Kò gbọdọ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 10, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 15
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògùn 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun maa fi ojoojumọ kun ọkan rẹ pẹlu irẹlẹ, ki o ba a le tẹsiwaju lati ma ni iriri igbega rẹ ni gbogbo abala aye rẹ. Amin.
Lẹyin igba ti Ọba Sọọlu ti ṣe aigbọran si Ọlọrun nipasẹ pe ko pa gbogbo awọn ara Amaleki run, Samuẹli sọ eyi fun un:
“Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli?” (1Sámúẹ́lì 15:17)
Nigba wo ni Ọlọrun fi ami ororo sọ Sọọlu di ọba lori Isiraẹli? Ni igba ti o jẹ onirẹlẹ ni. Ni igba ti ko ri ara rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o san ju awọn miran lọ ni. Ṣugbọn lẹyin igba ti a ti fi idi itẹ rẹ mulẹ tan, o fi aye gba igberaga ninu ọkan rẹ, o si bẹrẹ si ni ṣe bi o ti ṣe wu u.
Njẹ iha wo wa ni Ọlọrun kọ si eyi? O gba ijọba ti O fifun un kuro lọwọ rẹ. O si fi ọdọmọkurin kan, iyẹn Dafidi, rọpo rẹ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe o ja fitafita lati pa ijọba naa mọ fun ara rẹ ati fun arọmọdọmọ rẹ, ko ri i pa mọ. Idi si ni pe kiki nkan ti Ọlọrun ba fun wa ni a le pa mọ fun ara wa. A ko le pa nkan ti O ba ti gba kuro lọwọ wa mọ fun ara wa.
Ni kukuru, koko itan bibeli yi naa ni pe irẹlẹ wa ko gbọdọ jẹ fun igba diẹ. Dipo eyi, nkan ti a gbọdọ ni lati ibẹrẹ de opin ni. Ti a ba fi irẹlẹ han niwaju Ọlọrun fun igba diẹ, nṣe ni igbesoke wa naa yoo wa fun igba diẹ. Eyi jasi pe, ni kete ti a ba ti bẹrẹ si ni fi igberaga han, Ọlọrun kanna ti O ti n gbe wa ga yoo bẹrẹ si ni ja wa bọ. (Wo: Jákọ́bù 4:6; 1Pétérù 5:5)
Eyi si wa ni idi ti awọn kan ko ti ṣe ga ju ipo ti wọn wa laye lọ. Nigba ti wọn rẹ ara wọn silẹ niwaju Ọlọrun, O ṣaanu fun wọn, O si bẹrẹ si ni gbe wọn ga. Ṣugbọn nigba ti wọn de awọn ipo nla kan, wọn bẹrẹ si ni ṣiwawu. Wọn bẹrẹ si ni ṣe bi igba ti o jẹ wipe ọgbọn tabi agbara wọn ni o gbe wọn de ibi ti wọn wa. Nitorina, dipo ki Ọlọrun gbe wọn lọ si ibi ti o ga ju ibi ti wọn wa lọ, nṣe ni O fi wọn silẹ sibẹ, ti O si bẹrẹ si ni gbe awọn miran ni ayika wọn ga. Ti wọn ba si wa tẹsiwaju lati ma a rin ninu igberaga, a le pada re wọn jabọ si awọn aye ti o kere ju ibi ti wọn wa lọ.
Nitorina, irẹlẹ ko ki i ṣe nkan ti a kan nilo ki Ọlọrun ba a le gbe wa ga nikan; a tun nilo rẹ lati le jẹ ki O ma ba a jẹ ki jabọ kuro ni ibi giga ti O fi wa si. Nitori eyi, fi ara rẹ sipo irẹlẹ niwaju rẹ. O ko si ni lailai ni idi kankan lati bẹru pe yoo re ọ jabọ.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)




