bẹ ẹ? A ri ka ninu iwe mimọ pe Ẹmi Kirisiti kọ fun Apọsiteli Pọọlu ati awọn akẹgbẹ rẹ lati lọ waasu ni awọn ibikan. Kini idi? A ko sọ fun wa. Ṣe o wa le jẹ wipe Ọlọrun ko fẹ ki awọn ti o wa ni awọn ibi wọnyi di ẹni igbala ni? Rara, ko jẹ jẹ bẹẹ. Idi si ni pe bibeli sọ fun wa pe Ọlọrun fẹ ki a gba gbogbo eniyan la. (Wo: Iṣe Apọsiteli 16:6-8; 1Timoti 2:3-4)

Ki lo wa fa, nigbana, ti O fi kọ fun awọn ọkunrin yi lati wọ awọn ibi ti a sọ yi lọ lati waasu iyinrere ninu wọn? O le jẹ wipe o ṣeeṣe ki ewu wu wọn nibẹ ni asiko yi. Nitorina, ki iwọ, gẹgẹ bi ọkunrin, to bẹrẹ si ni mu iyinrere lọ si ọdọ awọn aṣewo ni ile itura wọn, ri daju pe o gbọ daradara lati ẹnu Ọlọrun. Ki iwọ naa pẹlu, gẹgẹ bi obinrin, to bẹrẹ si ni mu iyinrere tọ awọn ẹru-iku igbooro lọ ni abẹtẹ wọn, ri daju pe Ẹmi Ọlọrun ni o n dari rẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki iwọ naa lugbadi irufẹ nkan ti o ṣe Dina Jakọbu.

Nikukuru, bi a tilẹ ṣe ri ni ti ọrọ Dina, ko jade tọ awọn ọmọbinrin ilu naa lọ nitoripe o fẹ yi wọn pada kuro ninu ibọriṣa sọdọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, o lọ lati ki wọn ni. Eyi tunmọ si pe o ri wọn gẹgẹ bi ọrẹ, o si fẹ wa pẹlu wọn. O tilẹ ṣeeṣe ki o jẹ pe bi o ti ṣe da wa nile ni o su u ni ọjọ ti a n wi yi, ti o si wo pe ki oun kuro ni ile wọn ti ko ni arinrin, ile ti awẹjẹ-wẹmu ko ma lọ nibẹ, ile ti ko si orin taka-sufe lati jo si nibẹ ati ti ko si tun si awọn adẹrin poṣonu nibẹ lati jẹ ki eniyan gbagbe ibanujẹ rẹ. Ṣugbọn nigba ti ilẹ ọjọ yi yoo fi su, o ti wa ye oun gan funrarẹ pe ile wọn ti ko dun yẹn gan ni ibikan ṣoṣo ti ewu ko ti le wu ninu ilu naa.

Loni, a ni ọpọlọpọ Kirisitiẹni, paapaa julọ awọn ti o jẹ obinrin, ti awọn naa, bi Dina Jakọbu, ro wipe ilana ijọba Ọlọrun ko tasánsán to. Nitorina, wọn fẹ tọ diẹ wo lara iṣesi ti awọn ti aye yi. Rara o, awọn ko ṣetan lati rin ni ihoho wọ ọja bi ti wọn tabi lọ si awọn patí alẹ bi ti wọn tabi ko awọn ọrẹkunrin tabi ọrẹbinrin jọ bi ti wọn. Ṣugbọn wọn ṣa a fẹ tọ diẹ wo lara nkan ti wọn n ṣe. Eyi si ma n farahan ninu bi wọn ti ṣe n mura ati ninu iṣesi wọn nigba ti wọn ko ba si ninu awọn ipade ijọ wọn ati nipa ọna ti wọn n gba lo awọn ohun elo ibaraẹni-sọrọ ti ori ẹrọ ayelujara.

Wayi o, ko si ni ki irufẹ awọn eniyan yi, ti a ko ba ṣaanu fun wọn, ma fẹrẹ run aye wọn lọna kan tabi omiran bi Dina Jakọbu. Nigba ti eyi ba si ti wa ri bẹ ẹ tan, ohun gbogbo ti wọn ti n lakaka lati pa mọ ninu aye wọn ni wọn yo padanu laarin iṣẹju aaya. O wa le je wipe itiju ti yoo tẹle eyi gan ni yoo kuku fi idi iparun wọn mulẹ. Nitorina, ki o to gbesẹ rẹ jade kuro ninu aala aṣẹ Ọlọrun fun ọ, má ronú nìkan nipa ohun ti yoo jẹ èrè re nipa ṣiṣe bẹ, ṣugbọn tun ronu nipa ohun ti o o padanu nipa ṣiṣe e. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o fi agọ̀ tabi agídí sar lọ si ibikibi ti a o ti pa ọ run. Amin.

Ki o ni ọsẹ alayọ.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kíni ìdí tí a fi fi ipá báalòpọ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 25, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 8 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Àkórí: Ìmọrírì ń móríyá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 18, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 7

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Okudu 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba dari rẹ lati gbe awọn igbesẹ ati lati ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki awọn eniyan ma dupẹ lọwọ rẹ nitori rẹ ati ti yoo jẹ ki wọn ma gbadura fun ọ. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti yoo ti awọn eniyan lati dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aye rẹ ati lati gbadura tọkan-tọkan fun ọ ni ififunni ti a ṣe lọna ti o yẹ (2Kọrinti 9:12-14). Lọdun melokan sẹyin, mo pese akọsilẹ kan fun ẹkọ bibeli fun ijọ Ọlọrun kan ti mo n lọ nigbanna. Lẹyin ọjọ melokan ti oniruru ẹgbẹ ti o wa ninu ijọ yi ti lo akọsilẹ yi fun awọn ipade ẹkọ bibeli wọn, ṣa dede ni ọkan lara awọn adari awọn ẹgbẹ naa fi ẹbun kan ranṣẹ si mi.

Ki lo wa fa ti adari ẹgbẹ yi ṣe fi ẹbun naa ranṣẹ si mi? Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, bi o ti n ka akọsilẹ ẹkọ bibeli ti mo pese yi, nṣe ni Ẹmi Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri otitọ bibeli kan ti o ṣe igbagbọ rẹ ni anfaani ni ọna ti o ga. Nitorina, nibi ti o ti n kan ẹkọ yi gangan naa ni o ti pinnu pe oun yo fun ẹni ti o pese akọsilẹ ẹkọ naa ni ebun. O si ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Iha wo ni mo wa kọ si eyi? Akọkọ na, mo dahun pẹlu ọpẹ si Ọlọrun. Mo dupẹ lọwọ rẹ fun bi O ti ṣe fun mi ni ọrọ lati le bukun awọn eniyan rẹ. Mo tun dupẹ lọwọ rẹ fun bi O ti jẹ ki nkan ti mo n ṣe bukun fun o kere ju ẹnikan. Mo tun wa dupẹ lọwọ rẹ fun bi O ti ṣe ti ẹni yi lati bukun fun mi pẹlu ẹbun naa. Ti ko ba ṣe pe o fun mi ni ẹbun ni tabi pe o wa sọ fun mi pe nkan ti mo kọ bukun fun oun, ko si bi mo ti fẹ mọ pe o tipasẹ nkan ti mo kọ di alabukunfun. O wa ṣeeṣe ki a ri awọn miran ninu ijọ yi ti a bukun fun awọn naa nipasẹ akọsilẹ ẹkọ bibeli yi kanna. Amọ mi o le mọ wọn titi a o fi de ọrun. Idi ti mi o si fi ni mọ wọn afi igba ti a ba de ọrun ni pe wọn ko yọju lati mọ riri mi fun bi Ọlọrun ti ṣe lo mi lati bukun fun wọn.

Ni kukuru, ẹni ti o yọju lati fi imọriri han si mi pẹlu ẹbun mu ara mi ya lati dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori rẹ. Lafikun, o tun fun mi ni iwuri lati gbadura fun un. Iwọ naa mọ pe bi ẹnikan ba jọ wa loju pẹlu ẹbun rẹ, paapaa julọ nigba ti a ko reti rẹ, o pọn dandan ki a bẹrẹ si ni gbadura fun iru ẹni bẹ lẹsẹkẹsẹ. Irufẹ adura bayi si ma n jẹ adura atọkanwa. Nitorina, o di dandan ki o ṣiṣẹ agbara, niwọn igba ti o ba ti wa ni bamu pẹlu ifẹ Ọlọrun.

Wayi o, yatọ si pe ẹni yi ru mi soke lati gbadura fun nipasẹ ẹbun rẹ, o tun gbin irugbin imoriya sinu ọkan mi laitilẹ mọ. Ti o ba mọ pe nkan ti o n ṣe ko ja si asan ati pe o n bukun fun o kere ju ẹnikan, ti o si n jẹ ki ẹni naa fẹ di ẹni ti o n bukun fun awọn miran, o di dandan ki ara ya ọ lati tẹramọ nkan naa ti o n ṣe. A si ri awọn kan ti wọn ti tẹsiwaju ninu aye wọn lọna yi lati lọ jẹ ibukun fun ẹgbẹlẹgbẹ eniyan nipasẹ iwuri ti wọn rigba lati ọdọ ẹnikan ṣoṣo pere.

Ki ni koko ọrọ mi? Oun naa ni pe o nilo lati kọ bi a ti ṣe n mọ riri ẹnikẹni ti Ọlọrun ba n lo lati bukun fun ọ, paapaa julọ ninu ijọ. Ti o ba si wa jẹ pe iwọ nikan ṣoṣo ni yoo fi imọriri han si ẹni yi laarin gbogbo awọn ti Ọlọrun n lo wọn lati bukun fun, ri daju pe o ṣe bẹẹ. Idi si ni pe o le sọ bi imọriri rẹ yoo ṣe rin to ni jijẹ ki ẹni naa di ẹni ti o wulo ati ti o tun jẹ olododo si ninu ṣiṣe ifẹ Ọlọrun.

Ninu lẹta rẹ si awọn ara Filipi, Pọọlu sọrọ nipa bi oun ti ṣe ma n dupẹ lọwọ Ọlọrun ni igba gbogbo ti o ba ranti wọn ati bi o ti ṣe ma n fi ayọ gbadura fun wọn. O tilẹ mọ-ọn-mọ gbadura fun wọn ninu lẹta rẹ yi pe ki Ọlọrun pese fun gbogbo aini wọn lati inu ọrọ ologo rẹ ninu Kirisiti Jesu (Filipi 4:19). Ki ni idi? Idi ni pe awọn ara yi jẹwọ ara wọn leralera pe awọn mọ riri iṣẹ iranṣẹ rẹ ati awọn nkan ti Ọlọrun n tipasẹ rẹ ṣe. Wo diẹ lara nkan ti o sọ nipa wọn ninu lẹta rẹ: “Ẹyin paapaa si mọ pẹlu, ẹyin ara Filipi, pe ni ibẹrẹ iyin rere, nigba ti mo kuro ni Makẹdonia, ko si ijọ kan ti o fun mi ni iranlọwọ owo, bi ko ṣe ẹyin nikan ṣoṣo. Nitori nigba ti mo wa ni Tẹsalonika, ẹyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ lati pese fun aini mi. Kii ṣe nitori ti emi n fẹ ẹbun naa, ṣugbọn emi n fẹ eso ti yoo maa di pupọ nitori yin.” (Filipi 4:15-17)

Njẹ o ri bayẹn? Laarin gbogbo awọn ijọ ti Ọlọrun n lo Pọọlu lati bukun fun ni asikọ yẹn, ijọ awọn ara Filipi nikan ni o n fi gbogbo igba fun ni iranlọwọ ati iwuri. Abalajọ ti inu rẹ ṣe ma n dun nigba gbogbo ti o ba ranti wọn ati ti o ba n gbadura fun wọn. Ti iwọ naa ba fẹ ki awọn ti o n mojuto ọ ninu ijọ rẹ ma fi gbogbo igba fi idunnu mojuto ọ dipo ti wọn yoo kan fi ma ṣe eyi gẹgẹ bi ojuṣe wọn lati ṣe, a jẹ wipe o gbọdọ kọ bi a ti ṣe n mọ riri wọn. Ti o ba si wa jẹ wipe iwọ nikan ṣoṣo ni yoo ma ṣe eyi, bi ti ijọ awọn ara Filipi, ṣe bẹẹ. Idi si di ni pe o ko le ṣọ ọna ti Ọlọrun le gba lo iwuri ti o n fun wọn lọwọlọwọ yi lati jẹ ki wọn ṣe iṣẹ iranṣẹ wọn ni aṣepe. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati mu ọrọ yi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Ìmọrírì ń móríyá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 18, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 7 Read More »

Wọn kò ní sinmi títí ìfẹ́ rẹ̀ yóò fi jẹ́ ṣíṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Okúdù 11, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 6

Àkórí: Wọn kò ní sinmi títí ìfẹ́ rẹ̀ yóò fi jẹ́ ṣíṣe
Láti ọwọ́: J.O. Lawal
Ọjọ́: Okúdù 11, 2023
Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀
Nọ́múbà: Vol. 12, No. 6

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lalai-lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Okudu 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun sọ gbogbo awọn ti O ti yan lati gbe o ga ji lati ma gbero lati sinmi titi wọn yoo fi ṣe ifẹ rẹ fun ọ. Amin.

Lẹyin igba ti Ruutu ti ba Boasi sọrọ lori boya yoo ṣeeṣe ki igbeyawo waye laarin wọn tabi ko ni ṣeeṣe, gẹgẹ bi iya ọkọ rẹ, Naomi, ti ṣe pa a lasẹ fun, o pada wa sile lati jẹ ki iya yi mọ bi nkan ti ṣe lọ. Nigba ti yoo si fesi, o sọ fun un pe, ”Duro, ọmọbinrin mi titi ti iwọ yoo fi mọ bi ohun gbogbo yoo ti ri. Nitori pe ọkunrin naa ko ni sinmi titi ti ọrọ naa yoo fi yanju lonii.” (Ruutu 3:18) O si wa jẹ nkan ti o jọ ni loju pe Boasi ṣe gẹgẹ bi Naomi ti ṣe sọ wipe yoo ṣe. Ko farabalẹ sinmi rara titi o fi ri daju pe ọrọ igbeyawo Ruutu di yiyanju.

Ta wa lo jẹ ki eyi ṣelẹ? Ọlọrun ni. Oun ni O tari Boasi lati ma sare lọ-sare bọ lọjọ ti a n wi yi titi Ruutu ko fi nilo lati yọnu mọ lori jijẹ opo tabi wiwa lalai ni ọmọ laye. Ti iwọ naa ba si fa aye rẹ le lọwọ, gẹgẹ bi Ruutu se ṣe, Oun naa yoo ri daju pe awọn eniyan n sare lọ-sare bọ fun ọ, ti wọn ko si ni sinmi titi wọn yoo fi fi idi rẹ mulẹ si ibi ipo isesorere, isinmi ati iṣoriire ti O ti pese silẹ fun ọ.

Lafikun, bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, aṣalẹ ọjọ ti o ku ọla ti ọta Mọdekai, iyẹn Hamani, yoo yẹgi fun, ni Ọba Ahasiwerusi ko ni isinmi titi o fi ni ki wọn ba oun gbe iwe akọsilẹ awọn nkan ti o n ṣẹlẹ ninu ijọba rẹ. Igba ti wọn si wa n ka a fun un ni o ri mọ pe oun ti fi ohun kan pataki silẹ lai ṣe. Ko fun Mọdekai ni nkankan tabi bu ọla fun lori bi o ti ṣe gba ẹmi rẹ la nigbakan sẹyin lọwọ awọn ti o fẹ gbẹmi rẹ. (Wo: Esteri 6)

Nitorina, ninu ainibalẹọkan rẹ, o ronu titi lori ọrọ yi ti ilẹ ọjọkeji fi mọ, ti Hamani si fi wọle wa lati ba a sọrọ lori bi yoo ti ṣe so Mọdẹkai rọ sori igi. Iṣẹlẹ yi si wa ni Ọlọrun lo lati doju ete Hamani delẹ. Nitorina, dipo ki o gba aṣẹ lọwọ ọba lati so Mọdekai rọ, nkan ti Hamani ri gba ni aṣẹ lati bu ọla fun un kaakiri gbogbo ilu Susa.

Kini eyi n sọ fun wa? Oun sọ fun wa pe ki Ọlọrun ba ṣetan lati bu ọla fun eniyan ati lati gbe e ga, O mọ bi yoo ṣe ta awọn ti o yẹ ki o ṣiṣẹ yi ji, bi wọn tilẹ jẹ ọta rẹ, ti ko si ni jẹ ki wọn ni ibalẹọkan titi wọn yoo fi ṣe iṣẹ naa. Eyi si ni yoo jẹ iriri rẹ ninu ọsẹ tuntun yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Ọlọrun yoo ji gbogbo awọn ti O ti yan lati gbe ọ ga ati lati bu ọla fun ṣugbọn ti wọn n sun. Yoo ji wọn, yoo si jẹ ki wọn wa ni ainifọkanbalẹ titi wọn yoo fi ṣe ifẹ rẹ fun aye rẹ.

Ti o ba wa gba eyi gbọ, nṣe ni ki o le ṣiṣe aniyan kuro ninu ọkan rẹ. Wa bẹrẹ si ni dupẹ lọwọ rẹ, ki o si tun ma fiyin fun fun ohun ti o n ṣe. Ki o si to mọ bi o ti ṣe n lọ, gbogbo awọn nkan daradara ti O n ti ṣe fun idalare ati igbega rẹ ni iwọ naa yoo bẹrẹ si ni ri ifarahan wọn, ti eyi yoo si jẹ ki awọn eniyan ma a yin orukọ mimọ rẹ nipasẹ rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọn kò ní sinmi títí ìfẹ́ rẹ̀ yóò fi jẹ́ ṣíṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Okúdù 11, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 6 Read More »

Jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ so èso | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 04, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 5

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Mo yọ pẹlu rẹ bi a ti ṣe wọ inu oṣu tuntun miran ninu ọdun yi, oṣu Òkúdù 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun kọ ọkan rẹ lati ma wa ni iduro-ṣinṣin ati lati ma yẹṣẹ ni gbigbẹkẹle ati ni ṣiṣe ifẹ rẹ, ki ọkankan ninu ohun rere gbogbo ti O fẹ ṣe ninu aye re ma ba fo ọ ru, ni orukọ Jesu. Amin.

Nigba ti O n ṣalaye owe afunrugbin ti o lọ fun irugbin rẹ, Jesu Oluwa wa sọ eyi nipa awọn ti aye wọn yoo so eso ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wọn wa: “Ṣugbọn ti ilẹ rere ni awọn ti wọn fi ọkan otitọ ati rere gbọ ọrọ naa, wọn diimu ṣinṣin, wọn si fi suuru so eso.” (Luuku 8:15) Ki ni awọn nkan ti yoo jẹ ki ọrọ Ọlọrun so awọn eso ti O fẹ ri ninu aye wa, bi Jesu Oluwa wa ti fi han wa? Akọkọ ni gbigbọ ọrọ Ọlọrun.

Bibeli sọ wipe igbagbọ ma n wa nipa gbigbọ ọrọ Kirisiti (Roomu 10:17). Nitorina, gbigbọ nkan ti Ọlọrun ni lati sọ tabi ti o n sọ ṣe pataki gidigidi. Igba ti a ba si to gbọ ohun ti O n sọ nipa ara rẹ, nipa aye wa ati nipa ọrọ aye wa ni a to le reti pe ki a gbẹkẹle lati tọju wa tabi reti pe ki a mọ ohun ti O fẹ lati ọdọ wa. Nitorina, ti aye wa yoo ba so eso igbagbọ ninu Ọlọrun ati eso ohun ti Ọlọrun fẹ, a gbọdọ gbọ ọrọ igbagbọ ninu rẹ ati ọrọ ti yoo fi ifẹ rẹ fun aye wa han. Eyi jasi pe, a gbọdọ fun irugbin igbagbọ ninu rẹ ati irugbin ifẹ rẹ sinu ọkan wa. Aijẹbẹ, ko le si ikore ohun ti a ko gbin.

Nkan keji ti yoo jẹ ki ọrọ Ọlọrun so eso ninu ọkan wa ni ki ọkan wa diimu ṣinṣin. Ọtọ ni ki a fun irugbin si ori ilẹ kan; ọtọ tun si ni ki ilẹ naa fi aaye gba. Ti ipo ti ilẹ naa wa ko ba fi aaye gba irugbin yi lati gberu ati lati dagba so eso, o di dandan ki irugbin naa ku tabi ki o kan dagba lasan lalai so eso. Bẹẹ gẹẹ, ko to fun wa lati kan gbọ ọrọ Ọlọrun; o tun ṣe pataki ki a fi aye gba a lati dagba ati lati le so eso ninu aye wa. Ti a ko ba fi aye gba ọrọ Ọlọrun lati gbe inu wa, iyẹn ti a ko ba tẹwọgba ọrọ rẹ gẹgẹ bi ohun ti a nilo lati fi ṣiṣẹ ṣe ninu aye wa, ko ni mu awọn nkan ti o yẹ ki mu jade ninu aye wa jade. Yoo kan ṣofo lasan ni, bi a ti ṣe ri aridaju rẹ ninu aye ọpọ ti o ti gbọ ọrọ rẹ ni ọpọlọpọ igba, ti aye wọn ko si tun gba iyipada nipasẹ ọrọ naa.

Nkan ẹkẹta ti yoo jẹ ki ọrọ Ọlọrun so eso ninu aye wa ni ki a fi a ma fi ifarada ṣe amulo rẹ. Wo o, bi a tilẹ fun irugbin wa si ori ilẹ ti o dara, ilẹ ti o ni ohun gbogbo ti o le jẹ ki irugbin naa ṣe daradara, a si tun gbọdọ jẹ ki irugbin naa pẹ to lori ilẹ naa lati le dagba ati lati le mu ikore wa. Bi gbogbo awọn agbẹ ti ṣe mọ, gbogbo irugbin ni o ni akoko fun iseso tirẹ. Nitorina, a gbọdọ fi suuru mojuto, ki a si tun duro de titi yoo fi ṣetan. Aijẹbẹ, nṣe ni a o parun ki asiko rẹ to to, ti a o si padanu ikore wa, ti a o si tun fi laala wa ṣofo.

Bẹẹ gẹgẹ, gbogbo irugbin ọrọ Ọlọrun ti a ba gbin si ori ọkan wa ni o ni asiko iseso tirẹ. Ti a ko ba si fẹ padunu eyi, a gbọdọ fi suuru mojuto titi yoo fi se eso. Eyi tunmọ si pe, a gbọdọ tẹsiwaju lati ma ṣe amulo rẹ, ki a si tun ma gbadura lori ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun wa nipa ara rẹ, aye wa ati ọrọ aye wa titi a o fi ri esi ṣiṣe bẹ ẹ. Pe a ko i ti ma ri esi ṣiṣe amulo ohun ti Ọlọrun sọ ko tunmọ si pe a ko ni ri i. Irugbin ọrọ kọọkan ti Ọlọrun sọ fun wa di dandan ki o dagba ninu wa, ki o si tun se eso, ti a ba fi aaye gba a. Ṣugbọn bi siso eso rẹ yoo ṣe ya si jẹ nkan ti a le ma le sọrọ le lori – o ni i ṣe pẹlu iṣesi irugbin naa ati irufẹ idojukọ ti o nilo lati mojuto ninu aye wa.

Nitorina, ti a ba fẹ ki ọrọ Ọlọrun ki o so eso ododo, iwosan ati iṣoriire ninu wa, a nilo lati fi ifarada ṣe amulo rẹ titi a o fi ri pe ododo rẹ, ilera rẹ ati iṣoriire rẹ n jẹyọ ninu aye wa lẹkunrẹrẹ. Naamani, fun apẹrẹ, nilo lati wẹ ara rẹ ninu odo Jọdani ni igba meje ki a to wẹ ẹtẹ rẹ danu. Eyi ko wa tunmọ si pe iwọ naa gbọdọ ṣe ohun ti Ọlọrun so fun ọ lori awọn ọrọ aye rẹ kan ni ẹẹmeje, ki awọn isoro naa to jẹ yiyanju. Dipo eyi, o tunmọ si pe awọn igba kan ma n wa ti o jẹ wipe ki a ṣe amulo ọrọ Ọlọrun ni ẹẹkan tabi ẹẹmeji lori awọn ọrọ aye wa kan ko to lati fun wa ni ojutu lori wọn. A nilo lati duro ṣinṣin lori ṣiṣe amulo ọrọ rẹ fun igba ti o ṣe diẹ titi awọn esi ti a fẹ ri yoo fi wọle.

Wayi o, bi a o ṣe nilo lati pe to lori ṣiṣe amulo ohun ti Ọlọrun sọ ki a ba le ri eso rẹ lori awọn ọrọ aye kan ko ma ki i ṣe nkan ti mo le sọ. Ṣugbọn mo le sọ pe ti a ko ba rẹwẹsi tabi gbe igbẹkẹle wa ninu rẹ ju sọnu, a ko ni dojuti wa. Awọn esi ti a n foju sọna si yoo wa, yoo tilẹ tun ju ireti wa lọ paapaa. Ṣugbọn ti a ba n ṣe foniku-fọlande pẹlu ṣiṣẹ amulo ọrọ rẹ, ti a n gbọlude loorekoore kuro nidi ṣiṣe amulo ọrọ rẹ, nṣe ni a n fa irugbin ọrọ rẹ tu kuro lori ilẹ ọkan wa. Nitorina, ko le si ikore. Nṣe ni a o ri pe a ti fi irugbin ọrọ rẹ ati asiko ati ifarajin awa tikarawa ṣofo. Mo si wa gbadura pe ki opin de si ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu fifi ọrọ Ọlọrun ṣofo ti o n waye lọwọlọwọ ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ire.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ so èso | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 04, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 5 Read More »

Ohungbogbo kọ́ ni búrẹ́dì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 28, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 4

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Èbìbí ati Òkúdù 2023 pọ mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki oju rẹ ṣi lati mọ ohun gbogbo ti o wa ni ọwọ rẹ ti o yẹ ki o gbin gẹgẹ bi irugbin iṣoriire ati pe ki ọkan rẹ gba okun ati itọni lati gbin awọn nkan wọnyi si ibi ti wọn yoo ti dagba, ti wọn yoo si tun mu ikore ti o ga wa fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Jesu Oluwa wa, nigbakan ti O n waasu si awọn Juu, sọ eyi: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, bi ko ṣe pe alikama ba bọ si ilẹ, ti o ba si ku, o wa ni oun nikan; ṣugbọn bi o ba ku, a si so ọpọlọpọ eso.” (Johanu 12:24) O si sọ awọn ọrọ wọnyi lati jẹ ki o ye awọn eniyan bi o ti ṣe ṣe pataki to fun un, gẹgẹ bi ọmọ bibi kan ṣoṣo Ọlọrun, lati ku ki Ọlọrun ba le ni ọpọlọpọ ọmọ ninu ogo rẹ (Heberu 2:10). Nitorina, nṣe ni ohun ti O sọ ni asiko yi n tọka si nkan ti ẹmi.

Amọ ṣa o, a ko gbọdọ gbagbe pe awọn ọrọ Oluwa wa wọnyi n kọkọ tọka si nkan ti ara, eyi ti gbogbo awọn ti o jẹ agbẹ si mọ. Agbẹ kọọkan ni o mọ pe lati sọ irugbin kan di ẹgbẹlẹgbẹ irugbin, a kọkọ gbọdọ gbin in sibikan. Eyi jasi pe, a kọkọ gbọdọ jọwọ irugbin naa fun iku. Aijẹbẹ, ko ni kuro ni irugbin kan debi pe yoo wa di ilọpọ lọwọ wa. Ṣugbọn ni kete ti a ba ti gbin sinu ilẹ ti o dara, a ti fun un ni anfaani niyẹn lati dagba ati lati sọ ara rẹ di ilọpo-ilọpo lọwọ wa.

Wayi o, ko ki i ṣe idi iṣẹ ọgbin nikan ni ilana yi ti wulo. Ko fẹrẹ si abala aye yi ti ko ti wulo. Fun apẹrẹ, ti o ba fẹ ki ọrọ rẹ pọ si, ọkan lara nkan ti o gbọdọ fi ara rẹ jin fun ni gbigbin owo rẹ sori okowo kan tabi omiran. Aijẹbẹ, ohun ti o ni ko ni pọsi. Ayafi ti yoo ba tun dinku si.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni oye nkan yi ko ye. Lotitọ, wọn fẹ pọ si ni ọrọ, ki wọn si le ṣe gbogbo awọn nkan nla ti Ọlọrun fẹ ki wọn fi owo ṣe. Nitorina, wọn a ma gbadura, gbaawẹ ati pẹlupẹlu fun awọn eniyan Ọlọrun ni nkan. Ṣugbọn wọn ko ma gbin owo ti Ọlọrun fun wọn sori okowo tabi katakara kankan, ki o ba le pada tọ wọn wa ni ilọpo-ilọpo. Dipo eyi, ni ọpọ igba, nṣe ni wọn a ko ohun gbogbo ti o ba ti ọdọ Ọlọrun tọ wọn wa jẹ, ti wọn a si tun ma duro ki O fi awọn nkan miran ranṣẹ.

Eyi ko wa le yọri si ki wọn ni ọrọ. O dara lotitọ ki a ma gbadura, nitori, nipasẹ adura, a le ri awọn ipese Ọlọrun fun wa lati gbadun aye wa gba. O si tun dara ki a ma fifun awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ Ọlọrun, nitori nipa ṣiṣe eyi, a le gba awọn iṣẹ iyanu ti yoo gba wa lọwọ iyan tabi ti yoo fun wa ni iyara lati ṣe aṣeyọri. Amọ, a tun gbọdọ ni oye pe adura ko le jẹ ki irugbin ti a ko gbin dagba. Bẹẹ si ni, awọn iṣẹ iyanu ipese kan wa ti Ọlọrun ko ki i ṣe lojoojumọ. Iṣẹ iyanu Mana gan ko waye titi lailai fun awọn ọmọ Isiraẹli. O wa si opin ni asiko kan. O wa si opin nigba ti awọn ọmọ Isiraẹli de ibi ti wọn ti le ṣiṣẹ ọgbin lati kore wara ati oyin ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn.

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ṣetan lojoojumọ lati ṣe iṣẹ iyanu lati pese ohun ti a nilo ati lati sọ wọn di ilọpo-ilọpo fun wa, O tun jẹ ki o ye wa lati ipasẹ ọrọ rẹ pe ko ki i ṣe gbogbo nkan ti O ba fun wa naa ni burẹdi fun wa lati jẹ. Apa kan lara ipese rẹ fun wa jẹ irugbin ti a nilo lati gbin, ki a ba le gbe ipese rẹ fun aye wa ro. Ṣugbọn ti a ba tẹsiwaju lati ma fi aimoye jẹ ohun ti o yẹ ki a gbin, ko si bi a o ti ṣe le sọ ipese Ọlọrun fun wa di ilọpo-ilọpo, ti a o si tun le gbe ipese rẹ fun wa ro. Nitorina, dipo ti a o fi ma fi igba gbogbo ri ikore awọn nkan ti a gbin gba, eyi ti o jẹ iṣẹ iyanu funrarẹ, nṣe ni a o kan ri pe ọpọ igba ni a o ma duro de iṣẹ iyanu ipese miran ti a o tun ko jẹ bi a ti ṣe ma n ṣe. (Wo: 2Kọrinti 9:9-10)

O wa yẹ ki iwọ naa ri bayẹn idi ti ọpọ awọn eniyan Ọlọrun ṣe ma n pada ku sinu iṣẹ. Eyi ko yẹ ki o ri bẹ rara. Ṣugbọn ko ni ye ribẹ niwọn igba ti a ko ba ti mọ ifẹ Ọlọrun fun wa lori ilọrọ wa. Ki si ni ifẹ rẹ fun wa lori ilọrọ wa? Akọkọ, ifẹ rẹ ni pe ki a fi igbẹkẹle wa sinu rẹ nikan fun ọrọ wa, nitori Oun ni O ma n fun eniyan ni amuyẹ lati di ọlọrọ. Ekeji, ifẹ rẹ ni ki a ya irugbin wa sọtọ kuro lara burẹdi wa. Ẹkẹta ni pe ki a gbin irugbin wa si ibi ti o tọ, iyẹn sori okowo ti o tọ ati sinu awọn eniyan ti o tọ. Nipa ṣiṣe eyi, aṣẹ ibukun rẹ ti o sọ pe, “Niwọn igba ti aye ba ṣi wa, igba ọgbin ati ikore ko ni ṣe alaima wa,” ko ni kuna lati ṣiṣẹ ninu aye wa fun ilọrọ wa (Jẹnẹsisi 8:22).

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ohungbogbo kọ́ ni búrẹ́dì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 28, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 4 Read More »

Òun yó wá ẹlòmíràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 21, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 3

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2023. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo ṣe ifẹ Ọlọrun fun ọ pẹlu iyara ati otitọ ni gbogbo asiko, ki ẹlomiran ma ba gba ààyé rẹ ninu ijọba ayeraye Ọlọrun. Amin.

Johanu Onitẹbọmi, nigbakan ti o n waasu fun awọn ọmọ Isiraẹli, sọ eyi fun wọn: “Ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada. Ki ẹ ma si ṣe ro ninu ara yin pe, ‘Awa ni Abrahamu ni baba.’ Emi wi fun yin, Ọlọrun le mu awọn ọmọ jade lati inu awọn okuta wọnyi wa fun Abrahamu.” (Mátíù 3:8-9) Ki ni idi ti o fi sọ awọn ọrọ wọnyi si wọn? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe a ti fi ifẹ Ọlọrun han wọn nipasẹ awọn Iwe mimọ wọn, wọn ko ma gbe ni ibamu pẹlu rẹ. Sibẹsibẹ wọn ko dẹkun a ti ma dunnu lori wipe wọn jẹ arọmọdọmọ Aburahamu.

O wa ṣeni laanu wipe ọpọ loni lo dabi awọn wọnyi. Orukọ ati iyi awọn obi wọn tabi ti awọn baba ati iya awọn obi wọn ni wọn n fi ṣaye. Ṣugbọn awọn funrawọn ko ni orukọ rere tabi iyi kankan ti o le jẹ ki ẹnikẹni ti o ba mọ nkan ti o n ṣe fẹ da nkankan pọ pẹlu wọn. Nkan ti wọn ko si mọ ni pe ti wọn ko ba gbe igbe aye wọn ni ibamu pẹlu orukọ rere ati iyi awọn ti wọn ti ara wọn jade, asiko kan n bọ ti ko ni si ẹnikẹni ti yoo ka ibaṣepọ wọn pẹlu awọn ti wọn ti ara wọn jade wa si mọ. Dipo eyi, nṣe ni wọn yoo yi oju pada sọdọ awọn ti o n rin ni ipasẹ awọn ẹni nla yi, ti wọn yoo si bẹrẹ si ni kan sara si orukọ wọn.

Eyi gan wa ni nkan ti Johanu Onitẹbọmi n fi han awọn eniyan rẹ, awọn ara Isiraẹli, nigbati o sọ awọn ọrọ inu Iwe mimọ ti o wa loke yi fun wọn. O fẹ ki wọn mọ pe wọn ko le jẹ ogun ibaṣepọ Aburahamu pẹlu Ọlọrun. Nṣe ni awọn naa yoo nilo lati fidi ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ mulẹ nipa mimu un ni pataki gẹgẹ bi Aburahamu ti ṣe. Ki si ni idi? Idi ni wipe nṣe ni a ma n fi idi ibaṣepọ lọlẹ ni, a ki i jogun rẹ.

Wo o, pe ẹnikan jẹ ọrẹ ti o dara si awọn obi rẹ ti o ti ku ko tunmọ si pe yoo jẹ ọrẹ daradara si iwọ naa pẹlu. Ti o ko ba ba ẹni naa lo bi awọn obi rẹ ti ṣe ba a lo, ti o ba ya, o le yi ọkan rẹ pada nipa rẹ, ki o si ma ni nkankan ṣe pẹlu rẹ mọ. Ṣe eyi wa jasi pe o ti yi ọkan rẹ pada nipa awọn obi rẹ naa? Rara o! Ọrọ ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn obi rẹ ko ni iṣoro. Ṣugbọn ko si bi yoo ṣe tẹsiwaju pẹlu rẹ ninu ibaṣepọ kan naa, ti o ko ba ni fun ni irufẹ ọwọ ati ifẹ ti awọn obi rẹ fun un.

Nibakanaa, Johanu fẹ ki awọn Juu yi mọ pe ti wọn ko ba ni mu Ọlọrun ni pataki bi baba-nla wọn, Aburahamu, ti ṣe ṣe, wọn ko ni jẹgbadun Ọlọrun bi o ti ṣe jẹ igbadun rẹ. Dipo eyi, nṣe ni Ọlọrun yoo wa awọn ọmọ miran fun ara rẹ ti yoo ba lo pọ bi Aburahamu ti ṣe ṣe, bi O tilẹ wa nilo lati gbe awọn ọmọ naa dide lati ara awọn okuta kan. Nkan ti eyi si n sọ fun wa ni pe ti a ko ba ni ṣe ifẹ Ọlọrun lati ọkan wa, ti o ba to asiko kan, yoo wa awọn miran ti yoo ṣe Oun ti O fẹ lati rọpo wa, bi o tilẹ jẹ wipe idile awọn ti wọn ti sin in, ti wọn si fẹran rẹ ni a ti jade wa.

A si wa ri apẹrẹ ninu Iwe mimọ lori bi O ti ṣe rọpo awọn kan ti wọn ko ni ṣe ifẹ rẹ pẹlu awọn ti o ṣetan lati ṣe ohun ti O fẹ. Fun apẹrẹ, O fi Samuẹli rọpo awọn ọmọkunrin Eli, O si fi ṣe onidajọ fun Isiraẹli dipo wọn. O tun rọpo Ọba Sọọlu pẹlu Dafidi, bi o tilẹ jẹ wipe Dafidi ko ki i ṣe ọmọ-ọba. Adura mi si pe o ko ni ba ọrọ rẹ de ibi ti yoo ti rọpọ iwọ naa pẹlu ẹlomiran ninu ijọba rẹ, ninu idile rẹ, ni adugbo rẹ tabi ni ibi iṣẹ tabi ile-iwe rẹ.

Ṣugbọn iwọ naa nilo lati bẹrẹ si ni mu ibaṣepọ rẹ pẹlu rẹ ni ọkunkundun. O nilo lati bẹrẹ si ni mu ṣiṣe ifẹ rẹ ni pataki. Ki ni awọn nkan ti O fẹ ki o ṣe? Awọn ibo wo ni O fẹ ki O lọ? Awọn eniyan wo ni O fẹ ki o ran lọwọ pẹlu nkan ini rẹ? O nilo lati fi ara balẹ lati gbadura ati lati kẹkọ ninu ọrọ rẹ lati mọ awọn nkan wọnyi ati lati fi ara rẹ jin fun wọn. Aijẹbẹ, ojọkan yo jọkan ti yoo jasi dandan fun un lati wa ẹlomiran lati ṣe ohun ti o kọ lati ṣe, nitoripe iṣẹ rẹ ko jẹ alaimaṣe.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Òun yó wá ẹlòmíràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 21, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 3 Read More »

Igbagbọ ati iṣododo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 14, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 2

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun ninu oṣu Èbìbí 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun mu gbogbo erongba rẹ ni rere ti O fi ṣe ọ ni ara ijọ rẹ ati ijọ yi paapaa-julọ wa si imuṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, o pe ọdun mọkanla gerege bayi ti a ti n pade gẹgẹ bi ijọ ninu ilu yi. Mo si fi ogo ati ọla fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe fi idi wa mulẹ ninu ohun ti O fẹ ati fun bi O ti ṣe n gbe wa ro ninu ifẹ rẹ. Mo tun dupẹ lọwọ rẹ fun ohun gbogbo ti O ti ṣe fun wa ni olorijori ati gẹgẹ bi ijọ ati fun ohun gbogbo ti O ti ṣe nipasẹ wa ni ilẹ yi ati kaakiri agbaye. Ki orukọ rẹ ti o logo jẹ yiyin ati bibu ọla fun lati ọwọ ohun gbogbo ti O da titi lailai. Amin.

Mo tun mọ riri gbogbo wa patapata, paapaa-julọ awọn ti o ti wa pẹlu wa lati ibẹrẹ pẹpẹ, nigba ti a ko ju eniyan mẹwa pere lọ, fun gbigbagbọ ninu wiwa Ọlọrun ni aarin wa ati fun diduro ṣinṣin ni gbogbo asiko yi, pẹlupẹlu ni igba ti ko da bi ẹni pe a ko nibikan ti a n re. Mo ranti pe fun ọdun melokan ni a ko fi pọ niye kọja eniyan mẹwa. Ki si ni idi? Ṣe nitoripe a n rin lodi si ifẹ Ọlọrun ni? Rara o! Tabi ṣe nitori pe ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi rẹ ko si ni aarin wa ni? Rara o!

Niwọn imọ iwe mimọ ti mo ni, lati ibẹrẹ pẹpẹ titi de asiko yi ni a ti n rin ninu ifẹ Ọlọrun. Eyi si ribẹ nitoripe a n rin ninu ifẹ ati ninu ododo Kirisiti ati nipa fifi gbogbo igbẹkẹle wa fun ohunkohun ti a nilo sinu Ọlọrun funrarẹ. Siwajusi, ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi rẹ ko fi igba kankan ṣe alaima wa pẹlu wa ati ninu wa, lati kọ wa, lati tọ wa ati lati fun wa ni okun lati ṣe ifẹ rẹ.

Sibẹsibẹ, ti Ọlọrun funrarẹ ko ba bu si ijọ rẹ, akitiyan eniyan lati bu si ko le ṣe alaima yọri si idarudapọ ati idajọ lẹyinọrẹyin. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe a ko fi taratara pọ si ni iye fun ọdun melokan, a n tẹsiwaju lati ma pade lọsọọsẹ fun adura gbigba ati fun ẹkọ ọrọ Ọlọrun. A si tun tẹsiwaju lati ma fi ọrọ rẹ ti o n bukun fun wa lọ awọn miran pẹlu ẹnu wa ati nipasẹ oniruuru atẹjade, bi Ọlọrun ti ṣe ran wa lọwọ si. Ki si ni idi? Igbagbọ! A ni igbagbọ ninu Ọlọrun ati ninu pe yoo gbe wa ro gẹgẹ bi ijọ rẹ, yoo si tun bu si iṣẹ rẹ ti O gbe le wa lọwọ, ti a ba tẹsiwaju lati jẹ olotitọ si i, ti a ko si rẹwẹsi.

Wayi o, loni, bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo agbaye ni o si wa niwaju wa lati gba fun Jesu Oluwa wa, a mọ riri Ọlọrun nitoripe ojooojumọ ni O n kọ aye wa ki a ba le dabi aworan ọmọ rẹ Jesu Kirisiti ati ki a ba le pọ si ni iye. Yatọ si iyẹn, a tun dupẹ lọwọ rẹ fun bi O ti ṣe fun wa ni okun lati ma polongo ọrọ rẹ lori redio ati nipasẹ ẹrọ ayelujara. A si mọ pe yoo tẹsiwaju pẹlu iṣẹ rere ti O n ṣe ninu wa, ni aarin wa ati nipasẹ wa titi de opin igba.

Mo wa fẹ gba iwọ ti o n ka ọrọ yi niyanju lati ma ṣe fi oju tẹmubẹlu awọn ọjọ nkan kekere. Idi si nipe ti o ba duro bi olotitọ, Ọlọrun le mu ki ohun ti o dabi pe o kere, ti ko si niye lori loni di nla ni ọna ti ko ṣe fẹnu sọ (Sẹkaraya 4:10). Bi o tilẹ wa dabi ẹni pe yoo fẹ gba gbogbo ayeraye ki nkan ti o n ṣe fun Ọlọrun to di nla ni ọwọ rẹ, duro gẹgẹ bi olotitọ si. Idi ni pe ko ki i ṣe bi nkan ti oun ṣe fun Ọlọrun ṣe tobi tabi ga si ni yoo ṣe fun ọ lere si, niwọn igba ti o jẹ wipe Oun ni o wa nidi boya nkan ti o n ṣe tobi tabi ko tobi. Dipo eyi, bi o ti ṣe jẹ olotitọ si lati ṣe ohun yowu ti o n ṣe ni yoo pin ọ lere si. Oun yoo si pin ọ lere ni ibamu pẹlu lilawọ rẹ, ko si ki i ṣe ni ibamu pẹlu bi o ti ṣe ro pe o ṣiṣẹ si. (Wo: Matiu 20; 1Kọrinti 3:5-9)

Nitorina, gbe igbagbọ ati iṣododo si Ọlọrun leke ohun gbogbo ninu ohunkohun ti o ba n ṣe fun. Oun yoo si buyi fun ọ nitori eyi. Bi o si ṣe wa n darapọ mọ ijọ yi ninu ọdun tuntun yi ni biba Ọlọrun ṣe pọ lati jẹ Oun gbogbo ti O fẹ ki a jẹ ati lati ṣe ohun gbogbo ti O fẹ ki a ṣe, iwọ naa yoo si ri ni ṣiṣe logo ninu aye rẹ, ninu ile rẹ ati ninu ọrọ aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ṣa ma ba Ọlọrun rin, iwọ yoo si ma a rin lalai si ibẹru.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Igbagbọ ati iṣododo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 14, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 2 Read More »

Má gbé ìgbé ayé àìkọkóbàjẹ́ mọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 1

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ni ayọ lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2023. Adura mi si pe ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni okun lati ma fi igba gbogbo gbẹkẹle, bi o ti wu ki gba ri fun ọ tabi fun orilẹ-ede wa, ki O ba le mu gbogbo èròngbà rẹ̀ ni rere fun ọ wa si imuṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi ọpọ wa ti ṣe ri loni, pupọ si ninu awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin wa ni o n ti ara bọ iṣẹ gbajuẹ, idigunjalẹ, iṣeṣo-owo, iṣẹ aṣewo ati ọpọlọpọ iṣẹ ibajẹ miran lati ri aye gbe. Bi o tilẹ wa jẹ wipe oniruuru iroyin ni a n gbọ nipa awọn nkan buruku ti o n ṣẹlẹ si awọn ti o n kopa ninu awọn iṣẹ ibi wọnyi, ọpọlọpọ awọn ọdọ yi ni ko kọbiara si wọn rara. Dipo eyi, nṣe ni wọn n foju fo awọn atunbọtan awọn nkan wọnyi nitori igbadun ranpẹ ti wọn n ti ara wọn jẹ. Igba ti a o tun wa ba ọrọ jẹ, nṣe ni a tun ri pe ọpọ awọn obi awọn ọmọ wọnyi naa ni o tun n fọwọsi nkan ti wọn ṣe. O ma ṣe o!

Ṣugbọn ki ni o ma n fa irufẹ iṣeṣi yi? Ki ni o le fa ki awọn eniyan ma ri atunbọtan rinrin ni awọn ọna kan ninu aye awọn ti o wa ni ayika wọn, ki awọn naa si tun gba awọn ọna yi kan naa? Nkan kan gbogi ti o ma n fa ni àìkọjóbàjẹ́? Nigba ti awọn eniyan ko ba kọ ki nkan bajẹ lati gbe ile aye ati lati jẹ igbadun aye wọn, bi o tilẹ jẹ igbadun diẹ ranpẹ ni, wọn a ma ṣetan lati ṣe ohunkohun lalai wo atunbọtan rẹ.

Nitorina, ti o ba ri ara rẹ ni ipo ẹni ti o ṣetan lati ṣe ohunkohun lati gbe ile aye, lalai kọ ohun ti eyi le ṣe si ọkan rẹ, aye rẹ ati awọn ti o sunmọ ọ, jẹ ki o ye ọ pe iwọ naa ko kọ ki nkan bajẹ niyẹn. Ki si ni o ma n fa àìkọkóbàjẹ́? Aini imọ Ọlọrun ni.

Nigba ti awọn eniyan ko ba mọ Ọlọrun, wọn ko ni mọ ifẹ rẹ fun wọn ati agbara lati tọju wọn. Ti awọn eniyan ko ba si mọ ifẹ Ọlọrun fun wọn ati agbara rẹ lati tọju wọn, wọn ko ni gbekẹle lati tọju wọn. Nitorina, ti wọn ba ba ara wọn ni ipokipo ti o fẹ da ẹmi wọn tabi igbadun aye wọn légbodò, wọn ko ni kọ ki nkan bajẹ lati yọ ara wọn kuro ninu ipo naa.

Ṣugbọn ko si ẹnikẹni ti o le gba ara rẹ la kuro ninu iṣoro kankan. Ẹni ti Ọlọrun ba pa mọ naa nikan ni o le jẹ pipamọ. Idi niyi ti Jesu Oluwa wa fi sọ pe, “Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gba ẹmi rẹ la, yoo sọ ẹmi rẹ nu ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmi rẹ nu nitori mi, yoo ri i.” (Mátíù 16:25) Njẹ o ri bayẹn? Ko si bi o ko ṣe kọ ki nkan bajẹ to lati gba ara rẹ kuro lọwọ iṣẹ, aisan tabi iku ti o o ṣe aṣeyọri, niwọn igba ti àikọ́kòbàjẹ́ rẹ ko ba ti tari rẹ si ọdọ Ọlọrun. A si n ri kaakiri wa bi ọpọ, pẹlu àikọ́kòbàjẹ́ wọn lati gba ara wọn kuro lọwọ iṣẹ, idojuti, aisan, airọmọbi tabi iku, ṣe n pa aye ara wọn run, ti wọn n ba ile wọn jẹ, ti wọn si tun n sọ aye ti a n gbe inu rẹ di ibi ti o lewu pupọ si lati gbe.

Nitorina, dẹkun lati ma gbe igbesẹ ẹniti ko kọ kobajẹ, igbesẹ eniti o n ṣe ohun yowu ti o ba wa si ọkan rẹ lati gbadun aye, lati di ẹni iwosan, lati gbeyawo tabi lati lọmọ. Ọba Sọọlu fi igbakanri gbe igbesẹ àikọ́kòbàjẹ́ lodi si ifẹ Ọlọrun lati pa ijọba rẹ mọ. Sibẹsibẹ o padanu ohun ti o n gbiyanju lati pa mọ. Ti iwọ naa ba si gba ki ẹmi àikọ́kòbàjẹ́ ti ọ lati ṣe ohun ti o lodi si ifẹ Ọlọrun fun aye rẹ, nṣe ni iwọ naa yoo di aladanu nla, bi o ti wu ki o tiraka to lati ṣẹgun. (Wo: 1Samuẹli 13)

Ṣugbọn ti o ba fa aye rẹ le Ọlọrun lọwọ, o di dandan ki O pa a mọ fun ọ, ki O si tun ri daju pe ohun gbogbo ti o nilo lati gbe igbe aye ti o ni itumọ ati lati gbadun ayeraye rẹ pẹlu rẹ ni O fun ọ. Ki wa ni o fẹ ṣe bayi? Ṣe o fẹ tẹsiwaju lati ma gbe igba aye mi-o-kọ-kobajẹ ni, ki o si fooro ara rẹ jade kuro laye? Tabi ṣe o fẹ fa aye rẹ ati gbogbo aniyan rẹ le Ọlọrun lọwọ ni, ki o si farabalẹ wo bi yoo ṣe mojuto ọ lọna ti o peye? Adura mi ni pe ki Ẹmi Ọlọrun jẹ ki o ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi ni orukọ Jesu. Amin.

Ko ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má gbé ìgbé ayé àìkọkóbàjẹ́ mọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 1 Read More »

Kíló dé tí ò ń ṣe èyí sí ara rẹ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ si ọjọ Isinmi ti o kẹyin oṣu Igbe 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun la ọna fun ohun gbogbo ti O fẹ ki o ni ninu oṣu yi ti o ko i ti ri gba lati tọ ọ wa ki oṣu naa to pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe wọ inu ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti nkan ti Pọọlu sọ fun wa nipa bi o ti ṣe ṣeeṣe ki eniyan ma fi gbogbo igba kọ ọrọ Ọlọrun, ki o si tun ma mọ ohunkohun nipa rẹ tabi nipa otitọ rẹ (2Tímótì 3:7). Ki wa lo le fa ti ẹnikan yoo ma wa si awọn ipade ijọ, ti yoo si maa gbọ Ọlọrun, sibẹsibẹ ti ko ni ni imọ Ọlọrun tabi imọ awọn otitọ nipa ile aye ti o ṣe pataki ju lọ? Ara awọn nkan ti o ma n fa ni ki eniyan ma gbajumọ nkan ti o n kọ.

Ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ ọ wa, ti o ko si ma fi ọkan ba nkan ti a n kọ ọ lọ, ṣugbọn ti o n ronu nipa nkan miran tabi ti o n sun, ko si bi o ṣe fẹ ri nkankan mu jade ninu ohun ti o n kọ. O wa ṣeni laanu pe ki wọn ma ma kọbiara si ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wọn wa tabi ki wọn ma sun nigba ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ wọn wa ti di aṣa fun ọpọ ti a n pe ni Kirisitiẹni loni. Eyi tunmọ si pe nkan ti wọn n fi gbogbo igba ṣe ni eyi. Ko wa jẹ iyalẹnu pe lati igba ti wọn ti di Kirisitiẹni, ti wọn si ti n wa si ipade ijọ Ọlọrun, ko si iyipada kankan ti o ṣe fi oju ri ninu aye wọn.

Idi miran ti awọn eniyan tun ṣaba fi ma n kọ ọrọ Ọlọrun, sibẹsibẹ ti wọn ko ni mọ otitọ Ọlọrun ni ailoye nkan ti wọn n kọ. Jesu Oluwa sọ fun wa taratara pe ti eniyan ba gbọ ọrọ Ọlọrun, ti ko si ye, Satani yoo tọ ọ wa, yoo si ja ọrọ ti o ti gbọ gba kuro lọwọ rẹ. Nitorina, ko si bi ọrọ ti o gbọ ṣe fẹ gbe ohun rere kankan ṣe ninu aye rẹ — nṣe ni yoo ja si pabo. (Wo: Mátíù 13:19)

Wayi o, o ṣe e gbọ ti ẹni ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun ba gbọ ọrọ Ọlọrun, ti ko si ye. Idi si ni pe ko ni Ẹmi Ọlọrun ti o ma n fun awọn eniyan ni oye awọn otitọ ẹmi ninu rẹ (1Kọ́rínntì 2:12). Ṣugbọn ti ẹni ti o jẹ ọmọ Ọlọrun, ti o si ni Ẹmi rẹ ninu, ba wa n gbọ ọrọ rẹ, sibẹsibẹ ti oye nkan ti o n gbọ ko ye, a jẹ wipe o ṣeeṣe ki nkan ma ṣe tabi ki nkan ma ṣe olukọ rẹ. Nkan ti o n ṣe si le jẹ pe ko ki i lakakaka lati ni oye nkan ti o n kọ. Nitorina, ko ni gbiyanju lati ronu nipa ohun ti o gbọ tabi lati ṣe aṣaro le lori. Ko si tun ni gbiyanju lati wa inu Iwe mimọ lati ri boya nkan ti o gbọ otitọ ni tabi bẹẹkọ. Ki si ni idi? Idi ni pe o ya ọlẹ. Nitorina, bi awọn ara Heberu, ko ni ifẹ si nini imọ otitọ. Irufẹ ẹni bayi ko si le lailai dagba ninu nkan ti ẹmi. (Wo: Heberu 5:11-14)

Ṣiwaju si, a tun ni awọn ti o n gbọ ọrọ Ọlọrun, ti o si n ye wọn, ṣugbọn ti wọn ko ni lọkan lati ṣiṣẹ le lori. Ki wa ni yoo fa ti eniyan yoo gbọ ọrọ Ọlọrun, ti yoo si ye, sibẹsibẹ ti ko ni pinu lọkan rẹ lati ṣe amulo rẹ? Nkan ti o ṣaba ma n fa ni ki eniyan ma gbagbọ pe oun ni ọrọ ti o n gbọ wa fun. O le ri ọrọ yi pe o wa fun ẹlomiran lati ṣiṣẹ le lori, ṣugbọn ko ni ri bi igba ti o wa fun oun tikararẹ. Idi si ni yi ti awọn eniyan fi n gbọ ọrọ Ọlọrun ati awọn aṣẹ miran ninu awọn ipade ijọ wọn lọsọọsẹ, sibẹsibẹ ti wọn a jade lọ, ti wọn a si ṣe bi igba ti wọn ko gbọ nkankan tabi ki wọn lọ se idakeji nkan ti wọn gbọ.

Ibere wa ni pe, “Ki ni o de ti o n ṣe eyi si ara rẹ?” Ki lo fa ti o n fi akoko rẹ ṣofo lati ma kọ ọrọ Ọlọrun, ti o si jẹ wipe o ko ni lọkan lati ṣe amulo rẹ tabi ti o ko ni ifẹ lati ri pe ọrọ naa ṣiṣẹ ninu aye rẹ? Wo o, ọrọ Ọlọrun ko ni ṣe anfaani kankan fun ọ, ti o ko ba tẹwọgba, ki o si ṣe ohun ti o sọ. Rara o, ọrọ rẹ ko ni ṣi oju rẹ si otitọ ti o nilo lati di ominara laye, ti o ko ba kọ iha ti o tọ lati tẹwọgba ati lati ṣe amulo rẹ. Nitorina, ti o ba wa lara awọn ti o ti n gbọ ọrọ Ọlọrun fun bi ọdun melokan, sibẹsibẹ ti wọn ko dangajia ninu nkan ti Ọlọrun, o nilo lati tun ero rẹ pa lori nkan ti o n ṣe si ara rẹ, ki o si yi ọna rẹ pada. Aijẹbẹ, o ko ni dẹkun lati ma lu igbadi irọ eṣu ati aṣiṣe awọn ọdanran eniyan.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kíló dé tí ò ń ṣe èyí sí ara rẹ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 52 Read More »

Àdúrà àti ìfifúnni – kì í ṣe àdúrà nìkan | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 23, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Igbe 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya ọkan rẹ ya ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu ṣiṣe ahun si i, ki gbogbo orisun ibukun rẹ̀ ti o ti di ninu aye rẹ ba le jẹ ṣiṣi fun isoriire rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọpọ igba ni o ma n jẹ iyalẹnu fun ọpọ ninu wa pe awọn kan ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni rara n jẹ igbadun ojurere Ọlọrun fun igbega, ipamọ ati iṣoriire ni ọna ti o jẹ wipe awọn ti o jẹ onigbagbọ ti o wa ni ayika wọn gan ko jẹ igbadun rẹ. Idi kan pataki ti eyi si ṣe ri bẹ, bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, ni ififunni. Ṣe o ri, nigba ti bibeli sọ wipe Ọlọrun fẹran oninudidun ọlọrẹ, ko tunmọ si pe Kirisitiẹni nikan ni ọrọ yi bawi (2Kọrinti 9:7). Ti alaigbagbọ kan naa ba jẹ oninudidun ọlọrẹ, Ọlọrun yoo fi ifẹ rẹ han si ni ọna ti o jọju ati ti o han kedere pẹlu.

Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu bibeli nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Kọneliu:

Ọkunrin kan si wa ni Kesaria ti a n pe ni Kọneliu, balogun ọrun ti ẹgbẹ ọmọ-ogun ti a n pe ni Itali. Olufọkansi, ati ẹni ti o bẹru Ọlọrun tile tile rẹ gbogbo, ẹni ti o n tọrẹ aanu pupọ fun awọn eniyan, ti o si n gbadura sọdọ Ọlọrun nigba gbogbo. Niwọn wakati kẹsan-an ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ ọ wa, o si wi fun un pe, “Kọneliu!” Nigba ti o si tejumọ ọn, ti ẹru si ba a, o ni, “Ki ni, Oluwa?” O si wi fun un pe, “Adura rẹ ati ọrẹ-aanu, tirẹ goke lọ siwaju Ọlọrun fun iranti.”” (Iṣe Apọsiteli 10:1-4)

Tani Kọneliu, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ yi? Ṣe Kirisitiẹni ni! Irọ! Ṣe Juu ni? Irọ! Dipo awọn nkan yi, o jẹ jagunjagun keferi. Ṣibẹsibẹ, angẹli Ọlọrun kan farahan an lati sọ fun pe Ọlọrun da a mọ. Ki ni Ọlọrun da a mọ fun? O da a mọ fun adura rẹ ati pẹlu fun ififunni rẹ.

Dajudaju, Kọneliu, gẹgẹ bi jagungun, ni lati jẹ ọkunrin kan ti iṣẹ kun ọwọ rẹ. Sibẹsibẹ ko jẹ ki iṣẹ gba aye rẹ debi pe ko ni raaye lati gbadura. Ka tilẹ so otitọ, o fi ara rẹ jin lati gbadura to bẹẹ gẹẹ ti Ọlọrun fi da mọ gẹgẹ bi aladura. Njẹ Ọlọrun da iwọ naa bi aladura bi? Tabi iṣẹ ko jẹ ki o raaye lati ma ba a sọrọ?

Siwaju si, bi o tilẹ jẹ wipe jagunjagun ni Kọneliu, ko lo ipo rẹ lati ma lọ awọn eniyan lọwọ gba, bi ọpọ awọn ṣọja wa ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo lọkunrin ati lobirin ṣe ma n ṣaba ṣe e. Dipo eyi, nṣe ni o n fi owo ti ara ran awọn alaini lọwọ. O wa lawọ́ si awọn alaini debi wipe Ọlọrun damọ gẹgẹ bi ọlọrẹ oninudidun ati ẹni ti o n fi tọkantọkan fun ni. Nitorina, eniyan ko ni lati jẹ Kirisitiẹni ki Ọlọrun to mu ni pataki. Ti ẹni naa ba mu Ọlọrun ni pataki nipa gbigba adura si ati lílawọ́ si awọn miran, Oun naa yoo mu ni pataki, yoo si tun fi ara rẹ han an.

Bi a ti ṣe ri ni ti Kọneliu, nitoripe o n fi lemọ-lemọ gbadura si Ọlọrun ati fifun awọn alaini, ọjọ kan de ti Ọlọrun ranti gbogbo nkan ti o ti n ṣe, ti O si pinu pe Oun gbọdọ ṣe nkankan lori ọrọ igbala ayeraye rẹ. Wa ranti pe bibeli sọ fun wa pe ki a ma rẹwẹsi ni ṣiṣoore fun awọn miran nitoripe, ni akoko ti o tọ, Ọlọrun yoo ranti wa, yoo si pin wa lere (Galatia 6:9). Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe san wa ni ere fun lilawọ wa? Ko si ẹni ti o le sọ. Ọwọ rẹ ni o wa. Ṣugbọn o di dandan ki O pin wa ni ere fun un, yala Kirisitiẹni ni wa tabi bẹẹ kọ.

Nigba ti Ọlọrun ranti Kọneliu ni asiko ti a n sọ yi, ko ki i ṣe adura rẹ nikan ni O ranti rẹ fun. O tun ranti rẹ fun lilawọ rẹ pẹlu, O si ran angẹli rẹ si lati dari rẹ sọdọ Peteru, ọkunrin naa ti yoo fi ọna igbala han an. Nitorina, adura gbigba ko to fun wa lati ri awọn nkankan gba lọwọ Ọlọrun; a tun gbọdọ fi lilawọ kun adura wa. A si ri awọn ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni ti o ni oye eyi, ti o si ma n ṣe amulo rẹ. Ki si ni idi? Ìrírí ti jẹ ki o ye wọn pe irufẹ nkan bayi ma n ṣiṣẹ.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni oye ilana ẹmi yi ko ye rara. A ko mọ pe awọn asiko kan wa ti ko ki i ṣe adura wa ni Ọlọrun yoo lo lati ṣiṣẹ fun wa bikoṣe lilawọ wa. Nitorina, mejeeji ni o yẹ ki a fi ara wa jin fun. Nitoripe a ko mọ igba ti adura wa tabi (ati) lilawọ wa loni ni kọkọrọ ti yoo ṣi ilẹkun igbega tabi igbala wa lọla. Adura mi ni wipe o ko tun ni fi igba kankan padanu igbega tabi igbala rẹ mọ nitori aigbadura to tabi aififunni to. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àdúrà àti ìfifúnni – kì í ṣe àdúrà nìkan | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 23, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 51 Read More »