Tan ìyìnrere náà kálẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 16, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 50
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba ri ọ lo lati tan iyinrere ọmọ rẹ Jesus Kirisiti kalẹ. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ọkan lara idi ti ọpọ fi tipasẹ iṣẹ iranṣẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa di alabukunfun ni pe awọn ti a bukunfun nipasẹ rẹ n tan iyinrere rẹ kaakiri ọdọ gbogbo awọn ti o wa ni ayika wọn ati ni ibikibi ti wọn ba lọ. Fun apẹrẹ, lẹyin igba ti Jesu ti wo ọkunrun were kan san tan, O sọ eyi fun: “Lọ si ile si ọdọ awọn ẹbi rẹ, ki o si sọ fun wọn bi Ọlọrun ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣaanu fun ọ.” (Maaku 5:19) Ṣe ọkunrin wa lọ tabi ko lọ? O lọ. Bibeli sọ wipe, “Nitori naa, ọkunrin yii pada lọ, o bẹrẹ si royin ni Dekapolisi nipa ohun nla ti Jesu ṣe fun un. Ẹnu si ya gbogbo eniyan.” (Maaku 5:20)
Wayi o, nkankan naa ni a n reti lati ọdọ wa. Bi Oluwa ti n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ, ti O n yi aye wa pada, ti O si tun n ṣe oniruuru nkan iyanu fun wa ninu ijọ wa, nṣe ni o yẹ ki a ma tan iroyin didara rẹ si wa kaakiri. Ki ni idi? Idi ni ki awọn ti o ba gbọ wa naa ba le gba iwuru lati darapọ mọ wa lati ni iriri didara rẹ.
Njẹ o tilẹ mọ pe awọn ti Oluwa pa aṣẹ fun lati ma sọ ohunkohun nipa rẹ fun ẹnikẹni gan si papa tan iroyin didara rẹ kaakiri ibi gbogbo ti wọn lọ? Luuku, fun apẹrẹ, fi eyi han wa nipa nkan ti o ṣẹlẹ lẹyin ti Jesu ti wo ọkunrin adẹtẹ kan san:
“O si kilọ fun u pe, “Ki o ma ṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o s fi ara rẹ han fun alufaa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹri si wọn.” Ṣugbọn okiki rẹ n kan kalẹ: tobẹẹ ti ọpọ ijọ eniyan si jumọ pade lati gbọ ọrọ rẹ, ati lati gba dida ara lọdọ rẹ kuro lọwọ ailera wọn. Ṣugbọn Jesu a maa yẹra kuro, oun a si maa dawa lati gbadura.” (Luuku 5:14-16)
Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe Oluwa paṣẹ fun okunrin adẹtẹ yi lọna ti o ye yekeyeke pe ki o ma sọ ohun kan fun ẹnikẹni nipa Oun, ọkunrin yi ko dakẹ jẹ nipa ọrọ naa. Dipo eyi, bi awọn ti O ti wosan tẹlẹ, nṣe ni ọkunrin yi naa n lọ kaakiri, ti o si n sọrọ laibikita nipa rẹ ati nkan ti o ṣe fun un fun awọn eniyan. Eyi si jẹ ki ọpọ eniyan wa si ọdọ rẹ lati wa gbọ ọrọ rẹ ati lati gba iwosan fun awọn aisan wọn.
Ṣe o wa tọna fun ọkunrin yi lati ṣe aigbọran si Jesu Oluwa gẹgẹ bi o ti ṣe? Rara! Ninu akọsilẹ Maaku lori iṣẹlẹ yi kanna, o jẹ ki o ye wa pe aigbọran ọkunrin yi ko jẹ ki o ṣeeṣe fun Jesu lati wọ ibi kankan lalai da boolọ-ooya silẹ. Nitorina, aigbọran rẹ da rugudu silẹ fun Oluwa. Ṣugbọn ọkunrin yi ko ro wipe oun ṣe nkan ti ko dara rara ni asiko yi. O kan ro lọkan rẹ pe alanikanjọpọn ni oun yoo jẹ ti oun ba fi otitọ nipa ẹni ti o wo oun san, ti o si mu oun larada pamọ. (Wo: Maaku 1:40-45)
Ni kukuru, ọkunrin yi, ti Oluwa pasẹ fun lati ma sọ ohunkohun fun ẹnikẹni nipa rẹ woye lọkan rẹ pe alanikanjọpọn ni oun yoo jẹ ti oun ko ba sọ fun ẹnikẹni nitootọ ohun ti Jesu ṣe fun oun. Ṣe awa gan ko wa ni jẹ alanikanjọpọn ti o ga ju ti a ba kọ lati tan iyinrere didara rẹ si wa kaakiri, awa ti a ko gba aṣẹ kankan ti o jọ mọ eyi ti ọkunrin yẹn gba?
Nitorina, ti o ba ti n ni iriri didara ati agbara Ọlọrun ninu aye rẹ lati igba ti o ti dara pọ wa ninu ijọ yi, alanikanjọpọn ni ọ ti o ba panumọ lori rẹ, ti o ko tan iroyin naa kalẹ de ọdọ awọn miran. Lotitọ, ti o ba le fi idi rẹ mulẹ pe iwọ ko i ti ni iriri didara ati agbara Ọlọrun lati igba ti o ti darapọ mọ wa, yoo ye wa ti o ba ni ọ lara lati tan iroyin naa kalẹ. Idi si ni pe ko si iroyin kankan ti o fẹ tan kalẹ. Ṣugbọn ti o ko ba le fi idi rẹ mulẹ (ti mo si mọ pe o ko le fi idi rẹ mulẹ), o nilo lati bẹrẹ lati maa tan iroyin awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe fun ọ ati si ọ ninu awọn ipade wa de ọdọ awọn ti o wa ni ayika rẹ. Nipa ṣiṣe eyi, awọn naa yoo le darapọ mọ wa lati ni iriri didara Ọlọrun ninu aye wọn.
Wayi o, mo fẹ ki o mọ pe Ọlọrun n fi ọkan tan ọ lati ṣe eyi. O si di dandan ki O pin ọ lere fun isododo rẹ ni didari awọn miran si ọdọ rẹ̀ lati ni iri igbala, iwosan, itusilẹ ati isọdọtun. Nitorina, mu ọrọ yii ni pataki. Njẹ ki a ṣe ọkan rẹ le lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)





