Author name: 23?Racing_Horse

Àwọn tó lọ́ra láti kẹ́kọ̀ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 01, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 5

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Krisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kẹfa ọdun yi, iyẹn oṣu Òkúdù 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma a fi ojuoojumọ oṣu naa fun ọ ni okun lati ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ rẹ lati dagbasoke lati jẹ ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ. Amin.

Ninu iwe awọn Heberu, onkowe yi sọ fun wa pe o ṣeeṣe ki idagbasoke wa ninu ẹmi ba idena pade. Ọkan lara awọn nkan ti o si le jẹ ki eyi waye ni aiṣetan wa lati ṣe akitiyan lati kọ otitọ Ọlọrun, lati ni oye rẹ ati lati ṣe amulo rẹ ninu aye wa. Wo bi o ti ṣe gbe ọrọ naa kalẹ:

“Nipa eyi awa ni ohun pupọ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitori pe ẹ yigbi ni gbogbọ. Nitori pe bayii o ti yẹ ki ẹ jẹ olukọni, ẹ tun wa ni ẹni ti ẹnikan yoo maa kọ ni ibẹrẹ ipilẹ ẹkọ awọn ọrọ Ọlọrun, ẹ si tun di iru awọn ti o n mu wara, ti wọn ko si fẹ ounjẹ lile.” (Hébérù 5:11-12)

Njẹ o ri bayẹn? Eniyan Ọlọrun yi ni ọpọlọpọ nkan ti o fẹ ba awọn ara ninu Oluwa ti o kọkọ gba lẹta rẹ yi sọ lori igbe aye igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Ṣugbọn o nira fun lati ṣe bẹẹ. Ki ni idi? Idi, gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, ni pe wọn lọra lati kẹkọọ. Eyi ko si wa jasi pe wọn ko ni amuyẹ lati kẹkọọ ati lati ni oye nkan ti a n kọ wọn. Dipo bẹẹ, o jasi pe wọn ya ọlẹ ninu ki a kẹkọọ. A tun le sọ wipe eyi tunmọ si pe wọn ko ma ṣe akitiyan ti o nitunmọ kankan lati ni oye nkan ti a n kọ wọn ati lati fi wọn ṣiṣẹ ṣe.

Nitorina, bi eniyan Ọlọrun yi ti ṣe tẹsiwaju lati sọ ninu ẹsẹ bibeli naa, nigba ti o yẹ ki awọn eniyan wọnyi ti di olukọ, nigba ti o yẹ ki wọn ti di ẹni ti o n mojuto awọn ti o ṣẹṣẹ di onigbagbọ, nṣe ni awọn funralara wọn ṣi tun nilo ẹnikan ti yoo ṣẹṣẹ ma tun kọ wọn lẹẹkansi ni awọn nkan ipilẹ ọrọ Ọlọrun. Nigba ti o yẹ ki wọn ti di agbalala ninu ẹmi ti a le fa awọn ọmọ-ọwọ ninu ẹmi le lọwọ fun itọju, awọn funralara wọn si tun n fẹ ki a ma mojuto wọn bi ọmọ-ọwọ. Wa wo irufẹ iforo ti eyi ni lati jẹ fun eniyan Ọlọrun yi ati awọn adari awọn ara ninu Oluwa wọnyi. Bẹẹni, gbiyanju lati ro irufẹ irẹwẹsi ti eyi mu wa sinu ọkan wọn.

O si wa ṣeni laanu pe, loni gan, ẹwẹ, a si tun ri ọpọ awọn eniyan Ọlọrun ti awọn naa ya ọlẹ ninu ki a kọ awọn otitọ ẹmi ati ki a ṣe amulo awọn otitọ naa. Awọn wọnyi n jẹ ki awọn adari ijọ wọn ma kọ wọn ni nkankan naa ṣaaṣaa. Wọn n jẹ ki wọn ma ba wọn wi ṣaaṣaa lori bi wọn ṣe n gbe ile aye wọn ninu ẹtanu, ninu ikorira, ninu imọtara-ẹni-nikan, ninu ifẹkufẹ, ninu igberaga, ninu owu jijẹ ati ninu ainitara fun Ọlọrun. Nitorina, wọn n fa ifasẹyin fun iṣẹ iranṣẹ awọn adari wọn ati ti ijọ wọn – wọn n jẹ ki o nira fun wọn lati le kan si ati bukun fun ọpọ eniyan miran fun Oluwa.

Ki wa ni ki awọn adari ijọ ṣe si irufẹ awọn eniyan wọnyi? Ọna wo ni ki awọn adari gba lati mojuto awọn ti o n fooro ilakaka wọn lati tọ wọn ninu ifẹ Ọlọrun? Ni kukuru, bi onkọwe iwe Heberu ṣe sọ fun wa, nigba ti o ba to asiko kan, wọn yoo dẹkun lati ma tọju awọn ọlẹ-ẹmi onigbagbọ wọnyi bi ìkókó. Bẹẹni, wọn yoo nilo lati bẹrẹ si ni kọ wọn ni awọn nkan ti wọn ko fẹ kọ ati lati dẹkun lati ma mojuto wọn bi ọmọ-ọwọ ninu ẹmi nipa mimu wọn ṣe awọn nkan ti wọn ko fẹ ṣe funra wọn. (Wo: Hébérù 6:1-3)

Ṣe eyi yoo wa mu inu irufẹ awọn onigbagbọ wọnyi dun bi? Rara! Ki a tilẹ sọ otitọ, o le jẹ ki awọn miran lara wọn dẹkun patapata lati ma wa sinu ipade awọn ọmọ Ọlọrun. Amọ, yala o mu inu wọn dun tabi ko mu inu wọn dun, nkan ti o gbọdọ jẹ ṣiṣẹ gbọdọ jẹ ṣiṣe, ki awọn wọnyi ma ba a le di idagbasoke awọn ijọ wọn lọwọ mọ. Nitorina, ti o ba ti jẹ ọmọ Ọlọrun fun ọdun meji tabi ju bẹẹ lọ, ti o si tun wa kọ lati dagbasoke ninu igbagbọ rẹ ki o ba a le di ẹni ti adari ijọ rẹ le fi ọkan tan pẹlu oniruuru ojuṣe, o lọra lati kẹkọọ niyẹn, o si tun ya ọlẹ ninu ẹmi. Ti o ba si tẹsiwaju lati ri bi eleyi, ti o n fa ifasẹyin fun awọn adari ijọ rẹ, o le ma pẹ ti awọn naa yoo fi bẹrẹ si ni yẹra fun ọ, ki o ba a le dẹkun lati ma jẹ ìkókó ninu ẹmi. Eyi ko si le jẹ nkan ti yoo ba ọ lara mu.

Nitorina, sọji ki o to pẹ ju, ki o si bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun pe ki O fun ọ ni itara ati okun ti o peye lati bẹrẹ si ni ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati dadasoke ninu ẹmi lọna ti o peye. Aijẹbẹ, ko ni pẹ rara ti awọn ti wọn di atunbi lẹyin rẹ yoo fi di olukọ rẹ ninu Oluwa.

Kí o ní oṣù Òkúdù 2025 alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àwọn tó lọ́ra láti kẹ́kọ̀ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 01, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 5 Read More »

Gbájúmọ́ ǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 25, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 4

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Èbìbí 2025. Adura mi si ni pe gbogbo iṣẹ rere Ọlọrun lori aye rẹ ni yoo jẹ aṣepe, ni ibamu pẹlu nkan ti o nilo lojoojumọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Filipi, sọ eyi fun wa nipa Ọlọrun: “Nitori pe Ọlọrun ni o n ṣiṣẹ ninu yin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ete rere rẹ.” (Fílípì 2:13) Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu aye gbogbo awọn ti a jẹ ọmọ rẹ. Ki ni idi? Idi ni ki O ba a le mu ete rere rẹ fun aye wa ṣẹ.

Eyi jasi pe Ọlọrun ko joko tẹtẹrẹ. Ko ma a sun tabi kawọ-gbera, nigba ti awa n ṣiṣẹ karakara, ti a si n wọya-ija pẹlu Satani ati awọn ẹmikẹmi rẹ, ki a ba a le ja mọ nkan laye. Dipo eyi, nṣe ni Oun naa n ṣiṣẹ ninu aye wa, ki O ba a le ri daju pe gbogbo erongba rẹ ni rere fun wa wa si imuṣẹ ati wipe gbogbo akitiyan wa laye ko ja si pabo.

Wayi o, a le ma ri nkan ti Ọlọrun n ṣe ni awọn abala aye wa kan. O tilẹ le ma dabi igba ti o n ṣiṣẹ rara ninu aye wa. Eyi ko wa jasi pe ko ma ṣiṣẹ. Ọrọ rẹ sọ fun wa pe O n ṣiṣẹ ninu aye wa. Otitọ si ni ọrọ rẹ ni gbogbo igba. Nitorina, yala a le e ri nkan ti O n ṣe lati mu ete rere lori aye wa wa si imuṣẹ tabi a ko le e ri, nṣe ni ki a ṣa gba nkan ti ọrọ rẹ sọ gbọ, ki a si bẹrẹ si ni gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu rẹ. Ti a ko ba si rẹwẹsi, a o ri ifarahan awọn iṣẹ rerẹ rẹ ninu aye wa nigba ti asiko ba to.

O wa ṣeni laanu pe, ọpọ ninu wa fẹran lati gbajumọ nkan ti Satani ati awọn ẹmikẹmi rẹ n ṣe lati ba aye wa jẹ ju nkan ti Ọlọrun n ṣe lati sọ wa di ẹni ti o yẹ ki a da lọ. Ki a tilẹ sọ ododo, kiki nkan ti Satani n ṣe ni awọn miran ninu wa ma n ṣaba gbajumọ. A ko ki i tilẹ fojusọna rara lati ri nkan ti Ọlọrun n ṣe. Eyi si jẹ ọkan lara awọn idi ti a ko fi ma ri ifarahan ogo rẹ ati aṣepe iṣẹ rere rẹ ninu aye wa bi o ti ṣe yẹ ki o ri.

Lotitọ, iṣẹ Satani wa. Aisan, arun, Ìṣẹ́, ijamba ati iku wa. Lafikun, irora ati ibanujẹ wa. Awọn nkan wọnyi si le farahan wa to bẹẹ gẹẹ ti a o fi ro wipe ko si ọna abayọ kuro lọwọ wọn fun wa. Nkan ti Satani naa si fẹ ni eyi. O fẹ ki a ma a ro wipe ko si ọna abayọ fun wa kuro lọwọ awọn nkan ti o n lo lati pọn wa loju. Ni kete ti a ba si ti bẹrẹ si ni ronu bayi, a o yi oju wa kuro lara nkan ti Ọlọrun n ṣe lati gba wa la ati lati gbe wa soke.

Fun apẹrẹ, nigbati Mose wa lati gba awọn ọmọ Isiraẹli la kuro ni Ijibiti, awọn ara Ijibiti sọ ipọnju wọn di ilọpo-ilọpo. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori ọrọ wọn lati tu wọn silẹ, wọn ko kọbiara si nkan ti O n ṣe rara; kiki nkan ti wọn kọbiara si ni ipọnju wọn. Ti Mose naa ba wa lọ dabi ti wọn ni, ti o jẹ pe kiki ipọnju wọn nikan ni o n kọbiara si, dipo ti yoo fi gbajumọ nkan ti Ọlọrun n ṣe, itusilẹ wọn kuro ni Ijbiti ko ba di ọjọ miran-ọjọ ire. (Wo: Ẹ́kísódù 5)

Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ wipe Mose ri ipọnju awọn ara Isiraẹli yi, ti inu rẹ ko si dun si, ko gbajumọ ipọnju yi. Dipo eyi, nṣe ni o tẹ oju rẹ mọ Ọlọrun ati nkan ti O n ṣe lati gba wọn la. Nitorina, o ṣeeṣe fun lati gba itusilẹ lati ọwọ Ijibiti fun wọn nigba ti asiko to.

Nibakanna, bi o tilẹ jẹ wipe a le ri nkan ti Satani n ṣe lati pa wa lara, ti inu wa ko si dun si, a ko gbọdọ gbajumọ rara-rara. Aijẹbẹ, nkan ti o n ṣe yi ni a o ma fi asiko wa ṣofo lati sọrọ le lori. Eyi yoo si mu ki irẹwẹsi ba ọkan wa. Ṣugbọn ti o ba jẹ wipe Ọlọrun ati nkan ti O n ṣe ninu aye wa ni a tẹjumọ, bi o ti wu ki ohun ti Satani n ṣe ti ma pa wa lara to, ọkan wa yoo ma fi ojoojumọ gba okun lati fi suuru duro de e titi yoo fi mu ete rere rẹ ṣẹ ni abala kọọkan aye wa ati ni asiko ti o tọ. Nitorina, gbajumọ nkan ti Ọlọrun n ṣe ninu aye rẹ ati ni ayika rẹ. Iwọ ko si ni lailai padanu ifarahan ogo rẹ kankan mọ.

Kí o ní ọ̀ṣẹ̀ ológo.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Gbájúmọ́ ǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 25, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 4 Read More »

Kí oore-ọ̀fẹ́ ba à pọ̀ sí | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 18, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 3

Olufe: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di ilọpo-ilọpo si fun ọ lalai ni odiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2025. Adura mi si pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o le e ma ṣiṣẹ lodi si ifarahan oore-ọfẹ rẹ̀ ni ẹkunrẹrẹ ninu aye rẹ, ki o ba a le di gbogbo nkan ti O fẹ ki o da, ki O si tun jẹgbadun gbogbo nkan ti O fẹ ki o jẹgbadun laye. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o ma n di ifarahan oore-ọfẹ Ọlọrun lọwọ ninu aye awọn ọmọ rẹ ni ẹṣẹ. Irufẹ ẹṣẹ wo si ni eyi? Irufẹ ẹṣẹkẹṣẹ ni! Eyi tunmọ si pe bi iṣekuṣe ṣe le di ifarahan oore-ọfẹ Ọlọrun lọwọ ninu aye awọn ọmọ rẹ naa ni ojukokoro, ole-jija, ẹtanu, imutipara, owu-jijẹ ati ifọrọ-batẹnijẹ ṣe le e di lọwọ.

O wa ṣeni laanu pe, ọpọ ninu wa ni oye eyi ko ye. A ro wipe kiki awọn ẹṣẹ ti o han kedere bi agbere, imutipara ati ole-jija nikan ni o le di ifarahan oore-ọfẹ Ọlọrun lọwọ ninu aye wa. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ ni o le di ifarahan oore-ọfẹ rẹ lọwọ ninu aye wa. Idi si ni yi ti Pọọlu ṣe bere ibere yi lọwọ gbogbo wa: “Njẹ a le tẹsiwaju lati ma dẹṣẹ ki oore-ọfẹ le ma a pọ si bi?” Idahun re si ni pe, “Irọ o, a ko le tẹsiwaju lati ma gbe ninu ẹṣẹ, ki a si tun ma reti ọpọ oore-ọfẹ Ọlọrun si ninu aye wa.”

Ki ni idi ti eyi fi ri bẹ? Idi ni pe a nilo oore-ọfẹ Ọlọrun lati rin ni iṣẹgun lori ẹṣẹ. O si ti wa pese oore-ọfẹ lọfẹ-lọfẹ fun wa lati ṣe bẹẹ (Títù 2:11). Ti a ko ba wa ma a rin ni iṣẹgun lori ohun gbogbo ti o n jẹ ẹṣẹ, a jẹ wipe a ko i ti ma ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ rẹ niyẹn. Nitorina, a ko lẹtọ lati reti ifarahan oore-ọfẹ rẹ ninu aye wa lọpọlọpọ si.

Nkan ti a n sọ ni pe fun wa lati le ni iriri ifarahan oore-ọfẹ Ọlọrun ti o ga tabi pọ si ninu aye wa, a nilo lati kọkọ bẹrẹ si ni ṣe amulo ti o peye irufẹ oore-ọfẹ yowu ti O ti fifun wa naa. Ti a ko ba ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ ti O ti fifun wa naa, ko le e fun wa si i. Lotitọ, awọn eniyan le ma a gbadura pe ki a ri ọpọ oore-ọfẹ gba si. Ṣugbọn kiki igba ti a ba n lo oore-ọfẹ ti Ọlọrun ti pese fun wa naa, ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ, ni adura yi yoo ṣiṣẹ.

Wo Samusoni, fun apẹrẹ. Nigba ti o bẹrẹ si ni kopa ninu iṣẹkuṣe, ṣe Ọlọrun sọ oore-ọfẹ rẹ ninu aye rẹ di ilọpo-ilọpo si? Rara! Dipo eyi, nigba ti o to asiko kan, nṣe ni oore-ọfẹ naa dawọ iṣẹ duro. Nitorina, o bọ si ọwọ awọn ọta rẹ, wọn si ṣe e ni baṣubaṣu. Eyi si n fi han wa pe a ko le ma lo oore-ọfẹ Ọlọrun lati gbe igbe aye ti o lodi si ifẹ rẹ, ki a si tun ma reti pe ki o ma a fi gbogbo igba ṣiṣẹ daradara fun wa tabi pe ki o ma pọ si ninu aye wa.

Amọ ṣa o, a le reti pe ki ifarahan oore-ọfẹ Ọlọrun ninu aye wa bẹrẹ si ni yoro tabi ki o tilẹ dawọ iṣẹ duro patapata, ti a ko ba lo o rara tabi ti a ba a n ṣi i lo. Eyi yoo si fi wa si ikawọ eṣu lati jẹ niya. Ti a ko ba wa fẹ ki eyi ṣẹlẹ si wa, a nilo lati kọ bi a ti ṣe n ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ ti O fun wa lati rin ni iṣẹgun lori ẹṣẹ ati lati ṣe awọn iṣẹ rere ti O fẹ ki a ṣe. A si le ṣe eyi nipa fifi ara wa jin fun ọrọ rẹ, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn Kirisitiẹni. Adura mi si ni pe ki ọkan wa ma a fi ojoojumọ gba okun lati ṣe amulo ti o peye gbogbo oore-ọfẹ ti Ọlọrun ti fifun wa, ki O ba a le ma fi igba gbogbo sọ ọ di ilọpo-ilọpo fun wa lati jẹ gbogbo nkan ti O fẹ ki a jẹ laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kí oore-ọ̀fẹ́ ba à pọ̀ sí | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 18, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 3 Read More »

Ǹkan tí Ó ń rò nípa wa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 11, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 2

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O jẹ nkan idunnu ti o ga fun mi lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Èbìbí 2025 ati lati tun ki ọ kaabọ sinu ayẹyẹ ajọdun ọdun kẹtala ijọ wa. Adura mi ni pe ki Ọlọrun tẹsiwaju lati ma a gbe wa ro lati jẹ ohun gbogbo ti o fẹ ki a jẹ nipa agbara Ẹmi mimọ rẹ. Amin.

Nkan ayọ ni o jẹ nitootọ lati mọ wipe a ti n pade gẹgẹ bi ijọ ninu ilu yi fun ọdun mẹtala gbako. O si yẹ ki a mọ riri Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti ṣe ninu wa, fun wa ati nipasẹ wa laarin awọn ọdun mẹtala yi. O tun yẹ ki a mọ riri rẹ fun awọn nkan ti yoo si tun ṣe ni aarin wa, fun wa ati nipasẹ wa ninu ọdun ti a ṣẹṣẹ n bẹrẹ rẹ yi gẹgẹ bi ijọ. Adura mi si ni pe iṣẹ rere rẹ ko ni lailai dawọ duro ni aarin wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe n ṣe ajọyọ didara Ọlọrun si wa loni gẹgẹ bi ijọ, nkankan wa ti o ṣe pataki gan-an ki a kiyesi. Eyi si ni nkan ti O n ro nipa wa gẹgẹ bi ijọ. Ti a ba bere kaakiri, awọn eniyan yoo ni oniruuru nkan lati sọ nipa ijọ wa. Awọn nkan ti wọn yoo sọ si le dun un gbọ leti tabi ki o ma dun rara. Amọ a ko le gbe odiwọn bi a ti ṣe n ṣe daradara si gẹgẹ bi ijọ lori nkan ti awọn eniyan n ro tabi n sọ nipa wa. A ko tilẹ le gbe odiwọn bi a ti ṣe n ṣe daradara si lori nkan ti a n ro nipa ara wa. Odiwọn otitọ lori bi a ti ṣe n ṣe daradara si wa lọwọ Ọlọrun nikan. Yoo si wa dara ki gbogbo wa ma a gbadura pe ki O fi ohun ti O n ro nipa wa han wa, ki a ba a le fi ara wa jin lati ma gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu rẹ.

Bi a ti ṣe ri ninu iwe Ifihan, Oluwa sọ eyi nipa ijọ Laodikea:

“Nitori ti iwọ wi pe, emi ni ọrọ, emi si n pọ si i ni ọrọ, emi ko si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ ko si mọ pe, oṣi ni iwọ, ẹni-ikaaanu, talaka, afọju, ati ẹni ihoho. Emi fun ọ ni imọran pe ki o ra wura lọwọ mi ti a ti da ninu ina, ki iwọ le di ọlọrọ; ati aṣọ funfun, ki iwọ le fi wọ ara rẹ, ati ki itiju ihoho rẹ ma ba han, ki iwọ si fi ohun ikunra kun oju rẹ, ki iwọ le riran.” (Ìfihàn 3:17-18)

Njẹ o ri bayẹn? Ijọ yi ro wipe ọlọrọ ninu ẹmi ni oun ati wipe oun ko nilo ohunkohun. Ṣugbọn Oluwa sọ fun pe otoṣi, ẹni-ikaaanu, talaka, afọju ati ẹni ihoho ni o jẹ ninu ẹmi. Nitorina, ẹni kan ṣoṣo ti o mọ ipo ti ijọ kọọkan wa lotitọ ni Oluwa funrarẹ. Ti ko ba si sọ ipo ti a wa fun wa, a le e ro wipe a n ṣe daradara, nigba ti o jẹ wipe nṣe ni a n kuna, tabi ki a ro wipe a ko ṣe daradara, nigba ti o si jẹ wipe a n ṣe daradara niwaju Ọlọrun.

Nitorina, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ẹ jẹ ki a fi ara wa jin fun adura gbigba tọkantọkan pe ki Ọlọrun fi nkan ti O n ro nipa wa gẹgẹ bi ijọ han wa, ki a ma ba a ma a gbe igbesẹ lori iyi ti a ko ni niwaju Ọlọrun, ki a si sọ ipo ati ere wa ninu ijọba rẹ nu. Mo ba gbogbo wa yọ lẹẹkan si, bi a ti ṣe n ṣe ajọyọ ajọdun ọdun miran lori didara Ọlọrun si wa gẹgẹ bi ijọ. Adura mi ni pe ki Ọlọrun jẹ ki a duro ṣinṣin ninu gbogbo ifẹ rẹ si wa, ki O si tun ma a fi gbogbo igba jẹ ki ojurere ati aanu rẹ sinmi sori wa. Amin.

A kú àjọyọ̀ o.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ǹkan tí Ó ń rò nípa wa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 11, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 2 Read More »

Ó le ya ayé rẹ ya ìkorò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 04, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 1

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai ni odiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Èbìbí 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu ikoro nipa gbara Ẹmi rẹ. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe Ọlọrun le ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti i ṣe iriri ikoro nitootọ, lalai fi ti nkan ti o fa a ṣe. Nkan ti o kan nilo lati ṣe ni pe ki o ke pe e ninu adura, ki iwọ naa si ya ọkan rẹ ya ohun gbogbo ti o ni i ṣe pe ailẹmi idariji si ara rẹ ati si awọn miran ti wọn ti ṣe ọ ni ewu. Yoo si fi opin si gbogbo iriri ikoro ti o n ni, yoo si tun kun ọkan rẹ pẹlu ayọ.

Fun apẹrẹ, Josefu ni oniruuru iriri ikoro ninu aye rẹ. Ko si ni awọn iriri yi nitoripe o jẹ eniyan buburu sugbọn nitoripe awọn eniyan, pẹlupẹlu awọn arakunrin rẹ ti wọn jẹ ẹjẹ rẹ, gba eṣu laye lati lo wọn lati pọn ọn loju. Sibẹsibẹ, nitoripe o fi igbekẹle rẹ sinu Ọlọrun, ko si ni ẹnikẹni sinu, Ọlọrun ṣaanu fun, O fi opin si gbogbo iriri ikoro rẹ, O si tun gbe soke lọ si ibi giga. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 37-50)

Lafikun, a tun ni Naomi, ẹni ti oun ati Ruutu, pada wa lati ilẹ awọn ara Moabu pẹlu ọwọ-ofifo. Inu rẹ si bajẹ lori ipo ti o wa debi wipe o sọ fun awọn eniyan pe ki wọn ma pe oun ni ‘Naomi’ mọ, eyi ti o tunmọ si ‘Ọmọdara’, ṣuigbọn ki wọn ma a pe oun ni ‘Mara’, eyi ti o tunmọ si ‘Ọmọ-ikoro’. Ki si ni idi? Idi ni pe o ro wipe Ọlọrun ni O pọn idile oun loju. Ṣugbọn Ọlọrun kọ ni o pọn idile rẹ loju. Awọn ni wọn kuro ni ilẹ Juda ni asiko iyan lalai gba iṣipaya ẹmi. (Wo: Rúùtù 1)

Sibẹsibẹ, bi o tilẹ jẹ wipe oun ati ọkọ rẹ ni idi ti ikoro ṣe wọ aye wọn, Ọlọrun ṣaanu fun un, O si lo Ruutu, ẹni ti o jẹ ajeji, lati tu u ninu lọna ti o kọja ero rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, ẹri awọn eniyan nipe Ọlọrun lo Ruutu lati tu u ninu ni ọna ti ko le ti ri itunu gba, bi o tilẹ ni ọmọkurin meje. (Wo: Rúùtù 4:15)

Ti Jabesi nkọ? Ile aye tirẹ naa kun fun ikoro nitorope iya rẹ pe ikoro sori aye rẹ nigba ti o bi. Sibẹsibẹ, Ọlọrun tu u silẹ kuro ninu gbogbo iriri ikoro ati inira ti o n ni nigba ti o kigbe pe e. (Wo: 1Kíróníkà 4:9-10)

Wayi o, Ọlọrun kanna yi le ṣe nkankan naa fun ọ tabi awọn nkan ti o tilẹ tun dara ju iwọnyi lọ, ti iwọ naa ba kigbe pe e. Bẹẹni, O le ya aye rẹ ya ikoro, ti o ba le kigbe pe fun iranwọ. Nitorina, bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu tuntun yi, ke pe Ọlọrun lati fi opin si gbogbo iriri ikoro ti o le e ma ni ni aye. Yoo si da ọ lohun, yoo si tun kun ọkan rẹ pẹlu ẹkunrẹrẹ ayọ.

Kí o ní oṣù Èbìbí 2025 aláyọ̀.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ó le ya ayé rẹ ya ìkorò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 04, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 1 Read More »

A lè yí ọkàn Ọlọ́run padà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 27, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Ebibi 2025 papọ mọra wọn. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun tun ọ ṣe ni ibi yowu ti o ba ti n kuna laye, ki gbogbo ete rere rẹ fun ọ ba a le jẹ mimuṣẹ lalai si idena. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a kọ́ ninu bibeli ni pe ironupiwada otitọ le e yi ọkan Ọlọrun pada. Ṣugbọn a wa ni awọn ọrọ Iwe mimọ ti o sọ fun wa pe Ọlọrun ki i yi ọkan rẹ pada. Eyi tunmọ si pe ti O ba ti pinnu lati ṣe nkan, ko si ohunkohun ti o le di lọwọ lati ṣe e. Ki wa ni ki a ṣe pẹlu irufẹ awọn ẹsẹ Iwe mimọ yi? Ṣe ki a pa wọn ti gẹgẹ bi eyi ti ko wulo ni? Ki a ma ri! A ko le pa ẹsẹ Iwe mimọ kankan ti gẹgẹ bi eyi ti ko wulo. Idi si nipe ko si ẹsẹ Iwe mimọ ti ko wulo. Dipo bẹẹ, gbogbo ẹsẹ Iwe mimọ ni o ti ọdọ Ọlọrun wa, ti o si wulo fun igbero wa. (Wo: Númérì 23:19; 1Sámúẹ́lì 15:29; 2Tímótì 3:16-17)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe a ni awọn ẹsẹ Iwe mimọ ti o sọ fun wa pe Ọlọrun ko ki i yi ọkan rẹ pada, a tun ni awọn ẹsẹ Iwe mimọ miran ti awọn naa n fi awọn nkan ti o le yi Ọlọrun lọkan pada han wa. Ọkan lara awọn nkan naa ti o si le jẹ ki O yi ọkan rẹ pada, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ni ironupiwada otitọ. Fun apẹrẹ, Ọlọrun ni igba kan ran Wolii Elija si Ahabu lati ṣe idajọ oun ati ile rẹ fun pipa Naboti, ọkunrin alaiṣẹ kan. Ọlọrun sọ wipe Oun yoo pa gbogbo idile ọba yi run, Oun o si tun fi ẹran wọn fun awọn aja ati ẹyẹ jẹ. (Wo: 2Àwọn Ọba 21:17-24)

Wayi o, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ahabu jẹ ọba kan ti o buru pupọ, ti o si tun gberaga. Yatọ si eyi, arabinrin ti o fẹ, iyẹn Jesebẹli, tun wa buru ju oun alara gan lọ. Awọn mejeji yi si wa mu ijọba ẹru wa sori awọn eniyan Ọlọrun. Sibẹsibẹ, nigba ti ọkunrin yi gbọ ọrọ idajọ Ọlọrun, ko ni ki a ra Elija ko, ko bẹrẹ si ni bu u tabi ki o ma ba yan odi. Ko tilẹ ba jiyan lori ọrọ naa. Dipo bẹẹ, nṣe ni o rẹ ara rẹ silẹ, ti o fa aṣọ rẹ ya, ti o wọ aṣọ ọfọ, ti o si tun gba ààwẹ̀. (Wo: 1Àwọn Ọba 21:17-27)

Ki wa lo jẹ ki Ahabu ṣe bayẹn? Idi ni pe o mọ wipe oun jẹbi. O mọ wipe ko si awawi fun pipa ọkunrin alaiṣẹ kankan. Nitorina, nkan ti o tọ ni fun Ọlọrun lati ṣe idajọ rẹ ni ibamu pẹlu iṣẹ ọwọ rẹ. Nkan kan ti o kan le fi ireti rẹ sinu rẹ ni aanu. Ọna kan ṣoṣo fun lati si ri aanu Ọlọrun gba ni ki o rẹ ara rẹ silẹ, ki o si gba ẹṣẹ rẹ gẹgẹ bi ẹṣẹ. Aijẹbẹ, idajọ ti a ti ṣe fun oun ati idile rẹ di dandan ki o wa sori wọn.

Wayi o, ṣe Ọlọrun, ni asiko yi, wa fi aanu ati idariji fun Ahabu bi tabi ko fi fun un? O fi fun un. Bibeli sọ wipe, “Nigba naa ni ọrọ Oluwa si tọ Elijah ara Tiṣibi wa wi pe, “Njẹ iwọ ti ri bi Ahabu ti rẹ ara rẹ silẹ niwaju mi? Nitori ti o ti rẹ ara rẹ silẹ, emi ki yoo mu ibi naa wa ni ọjọ rẹ, ṣugbọn emi yoo mu u wa si ile rẹ ni ọjọ ọmọ rẹ.” (1Àwọn Ọba 21:28-29)

Njẹ o ri bayẹn? Nitoripe Ahabu gba ẹṣẹ rẹ lẹṣẹ, Ọlọrun sun ọjọ ibi ti O fẹ mu wa sori oun ati ile rẹ siwaju di awọn ọjọ awọn ọmọ rẹ. Eyi ja si pe Ọlọrun yi ọkan rẹ pada fun igba diẹ. Ti awọn ọmọ Ahabu naa ba wa lọ pa ẹṣẹ rẹ ti ni, ti wọn si rẹ ara wọn silẹ niwaju Oluwa, idajọ ti O pasẹ le wọn lori ko ba ma ti waye ni awọn ọjọ wọn. Ki a tilẹ sọ otitọ, Ọlọrun gan an tilẹ le pa ipinnu rẹ lati ṣe idajọ idile wọn rẹ. Ṣugbọn wọn ko yipada kuro ninu ẹṣẹ baba wọn. Nitorina, a pada pa gbogbo wọn run ni, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣeleri. (Wo: 2Àwọn Ọba 9)

Ki a ma fọrọgun, koko nkan ti a n sọ naa ni pe a le yi ọkan Ọlọrun pada nipasẹ ironupiwada otitọ. Nitorina, ti o ba yẹ Ọlọrun fi iya jẹ ọ fun nkankan ti o n ṣe ti ko dara, o le jẹ ki O yi ọkan rẹ pada nipa rironupiwada nitootọ. Ṣugbọn ti o ba tẹsiwaju lati ma a rin ninu igberega si i, ti o si kọ lati gba ẹṣẹ rẹ tabi aṣiṣe rẹ ni ẹṣẹ, idajọ rẹ le wa sori ri ki o to mọ nkan ti o n sẹlẹ. Ta wa ni o mọ bi eyi ṣe le buru fun ọ to. Nitorina, rẹ ara rẹ silẹ bayi, ki o si ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ rẹ. Njẹ ki o ri okun ninu rẹ lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

A lè yí ọkàn Ọlọ́run padà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 27, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 52 Read More »

Rírí iṣẹ́ Ọlọ́run tí o ga ju tàtẹ̀yìnwáLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 20, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ si ọjọ Isinmi Ajinde ti ọdun yi, iyẹn ọdun 2025. Adura mi si ni pe ohun gbogbo ti Jesu gbe ṣe fun wa nipasẹ iku, isinku, ajinde ati igbasoke rẹ ko ni ja si asan ninu aye wa. Amin.

Bi a ti ṣe bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ Jesu Oluwa wa yi: “Nitori mo wi fun ọ pe, mo ri ọ labẹ igi ọpọtọ ni iwọ ṣe gbagbọ? Iwọ o ri ohun ti o pọ ju wọnyi lọ.” (Jòhánù 1:50) Tani Jesu sọ eyi si? O sọ si Nataniẹli, ọkan lara awọn ọkunrin naa ti o pada di apọsiteli rẹ. Ki ni idi ti O ṣe sọ ọ si? Nikukuru, bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, Filipi ni o ṣọ fun Nataniẹli pe Jesu ti Nasarẹti ni Mesaya ti awọn ti n duro de ati wipe ki o kalọ lati wa a wo o. Ṣugbọn Nataniẹli ko ro wipe ohun rere kan le ti Nasarẹti jade wa. Sibẹsibẹ, o tẹle Filipi lọ lati ri i Jesu. (Wo: Jòhánù 1:44-46)

Wayi o, nigba ti ọkunrin yi pade Jesu, ti O si fun ni ifihan ibi ti o ti kọkọ wa ni ọjọ naa, ẹsẹkẹsẹ ni o gbagbọ, ti o si sọ wipe, “Iwọ ni ọmọ Ọlọrun; iwọ ni ọba Israẹli.” Nitoripe o wa mọ riri ifihan kekere ti Jesu fi fun un yi, Oluwa sọ fun pe yoo ri ohun ti o pọ ju nkan wọnyi lọ. Iyẹn jasi pe ọna lati ri ohun ti o pọ si lati ọwọ Ọlọrun ni ki a mọ riri ohun yowu ti O ba fi han wa tabi ti O ba ṣe fun wa, bi o ti wu ki nkan naa dabi ẹni pe o kere to.

Lotitọ, ko si nkan ti Ọlọrun ṣe fun wa tabi fi han wa ti a le pe ni yẹpẹrẹ tabi ohun ti o kere. Ṣugbọn bi o tilẹ dabi ẹni pe nkan ti o ṣe fun wa tabi fi han wa kere loju wa, iha ti a ba kọ si ni yoo sọ boya yoo fi ohun ti o ga ju eyi lọ han wa tabi ko ni fi han wa. Nigba ti Ọlọrun koọjọ farahan Mose, O fun ni ààmì meji. Awọn aami yi si lagbara pupọ. Ṣugbọn o nilo lati mọ riri wọn, ki o si tun mu Ọlọrun ni pataki nipasẹ wọn lati ri awọn aami ati iṣẹ iyanu ti o ga ju awọn wọnyi lọ. O si ri awọn aami, iṣẹ iyanu ati iṣẹ ara ti o ga ju awọn wọnyẹ lọ lati ọdọ Ọlọrun, awọn aami, iṣẹ iyanu ati iṣẹ ara ti o pọ ju nkan ti a le ka lọ.

Bakan naa si ni o ṣe ri pẹlu awọn Nataniẹli ati awọn apọsiteli Jesu Oluwa yoku. Gbogbo wọn ni wọn pada ri awọn nkan ti o ga ju awọn eyi ti a kọkọ fi han wọn nigba ti wọn pade rẹ. Ṣugbọn eyi ko ba ma ti ṣẹlẹ, ti wọn ko ba mọ riri awọn nkan ti O kọkọ ṣe fun wọn tabi fi han wọn.

Nitorina, ti a ba fẹ ri iṣẹ Ọlọrun ti o ga ju awọn eyi ti a ti ri sẹyin lọ, ti a ba fẹ ri iṣẹ iyanu, iṣẹ aami ati iṣẹ ara ti o ga ju ohun yowu ti Ọlọrun ti ṣe fun wa sẹyin lọ tabi ti O n ṣe fun wa lọwọlwọ, a gbọdọ fi han an pe a mọ riri ohun ti O n ṣe fun wa, bi o ti wu ki o kere loju to. Aijẹbẹ, a o kan ma gbọ ẹri ti o ga nipa didara rẹ si awọn miran ni, amọ awa ko ni ni ẹri kankan ti o jẹ ti wa lati jẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Rírí iṣẹ́ Ọlọ́run tí o ga ju tàtẹ̀yìnwáLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 20, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 51 Read More »

Pa wọ́n runLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 13, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 50

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ kọ ọ lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati rin ni iṣẹgun lori ohunkohun ti o n jẹ ẹṣẹ tabi ailera ẹmi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki ni idi ti mo ṣe gba adura yi fun ọ? Idi naa ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati pa ẹṣẹkẹṣẹ ti o le ni i ṣe pẹlu aye wa run. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi fun awọn ara Kolose:

“Nitorina ẹ ma pa ẹya-ara nyin ti mbẹ li aye run: agbere, iwa-eeri, ifẹkukẹ, ifẹ buburu, ati ojukokoro, ti iṣe ibọriṣa. Nitorin ohun ti ibinu Ọlọrun fi mbọwa sori awọn ọmọ alaigbọran. Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti n rin nigbakan ri, nigbati ẹnyin ti wa ninu nkan wọnyi. Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu: ibinu, irunu, arankan, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin. Ẹ ma si ṣe purọ fun ẹnikeji niyin, ẹnyin sa ti bọ ogbologbo ọkunrin ni silẹ pẹlu iṣẹ rẹ; E si ti gbe ọkunrin titun ni wọ, eyiti a sọ di titun si imọ gẹgẹ bi aworan ẹni ti o da a.” (Kólósè 3:5-10)

Njẹ iwọ naa ri gbogbo awọn nkan ti a ni lati pa run ati lati ya aye wa ya? Njẹ o si tun sakiyesi pe awa ni a o pa awọn nkan wọnyi run ninu aye wa? Eyi jasi pe bi o tilẹ jẹ wipe a ti di ọmọ Ọlọrun ati ẹda titun ninu Kirisiti lọwọlọwọ yi, awọn nkan buruku ti a n ṣe tẹlẹ yoo si tun fẹ jẹyọ ninu aye wa, ki wọn si sọ igbagbọ wa di radarada. Idi si ni pe o ti di aṣa fun wa lati ma ṣe awọn nkan wọnyi.

Ṣugbọn bi Pọọlu ti ṣe sọ fun wa, nitori awọn nkan buburu yi ni ibinu Ọlọrun ṣe n bọ wa sori awọn ọmọ alaigbọran. Nitorina, a ko tun gbọdọ fi ara wa jin fun wọn mọ. Dipo eyi, nṣe ni a gbọdọ pa wọn run. Njẹ a si wa le pa wọn run nitootọ? Njẹ a ni amuyẹ lati pa wọn run?

Ni kukuru, ti a ko ba le e pa wọn run, Ọlọrun ko ni sọ wipe ki a ṣe bẹ ẹ. Idi ti O ṣe sọ fun wa pe ki a ṣe bẹ ẹ ni pe a le ṣe bẹ ẹ. Amọ ọna wo ni a le gba ṣe bẹ ẹ? A ko le ṣe bẹ ẹ nipa ki o kan wu wa lọkan lati ṣe bẹ ẹ tabi nipa pipinu lati ṣe bẹ ẹ. Peteru, fun apẹrẹ, pinnu lati lati ma ṣẹ Jesu. Sibẹsibẹ, o ṣẹ ẹ ni ẹẹmẹta leralera ni alẹ ọjọ kan. Nitorina, ki a kan pinnu lati ma ṣe nkan ti ko dara ko to; a tun gbọdo ni amuyẹ lati ma ṣe ohun ti ko tọ. Aijẹbẹ, igbogun ẹṣẹ le sọ ipinnu wa di alailagbara, ki o si taari wa lati ṣe ohun ti o lodi si ifẹ ọkan wa. (Wo: Mátíù 26)

Awọn nkan wọnyi si ni idi ti bibeli fi tẹsiwaju lati sọ fun wa pe, “Nitori ti ẹnyin ba wa ni ti ara, ẹyin o ku: sugbọn nipa Ẹmi bi ẹnyin ba n pa iṣẹ ti ara run, ẹnyin o ye.” (Róòmù 8:13) Njẹ o ri bayẹn? Nipasẹ ipese Ẹmi Ọlọrun nikan ni a le e fi pa ohunkohun ti o n jẹ ẹsẹ tabi iwa ibajẹ run ninu aye wa. Aijẹbẹ, nṣe ni a o kan ri wipe a n kuna lera-lera.

Nitorina, ti o ba fẹ fi opin si ohunkohun ti o n jẹ ẹṣẹ ninu aye rẹ, o gbọdọ tọ Ẹmi Ọlọrun lọ fun amuyẹ lati ṣe bẹ ẹ. Lọna wo? Akọkọ, wa a ṣe eyi nipasẹ adura gbigba. Ekeji, wa a ṣe e nipasẹ ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati jijẹri ọrọ rẹ si ara rẹ. Ẹkẹta, wa a ṣe e nipasẹ didapọ mọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o n rin ninu ododo. Bi o si ṣe n fi igba gbogbo fi ara rẹ jin fun awọn nkan wọnyi, ko ni pẹ rara ti iwọ naa yoo fi ri funrarẹ pe gbogbo awọn nkan ti ko dara ti o n ba jijakadi ninu aye rẹ ni Ẹmi Ọlọrun ti pa run.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Pa wọ́n runLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 13, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 50 Read More »

Ó ṣe wá jẹ́ Màríà Magidalénì? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 06, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 49

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu Igbe 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fi ara rẹ han ọ ni ọna ti o peye si ninu oṣu yi, ki o ba a le dabi Jesu Oluwa siwaju ati siwaju si ni gbogbo ọna. Amin.

Ara awọn nkan ti yoo sọ bi Ọlọrun yoo ti ṣe fi ara rẹ han wa to si ni ipongbẹ wa fun un. Fun apẹrẹ, ẹni akọkọ ti Jesu fi ara rẹ han lẹyin ajinde rẹ ni Maria Magidaleni, ko ki i ṣe Peteru, Jemisi, Johanu tabi ọkan lara awọn apọsiteli yoku. Ki ni idi? Ki ni o pataki lara rẹ ti o fi jẹ wipe oun ni ẹni akọkọ ti o ri Jesu lẹyin ajinde rẹ? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, arabinrin yi ko ṣaa ki i ṣe iya tabi arabinrin Jesu. Lafikun, a ko tọka si gẹgẹ bi ọrẹ Jesu, bi a ti ṣe tọka si Lasaru ati awọn arabinrin rẹ gẹgẹ bi ọrẹ rẹ. Dipo eyi, nṣe ni a ṣe apejuwe rẹ ninu bibeli gẹgẹ bi obinrin naa ninu ẹni ti Jesu ti le ẹmi eṣu meje jade. (Wo: Lúùkù 8:2; Jòhánù 20:1-18)

Nitorina, àjẹ́ pọnbele ni Maria Magidaleni ki Jesu to pade rẹ. Bẹẹni, ika obinrin ni o jẹ ki o to pade Oluwa. Sibẹsibẹ, oun ni ẹni akọkọ ti Jesu fi ara rẹ han lẹyin ajinde rẹ. O ṣe wa jẹ oun ni?

Ni kukuru, bi a tun ṣe ri ninu bibeli, nitori ipongbẹ ti ko wọpọ ti arabinrin yi ni fun Oluwa ni O ṣe kọkọ fi ara rẹ han an. Bawo ni eyi ṣe jẹ bẹ? Akọkọ, lẹyin igbala rẹ kuro ninu igbe aye iwa ika rẹ, o di ọkan lara awọn perete ti o fi owo ati nkan ini wọn ran Jesu lọwọ julọ (Lúùkù 8:1-3). Ekeji, lẹyin igba ti a mu Jesu, ti a si tun kan mọ agbelebu, o wa lara awọn obinrin ti o wa pẹlu rẹ titi de opin, titi di igba ti O ku ati ti a tẹ siniu iboji (Mátíù 27:55-61).

Ẹkẹta, obinrin yi wa lara awọn obinrin ti o pada lọ si iboji Jesu ni ọjọ ajinde rẹ lati ṣe amojuto oku rẹ (Máàkù 16:1). Ẹkẹrin, nigba ti wọn de iboju Jesu, ti wọn ko si ba oku rẹ nibẹ, Maria Magidaleni nikan ni o kọ lati fi iboji naa silẹ. Awọn yoku, pẹlu Peteru ati Johanu, ti wọn wa sibẹ lati mọ ohun ti o ṣẹlẹ kuro. Ṣugbọn oun duro sibẹ, o si n sọkun fun Oluwa nitoripe o ro wipe awọn ika eniyan kan ti wa ji oku rẹ gbe. (Wo: Jòhánù 20:1-18)

Wayi o, asiko ti o n sọkun fun Oluwa lọwọ ni iwaju iboyi naa ni O fi ara rẹ han. O wa yẹ ki o ri bayi pe nitoripe oun ni o tara ju fun Oluwa ni asiko yẹn ni O ṣe kọkọ fi ara rẹ han ni ẹyin ajinde rẹ. Eyi si n jẹ ki o yẹ wa pe ko si ojuṣaaju pẹlu Oluwa. Ti a ba ni itara fun un, yoo fi ara rẹ han wa ni awọn ọna ti O le ma gba fi ara rẹ han awọn miran, lalai fi ti ọjọ ori wa, akọ ni wa tabi abo, ipo wa, awọ wa tabi itan aye wa ṣe.

Amọ ṣa o, ki a wa ma ṣe ro wipe o di dandan ki Oluwa fi ara rẹ han wa nitoripe a n jẹ orukọ inu bibeli bi Maria, Peteru, Jemisi, Johanu ati bẹẹbẹẹ lọ. Ti a ko ba ni itara fun un bi Maria Magidaleni ṣe ni itara fun un, ko ni fi nkan ti o to nkan han wa nipa ara rẹ. Nitorina, ẹ jẹ ki a ni itara fun un, ti a ba fẹ mọ ọn ni ọna ti o peye. A si le fi itara wa fun un han nipasẹ ifarajin wa fun ọrọ rẹ, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn Kirisitiẹni. Adura mi ni pe ki ọkan wa ma a fi ojoojumọ gba okun lati mu ifarajin wa si awọn nkan wọnyi ni ọkunkundun, ki a ba a le mọ Oluwa bi o ti ṣe yẹ ki a mọ ọn. Amin.

Kí o ní oṣù Igbe 2025 alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ó ṣe wá jẹ́ Màríà Magidalénì? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 06, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 49 Read More »

Wákàtí kan péré! | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 30, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so awọn oṣu Ẹrẹna ati Igbe ọdun 2025 papọ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọkan rẹ ni okun lati ṣe ohun gbogbo ti o tọ fun ọ lati ṣe lati le wa ni mimọ ati ailẹbi ni igba ti Jesu Oluwa wa ba de. Amin.

Ki Jesu Oluwa wa, nigba ti asiko rẹ to, ma ba a fa sẹyin kuro ninu kiku lori igi agbelebu fun irapada ọmọniyan, O nilo lati ṣe nkankan. Ki si nkan naa? O nilo lati gbadura. O wa nilo to iwọn asiko melo lati gbadura? Ko nilo odidi ọsẹ kan tabi odidi ọjọ kan lati gbadura. Wakati kan pere ni O nilo lati gbadura.

Bawo ni a ṣe wa mọ wipe wakati kan pere ni Jesu nilo ni asiko yi lati gbadura? A mọ nipasẹ Iwe mimọ. Bi akọsilẹ naa ṣe lọ, bi O ti ri wipe asiko Oun ti de tan, O mu mẹta lara awọn ọmọ-ẹyin rẹ, Peteru, Jemisi ati Johanu, lọwọ pẹlu rẹ lati lọ gbadura ni ibi kan ti a n pe ni Gẹtisimani. Ṣugbọn dipo ti wọn yoo fi ma gbaudra pẹlu rẹ, nṣe ni wọn n sun. Idi si ni pe o ti rẹ wọn gidigidi. Iwọ naa wo nkan ti bibeli sọ nipa awọn nkan wọnyi:

“O si wa, o ba wọn, wọn n sun, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ n sun? Iwọ ko le sọna ni wakati kan? Ẹ maa ṣọna, ki ẹ si maa gbadura, ki ẹ ma baa bọ sinu idanwo. Loootọ, ni ẹmi n fẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara.” (Máàkù 14:37-38)

Njẹ o ri bayẹn? Iwọn asiko melo ni Jesu woye pe ki awọn ọmọ-ẹyin yi lo lati gbadura pẹlu rẹ? Wakati kan pere! Lotitọ, Jesu le gbadura si Ọlọrun ju wakati kan lọ. Ṣaaju asiko yi, O ti gbadura ni ọpọ igba fun ọpọlọpọ wakati, nigba miran gan fun gbogbo aṣalẹ. Nitorina, ko yan lati gbadura fun wakati kan ni asiko yi nitoripe ko le gbadura fun ọpọlọpọ wakati. Dipo eyi, O yan lati ṣe bẹẹ nitoripe O mọ wipe ọpọlọpọ nkan ni a le yipada tabi ṣe pẹlu adura wa, bi ko tilẹ ju wakati kan lọ.

Wayi o, nitori adura wakati kan ti O gba si Ọlọrun fun ọkan rẹ ni akoko okunkun yi, O gba okun ati igboya ti o peye lati ku lori igi agbelebu ati lati gba irapada ayeraye fun wa. Bawo wa ni ti awọn ọmọ-ẹyin rẹ ti ko le darapọ mọ lati gbadura fun ara wọn fun wakati kan pere? Gbogbo wọn patapata ni wọn ṣẹ ẹ, ti wọn si tun kọ ọ silẹ. Ti ko ba wa jẹ wipe O ti gbadura fun wọn tẹlẹ pe ki igbagbọ wọn ma ṣe yẹ ni, ibi ti opin ko ba ti ba ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ niyẹn.

Ki wa ni eyi n kọ wa gan? Oun naa ni pe a ko le sọ bi adura ti a ba gba tọkantọkan ṣe le ṣiṣẹ fun wa tabi fun awọn ọmọ eniyan si, bi o tilẹ jẹ wipe fun wakati kan pere ni. Ki a tilẹ sọ otitọ, adura ìṣẹ́jú kan gan an le jẹ iyatọ laarin iye ati iku, aṣeyọri ati ikuna, iṣẹgun ati ijakulẹ. Odiwọn asiko wo ni o gba Dafidi lati gbadura pe ki Ọlọrun sọ imọ Ahitofeli di asan? Boya ni o gba to iṣẹju kan lọ. Ṣibẹṣibẹ, adura naa yi ohun gbogbo nipa ọtẹ ti o fẹ fi opin si pada. Adura naa yọri si iṣẹgun rẹ lori Abusalomu. (Wo: 2Sámúẹ́lì 15:31)

Ṣe mo wa n sọ wipe iṣẹju kan tabi wakati kan pere ni ki o fi ma gbadura bi? Rara o! Ki a sọ otitọ, awọn iṣoro kan wa ti o jẹ wipe o le gba wa ni adura wakati pupọ tabi ọjọ pupọ ki wọn to niyanju. Ṣugbọn ti a ba kẹkọ lati ma fiyesi pe adura wa le yi itan pada, nṣe ni a o bẹrẹ si ni ṣe amulo ti o peye gbogbo asiko ti a ba ni lati gbadura, bi o tilẹ jẹ pe wakati kan pere ni. Adura mi si ni pe ki a kun ọkan wa pẹlu okun ti o peye lati ọdọ Ọlọrun lati ma fi ojoojumọ rin ninu imọlẹ otitọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Wákàtí kan péré! | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 30, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 48 Read More »