Má gbé ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ rẹ nínú rẹ̀ sọnù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 25
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun naa, mojuto ajaga yowu ti o le ma a rin ọ mọlẹ, ki O si tun tu ọ lara ni ibi yowu ti ara ti le ma a ni ọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, bi o tilẹ jẹ wipe otitọ ni pe Ọlọrun le mojuto gbogbo ajaga wa, ki O si tun tu wa lara, o tun ṣe pataki ki a ma gbe igbẹkẹlẹ wa ninu rẹ ju sọnu nitori ohun yowu ti a le ma a la kọja. Ṣe o ri, pe Ọlọrun n mojuto ọrọ wa ko tunmọ si pe lẹsẹkẹsẹ naa ni a o ni iriri itura. A le ma a ni iriri itura lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn ti a ko ba gbe igbẹkẹle wa ninu rẹ sọnu, o di dandan ki a ni iriri ominira ti o peye kuro lọwọ ohun yowu ti Satani le ma gbiyanju lati lo lati fi pa wa run.
Fun apẹrẹ, nigba ti Ọlọrun ran Mose lọ si Ijibiti lati tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ, ko ki i ṣe lẹsẹkẹsẹ naa ni wọn ri itura gba. Dipo eyi, nṣe ni Farao mu nkan le si fun wọn. Ki a ti lẹ sọ otitọ, Mose ni lati pada sọdọ Ọlọrun lati sọ wipe:
“OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi? Nitori igbati mo ti tọ̀ Farao wá lati sọ̀rọ li orukọ rẹ, buburu li o ti nṣe si awọn enia yi; bẹ̃ni ni gbigbà iwọ kò si gbà awọn enia rẹ.” (Ẹ́kísódù 5:22-23)
Ṣe lotitọ wa ni pe Ọlọrun ko gbe igbesẹ kankan lati tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ? Rara o! O ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ fun itusilẹ wọn ni asiko naa. Amọ ṣa o, Mose ati awọn eniyan naa nilo lati fi suuru tẹsiwaju lati ma a gbẹkẹ le e, ki wọn ba a le jẹgbadun ere gbogbo nkan ti O n ṣe lati gba wọn la lẹkunrẹrẹ. Njẹ wọn wa ṣe eyi? Bẹẹni. Nitorina, a papa tu wọn silẹ kuro ni Ijibiti, a si tun dari wọn wọ inu Ilẹ-Ileri.
Nibakana, awa naa nilo lati ma a fi suuru tẹsiwaju ni gbigbẹkẹle Ọlọrun, ki a ba a le ni iriri ẹkunrẹrẹ ere gbogbo nkan ti O n ṣe lati ṣe ohun gbogbo ti o n ṣe ti wa ni aṣepe. Nitorina, bibeli sọ eyi fun wa:
“Nitorina ẹ máṣe gbe igboiya nyin sọnu, eyiti o ni ère nla. Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na.” (Hébérù 10:35-36)
Njẹ o ri bayẹn? Lakọkọ, a sọ wipe ki a ma ṣe gbe igbẹkẹle wa ninu Ọlọrun sọnu. Kini idi? Idi naa ni pe a o pin wa ni ere ti o ga lori rẹ. Eyi jasi pe, Ọlọrun ko ni lailai ja awọn ti ko ba gbe igbẹkẹle wọn ninu rẹ ju sọnu kulẹ. Ekeji, a sọ wipe ki a ni ifarada ni ṣiṣe ifẹ Ọlọrun ni asiko idojukọ aye wa. Eyi tunmọ si pe ki a ma ṣe dẹkun lati ma gbadura, lati ma ṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun, lati ma sọ ọrọ Ọlọrun si awọn idojukọ wa ati lati ma rin ninu ododo. Kini idi? Eyi nikan ni ọna fun wa lati ri imuṣẹ ifẹ rẹ ninu aye wa.
Wayi o, awọn idojukọ ti a n koju le jẹ ki o dabi ẹni pe ifasiko-ṣofo ni fun wa lati tẹsiwaju lati ma gbadura ati lati ma gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun, paapaa julọ ti nkan ba n buru si fun wa dipo ki wọn ma a san si. Ṣugbọn ọrọ Ọlọrun ti sọ fun wa pe oju ko ni ti awọn ti ko ba gbe igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun ju sọnu. Nitorina, tẹsiwaju lati ma gbadura ati lati ma ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun,. Nigba ti asiko ba si to, iwọ yoo kore didara ati igbala rẹ ninu aye rẹ lọna ti o ga.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)