O ní láti ṣe tán | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 28, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 35
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so ọdun yi, 2025, pọ mọ ọdun ti o n bọ, 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati lọ si inu ọdun tuntun naa, ki o si ṣaṣeyọri ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi gbogbo wa ti ṣe mọ, nṣe ni a ma n dagba si pẹlu ọjọ kọọkan ti Ọlọrun ba fi kun aye wa. Ṣugbọn bi o ti wu ki a dagba to laye yi, igba gbogbo ni Ọlọrun ma n ni ohun tuntun ti O fẹ ṣe fun wa tabi fi fun wa. Iṣetan wa ni yoo wa sọ boya ohun ti O fẹ ṣe fun wa tabi fi fun wa naa yoo pada jẹ tiwa nitootọ.
Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ eyi fun Jọsua nigba ti o ti dari awọn ọmọ Isiraẹli wọ inu ipin wa tan, ti o si tun ti di ògbó:
“JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.” (Jọ́súà 13:1)
Ki ni o de ti o jẹ wipe ọkunrin arugbo kan ni Ọlọrun n sọ awọn nkan wọnyi fun? Ki ni o de ti ko ma a sọ wọn fun awọn ọdọkunrin kan tabi omiran ni ilẹ naa? Idi ni pe Ọlọrun ko i ti ṣetan pẹlu Jọsua ni asiko naa, bi o tilẹ jẹ wipe o ti di ogbo. Niwọn igba ti oun naa ba si ṣetan lati tewọgba ohun yowu ti Ọlọrun fẹ ki o ni, ọjọ ori rẹ ko le jẹ iṣoro fun Ọlọrun.
Nibakanna, iye yowu ti ọjọ ori rẹ le jẹ lọdun yi tabi iye yowu ti ọjọ ori rẹ le jẹ ni ọdun ti o n bọ, Ọlọrun ko i ti ṣetan pẹlu rẹ, niwọn igba ti ẹmi ba si wa ni ẹnu rẹ. O si ni oniruuru ohun rere ati daradara ti O fẹ ṣe fun ọ ati ti O fẹ fi fun ọ. Ṣugbọn o ni lati ṣetan lati tẹwọgba ohun ti O fẹ ki o ni, ki o si ma lọ ọjọ ori rẹ gẹgẹ bi awawi lati padanu awọn ibukun rẹ.
Ma gbagbe pe Ọlọrun mọ iye ọjọ ori rẹ. Lafikun, O mọ gbogbo kudiẹ-kudiẹ rẹ. Niwọn igba ti ko ba si lo ọjọ ori rẹ tabi awọn kudiẹ-kudiẹ rẹ gẹgẹ bi awawi lati ma gbe ọ ga, fa ọ lọwọ soke tabi wo ọ san, iwọ naa ko gbọdọ lo wọn gẹgẹ bi awawi lati ma ni itẹsiwaju tabi lati ma a gbe ninu ailera laye. Dipo eyi, bi i Maria iya Jesu, nṣe ni ki iwọ naa tẹwọgba ohun yowu ti O fẹ ki o ni nipa sisọ wipe, “Jẹ ki o ri fun mi ni ibamu pẹlu ọrọ rẹ ati ifẹ inu rẹ.” Bi o si ṣe n ṣe eyi, iwọ yoo ri bi yoo ti ṣe pese ohun rere gbogbo ti o nilo lati ni iriri ẹkunrẹrẹ imuṣẹ ete rere rẹ fun aye rẹ fun ọ.
A ku imura ọdun tuntun o.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)