Author name: 23?Racing_Horse

Ibadọrẹ pẹlu aye | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 47

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ jẹ ki ìfẹ́ rẹ ninu ọkan rẹ ma jo bi ina, ki o ba a le jẹ olotitọ si titi de opin. Amin.

Bi a ti ṣe n kojú ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ki ọ nilọ pẹlu awọn ọrọ Jemisi yi ti o sọ pe, “Ẹyin pansaga ọkunrin, ati pansaga obinrin, ẹ kọ mọ pe ibarẹ aye iṣọta Ọlọrun ni? Nitori naa ẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aye di ọta Ọlọrun.” (Jákọ́bù 4:4) Ki ni koko nkan ti Jemisi n sọ nibiyi? Oun naa ni pe ko si bi a ṣe le mu Ọlọrun ni ọrẹ wa, ki a si tun nifẹ aye pẹlu. Niwọn igba ti a ba ti le mu aye yi ni ọrẹ wa, a ti mu Ọlọrun ni ọta wa niyẹn. Ọna ti eyi yoo wa gba pa wa lara ni ko ki i ṣe ohun ti ẹnikẹni le e sọ. Ṣugbọn o di dandan ki o pa wa lara.

Wayi o, o wa ṣeni laanu pe ọpọ ti a n pe ni ọmọ Ọlọrun, ti awọn naa si n sọ wipe awọn nifẹ rẹ, ni wọn si tun wa ninu ifẹ pẹlu awọn nkan ti aye yi pẹlu. Wọn si tun n fẹ maa sọrọ ati mura bi awọn ti aye yi. Wọn si n fẹ lati ma ṣe ariya gẹgẹ bi wọn ti n ṣe ariya. Wọn si tun wa ninu ifẹ pẹlu awọn orin ati sinima wọn. Bawo gan ni wọn ṣe wa fẹ sọ wipe awọn si fẹran Ọlọrun nitootọ? Tabi bawo ni wọn ṣe fẹ sọ wipe awọn nkan ti aye yi ti awọn dirọ mọ ninu ifẹ ko pa ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun lara? Kiki ọpurọ eniyan ni yoo sọ eyi.

Wa ma ṣi mi gbọ. Mi o sọ wipe gbogbo nkan ti awọn ti aye yi n ṣe ni ko dara. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ nkan ti awọn ti o wa laye yi n ṣe ni o tọna, ti o si dara fun awọn ọmọ Ọlọrun pẹlu ati ti awọn ọmọ Ọlọrun le kẹkọ lara wọn. Ṣugbọn awọn nkan kan naa tun wa ti awọn ti aye yi ma n ṣe lati ba aye ara wọn ati ti awọn miran jẹ. Ọmọ Ọlọrun ṣi gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan wọnyi, ki o si ya ara rẹ ya wọn. Aijẹbẹ, bi o ti wu ki o sọ wipe oun fẹran Ọlọrun to, idibajẹ yoo wọnu aye rẹ, a o si sọ di ọta Ọlọrun.

Ranti awọn ọmọbinrin Lọti. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn kuro ni Sodom gẹgẹ bi wundia ninu agọ ara wọn, otitọ ibẹ ni wipe wọn ko ki i ṣe wundia ninu ọkan wọn. Ki ni idi? Idi ni wipe awọn nkan ti wọn ri ati ti wọn gbọ ni Sodomu fi idibajẹ sinu ọkan wọn. Ki a tilẹ sọ otitọ, o ṣeeṣe ki wọn ti ṣe gbogbo nkan ti wọn n ri ati ti wọn n gbọ ni Sodomu ninu ọkan wọn ki wọn to fi ibẹ silẹ. Nitorina, nigba ti o to asiko kan, ti wọn ko si le mu ara wọn duro mọ, wọn rọ baba wọn lọti yo, wọn si tun ba a sun. O ma ṣe o! (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 19)

Nibakanna, a le ro wipe awọn nkan ti a n ri ati ti a n gbọ nipasẹ ibadọrẹ wa pẹlu aye ko pa wa lara. Ṣugbọn nṣe ni a kan n parọ tan ara wa jẹ. Ko si bi a o ṣe ba aye dọrẹ ti idibajẹ inu rẹ ko ni wọ inu aye wa. Ti o ba si ti wọ inu aye wa, awa naa le ṣe bi awọn ọmọbinrin Lọti ti ṣe. A le ṣe aṣemaṣe.

Idi si wa niyi ti ọrọ Ọlọrun fi ki wa nilọ pe ki a yago fun ibadọrẹ pẹlu aye. Yoo kan sọ wa di ọta Ọlọrun ni. Ti ba si ti wa sọ wa di ọta Ọlọrun, ki ni yoo ṣẹlẹ pẹlu ireti wa ninu ijọba ayeraye rẹ? O le yọ bọrọ kuro lọwọ wa. Mo gbadura pe ireti wa ninu ijọba Ọlọrun ko ni lailai yọ jabọ kuro lọwọ wa. Amọ awa naa gbọ ṣọ ara wa.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ibadọrẹ pẹlu aye | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 47 Read More »

Pa ọkàn rẹ mọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 46

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ẹrẹ́nà 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ ri daju pe esu ko ri ọkan rẹ sọ di radarada ni ọna kankan, ki o ma ba gbe igbesẹ ti yoo yọri si abamọ fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bibeli sọ wipe, “Ṣe aápọn lati pa ọkan rẹ mọ, nitori pe lati inu rẹ ni iye ti n sun jade.” (Ìwé Òwe 4:23) Ki ni eyi tunmọ si? O tunmọ si pe ọkan lara awọn nkan ti o ṣe pataki julọ ti o le ṣe fun ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ni ki o pa ọkan rẹ mọ nipasẹ agbara Ẹmi Mimọ. Ki si ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? O ṣe pataki nitoripe ohun gbogbo ti o n ṣe ni o n jẹ jade lati inu ọkan rẹ. Ti o ko ba wa pa ọkan rẹ mọ daradara, Satani yoo kun pẹlu oniruuru ibi. Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, nṣe ni iwọ yoo ba a ra rẹ nibi ti o ti n ṣe awọn nkan ti o ko lailai lero pe o le ṣe e.

Fun apẹrẹ, njẹ Judasi Isikariọti mọ wipe oun le dalẹ Jesu Oluwa, iyẹn nigba ti o kọkọ di ọkan lara wọn apọsiteli rẹ? Mi o ro bẹ ẹ. Sibẹsibẹ, nitoripe ko da aabo bo ọkan rẹ kuro lọwọ ojukokoro, Satani ṣe aṣeyọri lati wọ inu rẹ ati lati taari rẹ lati dalẹ Jesu Oluwa ati Olugbala rẹ. O ma ṣe o! (Wo: Jòhánù 13:2&27)

Ti Dafidi nkọ? Njẹ nigba ti Ọlọrun kọkọ yan gẹgẹ bi ọba lori Isiraẹli, ṣe o ro wipe oun le ja iyawo ẹnikan gba ni ọjọ kan, ki oun si tun pa ọkunrin naa? Rara o! O nifẹ Ọlọrun ju gbogbo irufẹ awọn nkan bayẹn lọ. Sibẹsibẹ, nitoripe ko pa ọkan rẹ mọ kuro lọwọ ifẹkufẹ, o ma pada ṣe aṣemaṣe. O ja Baṣẹba gba kuro lọwọ Huraya, o si tun pa ọkunrin naa. (Wo: 2Sámúẹ́lì 11)

Wayi o, ti Dafidi, ẹni bi ọkan Ọlọrun, ba le ṣe bayẹn, nitoripe o kọ lati pa ọkan rẹ mọ, nje o ko lero pe awa naa le ṣe nkan ti o jọ bẹ ẹ tabi ti o buru ju bẹ ẹ lọ? Ti Judasi Isikariọti naa, ẹni ti a ka yẹ lati ba Jesu gbe papọ, lati ba jẹun ati lati ba mu-un, ba le dalẹ rẹ nitoripe o kọ lati pa ọkan rẹ, njẹ o ko lero pe awa naa le ṣe ohun ti o farapẹ tabi ti o buru ju bẹ ẹ lọ?

Nitorina, ninu ọgbọn Ọlọrun, O sọ fun wa pe ki a mu pipa ọkan wa mọ kuro lọwọ erokero ati ero ifẹkufẹ ni ọkunkundun. Aijẹbẹ, a le pada wa sọ aye wa ati igbagbọ wa di radarada ni ọna ti o kọja ohun ti ẹnikẹni le ro. Nitori eyi, gbe ilẹkun ọkan rẹ ti mọ awọn ero ẹtanu, owu, ikorira tabi ifẹkufẹ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fi okun fun ọkan rẹ nipasẹ Ẹmi rẹ lati ma fi ojoojumọ ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Pa ọkàn rẹ mọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 46 Read More »

Àkórí: Kíyèsára, sì tún ma gbàdúrà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal| Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 09, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 45

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ nilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ẹrẹna 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o ko si sinu pakute yowu ti eṣu le ti dẹ fun ọkan rẹ, ki o ba a le duro lailẹbi nigba ti Jesu Kirisiti Oluwa wa ba farahan. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ki ọ nilọ pẹlu awọn ọrọ Jesu Kirisiti Oluwa wa wọnyi:

“Ṣugbọn ẹ maa kiye sara yin, ki ọkan yin ki o ma ṣe kun fun wọbia, ati fun ọti imupara, ati fun aniyan aye yii, ti ọjọ naa yoo fi de ba yin lojiji bi ikẹkun. Nitori bẹẹ ni yoo de ba gbogbo awọn ti n gbe ori gbogbo ilẹ aye. Njẹ ki ẹ maa ṣọna, ki ẹ si maa gbadura nigba gbogbo, ki ẹ ba le la gbogbo nnkan wọnyi ti n bọ wa ṣe ja, ki ẹ si le duro niwaju ọmọ-eniyan.” (Lúùkù 21:34-36)

Ki ni awọn nkan gbogi ti Oluwa wa fẹ ki a kiyesi, ki a si mu ni pataki, bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi? Akọkọ ninu wọn ni pataki ki a kiyesara. Ki ni idi ti a fi nilo lati kiyesara? Idi ni pe ojooojumọ ni ọta wa, Satani, yoo ma lo oniruuru nkan lati ba ọkan wa ja, ki o ba a le mu wa lẹru, ki o si jẹ ki a gbagbe pe aye yi ko ki i ṣe ile wa titi lailai. Ti a ko ba si kiyesara, a o ti sọ ara wọn nu sinu aniyan aye yi ati sinu oniruuru iwa aiwa-bi-Ọlọrun ti o le pa aye ati ọkan wa run, iyẹn ki a to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ.

Nitorina, kiyesara. Kiyesara lori awọn ibi ti o n lọ. Kiyesara lori awọn ti o n ba ṣọrẹ. Kiyesara lori awọn nkan ti o n jẹ ki oju rẹ ri ati lori awọn nkan ti o n jẹ ki eti rẹ gbọ. Si tun kiyesara lori irufẹ ero ti o n fi aye silẹ fun ninu ọkan rẹ. Aijẹbẹ, o le e ti padanu ara rẹ sinu aye yi ati sọwọ eṣu ki o to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ.

Nkan ekeji ti Oluwa wa fẹ ki a kiyesi, bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli yẹn, ni ifarajin wa fun adura gbigba. Lotitọ, oniruuru adura ni o wa. Ṣugbọn irufẹ adura ti O n sọrọ nipa nibiyi ni i ṣe pẹlu ipamọ ọkan wọn ni awọn ọjọ ikẹyin yi. Nitorina, lakọkọ, O sọ fun wa pe ki a gbadura pe ki a le bọ ninu awọn iṣẹlẹ ibi, ijamba, ajalu, ajakalẹ-arun, iyan ati bẹẹbẹẹ lọ, ti yoo ma ṣẹlẹ ni awọn ọjọ ikẹyin yi. Ekeji, O sọ fun wa pe ki a gbadura pe ki a le duro niwaju Oun nigba ti Oun ba pada de.

Ki wa gan ni koko gbogbo awọn nkan wọnyi? Oun naa ni pe ko si ọkankan ninu wa ti o le bọ ninu awọn ewu ati idibajẹ awọn ọjọ ikẹyin yi, ti Ọlọrun funrarẹ ko ba pa wa mọ. Igboya, ipinnu ati imọkan-le wa ko to lati pa wa mọ. Ọlọrun funrarẹ ni lati pa wa mọ. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ji ni ọjọ kan, ti a o si wa ri wipe awa gan-an ti da gbogbo nkan ti a ti fi igbakanri waasu lodi si.

Nitorina, yatọ si pe ki a ma fi ojoojumọ kiyesara ninu irinajo wa laye yi, a tun nilo lati fi ara wa jin fun gbigbadura pẹlu itara pe ki Ọlọrun, ninu aanu rẹ, pa ati aye ati ọkan wa mọ kuro ninu gbogbo awọn ewu ati idibajẹ awọn ọjọ ikẹyin wọnyi. Ti a ba si n ṣe eyi lemọ́lemọ́ pẹlu igbagbọ, a ko ni dojuti wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni a o pa wa mọ lati wa ni mimọ ati alailẹbi nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada de.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àkórí: Kíyèsára, sì tún ma gbàdúrà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal| Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 09, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 45 Read More »

Ojú rẹ̀ wà lára wọn ní gbogbo ìgbà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 02, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 44

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kẹta ọdun yi, iyẹn oṣu Ẹrẹna 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe aye ati ile rẹ lọsọ lakọtun ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu tuntun yi, mo fẹ gba ọ ni yanju pẹlu awọn ọrọ wọnyi lati inu Saamu Dafidi kan:

“Woo oju Oluwa wa lara awọn ti o bẹru rẹ, ati lara awọn ti o ni ireti ninu ifẹ rẹ ti o duro ṣinṣin. Lati gba ọkan wọn kuro lọwọ iku ati lati pa wọn mọ laaye lọwọ iyan.” (Sáàmù 33:18-19)

Ki ni a ri nibiyi? A ri wipe gbogbo igba ni oju Ọlọrun wa lara awọn ti o bẹru rẹ ati ti wọn fi ireti wọn sinu ifẹ rẹ ti o duro ṣinṣin. Eyi jasi pe, ko ki i fi igba kankan gbe oju rẹ kuro lara wọn, ibi yowu ki wọn lọ tabi ki wọn ti ba ara wọn.

Ki wa ni idi ti oju Ọlọrun fi n fi igba gbogbo wa lara irufẹ awọn eniyan wọnyi? Akọkọ, idi ni ki o ba a le gba wọn kuro lọwọ iku. Ranti wipe Dafidi ni o sọ awọn ọrọ wọnyi. O si sọ wọn gẹgẹ bi ijẹri si didara Ọlọrun si i. Gbogbo igba ni Ọlọrun n pa a mọ kuro lọwọ iku, bi o tilẹ jẹ wipe ọta rẹ, Ọba Sọọlu, gbe oniruuru igbesẹ lati pa a ati lati di lọwọ lati joko sori itẹ ọba Isiraẹli. Nigbẹyin-gbẹyin, ọta rẹ ni o padanu ẹmi rẹ. Ṣugbọn oun tẹsiwaju lati di ọba ti Ọlọrun ti n fẹ ki o da.

Nibakanna, ti awa naa ba n gbe ninu ibẹru Ọlọrun, ti a si tun fi igbẹkẹle wa sinu rẹ, dipo sinu eniyan tabi ete wọn, a o ma fi igba gbogbo jẹgbadun aabo rẹ kuro lọwọ iku ati iparun. Eyi jasi pe ohun yowu ti Satani le ṣe lati pa wa run tabi pa wa, ko ni ṣe aṣeyọri. Ṣugbọn awa o tẹsiwaju lati da ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a da laye.

Ekeji, oju Ọlọrun ma n fi igba gbogbo wa lara awọn ti o bẹru rẹ ati ti o fi ireti wọn sinu ifẹ rẹ ti o duro ṣinṣin ki O ba a le mu wọn wa láàyè ni asiko iyan. Eyi jasi pe bi o ti wu ki ọrọ-iṣuna ibi kan ri, Ọlọrun yoo maa fi igba gbogbo ri daju pe ebi ko pa awọn ti o n gbe aye wọn lati buyi kun ati ti ko gbe oju wọn kuro lara rẹ. Ki a ti lẹ so otitọ, gẹgẹ bi O ti ṣe sọ Isaaki di ọlọrọ ni asiko iyan, O le sọ awọn naa di ọlọrọ pẹlu. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 26)

Nibakanna, bi o tilẹ jẹ wipe ọrọ-iṣuna orilẹ-ede yi ki rọgbọ ni asiko yi, ti a ba n fi igba gbogbo gbe ninu ibẹru Ọlọrun, ti a si tun fi ireti wa sinu rẹ, yoo ri daju pe ebi ko pa wa. Ọna wo ni yoo gba ṣe eyi? Emi ko le sọ fun ọ. Idi si ni pe ko si bi mo ṣe fẹ mọ ọna naa ayafi ti O ba sọ fun mi. Ṣugbọn mo mọ wipe ti a ko ba gbe igbẹkẹle wa ninu rẹ ju sọnu, yoo ri daju pe a ko ṣe alaini ohun ti o dara kankan, bi o tilẹ jẹ wipe asiko iyan li a wa.

Nitorina, jẹ ki igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun duro ṣinṣin, irufẹ ohun yowu ti o n ṣẹlẹ layika rẹ ati irufẹ ohun yowu ti o ni tabi ti o ko ni ni asiko yi. Lafikun, tẹsiwaju lati ma gbe ninu ibẹru Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ ti fi ara wọn jin fun aiṣododo. Oun yoo si ri daju pe oju ko lailai ti ọ.

Kí o ní oṣú Ẹrẹ́nà 2025 tí ó lárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ojú rẹ̀ wà lára wọn ní gbogbo ìgbà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 02, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 44 Read More »

Fi ìfẹ́ rẹ han si | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Èrèlé 2025. Adura mi si ni pe ninu ọsẹ naa ki Ọlọrun pese ohun rere gbogbo ti ọkan rẹ n fẹ lati ni ninu oṣu yi ti ko i ti tẹ ọ lọwọ fun ọ. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Iwe mimọ yi nipa Solomọni ati bi o ti ṣe fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o yẹ fun ojurere Ọlọrun:

“Solomọni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si fi nfi turari jona ni ibi-giga. Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ naa ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomọni ru lori pẹpẹ na.” (1Àwọn Ọba 3:3-4)

Ọna wo ni Solomọni gba fi ifẹ rẹ han si Ọlọrun, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? Akọkọ, o fi han nipa ririn ni ibamu pẹlu awọn aṣẹ iwa-bi-Ọlọrun ti baba rẹ pa fun. Eyi jasi pe o n rin ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Ekeji, o fi ifẹ rẹ han si Ọlọrun nipa fifi fun un. O fun ni ẹgbẹrun kan ọrẹ ẹbọ-sisun ni ọjọ kan. Ko si si akọsilẹ ninu bibeli ẹnikẹni fi ifẹ rẹ han si Ọlọrun ni irufẹ ọna yi ṣaaju asiko yi.

Ni kukuru, nitoripe Solomọni gbe ifẹ rẹ fun Ọlọrun kọja ọrọ ẹnu lasan nipa ririn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ati nipa lila ọwọ si i, Ọlọrun naa fi ara han loju ala lati san an ni ẹṣan. Ọlọrun ni ki o bere ohun yowu ti o ba fẹ ki Oun ṣe fun un. Bayi si ni o ṣe di ẹni ti o gbọn ju, ti o si tun lọrọ ju gbogbo awọn eniyan igba aye rẹ lọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 3:5-12; 2Kíróníkà 1:1-12)

Ki ni eyi n kọ wa? O n kọ wa pe ko to fun wa lati ma a sọ fun Ọlọrun pe a nifẹ rẹ tabi lati ma sọ fun awọn eniyan pe a nifẹ Ọlọrun; a tun nilo lati ma fi ojoojumọ fi ifẹ ti a ni si i han. Bawo si ni a ṣe le fi ifẹ wa si i han? Akọkọ, a le fi han nipa ririn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ẹni yowu ti ko ba ni rin ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ko gbọdọ sọ wipe, “Mo nifẹ Ọlọrun.” Irọ lasan ni eyi yoo jẹ. Tí o ba fẹran rẹ nitootọ, ko kan ki i ṣe wipe o o fi ara rẹ jin lati mọ ohun ti O fẹ nikan, nṣe ni o o tun ma ṣe ohun ti O fẹ.

Ọna keji lati fi han pe a nifẹ Ọlọrun ni nipa lilawọ si i. Ṣe a le sọ wipe a nifẹ enikẹni ti a ko ba lawọ si? Rara! Ti a ba nifẹ eniyan, a o ma la ọwọ si wọn. A o fẹ fun wọn ni ohunkohun ti o ba wa ni ikawọ wa lati mu inu wọn dun. Ki a tilẹ sọ otitọ, nigbamiran, nitori ifẹ wa fun awọn kan, a le ṣe kọja agbara wa lati fifun wọn. Ti ba si wa nifẹ Ọlọrun naa nitootọ, a o ri awọn asiko ti a o ṣe kọja agbara wa lati fifun un.

Arabinrin kan fi igba kan fi ifẹ rẹ si Jesu han nipa dida odidi igo ororo ikunra olowo-iyebiye kan si lori. Awọn ti o ri eyi si binu si gidigidi. Ki ni idi? Wọn woye wipe ororo ikunra yi ti wọn ju nkan ti ẹnikan kan le fi ṣofọ bẹyẹn lọ. Ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ naa ni jesu sọ fun wọn pe ohun ti obinrin yi ṣe ko ki i ṣe fifi nkan sọfo rara. Dipo bẹẹ, o ṣe ohun ti o ṣe lati fi ifẹ rẹ han si i ni. Yatọ si iyẹn, o ṣe ohun ti o ṣe, gẹgẹ bi Oluwa ti ṣe sọ, lati pese agọ ara oun fun isinku ni, bi arabinrin funrarẹ ko tilẹ mọ eyi saaju asiko naa. O wa tunmọ si pe Ẹmi Ọlọrun ni O dari rẹ lati ṣe ohun ti o ṣe. Ere rẹ si ni pe gbogbo ibi ti a ba ti waasu iyinrere Oluwa ni a o ti ma darukọ rẹ. (Wọ: Mátíù 26:6-13; Máàkù 14:1-9; Jòhánù 12:1-8)

Nitorina, a tilẹ le sọ wipe ọkan lara ọna lati mọ bi a ti ṣe fi ara wa jin fun Ẹmi Ọlọrun to ni nipa lilawọ wa si Ọlọrun. Bawo wa ni o ṣe lawọ si i to? Bawo ni o ṣe lawọ si awọn iranṣẹ rẹ to? Bawo si tun ni o ṣe fi ara rẹ jin lati ma gbe igbe aye ti o dun mọ ninu to? Awọn nkan ti yoo jẹ ki a mọ boya o nifẹ rẹ lotitọ tabi o ko ni ni wọnyi. Adura mi ni pe ohun ti o pe ni ifẹ si Ọlọrun yoo ma fi igba gbogbo jẹ ojulowo dipo gbarọgudu, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Fi ìfẹ́ rẹ han si | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 43 Read More »

Má pa ìgbáyégbádùn wọn ti | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 42

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun tun ọ ṣe nibi yowu ti Satani ba ti n yọkẹlẹ lo ọ lati di iṣẹ rẹ lọwọ. Amin.

Mo fi igba kan ri ṣiṣẹ ni ile-iṣẹ ijọ kan nibi ti ọpọ awọn oṣiṣẹ wọn ti ma n ṣaba sa kuro lẹyin igba ti wọn ba ti ṣiṣẹ fun oṣu diẹ. Ki wa lo gbe wọn wa ṣiṣẹ nibẹ gan? Nkan ti o gbe wọn wa ṣiṣẹ nibẹ ni pe awọn naa woye pe ṣiṣe nibẹ yoo fun awọn ni anfaani lati sin Ọlọrun daradara si. Nitorina, wọn fi iṣẹ wọn, okowo wọn, ẹbi wọn ati bẹẹbẹẹ lọ silẹ lati wa ba Ọlọrun ṣiṣẹ.

O wa ṣeni laanu, bi mo ti ṣe tọka si tẹlẹ, pe wọn ko ki i pẹ rara ninu ile-iṣẹ ijọ yi ti wọn fi n kuro. Ki si ni idi? Ṣe nitoripe wọn ko ṣe iṣiro ti o peye nkan ti ṣiṣẹ pẹlu Ọlọrun lọna yi yoo na wọn ki wọn to wa ni? O le jẹ bẹẹ nitootọ pẹlu awọn kan lara wọn. Abi ṣe suuru ati ifarada wọn ko peye to ni? Eyi naa tun le ri bẹẹ pẹlu fun awọn kan lara wọn. Amọ idi kan ti o farahan kedere ti ọpọ ninu wọn ṣe n kuro bẹyẹn ni pe a ko mojuto igbayegbadun wọn.

Ta wa ni o yẹ ki o mojuto igbayegbadun awọn eniyan wọnyi? Akọkọ, pasitọ ti wọn n ba ṣiṣẹ lo yẹ ki o moju to o. Njẹ o si mojuto bi? Rara o, ko ma mojuto o. Dipo ti yoo fi mojuto, bi o tilẹ jẹ wipe kedere bayi ni o han si araye pe igba aye yọtọmi ni o n gbe, ko ri igbayegbadun awọn ti o n ba a ṣiṣẹ gẹgẹ bi nkan ti o ṣe pataki rara. Nitorina, ọpọ ninu wọn ni ko le jẹun daradara tabi mura daradara. Sibẹsibẹ, o n reti ki wọn ma fi han awọn ọmọ ijọ wọn pe sisin Ọlọrun lere lori. Ìsọlẹ́nu!

Siwaju si, awọn ọmọ ijọ yi naa yẹ ki wọn ka igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ijọ yi si pataki. Wọn ṣa mọ wipe ko ki i ṣe pe ere ni wọn n ṣe kiri. Wọn mọ wipe nitori wọn ni ijọ wọn ṣe n ṣe aṣeyọri lori awọn ojuṣe rẹ. Bi o tilẹ wa je wipe wọn n ri wipe ọpọ ninu awọn oṣiṣẹ yi ni o n tiraka lati gbe aye, nṣe ni wọn yoo ma duro de igba ti wọn ba n bẹbẹ fun iranlọwọ wọn dipo ki wọn jẹ ki Ọlọrun lo wọn lati mojuto igbayegbadun wọn. Sibẹsibẹ awọn ni ariwo wọn pọ ju pe awọn oṣiṣẹ ijọ wọn ko ki i duro nitoripe pasitọ wọn ko mojuto wọn. O ma ṣe o!

Ka ma fọrọgun, mo sọ eyi fun ọ lati jẹ ki o mọ wipe iha ti a ba kọ si si igbayegbadun awọn iranṣẹ Ọlọrun le jẹ ki wọn pa iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun wọn ti tabi ki o sọ wọn di alaiṣododo iranṣẹ. Njẹ o mọ wipe gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o yẹ ki o ma ṣiṣẹ ninu tẹmpili Ọlọrun ni asiko Nehemaya ti fi igbakan ri fi iṣẹ wọn silẹ lati lọ ma a ṣiṣẹ bi agbẹ, oniṣowo ati bẹẹbẹẹ lọ? Ki ni idi? Idi ni pe awọn eniyan pa igbayegbadun wọn ti ṣẹgbẹ kan. Nehemaya wa nilo lati da si ọrọ naa ati lati ba awọn adari awọn eniyan naa wi gidigidi ki wọn to bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ. (Wo: Nehemáyà 13:11-13)

Wayi o, mo gbagbọ nitemi pe ka sọ wi pe a lọ ri enikan bi Nehemaya ninu ijọ ti mo mẹnuba loke yen ni, ẹni ti yo ba awọn ọmọ ijọ naa ati pasitọ wọn wi fun bi wọn ko ṣe mojuto igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ijọ wọn, ọpọ ninu awọn ti o kuro ni ko ba duro, ti wọn ko ba si tẹsiwaju lati ma sin Ọlọrun ati ijọ naa pẹlu otitọ. Ṣugbọn ko si ẹnikankan. Nitorina, wọn sọ ọpọ oṣiṣẹ daradara ati olotitọ nu.

Nibakana, ayafi ti ọpọ ninu wa ati ọpọ ninu awọn adari ijọ wa ba gba ibawi ti o ga lori iha ti a n kọ si igbayegbadun awọn iransẹ Ọlọrun ti o wa ni laarin wa, a ko ni yi iwa wa pada. Niwọn igba ti a ko ba si yi iwa wa pada, ko si ni ki a ma ma a padanu ọpọ ti ko ba jẹ iranṣẹ Ọlọrun ti o ga nu sinu oniruuru okowo ati sọwọ oniruuru ile-isẹ aye yi.

Njẹ eyi yoo wa mu inu Ọlọrun dun bi? Rara o! Ṣugbọn yoo nilo lati duro naa ni titi yoo fi ri awọn ti ko ni jẹ ki aikọbiara wa si igbayegbadun wọn di wọn lọwọ lati ṣiṣẹ rẹ. Ta wa lo mọ asiko ti eyi yoo gba a? Ko si ẹni naa. Idi si ni yi ti gbogbo wa fi gbọdọ sọji, ki a si bẹrẹ si ni mu itọju gbogbo awọn ti Ọlọrun n lo lati ṣiṣẹ rẹ ati lati bukun fun wa lọkunkundun. Njẹ ki Ọlọrun fun wa ni okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má pa ìgbáyégbádùn wọn ti | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 42 Read More »

Má fi ìrẹ̀wẹ̀sì ṣe Wọ́n | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 09, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 41

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2025. Adura mi si nipe ki Ọlọrun ya ọ ya gbogbo àṣà ti o le sọ ọ di oludena fun ilọsiwaju ijọ Ọlọrun tabi awọn miran ti o wa ninu aye rẹ. Amin.

Ninu iwe Nọmba, ori 32, Mose sọ eyi fun awọn ẹya Gadi ati Rubẹni:

“Mose sọ fun awọn ọmọ Gadi ati fun ọmọ Rubẹni pe, “Ṣe ki awọn arakunrin yin lọ si ogun, ki ẹyin ki o si joko si bi? Ki ni o de ti o fi mu irẹwẹsi ba awọn ọmọ Isirẹli lati lọ si ibi ilẹ ti Oluwa ti fi fun wọn? Eyi ni nnkan ti baba yin ṣe nigba ti mo ran wọn lati Kadesi-Baniya lati lọ wo ilẹ naa. Lẹyin igba ti wọn lọ si Afonifoji Esikolu ti wọn ri ilẹ naa, wọn mu irẹwẹsi ba awọn ọmọ Isirẹli lati wọ ilẹ ti Oluwa ti fi fun wọn.”” (Nọ́ḿbà 32:6-9)

Ki ni idi ti o ṣe sọ awọn ọrọ kobakungbe yi si wọn? Idi ni pe wọn tọrọ lati ni ipin ilẹ ti wọn ki gbogbo orilẹ-ede naa to rekọja Odo Jọdani lati gba ilẹ Kenani ti Ọlọrun fẹ fi fun wọn. Mose si ri eyi gẹgẹ bi àmì aiṣododo ati igbesẹ lati fi irẹwẹsi mu awọn eniyan naa lati ma tẹsiwaju lati gba ilẹ ti Ọlọrun fẹ fi fun wọn. Nitorina, o bẹrẹ si ni ba wọn wi gidigidi.

Amọ ṣa o, awọn eniyan yi tọrọ nkan ti wọn tọrọ nitoripe wọn ri wipe ilẹ ti o wa ni odikeji Odo Jọdani dara jọjọ fun ọsin ẹran. Awọn si ni ọpọlọpọ agbo maalu ati agbo aguntan. Ki wa lo fa ti Mose ṣe binu si wọn debi wipe o bẹrẹ si ni ba wọn wi? Idi ni pe ko fẹ ki wọn jẹ idi ti irẹwẹsi yoo ṣe mu awọn yoku lati ma lọ fun ohun ti Ọlọrun fẹ fun wọn, ki wọn si tipasẹ eyi ko sinu iyọnu.

Bi Mose ti ṣe fi han wọn, idi ti gbogbo wọn ṣe di ẹni ti o n ranmu lori aṣalẹ fun ogoji ọdun ni pe mẹwa lara awọn ọkunrin mejila ti wọn ran lati ṣe aamí ilẹ ti Ọlọrun fẹ fun wọn ni o mu iroyin ibi ati irẹwẹsi tọ awọn eniyan naa wa. Nitori awọn mẹwa yi si wa ni gbogbo orilẹ-ede ṣe jiya, ki a ko si gba wọn laye lati jẹgbadun ipese Ọlọrun fun wọn lẹkunrẹrẹ fun ogoji ọdun. Ti ọkunrin mẹwa pere ba wa le jẹ ki odidi orilẹ-ede jiya fun ogoji ọdun, wa wo irufẹ iṣoro ti odidi ẹya meji lara wọn le mu wa si ori wọn. Idi si ni yi ti Mose ṣe tete yari fun wọn.

Ni kukuru, awọn eniyan yi fi Mose lọkan balẹ lati ma yọnu rara. Wọn sọ fun wipe awọn ko tẹru ti yoo fi irẹwẹsi ṣe awọn eniyan wọn lati ma ri ipese Ọlọrun ti o darajulọ fun wọn gba. Dipo eyi, nṣe ni awọn yoo fi awọn ẹbi awọn silẹ, ti awọn yoo si tẹsiwaju pẹlu wọn lati wọ Ilẹ Ileri naa titi ẹya kọọkan yoo fi gba ilẹ ini tirẹ. Bẹẹ gẹgẹ ni wọn si ṣe. (Wo: Jọ́súà 22:1-9)

Irufẹ ẹkọ wo wa ni a ri kọ ninu gbogbo eyi? Akọkọ, oun naa ni pe ki a ma a ṣọ bi awọn ọrọ ati igbesẹ wa ṣe le pa awọn ti o wa ninu aye wa lara, paapaa julọ awọn eniyan Ọlọrun. Lotitọ, a le ni awọn idi ti o dara ti a fi fẹ sọ tabi ṣe ohun ti o wa lọkan wa. Ṣugbọn ni asiko ti nkan ti a o sọ tabi ṣe ba a le fi irẹwẹsi mu awọn miran tabi ti o ba le kun wọn pẹlu ilọwọwọ, ki wọn si ri jinna si nkan ti Ọlọrun ti ṣeto fun wọn, a nilo lati sọ ara wa. Aijẹbẹ, a le pada wa jẹ idi ti aye wọn ati aye ti awa naa pẹlu yoo fi wa ni ojukanna titi lailai.

Ekeji, nibi ti a ba ti ri wipe awọn ti o wa ninu aye wa n ṣe nkan ti yoo fi irẹwẹsi sinu wa tabi sinu awọn miran, nṣe ni o yẹ ki a sọrọ soke, bi Mose ti ṣe ṣe. Lotitọ, awọn wọnyi le ni idi ti o dara fun nkan ti wọn n ṣe. Amọ ti a ko ba sọrọ soke, ki a si jẹ ki wọn ṣe alaye ara wọn, a le ma mọ boya o yẹ ki a fi ààyè gba wọn tabi ki a yari fun wọn pẹlu iduro-ṣinṣin. Eyi si le jẹ ki Satani ri ààye lati lo wọn lati sọ irinajo si igbega ati isinmi ti ko pẹ di eyi ti o gun gbọọrọ tabi eyi ti ko ni ṣeeṣe rara mọ wa lọwọ.

Ẹkẹta, ti awọn kan ti wọn ni awọn idi ti o tọ lati gba pe awọn igbesẹ wa yoo di wọn lọwọ tabi da wahala silẹ fun wọn laye ba ko wa loju, nṣe ni ki a fi suuru ati irẹlẹ ti o peye ṣalaye ara wa fun wọn. Aijẹbẹ, a le sọ nkan ti o bajẹ di balumọ. Ti awọn eniyan Gadi ati Rubẹni ba lọ yan lati ma ba a Mose jiyan ni, dipo ti wọn yoo fi ṣalaye ara wọn, o ṣeeṣe ki o gbadura si Ọlọrun lodi si wọn. Eyi si le jẹ ki wọn gba idajọ ti o kira lọwọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Datani, Kora ati awọn ti o wa pẹlu wọn ṣe gba idajọ ni ọwọ rẹ. (Wo: Nọ́ḿbà 16)

Nitorina, ma tọ ara rẹ lati ma jiyan pẹlu awọn eniyan ti wọn ba fi ẹsun kan ọ lori ọrọ kankan. Dipo eyi, nṣe ni ki o ma fi suuru ati irẹlẹ ṣalaye ara rẹ fun wọn. Nipa eyi, iwọ yoo le wo ibaṣepọ rẹ pẹlu wọn ṣan, dipo ti o o tun fi ba a jẹ si. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ma fi igba gbogbo kun ọ pẹlu ọgbọn ati okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má fi ìrẹ̀wẹ̀sì ṣe Wọ́n | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 09, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 41 Read More »

Àkórí: Fọwọ́sowọ́pọ́ pẹ̀lú rẹ̀Láti ọwọ́: J.O. LawalỌjọ́: Èrèlé 02, 2025Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀Nọ́múbà: Vol. 13, No. 40

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu keji ọdun yi, iyẹn oṣu Èrèlé 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun, nipasẹ Ẹmi rẹ ti o wa ninu rẹ, jẹ ki o rẹ ara rẹ silẹ niwaju rẹ, ki O ba a le dari rẹ lati ni iriri ẹkunrẹrẹ ojurere ati didaara rẹ ninu gbogbo oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ wọnyi lati inu ọkan lara awọn saamu Dafidi:

“Emi yoo kọ ọ, emi yoo si fi ẹṣẹ rẹ le ọna iwọ yoo rin. Emi o gba ọ ni iyanju, emi yoo si maa fi oju mi tọ ọ. Ma ṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti ko ni oye, ẹnu ẹni ti a gbọdọ fi ijanu bọ, ki wọn ma ba a sun mọ ọ.” (Sáàmù 32:8-9)

Tani o n sọrọ nibyi? Ọlọrun! Tani O n ba a sọrọ? Emi! Iwọ! Gbogbo wa! Ki si ni O n ba wa sọ? Akọkọ, O n sọ fun wa pe Oun ṣetan lati tọ ati lati kọ wa ni ọna ti o yẹ ki a gba laye. Eyi jasi pe ko ki i ṣe gbogbo ọna ti a ba gba laye yi naa ni yoo yọri si ibalẹ-ọkan ati iṣoriire fun wa. O ni ọna pato ti o yẹ ki a gba lati ni awọn nkan wọnyi. Ẹnikanṣoṣo ti O si mọ ọna yi, ti O si tun le dari wa sinu rẹ naa ni Ọlọrun, ẹlẹda wa.

Nkan keji ti Ọlọrun sọ ni pe Oun yoo ma a gba wa niyanju, Oun yoo si tun ma a daabo bo wa. Eyi tunmọ si pe O ṣetan lati ri daju wipe ọrọ aye wa ko lailai dojuru ati wipe a ko lailai wa lalai si aabo. Ki wa ni a nilo lati ṣe lati jẹgbadun ẹkọ, itọni ati aabo rẹ ni ojoojumọ aye wa? A kan nilo lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ni. Njẹ a o wa fọwọsowọpọ pẹlu rẹ? Ṣe iwọ yoo fọwọsowọpọ pẹlu Ọlọrun lati dari rẹ lati jẹgbadun ipesẹ rẹ ti o dara-julọ fun aye rẹ?

Bi a ti ṣe ri ninu ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yẹn, Ọlọrun kilọ fun wa lati ma jẹ alagidi bi awọn ẹranko. Ki ni idi? A ko ki i ṣe ẹranko. Eniyan ti a da ni aworan ati irisi rẹ ni a jẹ. Nitorina, a ni oye, a si wa ni ipo ẹni ti O le kọ, ti O si tun le dari. Awọn ẹranko ko ni oye. Nitoripe wọn ko ni oye, o ko le ṣalaye nkan fun wọn tabi jiroro pẹlu wọn. Nitorina, o nilo lati tan wọn jẹ tabi mu wọn ni tipatipa lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ. Aijẹbẹ, o ko ni i le mu wọn ṣe ohun yowu ti o fẹ ki wọn ṣe fun ọ.

Nibakanna, ti a ba yan lati ma ṣe bi ẹranko ninu ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun, ko ni i le fi irọrun kọ wa tabi dari wa lati ni iriri alaafia ati iṣoriire ninu aye wa bi O ti ṣe fẹ. Eyi wa jasi pe ti yoo ba ri ohun rere kankan gbeṣe ninu aye wa, yoo nilo lati mu wa gbọran si lẹnu ni ọna ti o le. Amọ ko ki i ṣaba ṣe eyi. Idi si nipe ko si aridaju pe a o gbọran si lẹnu, bi O tilẹ mu wa kẹkọ lọna ti o le.

Fun apẹrẹ, mo ti igbakanri fi wakati melokan gba enikan nijanju lori igbeyawo rẹ. Ṣibẹṣibẹ, nṣe ni o lọ ọ ṣe idakeji ohun ti mo sọ fun un. Nibayi, igbeyawo rẹ meji ọtọọtọ lo ti forisanpọn. Ti o ba si tun wa tun ọkọ miran fẹ loni, ko si aridaju pe igbeyawo tuntun naa ko tun ni forisanpọn. Idi si ni pe igba ti o ba to bẹrẹ si ni gbọran si Ọlọrun lẹnu ni yoo too dẹkun lati ma kẹkọ lọna ti o le.

Mo ba ọ sọ eyi ki o ba a le mọ wipe Ọlọrun ko fẹ ki a kọ ohunkohun laye yi ni ọna ti o le. Idi si ni pe a tilẹ le ma wa laye lati pitan rẹ. Nitorina, O fẹ kọ wa, dari wa ati daabo bo wa. Amọ a gbọdọ ya ara wa ya ohun gbogbo ti o n jẹ agidi, ki a si rẹ ara wa silẹ lati kẹkọ lọdọ rẹ ati lati ma a tẹle. Mo si gbadura pe ki gbogbo wa ma fi ojoojumọ ri okun gba lati ṣe bẹ ẹ gẹgẹ. Amin.

Kí o ní oṣù Èrèlé 2025 alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àkórí: Fọwọ́sowọ́pọ́ pẹ̀lú rẹ̀Láti ọwọ́: J.O. LawalỌjọ́: Èrèlé 02, 2025Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀Nọ́múbà: Vol. 13, No. 40 Read More »

Kí ọjọ́ ibi tó dé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 39

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Sẹrẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọ ni iwuri lati ma ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ rẹ lati jẹ alagbara ninu rẹ, ki ọjọ ibi kankan ma ba bori rẹ. Amin.

Ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, Pọọlu sọ wipe, “Nitori naa, ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹyin le duro tiiri si ọjọ ibi, nigba ti ẹyin ba si ti ṣe ohun gbogbo tan ki ẹ si duro.” (Éfésù 6:13) Ki ni aṣẹ si awọn eniyan Ọlọrun nibiyi? Oun naa ni pe ki wọn gbe gbogbo imọra Ọlọrun wọ. Eyi jasi pe ki wọn ṣe amulo ohun yowu ti Ọlọrun ti pese fun aabo wọn lati da aabo bo ara wọn. Nitorina, eyi ko ki i ṣe nkan ti Ọlọrun yoo ṣe fun wọn; dipo bẹẹ, o jẹ nkan ti wọn yoo ṣe fun ara wọn.

Wayi o, ki ni idi ti o ṣe ṣe pataki ki awọn eniyan Ọlọrun ṣe eyi? Oun naa ni ki wọn ba a le duro ṣinṣin nigba ti ọjọ ibi ba de. Nitorina, daju-ṣaka ni pe awọn ọjọ ibi kan yoo tọ ọmọ Ọlọrun kọọkan wa. Lotitọ, ko si ọjọ kan ti ko ni ibi ninu rẹ, o kere tabi o pọ. Ṣugbọn awọn ọjọ kan a ma a wa ninu eyi ti o jẹ wipe a n taari awọn ibi kan si ọkọọkan ninu wa. Nitori irufẹ awọn ọjọ wọnyi gan ni a ṣe nilo lati wa ni aabo pẹlu ihamọra Ọlọrun.

Fun apẹrẹ, asiko kan wa ti awọn kan kora wọn jọ papọ lati gbogun ti Daniẹli lati parun. Lọna wo? Nipa titan Ọba Darusi jẹ lati pasẹ pe ki gbogbo awọn ti o wa ninu ijọba rẹ ma ṣe gbadura si ọlọrun-kọlọrun kankan ayafi oun. Bi aṣe naa si ṣe sọ, aigbọran si i yoo sọ ẹni ti ọrọ ba kan di ero inu iho kiniun. (Wo: Dáníẹ́lì 6:1-9)

Ki wa lo fa ti awọn ọkunrin yi ṣe gbe irufẹ igbese yi? Idi ni pe wọn mọ pe idi ti awọn ko ṣe ri Daniẹli parun ṣaaju asiko naa ni pe o jẹ aladura ati ẹnikan ti o bẹru Ọlọrun. Nitorina, ero wọn ni pe ti awọn ba le di lọwọ lati ma gbadura fun o kere ju oṣu kan, o yẹ ki ọwọ awọn le tẹ ẹ, ki awọn si ri parun. Ti o ba si wa tẹsiwaju lati ma a gbadura, lodi si aṣẹ ọba, a jẹ wipe inu iho awọn kininu ni yoo ti ba ara rẹ niyẹn. Nitorina, ni ti wọn o, ko si ọna abayọ rara fun ọkunrin naa.

Amọ wọn kuna. Wọn kuna nitoripe Daniẹli ko lailai dẹkun lati ma a gbadura si Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe eyi tako aṣẹ ọba. Dipo bẹẹ, nṣe ni o tẹsiwaju lati ma a gbadura ati lati ma a gbadura lọna ti awọn ọta rẹ gan yoo fi mọ wipe o n gbadura. Ṣugbọn ọjọ ibi ni asiko yi jẹ fun un. Ọjọ ti gbogbo awọn ika ijoye Ọba Darusi gbogun ti ni. Ọjọ ti ọba funrarẹ gan ko le ran an lọwọ tabi gbala ni o jẹ. (Wo: Dáníẹ́lì 6:10)

Ki lo wa fa ti o fi tẹsiwaju lati ma a gbadura si Ọlọrun? O tẹsiwaju lati ma a gbadura si i nitoripe o ti ri daju-daju pe Ọlọrun ni ohun gbogbo fun oun. Ọkunrin yi ti n ṣe aṣaro lori ọrọ Ọlọrun, ti o si tun gbadura fun ọpọ ọdun saaju asiko yi. Eyi si ti gbe igbagbọ rẹ ro debi wipe ko si ihalẹ ẹnikẹni ti o le mi i. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo eniyan gbogun ti lasiko naa, ko tilẹ mira rara. Idi si ni pe o mọ wipe Ọlọrun le pa oun mọ.

Ṣe Ọlọrun wa pa a mọ tabi ko pa a mọ? Ọlọrun ma pa a mọ, O si tun dojuti gbogbo awọn ọta rẹ. Ṣugbọn ka wa sọ wipe ko ma gbe igbagbọ rẹ ro ki ọjọ ibi yi to de nkọ? Njẹ ko ni di ẹni iparun bi? Yoo fẹrẹ di ẹni iparun.

Ki gan wa ni koko nkan ti a n sọ? Oun naa ni pe ko yẹ ki a duro de ọjọ ibi ki a to bẹrẹ si ni gbe igbagbọ wa ninu Ọlọrun ro tabi ki a to bẹrẹ si ni wa aabo rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, a le e ma ranti tabi ki a ma ni igboya to lati wa aabo Ọlọrun nigba ti ọjọ ibi ba de, ti ko ba ti mọ wa lara tẹlẹ lati ma fa aye wa le e lọwọ.

Iwọ naa ro eyi wo: Njẹ eni ti ko ni gbadura nigba ti ko si ofin ti o lodi si adura gbigba yoo gbadura bi, ti ofin ba a le wa ti o lodi si i? Ko fẹrẹ jọ bẹẹ! Nitorina, ko ni fẹ ṣeeṣe ki o fi igbagbọ ninu Ọlọrun han lọjọ ibi, igbagbọ ti o ko ni ninu rẹ ni asiko ti nkan rọrun fun ọ. Idi niyi ti o fi jẹ pe nisinsinyi gan an ni o yẹ ki o gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ. Aijẹbẹ, o ko ni ni idahun fun eṣu nigba ti ojọ ibi ba de.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kí ọjọ́ ibi tó dé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 39 Read More »

Kìkì àwọn péréte | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Sẹrẹ 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun sọ ọ ji lati ṣe idamọ gbogbo ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati bẹrẹ si ni ṣe wọn lalai dẹsẹ duro. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si Timoti, sọ eyi fun un: “…Ṣe iṣẹ rẹ laṣepe.” (2Tímótì 4:5) Ki ni idi ti o ṣe sọ eyi fun un? O sọ eyi fun un nitoripe o mọ daju pe o mọ iṣẹ iranṣẹ rẹ ati awọn ojuṣe ti o soro mọ-ọn. Ti Timoti ko ba mọ ojuṣe iṣẹ iranṣẹ, ko si bi yoo ṣe le mọ-ọn-mọ mu wọn ṣẹ. Lotitọ, o le ṣeesi ṣe diẹ lara ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ, bi ko tilẹ mọ wọn. Ṣugbọn ko si bi o ṣe le mọ-ọn-ọn ṣe awọn ojuṣe ti ko mọ rara gẹgẹ bi ojuṣe rẹ laṣepe.

Wayi o, ti Timoti ko ba wa ma a ṣe awọn ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe, Ọlọrun ko ni i le bukun fun ẹnikọọkan ti O fẹ tipasẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ bukun fun bi O ti ṣe fẹ. Ṣe inu Ọlọrun yoo si dun si eyi bi? Rara, inu rẹ ko ni dun si. Nitorina, nṣe ni yoo nilo lati wa awọn ọna ti yoo gba sọ ọ ji lati ṣe gbogbo nkan ti o yẹ ki o ṣe tabi ki O wa awọn miran ti wọn yoo ṣe ohun ti o yẹ ki o ṣe ṣugbọn ti o n pati.

Nibakanna, Ọlọrun n reti ki ọmọ rẹ kọọkan ninu ijọ loni ṣe idamọ awọn ojuṣe iṣẹ iransẹ rẹ, ki o si bẹrẹ si ni ṣe wọn. Aijẹbẹ, ko ni le bukun fun awọn ti O fẹ tipasẹ rẹ bukun fun. Ibi ti eyi ba si ti ribẹ, yoo nilo lati wa ọna lati sọ wọn ji lati ṣe awọn iṣẹ ti wọn n pa a ti tabi lati wa awọn miran ti wọn yoo ṣe e.

O wa ṣeni laanu pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun n ṣe ohun gbogbo ti O le ṣe lati sọ ọpọ wa ji si awọn nkan ti o jẹ ojuṣe iṣẹ iransẹ wa, ọpọ igba ni a ko ki i ṣetan lati sọji nitori ibẹru, imẹlẹ, ailepa-ọkan-pọ, ojukokoro tabi aimọkanmọkan. Nitorina, ọpọ igba, ni Oun naa ma n nilo lati pe awọn miran lati ṣe awọn nkan ti a n kọ lati ṣe. Idi si niyi ti o fi jẹ wipe, ni ọpọ awọn ijọ Kirisitiẹni, awọn perete ti o fi ara wọn jin fun ọrọ Ọlọrun naa ni o tun ma n ṣaba fi ara wọn jin fun adura gbigba, ibẹwo, ififunni ati mimojuto awọn ile ijọsin wọn.

Fun apẹrẹ, ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinti, o sọ eyi fun wọn: “Mo layọ fun wiwa Sitefana ati Foritunatu ati Akayaku: nitori eyi ti o ku nipa ti yin wọn ti fi kun un.” (1Kọ́ríntì 16:17) Njẹ o ri bayẹn? Daju-ṣaka ni pe alagba ijọ Kọrinti ni awọn ọkunrin mẹta wọnyi. Eyi jasi pe wọn gbọdọ ni ọpọlọpọ ojuṣe ti wọn n gbe ni asiko naa. Sibẹsibẹ, bi ijọ Kọrinti yoo ti tobi to ni asiko yẹn, awọn ọkunrin mẹta yi i naa ni o tun fi nkan ini wọn ran Pọọlu lọwọ lati mojuto nkan ti gbogbo ijọ wọn yẹ ki o ṣe.

Njẹ eyi wa jẹ nkan ti o dara lati ma ṣẹlẹ ninu ijọ Ọlọrun kankan? Rara o! Ṣe awọn perete ni o yẹ ki wọn ma gbe gbogbo ẹru ti o yẹ ki gbogbo awọn ọmọ ijọ wọn ma a gbe? Rara o! Ṣe ko tilẹ ṣeeṣe ki o rẹ awọn perete wọnyi tabi ki irẹwẹsi mu wọn ni asiko kan, ki wọn si ma fẹ ṣe nkankan mọ? O ṣeeṣe. A si ti ri awọn eniyan ti irẹwẹsi mu, ti wọn si dẹkun lati ma lọ si awọn ipade ijọ wọn patapata nitoripe ẹru ti wọn n gbe wọ wọn lọrun.

Siwaju si, bi irẹwẹsi ko tilẹ mu awọn wọnyi, ṣe ko ki i ṣe awọn nikan ni Ọlọrun yoo pin ni ere ti o ye ki o jẹ ti gbogbo ijọ wọn? Awọn nikan naa ni yoo pin ni ere yi. Idi si ni pe Ọlọrun ko ni lailai pin eniyan lere fun ohun ti ẹni naa ko ba ṣe fun un. Yatọ si iyẹn, idagbasoke ati ilọsiwaju ijọ ninu eyi ti o jẹ wipe awọn perete nikan ni o ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ ṣiṣe yoo lọra. Eyi yoo si jẹ ki o ri idi ti a fi ni ọpọlọpọ ijọ ni ilẹ wa ti wọn ti wa fun ọpọ ọdun ṣugbọn ti wọn si tun jẹ èwe ninu isesorere ati iwulo.

Ni kukukru, mo n sọ awọn nkan wọnyi fun ọ lati jẹ ki o mọ wipe ko ki i ṣe nkan ti o dara ni fun wa gẹgẹ bi ijọ lati fi awọn nkan ti o yẹ ki gbogbo wa ma a ṣe fun Ọlọrun silẹ fun awọn kiki awọn melokan lati ṣe. Ti eyi ba si ri bẹ, a jẹ wipe a ti n ṣeesi di idagbsoke ati iwulo ijọ wa lọwọ niyẹn ati wipe o ṣeeṣe ki a tilẹ ti ma fi irẹwẹsi kun ọkan awọn kọọkan larin wa. Nitorina, a nilo lati ronupiwada, ki a si bẹrẹ gbe ojuṣe wa ninu adura gbigba, ififunni, ibẹniwo ati bẹẹbẹẹ lọ. Nigba naa ni ijọ waa yoo bẹrẹ si ni dagbasoke ati pọ si ni iwulo bi o ti ṣe tọ, nigba naa si tun awa naa ko ni padanu ere wa si ọwọ awọn miran.

Ki o ni ọsẹ atata.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kìkì àwọn péréte | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 38 Read More »