Author name: 23?Racing_Horse

Kò gbọdọ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 10, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògùn 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun maa fi ojoojumọ kun ọkan rẹ pẹlu irẹlẹ, ki o ba a le tẹsiwaju lati ma ni iriri igbega rẹ ni gbogbo abala aye rẹ. Amin.

Lẹyin igba ti Ọba Sọọlu ti ṣe aigbọran si Ọlọrun nipasẹ pe ko pa gbogbo awọn ara Amaleki run, Samuẹli sọ eyi fun un:

“Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli?” (1Sámúẹ́lì 15:17)

Nigba wo ni Ọlọrun fi ami ororo sọ Sọọlu di ọba lori Isiraẹli? Ni igba ti o jẹ onirẹlẹ ni. Ni igba ti ko ri ara rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o san ju awọn miran lọ ni. Ṣugbọn lẹyin igba ti a ti fi idi itẹ rẹ mulẹ tan, o fi aye gba igberaga ninu ọkan rẹ, o si bẹrẹ si ni ṣe bi o ti ṣe wu u.

Njẹ iha wo wa ni Ọlọrun kọ si eyi? O gba ijọba ti O fifun un kuro lọwọ rẹ. O si fi ọdọmọkurin kan, iyẹn Dafidi, rọpo rẹ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe o ja fitafita lati pa ijọba naa mọ fun ara rẹ ati fun arọmọdọmọ rẹ, ko ri i pa mọ. Idi si ni pe kiki nkan ti Ọlọrun ba fun wa ni a le pa mọ fun ara wa. A ko le pa nkan ti O ba ti gba kuro lọwọ wa mọ fun ara wa.

Ni kukuru, koko itan bibeli yi naa ni pe irẹlẹ wa ko gbọdọ jẹ fun igba diẹ. Dipo eyi, nkan ti a gbọdọ ni lati ibẹrẹ de opin ni. Ti a ba fi irẹlẹ han niwaju Ọlọrun fun igba diẹ, nṣe ni igbesoke wa naa yoo wa fun igba diẹ. Eyi jasi pe, ni kete ti a ba ti bẹrẹ si ni fi igberaga han, Ọlọrun kanna ti O ti n gbe wa ga yoo bẹrẹ si ni ja wa bọ. (Wo: Jákọ́bù 4:6; 1Pétérù 5:5)

Eyi si wa ni idi ti awọn kan ko ti ṣe ga ju ipo ti wọn wa laye lọ. Nigba ti wọn rẹ ara wọn silẹ niwaju Ọlọrun, O ṣaanu fun wọn, O si bẹrẹ si ni gbe wọn ga. Ṣugbọn nigba ti wọn de awọn ipo nla kan, wọn bẹrẹ si ni ṣiwawu. Wọn bẹrẹ si ni ṣe bi igba ti o jẹ wipe ọgbọn tabi agbara wọn ni o gbe wọn de ibi ti wọn wa. Nitorina, dipo ki Ọlọrun gbe wọn lọ si ibi ti o ga ju ibi ti wọn wa lọ, nṣe ni O fi wọn silẹ sibẹ, ti O si bẹrẹ si ni gbe awọn miran ni ayika wọn ga. Ti wọn ba si wa tẹsiwaju lati ma a rin ninu igberaga, a le pada re wọn jabọ si awọn aye ti o kere ju ibi ti wọn wa lọ.

Nitorina, irẹlẹ ko ki i ṣe nkan ti a kan nilo ki Ọlọrun ba a le gbe wa ga nikan; a tun nilo rẹ lati le jẹ ki O ma ba a jẹ ki jabọ kuro ni ibi giga ti O fi wa si. Nitori eyi, fi ara rẹ sipo irẹlẹ niwaju rẹ. O ko si ni lailai ni idi kankan lati bẹru pe yoo re ọ jabọ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kò gbọdọ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 10, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 15 Read More »

Ma rẹwẹsi | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 03, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo fi ki ọ kaabọ sinu oṣu Ogun 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati rin ni iṣẹgun lori gbogbo idojukọ aye rẹ ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Nigba ti Ọlọrun pe Joṣua lati gba iṣẹ lọwọ Mose ni didari awọn ọmọ Isiraẹli wọ inu Ilẹ Ileri, Ọlọrun sọ awọn ọrọ wọnyi fun un:

“Emi ko ha ti paṣẹ fun ọ bi? Jẹ alagbara ki o si mu aya le. Ma ṣe bẹru, ma si ṣe rẹwẹsi, nitori pe Oluwa a rẹ yoo wa pẹlu u rẹ ni ibikibi ti iwọ ba n lọ.” (Jóṣúà 1:9)

Ki ni idi ti Ọlọrun fi sọ fun ọkunrin yi lati ma bẹru tabi rẹwẹsi ṣugbọn lati jẹ alaragba ati ẹni ti aya rẹ le? Akọkọ, idi ni pe o di dandan ki o ba awọn asiko kan pade ti yoo fẹ dẹruba tabi kun ọkan rẹ pẹlu irẹwẹsi. Ti o ba si lọ bẹru tabi rẹwẹsi pẹrẹ, ko ni i le mu ete Ọlọrun fun aye rẹ ṣẹ.

Idi keji ti Ọlọrun fi sọ fun pe ki o ma bẹru tabi rẹwẹsi ni pe Oun funrarẹ yoo wa pẹlu rẹ lati daabo bo ati lati jẹ ki o rin ninu iṣẹgun nibikibi ti o ba lọ, bi o ti wu ki ibẹ lewu to. O wa ku sọwọ Joṣua lati gba ọrọ ti Ọlọrun ti sọ fun lati rin ninu iṣẹgun lori gbogbo idojukọ rẹ laye gbọ ati lati ṣiṣẹ le e lori. Ṣe o wa gba ileri Ọlọrun gbọ bi, ṣe o si tun ṣiṣẹ le lori? Bẹẹni. Idi si ni yi ti o ṣe ṣe aṣeyọri ni didari awọn ọmọ Isiraẹli lati jogun Ilẹ Ileri.

Nibakana, o di dandan ki awa naa ba awọn asiko pade laye ti yoo fẹ dẹruba wa tabi fi irẹwẹsi sinu ọkan wọ. A tilẹ le wa ni irufẹ awọn asiko naa lọwọlọwọ yi. Ṣugbọn bi o ti wu ki awọn asiko naa dẹruba wa to, Ọlọrun n sọ fun wa pe ki a ma bẹru wọn, ki a si ma jẹ ki wọn fi irẹwẹsi sinu ọkan wa. Ki ni idi? Idi ni pe yoo wa pẹlu wa nibikibi ti a ba lọ lati mojuto wa ati lati ri daju pe eṣu kọ pa aye wa run. Ti a ba si gba eyi gbọ, ti a si n ṣiṣẹ le lori, iṣẹgun yoo jẹ ti wa ni gbogbo ipo ti a ba ba ara wa laye.

Nitorina, bi o ti wu ki nkan ti o n dojukọ lọwọlọwọ yi ri, ma ṣe bẹru tabi rẹwẹsi. O le e dabi ẹni pe gbogbo ireti itusilẹ tabi iṣẹgun rẹ ni o ti bọ danu. Sibẹsibẹ, ma ṣe rẹwẹsi ni ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, tẹsiwaju lati ma a gbadura ati lati ma sọ ọrọ Ọlọrun ṣi awọn ipo ti o wa. Nipa bayi, oju ko ni ti ọ ṣugbọn iwọ yoo ni iriri iṣẹgun ti o ga.

Kí o ní oṣù Ògún 2025 alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ma rẹwẹsi | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 03, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 14 Read More »

Àkórí: Àìmọ ǹkan tí ó kàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 27, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 13

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu di ilọpo-ilọpo fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Agẹmọ 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ jẹ ki o fi ọkan si awọn nkan ti o ṣe pataki lotitọ laye yi, ki o ma ba fi aye rẹ sofo lori awọn nkan ti ko ni itumọ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, o ṣeeṣe ki a fi ara wa jin fun awọn nkan ti ko tọ, ki a si ro wipe Ọlọrun ni a n ṣe wọn fun. Eyi yoo si jẹ nitoripe a ko mọ bi a ti ṣe le mojuto nkan ni iwọn bi o ti ṣe ṣe pataki tabi bi o ti ṣe gbọdọ jẹ mimuṣe ni kiakia si. Nibiti eyi ba si ti ri bẹ, a le ri wipe a padanu awọn nkan ti o le mu iyipada ayeraye ba aye wa nibi ti a ba ti n sare le awọn nkan ti ko le fun wa ju igbadun asiko diẹ lọ.

Fun apẹrẹ, bibeli sọ nkankan ti o ṣẹlẹ nigba ti Jesu lọ si ile Maria ati Mata fun ibẹwo lọjọ kan. Wo bi Luuku ti ṣe royin rẹ ninu iwe iyinrere rẹ:

“O si ṣe, bi wọn ti n lọ, o wọ ileto kan, obinrin kan ti a n pe ni Mata si gba a si ile rẹ. O si ni arabinrin kan ti a n pe ni Maria ti o si jokoo lẹbaa ẹsẹ Jesu, ti o n gbọ ọrọ rẹ. Ṣugbọn Mata n ṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ ọ wa, o wi pe, “Oluwa, iwọ ko si bikita si ti arabinrin mi pe o fi mi silẹ lati maa nikan ṣe iranṣẹ? Wi fun n ki o ran mi lọwọ.” Ṣugbọn Jesu si dahun, o si wi fun un pe, “Mata, Mata, iwọ n ṣe aniyan ati laalaa nitori ohun pupọ. Ṣugbọn ohun kan ni a ko le ṣe alaini, Maria si ti yan ipa rere naa ti a ko le gba lọwọ rẹ.” (Lúùkù 38-42)

Ki ni akọsilẹ yi n fi han wa? O n fi nkankan han wa lori ki a ma mọ nkan ti o kan. Ta si ni ko mọ nkan ti o kan lọrọ rẹ ninu akọsilẹ naa? Mata ni. Lọna wo? Ṣe o ṣe nkan ti o buru nipa ṣiṣe iṣẹ karakara lati ṣe alejo Jesu ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ni asiko yi ni? Rara o! Ṣugbọn ko ba tilẹ kọkọ fi aye silẹ lati ba Oluwa sọrọ ati lati gbọ ohun rẹ. Eyi ko ba si ran an lọwọ lati mọ ọna ti o tọ ati asiko ti o yẹ lati ṣe alejo rẹ.

Awọn die ninu wa naa si ma n ṣaba ṣe aṣiṣe kan naa ti awọn eniyan ba bẹ wa wo. A o ma kanju lati ṣe alejo wọn lalai kọkọ lo asiko diẹ lati ba wọn fọrọ jomitoro ọrọ ati lati mọ eredi ibẹwo wọn. A si wa ma le fi ara balẹ rara lati ba wọn sọ ọrọ pataki kankan titi wọn yoo fi lọ, nitoripe a ṣa a fẹ ṣe alejo wọn. Eyi ko ki i ṣe ọna ti o tọ lati gbe ibaṣepọ ti o dara, ti o si tun ni itumọ ro.

Ni kukuru, nigba ti Mata n ṣe akitiyan gidigidi lati ṣe alejo Jesu, nṣe ni arabinrin rẹ, Maria, joko lati kẹkọ lọdọ rẹ. Eyi si wa bi i ninu debi pe ko le pa a mọra. Nitorina, o tọ Jesu wa lati sọ fun pe ki O ba Maria wi fun bi ko ti ṣe mọ nkan ti o kan lọrọ rẹ, ki O si tun ran sọdọ oun lati ran an lọwọ ni pipese awọn nkan ti wọn yoo fi ṣe alejo ati Oun ati awọn ọmọlẹyin rẹ.

Ṣugbọn dipo ti Oluwa yoo fi ṣe nkan ti o fẹ, nṣe ni O sọ fun pe oun gan an ni ko mọ nkan ti o kan lọrọ rẹ. Eyi jasi pe, nṣe ni o yẹ ki oun pẹlu joko gẹgẹ bi arabinrin rẹ lati kẹkọ lọdọ rẹ. Igbana ni ko ba ni imọ ti o peye si lori bi o ti ṣe le ṣe alejo rẹ, ki o si gba oriyin. Imọ yi ko ba si wa jẹ tirẹ titi aye ni. Amọ o padanu anfaani rẹ lati kẹkọ ati lati di eniyan daradara si lọjọ naa. O ma ṣe o!

Ki a ma fọrọgun, koko ọrọ naa ni pe a ko gbọdọ fi aye gba ohun rere yowu ti a ba n ṣe fun Ọlọrun lati ma jẹ ki a kọbiara si i, si ọrọ rẹ ati si adura ni ọna ti o peye. Aijẹbẹ, a ko ni mọ ọ ati bi o ti ṣe tọ lati ṣin in si i. Eyi si le jẹ ki a padanu ere awọn nkan rere yowu ti a ro wipe a n ṣe fun un.

Nitorina, ẹ jẹ ki a ma fi igba gbogbo mọ nkan ti o kan lọrọ wa, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Ibaṣepọ wa pẹlu rẹ gbọdọ ma fi gbogbo igba siwaju iṣẹ-isin wa si i. Njẹ ki ọkan wa gba okun lọna ti o peye lati ma ṣe lailai gbagbe nkan yi i. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àkórí: Àìmọ ǹkan tí ó kàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 27, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 13 Read More »

Àkórí: Ọlọ́rọ̀ ní àsìkò ìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 20, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 12

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo iyoku ọdun yi lati ri gbogbo ipese rẹ fun ọ lati gbe ninu anito, bi o tilẹ jẹ wipe orilẹ-ede wa n dojukọ ọda oniruuru nkan rere ni asiko yi. Amin.

Bibeli sọ wipe, “Woo, oju Oluwa wa lara awọn ti o bẹru rẹ, ati lara awọn ti o ni ireti ninu ifẹ rẹ ti o duro ṣinṣin. Lati gba ọkan wọn kuro lọwọ iku ati lati pa wọn mọ laaye lọwọ iyan.” (Sáàmù 33:18-19) Awọn wo ni oju Ọlọrun n fi igba gbogbo wa lara wọn? Awọn ti o bẹru rẹ, ti wọn si tun fi ireti wọn sinu ifẹ rẹ ti o duro ṣinṣin ni. Nitorina, ti o ba bẹru Ọlọrun, ti ireti rẹ si wa ninu rẹ, oju rẹ yoo ma fi gbogbo igba wa pẹlu rẹ nibikibi ti o ba lọ ati bi o ti wu ki nkan ri ninu aye rẹ.

Njẹ ki wa ni idi ti oju Ọlọrun yoo fi wa lara rẹ ni ọna yi? Bi Dafidi ti ṣe fi han wa ninu awọn ẹṣẹ saamu rẹ yẹn, idi akọkọ ni ki O ba a le gba ọ kuro lọwọ iku. Ṣe eyi ko wa jẹ nkan ti o dara bi? Nkan ti o dara ni. Nitorina, ma ṣe bẹru iku, pẹlu-pẹlu iku ti o farasin. Ko ni jẹ ipin rẹ. Idi si ni pe Ọlọrun yoo ma a fi igba gbogbo gba ọ kuro lọwọ rẹ.

Idi keji ti Ọlọrun yoo fi maa fi igba gbogbo ṣọ ọ ni ki O ba le mu ọ wa laaye ni asiko iyan. Eyi jasi pe bi o ti wu ki ọrọ-iṣuna ilẹ ti o wa buru to, Ọlọrun yoo ri daju pe ati iwọ ati ile rẹ ni a pa mọ. Bawo ni yoo ṣe ṣe eyi? O kọja nkan ti ẹnikẹni le sọ. Ṣugbọn niwọn igba ti ọrọ rẹ ti sọ fun wa pe yoo ṣe e, a le fi ọkan balẹ pe yoo ṣe e nitootọ. Nkan ti a kan nilo lati ṣe ni ki a ṣiṣẹ lori ohun yowu ti o ba sọ fun wa pe ki a ṣe.

Fun apẹrẹ, iyan ti o lagbara kan mu ni asiko Isaki. Iyan yi le debi wipe ọkunrin naa fẹ ṣipo-pada kuro nibi ti o wa lọ si Ijibiti. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun pe ki o ma ṣe bẹẹ. Ki ni idi? Idi ni pe awọn ipese rẹ fun lati soriire ko si ni Ijibiti ni asiko naa. Ibi ti o n gbe ni wọn wa. Ti o ba wa lọ gba Ijibiti lọ ni, nṣe ni ireti rẹ ko ba di asan. (Wo Jẹ́nẹ́sísì 26)

Awa dupẹ pe Isaki gbọran si Ọlọrun lẹnu, o si duro si ibi ti o wa. Nitoripe o si gbọran si i lẹnu, O ṣi oju rẹ lati bẹrẹ si ni dako. Nipa bayi naa si ni o ṣe di ọlọrọ ni asiko iyan.

Nibakana, Ọlọrun le sọ awa naa di ọlọrọ ni asiko iyan tabi tabi inira. A kan nilo lati fi igbẹkẹle wa sinu rẹ ni, ki a si ṣe ohun yowu ti O ba sọ fun wa lori ipese rẹ fun wa. Adura mi ni pe eti wa ko ni di si ohunkohun ti O ba sọ fun wa nipa ipese rẹ fun iṣoriire wa. Nipa bayi, awa naa, bi Isaki, yoo le di ọlọrọ ni asiko iyan gbogbogbòò yi, ki a si jẹ ẹni ibukun fun awọn ti o wa ni ayika wa.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àkórí: Ọlọ́rọ̀ ní àsìkò ìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 20, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 12 Read More »

Kò ṣeéṣe láti tẹ́ẹ lọ́rùn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 13, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 11

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati tẹ lọrun ni gbogbo ọna. Amin.

Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, nipasẹ igbagbọ nikan ni a fi le tẹ Ọlọrun lọrun. Ki wa ni idi ti a ṣe nilo lati tẹ Ọlọrun lọrun? Idi ni pe Oun ni ẹlẹda, oluwa ati onidajọ aye wa. Ti a ba si wa ri ẹnikẹni ti a nilo lati tẹ lọrun, Ọlọrun ni ẹni naa. Ti a ko ba si ma tẹ ẹ lọrun, nṣe ni a n doju ete ti O fi da wa delẹ. Nitorina, idalẹbi ayeraye ni kiki nkan ti a le reti lati gba lọwọ rẹ.

Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe sọ siwaju, nipasẹ igbagbọ nikan ni a fi le tẹ Ọlọrun lọrun. Wo nkan ti bibeli sọ lori eyi:

“Ṣugbọn laisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wu u, nitori ẹni ti o ba n tọ Ọlọrun wa ko le sai gbagbọ pe o ri bẹ, ati pe oun ni oluṣẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wa a.” (Hébérù 11:6)

Wayi o, ṣe akiyesi pe bibeli ko sọ wipe, “Laisi igbagbọ o ṣoro lati wu Ọlọrun.” Eyi ko ba jasi pe bi eniyan ko tilẹ ni igbagbọ ninu Ọlọrun, o ṣi ṣeeṣe ki o le tẹ ẹ lọrun, ti o ba tiraka to. Ṣugbọn nkan ti bibeli sọ kọ niyẹn. Nkan ti o sọ nipe laisi igbagbọ ko ṣeeṣe rara lati tẹ Ọlọrun lọrun.

Ki gan wa ni igbagbọ ninu Ọlọrun? Akọkọ, o tunmọ si mimu Ọlọrun ni pataki. O tunmọ si pe ki a gba ohun yowu ti Ọlọrun ba sọ fun wa nipa ara rẹ, nipa ara wa ati nipa aye yi lapọpọ gẹgẹ bi otitọ ti a gbọdọ fi ṣiṣẹ ṣe. Ẹnikẹni ti ko ba si wa ma gbe aye rẹ lọna yi ko le tẹ Ọlọrun lọrun rara, bi o ti wu ki o dara loju awọn miran to. O kan n ṣe ti ara rẹ ni.

Ekeji, igbagbọ ninu Ọlọrun tunmọ si pe ki a gbẹkẹle patapata. Ki wa ni idi ti a fi nilo lati gbẹkẹle patapata? Idi ni pe Oun ni orisun ohun rere gbogbo ti a nilo lati jẹ ohun gbogbo ti a da wa lati jẹ laye. Ki a ni igbagbọ ninu rẹ wa jasi pe ki a ma gbe aye wa pẹlu afisọkan pe a ko le ṣe ohunkohun ti a nilo lati ṣe tabi ni ohunkohun ti a nilo lati ni lalai fi tirẹ ṣe. Ẹnikẹni ti ko ba si ma gbe aye rẹ lọna yi ko ma a tẹ Ọlọrun lọrun, bi o ti wu ki aye ti o n gbe ṣebi igba ti o rẹwa to. Ẹni naa kan n ṣe ti ara rẹ ni.

Njẹ ti eniyan ba wa ṣe aṣeyọri debi ti eniyan le ṣe aṣeyọri de laye yi, ti ko si wa tẹ Ọlọrun lọrun, ki gan ni o ti ri gbe ṣe? Òfo! Ki ni idi ti eyi ṣe ri bẹ? Idi ni pe kiki awọn ti o ba gbe aye wọn lati tẹ Ọlọrun lọrun ni yoo ba gbe titi lailai ninu ijọba ayeraye rẹ. Awọn ti ko ba gbe aye wọn lati tẹ ẹ lọrun, ti wọn kan n ṣe ti ara wọn, ko ni ibo miran ti wọn yoo ti ba ara wọn ju ọrun apadi lọ, ti wọn yoo si jina si Ọlọrun titi lailai.

Ti a ko ba wa fẹ ki eyi jẹ iriri wa, a gbọdọ mu igbagbọ wa ninu Ọlọrun ni pataki. A gbọdọ mu ohunkohun ti O ba sọ fun wa ni pataki. A tun gbọdọ fi igbẹkẹle wa sinu rẹ nikan fun ohun yowu ti a ba nilo laye. Bi Jesu ti ṣe gbe aye rẹ ni yi nigba ti o wa lorilẹ aye yi. O mu Ọlọrun ni pataki nipa fifi igba gbogbo ṣe kiki awọn nikan ti o wu u (Jòhánù 8:29). O tun fi igbẹkẹle rẹ sinu rẹ fun ohun gbogbo ti O nilo lati tayọ laye (Jòhánù 5:19). Nigba ti asiko rẹ si to nibiyi, Baba tẹwọgba si ọwọ ọtun rẹ. Njẹ ki a tẹwọgba awa naa lati gba awọn aye ti O ti pese silẹ fun wa ninu ijọba ayeraye rẹ nigba ti asiko wa ba to nibiyi, bi a ti ṣe ni gbe aye wa bi Jesu ti ṣe gbe tirẹ, iyẹn nipasẹ igbagbọ ninu Ọlọrun. Amin.

Ki o ni ọṣẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kò ṣeéṣe láti tẹ́ẹ lọ́rùn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 13, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 11 Read More »

Ti o ba ro wipe o duro ṣinṣin | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 06, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 10

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di ilọpo-ilọpo fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o ko sinu pakute yowu ti eṣu ti kẹ lati pa ọkan rẹ run. Amin.

Njẹ Ọlọrun ni agbara lotitọ lati ma jẹ ki a ko sinu pakute eṣu lati pa aye wa ati ọkan wa run? Bẹẹni, O ni agbara lati ṣe bẹẹ. Bibeli sọ eyi nipa rẹ:

“Njẹ mo fi yin le ẹni ti o le pa yin mọ kuro ninu ikọṣẹ, ti o si le mu yin wa siwaju ogo rẹ lailabuku pẹlu ayọ nla lọwọ – ti Ọlọrun ọlọgbọn nikan ṣoṣo, Olugbala wa, ni ogo ati ọlanla, ijọba ati agbara, nipasẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa, ki gbogbo aye to wa, nisinsin yii ati titi laelae! Amin.” (Júdà 24-25)

Ṣe o ri bayẹn? Ọlọrun ni agbara lati ma jẹ ki a kọsẹ tabi ṣubu. Yatọ si iyẹn, O tun ni agbara lati fa wa le ara rẹ lọwọ lalailabuku ati pẹlu ayọ nla. Ki a ti lẹ sọ otitọ, ti ko ba pa wa mọ kuro ninu iṣubu, o di dandan ki a subu, ki a si ma de ijọba ayeraye rẹ. Siwaju si, ti ko ba fa wa le ara rẹ lọwọ lalailabuku ati pẹlu ayọ, ko si bi a o ṣe le duro niwaju Jesu Oluwa wa nigba ti O ba de ninu ogo rẹ.

Nitorina, a ni lati kọ lati ma fa ara wa le lọwọ ninu adura nipa fifi ojoojumọ sọ fun pe ki O lo agbara rẹ lati ma jẹ ki a ṣubu tabi doju ti i ninu aye yi. Yatọ si iyẹn, a ko tun gbọdọ ro wipe a ko le ṣubu nitoripe a n gbadura, a n kẹkọ ninu Iwe mimọ, a n fifunni ati pe a n gbe igbe aye iwa ododo lasiko yi. Idi si ni pe igba ti a ba ro wipe a duro deede tan ninu irinajo igbagbọ wa ni o rọrun julọ fun satani lati kọ lu wa.

Ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe Jesu gbadura, ti O si wa lalai jẹun fun ogoji ọjọ ati ogoji oru, Satani si tun wa lati dan an wo. Ti ko ba wa lọ kun fun ọrọ Ọlọrun ati okun Ẹmi Mimọ ni, nṣe ni ko ba ṣubu, ti ko ba si tun dojuti Ọlọrun. Nitorina, bi o ti wu ki aye rẹ dabi ẹni wipe o tọ to lọwọlọwọ yi, ma fi igba gbogbo ranti ọrọ Iwe Mimọ yi: “Nitori naa, ẹni ti o ba ro pe oun duro, ki o kiyesara ki o ma ba a ṣubu.” (1Kọ́ríntì 10:12)

Ni igba wo ni a nilo lati kiyesara ki a ma ba ṣubu? Asiko ti a ba ro wipe a duro ṣinṣin ni. Ẹni ti o mọ wipe oun ko duro ṣinṣin nibi ti o wa ko nilo ẹnikẹni lati sọ fun pe o nilo lati kiyesara ki o ma ba a ṣubu. O mọ wipe ti oun ko ba kiyesra, o di dandan ki oun ṣubu. Ṣugbọn ẹni ti o ba ri ara rẹ bi ẹni ti o duro ṣinṣin nibi ti o wa le ma ri idi kankan lati kiyesara lati ma ṣubu. Idi si niyi ti iṣubu rẹ fi le wa lojiji, ki o to mọ ohun ti o n ṣẹlẹ. A si wa ma le ri atunṣe fun un.

Nigba wo ni Mose kuna? Asiko ti o dabi ẹni pe o ti mọ ohun gbogbo nipa Ọlọrun tan ati wipe ko le lailai ṣẹ ẹ ni. Igba wo si ni Dafidi kuna? Asiko ti ijọba ti fi idi mulẹ ṣinṣin lọwọ rẹ ni. Nitorina, igba ti a nilo lati kiyesara ju lati ma ko sinu pakute Satani ni igba ti ohun gbogbo ba n lọ ni irọwọ-rọsẹ fun wa ninu irin wa pẹlu Ọlọrun ati ninu aye wa. Ti a ba wa kuna lati mọ eyi, ki a si ma rin ni ibamu pẹlu rẹ, nkan ti a o san fun àmọ̀jù wa le pọ ju nkan ti agbara wa le ka lọ. (Wo: Númérì 20; 2Sámúẹ́lì 11)

Awọn nkan wọnyi wa ni idi ti a fi gbọdọ fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun patapata lati ma jẹ ki a ṣubu tabi doju ti i, eyi ti a o fi ma ro wipe a wa ni ailewu nitoripe a fi ara wa jin fun adura gbigba, ọrọ Ọlọrun, igbe aye ododo ati ififunni. Igbẹkẹle wa ko gbọdọ lailai wa ninu ohun rere yowu ti a n ṣe lati mu inu Ọlọrun dun. Dipo bẹẹ, o gba ma fi igba gbogbo wa ninu Ọlọrun funrarẹ. Aijẹbẹ, ti a ko ba ṣaanu fun wa, a o ṣubu ni ibi ti a ko ti lero pe a le e ṣubu. Mo gbadura pe ọkankan ninu wa ko ni ṣubu kuro ni ibi oore-ọfẹ Ọlọrun fun wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ti o ba ro wipe o duro ṣinṣin | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 06, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 10 Read More »

Òun nìkan ní Ó ní agbára àṣepé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 29, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 9

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òkúdù ati oṣu Agẹmọ 2025 papọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni aṣepe, bi a ti ṣe n wọ inu abala keji ọdun yi ninu ọsẹ naa. Amin.

Dafidi, ninu ọkan ninu awọn saamu rẹ, sọ wipe, “Oluwa yoo ṣe ohun ti n ṣe temi laṣepe; Oluwa, aanu rẹ duro laelae; Ma ṣe kọ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.” (Sáàmù 138:8) Tani yoo ṣe ohun ti o ni i ṣe pẹlu Dafidi ni aṣepe? Oluwa! Ki ni idi! Idi ni pe Oun nikan ni O ni agbara aṣepe lọwọ. Ti ko ba wa ṣe awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe, ko si ohun yowu ti a le ṣe lati ṣe aye wa ni aṣepe ti yoo ṣiṣẹ.

Ṣe a wa nilo aṣepe ni abala aye wa kankan bi? Ti a ko ba wa mọ tabi lero pe a nilo aṣepe ni abala aye wa kan, a ko ni pongbẹ fun un tabi gbe igbesẹ lati lọ fun un. Dafidi, fun apẹrẹ, ri kedere pe oun nilo aṣepe in awọn abala aye oun kan ni asiko ti o kọ saamu yi. Lotitọ, Ọlọrun ti fun ni ipo ẹyẹ, ibalẹ-ọkan, ilera ti o peye ati ọrọ. Ṣibẹsibẹ, o si tun ri wipe awọn nkankan si wa ninu aye, ile ati ijọba rẹ ti o nilo ki a tun wọn ṣe, ki a si tun ṣe wọn ni aṣepe. Eyi ti yoo fi wa ko ọkan soke lori awọn nkan wọnyi tabi ti yoo maa lakaka lati mojuto wọn funrarẹ, nṣe ni o fa wọn le Ọlọrun lọwọ, ti o si sọ wipe, “Oluwa yoo ṣe ohun ti n ṣe temi laṣepe.”

Nibakana, awa naa kọkọ gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan ti o nilo aṣepe ninu aye wa, bi o ti wu ki nkan ma dun fun wa to lọwọlọwọ yi. Aijẹbẹ, a ko ni ri idi ti a fi nilo lati fa wọn le Ọlọrun lọwọ, ẹnikanṣoṣo ti O ni agbara aṣepe lọwọ. Siwaju si, lẹyin igba ti a ba ti ṣe idamọ awọn nkan naa ti o nilo aṣepe ninu aye wa, a ko gbọdọ gbiyanju lati mojuto wọn pẹlu ọgbọn tabi okun wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni ki a fa wọn le Ọlọrun lọwọ.

Ki ni idi ti a fi gbọdọ ṣe eyi? Idi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni wipe a ko ni agbara aṣepe lọwọ. Ọlọrun nikan ni O ni lọwọ. Ti a ba si wa tiraka lati ṣe bi Ọlọrun ni ṣiṣe awọn nkan ti o ni ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe, bi o ti wu ki awọn nkan wọnyi rọrun to loju, ko ni pẹ rara ti a o fi ri wipe a ti jẹ ki nkan burúkú di bùrùkù mọ ara wa lọwọ.

Ranti Ọba Jeroboamu. Ranti wipe Ọlọrun ni O yan gẹgẹ bi ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli. Ṣugbọn nigba ti o ri wipe awọn nkankan le pa ijọba oun lara, ko tọ Ọlọrun lọ lati ṣe iṣẹ ti O bẹrẹ ninu aye rẹ laṣepe. Nṣe ni o darale ọgbọn ara rẹ. Nitorina, o mu iparun wa sori ara rẹ, sori ile rẹ ati sori orilẹ-ede naa lapapọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 11-14)

Wayi o, mo wa gbadura wipe a ko ni mu iparun wa sori ara wa tabi sori awọn miran ni ayika wa ninu igbiyanju wa lati ṣe awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe. Amọ a gbọdọ kọ lati ma ko aye wa ati ọrọ aye wa le Ọlọrun lọwọ ninu adura fun aṣepe wọn. Idi si ni pe ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ logun, O si tun ni agbara lati ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu wa ni aṣepe.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Òun nìkan ní Ó ní agbára àṣepé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 29, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 9 Read More »

Má ṣé ọkàn rẹ lè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 22, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 8

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Òkúdù 2025. Adura mi si ni pe ki eti rẹ ma ṣe lailai di si ohunkohun ti Ẹmi Ọlọrun ba n sọ fun ọ, ki o ba a le ma a fi igba gbogbo wa ni ailewu lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki o gbe. Amin.

Ninu iwe Heberu, oru ikẹta, a fun wa ni ikilọ yi: “Nitori naa gẹgẹ bi Ẹmi Mimọ ti wi: “Loni-in bi ẹyin ba gbọ ohun rẹ, Ẹ ma ṣe ṣe ọkan yin le…”” (Hébérù 3:7-8) Tani o n ba wa sọrọ nibiyi? Ẹmi Mimọ ni! Ki si ni O n ba wa sọ? O n sọ fun wa pe nigba ti oni ba si n jẹ oni, a ko gbọdọ ṣe ọkan wa le ti Ọlọrun ba n ba wa sọrọ. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ sọ pe dandan lai ifẹ inu wa ni a o ṣe, nigba ti Ọlọrun tilẹ ti sọ fun wa ohun ti O fẹ ki a ṣe.

Njẹ ki wa ni idi ti ko fi yẹ ki a ṣe ọkan wa le ti Ọlọrun ba n ba wa sọrọ? Idi ni pe ṣiṣe eyi di dandan ki o yọri si idojuti, inira tabi iparun fun wa. Ranti nkan ti a sọ ninu bibeli nipa Farao ti o kọ lati jẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli jade lati lọ sin Ọlọrun. A sọ wipe ọba yi ṣe ọkan rẹ le, o si kọ lati ṣe ohun ti Ọlọrun pa lasẹ. Lemọlemọ ni o n kọ eti didi si nkan ti Ọlọrun n sọ fun. Bawo wa ni ọrọ naa ṣe yọri si fun oun ati awọn eniyan rẹ? O yọri si nkan ti ko dara rara-rara ni. (Wo: Ẹ́kísódù 8:15:32)

Amọ ṣa o, ẹnikan le wa sọ wipe, “Ṣebi Ọlọrun funrarẹ ni O ṣe ọkan Farao le. Ṣe o wa yẹ ki ẹnikẹni ru ẹbi le lori bi?” Otitọ ni pe Ọlọrun ni O ṣe ọkan ọkunrin yi le. Ki si ni idi ti O fi ṣe bẹ ẹ? Akọkọ, O ṣe bẹ ẹ nitoripe ọkunrin naa funrarẹ ko fi igba kankan ṣetan lati gbọ nkan ti Ọlọrun ni lati ba a sọ. Eyi si n fi han wa pe aiṣetan wa lati gbọ nkan ti Ọlọrun n ba wa sọ di dandan ki o yọri si iṣele ọkan wa. Eyi tunmọ si pe igbakigba ti a ba yan lati kọ eti didi si nkan ti Ọlọrun n ṣọ fun wa, nṣe ni ọkan wa yoo jẹ ṣiṣe le si otitọ rẹ si i. Yoo wa ma ṣoro si fun wa lati ronupiwada ati lati gba ara wa kuro lọwọ idajọ rẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 9:12; Ẹ́kísódù 10:20&27)

Idi miran ti Ọlọrun tun ṣe ṣe ọkan Farao le ni lati kọ wa pe Oun nikan ni O ni agbara lati jẹ ki awọn eniyan ronupiwada. Ti ko ba si lo agbara yi lati jẹ ki wọn ronupiwada, ko si nkankan ti a le sọ fun wọn tabi ṣe fun wa ti yoo jẹ ki wọn ronupiwada. Ranti pe igbakigba ti idajọ Ọlọrun ba wa sori Ijibiti nitori orikunkun Farao, nṣe ni yoo sọ fun Mose pe ki o ṣipẹ si Ọlọrun fun oun ati awọn eniyan rẹ. Ṣugbọn ni kete ti o ba ti ni iriri itura diẹ, nṣe ni yoo tun ṣe ọkan rẹ le lẹẹkan si.

Nitorina, nini iriri didara tabi aanu Ọlọrun ni ọna ti o ga ko to lati jẹ ki ẹnikẹni gbọran si lẹnu. Oun funrarẹ ni lati ṣiṣẹ lori ọkan wa lati jẹ ki a gbọ nkan ti O n sọ fun wa. Aijẹbẹ, bi O tilẹ fi wa sinu Edeni, bi O ti ṣe fun Adamu ati Efa, a o tun ṣe ọkan wa le si, ti a o si taari rẹ lati le wa jade kuro nibẹ.

Idi wa niyi ti o fi jẹ pe, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi, o nilo lati kọ lati ma a fi ojoojumọ gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o ṣe ọkan rẹ le si ohun yowu ti O ba n sọ fun ọ. Nipa bayi, iwọ yoo le ma fi igba gbogbo wa ni ailewu lati jẹgbadun didara ati aanu rẹ ni aye.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má ṣé ọkàn rẹ lè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 22, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 8 Read More »

Dídá olùtùnú rẹ mọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 15, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 7

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2025. Adura mi si ni pe ki o gba itunu Ẹmi Ọlọrun lẹkunrẹrẹ nibikibi ti ara ba ti n ni ọ tabi ti irẹwẹsi ba ti ba ọkan rẹ. Amin.

Wayi o, ọkan lara ọna ti Ọlọrun ma n gba tu wa lara ni asiko idanwo tabi idojukọ ni nipa riran awọn eniyan lati ṣe awọn nkan ti yoo tu wa lara fun wa. Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinti nipa bi Ọlọrun ṣe tu wọn lara nigba ti wọn wa ni Makedonia:

“Nitori pe nigba ti awa tilẹ de Makedonia, ara wa ko balẹ, ṣugbọn a n pọn wa loju niha gbogbo, ija n bẹ lode, ẹru n bẹ ninu. Ṣugbọn ẹni ti n tu awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tu wa ninu nipa dide Titu de.” (2Kọrinti 7:5-6)

Njẹ o ri bayẹn? Pọọlu jẹ ki o ye wa yekeyeke pe nkan ko rọgbọ fun oun ati awọn akẹgbẹ rẹ rara nigba ti wọn n waasu iyinrere ni Makedonia. A yọ wọn lẹnu, a si tun pọn wọn loju ni ibi gbogbo ti wọn ya si. Eyi jasi pe gbogbo igba ni wọn fi n wa ni bebe iyọnu. Nitorina, ifoya ko jina si wọn rara.

Bawo wa ni Ọlọrun ṣe mojuto wọn ni asiko naa, ti nkan ko fi su wọn, ki wọn si sọ ireti nu? Nipa riran Titu, ọkan lara awọn akẹgbẹ wọn ninu iṣẹ iranṣẹ, si wọn ni. Ki wa ni Titu ṣe fun wọn nigba ti o de ọdọ wọn? Pọọlu ko mẹnuba nkan ti o ṣe ninu akọsilẹ naa. Ṣugbọn o sọ fun wa pe Ọlọrun lo wiwa ọkunrin naa lati tu wọn lara. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe irẹwẹsi ti ba wọn ki o to de, wiwa rẹ fun ọkan wọn ni itura ati isọdọtun.

Nibakanna, Ọlọrun le ran awọn eniyan sinu aye wa lati tu wa lara ati lati gbe wa soke ninu awọn idanwo wa. Ṣugbọn njẹ a o da wọn mọ bi? Ti Pọọlu ko ba da Titu mọ gẹgẹ bi olutunu ti Ọlọrun ran lati tu wọn ninu ati lati gbe wọn soke ni Makedonia, njẹ ko ni padanu itunu ti o mu wa bi? Nṣe ni ko ba padanu rẹ. Lotitọ, oun ati awọn yoku le ti ma gbadura si Ọlọrun fun itura ninu gbogbo awọn idanwo wọn ni asiko naa. Ṣugbọn ti wọn ko ba da ẹni ti Ọlọrun ran lati tu wọn lara mọ, ti wọn ba kan lọ ri wiwa rẹ bi iṣọnu lasanlasan, nṣe ni wọn ko ba padanu idahun si adura wọn.

Nitorina, ọtọ ni ki Ọlọrun ran olutunu si wa ni idahun si adura wa; ọtọ ni ki awa naa da wọn mọ, ki a si fi aye gba wọn lati tu wa ninu. Ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i ṣe gbadun itunu rẹ ninu aye wọn bi o ti ṣe yẹ ni pe wọn ko da awọn ti o ran lati tun wọn ninu mọ. Ki ni idi? Idi kan pataki ni pe awọn eniyan wọnyi naa ni aleebu ti ara wọn. Nitorina, wọn le ni awọn iwa ti yoo rin awọn miran lara tabi ti yoo bi wọn ninu tabi ti yoo ṣi wọn lọna. Ti a ba si wa gbajumọ kiki awọn nkan ti ko dara ninu aye wọn, a le pada pa wọn ti, bu wọn tabi fi idibajẹ sinu aye wọn, ki a si padanu itunu ti Ọlọrun ran wọn lati fi fun wa.

Idi si ni yi ti a ṣe gbọdọ kọ lati ma gbadura si Ọlọrun lati ma fi igba gbogbo da awọn ti O n ran lati tu aye wa lara ati lati gbe wa soke mọ, ki a ba a le ba wọn ṣe pọ ni ọna ti o tọ, ki a si jẹ igbadun itunu ti wọn mu wa lẹkunrẹrẹ. Njẹ ki o gba okun lati ma fi ojoojumọ mu eyi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Dídá olùtùnú rẹ mọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 15, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 7 Read More »

Ìgbàgbọ́ tó múra sílẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 08, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 6

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji oṣu Okudu 2025. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ maa fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o ni. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ko le ri ohun rere kankan gba laye yi, ti ko ba jẹ wipe Ọlọrun ti pese ohun naa. Eyi jasi pe kiki nkan ti Ọlọrun ba fifun wa tabi pese nikan ni a le ri gba. Ti ko ba pese nkan, ko si ẹni naa, bi o ti wu ki igbagbọ rẹ ga to, ti o le ri ohun naa gba. (Wo: Jòhánù 3:27)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ti pese nkan fun wa, awa naa nilo lati fẹ lati ni nkan naa. Aijẹbẹ,nkan naa le ma lailai jẹ ti wa, ayaafi ti a ba ṣaanu fun wa. Fun apẹrẹ, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, idile Sakaraya ati Elisabẹti wa ni ailọmọ fun ọpọlọpọ ọdun, bi o tilẹ jẹ wi pe olododo ni wọn jẹ niwaju Ọlọrun. Eyi ko si wa jẹ ki wọn yipada tọ oriṣa kankan lọ. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn tẹsiwaju lati ma a gbadura si Ọlọrun lati ṣaanu fun wọn ati lati mu ẹgan wọn kuro. (Wo: Lúùkù 1:5-7)

Njẹ bawo ni mo ṣe wa mọ pe wọn n gbadura si Ọlọrun lati mu ẹgan airọmọbi kuro ninu ile wọn? Mo mọ nitoripe, bi a ti tun ṣe ri ninu bibeli, nigba ti Ọlọrun ran angẹli Geburẹli lati fun wọn ni iyinrere idahun si adura wọn, nkan akọkọ ti o sọ fun Sakaraya ni pe, “Adura rẹ ti gba.” Nitorina, ti a ko ba rẹwẹsi ni gbigbadura si Ọlọrun, o di dandan ki a ri idahun gba si adura wa, niwọn igba ti o ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Lotitọ, idahun naa le gba asiko diẹ ki o to de ọdọ wa. Ṣugbọn o di dandan ki o de. (Wo: Lúùkù 1:13)

Amọ ṣa o, njẹ idahun Ọlọrun si awọn adura wa yoo ba wa ni imurasilẹ nigbagbo bi? Njẹ a o wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ohun naa ti O fẹ ki a ni, eyi ti awa gan naa ti le ma gbadura ati pongbẹ fun, nigba ti a ba pada mu nkan naa tọ wa wa? Sakaraya ko si ni imurasilẹ lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ọmọ ti o ti n fi ọpọlọpọ ọdun gbadura fun nigba ti Ọlọrun pada la ọna fun ọmọ naa lati tọ ẹbi rẹ wa. Ko gbagbọ pe Ọlọrun le fun awọn ni ọmọ nitootọ ni ọjọ ogbo wọn. (Wo: Lúùkù 1:11-20)

Ki wa ni o n gbadura si Ọlọrun fun ọmọ fun ni gbogbo awọn ọdun wọnni? O dabi ẹni pe o kan n gbadura lati mu gbogbo ododo daju ni. Ti Ọlọrun ko ba wa ṣaanu fun, bi o tilẹ jẹ wipe ko gbagbọ, oun ni ko ba jẹ idi ti iyawo rẹ ko ba fi jade laye lalai lọmọ.

Nitorina, adura gbigba si Ọlọrun lati fun wa ni nkan ko to. Ọkan wa tun gbọgbọ ma fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba nkan ti a n gbadura fun lọwọ rẹ, bi o ti wu ki idahun si adura naa pe to ati bi o ti wu ki o dabi enipe o ṣoro fun idahun si adura naa lati tẹ wa lọwọ. Aijẹbẹ, adura wa fun nkan naa le pada jasi pabo.

Yatọ si eyi, a gbọdọ ma a fi igba gbogbo fi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun, ki igbagbọ wa ba a le gba okun lati ma fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Maria iya Jesu, fun apẹrẹ, ko fi igba kankan gbadura si Ọlọrun lati di iya olugbala araye. O tilẹ ṣeeṣe ki o ma fi igba kankan gbe yẹwo tabi ka si babara ẹṣẹ Iwe mimọ ti o sọrọ nipa wundia kan ti yoo loyun, ti yoo si bi olugbala. Ṣugbọn nigba ti angẹli Geburẹli wa lati sọ fun pe oun ni Ọlọrun yan lati jẹ iya olugbala, igbagbọ rẹ wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba nkan ti Ọlọrun ti yan an fun. Nitorina, o sọ wipe, “Jẹ ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọrọ rẹ.” O si ri bẹẹ. (Wo: Àìsáyà 7:14; Lúùkù 1:36)

Nibakanna, ti igbagbọ wa ba n fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati ri gba lọwọ Ọlọrun, ohun yowu ti O ba fẹ ki a ni yoo jẹ ti wa, bi a ko tilẹ fi igba kankan ri gbadura fun un. Nitorina, nṣe ni ki a kọ lati ma a fi ojoojumọ bọ ara wa pẹlu ọrọ rẹ, ki a ba a le ma fi igba gbogbo ni igbagbọ to murasilẹ lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Njẹ ki iwọ ati emi gba okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí o ga.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìgbàgbọ́ tó múra sílẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 08, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 6 Read More »